Go to full page →

Kínni ó Ń dá Ìpọ́njú Dúró IIO 159

Aposteli Pọọlu sọ wipe “gbogbo àwọn tí yóò gbé ìgbé ayé ìwà Ọlọrun nínú Kristi ní láti rí ìpọnjú”. Kínni ó wá ń dá ìpọnjú dúró? Ìdí kanṣoṣo náà ni wípé ijọ ti darapọ mọ àgbékalẹ ayé tóbẹẹ ti kò si ohunkóhun tí ó ń mú àtakò wá láti ọdọ ijọ si ayé. Irú ẹsìn ti ó gbòde kan báyìí kì í ṣe èyí ti ó jẹ mimọ gẹgẹ bi irú èyí ti o fi igbagbọ àwọn Kristẹni ti ìgbà ayé Jésù ati awọn aposteli hàn. Òtítọ ọrọ Ọlọrun ti a kò fi ìtara ati ẹmi mimọ sọ fún awọn ènìyàn èyí ti o ti tipasẹ bẹẹ mú ki ọrọ Ọlọrun ó má ní iyatọ léti awọn ènìyàn nitori pé a kò fi bẹẹ rí ìwà bí Ọlọrun bí ó ti wù ki o kéré tó ninu ijọ mọ ati wipe Onigbagbọ ti faramọ ayé ninu ìwà ese, eyi ti o ti wa mu awọn Onigbagbọ gbajumọ ninu aye. O yẹ ki isọji ti Igbagbọ ati ti agbára ó bẹrẹ bayìí gẹgẹ bi o ṣe wa ninu ijọ akọkọ ki eleyi baa le mu ẹmi ipọnju o sọji.-The Great Controversy, p. 48. IIO 159.4