Go to full page →

Ìkìlọ̀ Fún Àwọn Òṣìṣẹ́ IIO 169

Fún gbogbo àwon tí ó fé gba isé ìránsé rẹ̀ pàtàkì pèlú ìràn lówó ìwé tí a kó fún lílò ìpolongo ìkórè yìí. N so pé: E se takuntakun kí e sì wà lábé ìtoni Èmí Mímó. Ẹ jẹ́ kí isé ìgbàgbó yín ó máa lé sí. Jẹ́ kí àwon tí ó ní èbùn ogbón ó sìsé láti gba àwon aláìgbàgbò tí ó wà ní ibi gbogbo là. Ẹ se àwárí àwon okàn tó ń s’ègbé. Ẹ ronú lórí ìfé okàn Kristi láti mú àwon asáko padà sílé. E kíyèsí àwon òkàn gbogbo gégébí enití yóò jíyìn. Nínú isé ìhìnrere yín nínú ìjo ní tàbí níbikíbi, ẹ jẹ́ kí ìmólè yín ó tàn tóbéè geẹ́ tí enikéní kí yóò lè takò yín ní ìdájó kí ó si sọ wípé, “Ẹ̀ é se tí èyin kò fi sọ òtító náà fún mi?” tàbí, Ẹ é se tí ẹ kò fi bìkítà fún okàn mi? Ẹ jé kí á sá ípa wà láti ṣe alábàpín àwon ìwé wa pèlú àwon tí kìí se omo ìjo wa. Ẹ jé kí á lo gbogbo àńfaàní tí a bá ní láti bá àwon aláìgbàgbó sòrò kí a sì máa fún gbogbo okàn tí ó bá se tán ní àwon ìwé wá. Ẹ jé kí á ya árà wá sí mímò fún ìpolongo ìhìnrere. “Ẹ pèsè ònà sílè fún Olúwa kí e sì se ònà tí ó tó fún Olúwa ní aginjù.-MS, Consecrated Efforts to Reach Unbelievers, June 5, 1914. IIO 169.1