Go to full page →

Ìdánilójú Wà Fún Èsì Ayọ̀ IIO 204

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìyanu tòótọ́ nínú ojúlọ́wọ́ ìyípadà ọkàn tí kò tii lè yà wá nísìsìnyìí ni yóò ṣẹlẹ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn ńlá ńlá wọ̀nyìí ni wọ́n wà ní ìkáwọ́ Ọlọ́run. Tí àwọn òṣìṣẹ́ tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Rẹ̀ bá ń ṣiṣẹ́ wọn tọkàn tọkàn tí wọ́n sì ń lo àwọn àǹfààní tí ó sì ṣìlẹ̀ fún wọn, Ọlọ́run yóò yí ọkàn àwọn ènìyàn ńlá tí wọ́n wà ní àwọn ipò gíga wọ̀nyìí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́ ọ̀pọ̀ ni wọn yóò gba àgbékalẹ tí ọ̀run. Nígbà tí wọ́n bá ti gba òtítọ́ gbọ́, àwọn náà yóò padà di ohun èlò tí ń fi òtítọ́ yìí kọ́ ni lọ́rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn náà yóò ní ọkàn ìtara fún àwọn elẹ́gbẹ́ wọn tí àwọn ènìyàn tí fi ojú parẹ́. Ìjọ yóò máa dàgbà pẹ̀lu agbára nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi owó àti àkókó wọn jìn fún iṣẹ́ Olúwa.-The Acts of Apostles, p. 140. IIO 204.1

Ní ìgbà ìkẹhìn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé àti òṣèlú, àwọn ènìyàn pàtàkì ní àgbáyé yóò máa yà kúrò nínú òtítọ́ nítorí ayé kò mọ Ọlọ́run. Síbẹ̀, ó yẹ kí àwọn òṣìṣé Ọlọ́run máa lo gbogbo àǹfààní láti sọ òtítọ́ yìí fún àwọn ènìyàn wọ̀nyìí. Àwọn mìíràn yóò gbà wípé àìmọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ó ń dà wọ́n láàmú, wọ́n yóò sì gbà láti kọ́ ẹ̀kọ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ Jésù èyí tí í ṣe Olùkọ́ Àgbà jùlọ.-The Acts of Apostles, pp. 241-242. IIO 204.2