Go to full page →

Ìyìn àti Ọpẹ́ IIO 213

Yínyin Ọlọ́run pẹ̀lú ọkàn wa dàbí ìgbàtí a bá ń gbàdúrà. Ó yẹ kí a fihàn fún gbogbo àgbáyé wí pé a mọ rírì ìfẹ́ ńlá Ọlọ́run fún ìran ọmọ ènìyàn àti wí pé a tún ń retí àgbàyanu ẹ̀kúnrẹrẹ ìbùkún Rẹ̀ tí kò lópin. Lẹ́hìn ìtújáde Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ̀ sí orí wa, ayọ̀ wa àti ìṣe ìsìn wa yóò pọ̀ ju bẹ́ẹ̀ lọ, ní pàtàkì jùlọ bí a ti ṣe ń rántí oore àti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ ńlá tí Ó ń ṣe nínú ayé àwọn ọmọ Rẹ̀. Iṣẹ́ yìí máa ń lé agbára Sàtánì padà. Wọ́n máa ń lé ẹ̀mí ìkùnsínú àti ìráhùn jáde, títí tí olùdánníwò yóò fi pàdánù ìjà rẹ̀. Wọn yóò ní ìwà èyítí yóò mú àwọn olùgbé ayé yẹ fún ilé ńlá Rẹ̀ ní ọ̀run. Irú ẹ̀rí báyìí a máa ní ipa lórí àwọn elòmííràn. Kò tún sí ọ̀nà mìíràn tí ó dára jùló láti jèrè àwọn ọkàn fún Kírísítì.-Christ’s Object Lesson, pp. 299, 230. IIO 213.2

Ọlọ́run fẹ́ kí a sọ nípa oore àti agbára Rẹ̀. À ń bu ọlá fún-un nígbà tí a bá ń fi ìyìn àti ọpẹ́ fún-un. Ó sọ wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá yìn Mi ń ṣe Mí lógo”. Bí àwọn ọmọ Ísrẹ́lì ṣe ń rin ìrìn àjò wọn ní àginjù bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń fi orin mímọ́ yin Ọlọ́run. Gbogbo àwọn òfin àti àwọn ìlérí Olúwa ni wọ́n fi ń kọ orin, bí wọ́n ti ń rin ìrìn àjò wọn. Àti ní Kénánì, bí wọ́n ti ń pàdé níbi àwọn àsè mímó wọn, ni wọ́n ń ṣe ìrántí iṣẹ́ ìyanu ńlá Ọlọ́run tí wọ́n sì ń kọ orin ọpẹ́ kíkan sí Orúkọ Rẹ̀ Ọlọ́run ń fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ó fi ayé wọn yìn-Ín.-Christ’s Object Lesson, pp. 298, 299. IIO 213.3