Ọlọ́run rán àwọn ańgẹ́lì Rẹ̀ láti máa ṣe iṣẹ́ ìrańṣẹ́ fún àwọn ọmọ Rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ afọ́jú. Àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run ni wọ́n tọ́ ìṣísẹ̀ wọn tí wọ́n sì ń pa wọn mọ́ kúrò nínú ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ ewu tí wọn kò mọ̀ tí ó wà ní ọ̀nà wọn.-Testimonies, Vol. 3, p. 516. IIO 215.1
Ọlọ́run kò ní gbọ́ àdúrà àwọn ènìyàn Rẹ̀ nígbà tí wọ́n kò bá bìkítà fún àwọn àfọ́jú àti àwọn aláìsàn àárín wọn.-Testimonies, Vol. 3, p. 518. IIO 215.2
Tí a bá rí àwọn tí ó bá fẹ́ jẹ́ ohun ìdènà fún àwọn afọ́jú, ó yẹ kí a ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ sí àwọn irú ẹni bẹ́ẹ̀ nítorí Ọlọ́run ti fi wá ṣe olùṣọ́ fún àwọn afọ́jú, àwọn tí a ń pọ́n lójú, àwọn opó àti àwọn ọmọ aláìní baba. Òkúta ìdènà tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò túmọ̀ sí òkùta lásán èyí tí a yí sí ọ̀nà àwọn afọ́jú láti lè mú wọn ṣubú, ṣùgbọ́n ìtúmọ̀ rẹ̀ pọ̀ ju báyìí lọ, ó túmọ̀ si ohunkóhun tí a lè ṣe láti bà wọ́n nínú jẹ́, tàbí ṣiṣẹ́ lòdì sí ìfẹ́ wọn tàbí tako ọ̀rọ̀ tàbí àṣeyọrí wọn.-Testimonies, Vol. 3, p. 519. IIO 215.3
Àwọn afọ́jú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdènà ní ọ̀nà wọn nítorí ipò ìfọ́jú tí wọ́n wà. Ọkàn àwọn tí wọn kò káanú tàbí kẹ́dùn bí àwọn afọ́jú ṣe ń fọwọ́ wá ọ̀nà kiri ní ojú ọ̀na wọn nínú ayé tí kò ba wọn ṣọ̀rẹ́ yìí, ní láti jẹ́ ọ̀dájú, pẹ̀lu oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wọ́n nílò f’ọ́wọ tọ́. IIO 215.4