Olórun kìí déédé ṣe isé ìyanu láti mú kí òtító Rè tèsíwájú. Tí olùsógbà kò bá ko ilè, Olórun kò ní se isé ìyanu láti mú èrò jáde níbè. Ó máa ń sisé pèlú àgbékalè ń lá tí Ó fihàn wá. Tiwa ni láti mú kí àwon ìpinnu wònyí dàgbà kí a sì se isé èyí tí Olórun yóò jé kó ní àseyorí. Àwon tó káwó-gbera lásan tí won ń de Èmí Mímó láti mú won pèlú agídí, láti sisé yóò parun nínú òkùnkùn. Kò ye kí a kàn jòkó tetere lásán láì sisé kankan níbi isé Olórun.-South Watchman, Dec. 1, 1903. IIO 228.3
Àwon kan tó ń sisé ìjèrè okàn jé aláìlágbára, enití-n ǹ-kan-kìí-pé-sú. Won kò lè dá rìn tí e kò bá tì wón. Won kò ní àmúye àwon ìwà tí ó lè dá n ǹkan se bẹ́èni won kò ní èmí àti agbára tí ń mú òyàyà wá. Àwon tí ó bá fé se àseyorí gbodò ní ìgboyà kí won sì ní ìrètí. Kìí se wípé wón ní ìwà ìlóra nìkan bíkòse kí won ó tún ní àmúye ìwà ìyára.-Gospel Workers, p. 90. IIO 228.4
Olúwa nílò irú àwon òsìsé tí won yóò mú ìségun àgbélébùú Krístì tèsíwájú.-Review and Herald, May 6, 1890. IIO 228.5
Kìí se kí a má wàásù pèlú ìlóra àti àìjáfáfá bíkòse pèlú ìtara, ìgboyà àti òrò tí a ti pinnu télè tí ó sì hàn kedere.-Testimonies, Vol. 8, p. 16. IIO 229.1
A kò nílò àwon tí ń fi oge tàbí ako sòrò láti se ìwàásù yìí bíkòse kí a fi ìtara àti ìgbónára so òrò náà. A nílò àwon ènìyàn tó já fáfá, àwon ènìyàn tí won yóò fi tokàn-tara sisé pèlú agbára láti we ìjo mó àti tí won yóò sì kìlò fún ayé.-Testimonies, Vol. 5, p. 187. IIO 229.2
Olorun kò fé àwon òle lénu isé Rè; bíkòse àwon òsìsé tí ó ní àròjinlè, tí wón kún fún ìfé, inú rere.-Testimonies, Vol. 4, p. 411. IIO 229.3