Krìstèénì tòótó yóò sisé fún Olórun nínú ìlànà rè, kí se fún ojó tàbí osù kan bíkòse fún gbogbo ojó ayé rè làì fi ti ara rè se é.-Counsels To Teachers, p.518. IIO 232.1
Olùgbàlà kí eni tirè nínú isé rè. A fùn ní agbára láti fi sisé fún ìran omo ènìyàn. Gbogbo òsán Rè ló fi sisé tí ó sì fi gbogbo alé gbàdúrà, kí ó lè dojúko òtá àti ìmò búburú rè, ohun isé rè láti fi gba omo ènìyàn là. Eni tí ó bá fé Olórun kì ígbé gégé bí i wákàtí méjo ni a fi ń sise lé isé rè. Á fi gbogbo wákàtí rè sisé láì se ìsáǹsá rárá. Ó ń se ohun rere nígbàkuùgbà, ó ń rí ànfààní láti se isé fún Olórun. Ó ní àmuye tí ó ń fanimóra ní ìgbà gbogbo.-Testimonies, Vol. 9, p. 45. IIO 232.2
Eni tí ó bá fi ìwà àìtó tàbí àìbìkítà jé kí isé Olórun denukolè tàbí eni tí ó dí àwon òsìsé rè lówó, fi owó ara rè fàbàwón tí ó sòro láti wè kúrò sórí ara rè, béè ni ó sì gbé ìdènà ti ipa ìwúlò rè ní ojó iwájú.-Prophets and Kings, p. 659. IIO 232.3
Jesu wípé “Gbé àjàgà mi rù”. Àjàgà yìí ni irin isé. À ń gbé àjàgà sórí màálù láti jé kí ó sisé, àjàgà yìí wúlò púpò láti jé kí won ó sisé dáadáa. Pèlú àjàgà yìí, Krístì ń kó wa pé a pè wá láti se isé ìsìn ní gbogbo ojó ayé wa. Ká gba àjàgà rè sórí, kí a lè bá jé a-lá-bàá-jo-ṣiṣé-pò.- The Desire of Ages, p. 329. IIO 232.4