Go to full page →

Ìfẹ́ Ọlọ́run Láti Fifún Ni IIO 251

Olorun ní ìfé láti fi èmí-mímó fún àwon tó ń sìn ju bí àwon òbí se féràn láti fi èbùn fún omo won lò.-The Acts of Apostles, p. 50. IIO 251.2

Ní gbogbo ìgbà àti ibi, nínú gbogbo ìsòro àti ìbìnújé, nígbà tí ohun gbogbo bá dojúrú, tí a kò ní ìrètí fún ojó iwájú, tí à ń rò pé kò sí olùrànlówó, a yóò rán Olùtùnú láti dáhùn sí àdúrà tí a gbà pèlú ìgbàgbó. Ohun kan lè yàwá pèlú ore-òfé yìí, sùgbón kò sí ohunkóhun tí ó lè yàwá pèlú Olùtùnú òrun. Ní ibikíbi tí a lè wà, tí a lè lo, ó má wà lówó òtún wa nígbà gbogbo láti ràn wá lówó, gbé wa wò àti láti mú inú wa dùn.-The Desire of Ages, pp. 669, 670. IIO 251.3

Lójoojúmó, bí àwon òjísé se ń kúnlè níwájú Olúwa láti tún ìlérí won se pèlú Olúwa, yóò fún won ní èmí-mímó tí yóò mú won tají àti agbára ìsodimímó. Bí wón ti ń lo síwájú nínú isé won lójoojúmó, wón ní ìdánilójú pé àwon èmí òrun tí a lè rí bá won sisé papò.-The Acts of Apostles. IIO 251.4

À ń ´gbé ní àkókò agbára èmí-mímó. Ó ń wá láti wolé nípasè àwon omo aráyé, kí ó lè ni ipa tí ó pò sí nínú ayé.-Southern Watchman, Nov. 3, 1903. IIO 251.5