Go to full page →

Kò Gbọdọ̀ Sí Ìrònú Ìkùnà IIO 261

Àwon òsìsé Olórun kò gbodò rò, dèpòdépó kì won ò sòrò ìkùnà nínú iṣé ẹwon. Jésu Olúwa ni aláṣepé e wa nínú ohun gbogbo. Èmí rè gbodò jé ìmísí i wa, kí a fi ara wa sí owó Rè láti jé ohun èlò ìmólè, ipa wa láti se rere kì yóò tán. A lè gbà nínú olá-ńlá a Rè, ore-òfé tí kò nípèkun. —Gospel Workers, 19. IIO 261.4

Nígbà tí a bá jòwó ara a wa sílè fún Olórun pátápátá, tí a tèlé ìlànà a Rè nínú isé wa, yóò fi ara Rè ṣe olùparí isé náà. Kò ní jé kí làálàá wa já sófo. A kò gbodò fi ìgbà kan ronú ìkùnà rárá. A gbodò se ìbádàpò pèlú Olórun tí kò mo ìkùnà rárá.-Christ’s Object Lesson, p. 363. IIO 261.5

Olórun ní ìdára lára nígbà tí àwon ènìyàn Rè bá ro ara won pin. Ó fé kí ìran tí Ó yàn ó mo iyì ara won. Olórun fé wa, ìdí nìyí tí ó sé rán omo Rè ní isé bàǹtàbanta láti wá gbà wá là. Ó nílò wa, inú Olórun a sì máa dùn nígbà tí ó bá bèrè ohun ń lá lówó Rè, kí a lè gbé orúko Rè ga. A lè rí tí ohun ń lá tí a bá ní ìgbàgbó nínú Rè (The Desire of Ages, p. 668). IIO 262.1