Go to full page →

Bíbàkù Láti Sọ Ìdí Tí ó Mọ́gbọ́n Wá Fún Ìgbàgbọ́ IIO 46

Ọ̀pọ̀ tí ó jẹ́wọ́ láti gba òtítọ́ gbọ́ fún ìgbà ìkẹhìn yì í ni kò ní kúnjú òṣùwọ̀n. Wọn kò kọbi ara sí ohun ti o jaju lọ.Àyípadà ojú lásán ni wọ́n ní, kò jinlẹ̀, kì í ṣe tọkàn tọkàn, kò sì múná dóko.Wọn kò mọ ìdí tí wọn fi gba òtítọ́ gbọ́, nítorí pé,kìkì àwọn tó kù ti gbà á gbọ́, wọ́n sì mu ní yẹpẹrẹ pé òtítọ́ ni. Wọn kò lè sọ pẹ̀lú ọgbọ́n ìdí tí wọ́n ṣe gbàgbọ́....Àwọn yókù kò ní òye tàbí gbé ìrírí wọn ga, tàbí nípa ìmọ̀ èyí tí ó jẹ́ àǹfààní fún wọn àti iṣẹ́ tí wọ́n rí gbà. Agbára àti ìdúró ṣinṣin in wà pẹ̀lú ọlọ́kàn tòótọ́ àwọn olùkọ́.-Testimonies,vol.2,p.634. IIO 46.1