Go to full page →

Olórí Ẹlẹ́tàn Lẹ́nu Iṣẹ́ IIO 54

Ní àsìkò tí a wà yìí, tí òpin ohun gbogbo ní ayé ń súnmọ́ etíle, èṣù ń kó gbogbo ìgbìyànjú u rẹ̀ láti ta okùn mú aráyé, ó ń lo gbogbo ọ̀nà láti gba àwọn ọkàn, àti láti gbé ọkàn ènìyàn kúrò nínú ohun tí í ṣe ti òtítọ́ tí ó ṣe pàtàkì sí ìgbàlà. Ní ìlú kọ̀ọ̀kan àwọn aṣojú u rẹ̀ ń ṣe aápọn fún ṣíṣètò ara a wọn lẹlẹ́gẹ́jẹgbẹ́ àwọn tí wọ́n tako òfin Ọlọ́run.Olórí ẹlẹ̀tàn wà lẹ́nu iṣẹ́ láti ṣàfihàn àwọn ìpìlẹ̀ tí rúdurùdu àti ìṣọ̀tẹ̀, àwọn ènìyàn ni ìtara tí kò ní ìmọ̀ nínú.- The Acts of the Apostles, p.219 IIO 54.2

Sàtánì jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí kìí ṣe ìmẹ́lẹ́, ó mọ̀ pé àkókò kékeré ni òún ní, ó sì ń wá gbogbo ọ̀nà láti ṣe ìlòdì sí iṣẹ́ Olúwa lórí ilẹ̀ ayé.-Testimonies, vol.9,p.16. IIO 54.3

Sàtánì ní báyìí ń wá ọ̀nà láti mù àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní ipò àláì láápọn, láti má jẹ̀ ẹ́ kí wọn ṣa ipá wọn nínú títan òtítọ́ ká, àti pé níkẹhìn kí a le wọ̀n wọ́n nínú òsùwọ̀n, kí wọn má sì ṣe kúnjú òsùwọ̀n.- Testimonies, vol.1,p.260. IIO 54.4