Go to full page →

Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ọ Ti Ọ̀run IIO 135

Krístì ṣe alábápín nínú ìṣòro ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan tí ó ń jìyà. Nígbà tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ fa ara ènìyàn ya, Kristi ṣe alábápín ègún. Nígbà tí ìba bá ń mú ìnira bá ara,Ó ṣe alábápín ìrora.Bẹ́ ẹ̀ ni ó nífẹ̀ ẹ́ láti wo aláìsàn sàn nísinsinyìí,nígbà tí Òun fúnra a Rẹ̀ wà láyé. Àwọn ìránṣẹ́ ẹ Kristi ni àwọn aṣojú u RẸ̀, àwọn orísun fún iṣẹ́ ẹ RẸ̀. Ó nífẹ̀ ẹ́ nípasẹ̀ wọn láti lo agbára ìwòsàn-an RẸ̀.- The Desire of Ages, pp.823,824. IIO 135.1

Nípasẹ̀ àwọn iranṣẹ ẹ RẸ̀, Ọlọrun ṣe é pé kí àwọn aláìsàn, àwọn tí kò ṣorí ire, àti àwọn tí wọ́n ní àwọn ní ẹ̀mí èṣù, yóò gbọ ohùn-un RẸ̀. Nípasẹ̀ àwọn ènìyàn aṣojú u RẸ̀ Ó nífẹ̀ ẹ́ láti jẹ́ olùtùnú, irú èyí tí ayé kò mọ̀ rí.- The Ministry of Healing, p.106. IIO 135.2

Ọlọrun fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ń kópa nínú iṣẹ́ oniṣegun ajihinrere.- Testimonies, vol.7, p.51. IIO 135.3

Ọlọrun ti ṣe tán pẹ̀lú u wọn. Níbikíbi tí wọ́n bá lọ, aláìsàn ń rí ìwòsàn, àwọn òtòṣì ń gbọ́ iṣẹ́ ìhìnrere tí a wàásù fún wọn.- The Acts of the Apostles, p.106. IIO 135.4

Kristi kò gbé nínú ayé yì í mọ́ bí ènìyàn, láti lọ sí àwọn ilu ń la ńla, ìlú àti àwọn ìletò, wíwo aláìsàn sàn; ṣùgbọ́n Ó ti fún wa ní àṣẹ láti tẹ iṣẹ oniṣegun ajihinrere tí ó bẹ̀rẹ̀ síwájú.- Testimonies, vol.9, p.168. IIO 135.5