Go to full page →

Títa Àwọn Ìwé IIO 152

Ọpọlọpọ ni ó ti banújẹ́ tí ó sì ti rẹ̀wẹ̀sì, tí wọ́n jẹ́ aláìlera ní ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé. Jẹ́ kí wọn ṣe ohun láti ṣe rànwọ̀ fún ẹnìkan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọn yóò sì dàgbà nínú agbara Ọlọrun. Jẹ́ kí wọn jẹ́ akópa nínú títa ìwé e wa. Nipa báyíí, wọn yóò lè ran awọn mìíràn lọ́wọ́, ìrírí tí wọ́n bá sì rí gbà yóò fún wọn ní ìdánilójú pé wọ́n jẹ́ ọwọ́ ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun. Bí wọ́n ṣe ń bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Ọlọrun láti ràn wọ́n lọ́wọ́, Yóò darí i wọn sí ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n ń wá ìmọ́lẹ̀ náà. Kristi yóò fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú u wọn, kọ́ wọn ní ohun tí wọn yóò sọ àti tí wọn yóó ṣe. Nípa títu àwọn mìíràn nínú, àwọn náà yóò di ẹni ìtùnú.- The Colporteur Evangelist, p.40. IIO 152.1