Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Ijẹwọ

  “Ẹniti o bo ẹs̩ẹ rẹ̀ mọlẹ ki yio s̩e rere; s̩ugbọn ẹnikẹni ti o jẹwọ ti o si kọ ọ silẹ yio ri ãnu! Ówe 28:13.IOK 28.1

  Ọna ti a fi le ri ãnu Ọlọrun gba, jẹ ọna ti o rọrun ti o si tọ́. Ki is̩e ohun inira li Oluwa fẹ ki a se ki a to le ri idariji awọn ẹs̩ẹ wa gba ; ki s̩epe ki a ma lọ kakiri lati be ibi mimọ wo tabi ki a fi ara wa jiya, ki a to le fi ọkan wa fun Ọlọrun ọrun, tabi ki a jiya fun ẹs̩ẹ wa ni ; s̩ugbọn ẹniti ọ jẹwọ ti o si kọ ẹs̩ẹ rẹ̀ silẹ ni yio ri ãnu.IOK 28.2

  Aposteli sọ pe “Ẹ jẹwọ ẹs̩ẹ nyin fun ara nyin, ki ẹ si ma gbadura fun ara nyin, ki a le mu nyin larada.” Jakọbu 5:16. Jẹwọ ẹs̩ẹ rẹ fun Ọlọrun, On ni Ẹnikans̩ọs̩ọ ti o le dars̩ wọn js̩, ki ẹ si ma jẹwọ as̩is̩e nyin fun ara nyin. Bi iwọ ba s̩ẹ ọrẹ tabi aladugbo rẹ, Iwọ nilati jẹwọ as̩is̩e rẹ fun u, is̩ẹ tirẹ̀ na si ni lati fi tifẹtifẹ dari rẹ̀ ji ọ. Lẹhinna ni iwọ yio to wa ọna fun idariji ti Ọlọrun, nitoripe arakunrin ti o s̩e ni ibi na ti Ọlọrun ni is̩e, ati ni s̩is̩e e ni ibi, iwọ ti s̩ẹ si Ẹlẹda ati Olugbala rẹ̀ na pẹlu. A si mu ẹjọ na wa siwaju Onilaja tõtọ́ tis̩e Olori Alufa wa, “Ẹniti a ti danwo ni ọna gbogbo gẹgẹbi awa s̩ugbọn lai lẹs̩ẹ,” ati Ẹniti o si “Mọ ailera wa gbogbo,” (Heberu 4:15) ti o si le wẹ gbogbo abawọn ẹs̩ẹ nu.IOK 28.3

  Awọn ti ko rẹ ọkan wọn silẹ niwaju Ọlọrun nipa jijẹwọ ẹs̩ẹ wọn ko iti gbe is̩isẹ akọkọ fun itẹwọgba niwaju Ọlọrun. Bi awa ko ba ni iru imọ ti o yẹ fun ironupiwada tõtọ́, ti a ko si ti fi irẹlẹ ọkan tõtọ́ ati ibanujẹ ọkan jẹwọ ẹs̩ẹ wa, ki a si kọ̀ ais̩edede wa silẹ, a koi ti fi otitọ wa ọna idariji ẹs̩ẹ ; bi a ko ba si ti wa a, a koi ti ri alafia Ọlọrun. Idi kans̩os̩o ti a ko fi ri imukuro awọn ẹs̩ẹ wa is̩aju ni pe a ko fẹ rẹ ọkan wa silẹ ki a si tẹle awọn ilana ti ọrọ otitọ na. A fi ekọ ti o ye kõro koni nipa ọrọ yi. Ijewọ ese, ibase ti ikọkọ tabi ti gbanga, nilati jẹ eyiti a kẹdun ti a si fi igboiya sọ jade. Ki s̩epe ki a fi agbara mu elese na lati jẹwọ ni. Ki sepe ki a ma se ijẹwo ẹs̩ẹ ni ọna aibikita, tabi ki a fi agbara mu awọn ti ko mọ ohun ti ẹgbin ati iwọsi ti ẹsẹ jẹ. Ijẹwọ ti o ti isale ọkan wa le ri ọna tãra lati lo sodo Ọlorun eniti ãnu Rẹ̀ ko lopin. Dafidi sọpe “Oluwa mbẹ leti odọ awọn ti is̩e onirobinujẹ ọkan; o si gba iru awọn ti is̩e onirora ọkan la! Orin 34:18.IOK 28.4

  Ijẹwọ ẹsẹ totọ jẹ ohun pataki, a si ma tọkasi awọn ẹs̩ẹ kan pataki. O le jẹ iru ẹs̩ẹ ti o yẹ lati mu wa si iwaju Ọlọrun nikan; nwọn si le jẹ awọn ẹs̩ẹ ti a nilati jẹwọ fun ẹnikọkan ninu awọn ti a ti s̩ẹ nipa wọn ; nwọn si le jẹ ẹs̩ẹ ti o han gbangba, o si yẹ ki a jẹwọ nwọn ni gbangba. S̩ugbọn o yẹ ki gbogbo ijẹwọ ẹs̩ẹ jẹ ijẹwọ tãra ki o si jẹ ijẹwọ ẹs̩ẹ gãn eyiti a ti da.IOK 29.1

  Ni akoko Samueli awọn ọmọ Israeli s̩ako kuro lọdọ Ọlọrun. Nwọn si bẹrẹ si jẹ iya ẹs̩ẹ ; nitoripe nwọn ti sọ igbagbọ ati igbẹkẹle wọn nu ninu Ọlọrun, nwọn si sọ agbara ati mimọ́ ọgbọn ati oye lati jọba le orilẹ-ede wọn nu, nwọn si tun sọ igbẹkẹle ninu agbara Rẹ̀ lati gba ati dabobo ọna Rẹ̀ nu. Nwọn ya kuro lọdọ Ọba nla gbogbo aiye, nwọn si fẹ ki a jọba lori wọn gẹgẹbi ti awọn orilẹ-ede ti o yi wọn ka. Ki nwọn to le ri alafia, nwọn se ijẹwọ yi pe : “Nitoripe awa ti fi buburu kun gbogbo ẹs̩ẹ wa ni bibere ọba fun ara wa” I Samueli 12:19. Gbogbo aisedede ti a ka si wọn lọrun ni nwọn s̩e ijẹwọ wọn. Iwa ailọpẹ wọn mu ipọnju ba ọkan wọn, o si ya wọn kuro lọdọ Ọlọrun.IOK 29.2

  Laisi ironupawada ati iyipada tõtọ ijẹwọ ẹs̩ẹ ko le jẹ itẹwọgba lọdọ Ọlọrun. Ipinnu iyipada nilati wa ninu igbesi aiye wa ; gbogbo awọn ohun wọnni ti o le bi Ọlọrun ninu li a nilati kọ silẹ. Eyiyi yio si fi han pe nitõtọ a kãnu nitori ẹs̩ẹ. Afi is̩ẹ ti a nilati se han kedere niwaju wa: “Ẹ wẹ̀, ki ẹ mọ́; mu buburu ise nyin kuro niwaju Mi: dawọ duro lati se buburu: kọ́ lati se rere ; wa dajọ, ran awọn eniti a nilara lọwọ, se idajọ alainibaba, gba ejo opo wi.” Isaiah 1:16, 17.IOK 29.3

  “Bi enia buburu ba mu ogo pada, ti o si san ohun ti o ji pada, ti o si nrin ni ilana iye, li aise aisedede, yiyè ni yio yè, On kì yio ku.” Esekieli 33:15. Paulu sọ nipa isẹ ironupiwada pe: “Kiyesi i, nitori ohun kanna yi ti a mu nyin banujẹ fun bi eni-iwa-bi Ọlọrun, is̩ọra ti o mu ba nyin ti kara to, ijirẹbẹ nyin ti to, ani irunu, ani ibẹru, ani ifẹ gbigbona, ani itara, ani igbẹsan! ninu ohun gbogbo ẹ ti farahan pe ara nyin mọ́ ninu ọran na.” II Korinti 7:11.IOK 29.4

  Ẹniti o ti mõkun tobē̩gē̩ ninu ẹs̩ẹ, onis̩ẹ ibi kì i lè mọ iwa buburu rẹ̀, tabi mọ titobi ibi ti o ti se; afi ti o ba si jọwọ ara re lọwọ fun agbara Ẹmi Mimọ, sibẹ o wa ninu okunkun ẹse rẹ̀. Awọn ijewo ẹs̩ẹ rẹ̀ ki ise pẹlu otitọ ati ododo. Bi o ba ti njẹwọ ẹbi rẹ̀ ni yio ma fi ẹbẹ ati awawi sọrọ pe bi ko ba si ohun ti o fa a, on ki ba ti ẹe ohun ti nwọn nba on wi si yi.IOK 29.5

  Lẹhin igbati Adamu ati Efa ti jẹ eso igi ti a kilọ fun wọn pe ki nwọn ma jẹ, nwọn kun fun itiju ati ibẹru. Ero wọn akọkọ ni gẹgẹbi nwọn yio s̩e s̩e awawi fun ẹs̩ẹ wọn, ki nwọn ba le bọ lọwọ iku ti is̩e ere ẹs̩ẹ buburu na. Nigbati Ọlọrun bere nipa ẹs̩ẹ na lọwọ wọn, ninu idahun, Adamu pín ẹbi diẹ fun Ọlọrun ati diẹ fun iyawo rẹ̀: “Òbirin ti Iwọ fi pẹlu mi, on ni o fun mi ninu eso igi na, emi si jẹ.” Obirin na gbe ẹbi le ori ejo wipe “Ejo li o tan mi, mo si jẹ.” Genesis 3:12, 13. Ẽs̩e ti o fi da ejo? Es̩e ti o fi jẹki o wa sinu ọgba Edem? Awọn ibere ti o wa ninu awawi fun ẹs̩ẹ rẹ̀ niwọnyi, bayi li o si ko ẹbi is̩ubu wọn le Ọlọrun lori. Ẹbi ida-ara-ẹni lare bẹrẹ lati ọdọ baba èké ; o si nhan lara ọmọkunrin ati ọmọbirin Adamu. Ẹmi Mimọ ko si misi iru ijẹwọ bi iru eyi, bẹni Ọlọrun ko si le tẹwọgba a. Ironupiwada totọ a mã sun enia lati ru ẹbi ara rẹ̀, ati lati jẹwo rẹ̀ laisi ẹtan tabi agabagebe. Gẹgẹbi ọkunrin talaka agbowo ode, ti ko le gbe oju ara rẹ̀ soke tobẹ si ọrun, on yio kigbe pe, “Ọlọrun s̩ãnu fun mi emi ẹlẹs̩ẹ;” awọn ti o ba si s̩e ijẹwọ ẹs̩ẹ wọn ni ao dariji, nitoripe Jesu yio fi ẹjẹ ara Rẹ̀ bẹbẹ fun iru ọkan bē̩ ti o ronupiwada.IOK 31.1

  Apẹrẹ ti o han ninu ọrọ Ọlọrun nipa ironupiwada atọkanwa ati ẹmi ijẹwọ han ninu eyiti awawi fun ẹs̩ẹ ko si, tabi igbidanwo lati da ara ẹni lare. Paulu ko fẹ dabobo ara rẹ̀; o pe ẹs̩ẹ ti o da ni orukọ ti njẹ, on ko tilẹ wa ọna lati din ẹbi ara rẹ̀ ku. O wipe: “Awọn pupọ ninu awọn enia mimọ ni mo ha mọ inu tubu, nigbati mo ti gba as̩ẹ lọwọ awọn olori alufa; nigbati nwọn si npa wọn mo ni ohun si i. Nigba pupọ ni mo s̩ẹ́ wọn n’is̩ẹ́, ninu gbogbo Sinagogu, mo ndu lati mu won sọ blasfeme ; nigbati mo sọro si won gidigidi, mo s̩e inunibini si won de ajeji ilu.” Is̩e 26:10, 11.IOK 31.2

  On ko tilẹ siyemeji lati sọ gbangba pe “Kristi Jesu wa si aiye lati gba ẹlẹs̩ẹ la: ninu awọn ẹniti emi jẹ pataki.” I Timoteú 1:15.IOK 31.3

  Awọn onirẹlẹ ati onirobinujẹ okan, ti iyipada totọ ti segun li o le mọ iyi ifẹ Ọlọrun ati titobi iku Rẹ ni Kalfari : bi ọmo ti ijẹwọ ẹs̩ẹ fun baba ti o ni ife rẹ; gẹgẹbe ni onironupiwada yio mu ẹs̩ẹ rẹ wa siwaju Olorun. A si ti ko o pe “Bi awa ba jẹwọ es̩e wa, olotitọ ati olododo ni on lati dari ẹs̩ẹ wa ji wa, ati lati wẹ wa nu kuro ninu ais̩ododo gbogbo.” I johanu 1:9.IOK 31.4

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents