Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Jyasimimọ

  Ileri ti Ọlọrun s̩e ni wipe, “Ẹnyin o s̩e afẹri mi, ẹ o si ri mi, nitori ẹ o fi gbogbo ọkan yin wa mi.” Jeremiah 29:13.IOK 32.1

  A nilati jọwọ gbogbo ọkan wa lọwọ fun Ọlọrun, bi bē̩kọ iyipada na ko le de nipa eyiti ao fi sọ wa dabi ontikararẹ̀. Nipa ẹda awa yàtọ̀ pupọ si Ọlọrun. Ẹmi Mimọ sọ nipa ipo wa bayi pe,” . . . Ẹnyin ti ku nitori irekọja ati ẹs̩ẹ nyin ;” Efesu 2:1. . . . “gbogbo ori li o s̩aisan, gbogbo ọkan li o si daku. Lati atẹlẹsẹ de ori, ko si ilera ninu rẹ̀.” Isaiah 1:5, 6. “Nwọn o si le sọji kuro ninu idẹkun Es̩u, awọn ti a ti di ni igbekun lati ọwọ rẹ̀ wa si ifẹ rẹ̀. II Timoteu 2:26. Ọlọrun fẹ lati mu wa larada, ati lati sọ wa di omnira. S̩ugbọn nitoripe’ eyi nfẹ iyipada pipe, ati atunda gbogbo ara wa, A nilati jọwọ ara wa lọwọ fun u patapata.IOK 32.2

  Ijakadi lati bori ifẹ ara ẹni, ni ija ti o tobi julọ ti ẹda ti ja ri. Jijọwọ ara ẹni lọwọ ati fifi gbogbo ifẹ ẹni le Ọlọrun lọwọ, ijakadi nla ni ; sugbọn a nilati jọwọ ọkan wa lọwọ fun Ọlọrun ki o to le s̩ẽs̩e lati sọ́ di ọtun ninu iwa mimọ.IOK 32.3

  Ijọba ti Ọlọrun ki se tipatipa gẹgẹbi Es̩u ti mu ki o ri loju enia. S̩ugbọn o nrọ onikaluku ọkan ati ẹri-ọkan. Oluwa wipe. “Wa nisisiyi, ki ẹ si jẹki a sọ asọye pọ̀Isaiah 1:18. Ni ipe Ọlọrun si awon ẹda ọwọ Rẹ̀. Ọlọrun ko mu awọn ẹda ọwọ Rẹ̀ ni ipa lati sin On. Ibọ̀wọ̀ fun ti kì ba se pẹlu ifẹ atinuwa, ko ni itẹwọgba lọdọ Rẹ̀. Ituba ti enia ba s̩e pẹlu ipá, ko le mu idagbasoke ẹmi ati iwa pipe wá; s̩ugbọn enia yio dabi ẹ̀rọ ti a nmu s̩is̩ẹ lasan. Ki is̩e èrò Ẹlẹda wa niyi. Ifẹ okan Rẹ̀ nipe, ki enia t o fi s̩e olori ohun gbogbo ti o da, le de ipo ti o ga julọ ninu idagbasoke nipa ti ẹmi. O ti gbe ibukun giga na kalẹ niwaju wa, eyiti o fẹ mu wa de nipa ore-ọfẹ. O npe wa pe ki a fi ara wa fun, ki o le mu ifẹ Rẹ̀ s̩ẹ ninu wa. Ohun ti o ku fun wa ni wipe ki a yàn, bọya awa nfẹ idande kuro loko ẹru ẹs̩ẹ, ki awa pẹlu si di alabanin ominira ti o logo ti awọn Ọmọ Ọlọrun.IOK 32.4

  Ni fifi ara wa fun Ọlọrun, gbogbo nkan wọnni to le ya wa nipa kuro lọdọ Rẹ̀ li a nilati mu kuro lọwọ wa. Nitorina ni Olugbala fi sọ wipe “Gẹgẹ bē̩ni, ẹnikẹni to wu ki o se ninu nyin, ti ko ba kọ ohun gbogbo ti o ni silẹ, ko le s̩e ọmọ-ẹhin mi.” Luku 14:33. A nilati kọ ohunkohun ti yio ba fa ọkan wa kuro lọdọ Ọlọrun silẹ. Mamoni ni oris̩a ti ọpọlọpọ nsin. Ifẹ owo, ati èrò lati ni ọ̀rọ jẹ ẹwọn wura ti o so wọn mọ Eẹu. Awọn ẹlomiran si nsin ipo giga ati ọla ti aiye yi. Igbe aiye imọtara-ẹni nikan, ati idẹra si jẹ oris̩a fun awọn ẹlomiran. A nilati já okùn idè ẹrú yi kuro lara wa, Awa ko le jẹ ti Ọlọrun ati ti aiye pọ lẹkanṣoṣo na. Awa ki ṣe ọmọ Ọlọrun bi a ba nipa ninu nkan nwọnyi.IOK 32.5

  Awọn miran wà ti nwọn jẹwọ pe awọn nsin Ọlọrun s̩ugbọn nwọn gbẹkẹle agbara ti ara wọn lati pa ofin Rẹ mọ, ati lati hu iwa tõtọ̀ ki nwọn le ri igbala. Ifẹ Kristi ko s̩is̩ẹ ninu ọkàn wọn, s̩ugbọn nwọn a mã gbiyanju lati s̩e awọn is̩ẹ ti o yẹ fun onigbagbọ bi ẹnipe on ni Ọlọrun fẹ ki wọn s̩e ki nwọn ba le de ọrun. Iru isin bayi kò já mọ nkankan lọdọ Ọlọrun. Nigbati Kristi ba ngbe inu ọkàn, ọkan nã yio kun fun ifẹ, ati idapọ didun Rẹ̀ tõbē̩gẹ ti ọkan yio fi fà si Kristi ; bi a si ti nronu nipa rẹ̀, ao gbagbe ifẹkufẹ ti ara. Ife si Kristi yio si ma han ninu iwa wa. Iye awọn ti ifẹ Kristi ba nrọ̀ ki i fi oju kekere wo ipo ti Ọlọrun fẹ ki nwọn de, nwọn ki i bere fun opagun ti o rẹlẹ julọ, s̩ugbọn nwọn o fi ọkan si ati wà ni idapọ pipe pẹlu ifẹ Òlurapada wọn. Pẹlu ifẹ pipe nwọn a jọwọ gbogbo nkan lọwọ fũn, nwọn a si fi ifẹ ti o tobi to ohun ti wọn bere hàn. Ijẹwọ pe a jẹ ti Kristi laisi ifẹ ti o jinlẹ, je ọrọ lasan, às̩a gbigbẹ, ati lala ti ko lere.IOK 33.1

  Iwọ ha ro pe irubọ nla ni lati fi ohun gbogbo fun Kristi? Bere ibere yi lọwọ ara rẹ, “Kini Kristi fifun mi? Ọmọ Ọlọrun fi gbogbo rẹ silẹ, — iye Rẹ̀, Ifẹ Rẹ̀ ati ijiya fun irapada wa. O ha le je pe awa, ti a je aláiyẹ fun iru ife bayi, yio ha kò lati jọwọ ọkan wa lọwọ fun? Ni gbogbo wakati ati is̩ẹju ni igbe aiye wa ni awa ti je alabapin ibukun Òre-ọfe Rẹ̀, idi rẹ̀ niyi ti awa ko fi le mọ ijinlẹ òpè ati os̩ì ninu eyiti a ti rà wá pada. Aha le bojuwo eniti a pa lara nitori ẹs̩e wa, sibesibe ki a “si s̩àinãni ife ati irubọ Rẹ̀? Bi a ba ro nipa irẹsile ti Òluwa ogo, o ha ve ki a mã kun pe nipa ijakadi ati irẹara-sile nikan ni a fi le de ibi iye?IOK 33.2

  Ọkan igberaga a ma bere bayi pe, “Kini s̩e ti emi ko Je ni idaniloiu itewogba Ọlọrun afi bi mo ba re ara mi silẹ? E wo Jesu Kristi. Ko da ẹse kan ri, ju gbogbo rè lọ, O jẹ Omọ Alade-Orun; s̩ugbon nititori enia, o so ara Rẹ̀ di ẹs̩ẹ nitori awa ẹda.” . . . . “A kã mọ awọn alarekọja; o ru ẹs̩ẹ ọpọlọpọ, O si ns̩ipẹ fun awọn alarekọja.” Isaiah 53:12.IOK 33.3

  S̩ugbọn kini awa fi silẹ nigbati a ba fi gbogbo rẹ̀ silẹ? Ọkan ti ẹs̩ẹ ti sọ di aimọ, li a wã fifun Jesu lati wē̩ mọ nipa ẹjẹ ontikararẹ̀, ati lati gbã ià nipa ifẹ Rẹ̀ ti ko lẹgbẹ. Sibẹ awa ẹda ka si ohun ti o s̩oro lati fi gbogbo rẹ silẹ! Òhun itiju ni lati gbọ́, ati lati kọ.IOK 35.1

  Ọlọrun ko sọ wipe ohun ti o ẹe pataki fun wiwa lãyè wa ni ki a fi silẹ. Ninu ohun gbogbo ti o s̩e, Ọlọrun ko fi iwa lãye awọn ọmọ Rẹ̀ jafara. Ifẹ rẹ̀ ni pe ki awọn ti wọn ko ba ti yan Kristi le mọ ni ọkan wọn wipe ohun ti Kristi ni lati fifun wọn dara pupọpupọ ju eyiti awọn pãpà nwa kiri lọ. Enia npa ara rẹ lara lasan ni, o si nhuwa ais̩õtitọ si ọkan ara rẹ pẹlu, nigbati o ba nrò, ti o si ns̩e awọn nkan wọnni ti o lodi si ifẹ Ọlọrun. Ko si ayọ pipe ti enia le ni nipa titọ ọna ti Kristi kọ̀ fun wa lati tọ, nitoripe on ni Ẹniti o ns̩e eto ohun gbogbo to dara fun awọn Ẹda ọwọ Rẹ̀. Gbogbo ọna ais̩ododo, ọna ibanujẹ ni, ọna iparun si ni pẹlu.IOK 35.2

  As̩is̩e nla ni bi awa ba nro ni ọkan wa pe inu Ọlọrun a mã dun lati ri awọn ọmọ Rẹ̀ ninu iyà. Awọn ọrun papa a ma s̩e alabapin ninu ayọ wa. Ọlọrun ko ti ilẹkun ayọ mọ ẹnikẹni ninu awọn ẹda ọwọ Rẹ̀. Ohun ti Ọlọrun npe wa lati s̩e ni wipe ki awa ki o kọ̀ awọn ohun wọnni ti o le mu ibakù ati ijiya wa silẹ, ati awọn nkan wọnni to le ti ilẹkun ayọ ati ijọba ọrun mọ wa. Bi ipo wa ti ri, bē̩na gán ni Olurapada araiye s̩e ntẹwọ gba wa, pẹlu gbogbo aini wa, gbogbo aipe wa, ati gbogbo ailera wa ; ki si is̩e wipe yio wẹ wa nu kuro ninu ẹs̩ẹ wa nikan ni, s̩ugbọn yio tẹ gbogbo ifẹ ọkan awọn ti wọn ba ni ifẹ lati ba ru ajaga Rẹ̀ lọrun, yio si ba wọn ru ẹru wọn pẹlu. Ifẹ Rẹ̀ ni lati fi alafia ati isimi fun gbogbo awọn ti wọn ba wa sọdọ Rẹ̀ fun onjẹ iyè. Kiki ifẹ Ré fun wa ni wipe ki a s̩e awọn is̩ẹ wonni ti yio dari isisẹ wa lọ sibi ibukun giga ni, eyiti alaigbọran ko le ri lailai. Aiye otitọ ati ayọ ti ẹmi ni lati ni Kristi ninu ọkan-ẹniti is̩e ireti ogo.IOK 35.3

  Ọpọlọpọ li o mbere wipe, “Bawo ni mo s̩e le fi ara mi fun Ọlọrun?” Iwọ fe nitõtọ lati fi ara rẹ fun Jesu, s̩ugbọn iwọ jẹ alailera nipa ti ara, iwọ si jẹ ẹrú iyemeji, bẹni iwa ẹsẹ rẹ si njọba le ọ lori. Gbogbo ileri rẹ ati ipinnu rẹ dabi okùn ti a fi yanrin lasan s̩e. Iwọ ko le ko ero, is̩ẹ ati ifẹ ọkan rẹ gbogbo ni ijanu. Idamu awọn ileri ti o s̩e ti iwo ko mus̩ẹ, ati awon èjé rẹ ti iwọ jẹ́ s̩ugbọn ti iwọ ko san mu ki o rẹwẹsi ninu igbẹkẹle ati iduro s̩ins̩in rẹ, o si mu ki o ma ri ninu ọkan rẹ wipe Ọlọrun ko le tẹwọ gba ọ mọ; s̩ugbọn iwọ mas̩e sọ ireti nu. Ohun ti o nilati mọ̀ gan ni agbara ifẹ tõtọ. Eyi yi li ohun pataki ti njọba lori iwà ẹda enia, agbara ipninu tabi yiyàn. Ohun gbogbo simi lori ihuwasi wa gẹgẹbi ifẹ Ọlọrun. Ọlọrun ti fun enia ni agbara lati yàn; tiwọn si ni lati lõ. Iwọ ko le yi ọkan ara rẹ pada, iwọ ko si le ti ipa agbara ara rẹ fi ohun ti ọkan rẹ fẹ fun Ọlọrun; s̩ugbọn iwọ le yan lati sin. Iwọ le fi ìfẹ rẹ fun Kristi; yio si s̩e is̩ẹ na ni ọkan rẹ lati mu ki o fẹ ati lati s̩e ifẹ inu rere Rẹ̀. Bẹni gbogbo iwaẹda rẹ yio wa labẹ akoso Ẹmi Mimọ ti Kristi; gbogbo ifẹ rẹ yio dari sọdọ Rẹ̀, gbogbo ero ọkan rẹ yio si jẹ ọkan pẹlu tirẹ̀.IOK 35.4

  Awọn ero lati s̩e rere ati lati jẹ mimọ dara nitõtọ, s̩ugbọn bi o ba duro nidi rirò nikan, ko s̩anfãni kankan. Ọpọlọpọ ni yio di ẹni egbe nibiti nwọn gbe nireti ti nwọn si nfẹ lati di Onigbagbọ. Nwọn ko de ipo ati jọwọ ifẹ wọn lọwọ fun Ọlọrun. Nwọn ko yàn nisisiyi lati jẹ Atẹle Kristi tõtọ.IOK 36.1

  Nipa lilo ifẹ rẹ ni ọna tõtọ, iyipada pipe le de sinu igbe aiye rẹ. Nipa jijọwọ ifẹ rẹ lọwọ fun Kristi, iwọ dimọ agbara nla ni eyiti o tayọ gbogbo agbara miran. Iwọ yio gba agbara lati ọrun wa ti yio si mu ọ duro s̩ins̩in, ati nipa gbigbe ifẹ rẹ le Ọlọrun lọwọ nigbagbogbo, yio s̩ẽs̩e fun ọ lati le gbe igbe aiye titun, ani igbe aiye igbagbọ.IOK 36.2

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents