Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Anfani ti a wa ninu Adura

    Nipa awọn ohun ti Ọlọrun da, ati nipa ifihan Ọrọ Rẹ̀, nipa anu ati nipa agbara Ẹmi Mimọ Rẹ ni on fi ma nba wa sọrọ. S̩ugbọn awọn wọnyi ko to; O yẹ ki awa na si le s̩i ọkan wa paya fun U. Ki a to le ni ẹmi iye ati agbara, a nilati ni isopọ timọtimọ pẹlu Baba wa ọrun. Ọkan wa le fa si ọdọ Rẹ̀, a le mã se as̩aro lori is̩ẹ Rẹ̀, anu Rẹ̀, ati lori ibukun Rẹ̀. S̩ugbọn eyi ki is̩e isopọ pẹlu Rẹ̀ lojumejeji. Ki a to le ba Ọlọrun rin a nilati ni nkan ti o yẹ lati ba A sọ nipa igbesi aiye wa.IOK 68.1

    Adura ni sisi ọkan ẹni payá si Ọlọrun gẹgẹbi a ti si ọkan paya fun awọn ọrẹ wa. Ki is̩e pe lati fi han Ọlọrun ohun ti awa jẹ ; s̩ugbọn ki O le ran wa lọwọ lati gba A. Adura ki fa Ọlọrun wa ba wa sugbọn a mã gbé wa lọ soke lọdọ Rẹ.IOK 68.2

    Nigbati Jesu fi wa ni aiye O kọ awọn ọmọ-ẹhin Rẹ̀ bi a ti ngbadura. O kọ́ wọn lati mu aini wọn ojõjumọ tọ Ọlọrun lọ, ati lati ko gbogbo aniyan wọn le E. Idaniloju ti o fifun wọn pe ẹ̀bẹ̀ wọn yio jẹ itẹwọgba, si tun jẹ idaniloju fun awa nã pẹlu.IOK 68.3

    Nigbati Jesu tikararẹ ngbe larin awọn enia, On a ma gba adura nigbagbogbo. Olugbala wa mọ aini wa ati ailera wa, nipa pe on tikararẹ di ẹlẹ̀bẹ̀, ti o si nwá agbara lọdọ Baba Rẹ̀, lati le se imura silẹ kikun fun ijiya ati is̩ẹ Rẹ̀. On ni ẹgbọn wa inu ailera wa, “ti a danwo li ọna gbogbo gẹgẹbi awa;” s̩ugbọn gẹgẹbi ẹniti ko d’ẹs̩ẹ, ẹda Rẹ̀ fa sẹhin kuro ninu ẹ̀iẹ̀e ibi; o farada ijakadi ati wahala ninu aiye ẹẹ̀ẹ yi. Ẹran ara Rẹ gẹgẹbi ẹda so adura di dandan ati ohun anfani. O ri itunu ati ayọ ninu biba Baba Rẹ rin. Bi o ba jẹ pe Olugbala araiye ti is̩e Ọmọ Ọlọrun le mo iyi ti o wa ninu adura, bawo ni ẹda ti ko lagbara, ẹni kiku, ti o kun fun ẹs̩ẹ iba ti ma gba adura gbigbona to nigbagbogbo.IOK 68.4

    Baba wa orun ma nduro lati tu ibukun kikun sori wa. Anfani tilẹ ni fun wa lati ma mu ni kikun ninu omi iye ti ife. Iyalenu nla ni wipe kiun ni adura ti a ngba! Ọlọrun ti s̩etan lati fi ifẹ gbọ adura totọ ti onirẹlẹ ọmọ Rẹ, sibẹsibẹ ọpọlọpọ aifẹs̩e wa ni ko jẹki a mu aini wa tọ Ọlọrun lọ. Iru ero wo ni a ro pe awọn Angẹli ni ọrun ma nro nipa awọn talaka ati alainireti enia, ti ki ye dẹs̩ẹ nigbati ọkan Ọlọrun nrọ wọn pẹlu ifẹ Rẹ̀ ailopin, ti o si s̩etan lati s̩e fun wọn ju bi nwọn ti ro tabi bere lọ, sibẹsibẹ ti nwọn si ngba adura yẹpẹrẹ ti ko ni igbagbọ ninu? Awọn Angẹli fẹran ati ma wolẹ niwaju Ọlọrun pẹlu ifẹ ; nwọn si ni ifẹ lati ma wa nitosi Rẹ̀. Nwọn ka biba Ọlọrun rin si ayọ ti o ga julọ; sibẹ o dabi ẹnipe awọn ọmọ aiye, ti o s̩e alaini iranlọwọ ti Ọlọrun nikans̩os̩o le fifunni, ni itẹlọrun lati rin lọ laisi imọlẹ ti Ẹmi Rẹ ati ibakẹgbẹpọ on Tikararẹ.IOK 68.5

    Òkunkun lati ọdọ ẹni buburu ni a ma yi awọn ti o ba kọ adura gbigba silẹ ka. Ọrọ kẹlẹkẹlẹ ti o kun fun ẹtan ati idanwọ lati ọwọ ọta wa, ma nfa wọn lọ sinu ẹs̩ẹ ; idi rẹ na si ni pe nwọn ki ilo anfani daradara ti Ọlọrun ti fifun wọn ti is̩e adura gbigba.IOK 70.1

    E ha tis̩e ti awọn ọmọkunrin ati awọn ọmọbirin Ọlọrun nilati s̩e àifẹ́ gbadura, niwọn igbati adura jẹ kọ́kọ́rọ́ ni ọwọ onigbagbọ lati s̩i ile isura ọrun, nibi orisun is̩ura ati agbara ailopin? Ni aijẹ pe a kun fun is̩ọra-ẹni ati adura nigbagbogbo a wa ninu ewu aibikita ati iyapa kuro loju ọna tarà. Nigbagbogbo ni ọta fe mã gbe nkan di oju ọ̀na ti o lọ si ibi itẹ-ãnu, ki a má bá le ri õre-ọfẹ ati agbara lati le dojukọ idanwo nipa ẹbẹ ati igbagbọ.IOK 70.2

    Awọn idi kan pataki wà ti a fi le ni ireti pe Ọlọrun yio gbọ adura wa. Ọkan ninu awọn idi wọnyi ni pe a nilati mọ̀ pe a s̩e alaini iranlọwọ Rẹ̀. On ti s̩e ileri pe “Nitori emi o da omi lu ẹniti ongbẹ ngbẹ, ati ìsan omi si ilẹ gbigbẹ” Isaiah 44:3. Awọn wọnni ti ebi npa ti ongbẹ si ngbẹ si ipa ọna ododo ti wọn ntẹlẹ Ọlọrun pẹlu ọkan totọ, ni idaniloju pe ao tẹ wọn lọrun. A nilati si ọkan wa paya si agbara Ẹmi Mimọ bi bẹkọ a ko le ri ibukun Ọlọrun gbà.IOK 70.3

    Ijiyan ni aini wa nla jẹ lotọ, a si ma bẹbẹ kikankikan fun wa. S̩ugbọn o yẹ ki a wa Oluwa lati s̩e iru is̩ẹ wọnyi fun wa. O sọ wipe “Bere ao si fifun yin.” “Ẹniti ko da Ọmọ ontikalarẹ si, s̩ugbọn ti o jọwọ rè lọwọ fun gbogbo wa yio ha ti s̩e ti ki yio fun wa ni ohun gbogbo pẹlu Rẹ̀ lọfẹ? Matteu 7:7. Romu 8:32.IOK 70.4

    Bi a ba gba ẹs̩ẹ si aiyà wa, bi a ba di ẹs̩ẹ amọmọ̀ dá kan mu, Oluwa ko le gbo ohun ẹbe wa. Sugbọn adura onirobinujẹ ti o ronupiwada jasi itẹwọgba. Nigbati a ba mu ohun ai- tọ gbogbo wa si etọ, a le ni igbagbọ pe Ọlọrun yio dahun awọn ẹbẹ wa. Is̩ẹ rere wa ko le mu wa yẹ fun ojurere Ọlọrun ; itoye ti Jesu ni a le fi gba wa la, ẹjẹ Rẹ̀ ni a si le fi wẹ wa nu ; sibẹ a ni iẹẹ tiwa lati s̩e fun itẹwọgba wa.IOK 70.5

    Ohun pataki miran ti o le mu ibori wa fun wa nipa adura ni igbagbọ.” Nitori ẹniti o ba ntọ Ọlọrun wa ko le s̩aigbagbọ pe O mbẹ, ati pe On ni Olusẹsan fun awọn ti o fi ara bale wa a. (Heberu 11:6). Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹhin Rẹ̀ pe “Ohunkohun ti ẹnyin ba tọrọ nigbati ẹ ba ngbadura ẹ gbagbọ pe ẹ ti ri wọn gba na, yio si ri bẹ fun nyin” Marku 11:24. Njẹ a ha gba ọrọ Rẹ̀ gbọ?IOK 71.1

    Idaniloju na tobi o si gboro, Ẹniti o si seleri yi jẹ olotitọ. Nigbati a ba bere ti a ko si ri ohun gan na ti a nbere fun gba li akoko, a nilati ni igbagbo pe Oluwa gbọ, ati pe On yio si dahun adura wa. A kun fun asise oju-inu wa si kuru tobē̩ ti a kò le s̩ai bere, fun nkan ti ko ni mu ibukun fun wa, Baba wa lọrun ninu ifẹ Rẹ̀ a si fun wa ni eyiti yio se wa ni ire nla, iru eyiti awa papa iba fẹ lati ni ti o ba jẹ wipe a le wo nkan gẹgẹbi ti ọrun ki a si ri nkan gbogbo gẹgẹbi nwọn ti ri gan. Nigbati o ba dabi ẹnipe a ko ri idahun ibere wa gba, a nilati ma wo ileri ti Oluwa ti s̩e; nitori dajudaju akoko idahun yio de, a o si ri ibukun na ti a se alaini fun julọ gba. S̩ugbọn bi a ba fi ọkan si i pe a o dahun adura wa gẹgẹbi a ti fẹ gan ati fun ohun ti a bere gan nigbagbogbo, ero aidani-loju lasan ni. Ọgbọn Ọlọrun rekọja asise, On si kun fun ore tobẹ ti ko fa ohun rere sẹhin kuro lọdọ ẹniti nrin dede. Nitorina mas̩e foya lati gbekele E, bi o tilẹ jẹpe idahun rẹ ko de kiakia. Gbe ara rẹ le ileri Rẹ ti o daju, “Bere a o si fifun nyin.” Matteu 7:7.IOK 71.2

    Bi a ba gba imọran iyemeji ati ti oberu ti a si fẹ yanju eran ti a ko le ri gbangba ki a s̩ẹs̩ẹ to ni igbagbọ, iyemeji a tubọ ma pọ a si jinlẹ si ni. Sugbọn bi a ba tọ Ọlọrun lọ, pẹlu irẹlẹ ọkan ati gẹgẹbi alailagbara, gẹgẹbi a ti ri gan, ati ninu iwa irelẹ ati igbekẹle ti igbagbọ, ti a si fi aini wa han Ẹniti ọgbon Rẹ ko nipẹkun, Ẹniti o ri ohun gbogbo ti o da, Ẹniti o se akoso ohun gbogbo nipa ọrọ on ifẹ Rẹ, On yio si fetisi gbogbo ẹbẹ wa, yio si tan imole Rẹ si ọkan wa. Nipa adura totọ ni a fi so wa pọ mọ ero Olọrun. A le má ri ẹri ti o yanilẹnu li akoko ti oju Olurapada wa ntan si wa ninu anu ati ifẹ ; s̩ugbon bẹli o ri gan. A le se alaimọ̀ owọ Re ti nfikan wa ; sugbon ọwọ Rẹ wa lara wa nipa ifẹ ati anu Re.IOK 71.3

    Nigbati a ba wá lati tọrọ anu ati ibukun lọdọ Ọlọrun, a nilati ni ẹmi ifẹ ati idariji ninu ọkan wa. Bawo ni a tis̩e le gba adura yi pe “Dari gbese wa ji wa bi awa ti ndariji awọn onigbese wa,” Matt. 6:12. sibẹ ki a si mà ni ẹmi aile-darijini? Bi a ba fẹ ki adura wa o gba awa na nilati dariji awọn ẹlomiran to gẹgẹbi a ba ti fẹ idariji Ọlọrun to.IOK 71.4

    Iforiti ninu adura jẹ ọna kan ti a le fi ri gba. A nilati ma gba adura nigbagbogbo bi a ba fẹ ma dagba ninu igbagbọ ati iriri. A nilati ma “Duro gangan ninu adura,” Ẹ ma duro s̩ins̩in ninu adura igba, ki ẹ si ma s̩ọra ninu ọkanna pẹlu idupẹ. Romu 12:12. Kolose 4:2. Peteru gba awọn olugbagbọ niyanju pe,” I Peteru 4:7. Paulu sọ bayi pe “Ninu ohun gbogbo, nipa adura ati ẹbẹ pẹlu idupẹ, ẹ ma fi ibere yin han fun Ọlọrun. Filipi 4:6. Juda wipe, “Ẹnyin olufẹ, ti ẹ ngbadura ninu Ẹmi Mimọ, Ẹ ma pa ara yin mọ ninu ifẹ Ọlọrun.” (Juda 20, 12).IOK 72.1

    Adura laisimi ni irẹpọ ọkan totọ pẹlu Ọlọrun, ki iye lati ọdọ Ọlọrun le ma san si aiye wa; ati lati inu igbe-aiye wa ki ailabawọn ati iwa mimọ si ma san pada lọ ọdọ Ọlọrun.IOK 72.2

    Adura nfẹ ãyan; mase jẹki ohunkohun di ọ lọwọ. Sa gbogbo ipa rẹ lati jẹki idapọ wa larin Jesu ati ọkan rẹ. Wa aye lati mà lọ si gbogbo isin adura. Awọn wọnni ti nwa ãye nitotọ lati ma ba Ọlọrun sọrọ, yio mã wa dede sibi isin adura, nwọn a si ma sa ipa wọn lati s̩e is̩ẹ ti a yan wọn si, pẹlu itara ati ipinnu lati ri gbogbo anfani ti o yẹ gba. Nwọn o gbiyanju lati fi ara wọn si ibiti nwọn le ri itansan imọlẹ lati ọrun gba.IOK 72.3

    O yẹ ki a ma gbadura larin idile ; ju ohun gbogbo lọ a ko gbọdọ kọ adura ikọkọ silẹ; nitoripe eyi ni iye ọkan. O soro fun ọkan lati dagba dada niwọn igbati o ba kọ adura silẹ. Adura idile tabi ti agbajọ nikan ko to. Nibi ikọkọ jẹki ọkan rẹ si silẹ fun iyẹwo Olọrun. Ọlọrun ti ngbọ adura nikan ni o le gbọ adura ikọkọ. Ko si eti ajeji kan ti o nilati gbọ iru ẹ̀bẹ̀ bẹ. Ninu adura ikọ̀kọ̀, ọkàn ko si labẹ ohun idiwọ ti o yi i ka, o bọ lọwọ idagiri. Pẹlu iparọrọ ati itara ni ọkan wa yio fi wa Ọlọrun. Agbara ti o nti ọdọ ẹniti o nriran ni ikọkọ wa yio dun yio si ma ba ni gbe titi, eti ẹniti o s̩i silẹ lati gbọ igbe ti o njade lati inu ọkan. Nipa ẹmi irẹlẹ ati igbagbọ ti o pa rọrọ, ni okan fi ma nba Ọlọrun sọrọ, ti isi ma gba itansan imọlẹ ọrun lati gbe e ro, ati lati mu u lokun ninu ogun Es̩u. Ọlọrun ni ile is̩ọ́ agbara wa.IOK 72.4

    Ẹ ma gbadura ninu iyewu nyin ; bi ẹ ba si ti nlọ si ibi is̩ẹ yin ojojumọ, ẹ ma gbe ọkan yin soke si ọdọ Ọlọrun ; Bayi ni Enoku s̩e ba Ọlọrun rin. Iru adura jẹjẹ bayi ma nlo tara gẹgẹbi turari didun si ibi itẹ Ọlọrun. Es̩u ko si ni le s̩ẹgun ọkan ti O gbẹkẹle Ọlọrun.IOK 72.5

    Ko si akoko tabi ibiti a ko gbe le gbe ohun ẹbẹ wa soke si Ọlọrun. Ninu ẹmi adura ti O gbona ko si ohun ti O le di ọkan wa lọwọ. Ibas̩e larin ogunlọgọ enia larin ita, tabi nibi is̩ẹ a le mu ẹbẹ wa tọ Ọlọrun lọ, ki a si bẹbẹ fun itọsọna ti ọrun, gẹgẹbi Nehemiah nigbati O fi bẹbẹ niwaju ọba Atasasta. A le ri iyẹwu adura nibikibi ti O wu ki a wa. A nilati s̩i ilẹkun ọkan wa silẹ nigbagbogbo ki ipe wa si ma goke lọ ki Jesu le wa gbe inu ọkan wa gẹgẹbi alejo lati ọrun.IOK 73.1

    Bi o tilẹ jẹ pe abàwọn ati atẹgun ibajẹ yi wa ka, kò yẹ ki a mã mi ẽmi buburu rẹ si imu, s̩ugbọn a lè mã gbe inu afẹfẹ mimọ ti ọrun. A lè ti ilẹkun mọ awọn èro aimọ nipa gbigbe ọkan soke si waju Ọlọrun ninu adura tõtọ. Awọn wọnni ti ọkan wọn si silẹ lati gba iranlọwọ ati ibukun Ọlọrun yio mã rin ninu atẹ̀gun ti orun, ti O mọ́ ju ti aiye yi lọ, nigbagbogbo ni wọn O si mã ba Ọlọrun sọrọ.IOK 73.2

    O yẹ ki a tubọ mọ Jesu dãda, ki a si tubọ mọ riri nkan ti is̩e ti iyè ainipẹkun. Ẹwa iwa mimọ ni lati kun ọkan awọn ọmọ Ọlọrun ; ki eyi ki O si le ri bē̩, O yẹ ki a wa ãye fun is̩ipaya ohun ti ọrun :IOK 73.3

    Ẹ jẹki a fa ẽmi wa lo si oke ki Ọlọrun ba le mí afẹfẹ ti ọrun si wa. A le sunmọ Ọlọrun debi pe ninu gbogbo idanwo airotele ki ero wa le mã yi si ọdọ Rẹ̀ gẹgẹbi itanna iti yi oju si õrun. Fi aini rẹ, ayọ rẹ, ibanujẹ rẹ, aniyan rẹ, ati ẹ̀ru rẹ siwaju Ọlọrun. Iwọ ko le fi yọ Ọ lẹnu ; bē̩ni iwọ ko si le da A lagara. Ẹniti O mọ iye irun ori rẹ, ko le s̩ainãni aini awọn ọmọ Rẹ̀ “Oluwa kun fun iyónu O si li ãnu.” (Jakobu 5:11) Awọn ẹdun wa a mã fọwọkan ọkan ife Rẹ̀, papa nigbati a ba sọ wọn fun U. Mu ohunkohun ti O ndãmu ọkan to O lo. Ko si ohun ti O tobi ju fun U lati farada ; nitoripe on li O di awọn aiye mu, On ni nse akoso ohun gbogbo ti O wà ni aiye. Ko si ohun ti ise ti alafia wa ti O kere ju fun U lati le ka ninu iwe iriri wa ; ko si wahala ti O nira fun lati la kọja. Ko si ohun buburu kan ti O le kọlù awọn ọmo Rẹ̀ ti O kere julọ, ko si aniyan kan ti O le damn okan, ko si ohun ayọ, idunnu, tabi adura tõtọ ti a gba ti Baba wa ti mbẹ li ọrun ko se akiyesi, tabi ki O si fi ayọ ni ipin ninu re. ” O mu awọn onirora aiya larada, O si di ọgbé wọn.” Orin 147:3. Ibatan ti O wá lãrin Olọrun ati okan kokan yanju gẹdegbe O si kún tobē̩ ti O fi dabi ẹnipe ko tun si ẹlomiran ninu aiye ti 0 le tun pin ninu itọju Rẹ̀, tabi bi ẹnipe ko tun si ọkan miran mọ ti o fi Ayànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ fun.IOK 73.4

    Jesu wipe “Ẹnyin o bère li orukọ mi, Emi kò si wi fun nyin pe Emi o bẽre lọwọ Baba fun nyin” nitoriti Baba tikararẹ fẹran nyin”, “Èmi li o yàn nyin ki ohunkohun ti ẹ ba bẽre lọwọ Baba li orukọ mi, ki o le fifun nyin.” Johannu 16:26, 27; 15:16. S̩ugbọn lati gbadura ni orukọ Jesu ki is̩e kiki wipe ki a sa daruko Rẹ ni ibẹrẹ ati ipari adura wa lasan. O jẹ igbadura ninu ẽro ati ẹmi Jesu, ki a gba awọn ileri Rẹ̀, ki a simi le õre-ọfẹ Rẹ, ki a si mã s̩e is̩ẹ ti On nã s̩e.IOK 74.1

    Ọlọrun kò sọ wipe ki ẹnikẹni ninu wa di aládagbe, ki a si kọ ibagbe awọn arakunrin wa sile, ki a ba le ya ara wa sọtọ fun is̩ẹ isin. Igbe aiye wa nilati jẹ igbe-aiye bi ti Kristi, lãrin oke ati ọpọ enia. Ẹniti ko se ohun kan ju ki o ma gbãdura lọ yio tete dawo adura duro tabi ki adura rẹ ra di as̩a lasan. Nigbati awọn enia ba ti kọ igbe aiye ibanikẹgbẹ pọ silẹ, ti nwọn si ya ara wọn kuro ni ọna is̩ẹ igbagbọ, ti nwọn ko tun le ru agbelebu mọ; ti is̩ẹ Jesu si su wọn, ẹniti O s̩is̩ẹ kikankikan fun wọn, nwọn a sọ koko ọrọ adura nu, agbara fun as̩arò ko si si fun wọn mọ. Adura wọn a di ti imọ-ti-arawọn nikan. Nwọn ko tilẹ tun le gbadura fun aini ti awọn ẹlomiran tabi fun idagbaseke ti ijọba Kristi, tabi gbadura fun agbara lati fi s̩e is̩ẹ.IOK 74.2

    Adanù nla ni fun wa nigbati a ba kọ̀ anfani ifi ọwọ-sowọ lati fun ara wa ni agbara ati ọrọ iyanju ninu is̩ẹ Ọlọrun. Otitọ Ọrọ Rẹ̀ a si sọ iyi ati agbara rẹ nu ninu ọkan wa. Agbara iyasimimọ ọkan a dẹkun ati ma fi imọlẹ ati is̩iri fun u, a si wa fasẹhin nipa ohun ti ẹmi. Lãrin ẹgbẹ wa bi onigbagbọ ọhun nla ni a nsonu nipa aini ẹmi ibakedun fun ara wa. Ẹniti ko ni oyaya kò se ohun ti Ọlọrun fẹ ki o s̩e. Nipa ọyàyà s̩is̩e ni a fi nni ibakẹdun pẹlu awọn ẹlomiran, o si jẹ ọna idagbasoke ati agbara fun wa ninu ise Ọlọrun.IOK 74.3

    Bi awọn onigbagbo yio ba mã rin pọ, ki nwọn si ma sọrọ pọ nipa ifẹ Ọlọrun, ati nipa otitọ iyebiye ti irapada, ọkan awọn tikarawọn yio ni itura, itura yio si wa fun ọmọ-nikeji wọn. Lojõjummọ o yẹ ki a mã kọ ẹko gidigidi nipa Baba wa ọrun, ki a si tubọ mã ni iriri titun si nipa õre-ọfẹ Rẹ ; nigbana ni inu wa yio ma dun lati sọ ti ife Rẹ̀: bi a ba nse eyi, ọkan awa tikara wa yio gbona, a o si kun fun is̩iri. Bi a ba nro ti a si nsọ nipa Jesu ti a si din ọrọ nipa ti ara wa kù, oju Rẹ̀ yio tubọ wa lara wa lọpọlọpọ.IOK 74.4

    S̩ugbọn bi a o ba ma ro nipa Ọlọrun to bi a ti nri awọn ẹri itoju Rẹ̀ lori wa to, a nilati ma ti i si ọkan wa nigbagbogbo, ki a si ni inudidun lati ma sọrọ nipa Rẹ̀, ki a si ma fi iyin fun U. A mà nsọrọ nipa awọn nkan ti aiye to wa fun igba diẹ nitoripe a ni nudidun si wọn. A nsọrọ nipa awọn ọrẹ wa nitoripe a fẹran wọn; ayọ ati ibanujẹ wa a mã kan wọn. Sibẹ a ni idi ti o se pataki lati fẹran Ọlọrun ju awọn ọrẹ wa ninu aiye lọ ; o si yẹ ki o jẹ nkan ti o ba wa laramu julọ ninu aiye lati fi Ọlọrun s̩aju ninu ero wa, ki a mã sọ ti õre ati agbara Rẹ. Áwọn ẹbun iyebiye ti o fifun wa ki ise lati jẹki o gba ọkan ati ifẹ wa, tobẽ ti a kõ le fi ri ohun kankan mu wa fun Ọlọrun ; nigbagbogbo ni nwọn ni lati mã ran wa leti nipa Rẹ, ati lati dè wa pẹlu idè ife ati ọpẹ si Olõre wa ti ọrun. Ni isalẹ nhin a fi ara mọ aiye pupọju. Ẹ jẹki a gbe oju wa si ẹnu ilẹkun agọ loke, nibiti imọlẹ ogo Ọlọrun gbe ntan loju Kristi Ẹniti “O si le gba wọn la pẹlu titi de opin, ẹniti o ba tọ Ọlọrun wa nipasẹ Rẹ̀.” Heberu 7:25.IOK 76.1

    O yẹ ki a tubọ mã yin Ọlọrun “nitori õre Rẹ ati nitori is̩ẹ iyanu Rẹ si awọn ọmọ enia.” Orin 107:8. Itara igbagbọ wa ko nilati duro lori kiki titọrọ ati gbigba nikan. Ẹ mas̩e jẹki a mã ro nigbagbogbo nipa kiki aini wa, ki a si gbagbe awọn ohun rere ti a nri gba. Adura wa ko pọju, s̩ugbọn is̩ọpẹ wa ni kò to nkan. Awa ni imã tẹwọ gba ibukun lọwọ Ọlọrun nigbakũgba, sibẹ ọpẹ kekere li a nda, iyin diẹ li a si fifun U nitori ohun ribiribi ti O s̩e fun wa.IOK 76.2

    Nigba lailai Oluwa sọ fun awọn ọmọ Israeli nigbati nwọn pade nibi isin Rẹ̀ pe, “Nibe ni ki ẹnyin ki o si mã jẹ niwaju Oluwa Ọlorun nyin ki ẹnyin ki o si mà yọ̀ ninu ohun gbogbo ti ẹnyin fi ọwọ le, ẹnyin. ati awon ara ile nyin, ninu eyiti Oluwa Òlọrun rẹ fi bukun u fun ọ.” Deuteronomi 12:7. Ohunkohun ti a ba se fun ogo Ọlọrun a ni lati se e pẹlu ayọ nla, pẹlu orin iyin ati ọpẹ, ki ise pelu ibanujẹ ati iron.IOK 76.3

    Ọlọrun wa je oninũre Baba Alãnu. Ko ye ki a mã se is̩ẹ Rẹ̀ pẹlu ibanujẹ tabi gẹgẹbi isẹ iponju. O yẹ ki a fi isin Ọlọrun s̩e ayọ ki a si ni ipa ninu ise Rẹ̀. Olọrun ko ni fẹ ki awon ọmọ Rẹ̀ ti o ti pese igbala nla fun, mã hùwa si I bi akonis̩is̩ẹ ti o le, ti o si s̩oro lati tẹ lorun. On ni ọrẹ wọn ti o dara julọ; nigbati nwọn ba si nsin I, O fẹ lati wa pẹlu won, lati bukun ati lati tù wọn ninu, ati lati fi ifẹ ati ayọ kun ọkan won. Oluwa fẹ ki awọn omọ-Rè ni itunu ninu isin Rẹ̀, ati lati ni igbadun ninu is̩ẹ Rẹ̀ ju inira lo. On fe pe ki awọn ti o ba wa lati sin I mu ero iyebiye ti itọju ati ifẹ Rẹ̀ lọ pẹlu wọn, ki inu wọn le ma dun ninu gbogbo is̩ẹ wọn ojõjumọ, ki wọn ba le ni ore-ọfẹ lati s̩e is̩ẹ wọn pẹlu otitọ ati ododo ninu ohun gbogbo.IOK 76.4

    O yẹ ki a mã pejọ si ẹsẹ agbelebu. Kristi ẹniti a kàn mo agbelebu ni lati jẹ koko as̩aro wa, isọrọ wa ati ero wa ti o layọ julọ. A nilati ma pa gbogbo ibukun ti a ri gba lọdọ Ọlọrun mọ si aiya wa, nigbati a ba si mọ iyi ife nla Rẹ, o yẹ ki a mã ko gbogbo aniyan wa le atẹlẹwọ nì ti a kan mọ agbelebu fun wa.IOK 77.1

    Ọkan le goke lọ si ọrun nipa orin iyin. Orin ati duru ni a fi yin Ọlọrun ninu agọ loke ọrun, bi a si ti nfi ọpẹ wa hàn, isin wa nsunmọ isin ti awọn ẹgbẹ ogun ti ọrun. “Ẹnikẹni ti o ba ru ẹbọ iyin, o yin Ọlọrun logo.” Jẹki a fi ayọ ti o kun. fun òwo wa siwaju Eleda pelu idupe, ati ohun orin.” Orin 50:23: lsa. 51:3.IOK 77.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents