Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI OGUN—ISỌJI NLA TI ẸSIN

    Ninu asọtẹlẹ iṣẹ iranṣẹ angẹli akọkọ ti Ifihan 14, a sọ nipa isọji nla ti ẹsin kan labẹ ipolongo wiwa Kristi laipẹ. A ri angẹli kan ti o n fo “laarin agbede meji ọrun, ti oun ti iyinrere ainipẹkun lati waasu fun awọn ti n gbe ori ilẹ aye, ati si gbogbo orilẹ ede, ati ẹya, ati ede, ati eniyan.” “Pẹlu ohùn rara”, o kede iṣẹ iranṣẹ naa wipe: “Bẹru Ọlọrun ki ẹ si fi ogo fun nitori ti wakati idajọ Rẹ de: ki ẹ si jọsin Ẹni ti o da ọrun ati aye, ati okun, ati awọn orisun omi.” Ẹsẹ 6, 7.ANN 158.1

    Nitori ti a sọ wipe angẹli ni o n kede ikilọ pataki yii ṣe pataki. Nipasẹ iwa mimọ, ogo, ati agbara iranṣẹ ọrun, o tẹ ọgbọn Ọlọrun lọrun lati ṣe afihan bi iṣẹ ti a fẹ ki iṣẹ iranṣẹ yii ṣe ti ṣe pataki tó ati agbara ati ogo ti yoo tẹle. Angẹli naa si n fo ni “agbede meji ọrun,” “ohùn rara”ni a fi kede ikilọ naa, ati kikede rẹ si gbogbo awọn “ti n gbe ori ilẹ aye,” —”si gbogbo orilẹ ede, ati ẹya, ati ede, ati eniyan”—sọ nipa bi ẹgbẹ yii yoo ti yara kankan to ati bi yoo ti tan ka gbogbo aye to.ANN 158.2

    Iṣẹ iranṣẹ naa funra rẹ tan imọlẹ si igba ti ẹgbẹ yii yoo wa. A sọ wipe o wa lara “iyinrere ainipẹkun;” o si kede ibẹrẹ idajọ. A ti waasu iṣẹ iranṣẹ igbala lati igba yii wa; ṣugbọn iṣẹ iranṣẹ yii wà lara iyinrere ti a le kede ni akoko ikẹyin nikan nitori nigba naa ni o to le jẹ wipe wakati idajọ ti de. Awọn asọtẹlẹ wọnyi ṣe afihan awọn iṣẹlẹ ti yoo pari si ibẹrẹ idajọ. Eleyi jẹ otitọ ni pataki julọ nipa iwe Daniẹli. Ṣugbọn abala asọtẹlẹ rẹ ti o sọ nipa ọjọ ikẹyin ni a sọ fun Danieli pe ki o tì pa, ki o si fi edidi dii “titi fi di akoko ikẹyin.” Ayafi igba ti a ba wa ninu akoko ikẹyin yii ni a to le kede iṣẹ iranṣẹ nipa idajọ, lori imuṣẹ awọn asọtẹlẹ wọnyi. Ṣugbọn woli naa sọ wipe, ni igba ikẹyin, “ọpọ ni yoo sa sihin sọhun, imọ yoo si pọ si.” Daniẹli 12:4.ANN 158.3

    Apostoli Pọlu kilọ fun ijọ wipe ki wọn maṣe wọna fun wiwa Kristi ni akoko tirẹ. O sọpe, “Ọjọ naa ki yoo wa ayafi bi iyapa ba kọkọ wa ná, ti a si fi ẹni ẹṣẹ nì hàn.” 2 Tẹsalonika 2:3. O di opin akoko iyapa nla naa, ati opin akoko gbọọrọ ti iṣakoso “ọkunrin ẹṣẹ” ki a to le wọna fun wiwa Oluwa wa. “Ọkunrin ẹṣẹ,” ti a tun pe ni “ohun ijinlẹ aiṣedeede,” “ọmọ ègbé,” ati “ẹni ẹṣẹ nì” duro fun ijọ padi, eyi ti, gẹgẹ bi a ti sọ ọ ninu isọtẹlẹ, yoo jọba fun 1260 ọdun. Akoko yii pari ni 1798. Wiwa Kristi ko le ṣẹlẹ ṣaaju akoko yii. Ikilọ Pọlu kari gbogbo akoko Kristẹni titi di ọdun 1798. Ni abala akoko yii ni a o kede iṣẹ iranṣẹ bibọ lẹẹkeji.ANN 158.4

    A koi tii waasu iru iṣẹ iranṣẹ yii ri. Pọlu, bi a ti ri, ko waasu rẹ; o tọka awọn arakunrin rẹ si ọjọ iwaju jijina réré gẹgẹ bi akoko wiwa Oluwa. Awọn Alatunṣe ko waasu rẹ. Martin Luther sun ọjọ idajọ si bii 300 ọdun siwaju lati akoko tirẹ. Ṣugbọn lati 1798, a ti ṣi iwe Daniẹli silẹ, imọ nipa isọtẹlẹ ti pọ si, ti ọpọlọpọ si ti kede iṣẹ iranṣẹ ti idajọ ti o sunmọ etile.ANN 158.5

    Gẹgẹ bi iṣẹ Atunṣe nla ti ọrundun kẹrindinlogun, ẹgbẹ ti n kede ipadabọ farahan lẹẹkan naa ní awọn oriṣiriṣi orilẹ ede ti wọn ti n ṣe ẹsin Kristẹni. Ni ilẹ Europe ati Amẹrika, a dari awọn eniyan ti wọn nigbagbọ, ti wọn si n gbadura lati kọ nipa isọtẹlẹ, nipa ṣiṣe itọleseese akọsilẹ ti a misi, wọn ri pẹlu idaniloju wipe opin ohun gbogbo ti sunmọ etile. Ni ọpọlọpọ ilu, awọn ẹgbẹ Kristẹni ti wọn kò mọ ara wọn, ko ara wọn jọ pọ, nipasẹ ẹkọ Bibeli nikanṣoṣo, wọn ri mọ wipe wiwa Olugbala ti sunmọ etile.ANN 158.6

    Ni 1821, ọdun mẹta ṣaaju ki Miller to kọ ẹkọ isọtẹlẹ de ibi ti o tọka si akoko idajọ, Dr Joseph Wolff, “ajiyinrere si gbogbo aye,” bẹrẹ si nii polongo wipe wiwa Olugbala ti sunmọ etile. A bi Wolff si Germany, awọn obi rẹ si jẹ Heberu, baba rẹ jẹ rabbi awọn Ju. O ti gbagbọ ninu otitọ nipa ẹsin Kristẹni lati igba ti o ti wa ni ọmọde. O jẹ ọlọpọlọ pipe, ti iye rẹ yè kooro, o tẹti si ifọrọwerọ ti o waye ninu ile baba rẹ bi awọn Heberu onifọkansin ti n pejọ pọ lojoojumọ lati sọ nipa ireti ati afojusun awọn eniyan wọn, ogo Mesaya ti n bọ, ati imubọsipọ Israeli. Ni ọjọ kan, nigba ti o gbọ ti a darukọ Jesu ti Nasarẹti, ọdọmọkunrin naa beere pe tani i ṣe. “Ara Ju ti o ni ẹbun ju ẹnikẹni lọ” ni a fi da lohun; “ṣugbọn nigba ti o pe ara rẹ ni Mesaya, ajọ igbẹjọ awọn Ju da ẹjọ iku fun.” O beere pe, “Ki lo de ti a fi pa Jerusalẹmu run, ati idi ti a fi wa ni igbekun?” Baba rẹ dahun wipe, “O maṣe o! O maṣe o!, nitori ti awọn Ju pa awọn woli ni.” Ero naa wa sọ si ọkan ọmọ naa wipe: “Boya woli naa ni Jesu pẹlu, ti awọn Ju si pa a nigba ti o wa ni ailẹṣẹ.” Ifẹ ọkan rẹ lagbara debi pe, bi a tilẹ ti ṣe ofin pe ko gbọdọ wọ inu ile ijọsin, ni ọpọ igba ni a duro ni ita lati le gbọ iwaasu.ANN 158.7

    Nigba ti o jẹ ọmọ ọdun meje pere, o fọnu fun agbalagba Kristẹni kan nipa iṣẹgun ọjọ iwaju ti Israeli nigba ti Mesaya ba de, agbalagba naa fi aanu sọ fun wipe: “Ololufẹ, ọdọmọkunrin, maa sọ ẹni ti Mesaya n ṣe nitootọ fun ọ: Jesu Kristi ti Nasarẹti ni, . . . ẹni ti awọn baba nla rẹ kan mọgi; bi wọn ti ṣe si awọn woli atijọ. Lọ si ile ki o ka Aisaya ori kẹtalelaadọta, waa ri daju wipe Kristi ni Ọmọ Ọlọrun.” Igbagbọ kun inu ọkan rẹ lọgan. O lọ si ile o si ka Iwe Mimọ, o yaa lẹnu lati ri bi o ti wá si imuṣẹ rẹgi ninu Jesu ti Nasarẹti. À bí otitọ ni ọrọ awọn Kristẹni? Ọdọmọkunrin naa beere itumọ isọtẹlẹ naa lọwọ baba rẹ, ṣugbọn idakẹrọrọ kikoro ni o rí ti ko si le sọ nipa ọrọ naa mọ. Amọ eleyii tubọ jẹ ki ifẹ rẹ lati mọ nipa ẹsin Kristẹni o pọ si ni.ANN 159.1

    Imọ ti o n wa ni a mọọmọ pamọ kuro ni arọwọto rẹ ninu ile Ju rẹ; ṣugbọn nigba ti o pe ọmọ ọdun mọkanla, o kuro ni ile baba rẹ, o si wọ inu aye lọ lati wa ẹkọ funra rẹ, lati yan ẹsin ati iṣẹ ti yoo ṣe. O gbe ni ile awọn ibatan rẹ fun igba diẹ, ṣugbọn laipẹ, a le e jade bi apẹyinda, ni oun nikan, lailowolọwọ o nilati gbe igbesi aye rẹ laarin awọn ajeji. O lọ lati ibi kan si ekeji, o n fi pẹlẹkutu kẹkọ, o si n ri owo nipa kikọni ni ede Heberu. Nipasẹ olukọ Katoliki kan, o gba igbagbọ Romu o si ni ero wipe oun yoo di ajiyinrere si awọn eniyan rẹ. Pẹlu ero yii, o lọ, lẹyin ọdun diẹ, lati kẹkọ ni College of Propaganda ni Romu. Nibi, iṣesi rẹ lati da inu ro ati lati sọrọ bi nnkan ti ri mu ki o gba ẹkọ odi. O tako awọn aṣiṣe ijọ ni gbangba o tun sọ wipe wọn nilo atunṣe. Ni akọkọ awọn ijoye ijọ fi oju rere wo o, ṣugbọn lẹyin igba diẹ, a mu u kuro ni Romu. Labẹ iṣọ ijọ, o lọ lati ibi kan si ekeji, titi ti o fi han gbangba pe ko le tẹriba fun igbekun ẹsin Romu. A sọ wipe ko le ṣe e tunṣe mọ, a si fi silẹ lati lọ si ibi ti o ba fẹ. Bayii, o lọ si England, o si gba igbagbọ Protestant, o darapọ mọ ijọ England. Lẹyin ẹkọ fun ọdun meji, o jade lati bẹrẹ iṣẹ rẹ ni ọdun 1821.ANN 159.2

    Nigba ti Wolff gba otitọ nla ti wiwa Kristi ni akọkọ gẹgẹ bi “Ọkunrin Onirobinujẹ, ti o si mọ ẹdun ọkan,” o ri wipe awọn asọtẹlẹ kọni yekeyeke pẹlu nipa ipadabọ Rẹ lẹẹkeji pẹlu agbara ati ogo. Nigba ti o wọna lati dari awọn eniyan rẹ si Kristi ti Nasareti gẹgẹ bi Ẹni ti a ṣeleri, ati lati tọka wọn si wiwa Rẹ lakọkọ ni irẹlẹ gẹgẹ bi irubọ fun ẹṣẹ eniyan, o kọ wọn nipa wiwa Rẹ lẹẹkeji pẹlu gẹgẹ bi ọba ati olugbala.ANN 159.3

    O sọ pe “Jesu ti Nasarẹti, Mesaya tootọ, ẹni ti a gun ni ọwọ ati ẹsẹ, ti a mu wa gẹgẹ bi ọdọ aguntan ti a fẹ pa, ti o jẹ Ẹni ibinujẹ ti o tun mọ ẹdun, ẹni O wa lakọkọ lẹyin ti a gba ọpa aṣẹ kuro lọwọ Juda ati agbara iṣofin kuro labẹ ẹsẹ rẹ; yoo wa ni ẹẹkeji ninu ikuuku awọsanma, ati pẹlu kakaki olu angẹli” “yoo si duro lori oke Olifi; ijọba naa ti a fi igba kan fifun Adamu lori gbogbo ẹda, ti o si padanu (Jẹnẹsisi 1:26; 3:17), ni a o fifun Jesu. Yoo jẹ ọba lori gbogbo aye. Irora ati ipohunrere ẹkun ẹda yoo dopin, ṣugbọn a yoo gbọ orin iyin ati ọpẹ. . . . Nigba ti Jesu ba wá ninu ogo Baba Rẹ, pẹlu awọn angẹli mimọ, . . . awọn oku ninu Kristi ni yoo kọ jinde. I Tẹsalonika 4:16; I Kọrinti 15:32. Eyi ni awa Kristẹni pe ni ajinde akọkọ. Nigba naa ni ijọba ẹranko naa yoo yipada (Aisaya 11:6—9), wọn yoo si tẹriba fun Jesu. O. Dafidi 8. Alaafia yoo jọba ni gbogbo aye.” “Lẹẹkansi Oluwa yoo boju wo aye, yoo si sọ wipe, ‘Kiyesi daradara ni.”ANN 159.4

    Wolff gbagbọ wipe wiwa Oluwa sunmọ etile, itumọ ti o fun awọn akoko isọtẹlẹ gbe opin ohun gbogbo si akoko ti o sunmọ akoko ti Miller tọka si pẹkipẹki. Wolff dahun si awọn ti wọn kà lati inu Iwe Mimọ wipe, “Ni ti ọjọ ati wakati ko si ẹni ti o mọ ọ,” wipe eniyan ko ni mọ ohunkohun nipa bi wiwa Rẹ yoo ti sunmọ to, wipe: “Njẹ Oluwa wa sọ wipe a ko gbọdọ mọ ọjọ ati wakati bi? Ṣe ko fun wa ni awọn ami akoko, ki a le mọ bi wiwa Rẹ ba sunmọ, bi eniyan ti n mọ bi igba ẹrun ti n sunmọ nipasẹ bi igi ọpọtọ ti n yọ ewé? Matiu 24:32. Ṣe a ko gbọdọ mọ igba naa ni, nigba ti Oun funra Rẹ gba wa niyanju, kii ṣe lati ka woli Daniẹli nikan, ṣugbọn lati ni oye rẹ? ninu Danieli kan naa, nibi ti a ti sọ wipe ki a sé ọrọ naa mọ ọhun titi fi di akoko ikẹyin (eyi ti o ṣẹlẹ ni akoko ti Rẹ), ati wipe ‘ọpọ ni yoo sa sihin sọhun’ (ọrọ Heberu lati ṣalaye wíwò ati rironu lori akoko), ati pe imọ (nipa akoko naa) ‘yoo pọ si’ Daniẹli 12:4. Ni afikun, kii ṣe erongba Oluwa wa ni lati sọ pẹlu eyi wipe a ko ni mọ bi akoko ba ti n sunmọ etile, ṣugbọn wipe ‘ọjọ naa ati akoko naa’ ni pàtó ‘ni ẹnikẹni ko mọ.’ Ọpọ ninu rẹ ni O sọ wipe, a yoo mọ nipasẹ awọn ami akoko, lati le mu ki a gbaradi fun wiwa Rẹ, gẹgẹ bi Noah ti pese ọkọ silẹ.”ANN 159.5

    Nipa eto itumọ, tabi aṣitumọ Bibeli ti o wọpọ, Wolff kọwe wipe: “Eyi ti o pọju ninu ijọ Kristẹni ni wọn ti yapa kuro ninu itumọ Bibeli ti o ye kooro, ti wọn si n lo ilana ironu bii ti awọn ẹlẹsin Buddha, ti wọn gbagbọ wipe idunu eniyan ni ọjọ iwaju yoo jẹ nipa rinrin ninu afẹfẹ, wọn ro wipe bi wọn ba ti ri awọn Ju wọn nilati tumọ rẹ si Gentile; nigba ti wọn ba ka Jerusalẹmu, wọn gbọdọ tumọ rẹ si ijọ; bi a ba si sọ pe aye, o tumọ si ofurufu; ati nipa wiwa Oluwa, wọn gbọdọ tumọ rẹ si itẹsiwaju awọn ẹgbẹ ajiyinrere; ati lilọ si oke Oluwa, tumọ si ipade nla ti awọn Methodist.”ANN 160.1

    Laarin ọdun mẹrinlelogun, lati 1821 si 1845, Wolff ririnajo kaakiri: ni Africa, o bẹ Ijibiti ati Abyssinia wo; ni Asia, o la Palestine, Syria, Persia, Bokhana ati India kọja. O tun ṣe abẹwo si United States, ninu irin ajo rẹ sibi, o waasu ni erekuṣu Saint Helena. O lọ si New York ni August 1837; lẹyin igba ti o waasu ninu ilu naa tan, o waasu ni Philadelphia ati Baltimore, nikẹyin, o lọ si Washington. Nibi, o sọ pe “lori àbá tí ààrẹ àná, John Quincy Adams mu wá ni ọkan ninu awọn ipade ile igbimọ aṣofin gbogbo ilẹ naa, pẹlu ohun kan, wọn gba mi laaye lati lo gbọngan ile aṣofin fun idanilẹkọ, eyi ti mo ṣe ni ọjọ Satide, ti gbogbo ọmọ ile igbimọ aṣofin si wa nibẹ, bakan naa ni biṣọbu ti Virginia ati alufa ati awọn ọmọ ijọ ni Washington ṣe pẹlu. Awọn aṣejọba ni New Jersey ati Pennsylvania, ti mo ṣe idanilẹkọ lori awọn iwadi mi ni Asia, ati lori iṣejọba Kristi ní ti ara niwaju wọn, fun mi ni irú iyì kan naa.”ANN 160.2

    Dr Wolff rin irinajo lọ si awọn orilẹ ede ti wọn luko julọ laisi idaabobo aṣẹ Europe kankan, o farada ọpọlọpọ ijiya, ti ewu ti a ko le ka tan si yi i ka. A na a ni atẹlẹsẹ, a fi ebi pa a, a tàá bi ẹru, ni igba mẹta ni a dajọ iku fun. Awọn olè da lọna, ni igba miran o fẹrẹ ku nitori oungbẹ. Ni ẹẹkan a gba gbogbo ohun ti o ni ni ọwọ rẹ, a si fi i silẹ lati rin ọpọ ibuṣọ pẹlu ẹsẹ laarin awọn oke, yinyin si n jabọ si lara, ti atẹlẹsẹ rẹ ko mọ irora mọ nitori bi o ti n fi rin lori yinyin.ANN 160.3

    Nigba ti a kilọ fun nipa lilọ si ọdọ awọn ẹya alaigbede ti ko tun koni mọra laini ohun ìjà, o sọ pe, a ti fun oun “ni awọn ohun ija”—”adura, ìtara fun Kristi, ati igboya ninu iranlọwọ Rẹ.” O sọ pe, “Mo tun ni ifẹ Ọlọrun ati ti awọn alabagbe mi lọkan, Bibeli si wa ni ọwọ mi.” O n gbe Bibeli ni ede Heberu ati ni ede Gẹẹsi kaakiri ibi gbogbo ti o ba n lọ. O sọ nipa ọkan ninu awọn irin ajo rẹ ti o kẹyin bayii pe: “Mo . . . ṣi Bibeli silẹ ni ọwọ mi. Mo ri wipe agbara mi wa ninu Iwe naa, ati wipe okun rẹ yoo di mi mu.”ANN 160.4

    Bayii ni o ṣe ni iforiti ninu iṣẹ rẹ titi ti iṣẹ iranṣẹ idajọ ṣe de ibi pupọ ninu aye. Laarin awọn Ju, Turk, Parsee, Hindu, ati awọn ẹya ati iran miran o pin ọrọ Ọlọrun ni awọn ede wọnyii ti o si kede iṣakoso Mesaya ti n bọ.ANN 160.5

    Ninu irinajo rẹ si Bokhana o ri awọn ti wọn danikanwa ni ọna jinjin, ti wọn gbagbọ ninu ipadabọ Oluwa laipẹ. O sọ pe awọn Arab ti Yemen “ni iwe kan ti a n pe ni Seera, ti o sọ nipa ipadabọ Kristi lẹẹkeji ati iṣakoso Rẹ ninu ogo; wọn si n reti ki iṣẹlẹ nla kan o ṣẹlẹ ni ọdun 1840.” “Ni Yemen . . . mo lo ọjọ mẹfa pẹlu awọn ọmọ Rekabu. Wọn kii mu ọti waini, wọn ko gbin ọgba ajara, wọn ko fun irugbin, wọn n gbe ninu agọ, wọn ranti Jonadabu, ọmọ Rekabu; mo ri awọn ọmọ Israeli ni agbo wọn, awọn ẹya Dani, . . . ti wọn n reti pẹlu awọn ọmọ Rekabu wiwa Mesaya ni kankan ninu ikuuku awọsanma.”ANN 160.6

    Ajiyinrere miran tun ri wipe iru igbagbọ kan naa wa ni Tartary. Alufa ara Tartar kan beere lọwọ ajiyinrere naa nipa asiko ti Kristi yoo wa lẹẹkeji. Nigba ti ajiyinrere naa sọ wipe oun ko mọ ohun kan nipa rẹ, o ya alufa naa lẹnu jọjọ lati ri iru aimọkan bayii lọdọ ẹni ti o pe ara rẹ ni olukọ Bibeli, ti o si sọ ohun ti o gbagbọ, eyi ti o da lori asọtẹlẹ wipe Kristi n bọ laarin 1844.ANN 161.1

    Lati 1826 ni a ti n waasu iṣẹ iranṣẹ ipadabọ ni England. Ẹgbẹ naa ko ni àkóso bii ti ti ilẹ Amẹrika; kii ṣe gbogbo wọn ni wọn kọni ni akoko ti yoo wa ni pato, ṣugbọn wọn kede otitọ nla ti wiwa Kristi laipẹ ninu agbara ati ogo. Kii si i ṣe laarin awọn oniyapa ati awọn ti ko tẹle ilana Ijọ nikan. Mourant Brock, onkọwe ọmọ England kan, sọ wipe o to bi ẹẹdẹgbẹta (700) alufa ijọ England ti wọn n waasu “iyinrere ti ijọba yii.” A waasu iṣẹ iranṣẹ ti o n tọka si 1844 gẹgẹ bi akoko bibọ Oluwa ni Great Britain pẹlu. A pin awọn iwe ti wọn sọ nipa ipadabọ ti wọn tẹ jade ni United States kaakiri gan an ni. A ṣe atuntẹ awọn iwe ati atẹjade keekeke wọnyi ni England. Ni 1842 Robert Winter, ẹni ti a bi ni ilẹ England, ti o gba igbagbọ nipa ipadabọ ni ilẹ Amẹrika, pada si ilu abinibi rẹ lati kede wiwa Oluwa. Ọpọ ni wọn fọwọsowọpọ pẹlu rẹ ninu iṣẹ naa, ti a si kede iṣẹ iranṣẹ idajọ kaakiri gbogbo England.ANN 161.2

    Ni South Amerika, laarin aimọkan ati arekereke awọn alufa, Lacunza ọmọ Spain, ti o jẹ Jesuit, ka Bibeli o si gba otitọ nipa ipadabọ Kristi ní kánkán. O fẹ funni ni ikilọ naa, sibẹ ko fẹ ki Romu o fiya jẹ oun, o tẹ igbagbọ rẹ jade pẹlu orukọ “Rabbi Ben-Ezra,” o fi ara rẹ han bi Ju ti o yipada. Lacunza gbe ni ọrundun kejidinlogun, ṣugbọn 1825 ni iwe rẹ ti de London, a si tumọ rẹ si ede England. Atẹjade rẹ ṣiṣẹ lati mu ki ifẹ awọn eniyan England o tubọ jinlẹ si lori koko ọrọ ipadabọ lẹẹkeji.ANN 161.3

    Ni Germany, Bengel, alufa ni ijọ Lutheran ati ọjọgbọn ninu Bibeli ni o fi kọni ni ọrundun kejidinlogun. Nigba ti o pari ẹkọ rẹ, Bengel, “fi ara rẹ jin fun ẹkọ nipa ọrọ Ọlọrun, eyi tí iye rẹ ti o yè kooro ti o si já fáfá si ohun ẹsin, ati tí ikọni ati itọsọna ibẹrẹ aye rẹ dari rẹ si. Bi ti awọn ọdọmọkunrin yooku ti wọn ni arojinlẹ, ti wọn wa ṣaaju rẹ, ati nisinsinyii, o jijakadi pẹlu iyemeji ati inira nipa ẹsin, o si sọ pẹlu ero ọkan pupọ nipa ‘ọpọ ọkọ ti o gun lọkan, ti o mu ki igba ewe rẹ o nira lati gbe.’” Nigba ti o darapọ mọ igbimọ Kadina ti ilu Wurttemberg, o ṣe alagbawi fun ominira ẹsin. “Nigba ti o daabo bo ẹtọ ati anfani ijọ, o fọwọ si ki awọn ti wọn ro wipe wọn nilati kuro ninu ijọ, nitori ẹri ọkan wọn, o ni ominira ti o yẹ.” Wọn si ri anfani ẹtọ yii ni agbegbe abinibi rẹ.ANN 161.4

    Nigba ti o n kọ iwaasu kan lati inu iwe Ifihan 21 fun Sọnde ipadabọ ni imọlẹ ti ipadabọ Kristi lẹẹkeji wọ inu ọkan rẹ lọ. O ni oye asọtẹlẹ ifihan ju bi o ti ni ri lọ. Awọn iṣẹlẹ ti woli naa kọ silẹ ṣe pataki si ni ọna tuntun, awọn iṣẹlẹ ologo naa wa siwaju rẹ, o nilati dá ironu lori koko ọrọ naa duro fun igba diẹ. Ni ori pẹpẹ iwaasu iṣẹlẹ naa tun yọ si ni ọna ti o han kedere, ati pẹlu agbara. Lati igba yii lọ, o jọwọ ara rẹ fun ẹkọ isọtẹlẹ, paapa julọ, eyi ti o sọ nipa igba ikẹyin, laipẹ o ri wipe bibọ Kristi sunmọ etile. Ọjọ ti o yan gẹgẹ bi akoko ipadabọ lẹẹkeji fi ọdun diẹ ju eyi ti William Miller gbagbọ lọ.ANN 161.5

    Awọn iwe Bengel tan ka ibi gbogbo ti wọn ti n ṣe ẹsin Kristẹni. Wọn gba ero rẹ nipa asọtẹlẹ daradara ni Wurttemberg, a si gba a diẹ ni awọn ibi ti o ku ni Germany. Ẹgbẹ naa tẹsiwaju lẹyin iku rẹ ti a si gbọ iṣẹ iranṣẹ ipadabọ ni akoko kan naa ti wọn n fiye si ni awọn ilẹ yooku. Laipẹ, diẹ lara awọn onigbagbọ lọ si ilẹ Russia wọn si da ibudo silẹ nibẹ, awọn ijọ awọn ara Germany ni ilu naa si gbagbọ nipa ipadabọ Kristi laipẹ.ANN 161.6

    Imọlẹ naa tan ni France ati Switzerland. Ni Geneva nibi ti Farel ati Calvin ti tan otitọ iṣẹ Atunṣe kalẹ, Gausen waasu iṣẹ iranṣẹ ipadabọ lẹẹkeji. Nigba ti o jẹ akẹkọ, Gausen gba ẹmi ironu ti ko faaye gba ẹsin, eyi ti o gba gbogbo ilẹ Europe kan lati opin ọrundun kejidinlogun titi de ibẹrẹ ọrundun kọkandinlogun; nigba ti o bẹrẹ iṣẹ alufa, ki i ṣe wipe ko ni oye igbagbọ tootọ nikan, ṣugbọn o tun ṣe iyemeji nipa otitọ ọrọ Ọlọrun. Ni igba ọdọ rẹ, o nifẹ si ẹkọ isọtẹlẹ. Lẹyin ti o ka iwe Rollin, Ancient History (Itan Igba Atijọ), iye rẹ lọ si Daniẹli ori keji, o si yaa lẹnu jọjọ bi asọtẹlẹ naa ṣe wa si imuṣẹ rẹgi, gẹgẹ bi o ti ri ninu akọsilẹ opitan. Eyi jẹ ẹri si imisi Iwe Mimọ, ti o jẹ idakọro fun laarin ewu igba ikẹyin rẹ. Ikọni iyemeji nipa otitọ ọrọ Ọlọrun ko tẹ lọrun mọ, nipa kikọ ẹkọ Bibeli ati wiwa imọlẹ si, lẹyin igba diẹ, o ri igbagbọ tootọ.ANN 161.7

    Bi o ti n tẹsiwaju ninu iwadi rẹ nipa awọn isọtẹlẹ, o ri wipe wiwa Oluwa ti sunmọ etile. Bi otitọ nla yii ti lọwọ tó ati bi o ti ṣe pataki to wọ ọ lọkan, o fẹ lati mu tọ awọn eniyan lọ; ṣugbọn igbagbọ ti o wọpọ wipe ohun ijinlẹ ni awọn isọtẹlẹ Daniẹli, ati wipe ko le yeni jẹ idena nla fun. Nikẹyin, o pinu—bi Farel ti ṣe ṣaaju rẹ ni wiwaasu ni Geneva—lati bẹrẹ pẹlu awọn ọmọde, nipasẹ eyi, o ni ireti wipe yoo sọ ifẹ awọn obi wọn ji.ANN 162.1

    Nikẹyin, o sọ nipa iṣẹ rẹ yii pe: “Mo fẹ ki awọn eniyan o gbọ mi, ki i ṣe wipe ko ṣe pataki, ṣugbọn lodi si eyi, bi o ti niye lori to ni o jẹ ki n waasu rẹ ni ọna ti yoo fi ye wọn, ti mo si fi n kọ awọn ọmọ wọn. Mo fẹ ki wọn gbọ mi, mo si bẹru wipe wọn ki yoo gbọ bi mo ba kọkọ sọ ọ fun awọn agbalagba.” “Nitori naa mo pinu lati lọ ba awọn ti wọn kere julọ. Mo ko awọn ọmọde jọ; bi ẹgbẹ naa ba pọ si, bi wọn ba feti silẹ, ti inu wọn ba dun si, ti wọn si ni ifẹ si, ti o ye wọn, ti wọn tun le ṣe alaye koko ọrọ naa, o damiloju wipe laipẹ maa ni ẹgbẹ keji, ti awọn agbalagba yoo si ri wipe o ṣe pataki lati joko kẹkọ. Nigba ti a ba ṣe eyi, a ti ṣe aṣeyọri.”ANN 162.2

    Akitiyan rẹ yọri si rere. Bi o ti n ba awọn ọmọde sọrọ, awọn agbalagba n wa feti silẹ. Inu gbọngan ile ijọsin kun fun awọn olugbọ. Lara wọn ni awọn ọmọwe ati oloye, alejo ati ajeji ti wọn wa bẹ Geneva wo; bayii ni a ṣe gbe iṣẹ iranṣẹ naa lọ si ilẹ miran.ANN 162.3

    Aṣeyọri rẹ yii fun ni imoriya, Gausen wa tẹ awọn ẹkọ rẹ jade pẹlu ireti wipe yoo jẹ ki awọn ijọ ti n sọ ede French o kọ nipa awọn iwe isọtẹlẹ. Gausen sọ pe, “Lati tẹ awọn ẹkọ ti a fun awọn ọmọde jade, jẹ lati sọ fun awọn agbalagba ti wọn ṣá iru awọn iwe bẹẹ tì labẹ irọ wipe wọn ko le yeni wipe, ‘Bawo ni wọn ko file yeni, nigba ti wọn le ye awọn ọmọ yin?’” O fi kun wipe, “Mo ni ifẹ ọkan nla lati jẹ ki imọ asọtẹlẹ yii o di gbajugbaja laarin awọn ọmọ ijọ wa bi o ba ṣe e ṣe.” “Ni tootọ, bi mo ti rii si, ko si ẹkọ kan ti o le dahun si ibeere akoko yii ju yẹn lọ.” Nipasẹ eyi ni a fi le mura silẹ fun ewu ti o sunmọ etile, ati lati wọna ati lati duro fun Jesu Kristi.”ANN 162.4

    Bi o tilẹ jẹ wipe o jẹ ọkan lara awọn oniwaasu ni ede French ti o tayọ, ti a tun fẹran, lẹyin igba diẹ, a daa duro ninu iṣẹ alufa, ẹṣẹ rẹ si ni wipe dipo iwe ikọni ijọ, iwe akọsilẹ ọgbọn ori eniyan lasan ti ko ni igbagbọ tootọ, o lo Bibeli lati kọ awọn ọdọ. Lẹyin eyi, o di olukọ ni ile ẹkọ nipa ọrọ Ọlọrun, ni ọjọ aiku o tẹsiwaju ninu iṣẹ rẹ gẹgẹ bi olukọ, o n kọ awọn ọmọde lati inu Iwe Mimọ. Awọn eniyan nifẹ pupọpupọ si awọn iṣẹ rẹ lori asọtẹlẹ. Lati ipo ọjọgbọn rẹ, lati ile itẹwe, ati ninu iṣẹ ti o fẹran julọ gẹgẹ bi olukọ awọn èwe, o tẹsiwaju fun ọpọ ọdun lati ko ipa ti o pọ ti o si n ṣiṣẹ lati pe akiyesi ọpọlọpọ si kikọ nipa awọn asọtẹlẹ eyi ti o fihan wipe wiwa Oluwa sunmọ etile.ANN 162.5

    Ni Scandinavia a ṣe iwaasu nipa iṣẹ iranṣẹ ipadabọ pẹlu, awọn eniyan si nifẹ si. Ọpọlọpọ ni wọn ji dide kuro ninu aabo aibikita wọn ti wọn jẹwọ, ti wọn si n kọ ẹṣẹ wọn silẹ, ti wọn si n wa idariji ni orukọ Kristi. Ṣugbọn awọn alufa ijọ ilu tako ẹgbẹ naa, nipasẹ wọn a sọ diẹ lara awọn ti wọn n waasu rẹ sinu ọgba ẹwọn. Ni ọpọlọpọ ibi, bayii ni a ṣe pa awọn ti wọn n waasu ipadabọ Oluwa lẹnu mọ, o si tẹ Ọlọrun lọrun lati rán iṣẹ naa jade ni ọna ti o yanilẹnu, nipasẹ awọn ọmọde. Nitori ti wọn jẹ majẹsin, ofin ilu ko de wọn, a si gba wọn laaye lati waasu laisi idiwọ.ANN 162.6

    Ẹgbẹ gbajugbaja laarin awọn ti ko lọrọ, ni ibugbe awọn otoṣi ti wọn jẹ oṣiṣẹ ni awọn eniyan n pejọ pọ si lati gbọ ikilọ naa. Awọn ọmọde oniwaasu naa jẹ otoṣi. Diẹ lara wọn ko ju ọmọ ọdun mẹfa si mẹjọ lọ; nigba ti igbesi aye wọn jẹri si wipe wọn fẹran Olugbala, ati wipe wọn ṣe akitiyan lati gbe ni igbọran si ofin mimọ Ọlọrun, wọn ko ni ọgbọn ati agbara ti o ju ti ẹlẹgbẹ wọn lọ. Ṣugbọn nigba ti wọn ba duro niwaju awọn eniyan, o han kedere wipe agbara ti n lo wọn ki i ṣe lasan. Ohùn ati iṣesi wọn yatọ, pẹlu agbara mimọ wọn ṣe ikilọ nipa idajọ, nipa lilo awọn ọrọ Iwe Mimọ: “Bẹru Ọlọrun ki ẹ si fi ogo fun; nitori ti wakati idajọ Rẹ de.” Wọn ba ẹṣẹ awọn eniyan wi, ki i ṣe wipe wọn tako iwa ibajẹ ati iwa ipa nikan, ṣugbọn wọn ba ifẹ aye ati ifasẹyin wi, wọn si kilọ fun awọn olugbọ wọn lati yara kankan sa kuro ninu ibinu ti n bọ.ANN 162.7

    Awọn eniyan gbọ pẹlu iwariri. Ẹmi Ọlọrun ti n bani wi ba ọkan wọn sọrọ. Ọpọ ni wọn yẹ Iwe Mimọ wo pẹlu ifẹ tuntun, ti o jinlẹ, awọn alaileko-ara-ẹni-nijanu ati awọn oniwa ibajẹ yipada, awọn yoku fi iwa aiṣootọ wọn silẹ, iṣẹ ti wọn ṣe farahan to bẹẹ gẹẹ, ti awọn alufa ijọ ilu fi gba wipe ọwọ Ọlọrun wa ninu ẹgbẹ yii.ANN 163.1

    O jẹ ifẹ Ọlọrun lati sọ iroyin wiwa Olugbala ni awọn orilẹ ede Scandinavia; nigba ti a si pa awọn ojiṣẹ Rẹ lẹnu mọ, O fi Ẹmi Rẹ si ori awọn ọmọde, ki a baa le ṣe iṣẹ naa. Nigba ti Jesu sunmọ Jerusalẹmu ti awọn ero ti n yọ tẹle pẹlu ariwo iṣẹgun, ti wọn n ju imọ ọpẹ, ti wọn si n kigbe si Ọmọ Dafidi, awọn ojowu Farisi sọ fun ki o pa wọn lẹnu mọ; ṣugbọn Jesu dahun wipe amuṣẹ isọtẹlẹ ni gbogbo nnkan wọnyi, ati wipe bi awọn wọnyi ba pa ẹnu wọn mọ, awọn okuta yoo kigbe jade. Ihalẹ awọn alufa ati alaṣẹ jẹ ki ẹru o ba awọn eniyan, ti wọn si dakẹ ikede ayọ wọn bi wọn ti n wọ igboro Jerusalẹmu; ṣugbọn awọn ọmọde ti wọn wà ninu gbọngan tẹmpili fi orin sẹnu, wọn si n fi imọ ọpẹ wọn, wọn n kigbe: “Hosanna si Ọmọ Dafidi!” Matiu 21:8—16. Nigba ti awọn Farisi, ti inu wọn bajẹ jọjọ sọ fun, “Ṣe o gbọ ohun ti awọn wọnyi n sọ?” Jesu dahun, “Bẹẹni; ẹyin ko ha ka wipe, Lẹnu awọn ọmọde ati ọmọ ọmu ni iwọ ti mú iyin pé?” Bi Ọlọrun ti ṣiṣẹ nipasẹ awọn ọmọde ni akoko wiwa Kristi ni akọkọ, bẹẹ gẹgẹ ni O ṣiṣẹ nipasẹ wọn ni fifunni ni iṣẹ iranṣẹ ti ipadabọ Rẹ lẹẹkeji. Ọrọ Ọlọrun nilati wa si imuṣẹ, ki a baa le kede wiwa Olugbala fun gbogbo eniyan ati ede ati orilẹ ede.ANN 163.2

    William Miller ati awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ ni a fifun lati waasu ikilọ naa ni Amẹrika. Orilẹ ede yii di aarin gungun fun ẹgbẹ nla ti ipadabo. Nibi ni asọtẹlẹ iṣẹ iranṣẹ angẹli akọkọ ti ni imuṣẹ julọ. A gbe awọn iwe Miller ati ti awọn akẹgbẹ rẹ lọ si ilẹ jijina réré. Nibikibi ti awọn ajiyinrere ba de ni gbogbo aye, nibẹ ni a ran iroyin ayọ ti ipadabọ kankan Kristi si. A ran iṣẹ iranṣẹ ti iyinrere ainipẹkun lọ kaakiri: “Bẹru Ọlọrun, ki ẹ si fi ogo fun; nitori ti wakati idajọ Rẹ de.”ANN 163.3

    Ẹri asọtẹlẹ ti o dabi ẹnipe o n tọka si wiwa Kristi ni asiko ọgbin 1844 wọ ọkan awọn eniyan lọ. Bi iṣẹ iranṣẹ naa ti n lọ lati ipinlẹ de ipinlẹ, ni ibi gbogbo ni ifẹ awọn eniyan ti sọji. Ọpọlọpọ ni wọn gbagbọ wipe ironu nipa akoko isọtẹlẹ tọna, wọn fi igberaga ọkan wọn silẹ, wọn si fi tayọtayọ gba otitọ. Awọn alufa miran fi ero ati igbagbọ adamọ wọn silẹ, wọn fi owo oṣu ati ijọ wọn silẹ, wọn si parapọ lati kede wiwa Jesu. Awọn alufa ti wọn gba iṣẹ iranṣẹ yii kere niye; nitori naa awọn ọmọ ijọ ni a gbe e lé lọwọ. Awọn agbẹ fi oko wọn silẹ, awọn oniṣẹ ọwọ fi irin iṣẹ wọn silẹ, awọn oniṣowo fi okoowo wọn silẹ, awọn oṣiṣẹ fi ipo wọn silẹ; sibẹ iye awọn oṣiṣẹ kere niye bi a ba ṣe afiwe rẹ pẹlu iṣẹ ti wọn nilati ṣe. Ipo awọn ijọ ti ko mọ Ọlọrun, ati aye ti o wa ninu iwa ẹṣẹ di ẹru wuwo le ọkan awọn alóre otitọ, wọn si mọọmọ fi ara da wahala, aini ati ijiya, ki wọn ba le pe awọn eniyan si ironupiwada si igbala. Lootọ Satani tako wọn, ṣugbọn iṣẹ naa tẹsiwaju titi ti ọgọọrọ awọn eniyan fi gba otitọ nipa ipadabọ.ANN 163.4

    Ni ibi gbogbo ni a ti gbọ ẹri naa, ti n kilọ fun ẹlẹṣẹ, ati olufẹ aye ati ọmọ ijọ lapapọ lati sa kuro ninu ibinu ti n bọ. Bi Johanu Onitẹbọmi, aṣaaju fun Kristi, awọn oniwaasu gbe aaké lé gbongbo igi naa, wọn si rọ gbogbo eniyan lati so èso ti o yẹ fun ironupiwada. Ìpè kánkán wọn yatọ patapata si idaniloju alaafia ati aabo ti a n gbọ lati ori pẹpẹ iwaasu awọn ijọ; nibikibi ti a ba ti funni ni iṣẹ iranṣẹ naa, o n mi awọn eniyan lọkan. Ẹri ailabula ti Iwe Mimọ, ti agbara Ẹmi Mimọ mú wálé, fa igbagbọ eyi ti o ṣe wipe iwọnba eniyan diẹ ni wọn le tako o. Awọn afẹnusẹsin taji kuro ninu aabo eke wọn. Wọn ri ifasẹyin wọn, ifẹran aye ati aigbagbọ wọn, igberaga ati imọ-ti-ara-ẹni-nikan wọn. Ọpọ ni wọn wa Oluwa pẹlu ironupiwada ati irẹraẹnisilẹ. Ifẹ ti o ti rọ mọ aye fun igba pipẹ wa rọ mọ ọrun. Ẹmi Ọlọrun bàlé wọn, pẹlu ọkan ti o sẹrọ, wọn darapọ mọ awọn eniyan lati kede igbe naa: “Bẹru Ọlọrun, ki ẹ si fi ogo fun; nitori ti wakati idajọ Rẹ de.”ANN 163.5

    Awọn ẹlẹṣẹ beere pẹlu ẹkun: “Kini ki n ṣe lati le ri igbala?” Awọn ti igbesi aye wọn kun fun aiṣootọ n fẹ lati ṣe atunṣe. Gbogbo awọn ti wọn ri alaafia ninu Kristi fẹ ki awọn miran o pin ninu ibukun naa. Ọkan awọn obi yi si awọn ọmọ wọn, ọkan awọn yi si awọn obi. Idena igberaga ati àìdásíni kuro lọna. A ṣe ijẹwọ ẹṣẹ latọkanwa, ti awọn ara ile si n ṣiṣẹ fun igbala awọn ti wọn sun mọ wọn, ati ti awọn ololufẹ wọn. Ni ọpọ igba ni a maa n gbọ adura tọkantọkan nitori ẹlomiran. Ni ibi gbogbo ni awọn eniyan ti wa ninu ẹdun ọkan ti wọn n bẹbẹ pẹlu Ọlọrun. Ọpọ ni wọn jijakadi ni gbogbo oru ninu adura fun idaniloju wipe a ti dari ẹṣẹ wọn ji, tabi fun iyipada ara ile tabi alabagbe wọn.ANN 164.1

    Oriṣiriṣi eniyan ni wọn n lọ si ipade awọn Onireti. Awọn ọlọrọ ati awọn otoṣi, ẹni giga ati ẹni irẹsilẹ, lati ibi iṣẹ gbogbo ni wọn ti n wọna lati gbọ ikọni nipa ipadabọ funra wọn. Oluwa dí ẹmi atako lọwọ nigba ti awọn iranṣẹ Rẹ n ṣe alaye idi fun igbagbọ wọn. Ni igba miran, irin iṣẹ naa a jẹ alailagbara; ṣugbọn Ẹmi Ọlorun fun otitọ ni agbara. Wọn ni imọlara iwapẹlu awọn angẹli mimọ ninu awọn apejọ wọnyi, ti ọpọlọpọ si n darapọ mọ awọn onigbagbọ lojoojumọ. Bi a ti n ṣe alaye awọn ẹri nipa ipadabọ Kristi laipẹ, awọn ero a tẹti silẹ si awọn ọrọ mimọ naa. O dabi ẹnipe ọrun ati aye pade ara wọn. Awọn ọdọ ati ogbó ni imọlara agbara Ọlọrun. Awọn eniyan n lọ si ile wọn pẹlu iyin lẹnu wọn, ti ìró ayọ si n gba aṣalẹ kan. Ko si ẹni ti o lọ si awọn ipade naa ti yoo gbagbe awọn iṣẹlẹ ti wọn muni lọkan jọjọ naa.ANN 164.2

    Kikede akoko kan pato fun wiwa Kristi mu atako wa lati ọdọ ọpọ awọn eniyan, ni awujoọ, lati ọdọ awọn alufa lori pẹpẹ iwaasu titi de ọdọ ẹlẹṣẹ alaibikita julọ. Awọn ọrọ asọtẹlẹ wa si imuṣẹ: “Ni igba ikẹyin awọn ẹlẹgan yoo wà, wọn yoo maa rin ninu ifẹkufẹ ara wọn, ti wọn yoo si wipe, Nibo ni ileri wiwa Rẹ gbé wà? nitori lati igba ti awọn baba ti sun, ohun gbogbo tẹsiwaju gẹgẹ bi wọn ti wà rí lati ibẹrẹ dida aye.” 2 Peteru 3:3, 4. Ọpọ ti wọn sọ pe wọn fẹran Olugbala, ni wọn sọ wipe wọn ko ni atako si ikọni nipa bibọ lẹẹkeji, ṣugbọn wọn ko faramọ dida akoko kan pato. Ṣugbọn oju Ọlọrun ti o n ri ohun gbogbo mọ ọkan wọn. Wọn ko fẹ gbọ nipa wiwa Kristi lati ṣe idajọ aye ninu ododo. Wọn jẹ ọmọ ọdọ alaiṣootọ, iṣẹ wọn ko le la ibẹwo Ọlọrun to n yẹ ọkan wo kọja, wọn bẹru lati pade Ọlọrun wọn. Bi awọn Ju ni akoko wiwa Kristi ni akọkọ, wọn ko ṣetan lati ki Jesu kaabọ. Kii ṣe wipe wọn kọ lati tẹti si alaye lati inu Bibeli nikan, ṣugbọn wọn fi awọn ti n wọna fun Oluwa ṣẹsin. Satani ati awọn angẹli rẹ yọ, wọn tun sọ egun wọn niwaju Kristi ati awọn angẹli mimọ wipe awọn ti wọn pe ara wọn ni eniyan Rẹ ni ko ni ifẹ pupọ fun, wọn ko si reti ifarahan Rẹ.ANN 164.3

    “Ko si ẹni ti o mọ ọjọ tabi wakati” ni koko ọrọ ti awọn ti wọn ko gba igbagbọ nipa ipadabọ saba maa n lo. Iwe Mimọ sọ wipe: “Ni ti ọjọ ati wakati naa, ko si ẹni ti o mọ ọ, ani awọn angẹli ọrun pẹlu, ayafi Baba Mi nikan.” Matiu 24:36. Awọn ti wọn n wọna fun Oluwa ṣe alaye ẹsẹ yii ni ọna ti o yè kooro, ti o si ba ara wọn mu, wọn si ṣe afihan bi awọn alatako ṣe n ṣi i lo. Kristi sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ manigbagbe pẹlu awọn ọmọ ẹyin Rẹ lori oke Olifi lẹyin ti o kuro ninu tẹmpili fun igba ikẹyin. Awọn ọmọ ẹyin Rẹ beere pe: “Kini yoo jẹ ami wiwa Rẹ, ati ti opin aye?” Jesu fun wọn ni awọn ami, O tun sọ pe: “Nigba ti ẹyin ba ri nnkan wọnyi, ki ẹ mọ wipe o sunmọ etile, ani lẹnu ilẹkun.” Ẹsẹ 3, 33. A ko gbọdọ jẹ ki ọrọ Kristi kan o tako ekeji. Lootọ ko si ẹni ti o mọ ọjọ tabi wakati wiwa Rẹ, a kọ wa, a si fẹ ki a mọ nigba ti o ba sunmọ etile. A tun sọ fun wa wipe kikọ ikilọ Rẹ ati kikọ tabi ṣiṣe ainaani lati mọ nigba ti bibọ Rẹ ba sunmọ, yoo kun fun ewu fun wa gẹgẹ bi o ti ri fun awọn ti wọn gbe ni akoko Noah bi wọn ko ti ṣe mọ igba ti ikun omi de. Owe inu ẹsẹ kan naa, ti o fi ọmọ ọdọ olootọ we alaiṣootọ, ti o sọ nipa iparun ẹni ti o wi ninu ọkan rẹ pe, “Oluwa mi fa bibọ Rẹ sẹyin,” fihan bi Kristi yoo ti ka awọn ti O bá ba ti wọn n wọna, ti wọn si n fi wiwa Rẹ kọni si, ti yoo si fun wọn ni ere, ati bi o ti ka awọn ti wọn sẹ Ẹ si. “Nitori naa ẹ maa sọna” ni O wi. “Ibukun ni fun ọmọ ọdọ naa, ti Oluwa rẹ ba ti n ṣe bẹẹ nigba ti o ba de.” Ẹsẹ 42, 46. “Nitori naa bi o ko ba sọna, Emi yoo de si ọ bi ole, iwọ ki yoo si mọ wakati ti Emi yoo de si ọ.” Ifihan 3:3ANN 164.4

    Pọlu sọ nipa ẹgbẹ ti ifarahan Oluwa yoo ba ni aimurasilẹ. “Ọjọ Oluwa yoo wa bi ole ni oru. Nitori nigba ti wọn ba n sọ pe, Alaafia ati aabo; nigba naa ni iparun yoo de ba wọn lojiji; . . . wọn ki yoo le sa asala.” Ṣugbọn o fikun, fun awọn ti wọn ṣe igbọran si ikilọ Olugbala: “Ẹyin ara, ẹ ko si ninu okunkun, ti ọjọ naa i ba fi ba yin gẹgẹ bi ole. Ẹyin jẹ ọmọ imọlẹ ati ọmọ ọsan: a ki i ṣe ti oru tabi ti okunkun.” 1 Tẹsalonika 5:2—5.ANN 165.1

    Bayii ni a ṣe fihan wipe Iwe Mimọ ko fi aaye gba ki eniyan o wa ni aimọkan nipa bi wiwa Oluwa ti n sun mọle. Awọn ti wọn n wa awawi lati kọ otitọ silẹ kọ eti ọgbọin si alaye yii, ti ọrọ yii “ko si ẹni ti o mọ ọjọ tabi wakati” si n dún lọ lẹnu awọn ẹlẹgan, ani, ati awọn ti wọn pe ara wọn ni ojiṣẹ Kristi. Bi awọn eniyan ti n taji, ti wọn n beere nipa ọna igbala, awọn olukọ ẹsin duro si aarin wọn ati otitọ, wọn n wọna lati fi ọkan wọn balẹ nipa siṣi ọrọ Ọlọrun tumọ. Awọn alore alaiṣootọ fọwọsowọpọ ninu iṣẹ atannijẹ nla ni, wọn n kigbe, Alaafia, alaafia, nigba ti Ọlọrun ko kede alaafia, ọpọ ni wọn kọ lati wọ ijọba Ọlọrun, ti wọn tun n di awọn ti wọn n wọle lọwọ. A o beere ẹjẹ awọn ọkan wọnyi lọwọ wọn.ANN 165.2

    Awọn ọmọ ijọ ti ko lọrọ ti wọn si jẹ onifọkansin ni wọn kọkọ gba iṣẹ iranṣẹ yii. Awọn ti wọn kọ ẹkọ Bibeli funra wọn ri bi ọna ti o gbajugbaja lati tumọ asọtẹlẹ ko ti ba Bibeli mu to; nibikibi ti awọn alufa ko ba ti dari awọn eniyan, nibikibi ti wọn ba ti le wa inu Bibeli funra wọn, a nilati fi ikọni ti ipadabọ we Iwe Mimọ lasan ni lati le fi idi otitọ rẹ mulẹ.ANN 165.3

    Awọn arakunrin alaigbagbọ ṣe inunibini si ọpọlọpọ. Lati ma baa fi ipo wọn ninu ijọ silẹ, diẹ gba lati maṣe polongo ireti wọn; ṣugbọn awọn miran gba wipe igbọran wọn si Ọlọrun ko fi aaye gba wọn lati fi otitọ ti a fi si ikawọ wọn pamọ. Ki i ṣe awọn diẹ ni a le kuro ninu ijọ, ki si i ṣe fun idi miran bikoṣe wipe wọn gbagbọ ninu wíwá Kristi. Awọn ọrọ woli yii ṣe iyebiye si awọn ti wọn fi ara da idanwo igbagbọ: “Awọn arakunrin yin ti wọn korira yin, ti wọn le yin sita nitori orukọ Mi, sọ pe, Jẹ ki a fi ogo fun Oluwa: ṣugbọn yoo fi ara han fun ayọ yin, oju yoo si ti wọn.” Aisaya 66:5.ANN 165.4

    Awọn angẹli Ọlọrun n wo ayọrisi iṣẹlẹ naa pẹlu ifẹ ọkan ti o jinlẹ. Nigba ti awọn ijọ kọ iṣẹ iranṣẹ naa silẹ, awọn angẹli yipada pẹlu ibanujẹ. Ṣugbọn ọpọ ni a koi tii danwo pẹlu otitọ ti ipadabọ. Ọpọlọpọ ni awọn ọkọ, iyawo, obi, tabi ọmọ ṣi lọna, ti a jẹ ki wọn gbagbọ wipe ẹṣẹ ni lati tẹti si ẹkọ odi ti awọn Onireti fi n kọni. A ran awọn angẹli lati maa sọ awọn ọkan wọnyi, nitori imọlẹ miran yoo tan si wọn lati itẹ Ọlọrun wa.ANN 165.5

    Pẹlu ifẹ ọkan ti ko ṣe e fẹnu sọ, awọn ti wọn gba iṣẹ iranṣẹ naa n wọna fun wiwa Olugbala wọn. Akoko ti wọn n reti lati pade Rẹ sunmọ. Wọn n sunmọ akoko yii pẹlu idakẹjẹ mimọ. Wọn sinmi ninu ibaṣepọ didun pẹlu Ọlọrun, akoso alaafia ti yoo jẹ ti wọn ninu aye didan ti n bọ. Ko si ẹni ti o ni iriri ireti ati igbẹkẹle yii ti o le gbagbe awọn wakati iyebiye ti wọn fi duro. Fun awọn ọsẹ diẹ ṣaaju akoko yii, a pa iṣẹ aye ti fun ọpọ akoko. Awọn onigbagbọ tooto ṣe ayẹwo gbogbo ero ati ifẹ ọkan wọn finifini ayafi bi ẹnipe wọn wa lori ibusun iku wọn ati, ni wakati diẹ si, wọn yoo pa oju wọn de si iṣẹlẹ inu aye yii. Ko si ẹni ti o rán “aṣọ igbasoke”; ṣugbọn gbogbo wọn mọ wipe wọn ni idaniloju lati inu ọkan wa boya wọn ṣetan lati pade Olugbala; aṣọ funfun wọn ni ọkan mimọ—iwa ti a fọmọ kuro ninu ẹṣẹ nipasẹ ẹjẹ Kristi. I ba ti dara to bi awọn eniyan Ọlọrun ba si ni iru ẹmi iyẹ ọkan wo, iru igbagbọ gbigbona ti ko le yẹ kan naa. Bi o ba ṣe wipe wọn tẹsiwaju lati rẹ ara wọn silẹ niwaju Oluwa, ti wọn si n gbe ẹbẹ wọn wa siwaju itẹ aanu ni, ìrírí wọn i ba kun ju eyi ti wọn ni nisinsinyii lọ. Adura ko pọ mọ, imọlara ẹṣẹ ko pọ mọ, aisi igbagbọ ti o wa laaye jẹ ki ọpọ o ṣe aini oore ọfẹ ti Olugbala wá funni ni ọpọ yanturu.ANN 165.6

    Ọlọrun fẹ dan awọn eniyan Rẹ wo. O da ọwọ bo aṣiṣe kan ninu kika awọn akoko isọtẹlẹ. Awọn Onireti ko ri aṣiṣe wọn, bẹẹni eyi ti o loye julọ ninu awọn alatako wọn ko ri i. Awọn alatako wọn sọ pe: “Bi ẹ ti ṣe ka akoko isọtẹlẹ tọna. Iṣẹlẹ nla kan fẹ ṣẹlẹ; ṣugbọn ki i ṣe ohun ti Mr. Miller n sọ, iyipada aye ni, ki i si i ṣe ipadabọ Kristi lẹẹkeji.”ANN 165.7

    Asiko ti wọn n reti kọja, Kristi ko farahan fun idande awọn eniyan Rẹ. Awọn ti wọn fi igbagbọ ati ifẹ tootọ wọna fun Olugbala wọn ri ijakulẹ kikoro. Sibẹ erongba Ọlọrun n wa si imuṣẹ; O n dan ọkan awọn ti wọn n kede wipe wọn n duro de wiwa Rẹ wo. Awọn kan wa laarin wọn ti o jẹ wipe ko si idi pataki kan ti o mu wọn gbagbọ bikoṣe ibẹru. Ijẹwọ igbagbọ wọn ko yi ọkan wọn tabi igbesi aye wọn pada. Nigba ti iṣẹlẹ ti wọn n reti ko ṣẹlẹ, wọn sọ wipe inu wọn ko bajẹ; wọn ko fi igba kan gbagbọ wipe Kristi yoo wa. Wọn wa lara awọn ti wọn kọkọ gan ibanujẹ awọn onigbagbọ tootọ.ANN 166.1

    Ṣugbọn Jesu ati gbogbo ogun ọrun n fi ifẹ ati ikaanu wo awọn ti a n dan wo ti wọn si jẹ olootọ, bi o tilẹ jẹ wipe wọn ri ijakulẹ. Bi o ba ṣe wipe a le ṣi iboju ti n bo aye àìrí kuro ni, a ba ri awọn angẹli ti wọn n ṣu bo awọn ọkan ti wọn duro ṣinṣin wọnyi, ti wọn n daabo bo wọn kuro lọwọ ọfa Satani.ANN 166.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents