Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KEJILELOGUN—AWỌN ASỌTẸLẸ WA SI IMUṢẸ

    Nigba ti akoko ti a kọkọ reti wiwa Oluwa kọja,—ni igba òjò 1844—awọn ti wọn ti fi igbagbọ wọna fun ifarahan Rẹ kun fun iyemeji ati ainidaniloju fun igba diẹ. Nigba ti aye ri wọn gẹgẹ bi awọn ti a já kulẹ patapata ti a si sọ wipe wọn gba ẹtan gbọ, ọrọ Ọlọrun si ni orisun itunu wọn. Ọpọlọpọ ni wọn tẹsiwaju lati wa Iwe Mimọ, ti wọn n wa ẹri fun igbagbọ wọn ni akọtun ti wọn si n fi pẹlẹkutu kẹkọ isọtẹlẹ lati le ri imọlẹ si. Ẹri Bibeli ti o kin ipo wọn lẹyin fi ara han kedere. Awọn ami ti a ko le ṣe aṣiṣe wọn tọka si wipe wiwa Kristi ti sunmọ. Ibukun pataki Oluwa, ti ti iyipada awọn ẹlẹṣẹ ati ti isọji ẹmi ni aarin awọn Kristẹni jẹri si wipe iṣẹ iranṣẹ naa wa lati ọrun. Bi o tilẹ jẹ wipe awọn onigbagbọ ko le ṣe alaye ijakulẹ wọn, ọkan wọn balẹ wipe Ọlọrun ni o dari wọn ninu iriri wọn ni atẹyinwa.ANN 174.1

    Ikilọ ti a wé mọ asọtẹlẹ ti wọn ri wipe o ni i ṣe pẹlu akoko ipadabọ lẹẹkeji ni eyi ti ba ipo ainidaniloju ati iyemeji wọn mu, o si gba wọn niyanju lati duro pẹlu suuru ninu igbagbọ wipe ohun ti o ṣokunkun si iye wọn nisinsinyii yoo mọlẹ ni igba ti akoko ba to.ANN 174.2

    Lara awọn asọtẹlẹ wọnyi ni ti Habakuku 2:1—4: “Emi yoo duro, emi yoo si maa ṣọna, emi yoo duro si ori ile iṣọ, emi yoo si ṣọna lati ri ohun ti yoo sọ fun mi ati èsi ti yoo fọ nigba ti a bá ba mi wi. Oluwa si dami lohun wipe, kọ iran naa silẹ, ki o si han kedere lori tabili, ki ẹni ti o ka a baa le sare pẹlu rẹ. Nitori ti iran naa wa fun akoko ti a yan, ṣugbọn ni opin yoo sọrọ, ki yoo si ṣèké: bi o tilẹ pẹ, duro dè é; nitori ti yoo wa dandan, ki yoo si pẹ. Kiyesi, ọkan rẹ ti o gbega soke ko ṣe deede ninu rẹ: ṣugbọn olododo yoo wa nipa igbagbọ rẹ.”ANN 174.3

    Lati 1842 aṣẹ ti a pa ninu isọtẹlẹ yii lati “kọ iran naa silẹ, ki o si han kedere lori tabili, ki ẹni ti o ka a baa le sare pẹlu rẹ,” ti ta Charles Fitch lọyẹ lati ya aworan isọtẹlẹ, lati ṣe alaye awọn iran Danieli ati Ifihan. Itẹjade aworan yii ni a ri gẹgẹ bi imuṣẹ aṣẹ ti Habakuku pa. Ko si ẹni ti o kiyesi nigba naa wipe a sọ ninu asọtẹlẹ kan naa nipa ifasẹyin—akoko iduro—ninu imuṣẹ iran naa. Lẹyin ijakulẹ naa, ẹsẹ iwe mimọ yii wa ṣe pataki jọjọ: “Iran naa wa fun akoko kan, ṣugbọn nikẹyin, yoo sọrọ, ki yoo si ṣèké: bi o tilẹ pẹ, duro de e; nitori ti yoo wa dandan, ki yoo pẹ. . . . Olododo yoo wa nipa igbagbọ rẹ.”ANN 174.4

    Abala kan ninu isọtẹlẹ Isikiẹli tun jẹ orisun okun ati itunu fun awọn onigbagbọ: “Ọrọ Oluwa wa si ọdọ mi, o n wipe, Ọmọ eniyan, iru owe wo ni ẹ n pa ni ile Israeli, wipe, A fa awọn ọjọ naa sẹyin, gbogbo iran si n baku? Nitori naa, sọ fun wọn, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi. . . . Awọn ọjọ naa sunmọ etile, ti gbogbo iran yoo wa si imuṣẹ. . . . Emi yoo sọrọ, ọrọ ti Emi yoo sọ yoo si wa si imuṣẹ; a ki yoo fa a sẹyin mọ.” “Awọn ara ile Israeli sọ wipe, Iran ti o ri wa fun ọjọ pipe, o si n sọ tẹlẹ nipa akoko ti o jinna réré. Nitori naa sọ fun wọn, Bayii ni Oluwa Ọlọrun wi; A ki yoo fa awọn ọrọ Mi gun mọ, ṣugbọn ọrọ ti Mo ti sọ yoo wa si imuṣẹ.” Isikiẹli 12:21—25, 27, 28.ANN 174.5

    Inu awọn ti wọn n duro dun, wọn ni igbagbọ wipe Ẹni ti o mọ opin lati ibere ti woye, O si ti ri ijakulẹ wọn, O si ti fun wọn ni igboya ati ireti. Ti kii ba n ṣe abala Iwe Mimọ iru eyi, ti o gba wọn niyanju lati duro pẹlu suuru ki wọn si duro ṣinṣin ninu igbẹkẹle wọn ninu ọrọ Ọlọrun, igbagbọ wọn i ba baku ninu akoko idanwo yii.ANN 174.6

    Owe wundia mẹwa ti Matiu 25 tun ṣe alaye iriri awọn Onireti. Ninu Matiu 24, ni idahun si ibeere awọn ọmọ ẹyin Rẹ nipa awọn ami wiwa Rẹ ati ti opin aye, Kristi tọka si diẹ ninu awọn iṣẹlẹ ti wọn ṣe pataki julọ ninu itan aye ati ti ijọ lati akoko wiwa Rẹ ni akọkọ titi fi di akoko wiwa Rẹ lẹẹkeji, eyi ni, pipa Jerusalẹmu run, ipọnju nla ti ijọ labẹ inunibini awọn abọriṣa ati ijọ padi, oorun ti o ṣokunkun ati oṣupa ti o di ẹjẹ, ati jijabọ awọn irawọ. Lẹyin eyi, O sọ nipa wiwa Rẹ ninu ijọba Rẹ, O si pa owe ti o ṣe alaye awọn ẹgbẹ meji ti wọn n wọna fun ifarahan Rẹ. Ori 25 bẹrẹ pẹlu ọrọ: “Nigba naa ni ijọba ọrun yoo dabi awọn wundia mẹwa.” Nibi ni a ti sọ nipa ijọ ti yoo wa ni akoko ikẹyin, eyi kan naa ti a ṣe afihan rẹ ni opin ori kẹrinlelogun. Ninu owe yii, iriri wọn ni a ṣe apejuwe rẹ pẹlu awọn iṣẹlẹ inu aṣa igbeyawo ni iha ila oorun.ANN 174.7

    “Nigba naa ni ijọba ọrun yoo dabi wundia mẹwa, ti wọn gbe fitila wọn, ti wọn si jade lati lọ pade ọkọ iyawo. Marun ninu wọn jẹ ọlọgbọn, marun ninu wọn jẹ omugọ. Awọn ti wọn jẹ omugọ gbe fitila wọn, ṣugbọn wọn ko mu epo dani pẹlu wọn, ṣugbọn awọn ti wọn jẹ ọlọgbọn mu epo dani ninu kolobo pẹlu fitila wọn. Nigba ti ọkọ iyawo pẹ de, gbogbo wọn toogbe wọn si sun. Ni oruganjọ, ariwo ta, Kiyesi ọkọ iyawo n bọ; ẹ jade lọ pade rẹ.”ANN 175.1

    Wiwa Kristi, bi iṣẹ iranṣẹ angẹli akọkọ ti kede rẹ ni a ri gẹgẹ bi eyi ti o duro fun wiwa ọkọ iyawo. Iṣẹ atunṣe ti o wọpọ labẹ ikede wiwa Rẹ laipẹ, duro fun bi awọn wundia ti jade lọ. Gẹgẹ bi i ti Matiu ori kẹrindinlogun, awọn ẹgbẹ meji ni a ṣe afihan wọn ninu owe yii. Gbogbo wọn ni wọn mu fitila wọn lọwọ, Bibeli pẹlu imọlẹ rẹ, wọn jade lọ lati pade Ọkọ iyawo. Ṣugbọn nigba ti “awọn ti wọn jẹ omugọ mu fitila wọn, wọn ko gbe epo dani pẹlu wọn,” “awọn ọlọgbọn gbe epo dani ninu kolobo wọn pẹlu fitila wọn.” Awọn ẹgbẹ ti o kẹyin gba oore ọfẹ Ọlọrun, agbara Ẹmi Mimọ ti n yinilọkan pada to si n lanilọyẹ, eyi ti o jẹ ki ọrọ Rẹ o jẹ fitila si ẹsẹ ati imọlẹ si ọna. Ninu ibẹru Ọlọrun wọn kọ ẹkọ Iwe Mimo lati kọ nipa otitọ, wọn si fi tọkantọkan wa ọkan ati igbesi aye mimọ. Awọn wọnyi ni iriri lẹnikọọkan, igbagbọ ninu Ọlọrun ati ninu ọrọ Rẹ, eyi ti ijakulẹ tabi ifasẹyin ko le bi ṣubu. Awọn miran “gbe fitila wọn, wọn ko si mu epo dani pẹlu wọn.” Wọn gbe igbesẹ latari igbonara. Iṣẹ iranṣẹ ẹlẹru naa ru ibẹru wọn soke, ṣugbọn wọn gbẹkẹle igbagbọ awọn arakunrin wọn, ina kekere ti inu didun mu wa tẹ wọn lọrun laisi oye otitọ ti o ye kooro tabi iṣẹ oore ọfẹ ti o munadoko ninu ọkan. Awọn wọnyi jade lati lọ pade Oluwa, wọn kun fun ireti nitori ere ti yoo wa kankan; ṣugbọn wọn ko mura silẹ fun ifasẹyin ati ijakulẹ. Nigba ti idanwo de, igbagbọ wọn baku, ina wọn si jo ajorẹyin.ANN 175.2

    “Nigba ti ọkọ iyawo pẹ de, gbogbo wọn toogbe wọn si sun.” Pipẹ ti ọkọ iyawo pẹ duro fun akoko ti o kọja nigba ti wọn n reti Oluwa, ijakulẹ naa ati eyi ti o dabi ifasẹyin. Ni akoko ainidaniloju yii, ifẹ awọn ọlọkan meji, ti wọn fi oju gbagbọ bere si nii tutu, akitiyan wọn n rẹwẹsi; ṣugbọn awọn ti igbagbọ wọn duro lori imọ ti wọn ri ninu Bibeli ní apata ni abẹ ẹsẹ wọn, ti igbi ijakulẹ ko le san danu. “Gbogbo wọn toogbe, wọn si sun;” ẹgbẹ kan wa ni aibikita wọn si kọ igbagbọ wọn silẹ, ẹgbẹ keji duro pẹlu suuru wọn n wọna boya a yoo fun wọn ni imọlẹ ti o han kedere miran. Sibẹ ninu aṣalẹ idanwo, o dabi ẹnipe awọn ẹgbẹ ti o kẹyin, padanu itara ati ifọkansin wọn diẹ. Awọn onilọwọwọ ọkan ti wọn gba ẹsin lerefe ko le rọgbọku le ori igbagbọ awọn arakunrin wọn mọ. Olukuluku ni yoo duro fun ara rẹ.ANN 175.3

    Laarin akoko yii, irokuro ẹsin bẹrẹ si nii dide. Awọn kan ti wọn sọ wipe wọn jẹ onigbagbọ pẹlu itara ninu iṣẹ iranṣẹ naa kọ ọrọ Ọlọrun silẹ gẹgẹ bi atọna ti ko le baku, wọn n sọ wipe Ẹmi ni o n dari wọn, wọn jọwọ ara wọn silẹ fun èrò, àbá ati imọlara ọkan wọn lati dari wọn. Awọn kan wa ti wọn fi igbonara alaimọkan han, wọn n ba gbogbo ẹni ti ko fi ọwọ si iwa wọn wi. Awọn ẹgbẹ Onireti ko fi oju rere wo igbagbọ agbasodi wọn; sibẹ wọn ṣiṣẹ lati mu abuku ba iṣẹ otitọ.ANN 175.4

    Satani n wa ọna nipasẹ eleyi lati tako iṣẹ Ọlọrun, ki o si pa a run. Ẹgbẹ ti n waasu ipadabọ ru ifẹ awọn eniyan soke, ọgọọrọ awọn ẹlẹṣẹ ni wọn yipada, awọn olootọ si n fi ara wọn silẹ fun iṣẹ kikede otitọ, ani ni akoko iduro. Ọmọ alade iwa buburu n padanu awọn ọmọ ijọba rẹ; lati le mu abuku ba iṣẹ Ọlọrun, o wa lati tan awọn ti wọn gba igbagbọ naa jẹ, ki o si jẹ ki wọn gba a sodi. Awọn aṣoju rẹ si ti ṣetan lati tọka si gbogbo eke, gbogbo aṣiṣe, gbogbo iwa ti ko bojumu, ki wọn fi han awọn eniyan pẹlu asọdun ti o lagbara lati le jẹ ki awọn Onireti ati igbagbọ wọn o di ohun irira. Pẹlu eleyi, iye awọn ti o ba le ko wa lati jẹ ki wọn gba igbagbọ ipadabọ lẹẹkeji, nigba ti o si n dari ọkan wọn, bẹẹ gẹgẹ ni anfani rẹ a ṣe pọ to lati tọka awọn eniyan si wọn gẹgẹ bi aṣoju gbogbo onigbagbọ.ANN 175.5

    Satani ni “olufisun awọn ara,” ẹmi rẹ si ni o n dari awọn eniyan lati maa wa aṣiṣe ati ibaku awọn eniyan Ọlọrun, ki o si mu wọn wa si gbangba, nigba ti a ko ni mẹnuba iwa rere wọn. O maa n ṣiṣẹ nigba ti Ọlọrun ba n ṣiṣẹ fun igbala ọkan. Nigba ti awọn ọmọ Ọlọrun wa fi ara wọn han niwaju Oluwa, Satani pẹlu wa laarin wọn. Ninu gbogbo isọji o ṣetan lati mu awọn ti a ko ya ọkan wọn si mimọ ti oye wọn ko kun to wọle. Nigba ti awọn wọnyi ba gba awọn otitọ diẹ, ti wọn si ni ipo laarin awọn onigbagbọ, a ṣiṣẹ nipasẹ wọn lati mu awọn ikọni ti yoo tan awọn alaibikita jẹ wa. A ko le pe ẹnikẹni ni Kristẹni nitori pe a ri papọ mọ awọn ọmọ Ọlọrun, tabi ninu ile ijọsin tabi nibi tabili Oluwa. Satani saba maa n wa nibi awọn eto ọlọwọ julọ ni aworan awọn ti o le lo gẹgẹ bi aṣoju rẹ.ANN 176.1

    Ọmọ alade iwa buburu n jijakadi lori gbogbo ilẹ nibi ti awọn eniyan Ọlọrun ti n tẹsiwaju ninu irin ajo wọn lọ si ilu ọrun. Ninu gbogbo itan ijọ, ko si iṣẹ atunṣe kan ti o waye laisi idena nla kan. Bayii ni o se ri ni akoko Pọlu. Nibikibi ti awọn apostoli ba ti gbe ijọ kan dide, awọn kan a wa ti wọn a sọ wipe wọn gba igbagbọ naa, ṣugbọn ti wọn a mu ẹkọ odi wa, eyi ti o jẹ wipe bi wọn ba gba a, yoo le ifẹ fun otitọ jade nikẹyin ni. Luther pẹlu ri idamu ati iporuuru ọkan latari iṣẹ awọn onigbonara ẹsin ti wọn n sọ wipe Ọlọrun ni o n gba ẹnu wọn sọrọ, ti wọn si n gbe ero ati igbagbọ wọn ga ju ẹri Iwe Mimọ lọ. Ọpọlọpọ ti wọn ko ni igbagbọ ati iriri, ṣugbọn ti wọn kun fun ẹmi mo tó tán, ti wọn si fẹran lati maa gba ati lati maa sọ awọn ohun tuntun, ni afarawe otitọ awọn olukọ tuntun wọnyi saba maa n tanjẹ, wọn a si darapọ mọ awọn aṣoju Satani lati bi iṣẹ ti Ọlọrun mi si Luther lati gbé dide lulẹ. Awọn Wesley pẹlu ati awọn miran ti wọn bukun araye nipasẹ ipa ati igbagbọ wọn, ni wọn pade ète Satani ni gbogbo ọna ni bi o ti n ti awọn onigbonara ju, alaimoye, ati awọn ti ọkan wọn ko yipada sinu irokuro ẹsin ni gbogbo ifarahan rẹ.ANN 176.2

    William Miller ko fi oju rere wo awọn ipa ti wọn n yọri si irokuro ẹsin. O sọ ni ibamu pẹlu Luther pe, gbogbo ẹmi ni a nilati fi ọrọ Ọlọrun dan wo. Miller sọ wipe, “Eṣu ni agbara nla lori iye awọn kan ni akoko yii. Ati bawo ni a o ṣe mo iru ẹmi ti wọn jẹ? Bibeli dahun: ‘Nipa eso wọn ni a o fi mọ wọn.’ . . . Ọpọ ẹmi ni wọn ti jade lọ sinu aye; a si ti pawá laṣẹ lati dan awọn ẹmi wo. Ẹmi ti ko ni jẹ ki a gbe ni ifarabalẹ, pẹlu ododo, ati pẹlu iwabiọlọrun, ninu aye ni akoko yii kii ṣe Ẹmi Kristi. O damiloju kedere wipe Satani nipa ti o ga ninu awọn ẹgbẹ alariwo yii. . . . Ọpọlọpọ ni aarin wa ti wọn n ṣe bi ẹnipe a ti ya wọn si mimọ patapata, ni wọn n tẹle ikọni eniyan, ti o si han kedere wipe wọn ko ni imọ otitọ gẹgẹ bi awọn ti wọn ko sọ wipe wọn ni.” “Ẹmi aṣiṣe a dari wa kuro ninu otitọ; Ẹmi Ọlorun a si dari wa sinu otitọ. Ṣugbọn, ẹyin sọ wipe, eniyan le wa ninu aṣiṣe ki o si ro wipe oun ni otitọ. Ki wa ni? A dahun, Ẹmi ati ọrọ naa fi imọ ṣọkan. Bi eniyan ba fi ọrọ Ọlọrun da ara rẹ lẹjọ, ti o si ri irẹpọ ti o peye ninu ọrọ Ọlọrun, o nilati gbagbọ wipe oun ni otitọ; ṣugbọn bi o ba ri wipe ẹmi ti o n dari oun ko si ni ibamu pẹlu gbogbo ofin tabi Iwe Ọlọrun, ki o ṣọra, ki o ma baa bọ sinu pakute eṣu.” “Mo saba maa n ri ẹri ifọkansin lati inú ọkàn wá ninu oju ti o mọlẹ, agbọn ti o tutu, ati ọrọ ti ko jade gaara ju lati inu gbogbo ariwo inu ẹsin Kristẹni lọ.”ANN 176.3

    Ni awọn akoko iṣẹ Atunṣe awọn ọta rẹ fi ẹsun gbogbo iwa buburu igbonara ẹsin kan awọn gan ti wọn n ṣiṣẹ lati dena rẹ. Ohun kan naa ni awọn alatako ẹgbẹ ipadabọ ṣe. Nigba ti ṣiṣe afihan ni ọna ti ko tọ, ati sisọ aṣiṣe awọn ti wọn gba ẹsin sodi ati awọn alara gbigbona ẹsin pẹlu asọdun kò tó, wọn tun n sọ ohun ti ko fi ara jọ otitọ rara. Ẹtanu ati ikorira ni o mu ki wọn ṣe eyi. Ikede wipe Kristi wa lẹnu ilẹkun damu alaafia wọn. Wọn bẹru wipe o le jẹ otitọ wọn si n reti wipe ki o ma jẹ otitọ, eyi ni aṣiri ijakadi pẹlu awọn Onireti ati igbagbọ wọn.ANN 176.4

    Nitori pe awọn elerokero nipa esin diẹ kan ri aaye wọ ẹgbẹ awọn Onireti ko ni ki a sọ wipe ẹgbẹ naa kii ṣe ti Ọlọrun, gẹgẹ bi a ko ti le sọ wipe nitori pe awọn ẹlẹtan wa ninu ijọ ni akoko Pọlu ati Luther, nitori naa, a yoo da iṣẹ wọn lẹbi. Ẹ jẹ ki awọn eniyan Ọlọrun o ji dide kuro ninu orun wọn ki wọn si bẹrẹ iṣẹ ironupiwada ati atunṣe lakọtun; ẹ jẹ ki wọn wá inu Iwe Mimọ lati le kọ nipa otitọ gẹgẹ bi o ti wa ninu Kristi, ẹ jẹ ki wọn fi ara wọn jin fun Ọlọrun patapata, a ki yoo si ṣe iyemeji wipe Satani n ṣiṣẹ, o si n ṣọna. Pẹlu gbogbo itanjẹ ti o le ṣe, yoo fi agbara rẹ han, yoo si pe gbogbo awọn angẹli ti wọn ti ṣubu ninu agbegbe rẹ lati ran an lọwọ.ANN 176.5

    Ki i ṣe iwaasu ipadabọ lẹẹkeji ni o fa irokuro nipa ẹsin ati iyapa. Awọn nnkan wọnyi bẹrẹ ni igba ẹrun 1844, nigba ti awọn onireti wa ni ipo iyemeji ati iporuuru ọkan nipa ipo ti wọn wà gan. Iwaasu iṣẹ iranṣẹ angẹli akọkọ ati ti “ìkede ni oru” ṣiṣẹ ni pato lati pana igbonara ẹsin ati iyapa. Awọn ti wọn kopa ninu ẹgbẹ ọlọwọ yii wa ni irẹpọ; ọkan wọn kun fun ifẹ fun ara wọn ati fun Jesu, Ẹni ti wọn n reti lati ri laipẹ. Igbagbọ kan, ireti onibukun kan, gbe ọkan wọn soke kọja agbara ipa eniyan kankan, o si jẹ aabo fun igbejako Satani.ANN 177.1

    “Nigba ti ọkọ iyawo pẹ de, gbogbo wọn toogbe wọn si sun. Ni oruganjọ, ariwo ta, kiyesi ọkọ iyawo n bọ; ẹ jade lọ pade rẹ. Nigba naa ni gbogbo awọn wundia dide wọn si tun fitila wọn ṣe.” Matiu 25:5—7. Ni igba ẹrun ni 1844, laarin igba ti a kọkọ ro wipe 2300 ọjọ yoo pari ati asiko ikore ọdun kan naa, eyi ti a ri wipe o si gun siwaju, a kede iṣẹ iranṣẹ naa pẹlu ọrọ Iwe Mimọ gan: “Kiyesi, Ọkọ iyawo n bọ!”ANN 177.2

    Ohun ti o mú ẹgbẹ yii wá ni awari wipe aṣẹ Artaxerxes lati tun Jerusalẹmu kọ, ti o jẹ ibẹrẹ akoko 2300 ọjọ, bẹrẹ ni igba ikore 457 B. C., ki i si i ṣe ibẹrẹ ọdun naa, gẹgẹ bi wọn ti gbagbọ tẹlẹ. Bi a ba ka a lati igba ikore 457, 2300 ọdun yoo pari ni igba ikore 1844.ANN 177.3

    Awọn koko ọrọ ti a mu jade lati ara apẹẹrẹ inu Majẹmu Laelae tun tọka si akoko ikore gẹgẹ bi akoko ti iṣẹlẹ ti a fi “ṣiṣe iwẹnumọ ibi mimọ” ṣe apejuwe yoo ṣẹlẹ. Eyi yeni yekeyeke nigba ti a fiyesi ọna ti awọn apẹẹrẹ ti wọn sọ nipa wiwa Kristi ni akọkọ ti ṣe wa si imuṣẹ.ANN 177.4

    Pipa ọdọ aguntan ajọ irekọja jẹ apẹẹrẹ iku Kristi. Pọlu sọ wipe: “A ti fi Kristi Ajọ Irekọja wa rubọ fun wa.” 1 Kọrintin 5:7. Ìtì eso akọso, eyi ti a n fì niwaju Oluwa ni akoko ajọ irekọja tọka si ajinde Kristi. Pọlu, nigba ti o n sọrọ nipa ajinde Oluwa ati gbogbo awọn eniyan Rẹ sọ wipe: “Kristi akọso eso; lẹyin eyi, awọn ti i ṣe ti Kristi ni igba wiwa Rẹ.” 1 Kọrintin 15:23. Gẹgẹ bi ìtì tí a n fi, eyi ti i ṣe eso akọkọ ti o pọn ti a ko jọ ṣaaju ikore, Kristi jẹ akọso eso ikore ayeraye fun awọn ti a rapada ti a yoo kojọ sinu ọgba Ọlọrun ni akoko ajinde ni ọjọ iwaju.ANN 177.5

    Awọn apejuwe yii wa si imuṣẹ, ki i ṣe ni ibamu pẹlu iṣẹlẹ nikan, ṣugbọn ni ibamu pẹlu akoko pẹlu. Ni ọjọ kẹrinla ti oṣu akọkọ awọn Ju, ni ọjọ ati oṣu naa gan eyi ti, fun ẹdẹgbẹjọ (1500) ọdun sẹyin a pa ọdọ aguntan irekọja, Kristi, lẹyin ti o jẹ irekọja pẹlu awọn ọmọ ẹyin Rẹ, fi ajọ naa lelẹ eyi ti yoo jẹ ohun iranti iku Rẹ gẹgẹ bi “Ọdọ Aguntan Ọlọrun, Ẹni ti yoo ko ẹṣẹ araye lọ.” Ni aṣalẹ ọjọ kan naa awọn ìkà eniyan mu lati kan An mọ agbelebu ati lati pa. Gẹgẹ bi imuṣẹ ìtì tí a fì, a jí Oluwa dide kuro ninu ipo oku ni ọjọ kẹta, “akọso awọn ti o sun,” apẹẹrẹ gbogbo awọn olododo ti yoo jinde, awọn ti a yoo yi “ara buburu” wọn pada “lati dabi ara ologo Rẹ.” Ẹsẹ 20; Filipi 3:21.ANN 177.6

    Ni ọna kan naa awọn apẹẹrẹ ti wọn sọ nipa ipadabọ yoo wa si imuṣẹ ni akoko ti isin alapẹrẹ tọka si. Labẹ eto Mose ṣiṣe iwẹnumọ fun ibi mimọ, tabi Ọjọ Iwẹnumọ, maa n bọ si ọjọ kẹwa oṣu keje awọn Ju (Lefitiku 16:29—31), nigba ti olu alufa, lẹyin ti o ba ti ṣe iwẹnumọ fun gbogbo Israeli, ti o si ti mu ẹṣẹ wọn kuro ninu ibi mimọ, yoo jade lati wa bukun fun awọn eniyan naa. Bẹẹ gẹgẹ ni a ṣe gbagbọ wipe Kristi, Olu Alufa wa nla, yoo fi ara han lati fọ aye mọ nipa pipa ẹṣẹ ati awọn ẹlẹṣẹ run, ati lati bukun awọn eniyan Rẹ ti n duro de E pẹlu aiku. Ọjọ kẹwa oṣu keje, Ọjọ Iwẹnumọ, akoko lati ṣe iwẹnumọ ibi mimọ, eyi ti o bọ si ọjọ kejilelogun oṣu kẹwa ni ọdun 1844, ni a ka si akoko wiwa Oluwa. Eyi wa ni ibamu pẹlu alaye ti a ti ṣe tẹlẹ wipe 2300 ọjọ yoo pari ni akoko ikore, a ko sì ríwí si ọrọ yii.ANN 177.7

    Ninu owe Matiu 25, akoko diduro ati titoogbe ṣaaju dide ọkọ iyawo. Eyi wa ni ibamu pẹlu koko ọrọ ti a ṣẹṣẹ ṣalaye tan, lati inu asọtẹlẹ ati lati inu awọn apẹẹrẹ. Wọn jẹ ootọ pọnbele; ọgọọrọ awọn onigbagbọ ni wọn kede “igbe ọganjọ oru.”ANN 177.8

    Bi igbi okun, ẹgbẹ yii bo gbogbo ilẹ. Lati ilu de ilu, lati abule de abule, ati titi de awọn ileto ti wọn farasin, o jade lọ titi ti awọn eniyan Ọlọrun ti n duro fi ji dide patapata. Irokuro ẹsin poora niwaju ikede yii bi yinyin ti n parẹ niwaju oorun. Awọn onigbagbọ ri wipe iyemeji ati iporuuru ọkan wọn kuro, ireti ati igboya fun ọkan wọn lokun. Iṣẹ naa ko ni aṣeju ninu eyi ti o saba maa n ṣẹlẹ nigba ti ẹmi eniyan ba ru soke laisi idari ọrọ ati Ẹmi Ọlọrun. O dabi akoko irẹsilẹ ati ipada sọdọ Oluwa laarin awọn ọmọ Israeli lẹyin ti wọn ba ti gba iṣẹ iranṣẹ ibawi lati ẹnu awọn iranṣẹ Rẹ. O ni aami ti o maa n wà lara iṣẹ Ọlọrun ni akoko gbogbo. Ariwo ayo kọ wọpọ, ṣugbọn awọn eniyan n yẹ ọkan wọn wo, wọn n jẹwọ ẹṣẹ, wọn si n kọ aye silẹ. Imurasilẹ lati pade Oluwa ni o gba ẹmi wọn kan. Wọn tẹsiwaju ninu adura wọn si fi ara wọn jin fun Ọlọrun patapata.ANN 178.1

    Nigba ti o n ṣe alaye iṣẹ naa, Miller sọ wipe: “Ko si fifi ayọ han lọna nla: a pa iyẹn mọ di ọjọ iwaju, nigba ti ọrun ati aye yoo yọ papọ pẹlu ayọ ti ko ṣe e fẹnu sọ ti o kun fun ogo. Ko si ariwo: Iyẹn naa, a pa mọ fun ariwo lati ọrun. Awọn akọrin dakẹ: wọn n duro lati darapọ mọ ẹgbẹ awọn angẹli, ẹgbẹ akọrin lati ọrun. . . . Ko si idarudapọ irusoke ẹmi: gbogbo wọn wa pẹlu ọkan kan ati iye kan.”ANN 178.2

    Ẹlomiran ti o kopa ninu ẹgbẹ yii jẹri wipe: “O fa yiyẹ ọkan wò ati rirẹ ọkan silẹ niwaju Ọlọrun ọrun ni ibi gbogbo. O mu ki ifẹ ọkan wọn o kuro ninu ohun aye, iwosan ija ati ibinu, ijẹwọ ẹṣẹ ati irẹra ẹni silẹ niwaju Ọlọrun, ati adura ikaanu fun ẹṣẹ ati irobinujẹ ọkan si I fun idariji ẹṣẹ ati oju rere. O fa irẹra-ẹni-silẹ ati irẹ-ọkan-silẹ eyi ti a koi tii riri. Bi Ọlọrun ti paṣẹ nipasẹ Joeli, nigba ti ọjọ nla Ọlọrun ba sunmọ etile, o mu ki eniyan o fa ọkan rẹ ya ki i si i ṣe aṣọ ati yíyí sí Ọlọrun pẹlu awẹ ati ẹkun ati ọfọ. Bi Ọlọrun ti sọ nipasẹ Sekaraya, a tu ẹmi oore ọfẹ ati ipẹ si ori awọn ọmọ Rẹ; wọn wo O, Ẹni ti a gun ni ọkọ, ọfọ nla ṣẹlẹ ni ilẹ naa . . . awọn ti n wọna fun Ọlọrun pọn ọkan wọn loju niwaju Rẹ.”ANN 178.3

    Ninu gbogbo awọn ẹgbẹ ẹsin lati akoko awọn apostoli, ko si eyi ti o dabi ti igba ikore 1844 nitori pe ko ni ibaku eniyan ati itanjẹ Satani bii ti awọn iyoku. Ani lẹyin ọpọlọpọ ọdun, gbogbo awọn ti wọn kopa ninu ẹgbẹ yii, ti wọn duro gbọin lori ipele otitọ si ni imọlara agbara mimọ iṣẹ alabukun naa, wọn si jẹri si wipe lati ọdọ Ọlọrun ni o ti wa.ANN 178.4

    Pẹlu ipe, “Ọkọ iyawo n bọ; ẹ jade lọ pade Rẹ,” awọn ti wọn n duro “dide wọn si tun fitila wọn ṣe;” wọn kọ ẹkọ ọrọ Ọlọrun pẹlu ifẹ ti o ju ti tẹlẹ lọ. A ran awọn angẹli lati ọrun lati ta awọn ti n rẹwẹsi ji ati lati pese wọn silẹ lati gba iṣẹ iranṣẹ naa. Iṣẹ naa ko duro ninu ọgbọn ati ẹkọ eniyan, bikoṣe ninu agbara Ọlọrun. Kii ṣe awọn ti wọn ni ẹbun julọ, bikoṣe awọn onirẹlẹ ati onifọkansin ni wọn kọkọ gbọ ti wọn si ṣe igbọran si ipe naa. Awọn agbẹ fi ohun ọgbin wọn silẹ ninu oko, awọn oniṣẹ ọwọ fi irin iṣẹ wọn silẹ, pẹlu omije, wọn fi ayọ jade lọ lati lọ ṣe ikilọ naa. Lapapọ, awọn ijọ kọ eti ọgbọin si iṣẹ iranṣẹ yii, iye awọn ti wọn gba iṣẹ iranṣẹ naa si jade kuro ninu wọn. Ninu iṣọwọṣiṣẹ Ọlọrun ikede yii wà ni iṣọkan pẹlu iṣẹ iranṣẹ angẹli keji o si fun iṣẹ naa lagbara.ANN 178.5

    Iṣẹ iranṣẹ wipe, “Wo o Ọkọ iyawo n bọ!” ko la ariyanjiyan pupọ lọ, bi o tilẹ jẹ wipe ẹri Iwe Mimọ yeni yekeyeke ti o tun han kedere. Agbara ti o n mi ni lọkan jade pẹlu rẹ. Ko si iyemeji, ko si ariyanjiyan. Nigba ti Kristi gun kẹtẹkẹtẹ wọ Jerusalẹmu awọn ti wọn pejọ lati gbogbo ilẹ naa lati ṣe ajọyọ wọ lọ si oke Olifi, bi wọn ti darapọ mọ awọn ero ti wọn n tẹle Jesu, wọn ni imisi akoko naa, wọn si kigbe wipe: “Ibukun ni fun Ẹni ti n bọ wa ni oruko Oluwa!” Matiu 21:9. Ni ọna kan naa ni awọn alaigbagbọ ti wọn rọ wa si ipade awọn onireti—diẹ wa lati le mọ ohun ti wọn n ṣe, awọn miran wa lati le fi wọn ṣe ẹlẹya—ni imọlara agbara ti o wa pẹlu iṣẹ iranṣẹ naa: “Wo o Ọkọ iyawo n bọ wa.”ANN 178.6

    Ni akoko naa igbagbọ ti o n mu adura gba wa—igbagbọ ti o bọwọ fun bi a ti n fi èrè funni. Gẹgẹ bi ojo lori ilẹ gbigbẹ, Ẹmi oore ọfẹ bọ si ori awọn ti n fi tọkantọkan wa a. Awọn ti wọn n reti lati duro lojukoju pẹlu Olurapada wọn ni ayọ ti ko ṣe e fẹnu sọ. Agbara Ẹmi Mimọ ti n dẹni lọkan yọ ọkan wọn bi ibukun Rẹ ti ba si ori awọn olootọ ati onigbagbọ ni ọna kikun.ANN 178.7

    Ni pẹlẹkutu ati tọwọtọwọ awọn ti wọn gba iṣẹ iranṣẹ naa sunmọ akoko ti wọn n reti lati pade Oluwa wọn. Laraarọ wọn ri gẹgẹ bi ojuṣe wọn lati ri idaniloju wipe Ọlọrun gba wọn. Ọkan wọn wa ni iṣọkan, wọn si n gbadura fun ara wọn ati pẹlu ara wọn. Ni ọpọ igba wọn maa n pade ni ibi ti o farasin lati ba Ọlọrun sọrọ, igbe ẹbẹ wọn si n goke lọ si ọrun laarin awọn papa oko. Idaniloju wipe Olugbala tẹwọ gba wọn ṣe pataki si wọn ju onjẹ oojọ wọn lọ; ti ikuuku ba si bo ọkan wọn mọlẹ, wọn ko ni sinmi titi ti a fi fẹ kuro. Bi wọn ti ni imọlara oore ọfẹ ti n dariji ni, wọn wọna lati ri Ẹni ti ọkan wọn fẹ.ANN 179.1

    Ṣugbọn lẹẹkan si, wọn a tun ri ijakulẹ. Igba ti wọn n reti kọja, Olugbala wọn ko farahan. Won ti wọna fun wiwa Rẹ pẹlu igboya ti ko mi, bayii, ọkan wọn dabi ti Maria nigba ti o de ibi ti a sin Olugbala si, ti o ri wipe o ṣofo, o sọ pẹlu ẹkun wipe: “Wọn ti gbe Oluwa mi lọ, mi o si mọ ibi ti wọn gbe tẹ si.” Johanu 20:13ANN 179.2

    Ẹmi ọwọ ati ibẹru wipe iṣẹ iranṣẹ naa le jẹ otitọ, fun igba diẹ jẹ ikoni nijanu fun awọn alaigbagbọ. Lẹyin ti akoko naa kọja, eyi ko kuro lẹẹkan naa; ni akọkọ, wọn ko le yọ fun iṣẹgun lori awọn ti a ja kulẹ; ṣugbọn nigba ti wọn ko ri aami ibinu Ọlọrun, ibẹru wọn kuro ni ọkan wọn, wọn si bẹrẹ iṣẹ ẹgan ati ifini ṣẹsin wọn. Ọpọ awọn ti wọn sọ wipe wọn gbagbọ ninu wiwa Oluwa ni wọn kọ igbagbọ wọn silẹ. Awọn ti wọn nigboya gidigidi ni ọgbẹ ọkan ninu igberaga wọn debi pe o ṣe wọn bi ẹnipe ki wọn sa kuro ninu aye. Bi Jonah, wọn ṣe aroye nipa Ọlọrun, wọn si yan iku dipo iye. Awọn ti wọn gbe igbagbọ wọn si ori ero ẹlomiran, ti ki i si i ṣe ọrọ Ọlọrun tun mura tan lati yi ero wọn pada. Awọn ẹlẹgan jere awọn alailagbara ati ojo sinu ẹgbẹ wọn, gbogbo awọn wọnyi parapọ lati kede wipe ko si ibẹru ati ireti mọ. Akoko ti kọja, Oluwa ko wa, aye le wa bakan naa fun ọpọ ẹgbẹrun ọdun.ANN 179.3

    Awọn onigbagbọ tootọ, ati onifọkansin ti fi ohun gbogbo silẹ nitori Kristi wọn si ni ipin ninu iwapẹlu Rẹ ju ti tẹlẹ lọ. Bi wọn ti gbagbọ, wọn ti fun araye ni ikilọ ti o kẹyin, wọn si reti wipe laipẹ a yoo gba wọn sinu awujọ Oluwa wọn ọrun ati awọn angẹli ọrun, ni ọna pupọ wọn ti yago kuro ninu awujọ awọn ti ko gba iṣẹ iranṣẹ naa. Pẹlu ifẹ ọkan ti o gbona, wọn gbadura pe: “Wá Jesu Oluwa, wá kankan.” Ṣugbọn ko wa. Ni bayii, lati gbe ẹru wuwo aye yii, ati lati fi ara da eebu ati ẹgan awọn ẹlẹgan aye jẹ idanwo nla igbagbọ ati ti suuru.ANN 179.4

    Sibẹ ijakulẹ yii ko tobi to eyi ti awọn ọmọ ẹyin ni iriri rẹ ni igba ti Kristi wa ni akọkọ. Nigba ti Jesu gun kẹtẹkẹtẹ pẹlu iṣẹgun wọ Jerusalẹmu, awọn atẹle Rẹ gbagbọ wipe O ti fẹ gun ori itẹ Dafidi, ki O si gba Israeli kuro ni ọwọ awọn aninilara wọn. Pẹlu ireti nla ati iwọna pẹlu ayọ, wọn n figagbága ni bibọwọ fun Ọba wọn. Ọpọ ni wọn tẹ aṣọ wọn silẹ lati jẹ ki O rin kọja, tabi ki wọn tẹ màrìwò siwaju Rẹ. Pẹlu ayọ wọn parapọ lati kigbe wipe: “Hosanna si Ọmọ Dafidi!” Nigba ti awọn Farisi fẹ ki Jesu da awọn ọmọ ẹyin Rẹ lẹkun, nitori ti ariwo ayọ wọn n bi wọn ninu, o si n damu alaafia wọn, O dahun: “Bi awọn wọnyi ba dakẹ, lọgan ni awọn okuta yoo kigbe sita.” Luku 19:40. Asọtẹlẹ nilati wa si imuṣẹ. Awọn ọmọ ẹyin n mu erongba Ọlọrun wa si imuṣẹ; sibẹ wọn yoo ni ijakulẹ kikoro. Ṣugbọn ọjọ diẹ ni o tẹle nigba ti wọn ri Olugbala ti O n ku iku oró, ti wọn si tẹ Ẹ sinu iboji. Ireti wọn ko wa si imuṣẹ ni ọna ti wọn ro, ireti wọn si ku pẹlu Jesu. Igba ti Oluwa wọn jade pẹlu iṣẹgun lati inu iboji ni wọn to ri wipe a ti sọ gbogbo rẹ tẹlẹ ninu isọtẹlẹ ati pe “Kristi nilati jiya, ki o si ji dide kuro ninu ipo oku.” Iṣe 17:3.ANN 179.5

    Ẹẹdẹgbẹrin (500) ọdun ṣaaju, Oluwa ti kede nipasẹ woli Sekaraya wipe: “Ẹ bu sayọ, ẹyin ọmọbinrin Sioni, ẹ kigbe, ẹyin ọmọbinrin Jerusalẹmu: kiyesi Ọba rẹ n bọ wa sọdọ rẹ: O jẹ olododo O si ni igbala; onirẹlẹ, ti O n gun kẹtẹkẹtẹ O n gun ọmọ kẹtẹkẹtẹ.” Sekaraya 9:9. Bi awọn ọmọ ẹyin ba mọ wipe Kristi n lọ si ibi idajọ ati iku ni, wọn ki ba ti mu asọtẹlẹ yii ṣẹ.ANN 179.6

    Ni ọna kan naa Miller ati awọn akẹgbẹ rẹ mu isọtẹlẹ ṣẹ wọn si funni ni iṣẹ iranṣẹ eyi ti Imisi ti sọtẹlẹ wipe a yoo fun araye, ṣugbọn ti wọn ki ba ti fun ni bi wọn ba ni oye kikun nipa asọtẹlẹ ti o tọka si ijakulẹ wọn, ti o tun sọ nipa iṣẹ iranṣẹ miran ti a yoo waasu fun gbogbo orilẹ ede ki Oluwa to wa. A funni ni iṣẹ iranṣẹ angẹli akọkọ ati ekeji ni akoko ti o yẹ, wọn si ṣe iṣẹ ti Ọlọrun fẹ ki wọn ṣe.ANN 179.7

    Araye n woye, wọn n reti wipe, bi akoko naa ba kọja ti Kristi ko si fi ara han, a yoo kọ gbogbo eto ẹgbẹ Onireti silẹ. Ṣugbọn nigba ti ọpọlọpọ kọ igbagbọ wọn silẹ labẹ idanwo nla, awọn kan wa ti wọn duro gbọin. Awọn eso ẹgbẹ Onireti, ẹmi irẹlẹ ati yiyẹ ọkan wo, kikọ aye silẹ ati titun aye ẹni ṣe, eyi ti o tẹle iṣẹ wọn jẹri si wipe ti Ọlọrun ni. Wọn ko le sẹ wipe agbara Ẹmi Mimọ jẹri si iwaasu ipadabọ lẹẹkeji, wọn ko si le ri aṣiṣe kankan ninu iṣọwọṣiro akoko isọtẹlẹ. Eyi ti o lagbara julọ ninu awọn alatako wọn ko le bi agbekalẹ iṣọwọtumọ asọtẹlẹ wọn lulẹ. Laisi ẹri Bibeli, wọn ko le gba lati kọ ipo wọn silẹ ipo ti wọn de lẹyin ikẹkọ Bibeli pẹlu adura tọkantọkan, pẹlu ọkan ti Ẹmi Ọlọrun mi si ati ọkan ti o n gbina pẹlu agbara iwalaaye rẹ; ipo ti o duro gbọin bi o tilẹ jẹ wipe awọn olukọ ẹsin ti wọn lokiki ati awọn ọlọgbọn aye tako o kikankikan, eyi ti o duro bi o tilẹ jẹ wipe awọn sọrọsọrọ ati awọn ọmọwe tako o, bi o tilẹ jẹ wipe awọn ẹni iyi ati eniyan lasan ni awujọ fi ṣe ẹfẹ ti wọn si kẹgan rẹ.ANN 180.1

    Lootọ, ibaku wá lori ohun ti wọn n reti, ṣugbọn eyi ko le mi igbagbọ wọn ninu ọrọ Ọlọrun. Nigba ti Jonah waasu ninu igboro Ninefe wipe laarin ogoji ọjọ, a yoo pa ilu naa run, Oluwa gba irẹraẹnisilẹ awọn ara Ninefe, O si fi kun akoko oore ọfẹ won; sibẹ ọdọ Ọlọrun ni iṣẹ iranṣẹ Jonah ti wa, a si dan Ninefe wo gẹgẹ bi ifẹ Rẹ. Awọn Onireti gbagbọ bakan naa wipe Ọlọrun dari wọn lati funni ni ikilọ nipa idajọ. Wọn sọ pe, “O ti dan ọkan gbogbo awọn ti wọn gbọ ọ wo, o si ta ifẹ fun ifarahan Oluwa ji; tabi o ti mu ikorira fun wiwa Rẹ wá eyi ti o jẹ wipe a ri ni bi o ti wu ki o mọ. O ti pa ala, . . . ki awọn ti wọn yoo yẹ ọkan ara wọn wo le mọ iha ẹni ti wọn yoo wa, bi o ba ṣe wipe Oluwa wa nigba naa—boya wọn a le kigbe wipe, ‘Kiyesi! Ọlọrun niyi, awa ti duro de E, yoo si gba wa;” tabi boya wọn a pe apata ati oke lati wo lu wọn lati le fi wọn pamọ kuro niwaju Ẹni ti o joko lori itẹ ati kuro lọwọ ibinu Ọdọ Aguntan. Gẹgẹ bi a ti gbagbọ, bayi ni Ọlọrun se dan awọn eniyan Rẹ wo, O dan igbagbọ wọn wo, O yẹ wọn wo, O si ri boya wọn a yipada ni akoko idanwo kuro ninu ipo eyi ti I ba ri wipe o dara lati fi wọn si; tabi boya wọn a kọ aye yii silẹ, wọn a si ni igbagbọ ninu ọrọ Ọlọrun patapata.”ANN 180.2

    Ero ọkan awọn ti wọn gbagbọ wipe Ọlọrun ni O n dari wọn ninu awọn iriri wọn latẹyin wa ni a ṣalaye ninu ọrọ William Miller: “Bi mo ba le tun aye mi gbe lẹẹkansi, pẹlu ẹri kan naa ti mo ni, ni tootọ si Ọlọrun ati eniyan, maa ṣe gẹgeẹ bi mo ti ṣe.” “Mo ni ireti wipe mo ti fọ ẹjẹ awọn eniyan mọ kuro lara aṣọ mi. Mo mọ wipe, gẹgẹ bi o ti wa ninu agbara mi mo bọyọ kuro ninu ẹbi idalẹbi wọn.” Eniyan Ọlọrun yii kọwe wipe, “Bi o tilẹ jẹ wipe mo ti ni ibaku lẹẹmeji, mi o tẹba, tabi ni irẹwẹsi. . . . Ireti mi ninu wiwa Kristi si lagbara bii ti tẹlẹ. Mo ṣe ohun ti mo ri gẹgẹ bi ojuṣe mi lẹyin ayẹwo fun ọpọlọpọ ọdun. Bi mo ba ṣe aṣiṣe, ni ìhà aanu ni mo ṣe si, lati fẹran awọn arakunrin mi, ati igbagbọ mi nipa ojuṣe mi si Ọlọrun.” “Ohun kan ni mo mọ, mi o waasu ohunkohun ayafi eyi ti mo gbagbọ, Ọlọrun si wa pẹlu mi; agbara Rẹ fi ara han ninu iṣẹ naa, èrè pupọ si ni o ti ibẹ jade.” “Ọpọ eniyan, gẹgẹ bi awọn eniyan ti ri, ni wọn kọ ẹkọ Iwe Mimọ nipasẹ iwaasu akoko naa; nitori eyi, nipasẹ igbagbọ ati ẹjẹ Kristi, wọn ti ba Ọlọrun laja.” Mi o bẹbẹ fun ẹrin agberaga, mi o bẹru nitori ifajuro aye. Bayi, mi o ni ra oju rere wọn, tabi ki n rekọja ojuṣe mi lati dan wọn wo. Mi o ni wa ẹmi mi lọwọ wọn, tabi ki n lọra lati padanu rẹ, bi Ọlọrun ninu iṣọwọṣiṣẹ Rẹ ba ṣe bẹẹ ṣe eto rẹ.”ANN 180.3

    Ọlọrun ko kọ awọn eniyan Rẹ silẹ; Ẹmi Rẹ si wa pẹlu awọn ti ko fi igbonara sẹ imọlẹ ti wọn gba, ki wọn si kẹgan ẹgbẹ Onireti. Awọn ti a n danwo ti wọn duro ni akoko wahala yii ri ọrọ imoriya ati ikilọ ninu Episteli Heberu: “Maṣe sọ igboya rẹ nu, eyi ti o ni èrè nla. Nitori ẹ nilo suuru, wipe lẹyin ti ẹyin ba ti ṣe ifẹ Ọlọrun, ẹ yoo gba ileri naa. Nitori fun igba diẹ, Ẹni ti yoo wa yoo wa, ki yoo si pẹ. Olododo yoo wa nipa igbagbọ: ṣugbọn bi ẹnikẹni ba fa sẹyin, ọkan Mi ki yoo nifẹ si. Ṣugbọn awa ko si lara awọn ti wọn fa sẹyin sinu iparun; bikoṣe lara awọn ti wọn gbagbọ si igbala ọkan.” Heberu 10: 35—39.ANN 180.4

    Wipe ijọ ni akoko ikẹyin ni a gba niyanju yii farahan ninu awọn ọrọ ti wọn tọka si bi wiwa Oluwa ti sunmọ: “Fun igba diẹ si, Ẹni ti yoo wa yoo wa, ki yoo si pẹ.” O si han kedere wipe yoo dabi ẹnipe ifasẹyin wa, yoo si dabi ẹnipe o pẹ ki Oluwa o to de. Ikilọ ti a fifunni nibi ni i ṣe ni pataki julọ pẹlu iriri awọn Onireti ni akoko yii. Awọn ti a ba sọrọ nibi wa ninu ewu atidoju igbagbọ wọn bolẹ. Wọn ti ṣe ifẹ Ọlọrun ni titẹle itọsọna Ẹmi Rẹ ati ọrọ Rẹ; sibẹ wọn ko ni oye erongba Rẹ ninu iriri wọn latẹyin wa, bẹẹ si ni wọn ko ni oye ọna ti o wa niwaju wọn, wọn wa ninu idanwo boya ki wọn ṣe iyemeji, boya Ọlọrun ni O n dari wọn lootọ. Ni akoko yii, awọn ọrọ wọnyi nitumọ: “Olododo yoo wa nipa igbagbọ.” Bi imọlẹ nla ti “igbe ni oruganjọ” ti tan si ọna wọn, wọn ri bi asọtẹlẹ ti n ṣipaya ti awọn ami ti wọn n ṣẹ kankan n sọ fun wọn wipe wiwa Kristi sunmọle, wọn ti rin, gẹgẹ bi a ti le sọ nipa ohun ti oju wọn ri. Ṣugbọn nisinsinyi, ti ori wọn tẹba nitori ireti wọn ti o jakulẹ, nipa igbagbọ ninu Ọlọrun ati ninu ọrọ Rẹ ni wọn fi le duro. Awọn araye ti n kẹgan sọ wipe: “A ti tan yin jẹ. Ẹ kọ igbagbọ yin silẹ, ki ẹ si sọ wipe Satani ni o n dari ẹgbẹ yii.” Ṣugbọn ọrọ Ọlọrun sọ wipe: “Bi ẹnikẹni ba fa sẹyin, ọkan Mi ki yoo ni inudidun si.” Lati wa kọ igbagbọ wọn silẹ bayi, ki wọn si sẹ agbara Ẹmi Mimọ ti o ti wa pẹlu iṣẹ iranṣẹ wọn, yoo tumọ si fifasẹyin sinu iparun. Ọrọ Pọlu gba wọn niyanju lati duro ṣinṣin: “Ẹ maṣe sọ igboya yin danu;” “ẹ nilo suuru,” “fun igba diẹ si Ẹni ti yoo wa yoo wa, ki yoo si pẹ.” Ohun kan ṣoṣo ti o tọna ti wọn le ṣe ni lati mu imọlẹ ti wọn ti gba lati ọdọ Ọlọrun lọkunkundun, ki wọn si di ileri Rẹ mu, ki wọn tẹsiwaju lati wá inu Iwe Mimọ, ki wọn si fi suuru duro ki wọn si maa sọna lati gba imọlẹ si.ANN 181.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents