Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KẸTALELOGUN—KINI IBI MIMỌ?

    Ẹsẹ iwe mimọ ti i ṣe ipilẹ ati òpó aarin gungun ti ipadabọ nì kede wipe: “Titi fi di ẹgbẹrun meji o le ọgọrun mẹta (2300) ọjọ ni a o ṣe iwẹnumọ ibi mimọ.” Daniẹli 8:14. Awọn wọnyi jẹ ọrọ ti ko ṣajeji si awọn onigbagbọ ninu wiwa Oluwa laipẹ. Ọpọ ni wọn sọ asọtẹlẹ yii ni asọtunsọ gẹgẹ bi akọmọna igbagbọ wọn. Gbogbo wọn ro wipe lori iṣẹlẹ ti a sọtẹlẹ naa ni afojusun wọn, ti o mọlẹ julọ ati ireti ti wọn fẹran julọ duro le lori. Awọn ọjọ asọtẹlẹ wọnyi ni a fihan wipe wọn pari ni akoko ikore ni 1844. Ni ibamu pẹlu awọn Kristẹni yooku, awọn Onireti nigba naa gbagbọ wipe aye, tabi diẹ ninu rẹ, ni ibi mimọ. Wọn ni oye wipe ṣiṣe iwẹnumọ ibi mimọ tumọ si fifọ aye mọ pẹlu ina ọjọ nla ikẹyin, ati wipe eyi yoo ṣẹlẹ ni asiko ipadabọ lẹẹkeji. Eyi ni o fa akotan ọrọ wipe Kristi yoo pada wa si aye ni 1844.ANN 182.1

    Ṣugbọn akoko ti a yan kọja, Oluwa ko si fi ara han. Awọn onigbagbọ mọ wipe ọrọ Ọlọrun ko le baku; o nilati jẹ wipe itumọ ti wọn fun isọtẹlẹ ni kò peye; ṣugbọn nibo ni aṣiṣe naa wa? Ọpọ ni wọn fi igbonara yanju iṣoro naa nipa sisọ wipe 2300 ọjọ ko pari ni 1844. Wọn ko ri idi fun eleyi ju wipe Kristi ko wa ni akoko ti wọn reti Rẹ. Wọn sọ pe bi ọjọ asọtẹlẹ ba pari ni 1844, Kristi i ba ti pada wa lati ṣe iwẹnumọ ibi mimọ nipa fifọ aye mọ pẹlu ina; ati pe nigba ti ko i tii wa, awọn ọjọ naa koi tii le pari.ANN 182.2

    Lati gba ọrọ yii ni lati kọ iṣọwọka akoko isọtẹlẹ ti wọn gba tẹlẹ silẹ. 2300 ọjọ ni a ri wipe o bẹrẹ ni igba ti aṣẹ Artaxerxes lati ṣe atunṣe Jerusalẹmu ati lati tun kọ bẹrẹ ni igba ikore 457 B. C. Bi a ba mu eleyi gẹgẹ bi akoko ibẹrẹ, ibaṣepọ ti o peye wa ninu imuṣẹ gbogbo awọn iṣẹlẹ ti a sọ tẹlẹ ninu alaye akoko naa ninu Daniẹli 9:25—27. Ọkan din laadọrun ọsẹ, 483 ọdun akọkọ ninu 2300 ọdun, yoo lọ de akoko Mesaya, Ẹni Ami Ororo; ati itẹbọmi Kristi ati ifami ororo yan Ẹmi Mimọ, A. D. 27, akoko gan pato ti o mu alaye naa ṣẹ. Ni aarin ọsẹ ti o kẹyin ninu aadọrin ọsẹ, a o ge Mesaya kuro. Ọdun mẹta aabọ lẹyin itẹbọmi Rẹ, a kan Kristi mọ agbelebu ni akoko riru ewé ni A. D. 31. Aadọrin ọsẹ tabi 490 ọdun, yoo ni i ṣe pẹlu awọn Ju ni pato. Ni opin akoko yii orilẹ ede naa fi ontẹ lu bi o ti kọ Kristi silẹ nipa ṣiṣe inunibini si awọn ọmọ ẹyin Rẹ, awọn ọmọ ẹyin si tọ awọn Keferi lọ ni A. D. 34. Nigba ti ọdun 490 ninu 2300 ọdun ti pari, yoo ku 1810 ọdun silẹ. Lati A. D. 34, 1810 lọ de 1844. Angẹli naa sọ wipe, “Nigba naa ni a o ṣe iwẹnumọ ibi mimọ.” Gbogbo alaye asọtẹlẹ ti o ṣaaju ni wọn wa si imuṣẹ, laisi ariyanjiyan, ni akoko ti a la kalẹ.ANN 182.3

    Pẹlu iṣọwọka akoko yii, ohun gbogbo ni o han kedere ti o tun wa ni irẹpọ, ayafi wipe a ko ri ki iṣẹlẹ kankan ṣẹlẹ ki o dahun si ṣiṣe iwẹnumọ ibi mimọ ni 1844. Lati sọ wipe ọjọ naa ko pari ni akoko naa ni lati sọ gbogbo rẹ sinu idarudapọ ati lati kọ ipo ti a gbe kalẹ nipa imuṣẹ asọtẹlẹ ti ko yẹsẹ silẹ.ANN 182.4

    Ṣugbọn Ọlọrun ni O dari awọn eniyan Rẹ ninu ẹgbẹ nla ti ipadabọ; agbara ati ogo Rẹ tẹle iṣẹ wọn, ko si ni gba ki o pari sinu okunkun ati ijakulẹ, ki a wa kẹgan rẹ gẹgẹ bi èké ati irusoke ifẹ ọkan. Ko fi ọrọ Rẹ silẹ ninu iyemeji ati aidaniloju. Bi o tilẹ jẹ wipe ọpọ ni wọn kọ iṣọwọka akoko isọtẹlẹ ti wọn n lo tẹle silẹ ti wọn si sọ wipe ẹgbẹ ti o dide latari rẹ ko tọna, awọn miran ko fẹ fi koko igbagbọ ati iriri ti Iwe Mimọ ti lẹyin, ti Ẹmi Ọlọrun tun jẹri si silẹ. Wọn gbagbọ wipe wọn lo agbekalẹ itumọ ti o peye ninu bi wọn ti n kẹkọ isọtẹlẹ, ati wipe ojuṣe wọn ni lati di otitọ ti wọn ri mu ṣinṣin, ki wọn si tẹsiwaju ninu ẹkọ Bibeli. Pẹlu adura atọkanwa, wọn ṣe atunyẹwo ipo wọn, wọn si kẹkọ Iwe Mimọ lati le ri aṣiṣe wọn. Nigba ti wọn ko ri aṣiṣe ninu iṣọwọka akoko isọtẹlẹ wọn, wọn ṣe ayẹwo finifini koko ọrọ ti a pe ni ibi mimọ.ANN 182.5

    Ninu ayẹwo wọn, wọn kọ wipe ko si ẹsẹ Iwe Mimọ lati fi gbe igbagbọ ti o wọpọ wipe aye yii ni ibi mimọ lẹsẹ; ṣugbọn wọn ri alaye kikun lori ibi mimọ ninu Bibeli, irisi rẹ, ibi ti o wa ati awọn eto inu rẹ; ẹri awọn onkọwe mimọ sọ ọ ni ọna ti o yeni yekeyeke ti ko fi yẹ ki ibeere o wa. Apostoli Pọlu ninu iwe Heberu sọ wipe: “Majẹmu iṣaaju paapaa ni ilana ijọsin ti o mọ, ati ibi mimọ kan ti a ṣe fun ijọsin ninu aye yii. Nitori pe a pa agọ kan; eyi ti iṣaaju ninu eyi ti ọpa fiitila ati tabili ati akara ifihan gbe wa, eyi ti a n pe ni ibi mimọ. Ati lẹyin aṣọ ìkélé keji, oun ni agọ ti a n pe ni ibi mimọ julọ; ti o ni awo turari wura ati apoti majẹmu ti a fi wura yi ara rẹ ka, ninu eyi ti ikoko wura ti mana wa ninu rẹ gbe wa, ati ọpa Aroni ti o rudi, ati awọn walaa majẹmu; ati lori rẹ ni awọn kerubu ogo ti wọn ṣiji bo itẹ naa.” Heberu 9:1—5.ANN 182.6

    Ibi mimọ ti Pọlu n sọ nibi ni agọ ti Mose pa, eyi ti Ọlọrun palaṣẹ fun gẹgẹ bi ibugbe Ẹni Giga julọ ni aye. “Jẹ ki wọn pa agọ kan fun Mi; ki Emi le gbe ni aarin wọn” (Eksodu 25:8), ni aṣẹ ti a fun Mose nigba ti o wa ni ori oke pẹlu Ọlọrun. Awọn ara Israeli n rin ninu aginju, a si pa agọ naa ni ọna ti a fi le gbe lati ibi kan de ekeji; sibẹ o jẹ ile ti o rẹwa. Ogiri rẹ jẹ igi ti a fi wura kun jọjọ, ti a gbe sinu ihò fadaka, nigba ti orule rẹ jẹ oriṣi aṣọ ìlekè, tabi aṣọ ti a fi n bo nnkan, awọ, aṣọ ọgbọ wiwe ti a ya aworan kerubu si. Gbọngan ita, ti o ni pẹpẹ ẹbọ sisun, agọ naa funra rẹ ni yara meji ti a pe ni ibi mimọ ati ibi mimọ julọ, ti a fi aṣọ ìkélé ti o rẹwa da, tabi iboju; iru iboju kan naa ni o bo ẹnu ọna yara akọkọ.ANN 183.1

    Ọpa fitila wa ni iha gusu ninu ibi mimọ pẹlu awọn itanna meje rẹ ti n fun ibi mimọ ni imọlẹ lọsan loru; ni iha ariwa ni tabili akara ifihan wa; niwaju iboju ti o pin ibi mimọ ati ibi mimọ julọ si meji ni pẹpẹ turari oniwura wa, nibi ti eefin oloorun didun, pẹlu adura Israeli ti n goke lọ siwaju Ọlọrun lojoojumọ.ANN 183.2

    Ni ibi mimọ julọ ni apoti kekere kan wa, apoti ti a fi igi ojulowo ṣe ti a tun fi wura kun, nibi ti a gbe walaa okuta si, nibẹ ni Ọlọrun kọ Ofin Mẹwa si. Ni ori apoti naa ni itẹ aanu wa eyi ti o duro gẹgẹ bi ibori apoti mimọ naa, iṣẹ ọnà ti o dara, ti a gbé kerubu meji le lori, ọkan lẹgbẹ kini ati ekeji, wura ojulowo ni a fi ṣe gbogbo wọn. Ninu yara yii ni Ọlọrun ti n fi ara han ninu ikuuku ogo laarin awọn kerubu.ANN 183.3

    Lẹyin ti awọn Heberu tẹdo si Kenani, tẹmpili Solomoni ni o rọpo agọ yii, bi o tilẹ jẹ wipe o jẹ ile, ti o tun tobi ju u lọ, odiwọn kan naa ni wọn lo, a tun ṣe e lọṣọ bakan naa. Bayi ni ibi mimọ naa ṣe wa—ayafi igba ti o wa ni ahoro ni akoko Daniẹli—titi fi di igba ti awọn Romu fi pa a run ni A. D. 70.ANN 183.4

    Ibi mimọ kan ṣoṣo ti o wa ninu aye ri niyii, ohun nikan ni Bibeli sọ nipa rẹ. Eyi ni Pọlu pe ni ibi mimọ ti majẹmu akọkọ. Ṣugbọn ṣe majẹmu tuntun ko ni ibi mimọ ni?ANN 183.5

    Ni yiyi si iwe Heberu, awọn ti wọn n wa otitọ ri wipe a le ri dimu ninu ọrọ Pọlu ti a ka loke wipe majẹmu keji, tabi majẹmu tuntun ni ibi mimọ: “Majẹmu iṣaaju paapa ni ilana ijọsin ti o jẹ mimọ, ati ibi mimọ kan ti a ṣe fun ijọsin ninu aye yii.” Lilo ọrọ ti a pe ni “paapaa” fihan wipe Pọlu ti mẹnuba ibi mimọ yii tẹlẹ. Bi a ba pada sẹyin lọ si ori kẹjọ, a ka wipe: “Njẹ pataki ohun ti a n sọ ni eyi: Awa ni iru Olori alufa kan, ẹni ti o joko ni ọwọ ọtun itẹ Ọlanla ninu awọn ọrun; Alufa ibi mimọ, ati agọ tootọ, eyi ti kii ṣe eniyan ni o kọ bikoṣe Oluwa.” Heberu 8:1, 2.ANN 183.6

    Nibi ni a ti fi ibi mimọ majẹmu tuntun han. Eniyan ni o kọ ibi mimọ ti majẹmu akọkọ, Mose ni o kọ; Oluwa ni o kọ eyi , ki i ṣe eniyan. Ninu ibi mimọ yẹn awọn alufa ti aye yii ni wọn n ṣe iṣẹ isin wọn nibẹ; ninu eyi, Kristi, Olu Alufa wa nla, ni O n ṣesin ni ọwọ ọtun Ọlọrun. Ibi mimọ kan wa ni aye, ikeji wa ni ọrun.ANN 183.7

    Siwaju si, a pa agọ ti Mose kọ ni ibamu pẹlu apẹẹrẹ kan. Oluwa ti pa a laṣẹ: “Gẹgẹ bi gbogbo eyi ti mo fi han ọ, nipa apẹẹrẹ agọ, ati apẹẹrẹ gbogbo ohun elo inu re, bẹẹ ni ki ẹyin ki o ṣe e.” Siwaju si, a tun pa aṣẹ yii, “Si kiyesi ki iwọ o ṣe wọn gẹgẹ bi apẹẹrẹ ti a fi han ọ lori oke.” Eksodu 25:9, 40. Pọlu sọ wipe ibi mimọ akọkọ “jẹ apẹẹrẹ fun ti akoko yii, nibi ti a ti n ru ọrẹ ati ẹbọ;” wipe awọn ibi mimọ rẹ jẹ “apẹẹrẹ awọn ohun ti ọrun;” wipe awọn alufa ti wọn n mu ọrẹ wa gẹgẹ bi ofin n ṣe e “gẹgẹ bi apẹẹrẹ ati ojiji awọn ohun ti ọrun,” ati pe “Kristi ko wọ awọn ibi mimọ ti a fi ọwọ kọ, eyi ti i ṣe aworan ibi mimọ tootọ; ṣugbọn sinu ọrun funra Rẹ, ni bayi lati fi ara han niwaju Ọlọrun fun wa.” Heberu 9:9, 23; 8:5; 9:24.ANN 183.8

    Ibi mimọ ni ọrun, nibi ti Jesu ti n ṣiṣẹ fun wa, òhun ni ibi mimọ gan, eyi ti ibi mimọ ti Mose kọ jẹ apẹẹrẹ fun. Ọlọrun fi Ẹmi Rẹ si ori awọn ti wọn kọ ibi mimọ aye. Iṣẹ ọna ti wọn fi kọ jẹ afihan ọgbọn ọrun. Awọn ogiri rẹ ni irisi wura pupọ, ti o n fi ina lati ara fitila meje ti ọpa fitila han ni gbogbo ọna. Tabili akara ifihan ati pẹpẹ turari n dan gbinrin bi wura ti a ṣe lọṣọ. Awọn aṣọ ileke didara ti a fi ṣe orule, ti a ṣe iṣẹ ọna awọn angẹli si pẹlu awọ búlù ati awọ aluko ati pupa, fi kun ẹwa ìrí naa. Lẹyin aṣọ ikele keji ni Shekinah mimọ wa, iri ifihan ogo Ọlọrun, ko si ẹni ti o le de iwaju rẹ ki o si ye ayafi olu alufa.ANN 183.9

    Ẹwa ti ko lafiwe agọ aye ṣe afihan fun oju eniyan awọn ogo tẹmpili ti ọrun nibi ti Kristi aṣaaju wa ti n ṣiṣẹ fun wa niwaju itẹ Ọlọrun. Ibugbe Ọba awọn ọba, nibi ti ẹgbẹẹgbẹrun ti n jọsin fun, ti ẹgbẹrun lọna ẹgbẹẹgbẹrun ti duro niwaju Rẹ (Daniẹli 7:10); tẹmpili yii kun fun ogo itẹ ayeraye, nibi ti awọn serafu, awọn ẹṣọ rẹ ti n dan, n bo oju wọn fun ijọsin, le ri afarawe ninu ile ti o rẹwa julọ ti eniyan kọ, ṣugbọn ti o jẹ ifihan ti o ri baibai ni ti titobi ati ogo rẹ. Sibẹ awọn otitọ ti wọn ṣe pataki nipa ibi mimọ ti ọrun ati iṣẹ nla ti a n ṣe nibẹ fun irapada eniyan ni ibi mimọ aye ati awọn eto rẹ fi kọni.ANN 184.1

    Awọn yara mimọ ibi mimọ ti ọrun ni a ṣe afihan wọn pẹlu yara meji ninu ibi mimọ ni aye. Gẹgẹ bi a ti gba apostoli Johanu laaye lati ri tẹmpili Ọlọrun ni ọrun ninu iran, o ri “fitila meje ti n jo niwaju itẹ naa” nibẹ. Ifihan 4:5. O ri angẹli “ti o ni àwo turari wura; a si fun ni turari pupọ, ki o le ru u pẹlu adura awọn eniyan mimọ lori pẹpẹ wura ti o wa niwaju itẹ naa.” Ifihan 8:3. Nibi a gba woli naa laaye lati ri abala akọkọ ninu ibi mimọ ni ọrun, o si ri “fitila meje” ati “pẹpẹ wura” nibẹ ni eyi ti ọpa fitila wura ati pẹpẹ turari ninu ibi mimọ ti aye duro fun wa. Lẹẹkan si, “a ṣi tẹmpili Ọlọrun silẹ” (Ifihan 11:19), o si wo inu aṣọ ìkélé, ninu ibi mimọ julọ. Nibi ni o ti ri “apoti ẹri Rẹ,” ti apoti mimọ ti Mose kan ti a gbe ofin Ọlọrun si duro fun.ANN 184.2

    Bayi ni awọn ti wọn kẹkọ koko ọrọ naa ṣe ri ẹri aridaju wipe ibi mimọ wa ni ọrun. Mose kọ ibi mimọ aye ni ibamu pẹlu aworan ti a fi han an. Pọlu kọni wipe apẹẹrẹ naa ni ti ibi mimọ tootọ ti o wa ni ọrun. Johanu si jẹri si wipe oun ri ni ọrun.ANN 184.3

    Ninu tẹmpili ni ọrun, ibugbe Ọlọrun, a fi idi itẹ Rẹ lelẹ ni ododo ati idajọ. Ninu ibi mimọ julo ni ofin Rẹ wa, odiwọn nla fun ohun ti o tọna, eyi ti a o fi dan gbogbo eniyan wo. Apoti naa ti a gbe walaa ofin sinu rẹ ni a fi itẹ aanu bo, niwaju eyi ti Kristi ti n fi ẹjẹ Rẹ bẹbẹ nitori ẹlẹṣẹ. Bayii a ṣe ṣe afihan iṣọkan ti o wa laarin idajọ ati aanu ninu eto irapada eniyan. Ọgbọn ayeraye nikan ni o le pete iṣọkan yii, agbara ayeraye nikan ni o le mu wa si imuṣẹ; o jẹ iṣọkan ti o mu iyanu ati iyin kun gbogbo ọrun. Awọn kerubu ibi mimo ti aye n fi tọwọtọwọ boju wo itẹ aanu, eyi ti o ṣe afihan ifẹ ọkan ti ogun ọrun fi n ronu lori iṣẹ igbala. Eyi ni ohun ijinlẹ aanu eyi ti awọn angẹli n fẹ lati wo—wipe Ọlọrun le jẹ olododo nigba ti O n da ẹlẹṣẹ ti o ronupiwada lare, ti O si tun ibaṣepọ Rẹ ṣe pẹlu iran ti o ṣubu; wipe Kristi le rẹ ara Rẹ silẹ lati fa ọpọ awọn eniyan kuro ninu kòtò iparun ki O si fi aṣọ ododo Rẹ ti ko ni abawọn wọ wọn lati so wọn pọ mọ awọn angẹli ti ko lẹṣẹ, ki wọn si le maa gbe titi lae niwaju Oluwa.ANN 184.4

    Iṣẹ Kristi gẹgẹ bi alagbawi eniyan ni a sọ ninu asọtẹlẹ ti o rẹwa ti Sekaraya nipa Ẹni naa “ti orukọ rẹ n jẹ Ẹka.” Woli naa sọ pe: “Yoo kọ tẹmpili Oluwa; yoo si gbe ogo, yoo si ṣe akoso lori itẹ [Baba] Rẹ; yoo si jẹ alufa lori itẹ Rẹ: imọran alaafia yoo si wa laarin Awọn mejeeji.” Sekaraya 6:12, 13.ANN 184.5

    “Yoo kọ tẹmpili Oluwa.” Nipa irubọ ati ibalaja Rẹ, Kristi di ipilẹ ati onkọle ijọ Ọlọrun. Apostoli Pọlu tọka si I gẹgẹ bi “pataki Okuta igun ile; ninu ẹni ti gbogbo ile naa ti a n kọ ṣọkan pọ, n dagba soke ni tẹmpili mimọ ninu Oluwa: ninu ẹni ti” o sọ wipe, “a kọ papọ fun ibugbe Ọlọrun nipasẹ Ẹmi.” Efesu 2: 20—22ANN 184.6

    “Yoo ru ogo naa.” Kristi ni o ni ogo irapada iran ti o baku. Titi de ayeraye, orin awọn ti a rapada yoo jẹ: “Si Ẹni ti o fẹ wa ti o si wẹ wa mọ kuro ninu ẹṣẹ wa ninu ẹjẹ ara Rẹ, . . . ti Rẹ ni ogo ati ijọba lae ati laelae.” Ifihan 1:5, 6.ANN 184.7

    “Yoo joko yoo si ṣe akoso lori itẹ Rẹ; yoo si di alufa lori itẹ Rẹ.” Ki i ṣe “lori itẹ ogo Rẹ” nisinsinyii; ijọba ogo koi tii bẹrẹ. O di igba ti iṣẹ ibalaja Rẹ ba pari ki Ọlọrun to “fun ni itẹ Dafidi baba Rẹ,” ijọba ti “ki yoo lopin.” Luku 1:32, 33. Gẹgẹ bi alufa, Kristi wa pẹlu Baba bayii lori itẹ Rẹ. Ifihan 3:21. Ẹni ti o “fi ara da ẹdun wa, ti o gbe ibinujẹ wa,” ti “a danwo ninu ohun gbogbo gẹgẹ bi tiwa, sibẹ ti O wa ni ailẹṣẹ” ki o baa le “ran awọn ti a n danwo lọwọ” O wa ni ori itẹ pẹlu Ẹni ayeraye, Ẹni ti a ko da. “Bi ẹnikẹni ba dẹṣẹ, a ni alagbawi kan pẹlu Baba.” Aisaya 53:4; Heberu 4:15; 2:18; 1 Johanu 2:1. Ẹbẹ Re ni ara ti a gún, ti a fọ, igbesi aye ti ko ni abawọn. Ọwọ ti a ṣa lọgbẹ, ẹgbẹ ti a gun loko, ẹsẹ ti a bajẹ n bẹbẹ fun eniyan ti o ṣubu, ti a ra irapada rẹ pẹlu ohun ti a ko le diye le.ANN 185.1

    “Imọran alaafia yoo si wa laarin Awọn mejeeji.” Ifẹ Baba, ti ko kere ni ọnakọna si ti Ọmọ ni orisun igbala fun iran ti o sọnu. Jesu sọ fun awọn ọmọ ẹyin Rẹ ki O ti lọ wipe: “Mi o sọ fun yin wipe maa bẹ Baba nitori yin: nitori ti Baba funra Rẹ fẹran yin.” Johanu 16:26, 27. Ọlọrun wa “ninu Kristi, O n ba araye laja pẹlu ara Rẹ.” 2 Kọrintin 5:19. Ninu iṣẹ iranṣẹ ninu ibi mimọ ti oke, “imọran alaafia yoo wa laarin awọn mejeeji.” “Ọlọrun fẹ araye to bẹẹ gẹẹ, ti O fi Ọmọ bibi Rẹ kan ṣoṣo funni, pe ẹnikẹni ti o ba gbagbọ ninu Rẹ ko ni ṣegbe, ṣugbọn yoo ni iye ainipẹkun.” Johanu 3:16.ANN 185.2

    A dahun ibeere, Kini ibi mimọ? ninu Bibeli ni ọna ti o han kedere. Ọrọ ti a pe ni “ibi mimọ,” bi a ti lo o ninu Bibeli tọka si, ni akọkọ agọ ti Mose pa, gẹgẹ bi aworan ohun ti ọrun; ni ẹẹkeji, si “agọ tootọ” ni ọrun, eyi ti ibi mimọ ti aye n tọka si. Nigba ti Jesu ku isin ti o n tọka si eyi ti n bọ pari. “Ibi mimọ tootọ” ni ọrun ni ibi mimọ ti majẹmu tuntun. Bi asọtẹlẹ Daniẹli 8:14 ti wa si imuṣẹ ni akoko ti wa yii, ibi mimọ ti o n tọka si nilati jẹ ibi mimọ ti majẹmu tuntun. Ni opin 2300 ọjọ, ni 1844, ko si ibi mimọ ni aye fun ọpọlọpọ ọdun. Bayii, asọtẹlẹ “Titi fi di 2300 ọjọ; nigba naa ni a o ṣe iwẹnumọ ibi mimọ,” laiṣe aniani n tọka si ibi mimọ ti ọrun.ANN 185.3

    Ṣugbọn a koi ti i dahun ibeere ti o ṣe pataki julọ: Kini ṣiṣe iwẹnumọ ibi mimọ? Isin kan wa ninu ibi mimọ ti aye ti a ṣe alaye rẹ ninu Iwe Mimọ Majẹmu Laelae. Ṣugbọn ṣe ohunkohun wà ni ọrun lati fọ mọ bi? Ninu Heberu 9, a ṣe ikọni nipa fifọ ibi mimọ ti aye ati ti ọrun mọ ni ọna ti o han kedere. “O si fẹrẹ jẹ wipe ohun gbogbo ni a fi ẹjẹ wẹ mọ nipa ofin; ati laisi itajẹ silẹ ko si idariji fun ẹṣẹ. Nitori naa o di dandan ki a fi iwọnyi [ẹjẹ ẹranko] wẹ apẹẹrẹ awọn ohun ti n bẹ ni ọrun mọ; ṣugbọn awọn ohun ti ọrun funra wọn pẹlu ẹbọ ti o dara ju iwọnyi lọ” (Heberu 9:22, 23), ani ẹjẹ Kristi ti o ṣe iyebiye.ANN 185.4

    A nilati ṣe ifọmọ, ni ti apẹẹrẹ ati ti ojulowo isin naa pẹlu ẹjẹ: ni titi akọkọ pẹlu ẹjẹ ẹranko, ni ti ti ikẹyin pẹlu ẹjẹ Kristi. Pọlu sọ gẹgẹ bi idi ti a nilati fi ṣe iwẹnumọ yii pẹlu ẹjẹ pe, laisi itajẹsilẹ ko si idariji fun ẹṣẹ. Idariji tabi mimu ẹṣẹ kuro, ni iṣẹ ti a nilati ṣe. Ṣugbọn kini ni ẹṣẹ ṣe nii ṣe pẹlu ibi mimọ, boya ni ọrun tabi lori ilẹ aye? A le kọ eyi nipa wiwo isin ti ṣe apẹẹrẹ; nitori alufa ti n ṣe isin ni aye jọsin gẹgẹ bi “apẹẹrẹ ati ojiji si awọn ohun ti ọrun.” Heberu 8:5.ANN 185.5

    Iṣẹ iranṣẹ ibi mimọ ni aye wa ni abala meji; awọn alufa ti wọn n ṣe isin ojoojumọ ni ibi mimọ, nigba ti olu alufa n ṣe iṣẹ pataki iwẹnumọ ẹṣẹ ni ẹẹkan lọdun ninu ibi mimọ julọ, fun afọmọ ibi mimọ. Lojoojumọ, ẹlẹṣẹ ti o ba ronupiwada n mu ọrẹ rẹ wa si ẹnu ọna agọ, yoo gbe ọwọ rẹ le ori ohun irubọ ti ko lẹṣẹ. A yoo wa pa ẹranko naa.ANN 185.6

    “Laisi itajẹsilẹ,” apostoli naa sọ wipe ko si idariji fun ẹṣẹ. “Ẹmi ẹran ara wa ninu ẹjẹ.” Lefitiku 17:11. Ofin Ọlọrun ti a ru nilo ẹmi arufin. Ẹjẹ, ti o duro fun ẹmi ti ẹlẹṣẹ padanu, ẹni ti ohun irubọ n ru ẹbi rẹ, ni alufa a gbe lọ si ibi mimọ ti yoo si wọn siwaju aṣọ ikele eyi ti o bo apoti ti ofin, ti ẹlẹṣẹ ru wa ninu rẹ. Nipasẹ isin yii, nipasẹ ẹjẹ, ni ọna apẹẹrẹ, a ti gbe ẹṣẹ naa lọ sinu ibi mimọ. Ni igba miran, a ko ni gbe ẹjẹ naa lọ si ibi mimọ; ṣugbọn alufa ni yoo jẹ ẹran naa, gẹgẹ bi Mose ti dari awọn ọmọ Aroni wipe: “Ọlọrun ti fifun yin lati ru ẹṣẹ ijọ.” Lefitiku 10:17. Awọn isin mejeeji tumọ si gbigbe ẹṣẹ lati ọdọ ẹlẹṣẹ wa sinu ibi mimọ.ANN 185.7

    Iru awọn iṣẹ ti n lọ lojoojumọ, jalẹ ọdun niyii. Bayii ni a ṣe n gbe awọn ẹṣẹ Israeli lọ si ibi mimọ, a wa nilo iṣẹ pataki lati mu wọn kuro. Ọlọrun paṣẹ ki a ṣe iwẹnumọ ẹṣẹ fun abala mimọ mejeeji. “Yoo ṣe iwẹnumọ fun ibi mimọ, nitori aimọ awọn ọmọ Israeli, ati nitori irekọja wọn ni gbogbo ẹṣẹ wọn: bakan naa ni yoo ṣe fun agọ ajọ, ti o wa laarin wọn ninu aimọ wọn.” A nilati ṣe iwẹnumọ fun pẹpẹ lati “fọ ọ mọ, ati lati ya a si mimọ kuro ninu aimọ awọn ọmọ Israeli.” Lefitiku 16:16, 19.ANN 186.1

    Ni ẹẹkan lọdun, ni Ọjọ nla Iwẹnumọ, alufa a wọ inu ibi mimọ julọ fun ifọmọ ibi mimọ. Iṣẹ ti a ṣe nibẹ pari iṣẹ isin jalẹ ọdun naa. Ni Ọjọ Iwẹnumọ, a o mu ewurẹ meji wa si ẹnu ọna agọ, a o si ṣẹ gègé le wọn, “gege kan fun Oluwa, ati ekeji fun ẹran ìyà.” Ẹsẹ 8. A o pa ẹran tí gege Ọlọrun ṣẹ le lori gẹgẹ bi ẹbọ ẹṣẹ fun awọn eniyan. Alufa a si mu ẹjẹ rẹ wa sinu aṣọ ìkélé, yoo si wọn si ori itẹ aanu ati siwaju itẹ aanu. A yoo wọn ẹjẹ naa si ori pẹpẹ turari ti o wa niwaju aṣọ ikele.ANN 186.2

    “Aroni yoo si gbe ọwọ rẹ mejeeji le ori ewurẹ ti o wa laaye, yoo si jẹwọ gbogbo aiṣedeede awọn ọmọ Israeli, ati gbogbo irekọja wọn ninu gbogbo ẹṣẹ wọn, yoo gbe ori ewurẹ naa, yoo si ran lọ sinu aginju lati ọwọ ẹni ti o yẹ: ewurẹ naa yoo ru gbogbo irekọja wọn lọ si ilẹ ti a ko tẹdo.” Ẹsẹ 21, 22. Ẹran iya naa ko ni wọ agọ awọn ọmọ Israeli mọ lae, ẹni ti o mu u jade yoo wẹ ara rẹ pẹlu omi ki o to wọ inu agọ ijọ.ANN 186.3

    A ṣe gbogbo eto naa lati le jẹ ki awọn ọmọ Israeli mọ bi Ọlọrun ti jẹ mimọ to ati bi O ti korira ẹṣẹ to; ati lati fihan wọn wipe wọn ko le fi ara kan ẹṣẹ laidi alaimọ. Gbogbo eniyan ni o pan dandan fun lati jẹ ọkan wọn niya nigba ti iṣẹ iwẹnumọ ba n lọ lọwọ. A o pa gbogbo iṣẹ tì, ti gbogbo ijọ Israeli yoo lo ọjọ naa ni irẹra-ẹni-silẹ niwaju Ọlọrun pẹlu adura ati awẹ ati yiyẹ ọkan ẹni wo finifini.ANN 186.4

    Iṣẹ apẹẹrẹ yii kọni ni awọn otitọ pataki nipa iwẹnumọ ẹṣẹ. A gba ohun miran ni ipo ẹlẹṣẹ; ṣugbọn ẹjẹ ohun irubọ ko pa ẹṣẹ naa rẹ. A pese ọna miran silẹ ti a o fi gbe wá sinu ibi mimọ. Nipa mimu ẹjẹ naa wa ẹlẹṣẹ gba aṣẹ ofin, o jẹwọ ẹbi rẹ ni riru ofin, o fi ifẹ rẹ han fun idariji nipa igbagbọ ninu Olurapada ti n bọ wa; ṣugbọn a ko yọ ọ silẹ patapata kuro ninu idalẹbi ofin. Ni Ọjọ Iwẹnumọ olu alufa, lẹyin ti o ba ti gba ọrẹ lati ọdọ ijọ, wọ inu ibi mimọ julọ pẹlu ẹjẹ ọrẹ yii, yoo sì wọn si ori itẹ aanu, taara sori ofin, lati le tẹ ẹtọ rẹ lọrun. Nigba naa, ninu ojuṣe rẹ gẹgẹ bi olugbala, yoo gbe awọn ẹṣẹ naa si ori ara rẹ, yoo si gbe kuro ninu ibi mimọ. Yoo gbe ọwọ rẹ mejeeji sori ẹran iya naa, yoo jẹwọ gbogbo ẹṣẹ wọnyi le lori, ni bayi ni ọna apẹẹrẹ, o n gbe ẹṣẹ naa si ori ewurẹ lati ọdọ ara rẹ. Ewurẹ naa a wa ko wọn lọ, a wa gba wipe a ti pin wọn niya pẹlu awọn eniyan naa titi lae.ANN 186.5

    Iru eto ti a n ṣe “gẹgẹ bi apẹẹrẹ ati ojiji awọn ohun ti ọrun” niyi. Ohun ti a ṣe bi apẹẹrẹ ninu isin ibi mimọ ni aye ni a ṣe nitootọ ninu isin ni ibi mimọ ti ọrun. Lẹyin ti O goke re ọrun Olugbala wa bẹẹrẹ iṣẹ Rẹ gẹgẹ bi olu alufa wa. Pọlu sọ wipe: “Kristi ko wọ awọn ibi mimọ ti a fi ọwọ kọ, eyi ti i ṣe apẹẹrẹ ti otitọ, ṣugbọn sinu ọrun funra rẹ, bayi lati fi ara han niwaju Ọlọrun fun wa.” Heberu 9:24.ANN 186.6

    Iṣẹ iranṣẹ alufa yipo ọdun nì abala akọkọ ní ibi mimọ, “ninu aṣọ ikele” eyi ti o jẹ ilẹkun ti o pin ibi mimọ niya pẹlu agbala ita, duro fun iṣẹ iranṣẹ ti Kristi bẹẹrẹ ni igba ti O goke re ọrun. Iṣẹ alufa ni iṣẹ iranṣẹ ojoojumọ lati mu ẹjẹ ọrẹ ẹbọ wa siwaju Ọlọrun, ati turari ti o n goke pẹlu adura Israeli. Bẹẹ gẹgẹ ni Kristi n bẹbẹ ẹjẹ Rẹ niwaju Baba nitori ẹlẹṣẹ, ti O tun n gbe adura awọn onigbagbọ ti wọn ronupiwada wa siwaju Rẹ, pẹlu oorun didun ti o ṣeyebiye ti ododo Rẹ. Iru iṣẹ iranṣẹ ti o n lọ ninu abala akọkọ ninu ibi mimọ ni ọrun niyi.ANN 186.7

    Nibẹ ni igbagbọ awọn ọmọ ẹyin tẹle lọ bi O ti n goke kuro ni oju wọn. Nibi ni ireti wọn wa, “ireti ti awa ni” Pọlu sọ pe “gẹgẹ bi idakọro fun ọkan, ti o daju ti o si duro gbọin, ati eyi ti o wọ inu aṣọ ikele, nibi ti aṣaju wa wọ lọ fun wa, ani Jesu, ti O di olu alufa titi lae.” “Ki i ṣe pẹlu ẹjẹ ewurẹ tabi ọmọ malu, ṣugbọn pẹlu ẹjẹ ara Rẹ ni o wọ lẹẹkan ṣoṣo, lọ sinu ibi mimọ, lẹyin ti O ti gba irapada ainipẹkun fun wa.” Heberu 6:19; 9:12.ANN 186.8

    Fun 1800 ọdun iṣẹ iranṣẹ yii tẹsiwaju ninu abala akọkọ ninu ibi mimọ. Ẹjẹ Kristi n bẹbẹ fun ẹlẹṣẹ, o jẹ ki wọn ri idariji ati itẹwọgba pẹlu Baba, sibẹ ẹṣẹ wọn si wa ninu iwe akọsilẹ. Gẹgẹ bi o ti wa ninu isin ti apẹẹrẹ, iṣẹ iwẹnumọ maa n wa ni opin ọdun, bẹẹ gẹgẹ ni kí iṣẹ Kristi fun irapada eniyan to pari, a yoo ṣe iṣẹ iwẹnumọ fun imukuro ẹṣẹ kuro ninu ibi mimọ. Eyi ni eto ti o bẹrẹ nigba ti 2300 ọjọ pari. Ni igba naa, bi Daniẹli ti sọ ọ tẹlẹ, Olu Alufa wa wọ ibi mimọ julọ, lati ṣe abala ti o kẹyin ninu iṣẹ pataki Rẹ—lati ṣe iwẹnumọ ibi mimọ.ANN 187.1

    Gẹgẹ bi a ti n ṣe ni igba atijọ ti a n gbe ẹṣẹ awọn eniyan sori ẹbọ ẹṣẹ pẹlu igbagbọ ati nipasẹ ẹjẹ rẹ ti a n gbe, ní àmì, si ara ibi mimọ, bakan naa ninu majẹmu tuntun ẹṣẹ awọn ti wọn ba ronupiwada ni a gbe si ara Kristi nipa igbagbọ, ani ti a tun gba si ara ibi mimọ ti ọrun. Ati bi a ti n kasẹ ifọmọ ti ami nilẹ pẹlu imukuro ẹṣẹ ti wọn ba a jẹ, bẹẹ gẹgẹ ni ifọmọ tootọ ti ọrun yoo kasẹ nilẹ pẹlu imukuro, tabi pipa awọn ẹṣẹ ti a kọ silẹ nibẹ rẹ. Ṣugbọn ki a to le ṣe eyi, a nilati ṣe ayẹwo awọn iwe ti a kọ silẹ lati le mọ ẹni ti o yẹ fun anfani iwẹnumọ nipasẹ ironupiwada ẹṣẹ ati igbagbọ ninu Kristi. Fifọ ibi mimọ mọ, nitori naa ni i ṣe pẹlu iṣẹ iyẹwewo—iṣẹ idajọ. A nilati ṣe eyi ki Kristi to wá lati ra awọn eniyan Rẹ pada; nitori nigba ti O ba de, èrè Rẹ yoo wa pẹlu Rẹ lati fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ. Ifihan 22:12.ANN 187.2

    Ni bayii awọn ti wọn rin ninu imọlẹ ọrọ isọtẹlẹ ri wipe, dipo ki O wa si aye ni opin 2300 ọjọ ni 1844, nigba naa ni Kristi wọ inu ibi mimọ julọ ni ibi mimọ ti ọrun lati ṣe iṣẹ aṣekagba ti iwẹnumọ ni imurasilẹ fun wiwa Rẹ.ANN 187.3

    A tun ri wipe, nigba ti ọrẹ ẹṣẹ tọka si Kristi gẹgẹ bi ẹbọ, ti olu alufa si duro fun Kristi gẹgẹ bi olugbala, ẹran iya duro fun Satani, ati olupilese ẹṣẹ, lori ẹni ti a yoo ko ẹṣẹ awọn ti wọn ronupiwada nitootọ le lori nikẹyin. Nigba ti olu alufa nipasẹ agbara ọrẹ ẹṣẹ ba gbe ẹṣẹ kuro ninu ibi mimọ, a gbe si ori ẹran iya. Nigba ti Kristi, nipasẹ agbara ẹjẹ Rẹ, ba mu ẹṣẹ awọn eniyan Rẹ kuro ninu ibi mimọ ti ọrun ni opin iṣẹ iranṣẹ Rẹ, yoo ko wọn sori Satani, ẹni ti yoo jẹbi wọn nikẹyin ni igba idajọ. A ran ẹran iya lọ si ilẹ ti a ko tẹdo, ti ko si ni pada si ajọ Israeli mọ lae. Bẹẹ gẹgẹ ni a yoo le Satani kuro niwaju Ọlọrun ati awọn eniyan Rẹ, ki yoo sì sí mọ ni igba iparun ikẹyin fun ẹṣẹ ati awọn ẹlẹṣẹ.ANN 187.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents