Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KẸTADINLỌGBỌN—ISỌJI TI ODE ONI

    Ni ibikibi ti a ba ti fi otitọ waasu ọrọ Ọlọrun, o maa n ni abajade ti yoo jẹri si wipe ọdọ Ọlọrun ni o ti wa. Ẹmi Ọlọrun maa n tẹle iṣẹ iranṣẹ awọn iranṣẹ Rẹ, ọrọ naa si maa n ni agbara. Awọn ẹlẹṣẹ a ri ti ẹri ọkan wọn taji. “Imọlẹ ti o n tan si gbogbo eniyan ti o wa ninu aye” tan si ibi kọlọfin ọkan wọn, awọn ohun ikọkọ ti okunkun si farahan. Wọn ni idalẹbi ti o jinlẹ ninu ọkan ati iye wọn. Wọn ni idalẹbi ẹṣẹ ati ododo ati ti idajọ ti n bọ. Wọn ni oye ododo Jehofa, ẹru si ba wọn lati fi ara han niwaju Oluyẹ-ọkan-wo ninu ẹbi ati aimọ wọn. Ninu irora ọkan wọn, wọn kigbe sita: “Tani yoo gba mi lọwọ ara iku yii?” Bi agbelebu Kalfari, pẹlu ẹbọ ayeraye rẹ fun ẹṣẹ eniyan ti farahan, wọn ri wipe ko si ohunkohun ayafi oore ọfẹ Kristi nikan ni o le ṣe etutu fun irekọja wọn; eyi nikan ni o le ba eniyan laja pẹlu Ọlọrun. Pẹlu igbagbọ ati irẹlẹ, wọn tẹwọgba Ọdọ Aguntan Ọlọrun, ti O ko ẹṣẹ araye lọ. Nipasẹ ẹjẹ Jesu wọn ni “imukuro awọn ẹṣẹ ti wọn ti koja.”ANN 205.1

    Awọn ọkan wọnyi so eso ti o wa ni ibamu pẹlu ironupiwada. Wọn gbagbọ, a ṣe itẹbọmi fun wọn, wọn si dide lati rin ninu igbe aye ọtun—ẹda tuntun ninu Kristi Jesu, ki i ṣe lati rin gẹgẹ bi ifẹkufẹ ara ti atẹyinwa, ṣugbọn nipa igbagbọ Ọmọ Ọlọrun lati tẹle igbesẹ Rẹ, lati fi iwa Rẹ han ati lati sọ ara wọn di mimọ gẹgẹ bi O ti jẹ mimọ. Wọn wa fẹran awọn ohun ti wọn korira tẹlẹ, wọn si korira awọn ohun ti wọn fẹran nigbakan ri. Agberaga ati afunnu di onirẹlẹ ati ọlọkan tutu. Olufẹ asan ati ẹni to jọ ara re loju di ẹni ti n ronu ati oniwapẹlẹ. Alaimọ di ẹni ti n bọwọ fun nnkan. Ọmuti di ẹni ti ara rẹ balẹ, onifẹkufẹ di ẹni mimọ. Wọn gbe iṣeraenilọṣọ asan aye tì si ẹgbẹ kan. Awọn Kristẹni ko wa “ọṣọ ode ti irun didi, ati ti wiwọ wura tabi wiwọ aṣọ; . . . ṣugbọn ọkunrin ti o pamọ ni ọkan, eyi ti ko le dibajẹ, ani ohun ọṣọ ti ẹmi idakẹjẹ ati irẹlẹ ti o ṣeyebiye niwaju Ọlọrun.” 2 Peteru 3:3, 4.ANN 205.2

    Isọji mu iyè-ọkàn ti n wo finifini ati irẹlẹ wa. Wọn n ṣe ipẹ atọkanwa ti o lọwọ fun ẹlẹṣẹ, nipa kikede aanu fun ẹni ti Kristi fi ẹjẹ Rẹ ra. Awọn ọkunrin ati obinrin gbadura, wọn ba Ọlọrun jijakadi fun igbala ọkan. A n ri eso iru isọji yii ninu ọkan ti wọn ko sa fun isẹra-ẹni ati ifiara-ẹni-rubọ, ṣugbọn ti inu wọn dun wipe a ka wọn yẹ lati le jiya ẹgan ati idanwo nitori Kristi. Awọn eniyan ri iyipada ninu igbesi aye awọn ti wọn n pe orukọ Jesu. Awujọ ri ibukun nitori iṣesi wọn. Wọn n kojọ pọ pẹlu Kristi, wọn n gbin si ti Ẹmi lati le kore iye ainipẹkun.ANN 205.3

    A le sọ nipa wọn wipe: “Ẹyin banujẹ si ironupiwada.” “Nitori ibanujẹ ti iwabiọlọrun n ṣiṣẹ ironupwiada si igbala ti a ki yoo kabamọ rẹ: ṣugbọn ibanujẹ ti aye n ṣiṣẹ iku. Kiyesi ohun kan yii, wipe ẹyin banujẹ ni ọna ti Ọlọrun, iru iṣọra wo ni o mu wa ninu yin, bẹẹ ni, iru ibinu wo, bẹẹ ni, iru ibẹru wo, bẹẹ ni, iru igbonara wo, bẹẹ ni, iru itara wo, bẹẹ ni, iru igbẹsan wo! Ninu ohun gbogbo ẹ fi han wipe ẹ mọ ninu ọrọ naa.” 2 Kọrintin 7:9—11.ANN 205.4

    Eyi jẹ abayọri iṣẹ Ẹmi Ọlọrun. Ko si ẹri fun ironupiwada tootọ ayafi ti o ba ṣe iṣẹ atunṣe. Bi o ba da ẹjẹ pada, bi o ba da ohun gbogbo ti o ba jí pada, bi o ba jẹwọ ẹṣẹ rẹ, ti o fẹran Ọlọrun ati eniyan ẹlẹgbẹ rẹ, o nilati da ẹlẹṣẹ loju wipe yoo ni alaafia pẹlu Ọlọrun. Iru awọn ohun ti wọn maa n tẹle akoko isọji ẹsin ni aye atijọ ni eyi. Bi a ba ti ibi eso wọn wo o, o fihan wipe wọn jẹ alabukunfun Ọlọrun ninu igbala eniyan ati gbigbé iran eniyan soke.ANN 205.5

    Ṣugbọn ọpọ isọji aye ode oni fi iyatọ ti o han kedere han si awọn ifihan oore ọfẹ ọrun eyi ti o tẹle iṣẹ awọn iranṣẹ Ọlọrun ni igba atẹyinwa. O jẹ otitọ wipe ifẹ awọn eniyan n pọ si, ọpọlọpọ ni wọn n sọ wipe wọn ti yipada, ọgọọrọ awọn eniyan ni wọn si n lọ si ile ijọsin; sibẹ ayọrisi wọn ko le jẹ ki a gbagbọ wipe idagbasoke wa ninu igbesi aye ẹmi ni tootọ. Ina ti o ru soke fun igba diẹ yoo ku laipẹ, ti okunkun ti yoo tẹle a wa dudu ju ti iṣaaju lọ.ANN 205.6

    A saba maa n ṣe awọn isọji ti wọn wọpọ ni ode oni lati tẹ ero eniyan lọrun, lati ru ẹmi ọkan wọn soke, lati tẹ ifẹ fun ohun tuntun ti o tun muni tagìrì lọrun. Awọn ọkan ti a ba jere ni ọna yii a ni ifẹ kinkini fun otitọ Bibeli, ifẹ kekere si ẹri awọn woli ati apostoli. Bi ijọsin ko ba dabi eyi ti yoo ru ifẹ wọn soke, wọn ko ni fẹ ni ifẹ si. Wọn ko ni ji giri si iṣẹ iranṣẹ ti o ba nilo ironu ti o jinlẹ. Wọn ko ni tẹti si ikilọ ọrọ Ọlọrun ti o ni i ṣe pẹlu ohun iye ainipẹkun.ANN 206.1

    Ẹnikẹni ti o ba yipada lootọ, ibaṣepọ pẹlu Ọlọrun ati si ohun iye ainipẹkun ni yoo jẹ koko ọrọ ti o tobi julọ ninu igbesi aye rẹ. Nibo ni ẹmi ifara-ẹni jin fun Ọlọrun wa ninu awọn ijọ ti wọn gbajugbaja loni? Awọn ti a jere ọkan wọn ko kọ igberaga wọn ati ifẹ aye silẹ. Wọn ko fẹ lati sẹ ara wọn, lati gbe agbelebu, ati lati tẹle Jesu onirẹlẹ, ọlọkan tutu, ju bi wọn ti fẹ ki wọn to ronupiwada lọ. Ẹsin di ohun amuṣere fun awọn alaimọlọrun ati alaigbagbọ nitori pe ọpọ awọn ti n jẹ orukẹ rẹ jẹ alaimọkan nipa ẹkọ rẹ. Agbara iwabiọlọrun ti fi ọpọlọpọ ijọ silẹ. Ajọyọ, eré ìtàgé ni ile Ọlọrun, itaja ni ile Ọlọrun, ile ti o rẹwa, ifi ara ẹni han ti lé ero nipa Ọlọrun sẹyin. Ilé ati ọrọ, ati iṣẹ aye ti kun inu ọkan titi ti awọn ohun ti wọn ni i ṣe pẹlu iye ainipẹkun ko fi ni ni akiyesi ti o yẹ.ANN 206.2

    Laika bi igbagbọ ati ifọkansin ti n rẹwẹsi kaakiri si, awọn atẹle Kristi tootọ ṣi wa ninu awọn ijọ wọnyii. Ki Ọlọrun to bẹ aye yii wo pẹlu idajọ ti o kẹyin, isọji iwabiọlọrun yoo wa laarin awọn eniyan Ọlọrun ni ọna ti a koi tii riri lati igba awọn apostoli wá. A o tu Ẹmi ati agbara Ọlọrun si ori awọn eniyan Rẹ. Ni igba naa, ọpọlọpọ ni yoo ya ara wọn sọtọ kuro ninu awọn ijọ wọnyi ti ifẹ aye yii ti rọpo ifẹ Ọlọrun ati otitọ Rẹ ninu ọkan wọn. Ọpọlọpọ, ati alufa ati awọn eniyan ni yoo fi tayọtayọ gba awọn otitọ nla wọnni ti Ọlọrun jẹ ki a waasu wọn ni akoko yii lati pese awọn eniyan kan silẹ fun wiwa Oluwa lẹẹkeji. Ọta awọn eniyan fẹ lati di iṣẹ yii lọwọ; ki akoko iru ẹgbẹ yii to de, yoo ṣe akitiyan lati di i lọwọ nipa mimu ayédèrú wá. Ninu awọn ijọ wọnyẹn ti o le ko si abẹ agbara itanjẹ rẹ yoo jẹ ki o dabi ẹnipe a tu ibukun Ọlọrun pataki sita; a yoo ri ohun ti a le pe ni ifẹ nla si ọrọ ẹsin. Ọpọlọpọ ni yoo yọ wipe Ọlọrun n ṣe iṣẹ pẹlu iyanu ni aarin wọn, nigba ti iṣẹ naa jẹ ti ẹmi miran. Labẹ aworan ẹsin, Satani yoo wa ọna lati na agbara rẹ si ori awọn Kristẹni.ANN 206.3

    Ninu ọpọlọpọ awọn isọji to ṣẹlẹ laarin aadọta ọdun sẹyin, ipa kan naa ni o n ṣiṣẹ, ni ọna ti o kere tabi ti o pọ, eyi a si tubọ fi ara han si ninu awọn ẹgbẹ ti yoo farahan ni ọjọ iwaju. A ri iru irusoke ifẹ ọkan, dida otitọ papọ mọ irọ, eyi ti a ṣe daradara lati sini lọna. Sibẹ ko si ẹnikẹni ti o nilo lati di ẹni itanjẹ. Ninu imọlẹ ọrọ Ọlọrun, ko nira lati da ohun ti awọn ẹgbẹ yii jẹ mọ. Nibikibi ti awọn eniyan ba ti kọ ẹri Bibeli silẹ, ti wọn yipada kuro ninu otitọ ti o farahan kedere, ti n dan ọkan wo, eyi ti o nilo isẹra ẹni ati kikọ aye silẹ, o yẹ ki a mọ daju wipe Ọlọrun ko le rọ ojo ibukun Rẹ sibẹ. Pẹlu odiwọn ti Kristi funra Rẹ fifunni, “Ẹyin yoo mọ wọn nipa eso wọn” (Matiu 7:16), o han kedere wipe awọn ẹgbẹ wọnyi kii ṣe iṣẹ Ẹmi Ọlọrun.ANN 206.4

    Ninu otitọ ọrọ Rẹ, Ọlọrun ti fun eniyan ni ifihan ara Rẹ; fun gbogbo awọn ti wọn ba si fẹ gba a, o jẹ aabo kuro lọwọ itanjẹ Satani, kikọ awọn otitọ yii silẹ ni o ṣi ilẹkun fun awọn iwa ẹṣẹ ti wọn wa n tankalẹ ninu ẹsin bayii. A ti gbagbe ohun ti ofin Ọlọrun jẹ ati bi o ti ṣe pataki to lọna pupọ. Ero ti ko tọna nipa ohun ti ofin jẹ, bi o ti wa titi lae, ati ojuṣe eniyan si ofin mimọ ni o fa aṣiṣe ninu ibaṣepọ wọn pẹlu iyipada ati isọdimimọ, ohun si ni o fa fifa odiwọn ifọkansin wa sisalẹ ninu awọn ile ijọsin. Nibi ni a ti ri aṣiri ohun ti o fa a ti a ko fi ri Ẹmi ati agbara Ọlọrun ninu awọn isọji akoko yii.ANN 206.5

    Ni ọpọlọpọ awọn oriṣiriṣi ijọ, awọn eniyan ti wọn di olokiki nitori ifọkansin wọn ni wọn kiyesi eyi ti wọn si kaanu nitori rẹ. Ọjọgbọn Edwards A. Park, nigba ti o n sọ nipa idamu ẹsin ti o wa ninu rẹ lọwọlọwọ sọ pe: “Ọkan ninu awọn orisun ewu naa ni fifi ori pẹpẹ iwaasu silẹ lati lọ fi ipa muni lati gba ofin Ọlọrun. Ni aye atijọ ori pẹpẹ iwaasu jẹ ìró ohùn ẹri ọkan. . . . Awọn oniwaasu olokiki wa n ṣe iwaasu wọn lọjọ nipa titẹle apẹẹrẹ Oluwa, wọn si n gbe ofin ati ilana rẹ, ati ikilọ rẹ ga. Wọn ṣe atunsọ ọrọ meji nla nì, wipe ofin jẹ akọsilẹ iwa pipe Ọlọrun, ati pe ẹnikẹni ti ko ba fẹran ofin ko fẹran iyinrere; nitori ofin ati iyinrere jẹ digi ti o fi bi Ọlọrun ti jẹ nitootọ han. Ewu yii yọri si omiran, ti airi ẹṣẹ ni bi o ti buru to, bi ipa rẹ ti lọ to, ati abuku rẹ. Bi ofin ba ti se tọna to, bẹẹ ni ṣiṣe aigbọran si ti buru to. . . .ANN 206.6

    “Eyi ti o sunmọ ewu ti a darukọ rẹ tan ni ewu fifi oju tinrin idajọ Ọlọrun. Iwa ti o wọpọ lori pẹpẹ iwaasu iwoyi lati ya idajọ Ọlọrun sọtọ pẹlu aanu Ọlọrun, sọ aanu di ifẹ ọkan lasan dipo ki o gbe e ga gẹgẹ bi ipilẹ ẹkọ ti n muni wùwà. Iṣọwọ-ṣẹtumọ ọrọ Ọlọrun ni ode oni pin ohun ti Ọlọrun ti sopọ niya. Ṣe ofin Ọlọrun jẹ ohun ti o dara abi ohun ti o buru? O jẹ ohun ti o dara. Nitori naa idajọ dara; nitori ti o jẹ ifẹ lati mu ofin ṣe. Lati inu iwa lati maa yẹpẹrẹ ofin ati idajọ Ọlọrun, ewu ti o wa ninu aigbọran eniyan ati bi ipa rẹ ti pọ to, awọn eniyan dede n wu iwa fifi oju tinrin oore ọfẹ ti o pese iwẹnumọ fun ẹṣẹ.” Pẹlu eleyi oore ọfẹ padanu iyi ati bi o ti ṣe pataki to ninu iye awọn eniyan, laipẹ laijina wọn ṣetan lati ti Bibeli funra rẹ si ẹgbẹ kan.ANN 207.1

    Ọpọ awọn olukọ ẹsin loni n sọ wipe Kristi pa ofin rẹ nipasẹ iku Rẹ, nitori naa a ko nilo lati pa a mọ. Awọn kan wa ti wọn fi han gẹgẹ bi eru wuwo, wọn si ṣe agbekalẹ ominira ti wọn n jẹgbadun rẹ ni iyatọ si imunisin ofin.ANN 207.2

    Ṣugbọn ki i ṣe bi awọn woli ati awọn apostoli ṣe ri ofin Ọlọrun niyi. Dafidi wipe: “Emi a rin ni ominira: nitori ti mo wá ilana Rẹ.” O. Dafidi 119:45. Apostoli Jakọbu, ẹni ti o kọwe lẹyin iku Kristi, pe Ofin Mẹwa ni “olu ofin” ati “ofin ominira ti o pe.” Jakọbu 2:8; 1:25. Olufihan, ni aadọta ọdun lẹyin ti a kan Jesu mọ agbelebu kede ibukun si ori awọn “ti wọn pa ofin Rẹ mọ, ki wọn le ni ẹtọ si igi iye, ki wọn baa si le gba ẹnu ọna ilu naa wọle.” Ifihan 22:14.ANN 207.3

    Sisọ wipe Kristi pa ofin Baba Rẹ run nipasẹ iku Rẹ ko fẹsẹ mulẹ. Bi o ba jẹ wipe o ṣe e ṣe ki a yi ofin pada tabi ki a kọ ọ silẹ ni, ko ni nilo ki Kristi ku lati gba eniyan la kuro ninu ẹbi ẹṣẹ. Iku Kristi, dipo ki o pa ofin run, fihan wipe ko ṣe e parun ni. Ọmọ Ọlọrun wá lati wa “gbe ofin ga ki O si mu ki o niyi.” Aisaya 42:21. O sọ pe: “Maṣe ro wipe Mo wa lati pa ofin run;” “titi ti ọrun ati aye yoo fi kọja lọ, kinkini ninu ofin ki yoo kọja lọ.” Matiu 5:17, 18. O sọ nipa ara Rẹ wipe: “Mo ni inu didun lati ṣe ifẹ Rẹ, Ọlọrun Mi: bẹẹ ni, ofin Rẹ wa ninu ọkan Mi.” O. Dafidi 40:8.ANN 207.4

    Gẹgẹ bi ofin ti wa gan an, ko se e yipada. O jẹ ifihan ifẹ ati iwa Ẹni ti o kọ ọ. Ọlọrun jẹ ifẹ, ofin Rẹ si jẹ ifẹ pẹlu. Ipilẹ nla rẹ ni ifẹ si Ọlọrun ati ifẹ si eniyan. “Ifẹ ni akoja ofin.” Romu 13:10. Iwa Ọlọrun jẹ ododo ati otitọ; bi ofin Rẹ si ti jẹ niyii. OniO. Dafidi sọ wipe: “Otitọ ni ofin Rẹ;” “gbogbo aṣẹ Rẹ jẹ ododo.” O. Dafidi 119:142, 172. Apostoli Pọlu sọ wipe: “Bẹẹ si ni pe mimọ ni ofin, mimọ ni aṣe ati ododo ati didara.” Romu 7:12. Iru ofin yii ti i ṣe afihan ọkan ati ifẹ Ọlọrun nilati wa titi lae gẹgẹ bi Ẹni ti o kọ ọ.ANN 207.5

    Iṣẹ ironupiwada ati isọdimimọ ni lati ba eniyan laja pẹlu Ọlọrun nipa mimu wọn wà ni ibamu pẹlu ipilẹ ofin Rẹ. Ni atetekọṣe, a da eniyan ni aworan Ọlọrun. O wa ni irẹpọ pipe pẹlu ẹda ati ofin Ọlọrun; a kọ awọn ipilẹ ẹkọ ododo sinu ọkan rẹ. Ṣugbọn ẹṣẹ pin niya pẹlu Ẹlẹda rẹ. Ko le fi aworan Ọlọrun han mọ. Ọkan rẹ wọya ija pẹlu ẹkọ ofin Ọlọrun. “Ero ti ara wa ni iṣọta pẹlu Ọlọrun: nitori ki i ṣe gẹgẹ bi ofin Ọlọrun, oun ko tilẹ le ṣe e.” Romu 8:7. Ṣugbọn “Ọlọrun fẹran araye pupọpupọ ti o fi Ọmọ Rẹ kan ṣoṣo ti O bi funni” ki eniyan le ba Ọlọrun laja. Nipasẹ oore ọfẹ Kristi, a le da pada lati wà ni ibamu pẹlu Ẹlẹda rẹ. Oore ọfẹ ọrun nilati sọ ọkan rẹ di ọtun; o ni lati ni igbe aye tuntun lati oke wa. Iyipada yii ni a n pe ni atunbi, laisi rẹ, Jesu sọ wipe, “ko le ri ijọba Ọlọrun.”ANN 207.6

    Igbesẹ akọkọ ninu ibalaja pẹlu Ọlọrun ni nini ẹbi ẹṣẹ. “Ẹṣẹ ni riru ofin.” “Nipasẹ ofin ni a fi n ni imọ ẹṣẹ.” 1 Johanu 3:4; Romu 3:20. Lati le ri ẹbi rẹ, ẹlẹṣẹ nilati dan iwa rẹ wo pẹlu odiwọn ododo nla ti Ọlọrun. O jẹ digi ti i fi iwa ododo pipe han ti yoo si ran an lọwọ lati ri ibaku ninu tirẹ. Ofin fi ẹṣẹ eniyan han, ṣugbọn o funni ni atunṣe. Nigba ti o ṣeleri iye fun olugbọran, o kede wipe iku ni ipin olurekọja. Iyinrere Kristi nikan ni o le funni ni ominira kuro ninu idalẹbi tabi isọdi eeri ẹṣẹ. O nilati ni ironupiwada si ọdọ Ọlọrun, ofin Ẹni ti o ru; ati igbagbọ ninu Kristi, ẹbọ imukuro ẹṣẹ rẹ. Bayii ni o gba “imukuro ẹṣẹ ti o ti kọja” o si di alabapin iwa Ọlọrun. O di ọmọ Ọlọrun nigba ti o ba ti gba ẹmi isọdọmọ, nipa eyi ti o kigbe wipe: “Abba, Baba!”ANN 208.1

    Njẹ o wa wà ni ominira lati ru ofin Ọlọrun bi? Pọlu sọ wipe: “Njẹ a sọ ofin Ọlọrun di asan nipa igbagbọ bi? Ki a ma ri: ṣugbọn, a fi idi ofin mulẹ.” “Bawo ni awa ti a ti di oku si ẹṣẹ ṣe le maa gbe ninu rẹ?” Johanu sọ pẹlu: “Eyi ni ifẹ Ọlọrun, wipe ki a pa aṣẹ Rẹ mọ: awọn aṣẹ Rẹ ko si nira.” Romu 3:31; 6:2; 1 Johanu 5:3. Ninu atunbi a mu ọkan wà ni ibamu pẹlu Ọlọrun, bi a ti n mu wa ni ibamu pẹlu ofin Rẹ. Nigba ti ayipada nla yii ba ṣẹlẹ ninu ẹlẹṣẹ, o ti kọja lati inu iku lọ si iye, lati inu ẹṣẹ si iwa mimọ, lati riru ofin ati iṣọtẹ si igbọran ati iṣotitọ. Igbe aye atijọ ti iyapa kuro lọdọ Ọlọrun ti pari; igbe aye tuntun ti ibalaja, ti igbagbọ ati ifẹ ti bẹrẹ. Nigba naa ni “ododo ofin” yoo di mimuṣẹ ninu wa, awa ti ko rin gẹgẹ bi ohun ti ara, bikoṣe gẹgẹ bi ohun ti Ẹmi.” Romu 8:4. Èdè ọkan yoo si jẹ: “Ẹmi ti fẹ ofin Rẹ to! aṣaro mi ni ni gbogbo ọjọ.” O. Dafidi 119:97.ANN 208.2

    “Ofin Ọlọrun pe, o n yi ọkan pada.” O. Dafidi 19:7. Laisi ofin, eniyan ko ni oye iwa mimọ ati ailabawọn Ọlọrun tabi ẹbi ati idọti wọn. Wọn ko ni ẹbi tootọ fun ẹṣẹ ati idi fun ironupiwada. Lairi wipe wọn ti sọnu gẹgẹ bi arufin Ọlọrun, wọn ko ni ri wipe wọn nilo ẹjẹ Kristi ti n mu ẹṣẹ kuro. Wọn gba ireti igbala laisi iyipada patapata ninu ọkan tabi atunṣe igbesi aye. Idi niyi ti iyipada lerefe fi wọpọ, ti ọpọ eniyan si n darapọ mọ ijọ ti ko sopọ mọ Kristi.ANN 208.3

    Awọn ero ti ko tọ nipa isọdimimọ, ti o jade latari ainaani tabi kikọ ofin Ọlọrun silẹ wọpọ laarin awọn ẹgbẹ ẹsin ti akoko naa. Awọn ero wọnyi ko tọna ni ẹkọ bẹẹ si ni wọn lewu lati tẹle; nitori wipe awọn eniyan fi oju rere wo o, o wa jẹ ki o ṣe pataki ki gbogbo eniyan o ni oye ohun ti Iwe Mimọ fi kọni lori koko yii.ANN 208.4

    Isọdimimọ tootọ jẹ ikọni Bibeli. Apostoli Pọlu ninu lẹta rẹ si ijọ Tẹsalonika sọ wipe: “Eyi ni ifẹ Ọlọrun, ani isọdimimọ yin.” O tun gbadura wipe: “Ki Ọlọrun alaafia funra Rẹ sọ yin di mimọ patapata.” 1 Tẹsalonika 4:3; 5:23. Bibeli fi kọni gedegbe ohun ti isọdimimọ jẹ ati bi a tile ni. Olugbala gbadura fun awọn ọmọlẹyin Rẹ wipe: “Sọ wọn di mimọ pẹlu otitọ Rẹ.” Johanu 17:17. Pọlu si kọni ki “Ẹmi Mimọ” o ya awọn onigbagbọ “si mimọ.” Romu 15:16. Kini iṣẹ Ẹmi Mimọ? Jesu sọ fun awọn ọmọlẹyin Rẹ wipe: “Nigba ti Oun, Ẹmi Otitọ nì ba de, yoo dari yin sinu gbogbo otitọ.” Johanu 16:13. OniO. Dafidi sọ wipe: “Otitọ ni ọrọ Rẹ.” Nipasẹ ọrọ ati Ẹmi Ọlọrun, a ṣi ipilẹ nla ododo tí o wà ninu ofin silẹ fun eniyan. Nigba ti ofin Ọlọrun jẹ “mimọ ati ododo ati didara,” akọsilẹ iwa pipe Ọlọrun, o daju wipe iwa ti a ba wu ni igbọran si ofin naa yoo jẹ mimọ. Kristi ni apẹẹrẹ ti o peye fun iru iwa yii. O sọ wipe: “Mo ti pa aṣẹ Baba Mi mọ.” “Ni igba gbogbo ni mo n ṣe ohun ti o tẹ Ẹ lọrun.” Johanu 15:10; 8:29. Awọn atẹle Kristi nilati dabi Rẹ—nipa oore ọfẹ Ọlọrun lati ni iwa ti o wa ni ibamu pẹlu agbekalẹ ofin mimọ Rẹ. Eyi ni isọdimimọ Bibeli.ANN 208.5

    Nipa igbagbọ ninu Kristi nikan ni a fi le ṣe eyi, nipasẹ agbara Ẹmi Ọlọrun ti n gbe inu ẹni. Pọlu gba awọn onigbagbọ niyanju wipe: “Ẹ ṣiṣẹ igbala yin yọri pẹlu ibẹru ati iwariri. Nitori Ọlọrun ni O n ṣiṣẹ ninu yin lati le fẹ ati lati ṣiṣẹ gẹgẹ bi ifẹ inu rere Rẹ.” Filipi 2:12, 13. Kristẹni yoo ni idanwo lati dẹṣẹ, ṣugbọn yoo maa ba jijakadi nigbagbogbo. Nibi ni a ti nilo iranlọwọ Kristi. Ailera eniyan dapọ mọ okun Ọlọrun, igbagbọ si wipe: “Ọpẹ ni fun Ọlọrun, ti O fun wa ni iṣẹgun nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa.” 1 Kọrintin 15:57.ANN 208.6

    Bibeli fihan kedere wipe iṣẹ isọdimimọ jẹ eyi ti o n tẹsiwaju. Nigba ti ẹlẹṣẹ ba ni alaafia pẹlu Ọlọrun nipa ẹjẹ imukuro ẹṣẹ ni akoko iyipada, igbesi aye Kristẹni ṣẹṣẹ bẹrẹ ni. Ni bayii yoo “tẹsiwaju lọ sinu iwa pipe;” yoo dagba “de iwọn giga ti kikun Kristi.” Pọlu sọ pe: “Ohun kan yii ni mo n ṣe, mo n gbagbe gbogbo ohun atẹyinwa, mo si n naga wo awọn ohun iwaju, emi n lepa lati de opin ire ije ni fun èrè ìpè giga Ọlọrun ninu Kristi Jesu.” Filipi 3:13, 14. Peteru gbe awọn ipele ti a yoo fi ni isọdimimọ ti Bibeli ka iwaju wa: “Pẹlu gbogbo aisinmi, ẹ fi iwa rere kun igbagbọ yin; ati imọ kun iwa rere; ati iwọntuwọnsi kun imọ; ati suuru kun iwọntuwọnsi; ati iwabiọlọrun kun suuru; ati ifẹ ọmọ-ẹnikeji kun iwabiọlọrun; ati ifẹni kun ifẹ ọmọ-ẹnikeji. . . . Bi ẹyin ba ṣe gbogbo ohun wọnyi, ẹyin ki yoo ṣubu lae.” 2 Peteru 1:5—10.ANN 209.1

    Awọn ti wọn ni iriri isọdimimọ Bibeli yoo fi ẹmi irẹlẹ han. Bi i Mose, wọn ti ri ọlanla iwa mimọ ti o lẹru, wọn si ri aiyẹ wọn ni afiwe pẹlu iwa mimọ ati iwa pipe ti o ga ti Ẹni Ailopin.ANN 209.2

    Woli Daniẹli jẹ apẹẹrẹ isọdimimọ tootọ. Igbe aye ọlọjọ pipẹ rẹ kun fun iṣẹ rere fun Oluwa rẹ. O jẹ ẹni ti Ọrun “fẹran jọjọ” (Daniẹli 10:11). Dipo ki o sọ wipe oun mọ ati pe oun wa ni ailabawọn, woli ti a buyi fun yii ri ara rẹ ni ọkan pẹlu awọn ẹlẹṣẹ tootọ ni Israeli bi o ti n bẹbẹ niwaju Ọlọrun nitori awọn eniyan rẹ: “A ko mu ẹbẹ wa wá siwaju Rẹ nitori ododo wa, ṣugbọn nitori aanu nla Rẹ.” “A ti ṣẹ, a ti wuwa buburu.” O sọ pe: “Mo n sọrọ, mo si n gbadura, mo si tun n jẹwọ ẹṣẹ mi ati ti awọn eniyan mi.” Nigba ti Ọmọ Ọlọrun si farahan, lati fun ni ikilọ, Daniẹli sọ pe: “Ẹwà mi dibajẹ ninu mi, emi ko si ni okun kan.” Daniẹli 9:18, 15, 20; 10:8ANN 209.3

    Nigba ti Jobu gbọ ohùn Ọlọrun lati inu ẹfufu líle, o sọ pe: “Mo korira ara mi, mo si sapamọ sinu erupẹ ati eeru.” Jobu 42:6. Nigba ti Aisaya ri ogo Oluwa, ti o gbọ ti awọn kerubu n kigbe, “Mimọ, mimọ, mimọ ni Oluwa awọn ọmọ ogun,” ni o to kigbe wipe, “Ègbé ni fun mi! nitori ti mo gbé.” Aisaya 6:3, 5. Pọlu, lẹyin ti a gbe lọ si ọrun kẹta ti o si gbọ ohun ti kò ṣe e ṣe ki eniyan o sọ sita, sọ nipa ara rẹ gẹgẹ bi “ẹni ti o kere julọ ninu awọn eniyan mimọ.” 2 Kọrintin 12:2—4; Efesu 3:8. Johanu ẹni ti a fẹran, ti o gbe ori lé àyà Jesu wo ogo Rẹ, o ṣubu bi oku si ẹsẹ angẹli naa. Ifihan 1:17.ANN 209.4

    Awọn ti wọn n rin ninu ojiji agbelebu Kalfari ko le ni igberaga tabi ifọnu wipe awọn ti bọyọ kuro lọwọ ẹṣẹ. Wọn mọ wipe ẹṣẹ wọn ni o fa irora ti o fọ ọkan Ọmọ Ọlọrun, ero yii a si jẹ ki wọn rẹ ara wọn silẹ. Awọn ti wọn sunmọ Jesu julọ ni wọn ri ailagbara ati ẹṣẹ iran eniyan julọ, ireti kan ṣoṣo ti wọn ni ṣi ni oore ọfẹ Olugbala ti a kan mọgi ti O si jinde.ANN 209.5

    Isọdimimọ ti o wọpọ ninu ẹsin lode oni ní ẹmi igberaga ati aibikita fun ofin Ọlọrun eyi ti o fihan gẹgẹ bi ajeji si ẹsin Bibeli. Awọn ti wọn n waasu rẹ sọ wipe isọdimimọ jẹ ohun ti o n waye loju ẹsẹ, nipasẹ eyi ti wọn n ni iwa mimọ ti o peye nipa igbagbọ. Wọn sọ pe, “Sa a nigbagbọ, ibukun naa yoo si jẹ tirẹ.” Ẹni ti o ba gba a ko ni ohunkohun lati ṣe. Pẹlupẹlu, wọn gbónu si aṣẹ ofin Ọlọrun, wọn n sọ wipe wọn ko ni ojuṣe lati pa ofin mọ. Ṣugbọn njẹ o ṣe e ṣe ki eniyan o jẹ mimọ, ki o wa ni ibamu pẹlu iwa ati ifẹ Ọlọrun, laiwà ni ibamu pẹlu awọn ipilẹ ẹkọ ti i ṣe afihan iwa ati ifẹ Rẹ, ati eyi ti O fẹ han?ANN 209.6

    Ifẹ fun ẹsin ti o rọrun ti ko nilo ilakaka, isẹra-ẹni, ipinya kuro ninu iwa wèrè aye, ti sọ ikọni nipa igbagbọ, ani igbagbọ nikan di ikọni ti o gbajugbaja; ṣugbọn kini ọrọ Ọlọrun wi? Apostoli Jakọbu sọ wipe: “Èrè kini o jẹ, ẹyin ara mi, bi eniyan ba sọ wipe oun ni igbagbọ ti ko ni iṣẹ? ṣe igbagbọ le gba a la bi? . . . Njẹ iwọ fẹ mọ, olufẹ asán, wipe oku ni igbagbọ laisi iṣẹ bi? Njẹ a ko da Abrahamu baba wa lare nipa iṣẹ bi nigba ti o fi Isaaki ọmọ rẹ rubọ lori pẹpẹ? Njẹ ẹyin ri bi igbagbọ ti ṣiṣẹ pẹlu iṣẹ rẹ, ati pe iṣẹ ni o n sọ igbagbọ di pipe? . . . Nitori naa ẹ wo bi a ti n dá eniyan lare nipa iṣẹ, ki i sii ṣe nipa igbagbọ nikan.” Jakọbu 2:14—24.ANN 209.7

    Ẹri ọrọ Ọlọrun tako ikọni tí n dẹkun ẹni, ti igbagbọ laisi iṣẹ yii. Ki i ṣe igbagbọ ni o n wa ojurere Ọrun laiṣe awọn ohun ti o yẹ lati le gba aanu, idagbale ni; nitori ti igbagbọ tootọ ni ipilẹ rẹ ninu awọn ileri ati agbekalẹ Iwe Mimọ.ANN 210.1

    Ki ẹnikẹni maṣe tan ara rẹ jẹ pẹlu igbagbọ wipe wọn le jẹ mimọ nigba ti wọn mọọmọ n ru ọkan ninu ofin Ọlọrun. Ẹṣẹ amọọmọda n pa ẹri ohùn Ẹmi Mimọ lẹnu mọ ni, o si n pin ọkan niya pẹlu Ọlọrun. “Ẹṣẹ ni riru ofin.” Ati pe, “ẹnikẹni ti o ba n dẹṣẹ [ru ofin] koi tii ri I, bẹẹ si ni ko mọ Ọ.” 1 Johanu 3:6. Lootọ Johanu sọ nipa ifẹ ni ọna kikun ninu awọn episteli rẹ, sibẹ ko lọra lati fihan bi awọn ti wọn n sọ wipe a ti sọ wọn di mimọ nigba ti wọn n ru ofin Ọlọrun ti rí gan an. “Ẹni ti o ba sọ wipe, emi mọ Ọ, ti ko si pa aṣẹ Rẹ mọ, opurọ ni, ko si sí otitọ ninu rẹ. Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba n pa ọrọ Rẹ mọ, ninu rẹ ni a gbe sọ ifẹ di pípé.” 1 Johanu 2:4, 5. Eyi ni a o fi dán ohun ti eniyan ba gbagbọ wo. A ko le sọ wipe ẹnikẹni jẹ mimọ laifi odiwọn iwa mimọ ni ọrun ati ni aye yẹ ẹ wò. Bi eniyan ko ba mọ bi ofin iwa ti ni agbara tó, bi wọn ba fi oju tẹnbẹlu ti wọn ko si ka ilana Ọlọrun si, bi wọn ba ru ọkan ninu eyi ti o kere julọ ninu awọn ofin wọnyi ti wọn si fi kọni, wọn ki yoo niye lori niwaju Ọrun, a yoo si ri wipe ọrọ wọn ko fẹsẹ mulẹ.ANN 210.2

    Ki eniyan sọ wipe oun wa ni ailẹṣẹ, funra rẹ, jẹ ẹri wipe ẹni ti o n sọ bẹẹ jinna si iwa mimọ. Nitori pe ko ni oye tootọ nipa iwa mimọ ati ailabawọn Ọlọrun tabi ohun ti o yẹ ki awọn ti wọn maa n wa ni iṣọkan pẹlu iwa Rẹ ni; nitori pe ko ni oye tootọ nipa iwa mimọ Kristi ati bi O ti dara to ati bi ẹṣẹ ti buru to, ni eniyan fi le ri ara ni ẹni mimọ. Bi oye rẹ nipa iwa Ọlọrun ati ojuṣe rẹ si ba ti kere to, bẹẹ ni yoo ṣe jẹ olododo to ni oju ara rẹ.ANN 210.3

    Isọdimimọ ti Iwe Mimọ ṣe alaye kan gbogbo ara—ẹmi ọkan ati ara. Pọlu gbadura fun awọn ara Tẹsalonika pe ki “a pa gbogbo ẹmi ati ọkan ati ara wọn mọ ni ailabawọn titi fi di igba wiwa Jesu Kristi Oluwa wa.” 1 Tẹsalonika 5:23. O tun kọwe si awọn onigbagbọ wipe: “Nitori naa mo rọ yin ará nipa aanu Ọlọrun, pe ki ẹ fi ara yin silẹ ni ẹbọ aaye mimọ, ti o jẹ itẹwọgba niwaju Ọlọrun.” Romu 12:1. Ni akoko awọn Israeli ni igba atijọ gbogbo ọrẹ ti a mu wa fun irubọ si Ọlọrun ni a n yẹwo finifini. Bi a ba ri abuku kan ni ara rẹ, a ko ni gba a; nitori ti Ọlọrun ti paṣe wipe ki ọrẹ naa o wa “ni ailabawọn.” Bẹẹ gẹgẹ ni a ṣe rọ awọn Kristẹni lati fi ara wọn silẹ ni “ẹbọ aaye mimọ ti o jẹ itẹwọgba niwaju Ọlọrun.” Lati le ṣe eyi, wọn nilati pa agbara wọn mọ ni ipo ti o dara julọ. Gbogbo iwa ti n ko aarẹ bá okun ara tabi ti ọpọlọ muni kuna lati yẹ fun iṣẹ Ẹlẹda rẹ. Njẹ inu Ọlọrun a dun bi a ba ṣe ohun ti o kere si eyi ti agbara wa le ṣe lọ bi? Kristi sọ wipe: “Ki iwọ ki o fẹran Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkan rẹ.” Awọn ti wọn fẹran Ọlọrun pẹlu gbogbo ọkan wọn a fẹ lati fun ni iṣẹ ti o dara julọ ninu igbesi aye wọn, latigbadegba ni wọn a si maa wá lati mu gbogbo agbara wọn wà ni ibamu pẹlu awọn ofin ti yoo fi okun fun agbara wọn lati ṣe ifẹ Rẹ. Wọn ki yoo sọ ọrẹ ti wọn mu wa si ọdọ Baba wọn ọrun di alaarẹ tabi eleeri nipa gbigba ara wọn laaye lati jẹ tabi ṣe ohun ti ko fẹ.ANN 210.4

    Peteru sọ wipe: “Ẹ yago fun ifẹkufẹ ara, eyi ti n ba ọkan jijakadi.” 2 Peteru 2:11. Gbogbo itẹra-ẹnilọrun ni ọna ẹṣẹ n sọ agbara eniyan di oku, o si n pa agbara lati ronu ati lati ni oye lori nnkan ti ẹmi, ọrọ tabi Ẹmi Ọlọrun ko le ṣiṣẹ kan lọ titi lori iru ọkan bẹẹ. Pọlu kọwe si awọn ara Kọrintin wipe: “Ẹ jẹ ki a fọ ara wa mọ kuro ninu idọti ti ara ati ti ẹmi, ki a si sọ iwa mimọ di pipe ninu ibẹru Ọlọrun.” 2 Kọrintin 7:1. O ri “iwọntuwọnsin” ni ọna kan naa pẹlu awọn eso Ẹmi—”ifẹ, ayọ, alaafia, iwapẹlẹ, iwa rere, iwa tutu.” Galatia 5:22, 23.ANN 210.5

    Pẹlu awọn ọrọ imisi wọnyi, awọn Kristẹni melo ni wọn n sọ ara wọn di alailera nipa lile ọrọ tabi ijọsin ọṣọ ara; awọn melo ni wọn n sọ iwabiọlọrun wọn di ainilari nipa àjẹkì, ọti mimu, nipa faaji ti ko tọ. Dipo ki ijọ o ba iru iwa buburu bayii wi, ni ọpọ igba o n jẹ ki o tẹsiwaju nipa ṣiṣipẹ si ifẹ lati tẹ ara lọrun, lati nifẹ ọrọ tabi ifẹ faaji, lati le fikun iṣura rẹ, eyi ti ifẹ fun Kristi kò lókun lati mú wá. Bi Kristi ba wọ inu awọn ijọ loni ti O ri ajọyọ ati itaja àìmọ ti a n ṣe nibẹ ni orukọ ẹsin, ṣe ki yoo le awọn olùsọ-ibi-mimọ-di-aimọ naa jade bi o ti le awọn olupa-owó-dà kuro ninu tẹmpili?ANN 210.6

    Apostoli Jakobu sọ wipe ọgbọn ti o ti oke wá “kọkọ jẹ mimọ.” Bi o ba ṣe wipe o ṣe alabapade awọn ti wọn n pe orukọ Jesu ti o ṣeyebiye pẹlu ètè tí tábà ti sọ di eeri, ti eemi ati ara wọn ti di eeri nipasẹ oorun buburu rẹ, ti wọn n ba afẹfẹ ọrun jẹ ti wọn si n fi ipa mu gbogbo awọn ti wọn yi wọn ka lati mí majele yii simu ni—bi o ba ṣe wipe apostoli naa ṣe alabapade iṣesi ti o tako iwamimọ iyinrere bayii, njẹ ko ni bawi wipe o jẹ “ti aye, ti ifẹkufẹ ara ati ti eṣu?” Ẹrú taba, n sọ wipe oun ni ibukun isọdimimọ patapata, wọn n sọ nipa ireti wọn ni ọrun; ṣugbọn ọrọ Ọlọrun sọ ọ ni kedere wipe “ohun alaimọ kan ki yoo si wọ inu rẹ rara.” Ifihan 21:27.ANN 211.1

    “Njẹ ẹyin ko mọ wipe tẹmpili Ẹmi Mimọ ni ẹyin n ṣe ti o wa ninu yin, eyi ti ẹyin ni lati ọdọ Ọlọrun, ẹyin ki i si i ṣe ti ara yin? nitori ti a ti ra yin ni iye kan: nitori naa ẹ yin Ọlọrun logo ninu ara yin, ati ninu ẹmi yin ti i ṣe ti Ọlọrun.” 1 Kọrintin 6:19, 20. Ẹnikẹni ti ara rẹ ba jẹ tẹmpili Ẹmi Mimọ ko ni sọ ọ di ẹrú pẹlu iwa buburu. Ti Kristi ni agbara rẹ n ṣe, Ẹni ti o ra a pẹlu iye owo ẹjẹ, ohun ini rẹ jẹ ti Oluwa. Bawo ni yoo ṣe wa ni ailẹbi bi o ba n na owo ti a fi si ikawọ rẹ ni ina apa? Awọn ti wọn pe ara wọn ni Kristẹni n na owo gọbọi le awọn ohun ti ko nitumọ ti wọn tun le panilara lọdọọdun, nigba ti awọn ọkan n ṣegbe nitori ọrọ iye. A n ja Ọlọrun lole ninu idamẹwa ati ọrẹ, nigba ti iye ti a n ná lori pẹpẹ irubọ ifẹkufẹ ti n panilara ju iye ti a n na lọ fun iranlọwọ awọn alaini tabi fun iranlọwọ iyinrere. Bi gbogbo awọn ti wọn n pe ara wọn ni atẹle Kristi ba wa ni isọdimimọ ni tootọ, dipo ki wọn ná ohun ini wọn lori ohun ti ko nitumọ ti o tun le pani lara, wọn a ko wá sinu ile iṣura Oluwa, awọn Kristẹni a si mu apẹẹrẹ iwọntuwọnsi, isẹra-ẹni, ati ifi-ara-ẹni-rubọ lelẹ. Nigba naa ni wọn a jẹ imọlẹ aye.ANN 211.2

    Aye ti fi ara rẹ fun itẹra-ẹni-lọrun. “Ifẹkufẹ ara, ifẹkufẹ oju, ati igberaga ọkan” n dari ọpọ eniyan. Ṣugbọn awọn atẹle Kristi ni ìpè ti o mọ ju eyi lọ. “Ẹ jade kuro laarin wọn, ki ẹ si da duro, ni Oluwa wi, ki ẹ ma si ṣe fi ọwọ kan ohun aimọ.” Ninu imọlẹ ọrọ Ọlọrun a tọna ni sisọ wipe isọdimimọ ko le jẹ otitọ bi ko ba ṣe iṣẹ kikọ lílé ohun ẹṣẹ ati itẹlọrun aye silẹ patapata.ANN 211.3

    Si awọn ti wọn tẹle agbekalẹ yii, “Ẹ jade kuro ni aarin wọn, ki ẹ si da duro . . . ki ẹ ma si ṣe fi ọwọ kan ohun aimọ,” ileri Ọlọrun ni pe, “Emi yoo tẹwọ gba yin, Emi yoo si jẹ Baba fun yin, ẹyin yoo si jẹ ọmọkunrin ati ọmọbinrin Mi ni Oluwa Alagbara wi.” 2 Kọrintin 6:17, 18. O jẹ anfani ati ojuṣe fun gbogbo Kristẹni lati ni iriri kikun ninu ohun ti Ọlọrun. Jesu sọ wipe “Emi ni imọlẹ aye.” “Ẹni ti o ba tẹle Mi ki yoo rin ninu okunkun, ṣugbọn yoo ni imọlẹ aye.” Johanu 8:12. “Ipa ọna olododo dabi imọlẹ ti n tan, ti o n tan si titi fi di ọjọ pípé.” Owe 4:18. Gbogbo igbesẹ igbagbọ ati igbọran n mu ọkan sunmọ Imọlẹ aye si ni, ninu Ẹni ti “ko si okunkun rara.” Itansan didan Oorun Ododo n tan sori awọn iranṣẹ Ọlọrun, wọn si nilati jẹ ki o tan sita. Bi awọn irawọ ti n sọ fun wa wipe imọlẹ nla wa ni ọrun, ogo eyi ti n mu wọn tan, bẹẹ gẹgẹ ni o yẹ ki awọn Kristẹni o fihan wipe Ọlọrun wa ni ori itẹ agbaye, Ẹni ti ogo yẹ fun iwa Rẹ, ti a si nilo lati wuwa bii Rẹ. Awọn ẹlẹri Rẹ yoo fi ẹbun Ẹmi Rẹ, iwa mimọ ati ailabawọn iṣesi Rẹ han.ANN 211.4

    Pọlu, ninu lẹta rẹ si awọn ara Kolose ṣe alaye ibukun nla ti a fun awọn ọmọ Ọlọrun, o sọ pe: A “ko ṣiwọ lati maa gbadura fun yin, ati lati fẹ ki ẹ kun fun imọ ifẹ Rẹ ninu gbogbo ọgbọn ati oye ẹmi; ki ẹyin le maa rin irin ti o yẹ Ọlọrun ninu gbogbo inu didun, ni siso eso ninu gbogbo iṣẹ rere, ti ẹ si n pọ si ninu imọ Ọlọrun, ki ẹ ni okun pẹlu gbogbo ipa, gẹgẹ bi agbara ologo Rẹ, si gbogbo suuru ati ipamọra ati inu didun.” Kolose 1:9—11ANN 211.5

    Ẹwẹ, o kọ nipa ifẹ ọkan rẹ ki awọn arakunrin ni Efesu le ni oye giga nipa anfani Kristẹni. O ṣe alaye fun wọn, ni ọna ti o yeni julọ, agbara iyanu ati imọ ti wọn le ni gẹgẹ bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin Ẹni Giga julọ. Ti wọn ni “lati ní okun pẹlu agbara Ẹmi Rẹ ninu ọkunrin inu,” lati “ni gbongbo ki a si fi idi wọn mulẹ ninu ifẹ,” lati “ni oye pẹlu gbogbo eniyan mimọ ìbú, ati ìwọn, ati ìjìn, ati gíga; ati lati mọ ifẹ Kristi, ti o ju imọ lọ”. Ṣugbọn adura apostoli naa de opin anfani ti o ga julọ nigba ti o n gbadura wipe ki “a le fi gbogbo ẹkun Ọlọrun kun yin.” Efesu 3:10—16.ANN 211.6

    Nibi ni a ti fihan wa bi ipo ti a le de ti ga to nipa igbagbọ ninu awọn ileri Baba wa ọrun, nigba ti a ba ṣe ohun ti O là kalẹ fun wa. Nipasẹ oore ọfẹ Kristi, a ni anfani si itẹ Agbara Ayeraye. “Ẹni ti ko da Ọmọ Oun tikara Rẹ si, ṣugbọn ti O jọwọ Rẹ fun gbogbo wa, yoo ha ti ṣe ti ki yoo fun wa ni ohun gbogbo pẹlu Rẹ lọfẹ?” Romu 8:32. Baba fun Ọmọ Rẹ ni Ẹmi Rẹ lai lo odiwọn, àwa pẹlu le pin ninu ẹkun re. Jesu sọ pe, “Bi ẹyin ti i ṣe eniyan buburu ba mọ bi a ti n fi ẹbun rere fun awọn ọmọ yin: melomelo ni Baba yin ni ọrun yoo ti fi Ẹmi Mimọ Rẹ fun awọn ti n bere lọwọ Rẹ?” Luku 11:3. “Bi ẹyin ba beere ohunkohun ni orukọ Mi, Emi yoo ṣe e.” “Beere, ẹyin yoo si ri gba, ki ayọ yin le kun.” Johanu 14:14; 16:24.ANN 212.1

    Nigba ti ìgbé aye Kristẹni nilati kun fun irẹlẹ, ko gbọdọ ni ibanujẹ tabi ibara-ẹni-jẹ. O jẹ anfani fun gbogbo eniyan lati gbe igbe aye debi pe Olorun a fi ọwọ si, yoo si bukun fun. Ki i ṣe ifẹ Baba wa ọrun ni ki a wa labẹ idalẹbi ati okunkun ni gbogbo igba. Ko si ẹmi irẹlẹ tootọ ninu ki a maa rin pẹlu ori ti o tẹba ati ọkan ti o kun fun ero ara ẹni. A le lọ si ọdọ Jesu fun iwẹnumọ, ki a si duro niwaju ofin laisi itiju tabi ikaanu. “Nitori naa ko si idalẹbi fun awọn ti wọn wa ninu Kristi Jesu, awọn ti ko rin ni ti ara, bikoṣe ni ti Ẹmi.” Romu 8:1.ANN 212.2

    Nipasẹ Jesu Kristi awọn ọmọ Adamu ti wọn kuna di “ọmọ Ọlọrun.” “A ti Ẹni ti n sọni di mimọ ati awọn ti a n sọ di mimọ jẹ ọkan: idi niyii ti ko fi tiju lati pe wọn ni arakunrin.” Heberu 2:11. Igbe aye Kristẹni nilati jẹ igbe aye igbagbọ, iṣẹgun ati ayọ ninu Ọlọrun. “Olukuluku ẹni ti a ba ti bi nipa ti Ọlọrun ti ṣẹgun aye: eyi si ni iṣẹgun naa ti o ṣẹgun aye, ani igbagbọ wa.” 1 Johanu 5:4. Lootọ ni Nehemaya, iranṣẹ Ọlọrun sọ wipe: “Ayọ Oluwa ni okun yín.” Nehemaya 8:10. Pọlu tun sọ wipe: “Ẹ yọ ninu Oluwa nigba gbogbo: lẹẹkan si mo sọ wipe, Ẹ yọ.” “Ẹ maa yọ nigba gbogbo. Ẹ maa gbadura laisinmi. Ninu ohun gbogbo ẹ maa dupẹ: nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun ninu Kristi Jesu nipa yin.” Filipi 4:4; 1 Tẹsalonika 5:16—18.ANN 212.3

    Awọn eso iyipada ati isọdimimọ Bibeli niyii; nitori wipe awọn Kristẹni ko naani ipilẹ nla fun ododo ti a gbe kalẹ ninu ofin ni awọn wọnyi fi ṣọwọn. Idi niyi ti iṣẹ Ẹmi Ọlọrun ti o wa titi, eyi ti a ri ninu awọn isọji atẹyinwa fi ṣọwọn.ANN 212.4

    Nipa wiwo ni a fi n yipada. Bi a si ti n kọ awọn ilana mimọ ninu eyi ti Ọlọrun ti fi iwa pipe ati iwa mimọ iṣesi Rẹ han eniyan silẹ, ti iye awọn eniyan si n ṣi si ẹkọ ati ero eniyan, ko yanilẹnu wipe ifọkansin alaaye dinku ninu ijọ. Oluwa sọ wipe: “Wọn ti kọ Mi silẹ orisun omi iye, wọn si ti gbẹ ihò, ihò fifọ, funra wọn ti ko le gba omi duro.” Jeremaya 2:13.ANN 212.5

    “Alabukunfun ni ẹni naa ti ko rin ninu imọran awọn alaiwabiọlọrun. . . . Ṣugbọn idunnu rẹ wa ninu ofin Oluwa; ninu rẹ ni o n ṣe aṣaro ni ọsan ati ni aṣalẹ. Yoo dabi igi ti a gbin si ipa odo, ti n mu eso rẹ wa ni akoko rẹ; ewe rẹ pẹlu ki yoo yẹ; ohun ti o ba si ṣe, yoo yọri si rere.” O. Dafidi 1:1—3. Ayafi bi a ba da ofin Ọlọrun pada si aaye rẹ ni a to le ri isọji igbagbọ ati iwabiọlọrun ti igba atijọ laarin awọn ti wọn pe ara wọn ni eniyan Rẹ. “Bayii ni Oluwa wi, Ẹ duro loju ọna, ki ẹ si wò, ki ẹ si beere fun oju ọna atijọ, nibi ti ọna rere wa, ki ẹ si rin ninu rẹ, ẹyin yoo si ri isinmi fun ọkan yin.” Jeremaya 6:16.ANN 212.6

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents