Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KỌKANLELỌGBỌN—AṢOJU AWỌN ẸMI EṢU

    Ibaṣepọ ti o wa laarin aye ti a ri ati aye airi, iṣẹ iranṣẹ awọn angẹli Ọlọrun ati aṣoju awọn ẹmi eṣu ni a fihan kedere ninu Iwe Mimọ, a ko sile yọ wọn kuro ninu itan iran eniyan. O wọpọ ni ode oni lati maṣe gbagbọ wipe awọn ẹmi eṣu wa, nigba ti a ri awọn angẹli mimọ ti wọn n “ṣiṣẹ iranṣẹ fun awọn ti yoo jogun igbala” (Heberu 1:14) bi ẹmi awọn oku. Ṣugbọn ki i ṣe wipe Iwe Mimọ kọ wa wipe awọn angẹli wa nikan, ati rere ati buburu, ṣugbọn o fiyeni laiṣe iyemeji wipe wọn ki i ṣe ẹmi awọn oku.ANN 228.1

    Ṣaaju ki a to da eniyan, awọn angẹli ti wa; nitori nigba ti a ṣe ipilẹ aye, “awọn irawọ owurọ kọrin, gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun si kigbe fun ayọ.” Jobu 38:7. Lẹyin iṣubu eniyan, a ran awọn angẹli lati ṣọ igi iye, eyi si ṣẹlẹ ki eniyan kankan o to ku. Nipa iṣẹda wọn, awọn angẹli lagbara ju eniyan lọ, nitori ti oniO. Dafidi sọ wipe a da eniyan “rẹlẹ ju awọn angẹli lọ.” O. Dafidi 8:5.ANN 228.2

    A sọ iye wọn fun wa ninu Iwe Mimọ ati agbara ati ogo awọn ẹda ọrun, ibaṣepọ wọn pẹlu iṣejọba Ọlọrun ati ibaṣepọ wọn pẹlu iṣẹ irapada. “Oluwa ti pese itẹ Rẹ silẹ ni awọn ọrun, ijọba Rẹ si n jọba lori ohun gbogbo.” Woli naa sọ wipe, “Mo gbọ ohun ọpọ awọn angẹli yi itẹ naa ka.” Ninu aafin Ọba awọn ọba wọn duro—”awọn angẹli tiANN 228.3

    wọn pọ ni ipa,” “awọn iranṣẹ Rẹ ti wọn n ṣe didun inu Rẹ,” “ti wọn n gbọ ohùn ọrọ Rẹ.” O. Dafidi 103:19—21; Ifihan 5:11. Ẹgbaarun lọna ẹgbaarun ati ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun ni awọn iranṣẹ ọrun ti woli Daniẹli ri. Apostoli Pọlu sọ wipe wọn jẹ “ọwọ ti a ko le kà.” Daniẹli 7:10; Heberu 12:22. Gẹgẹ bi iranṣẹ Ọlọrun, wọn jade lọ, bi “kikọ mọnamọna,” Isikiẹli 1:14, ogo wọn tan pupọpupọ, bẹẹ si ni wọn fò yara kankan. Angẹli ti o farahan nibi iboji Olugbala, ti irisi rẹ “dabi mọnamọna, aṣẹ rẹ dabi yinyin,” mu ki awọn oluṣọ o wariri nitori ibẹru rẹ, wọn “si dabi oku.” Matiu 28:3, 4. Nigba ti Senakerubu, agberaga ara Asiria, kẹgan ti o si sọ ọrọ odi si orukọ Ọlọrun, ti o fi iparun ṣẹruba Israeli, “o ṣẹlẹ wipe ni aṣalẹ naa, angẹli Oluwa jade lọ, o si pa ọkẹ mẹsan o le ẹgbẹẹdọgbọn eniyan ni ibudo awọn ara Asiria.” A “ge gbogbo awọn alagbara ogun, ati awọn aṣaaju, ati awọn balogun,” kuro ninu awọn ọmọ ogun Senakerubu. “O si pada si ile rẹ pẹlu itiju.” 2 Awọn Ọba 19:35; 2 Kronika 32:21.ANN 228.4

    A n ran awọn angẹli ni iṣẹ aanu si awọn ọmọ Ọlọrun. Si Abrahamu pẹlu ileri ibukun; si awọn ilẹkun Sodomu, lati gba Lọti olododo silẹ kuro ninu iparun ina; si Elija bi aarẹ ati ebi ti fẹ gba ẹmi rẹ ninu aṣalẹ; si Elisha pẹlu kẹkẹ ina ati ẹṣin ina ti wọn yi ilu kekere naa ka nibi ti awọn ọta ti i mọ; si Daniẹli, nigba ti o n wa ọgbọn Ọlọrun ninu aafin ọba abọriṣa, tabi nigba ti a fi silẹ lati di ẹran ijẹ kiniun; si Peteru ti a ti dajọ iku fun ninu ọgba ẹwọn Hẹrọdu; si awọn ẹlẹwọn ni Filipi; si Pọlu ati awọn akẹgbẹ rẹ ninu ẹfufu lile oru lori okun; lati ṣi iye Kọneliu lati gba iyinrere, lati ran Peteru pẹlu iṣẹ iranṣẹ igbala si ajeji Keferi—ni igba gbogbo ni a ri ti awọn angẹli n ṣiṣẹ fun awọn eniyan Ọlọrun.ANN 228.5

    A ti yan awọn angẹli oluṣọ kọọkan fun gbogbo atẹle Kristi. Awọn oluṣọ ọrun wọnyi ni wọn n daabo bo awọn olododo kuro lọwọ agbara eṣu. Eyi ni Satani funra rẹ tọka si nigba ti o sọ pe: “Jobu ha bẹru Ọlọrun lasan bi? Iwọ ko ha ṣọgba yi ka, ati ile rẹ, ati gbogbo ohun ti o ni ni iha gbogbo?” Jobu 1: 9, 10. Awọn ọna ti Ọlọrun n gba lati daabo bo awọn eniyan Rẹ ni a fihan ninu awọn ọrọ oniO. Dafidi: “Angẹli Oluwa yi awọn ti o bẹru Rẹ ka, o si gba wọn.” O. Dafidi 34:7. Nigba ti O n sọ nipa awọn ti wọn gbagbọ ninu Rẹ, Olugbala sọ wipe: “Ẹ kiyesara ki ẹ maṣe gan ọkan ninu awọn kekeeke wọnyi; nitori mo sọ fun yin, wipe ni ọrun, ni igba gbogbo ni awọn angẹli wọn n wo oju Baba Mi.” Matiu 18:10. Awọn angẹli ti a yan lati ṣe iṣẹ iranṣẹ fun awọn ọmọ Ọlọrun maa n ri aye de ọdọ Rẹ ni igba gbogbo.ANN 228.6

    Awọn eniyan Ọlọrun ti wọn n ri agbara ẹtan ati arankan ti ko dẹyin ọmọ alade okunkun, ati ijakadi pẹlu gbogbo agbara buburu, ni idaniloju iṣọ awọn angẹli ọrun. A ko funni ni iru idaniloju yii laisi idi fun. Bi Ọlọrun ba fun awọn ọmọ Rẹ ni ileri oore ọfẹ ati aabo, nitori pe wọn yoo koju awọn aṣoju iwa ibi ti wọn lagbara ni—awọn aṣoju ti wọn pọ, ti wọn lagidi, ti ki i kaarẹ, ti ko si ẹni ti o le wa ni aimọkan tabi aibikita si agbara ati arankan wọn ki o si wa ni ailewu.ANN 229.1

    Ni atetekọṣe, a da awọn ẹmi buburu wọnyi ni ailẹṣẹ, wọn dọgba ni iṣẹda, agbara ati ogo pẹlu awọn ẹda mimọ ti wọn jẹ iranṣẹ Ọlọrun bayii. Ṣugbọn wọn ṣubu nipasẹ ẹṣẹ, wọn wa fọwọsowọpọ fun abuku Ọlọrun ati iparun eniyan. Ni iṣọkan pẹlu Satani ninu iṣọtẹ rẹ, a le wọn kuro ni ọrun papọ pẹlu rẹ, wọn si fọwọsowọpọ pẹlu rẹ ninu ijakadi rẹ pẹlu aṣẹ Ọlọrun ni igba gbogbo. A sọ fun wa ninu Iwe Mimọ nipa irẹpọ ati iṣejọba wọn, oriṣiriṣi abala ti wọn pin si, ọgbọn ati arekereke wọn, ati ete buburu wọn lati tako alaafia ati idunnu eniyan.ANN 229.2

    Itan inu Iwe Majẹmu Laelae sọ fun wa iwalaaye wọn ati iṣọwọṣiṣẹ wọn lerefe; ṣugbọn ni akoko ti Kristi wa lori ilẹ aye ni awọn ẹmi eṣu fi agbara wọn han ni ọna ti o lagbara julọ. Kristi ti bẹrẹ iṣẹ lori eto ti a ṣe fun irapada eniyan, Satani si pinu lati lo ẹtọ rẹ lati dari aye. O ti ṣe aṣeyọri ni fifi ẹsin ibọriṣa lelẹ ni gbogbo aye ayafi ni ilẹ Palestine. Ilẹ kan ṣoṣo ti koi ti i bọ sọwọ adanniwo patapata. Kristi wa lati tan imọlẹ ọrun sori awọn eniyan. Nibi awọn agbara meji n jijadu fun akoso. Jesu n na ọwọ ifẹ Rẹ O n pe gbogbo awọn ti wọn ba fẹ lati gba idariji ẹṣẹ ati alaafia ninu Oun. Awọn ẹgbẹgun okunkun ri wipe wọn ko ni agbara ayeraye, wọn si ni oye wipe bi iṣẹ Kristi ba yọri si rere, iṣakoso wọn yoo pari laipẹ. Satani binu bi kiniun ti a fi ẹwọn si lọrun o si fi agidi lo agbara rẹ lori ara ati ọkan eniyan.ANN 229.3

    A sọ ọ kedere ninu Iwe Majẹmu Tuntun wipe awọn eniyan n ni ẹmi aimọ. Awọn ti a ba fiyajẹ bayii ki i jiya aisan ara lasan. Kristi ni oye pipe nipa ohun ti Oun n ṣiṣẹ pẹlu, O si mọ wipe awọn ẹmi eṣu yii wa.ANN 229.4

    Apẹẹrẹ ti o han kedere nipa iye, agbara ati iwa buburu wọn, ati agbara ati aanu Kristi pẹlu ni a ri ninu alaye Iwe Mimọ nipa wiwo ẹlẹmi aimọ ti Gadara san. Awọn were otoṣi yii kọ gbogbo ikoraẹni-nijanu silẹ, wọn n gbolẹ, wọn n ru itọ lẹnu, wọn n binu, ayika si kun fun ariwo wọn, wọn n ṣe ara wọn nijamba, wọn si n ṣe gbogbo ẹni ti o ba sunmọ wọn nijamba pẹlu. Ara wọn ti n ṣẹjẹ ti o ti bajẹ ati iye wọn ti o ti síwín jẹ ohun ti o dun mọ ọmọ alade okunkun ninu. Ọkan ninu awọn ẹmi aimọ ti n dari awọn ti n jiya yii sọ wipe: “Orukọ mi ni Lijioni: nitori ti a pọ.” Maku 5:9. Ninu ẹgbẹ ogun Romu, lijioni to bi ẹgbẹrun mẹta si marun ọmọ ogun. Awọn ọmọ ogun Satani pẹlu wa lẹgbẹẹgbẹ, ẹgbẹ kan ṣoṣo ti awọn ẹmi aimọ wa ko kere ju lijioni kan lọ.ANN 229.5

    Ni aṣẹ Jesu awọn ẹmi aimọ naa fi ẹni ti wọn n fiyajẹ silẹ, ara wọn balẹ, wọn joko labẹ ẹsẹ Olugbala, oju wọn walẹ, wọn ni oye, wọn si ni irẹlẹ. Ṣugbọn a gba awọn ẹmi aimọ naa laaye lati gba agbo ẹlẹdẹ kan sinu okun; adanu yii pọ loju awọn ara Gadara ju ibukun ti Kristi fifunni lọ, a si rọ Oluwosan ọrun lati kuro nibẹ. Eyi jẹ atubọtan ti Satani fẹ lati ri. Nipa kiko ẹbi adanu wọn si ori Jesu, o ru ẹru onimọ-ti-ara-ẹni-nikan awọn eniyan naa soke, o si di wọn lọwọ lati gbọ ọrọ Rẹ. Ni igba gbogbo ni Satani n fi ẹsun kan awọn Kristẹni gẹgẹ bi okunfa adanu, ajalu ati ijiya dipo ki o jẹ ki ẹgan naa bọ si ibi ti o yẹ—ori ara rẹ ati awọn aṣoju rẹ.ANN 229.6

    Ṣugbọn eto Kristi ko yipada. O gba awọn ẹmi eṣu laaye lati pa agbo ẹlẹdẹ naa run gẹgẹ bi ibawi fun awọn Ju ti wọn n sin ẹran aimọ yii nitori owo. Ti ki i ba n ṣe wipe Kristi da awọn ẹmi aimọ naa lẹkun ni, ki i ṣe awọn ẹlẹdẹ nikan ni wọn i ba ti sinu okun, ṣugbọn ati awọn oluṣọ wọn ati awọn to ni wọn pẹlu. Agbara Rẹ nikan ṣoṣo ni o fi pa awọn oluṣọ ati awọn ti wọn ni ẹlẹdẹ naa mọ, ninu aanu O lo o fun igbala wọn. Siwaju si, a gba iṣẹlẹ yii laaye lati ṣẹlẹ ki awọn ọmọ ẹyin le jẹri si agbara buburu ti Satani ni lori eniyan ati ẹranko. Olugbala fẹ ki awọn atẹle Rẹ o ni imọ nipa ọta ti wọn yoo koju, ki a maa baa tan wọn jẹ ki a si bori wọn nipasẹ arekereke rẹ. O tun jẹ ifẹ Rẹ pẹlu ki awọn eniyan agbegbe naa o ri agbara Rẹ lati ja igbekun Satani ati lati tu onde silẹ. Bi o tilẹ jẹ wipe Jesu funra Rẹ fi ibẹ silẹ, awọn eniyan ti a fi iyanu tu silẹ duro nibẹ lati kede aanu Ẹni ti o ṣe wọn loore.ANN 229.7

    Awọn apẹẹrẹ miran ti wọn fi ara jọ eyi ni a kọ sinu Iwe Mimọ. Ẹmi aimọ n damu ọdọmọbinrin ara Sirofenisia pupọpupọ, eyi ti Jesu le jade pẹlu ọrọ Rẹ. Maku 7:26—30. “Ọkan ti o ni ẹmi aimọ, ti o yadi ti ko si le sọrọ” (Matiu 12:22); ọdọ kan ti o ni ẹmi iyadi ti o saba maa “n sọ ọ sinu ina, ati sinu omi, lati pa a run.” (Maku 9:17—27); wèrè ti, “ẹmi aimọ n da laamu” (Luku 4:33—36) tí o di idakẹrọrọ inu sinagọgu lọwọ ni ọjọ isinmi ni Kapanaumu—gbogbo wọn ni Olugbala alaanu wosan. Ni ibi gbogbo, Kristi sọrọ si awọn ẹmi aimọ bi ẹni ti o ni oye, ti O si paṣẹ fun wọn lati jade kuro ninu ẹni ti wọn n jẹ niya, ki wọn ma si ṣe damu rẹ mọ. Awọn olujọsin ni Kapanaumu, nigba ti wọn ri agbara nla Rẹ, “yanu, wọn si sọ laarin ara wọn wipe, Iru ọrọ wo ni eyi! nitori pẹlu aṣẹ ati agbara ni O fi paṣẹ fun awọn ẹmi aimọ, wọn si jade sita.” Luku 4:36.ANN 230.1

    A saba maa n fi awọn ti wọn ni ẹmi aimọ han bi ẹnipe wọn n jiya pupọpupọ; ṣugbọn ki i ri bẹẹ ni gbogbo igba. Lati le ri agbara ẹmi, awọn miran gba agbara Satani laaye. Awọn wọnyi ki i ni wahala pupọ pẹlu awọn ẹmi aimọ. Lara ẹgbẹ yii ni awọn ti wọn ni ẹmi afọṣẹ wa,—Simoni Magu, Elima oṣo, ati ọmọbinrin ẹni ti o n tẹle Polu ati Sila ni Filipi.ANN 230.2

    Ko si ẹni ti o wa ninu ewu iṣakoso awọn ẹmi aimọ bi awọn ti wọn ko gbagbọ wipe eṣu ati awọn angẹli rẹ wa, pẹlu gbogbo ẹri to pọ yanturu ninu Iwe Mimọ. Niwọn igba ti a ba jẹ alaimọkan nipa arekereke wọn, wọn ni anfani to pọ; ọpọlọpọ ni wọn n tẹle àbá wọn, nigba ti wọn n ro wipe wọn n tẹle ọgbọn ara wọn. Idi niyi, bi a ti n sunmọ opin akoko, nigba ti Satani yoo ṣiṣẹ pẹlu agbara nla lati ṣe itanjẹ ati lati panirun, o n tan igbagbọ wipe oun ko si kaakiri. Iwa rẹ ni lati fi ara rẹ ati iṣọwọṣiṣẹ rẹ pamọ.ANN 230.3

    Ko si ohun ti atannijẹ nla naa bẹru bii ki a ni oye nipa awọn ète rẹ. Lati le fi iwa ati erongba rẹ pamọ, o fi ara rẹ han ni ọna ti ko ni ṣe ju lati mu ẹgan wa ti yoo si panilẹrin lọ. O tẹ lọrun daradara nigba ti a ba ya aworan rẹ bi ohun ti o ri ni lara tabi ti o panilẹrin, ti ko duro daradara, apakan eniyan ati apakan ẹranko. Inu maa rẹ dun nigba ti awọn ti wọn ro wipe wọn gbọn ti wọn si loye ba lo orukọ rẹ ninu awada ati yẹyẹ.ANN 230.4

    Nitori pe o ti fi ọgbọn arekereke fi ara rẹ pamọ ni o maa n jẹ ki a saba maa n bere wipe: “Ṣe iru ẹda bayi wa lootọ?” O jẹ ẹri aṣeyọri rẹ wipe awọn ẹlẹsin pupọ ni wọn gba ero ti o sọ ọrọ ti o farahan ninu Iwe Mimọ di onirọ. Nitori wipe Satani le tete ṣe akoso iye awọn ti ko mọ nipa agbara rẹ ni ọrọ Ọlọrun fi fun wa ni ọpọlọpọ apẹẹrẹ nipa iṣẹ laabi rẹ, ti o n ṣi aṣọ kuro loju awọn agbara ikọkọ rẹ, ti a si n tipa eyi jẹ ki a ṣọra fun igbejako rẹ.ANN 230.5

    Agbara ati arankan Satani ati awọn ogun rẹ i ba bawa lẹru daradara ti ki i ba ṣe wipe le ri aabo ati igbala ninu agbara Olurapada ti o ga julọ. A maa n fi pẹlẹkutu ti ile wa pẹlu kọkọrọ lati daabo bo ohun ini wa ati ẹmi wa kuro lọwọ awọn eniyan buburu; ṣugbọn a ki i saba maa n ronu wipe latigbadegba ni awọn angẹli buburu n wa ọna si ọdọ wa, ti a ko si ni agbara kankan ninu ara wa lati dojukọ igbejako wọn. Bi a ba gba wọn laaye, wọn le dawa niye ru, ki wọn ba ara wa jẹ ki wọn fiya jẹ wa, ki wọn ba ohun ini wa jẹ ati ẹmi wa pẹlu. Iparun ati ijiya nikan ni idunnu wọn. Ipo awọn ti wọn ko gba ọrọ Ọlọrun ti wọn jọwọ ara wọn fun idanwo Satani titi ti Ọlọrun fi fi wọn silẹ fun iṣakoso awọn ẹmi eṣu jẹ eyi ti o banilẹru. Ṣugbọn awọn ti wọn tẹle Kristi ni aabo nigbagbogbo labẹ abo Rẹ. A n ran awọn angẹli ti wọn pọ ni agbara lati daabo bo wọn. Eṣu ko le da aabo ti Ọlọrun fi bo awọn eniyan Rẹ lu.ANN 230.6

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents