Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KẸTALELỌGBỌN—ITANJẸ NLA AKỌKỌ

    Lati ibẹrẹ itan eniyan ni Satani ti bẹrẹ iṣẹ rẹ lati tan iran wa jẹ. Ẹni ti o bẹrẹ iṣọtẹ ni ọrun fẹ lati so awọn olugbe aye yii pọ mọ ara rẹ ninu ijakadi rẹ pẹlu ijọba Ọlọrun. Adamu ati Efa ni idunu pipe ninu igbọran si ofin Ọlọrun, eyi si jẹ ẹri atigbadegba lati tako ohun ti Satani sọ ni ọrun, wipe ofin Ọlọrun n pọnni loju ko si dara fun rere awọn ẹda Rẹ. Siwaju si, ilara Satani ru soke bi o ti ri ile daradara ti a pese fun tọkọtaya alailẹṣẹ naa. O pinnu lati fa iṣubu wọn, wipe lẹyin ti a ba ti ya wọn nipa kuro ni ọdọ Ọlọrun ti o si fi wọn si abẹ agbara rẹ tan, aye yoo jẹ ohun ini rẹ, yoo si tẹ ijọba rẹ dó sibi ni atako si Ẹni Giga julọ.ANN 237.1

    Bi Satani ba fi ara rẹ han gẹgẹ bi iwa rẹ ti rí ni, wọn i bá ti le pada sẹyin, nitori ti a ti ki Adamu ati Efa nilọ nipa ọta ti o lewu yii; ṣugbọn o n ṣiṣẹ ninu okunkun, o n fi erongba rẹ pamọ, ki o ba le ri iṣẹ rẹ ṣe daradara. O lo ejò bi ohun elo, nigba naa o jẹ ẹda ti o dun un wò loju, o ba Efa sọrọ: “Njẹ Ọlọrun sọ wipe, Ẹ ko gbọdọ jẹ ninu gbogbo eso ọgba?” Jẹnẹsisi 3:1. Bi o ba ṣe wipe Efa kọ lati ba oludanwo naa ṣe ariyanjiyan ni, i ba wa ni ailewu; ṣugbọn o ba dọrẹ, o si ṣubu sinu itanjẹ rẹ. Bayi ni a si ṣe n bori ọpọlọpọ. Wọn ṣe iyemeji, wọn si n ṣe ariyanjiyan nipa ofin Ọlọrun; dipo ki wọn ṣe igbọran si aṣẹ Ọlọrun, wọn gba ero eniyan eyi ti o fi itanjẹ Satani pamọ.ANN 237.2

    “Obirin naa sọ fun ejo naa pe, A le jẹ ninu awọn eso igi ọgba: ṣugbọn eso igi ti o wa ni aarin ọgba ni Ọlọrun sọ pe, Ẹyin ko gbọdọ jẹ ninu rẹ, bẹẹ si ni ẹyin ko gbọdọ fi ọwọ kan an, ki ẹ ma baa ku. Ejo naa si sọ fun obirin naa, Ẹyin ki yoo ku ikukiku kan: nitori ti Ọlọrun mọ wipe ni ọjọ ti ẹyin ba jẹ ninu rẹ, nigba naa ni oju yin yoo la, ẹ o si da bi Ọlọrun, ni mimọ rere ati buburu.” Ẹsẹ 2—5. O sọ wipe wọn yoo dabi Ọlọrun, wọn a ni ọgbọn ti o pọ ju ti tẹlẹ lọ wọn a si le gbé igbesi aye ti o dara si. Efa ṣubu sinu idanwo; nipasẹ agbara rẹ, a mu Adamu dẹṣẹ. Wọn gba ọrọ ejo wipe Ọlọrun ko ni ṣe ohun ti O sọ, wọn ko gbẹkẹle Ẹlẹda wọn, wọn si ro wipe O n dí ominira wọn lọwọ ati wipe wọn le ni ọgbọn nla ati igbega nipa riru ofin Rẹ.ANN 237.3

    Ṣugbọn kini Adamu, lẹyin ẹṣẹ rẹ, ri wipe o jẹ itumọ ọrọ yii, “Ni ọjọ ti ẹyin ba jẹ ninu rẹ, kiku ni ẹyin yoo ku?” Ṣe o ri wipe o tumọ si ohun ti Satani jẹ ki wọn gbagbọ, wipe yoo mu wọn wọnu igbesi aye ti o ga si? À bá sọ wipe rere nla wà lati jere ninu ẹṣẹ, a ba si sọ wipe Satani ni ẹni ti o ṣe iran wa loore. Ṣugbọn Adamu ko ri eyi gẹgẹ bi itumọ ọrọ Ọlọrun. Ọlọrun sọ wipe gẹgẹ bi ijiya fun ẹṣẹ rẹ, eniyan yoo pada sinu ilẹ nibi ti a ti mu jade wa: “Erupẹ saa ni iwọ, iwọ o si pada di erupẹ.” Ẹsẹ 19. Awọn ọrọ Satani, “Oju yin yoo la,” jẹ ootọ ni abala kan ṣoṣo yii pe: Lẹyin ti Adamu ati Efa ṣe aigbọran si Ọlọrun, oju wọn ṣi silẹ lati ri iwa omugọ wọn; wọn mọ ibi wọn si jẹ eso kikoro ti aigbọran.ANN 237.4

    Ni aarin ọgba ni igi iye wa, eyi ti eso rẹ ni agbara lati muni wa laaye titi lae. Bi Adamu ba tẹsiwaju lati jẹ olugbọran si Ọlọrun ni, i ba ri aye, laisi idena si igi yii, i ba si wa laaye titi lae. Ṣugbọn nigba ti o dẹṣẹ, a ko gba a laaye lati jẹ ninu igi iye, o si di ẹni ti o n ku. Ọrọ Ọlọrun wipe, “Erupẹ ni iwọ, iwọ yoo si pada di erupẹ,” tọka si aisi ẹmi rara.ANN 237.5

    Aiku, ti a ṣeleri fun eniyan bi o ba ṣe igbọran, ni o padanu nipasẹ aigbọran. Adamu ko le fun awọn ọmọ rẹ ni ohun ti ko ni; ki ba ti si ireti fun iran ti o ṣubu yii bi Ọlọrun ko ba mu aiku wa si arọwọto wọn nipasẹ irubọ Ọmọ Rẹ. Nigba ti “iku kọja sori gbogbo eniyan, nitori gbogbo eniyan ni o saa ti ṣẹ,” Kristi “fi iye ati aiku han nipasẹ iyinrere.” Romu 5:12; 2 Timoti 1:10. Nipasẹ Kristi nikan ṣoṣo ni a fi le ni aiku. Jesu sọ wipe: “Ẹni ti o ba gbagbọ ninu Ọmọ o ni iye ainipẹkun: ẹni ti ko ba si gba Ọmọ gbọ ki yoo ri iye.” Johanu 3:36. Gbogbo eniyan ni o le ni ibukun ti a ko le diyele yii bi wọn yoo ba ṣe awọn ohun ti o beere fun. Gbogbo “awọn ti n fi suuru tẹsiwaju ninu iṣẹ rere n wa ogo ati ọla ati aiku,” yoo gba “iye ainipẹkun.” Romu 2:7.ANN 237.6

    Ẹnikan ṣoṣo ti o ṣeleri iye fun Adamu ninu aigbọran ni atannijẹ nla. Ọrọ ti ejo naa sọ fun Efa ni Edẹni—”Ẹyin ki yoo ku ikukiku kan”—ni iwaasu akọkọ ti a ṣe lori aiku ọkan eniyan. Sibẹ, gbolohun yii, ti o duro lori aṣẹ Satani nikan ṣoṣo, ni a n gbọ lori pẹpẹ iwaasu awọn Kristẹni, ti ọpọlọpọ eniyan si n gba a witiwiti bi awọn obi wa akọkọ ti gba a. Ọrọ mimọ ti o wipe, “Ọkan ti o ba ṣẹ ni yoo ku” (Isikiẹli 18:20), ni a tumọ si: Ọkan ti o ba ṣẹ ki yoo ku, ṣugbọn yoo wa titi lae. O ya wa lẹnu lati ri ifẹ ajeji ti o n mu ki ọkan eniyan o gbagbọ ninu ọrọ Satani ti wọn si jẹ alaigbagbọ ninu ọrọ Ọlọrun.ANN 238.1

    Bi o ba ṣe wipe eniyan ni anfani lati de ibi igi iye lẹyin ti o ṣubu ni, i ba wa laaye titi lae, bayi ni ẹṣẹ i ba ṣe wa titi lae pẹlu. Ṣugbọn awọn kerubu pẹlu ida ina sọ “ọna ti o lọ si ibi igi iye” (Jẹnẹsisi 3:24), ko si si ọkan ninu idile Adamu ti a gba laaye lati kọja idena yii lati le jẹ ninu eso ti n funni ni iye yii. Nitori naa, ko si ẹlẹṣẹ ti o wa laaye titi.ANN 238.2

    Ṣugbọn lẹyin iṣubu, Satani rọ awọn angẹli rẹ lati ṣe akitiyan pataki lati kọni ni igbagbọ wipe pẹlu bi a ṣe da eniyan, ko le ku; nigba ti a si ti mu ki eniyan o gba eke yii, a mu ki wọn gbagbọ wipe ẹlẹṣẹ yoo gbe titi lae ninu ijiya. Ọmọ alade okunkun n ṣiṣẹ nipasẹ awọn aṣoju rẹ, o n fi Ọlọrun han gẹgẹ bi onroro ti o fẹ gbẹsan ni sisọ wipe gbogbo awọn ti ko ṣe ifẹ Rẹ ni O n dàsí ọrun apaadi, yoo mu ki wọn mọ ibinu Oun nigba ti wọn ba n jẹrora ti a ko le fẹnu sọ ti wọn n runra ninu ina ayeraye, Ẹlẹda wọn a wo wọn pẹlu itẹlọrun.ANN 238.3

    Bayi ni ọta nla nì ṣe fi iwa rẹ ṣe alaye Ẹlẹda ati Oninurere fun gbogbo eniyan. Satani ni o ni iwa ika. Ifẹ ni Ọlọrun; ohun gbogbo ti O da mimọ, ailabawọn, ati daradara ni ki oluṣọtẹ nla akọkọ to mu ẹṣẹ wa. Satani funra rẹ ni ọta ti o n dan eniyan wo lati dẹṣẹ, yoo wa paarun bi o ba le ṣe bẹẹ; nigba ti ọwọ rẹ ba ba ẹni ti n jiya lọwọ rẹ tan, inu rẹ a dun nitori iparun ti o mu wa. Bi a ba gba a laaye, a rọ gbogbo aye yii da sinu awọn rẹ. Bi ki i ba n ṣe nitori iranlọwọ agbara Ọlọrun, ko si ọmọkunrin tabi ọmọbinrin Adamu ti i ba sa asala.ANN 238.4

    Satani n wọna lati bori awọn eniyan loni, gẹgẹ bi o ti bori awọn obi wa akọkọ, nipa mími igbẹkẹle wọn ninu Ẹlẹda wọn ki o si dari wọn lati ṣeyemeji nipa ọgbọn ijọba Rẹ ati ododo awọn ofin Rẹ. Satani ati awọn aṣoju rẹ fi Ọlọrun han bi ẹni ti o buru ju awọn funra wọn lọ, lati le da iwa ika ati iṣọtẹ wọn lare. Atannijẹ nla naa n ṣe akitiyan lati ti iwa ika rẹ si ori Baba wa ọrun, ki o le fi ara rẹ han gẹgẹ bi ẹnipe a ṣẹ ẹ nipa lile kuro ni ọrun nitori pe o kọ lati ṣe igbọran si adari ti ko dara. O fi ominira ti wọn a gbadun labẹ iṣakoso rere oun han araye, ni idakeji si ihamọ ti ofin onroro Jehofa fini si. Ni ọna yii o ṣe aṣeyọri lati tan awọn ọkan jẹ kuro ninu igbọran wọn si Ọlọrun.ANN 238.5

    Ikọni wipe a n jẹ awọn ẹni buburu ti wọn ti ku niya pẹlu ina ati sulfuru ninu ina ọrun apaadi ti n jo titi lae ti tako ero wa nipa ifẹ ati aanu, ani idajọ tó; wipe fun ẹṣẹ igba perete ti wọn gbe ninu aye, wọn yoo jiya inira titi ti Ọlọrun a fi wa laaye. Sibẹ, a n kọni ni ẹkọ yii kaakiri, o si maa n wa ninu ijẹwọ igbagbọ ọpọ ijọ ẹsin Kristẹni. Ọmọwe ninu ẹkọ nipa Ọlọrun kan sọ wipe: “Ijiya inu ina apaadi a mu ki inu awọn eniyan mimọ o dun titi lae. Nigba ti wọn ba ri awọn miran ti wọn ni iṣẹda kan naa, ti a bi sinu ipo kan naa, ninu iru ijiya bayii, ti a si wa yà wọn sọtọ, yoo jẹ ki wọn mọ bi inu wọn ti dun to.” Omiran sọ bayii: “Nigba ti idajọ idalẹbi ba n lọ titi lae lori awọn ohun elo ibinu, eefin ijiya wọn a maa lọ soke niwaju awọn ohun elo aanu titi lae, dipo ki wọn wa ninu awọn ohun elo ijiya yii, wọn a sọ pe, Amin, Aleluya, ẹ yin Oluwa.”ANN 238.6

    Nibo ninu ọrọ Ọlọrun ni a tile ri iru ikọni yii? Ṣe awọn ti a rapada ni ọrun a padanu gbogbo ero ikẹdun ati ikaanu ati ero wipe eniyan ni gbogbo wa ni? Ṣe wọn a padanu awọn nnkan wọnyi lati le fi ainikẹdun tabi onroro ika rọpo ni? Rara, rara o; eyi ki i ṣe ikọni Iwe Ọlọrun. Awọn ti wọn sọ ayọka to wa loke yẹn le jẹ ọmọwe ati olotitọ eniyan, ṣugbọn a tan wọn jẹ nipa arekereke Satani. O dari wọn lati ṣi ọrọ ti o han kedere ninu Iwe Mimọ tumọ, wọn n fun ni alaye ikoro ati ika ti ki i ṣe ti Ẹlẹda wa bikoṣe ti ara rẹ. “Bi mo ti wa laaye ni Oluwa wi, Emi ko ni inu didun ninu iku ẹlẹṣẹ, ṣugbọn ki ẹlẹṣẹ o yipada kuro ninu ọna rẹ ki o si ye: ẹ yipada, ẹ yipada kuro ninu ọna buburu yin, eese ti ẹyin o fi ku?” Isikiẹli 33:11.ANN 238.7

    Kini Ọlọrun a jere bi a ba gba wipe inu Rẹ dun si iriri ijẹniniya ti ko lopin, wipe inu Rẹ a dun ti o ba gbọ irora, igbe gooro, ati egun awọn eda ti n jiya ti O fi sinu ina apaadi? Ṣe awọn ariwo ti o banilẹru wọnyi le jẹ orin ni eti Ifẹ Ailopin? A n sọ wipe fifi awọn ẹlẹṣẹ jiya ailopin yoo fi bi Ọlọrun ti korira ẹṣẹ han gẹgẹ bi iwa ibi ti o le ko ibajẹ ba ayọ ati eto inu gbogbo agbaye. Ha, isọrọ odi yii ti buru to! A fi bi ẹnipe ikorira Ọlọrun fun ẹṣẹ ni yoo jẹ idi ti yoo fi wa titi lae. Nitori gẹgẹ bi ikọni awọn ẹlẹkọ nipa Ọlọrun yii, ijiya ailopin laisi ireti aanu yoo bi awọn ti a n jẹ niya ninu, bi wọn si ti n fi ibinu wọn han pẹlu egun ati ọrọ odi, bẹẹ ni a maa fikun ẹru ẹbi wọn titi aye. Fifikun ẹṣẹ titi aye ko fi ogo fun Ọlọrun.ANN 239.1

    O kọja agbara oye eniyan lati ṣiro ibi ti ẹkọ odi ijiya titi lae yii ti fa. Ẹsin Bibeli, ti o kun fun ifẹ ati iwa rere, ti o pọ ni ikaanu, ni a fi aimọkan ṣu okunkun bo ti a si wọ ni aṣọ ẹru jẹjẹ. Nigba ti a ba wo ọna eke ti Satani gba lati fi iwa Ọlọrun han, njẹ o yẹ ki o ya wa lẹnu idi ti a fi n bẹru, paya, ti a tun n korira Ẹlẹda alaanu wa? Igbagbọ nipa Ọlọrun gẹgẹ bi Ẹni ti O panilaya ti o tan kaakiri gbogbo aye lati ara ikọni lati ori pẹpẹ iwaasu ti sọ ọpọlọpọ di oniyemeji ati alaigbagbọ.ANN 239.2

    Igbagbọ ijiya ayeraye jẹ ọkan lara awọn ẹkọ eke ti wọn para pọ di ọti waini irira Babiloni, eyi ti o mu ki gbogbo orilẹ ede mu ninu rẹ. Ifihan 14:8; 17:2. Wipe awọn iranṣẹ Kristi le gba ẹkọ odi yii ki wọn tun waasu rẹ lati ori pẹpẹ mimọ jẹ ohun ijinlẹ lootọ. Wọn gba a lati ọdọ Romu gẹgẹ bi wọn ti gba ọjọ isinmi eke. Lootọ awọn eniyan nla ati eniyan rere ti fi kọni; ṣugbọn imọlẹ lori koko ọrọ yii ko tan si wọn gẹgẹ bi o ti tan si wa. Wọn ni ojuṣe fun imọlẹ ti o tan ni akoko wọn; a ni ojuṣe fun eyi ti o tan ni akoko wa. Bi a ba yiju kuro ni ara ẹri ọrọ Ọlọrun, ti a wa gba ẹkọ eke nitori pe awọn baba wa fi kọni, a ṣubu si abẹ idalẹbi ti a ṣe sori Babiloni, a n mu ninu waini irira rẹ.ANN 239.3

    Ẹgbẹ nla kan wa ti ikọni ijiya ainipẹkun yii ko ni irira, ti wọn si bọ sinu aṣiṣe miran ni idakeji. Wọn ri wipe Iwe Mimọ ṣe alaye Ọlọrun gẹgẹ bi Ẹni ti o kun fun ifẹ ati aanu, wọn ko si le gbagbọ wipe yoo ju awọn ẹda ọwọ Rẹ sinu ina ajooku ọrun apaadi. Ṣugbọn ni gbigbagbọ wipe ọkan ko le ku, wọn ko ri ọna miran ju ki wọn gbagbọ wipe gbogbo eniyan ni a o gbala nikẹyin lọ. Ọpọ ni wọn ri awọn ikilọ Bibeli gẹgẹ bi ohun ti a ṣe lati dẹruba awọn eniyan lati le ṣe igbọran lasan ati wipe wọn ko ni wa si imuṣẹ bi a ti sọ ọ. Nipa eyi ẹlẹṣẹ le maa gbe ninu faaji imọti-ara-ẹni-nikan, ki o ma ka aṣẹ Olorun si, sibẹ ki o maa reti lati ri oju rere nikẹyin. Iru ikọni yii ti o tẹ aanu Ọlọrun loju, ṣugbọn ti ko bikita nipa ododo Rẹ, tẹ ọkan ti ko ni iyipada lọrun, o si n jẹ ki ẹlẹṣẹ o tẹsiwaju ninu ẹṣẹ.ANN 239.4

    Lati fihan bi awọn onigbagbọ ninu igbala gbogbo eniyan ti lọ Iwe Mimọ lọrun lati fi idi ikọni ti n pa ọkan run wọn mulẹ, o ṣe pataki ki a ka ninu ọrọ wọn. Nibi isinku ọdọmọkunrin ti ko lẹsin kan, ti o ku lọgan ninu ijamba kan, oniwaasu ti o gbagbọ ninu igbala gbogbo aye kan kà lati inu Iwe Mimọ gẹgẹ bi ẹsẹ rẹ, ọrọ kan nipa Dafidi: “O si gba ipẹ ni ti Amnoni: o saa ti ku.” 2 Samuẹli 13:39.ANN 239.5

    Oniwaasu naa sọ pe, “A saba maa n bi mi leere wipe, kini yoo jẹ atubọtan awọn ti wọn ku ninu ẹṣẹ boya ninu iwa ọmuti, ti wọn ku pẹlu abawọn iwa ọdaran ti a ko fọ mọ kuro ninu aṣọ wọn, tabi ti wọn ku bi ọdọmọkunrin yii ti ku laijẹwọ tabi jẹ igbadun iriri ẹsin. A faramọ Iwe Mimọ; idahun rẹ yoo mu iṣoro nla naa kuro. Amnoni jẹ ẹlẹṣẹ paraku; ko ronupiwada, a rọ ọ ni ọti yo, ninu ipo yii si ni a ti pa a. Dafidi jẹ woli Ọlọrun, o gbọdọ mọ boya yoo dara fun Amnoni tabi ko ni dara fun ninu aye ti n bọ. Ki ni o wa ninu ọkan rẹ? ‘Ọkan ọba Dafidi si fa gidigidi si Absalomu: nitori o ti gba ipẹ ni ti Amnoni: o saa ti ku.’ Ẹsẹ 39.ANN 239.6

    “Kini a wa le fayọ lati inu ede yii? Ṣe ki i ṣe wipe ijiya ailopin ko si lara igbagbọ ẹsin rẹ bi? Bẹẹ ni a ṣe ro; nibi a ri idahun iṣẹgun ni atilẹyin fun ẹkọ ti o dunmọni ninu julọ, ti o ni ilalọyẹ julọ, ti o si ṣeni loore julọ ti iwa mimọ ati alaafia gbogbo aye nikẹyin. O gba ipẹ nitori pe ọmọ rẹ ti ku. Ki lo de ti o fi ri bẹ? Nitori pe pẹlu oju aṣọtẹlẹ o wo ọjọ iwaju ti o logo, o si ri ọmọ naa ti o jinna rere si gbogbo idanwo, a yọ kuro ninu igbekun a si fọ ọ mọ kuro ninu idibajẹ ẹṣẹ, lẹyin ti a sọ ọ di mimọ, ti a si laalọyẹ tan, a gba a si awujọ awọn ẹmi ti wọn ti goke lọ ti n yọ. Itunu rẹ kan ṣoṣo ni wipe, ni mimu kuro ninu aye ẹṣẹ ati ijiya yii, ọmọ rẹ ti o fẹran ti lọ si ibi ti eemi Ẹmi Mimọ ti o dara julọ a ti mi si ọkan ti o ṣokunkun, nibi ti iye rẹ a ti ṣi si ọgbọn ọrun ati idunnu ifẹ ailopin, nipa eyi, a pese rẹ silẹ pẹlu ara ti a ti ya si mimọ lati le jẹgbadun isinmi ati awujọ ajogunba ti ọrun.ANN 239.7

    “Ninu awọn ero yii a fẹ ki a mọ wipe igbala ọrun ko duro lori ohunkohun ti a le ṣe ninu aye yii; boya lori ọkan ti a ti yipada nisinsinyii, tabi igbagbọ ti isinsinyii, tabi igbagbọ ninu ẹsin ti isinsinyii.”ANN 240.1

    Bayi ni ẹni ti o pe ara rẹ ni iranṣẹ Kristi ṣe n ṣe atunsọ irọ ti ejo naa pa ni Edẹni: “Ẹyin ki yoo ku ikukiku kan.” “Ni ọjọ naa ti ẹyin ba jẹ ninu rẹ, oju yin yoo la, ẹyin yoo si dabi Ọlọrun.” O sọ wipe eyi ti o buru julọ ninu awọn ẹlẹṣẹ—apaniyan, ole, ati alagbere—yoo ri atunṣe lẹyin iku lati le wọ inu igbadun ainipẹkun.ANN 240.2

    Nibo ni ayi-Iwe Mimọ lọrun yii ti ri idahun rẹ? Lati inu ẹsẹ kan ṣoṣo ti o sọ nipa bi Dafidi ti gba f‘Ọlọrun. Ọkan rẹ “fa si Absalomu gidigidi; nitori ti o gba ipẹ ni ti Amnoni, nitori ti o ti ku.” Nigba ti akoko ti sẹ ẹdun ọkan rẹ rọ, ero rẹ yi kuro lati ara oku wa si alaaye ọmọ ti o sa kuro nile funra rẹ nitori ibẹru ijiya ti o tọ si iwa ọdaran rẹ. Eyi jẹ ẹri wipe, aba-ọmọ-baba-ẹni-sun, ọmuti Amnoni ti lọ si ibi igbadun lọgan lẹyin iku rẹ, nibi ti a o ti fọ ọ mọ ti a o si pese rẹ silẹ fun ibapejọpọ awọn angẹli alailẹṣẹ! Arosọ didun ni lootọ lati tẹ ọkan ti ko yipada lọrun! Ikọni Satani funra rẹ ni eleyi, o si n ṣe ifẹ rẹ daradara. Njẹ o yẹ ki o yawa lẹnu wipe iwa ibajẹ pọ si pẹlu iru iwaasu bayii?ANN 240.3

    Ohun ti ẹlẹko eke yii ṣe jẹ apẹẹrẹ ohun ti ọpọ awọn miran maa n ṣe. A yọ ẹsẹ diẹ ninu Iwe Mimọ kuro ni aye wọn, eyi ti i ba fihan wipe itumọ wọn yatọ patapata si eyi ti wọn fun; iru awọn ẹsẹ ti a le yẹ lẹsẹ bayi ti a lọ lọrun ni a wa n lo lati gbe ikọni ti ko ni ipilẹ ninu ọrọ Ọlọrun lẹsẹ. Ẹri ti a lo lati fi sọ wipe Amnoni ọmuti wa ni ọrun jẹ eyi ti o tako gbolohun Iwe Mimọ ti o han kedere wipe ko si ọmuti kan ti yoo jogun ijọba Ọlọrun. 1 Kọrintin 6:10. Bayi ni awọn oniyemeji, alaigbagbọ ati oniyemeji ẹsin ṣe n yi otitọ pada di irọ. Ti a si n tan ọpọlọpọ jẹ nipasẹ arekereke wọn ti a si jẹ ki wọn sun sinu aabo ẹran ara.ANN 240.4

    Bi o ba jẹ otitọ wipe ọkan gbogbo eniyan n lọ taara si ọrun lẹyin iku, i ba jẹ ohun ti o dara bi a ba feran iku ju ki a wa laaye lọ. Ọpọlọpọ ni ikọni yii ti mu ki wọn ṣe iku pa ara wọn. Nigba ti wahala, idamu ati ijakulẹ ba bo wọn mọlẹ, o dabi ẹnipe ohun ti o rọrun ni lati da ẹmi ẹni legbodo ki eniyan si goke lọ sinu igbadun aye ainipẹkun.ANN 240.5

    Ọlọrun ti funni ni ẹri ti a ko le ṣe aṣiṣe rẹ ninu ọrọ Rẹ wipe oun yoo jẹ awọn ti wọn ru ofin Rẹ niya. Awọn ti wọn sọ ọrọ didun si ara wọn wipe O jẹ alaanu ju ki O ṣe idajọ lori ẹlẹṣẹ lọ tilẹ nilati wo agbelebu Kalfari lasan ni. Iku Ọmọ Ọlọrun alailabawọn jẹri si wipe “iku ni ere ẹṣẹ,” wipe gbogbo titẹ ofin Ọlọrun loju ni yoo gba idajọ ti o tọ si. Kristi ti ko lẹṣẹ di ẹṣẹ fun eniyan. O ru ẹbi ẹṣẹ, bi Baba Rẹ ti gbe oju Rẹ pamọ kuro ni ọdọ Rẹ titi ti ọkan Rẹ fi bajẹ, ti O si ku, a ṣe gbogbo irubọ yii ki a baa le ra ẹlẹṣẹ pada. Ko si ọna miran ti a fi le da eniyan lare kuro ninu ijiya ẹṣẹ. Gbogbo ọkan ti o ba si kọ lati kopa ninu iwẹnumọ ti a ti ṣe pẹlu ohun iyebiye naa yoo funra rẹ ru ẹbi ati ijiya ẹṣẹ.ANN 240.6

    Ẹ jẹ ki a wò siwaju si ohun ti Bibeli fi kọni nipa awọn alaiwabiọlọrun ati awọn ti ko ronupiwada, awọn ti ẹni ti o gbagbọ ninu igbala gbogbo aye fi si ọrun gẹgẹ bi angẹli mimọ, alayọ.ANN 240.7

    “Emi yoo fun ẹni ti ongbẹ n gbẹ lati inu orisun omi iye lọfẹ.” Ifihan 21:6. Awọn ti ongbẹ ba n gbẹ nikan ni a ṣe ileri yii fun. Awọn ti wọn ba mọ wipe wọn nilo omi iye nikan, ti wọn wa laika ohun miran si ni a o fun. “Ẹni ti o ba ṣẹgun ni yoo jogun ohun gbogbo; Emi yoo si jẹ Ọlọrun rẹ, oun yoo si jẹ ọmọ Mi.” Ẹsẹ 7. Nibi pẹlu, a ṣe alaye ojuṣe eniyan. Lati le jogun ohun gbogbo, a nilati doju ija kọ ẹṣẹ, ki a si ṣẹgun rẹ.ANN 240.8

    Oluwa sọ nipasẹ woli Aisaya wipe: “Sọ fun olododo wipe yoo dara fun.” “egbe ni fun ẹni ibi! ki yoo dara fun: nitori ti a o fi ere iṣẹ ọwọ rẹ fun.” Aisaya 3:10, 11. “Bi ẹlẹṣẹ ba wuwa buburu ni ọgọrun igba,” ọlọgbọn ni sọ wipe, “ti o si wa laaye fun igba pipẹ, sibẹ, mo mọ daju wipe yoo dara fun awọn ti wọn bẹru Ọlọrun, ti wọn bẹru niwaju Rẹ: ṣugbọn ki yoo dara fun eniyan buburu.” Oniwaasu 8:12, 13. Pọlu pẹlu jẹri wipe ẹlẹṣẹ n pa “ibinu mọ” funra rẹ “di ọjọ ibinu ati ifihan idajọ ododo Ọlọrun; Ẹni ti yoo fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ;” “wahala ati iporuuru ọkan fun gbogbo ọkan ti o ba wuwa buburu.” Romu 2:5, 6, 9.ANN 241.1

    “Ko si alagbere, tabi alaimọ, tabi oloju kokoro, ti i ṣe abọriṣa, ti yoo ni ipin kan ninu ijọba Kristi ati ti Ọlọrun wa.” Efesu 5:5. “Ẹ maa lepa alaafia pẹlu gbogbo eniyan, ati iwa mimọ laisi eyi, ko si ẹni ti yoo ri Oluwa.” Heberu 12:14. “Ibukun ni fun awọn ti wọn ṣe ofin Rẹ ki wọn le ni ẹtọ si igi iye, ki wọn si le gba ẹnu ọna wọ inu ilu naa. Nitori ni ita ni awọn aja, ati oṣo, ati alagbere, ati apaniyan, ati abọriṣa, ati gbogbo ẹni ti o fẹran ti o si n ṣe eke gbe wa.” Ifihan 22:14, 15.ANN 241.2

    Ọlọrun ti fi iwa Rẹ ati ọgbọn ti yoo fi mu ẹṣẹ kuro nilẹ han eniyan. “Oluwa Ọlọrun, alaanu ati oloore ọfẹ, onipamọra ti o pọ ni oore ati otitọ, ti n pa aanu mọ fun ẹgbẹẹgbẹrun, ti n dari aiṣedeede ati irekọja ati ẹṣẹ ji, ti ki yoo si jẹ ki ẹlẹbi o lọ lọfẹ.” Eksodu 34:6, 7. “Gbogbo awọn eni ibi ni yoo parun.” “Ṣugbọn awọn onirekọja ni a o parun pọ: opin awọn eniyan buburu ni a o ge kuro.” O. Dafidi 145: 20; 37:38. A o lo agbara ati aṣẹ ijọba Ọlọrun lati ṣe iṣọtẹ rọ; sibẹ gbogbo idajọ ni yoo wa ni ibamu pipe pẹlu iwa Ọlọrun gẹgẹ bi alaanu, onipamọra ati oloore ọfẹ.ANN 241.3

    Ọlọrun ko ni fi ipa mu ẹnikẹni. Ko ni inudidun si ki a ṣe igbọran bi ẹru. O fẹ ki ẹda ọwọ Rẹ o fẹran Oun nitori pe O tọ si ifẹ rẹ. A fẹ ki wọn fẹran Oun nitori pe wọn ni oye ọgbọn, ododo ati aanu Oun. Gbogbo awọn ti wọn ba si ni oye ti o tọ nipa awọn iwa wọnyi a fẹran Rẹ nitori pe a fa wọn sọdọ Rẹ nitori ti wọn fẹran awọn iwa yii.ANN 241.4

    Ipilẹ iwa ti inu rere, aanu ati ifẹ ti Olugbala wa fi kọni ti o si fi ara han ninu iwa Rẹ jẹ ifihan ifẹ ati iwa Ọlọrun. Kristi sọ wipe Oun ko kọni ni ohun kan ayafi eyi ti Oun gba lati ọdọ Baba. Ipilẹ ijọba Ọlọrun wa ni ibamu pẹlu ilana Olugbala, “Ẹ fẹran awọn ọta yin.” Ọlọrun ṣe idajọ lori awọn ẹni buburu nitori rere gbogbo agbaye ni, ani fun rere awọn ti a ṣe idajọ Rẹ le lori. I ba mu inu wọn dun bi O ba le ṣe bẹẹ ni ibamu pẹlu ofin ijọba ati ododo iwa Rẹ. O fi apẹẹrẹ ifẹ Rẹ yi wọn ká, o fun wọn ni oye ofin Rẹ, O si n fi ipe aanu Rẹ tẹle wọn kiri; ṣugbọn wọn kẹgan ifẹ Rẹ, wọn sọ ofin Rẹ di asan, wọn si kọ aanu Rẹ silẹ. Nigba ti wọn n gba ẹbun Rẹ nigba gbogbo, wọn n tabuku Ẹni ti n funni ni ẹbun; wọn korira Ọlọrun nitori ti wọn mọ wipe O korira ẹṣẹ wọn. Oluwa fi ara da iwa aitọ wọn fun igba pipẹ, ṣugbọn akoko ipinu yoo de nikẹyin, ti a o ṣe ipinu lori gbogbo atubọtan wọn. Ṣe yoo wa so awọn ọlọtẹ yii mọ ẹgbẹ Rẹ bi? Ṣe yoo fi ipa mu wọn lati ṣe ifẹ Rẹ?ANN 241.5

    Awọn ti wọn ti yan Satani gẹgẹ bi adari wọn, ti o si jẹ wipe agbara rẹ ni o n dari wọn ko ṣetan lati wa siwaju Ọlọrun. Igberaga, ẹtan, ainiwọntuwọnsi, iwa ika ti duro sinu iwa wọn. Ṣe wọn le wọ ọrun lati gbe titi lae pẹlu awọn ti wọn ti gàn, ti wọn si korira ninu aye? Onirọ ko le wa ni ibamu pẹlu otitọ laelae, irẹlẹ ko ni tẹ ikara-ẹni-si ati igberaga lọrun, iwa mimọ ko le fi ara da iwa ibajẹ, ifẹ ainimọ-ti-ara-ẹni-nikan ko le wu ifẹ ti ara-ẹni-nikan. Iru orisun igbadun wo ni ọrun le fun awọn ti wọn ti fi ara wọn jin fun ifẹ aye ati imọ-ti-ara-ẹni-nikan.ANN 241.6

    Ṣe a le dede gbe awọn ti wọn gbe igbesi aye wọn ni iṣọtẹ si Ọlọrun sinu ọrun lati ri iwa pipe ati iwa mimọ to n gbe nibẹ,—gbogbo ọkan ti o kun fun ifẹ, gbogbo oju ti o n tan pẹlu ayọ, ti orin didun si n lọ soke fun iyin Ọlọrun ati Ọdọ Aguntan, ti ọwọ imọlẹ ailopin n tan si ori awọn ti a gbala lati oju Ẹni ti o joko si ori itẹ,—ṣe ọkan awọn ti o kun fun ikorira Ọlọrun, otitọ ati iwa mimọ, le darapọ mọ awọn ero ọrun lati kọ orin iyin wọn? Ṣe wọn le fi ara da ogo Ọlọrun ati ti Ọdọ Aguntan? Rara, rara: a fun wọn ni akoko aanu, ki wọn fi le ni iwa ọrun; ṣugbọn wọn ko kọ ọkan wọn lati ni ifẹ iwa mimọ; wọn ko kọ ede ọrun, bayii o ti pẹ ju. Igbesi aye iṣọtẹ si Ọlọrun ko jẹ ki wọn yẹ fun ọrun. Iwa ailabawọn rẹ, iwa mimọ ati alaafia rẹ yoo jẹ ijiya fun wọn; ogo Ọlọrun yoo jẹ ina ajonirun. Wọn a fẹ lati sa kuro ni ibi mimọ naa. Wọn a fẹran iparun, ki a ba le pa wọn mọ kuro ni oju Ẹni ti o ku lati ra wọn pada. Awọn eniyan buburu ni wọn funra wọn yan atubọtan wọn. Bi a ko ti ṣe gba wọn si ọrun jẹ ohun ti wọn yan funra wọn, eyi si jẹ ipinu ododo ati aanu bi a ba wo o lati ọdọ Ọlọrun.ANN 241.7

    Bi àgbàrá ikun omi, ina ọjọ nla naa kede idajọ Ọlọrun wipe awọn ẹni buburu ko ṣe e wosan. Wọn ko ni iwa lati tẹriba fun aṣẹ Ọlọrun. Wọn lo ifẹ wọn fun iṣọtẹ, nigba ti aye si pari, o ti pẹ ju fun wọn lati yi iṣọwọronu wọn pada si idakeji, lati yipada kuro ninu irekọja si igbọran, lati inu ikorira si ifẹ.ANN 242.1

    Ni dida Keeni apaniyan si, Ọlọrun fun araye ni apẹẹrẹ ohun ti yoo jẹ ayọrisi dida ẹlẹṣẹ si lati tẹsiwaju ninu igbesi aye aiṣedeede lainijanu. Nipasẹ ikọni ati apẹẹrẹ Keeni, a dari ọpọlọpọ awọn ọmọ rẹ sinu ẹṣẹ titi ti “iwa buburu eniyan fi pọ lori ilẹ aye” ti “gbogbo ero inu ọkan rẹ si jẹ kiki da ibi lojojumọ.” “Aye pẹlu ti dibajẹ niwaju Ọlọrun, aye si kun fun iwa ipa.” Jẹnẹsisi 6:5, 11.ANN 242.2

    Ninu aanu si aye, Ọlọrun pa awọn eniyan buburu rẹ rẹ ni akoko Noah. Ninu aanu, O pa awọn oniwa ibajẹ ninu Sodomu run. Nipasẹ agbara itanjẹ Satani awọn ti n ṣiṣẹ ẹṣẹ n ri ikaanu ati igboriyin, bayi ni wọn ṣe n dari awọn miran sinu iṣọtẹ. Bi o ṣe ri niyi ni akoko Keeni ati Noah, ati ni akoko Abrahamu ati Lọti, bẹẹ ni o ṣe ri ni akoko wa. Ninu aanu si gbogbo aye ni Ọlọrun yoo pa awọn ti wọn kọ oore ọfẹ Rẹ silẹ run nikẹyin.ANN 242.3

    “Iku ni ere ẹṣẹ; ṣugbọn ẹbun ọfẹ Ọlọrun ni iye ainipẹkun nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa.” Romu 6:23. Nigba ti iye jẹ ipin awọn olododo, iku ni ipin awọn ẹni buburu. Mose sọ fun awọn ọmọ Israeli wipe: “Mo gbe ire ati iye, iku ati ibi ka iwaju yin loni.” Deutaronomi 30:15. Iku ti a n sọ nibi ki i ṣe eyi ti a pe sori Adamu, nitori gbogbo eniyan ni o n jiya ijiya irekọja rẹ. “Iku keji” ni, eyi ti a gbe kalẹ ni atako si iye ainipẹkun.ANN 242.4

    Ni ayọrisi si ẹṣẹ Adamu, iku rekọja wa sori gbogbo eniyan. Gbogbo eniyan ni wọn n kọja lọ sinu iboji. Ati nipasẹ ipese eto igbala, a o mu gbogbo eniyan jade wa lati inu iboji wọn. “Ajinde oku yoo wa, ati ti olododo ati ti alaiṣododo;” “nitori ninu Adamu gbogbo eniyan n ku, bẹẹ gẹgẹ, ninu Kristi a o sọ gbogbo eniyan di alaaye.” Iṣe 24:15; 1 Kọrintin 15:22. Ṣugbọn a ṣe iyatọ si aarin awọn ẹgbẹ mejeeji ti a mu jade wa. “Gbogbo awọn ti wọn wa ninu iboji yoo gbọ ohùn Rẹ, wọn yoo si jade wa; awọn ti wọn ṣe rere, si ajinde iye; ati awọn ti wọn ṣe buburu si ajinde idalẹbi.” Johanu 5:28, 29. Awọn ti a “ka ye” fun ajinde iye jẹ “alabukun fun ati mimọ.” “Ni ori awọn wọnyi, iku keji ko lagbara.” Ifihan 20:6. Ṣugbọn awọn ti ko ri idariji gba nipasẹ ironupiwada ati igbagbọ yoo gba ijiya irekọja—”ere ẹṣẹ.” Wọn yoo jiya ti o yatọ si ara wọn ni pipẹ ati ni bi o ti lagbara to, “gẹgẹ bi iṣẹ wọn,” ṣugbọn ni ikẹyin, yoo yọri si iku keji. Nigba ti ko ṣe e ṣe fun Ọlọrun, ni ibamu pẹlu idajọ ati aanu Rẹ, lati gba ẹlẹṣẹ la ninu ẹṣẹ rẹ, O mu ẹmi rẹ kuro eyi ti irekọja rẹ mu ki o padanu, ati eyi ti oun funra rẹ fihan wipe ko tọ si oun. Onkọwe ti a misi kan sọ pe: “Ni igba diẹ si, awọn eniyan buburu ki yoo si: bẹẹni iwọ yoo wá àyè rẹ finifini, ki yoo si si.” Omiran tun sọ pe: “Wọn yoo dabi ẹnipe wọn ko wa laaye ri.” O. Dafidi 37:10. Obadaya 16. Pẹlu ẹgan ti o yi wọn ka, wọn a tẹri sinu okunkun ayeraye laini ireti.ANN 242.5

    Bayi ni ẹṣẹ yoo ṣe pari, pẹlu gbogbo iṣoro ati iparun ti o ti ipa rẹ wa. OniO. Dafidi sọ wipe: “Iwọ pa awọn eniyan buburu run, Iwọ pa orukọ wọn rẹ lae ati laelae. Ah iwọ ọta, iparun de opin ayeraye.” O. Dafidi 9:5, 6. Johanu ninu Ifihan wo ọjọ iwaju ni igba ainipẹkun, o gbọ orin iyin ni gbogbo agbaye ti ko si si idiwọ kan. A gbọ ti gbogbo ẹda ni ọrun ati aye n fi ogo fun Ọlọrun. Ifihan 5:13. Ko ni si ọkan ti o ṣegbe kankan ti yoo tabuku Ọlọrun bi o ti n yan ninu ijiya ailopin; ko si ẹni abuku kan ninu ina apaadi ti yoo da igbe rẹ pọ mọ orin awọn ẹni ti a gbala.ANN 242.6

    Lori aṣiṣe wipe a da eniyan pẹlu aiku ni ikọni wipe eniyan mọ nnkan ninu iku duro le lori—ikọni bi i ti ijiya ainipẹkun, ti o tako awọn ikọni Iwe Mimọ, si ironu eniyan, ati imọlara wa gẹgẹ bi eniyan. Gẹgẹ bi igbagbọ ti o wọpọ, awọn ti a ra pada ni ọrun mọ gbogbo ohun ti n ṣẹlẹ lori ilẹ aye paapa julọ nipa igbesi aye awọn ọrẹ wọn ti wọn fi silẹ. Ṣugbọn bawo ni yoo ṣe jẹ orisun ayọ fun awọn ti wọn ti ku lati mọ wahala awọn alaaye, lati ri ẹṣẹ ti awọn ti wọn fẹran n da, ki wọn si ri bi wọn ti n fi ara da gbogbo ibanujẹ, ijakulẹ, ati irora aye yii? Igbadun melo ni awọn ti n rababa lori awọn ọrẹ wọn laye a maa gbadun ni ọrun? Igbagbọ wipe lọgan ti eemi ba ti fi ara silẹ, a a sọ ọkan alaigbagbọ sinu ina ọrun apaadi ti ṣi ni lara to! Irora ọkan awọn ti wọn n ri ọrẹ wọn ti n kọja lọ sinu iboji ni aimurasilẹ, lati wọ inu ayeraye idamu ati ẹṣẹ a ti pọ to! Ọpọ ni wọn ti di aṣiwere nitori ero ayọnilẹnu yii.ANN 243.1

    Kini Iwe Mimọ sọ nipa awọn nnkan wọnyi? Dafidi sọ wipe eniyan ko mọ nnkankan ninu ipo oku. “Eemi rẹ jade lọ, o pada di erupẹ rẹ: ni ọjọ naa gan ni ero rẹ ṣegbe.” O. Dafidi 146:4. Solomoni ṣe iru ijẹri kan naa: “Alaaye mọ wipe oun yoo ku: ṣugbọn oku ko mọ ohun kan.” “Ifẹ wọn, ati ikorira wọn, ati arankan wọn ti ṣegbe; bẹẹ ni wọn ko ni ini kankan mọ titi aye ninu ohun gbogbo ti a n ṣe labẹ ọrun.” “Ko si iṣẹ tabi ète tabi imọ tabi ọgbọn ninu ipo oku, nibi ti iwọ n lọ.” Oniwaasu 9:5, 6, 10.ANN 243.2

    Ni idahun si adura rẹ, nigba ti a fi ọdun marundinlogun kun igbesi aye Isikaya. Ọba naa fi imoore rẹ han nipa kikọ orin iyin si Ọlọrun fun aanu nla Rẹ. Ninu orin rẹ, o sọ fun wa idi ti oun fi n yọ bẹẹ: “Isa oku ko le fi iyin fun Ọ; iku ko le ṣe iranti Rẹ: awọn ti wọn n lọ sinu koto ko le reti fun otitọ Rẹ. Alaaye, alaaye, ni yoo yin Ọ, bi mo ti n ṣe loni yii.” Aisaya 38:18, 19. Igbagbọ ti o wọpọ loni fi awọn oku olododo han bi ẹnipe wọn wa ni ọrun, wọn wọ inu adun, wọn si n yin Ọlọrun pẹlu ahọn ainipẹkun; ṣugbọn Isikaya ko le ri iru anfani ologo yii ninu iku. Ẹri ọrọ oniO. Dafidi wa ni ibamu pẹlu ọrọ rẹ wipe: “Ko si iranti Rẹ ni iku: ninu isa oku tani yoo fi iyin fun Ọ?” “Awọn oku ki i yin Oluwa, tabi ẹni ti o ba lọ si ibi idakẹrọrọ.” O. Dafidi 6:5; 115:17.ANN 243.3

    Peteru ni ọjọ Pẹntikọsti sọ wipe Dafidi “ti ku a si ti sin, iboji rẹ si wa pẹlu wa loni.” “Nitori Dafidi koi ti i goke re ọrun.” Iṣe 2:29, 34. Wipe Dafidi si wa ninu iboji titi di ọjọ ajinde fihan wipe awọn olododo ko lọ si ọrun lẹyin iku. Nipasẹ ajinde nikan, ati nitori pe Jesu jinde nikan ni Dafidi ṣe le joko ni ọwọ ọtun Ọlọrun nikẹyin.ANN 243.4

    Pọlu tun sọ wipe: “Bi awọn oku ko ba ji dide, nigba naa ni Kristi ko ji dide: bi Kristi ko ba si ji dide, lasan ni igbagbọ yin, ẹyin si wa ninu ẹṣẹ yin. Awọn pẹlu ti wọn sun ninu Kristi si ṣègbé.” 1 Kọrintin 15:16—18. Bi awọn olododo ba n lọ taara si ọrun nigba ti wọn ba ku, fun bi ẹgbẹrun ọdun mẹrin sẹyin, bawo ni Pọlu ṣe le sọ wipe bi ko ba si ajinde, “awọn pẹlu ti wọn sun ninu Kristi ṣegbe”? A ba ma nilo ajinde mọ.ANN 243.5

    Ajẹriku Tyndale, n sọ nipa ipo oku wipe: “Mo jẹwọ ni gbangba wipe, emi ko gbagbọ wipe wọn wa ninu ogo kikun tí Kristi wa ninu rẹ, tabi ti awọn angẹli Ọlọrun ti a yan wa ninu rẹ. Bẹẹ ni ko si ninu kókó igbagbọ mi kankan; nitori bi o ba jẹ bẹẹ, a jẹ wipe iwaasu ajinde ti ara a jẹ ohun asán.”ANN 243.6

    O jẹ ohun ti o han kedere wipe ireti ibukun ainipẹkun ninu iku ti jẹ ki a kọ ikọni ajinde ti Bibeli silẹ pupọpupọ. Irufẹ yii ni Ọmọwe Adam Clarke sọrọ le lori, o sọ pe: “Ikọni ajinde dabi ẹnipe o ṣe pataki jọjọ laarin awọn Kristẹni akọkọ ju bi o ti ri loni lọ! Bawo ni o ṣe ri bẹẹ? Awọn apostoli n tẹnumọ nigba gbogbo, wọn si n rọ awọn atẹle Ọlọrun lati ṣaapọn, lati ṣe igbọran ati lati ni inu didun nitori rẹ. Awọn ti wọn tẹle wọn ni akoko yii ki i saba n mẹnu ba a! Bẹẹ ni awọn apostoli ṣe iwaasu, bẹẹ si ni wọn gbagbọ; bẹẹ ni awa waasu, bẹẹ si ni awọn olugbọ wa gbagbọ. Ko si ikọni kan ninu iyinrere ti a tẹnumọ julọ; bẹẹ ni ko si si ikọni kan ninu iwaasu akoko yii ti a ṣe aibikita si julọ!”ANN 243.7

    Eyi tẹsiwaju titi ti otitọ ologo ti ajinde fi fẹrẹ farasin ti awọn Kristẹni si fi fẹrẹ gbagbe rẹ patapata. Onkọwe aṣaaju ẹsin kan sọrọ lori ọrọ Pọlu ni 1 Tẹsalonika 4:13—18, o wipe: “Fun gbogbo idi fun itunu, ikọni ti aiku onibukun awọn olododo ti rọpo ikọni ti o le fa iyemeji ti wiwa Oluwa lẹẹkeji ni ọdọ wa. Nigba ti a ba ku, Oluwa wá fun wa. Ohun ti o yẹ ki a duro ki a si maa ṣọna fun ni eyi. Awọn oku ti kọja lọ sinu ogo na. Wọn ko duro de ohùn kakaki fun idajọ ati ibukun wọn.”ANN 243.8

    Ṣugbọn nigba ti O fẹ fi awọn ọmọlẹyin Rẹ silẹ, Jesu ko sọ fun wọn wipe wọn a wa si ọdọ Oun ni aipẹ. “Mo n lọ pese aye silẹ fun yin,” ni O wi. “Bi mo ba si lọ pese aye silẹ fun yin, Emi yoo pada wa, lati gba yin si ọdọ Emi tikalara Mi.” Johanu 14:2, 3. Pọlu tun sọ fun wa siwaju si pe “Oluwa funra Rẹ yoo sọkalẹ wa lati ọrun pẹlu ariwo, pẹlu ohun Olori angẹli, ati pẹlu kàkàkí Ọlọrun; awọn oku ninu Kristi ni yoo kọ jinde; nigba naa ni awa ti a wà laaye ti o ku lẹyin yoo lọ pade wọn ninu ikuuku awọsanma, lati pade Oluwa ninu afẹfẹ: bẹẹ ni a o si maa wa pẹlu Oluwa titi lae.” O tun fi kun wipe: “Ẹ maa fi awọn ọrọ wọnyi tu ara yin ninu.” 1 Tẹsalonika 4:16—18. Awọn ọrọ itunu wọnyi ti yatọ patapata si ti alufa ti o gbagbọ wipe gbogbo aye ni a o gbala ti a ṣe atunsọ rẹ ni akọkọ nì tó! O tu awọn ọrẹ ti wọn padanu eniyan wọn ninu pẹlu idaniloju pe, bi o ti wu ki ẹṣẹ oku o pọ to, nigba ti o ba mí eemi ikẹyin nibi, a o gba si aarin awọn angẹli. Pọlu tọka awọn arakunrin rẹ si wiwa Oluwa ni ọjọ iwaju, nigba ti a o ja ẹwọn iboji ti awọn “oku ninu Kristi” a si jinde si iye ainipẹkun.ANN 244.1

    Ki ẹnikẹni to le wọ inu ibugbe awọn alabukun fun, a nilati ṣe ayẹwo ẹjọ wọn, a nilati ṣe ayẹwo iwa ati iṣe wọn niwaju Ọlọrun. Gbogbo eniyan ni a o ṣe idajọ rẹ gẹgẹ bi awọn ohun ti a kọ sinu awọn iwe, ti a o si fi ere fun wọn gẹgẹ bi iṣẹ wọn ti ri. Idajọ yii ko ni waye nigba ti eniyan ba ku. Ẹ kiyesi ọrọ Pọlu: “O ti yan ọjọ kan, ninu eyi ti yoo ṣe idajọ aye ninu ododo nipasẹ Ọkunrin naa, Ẹni ti O ti yan; O si ti fun gbogbo eniyan ni idaniloju lori eyi, nipa jiji dide kuro ninu oku.” Iṣe 17:31. Nibi apostoli naa sọ ọ ni kedere wipe a ti yan ọjọ kan, nigba naa ni ọjọ iwaju, fun idajọ aye.ANN 244.2

    Judah sọ nipa akoko kan naa. “Awọn angẹli ti wọn ko duro ni ipo wọn, ṣugbọn ti wọn fi ibugbe wọn silẹ ni o pamọ sinu ẹwọn ayeraye ninu okunkun di idajọ ọjọ nla.” O tun lo ọrọ Enoku wipe: “Kiyesi Oluwa n bọ wa pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun awọn ẹni mimọ Rẹ, lati ṣe idajọ lori gbogbo eniyan.” Juda 6, 14, 15. Johanu sọ wipe oun “ri awọn oku, ẹni kekere ati ẹni nla, duro niwaju Ọlọrun; a si ṣi awọn iwe silẹ: . . . a si ṣe idajọ awọn oku lati inu awọn ohun ti a kọ sinu iwe naa.” Ifihan 20:12.ANN 244.3

    Ṣugbọn bi awọn oku ba ti n jẹgbadun irọrun ni ọrun bayi tabi ki wọn maa jẹrora ninu ina ọrun apaadi, kini idajọ ọjọ iwaju wulo fun? Awọn ikọni ọrọ Ọlọrun lori awọn koko ọrọ pataki yii ko farasin, bẹẹ ni wọn ko tako ara wọn; eniyan lasan le ni oye wọn. Ṣugbọn oye ti o yè kooro wo ni o le ri ọgbọn tabi ododo ninu iṣọwọronu ti o wa nisinsinyii? Ṣe awọn olododo, lẹyin ayẹwo ẹjọ wọn ni idajọ a gba igboriyin, “Ku iṣẹ iwọ iranṣẹ rere ati olootọ: . . . wọ inu ayọ Oluwa Ọlọrun rẹ,” nigba ti wọn ti n gbe ni iwaju Rẹ ná, boya wọn tilẹ ti n gbe fun ọdun pipẹ? Ṣe a a pe awọn eniyan buburu lati ibi idaloro lati gba idajọ Onidajọ aye: “Ẹ kuro lọdọ Mi, ẹyin ẹni egun, sinu ina ainipẹkun”? Matiu 25:21, 41. Ah, yẹyẹ ti o banilẹru! Yiyẹ ọgbọn ati ododo Ọlọrun lulẹ ni ọna ti o doju tini!ANN 244.4

    Igbagbọ nipa aiku ọkan jẹ ọkan lara awọn ẹkọ eke Romu, ti o wa lati inu ẹsin ibọriṣa, ti a mu wọ inu ẹsin Kristẹni. Martin Luther ka a mọ ara “awọn itan arosọ ti o lodi si iwa ẹda ti o jẹ ara ààtàn awọn ofin Romu.” Ni sisọrọ lori ọrọ Solomoni ninu Oniwaasu, wipe oku ko mọ ohun kan, Alatunṣe naa sọ pe: “Ibomiran ti o fihan wipe awọn oku ko ni imọ kan. O sọ pe, ko si iṣe, ko si imọ, ko si oye, ko si ọgbọn nibẹ. Solomoni ri wipe awọn oku n sun, wọn ko sì mọ ohun kankan rara. Nitori ti awọn oku sun silẹ, laika ọjọ tabi ọdun, ṣugbọn nigba ti wọn ba ji a dabi ẹnipe wọn ko sun pe iṣẹju kan.”ANN 244.5

    Ko si ibi kan ninu Iwe Mimọ ti a ti ri wipe awọn olododo n lọ si ibi èrè wọn tabi awọn ẹni buburu n lọ si ibi ijiya wọn nigba ti wọn ba ku. Awọn baba ati awọn woli ko fi iru idaniloju yii silẹ. Kristi ati awọn apostoli Rẹ ko tilẹ sọ ohun ti o jọ ọ. Bibeli fi kọni ni kedere wipe awọn oku ko lọ si ọrun lọgan ti wọn ba ku. A fi wọn han wipe wọn n sun titi di ọjọ ajinde. 1 Tẹsalonika 4:14; Jobu 14:10—12. Ni ọjọ naa gan ti okùn fadaka tu ti ọpọn wura si fọ (Oniwaasu 12:6), ero eniyan parẹ. Awọn ti wọn lọ sinu iboji wa ni idakẹrọrọ. Wọn ko mọ ohun kan ti n lọ labẹ oorun. Jobu 14:21. Isinmi alabukun fun olododo ti o ti rẹ! Akoko, boya o pẹ tabi o ya, dabi igba kekere si wọn. Wọn sun; kakaki Ọlọrun ni yoo ji wọn si aiku ologo. “Nitori ti kakaki yoo dun, a o si ji awọn oku dide ni aidibajẹ. . . . Nigba ti ara idibajẹ yii ba gbe aidibajẹ wọ, ti ara kiku yii ba gbe aiku wọ, nigba naa ni ohun ti a kọ silẹ yoo ṣẹ wipe, A gbe iku mi ni iṣẹgun.” 1 Kọrintin 15:52—54. Bi a ṣe n pe wọn jade kuro ninu ọrun wọn, wọn a bẹrẹ ironu wọn nibi ti wọn fi i silẹ si. Ohun ti wọn ni imọlara rẹ kẹyin ni irora iku; ero wọn ti o kẹyin ni wipe wọn n ṣubu si abẹ agbara ipo oku. Nigba ti wọn ba ji dide kuro ninu iboji, ero ayọ wọn akọkọ yoo jade pẹlu ọrọ iṣẹgun: “Iku, oró rẹ da? Isa oku, iṣẹgun rẹ da?” Ẹsẹ 55.ANN 244.6

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents