Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  ORI KẸTADINLOGOJI—IWE MIMỌ GẸGẸ BI AABO

  “Si ofin ati si ẹri: bi wọn ko ba sọ gẹgẹ bi ọrọ yii, nitori pe ko si imọlẹ ninu wọn ni.” Aisaya 8:20. A dari awọn eniyan Ọlọrun sinu Iwe Mimọ gẹgẹ bi aabo wọn kuro lọwọ agbara awọn olukọ eke ati agbara atannijẹ awọn ẹmi okunkun. Satani lo gbogbo ọna ti o le lo lati di awọn eniyan lọwọ lati le ni imọ Bibeli nitori awọn ọrọ to da ṣaka to wa ninu rẹ fi awọn ẹtan rẹ han. Ni akoko gbogbo isọji iṣẹ Ọlọrun ọmọ alade iwa buburu n ṣiṣẹ takuntakun, o n lo gbogbo agbara nisinsinyii fun ijakadi ti o kẹyin pẹlu Kristi ati awọn atẹle Rẹ. Itanjẹ nla ti o kẹyin yoo ṣi silẹ niwaju wa laipẹ. Aṣodi si Kristi yoo ṣe iṣẹ iyanu rẹ niwaju wa. Ayederu yii yoo fi ara jọ ojulowo debi pe ko ni ṣe e ṣe lati mọ iyatọ laarin wọn ayafi nipasẹ Iwe Mimọ. Ẹri wọn ni a o fi dan gbogbo ọrọ ati iṣẹ iyanu wo.ANN 264.1

  A o tako awọn ti wọn n gbiyanju lati ṣe igbọran si ofin Ọlọrun, a o si fi wọn ṣẹsin. Inu Ọlọrun nikan ni wọn ti le duro. Lati le farada idanwo ti o wa niwaju wọn, wọn nilati ni oye ifẹ Ọlọrun gẹgẹ bi a ti fihan ninu ọrọ Rẹ; ọna kan ṣoṣo ti wọn file bọwọ fun ni nini oye ti o tọ nipa iwa, iṣejọba, ati erongba Rẹ, ki wọn si wuwa ni ibamu pẹlu wọn. Awọn ti wọn ti fun iyè wọn lokun pẹlu awọn otitọ Bibeli nikan ni yoo le duro la ijakadi nla ti o kẹyin kọja. Idanwo ti n bẹ ọkan wo yoo wa si ọdọ gbogbo eniyan: Ṣe maa ṣe igbọran si Ọlọrun ju eniyan lọ? Akoko ipinu ku si dẹdẹ. Ṣe a ti fi ẹsẹ wa mulẹ sori apata ọrọ Ọlọrun ti ko le yẹ? N jẹ a ṣetan lati duro gbọin lati gbeja ofin Ọlọrun ati igbagbọ Jesu?ANN 264.2

  Ki a to kan an mọ agbelebu, Olugbala ṣe alaye fun awọn ọmọ ẹyin Rẹ wipe a o pa Oun ati pe Oun yoo jinde kuro ninu iboji, awọn angẹli si wa nibẹ lati tẹ ọrọ naa mọ iye ati ọkan wọn. Ṣugbọn awọn ọmọ ẹyin n wa idasilẹ ti ara kuro ninu ajaga Romu, wọn ko le fi ara da ero wipe Ẹni ti wọn gbẹkẹle a ku iku itiju. Awọn ọrọ ti wọn nilo lati ranti kuro ninu ọkan wọn, nigba ti akoko idanwo de, o ba wọn ni aimurasilẹ. Iku Jesu ja ireti wọn kulẹ patapata afi bi ẹnipe ko kilọ fun wọn tẹlẹ. Bẹẹ gẹgẹ ninu awọn asọtẹlẹ, a ṣi ọjọ iwaju silẹ kedere fun wa gẹgẹ bi a ti ṣi silẹ fun awọn ọmọ ẹyin nipasẹ ọrọ Kristi. Awọn iṣẹlẹ ti wọn ni i ṣe pẹlu opin akoko oore ọfẹ ati iṣẹ imurasilẹ fun akoko idamu, ni a fihan kedere. Ṣugbọn ọpọ eniyan ko ni oye awọn otitọ pataki yii a fi bi ẹni pe a ko ṣe afihan wọn rara. Satani n ṣọna lati gba gbogbo ero ti yoo muni gbọn si igbala lọ, ti akoko wahala naa a si ba wọn ni aimurasilẹ.ANN 264.3

  Nigba ti Ọlọrun ba ran ikilọ ti o ṣe pataki to bẹẹ gẹẹ ti a ṣe afihan rẹ gẹgẹ bi awọn angẹli mimọ ti n fo ni aarinmeji ọrun, si eniyan, O fẹ ki gbogbo ẹni ti o ba ni agbara lati ronu o tẹti silẹ si iṣẹ iranṣẹ naa. Idajọ ti o banilẹru ti a ṣe fun jijọsin ẹranko naa ati aworan rẹ (Ifihan 14:9—11), yẹ ki o mu gbogbo eniyan o fi tọkantọkan kẹkọ asọtẹlẹ lati mọ ohun ti ami ẹranko naa jẹ, ati bi wọn ko ṣe ni gba a. Ṣugbọn ọgọọrọ awọn eniyan yi eti wọn kuro ninu gbigbọ otitọ, wọn si yi si itan arosọ. Apostoli Pọlu sọ ni wiwo ọjọ ikẹyin wipe: “Akoko yoo wa nigba ti wọn ko nile farada ẹkọ ti o ye kooro.” 2 Timoti 4:3. Akoko naa ti de ni kikun. Awọn eniyan ko fẹ otito Bibeli, nitori pe o di ifẹ ọkan ẹṣẹ ti o fẹran aye lọwọ, Satani si fun wọn ni ẹtan ti wọn n fẹ.ANN 264.4

  Ṣugbọn Ọlọrun yoo ni awọn eniyan lori ilẹ aye lati fiyesi Bibeli, ani Bibeli nikan ṣoṣo, gẹgẹ bi odiwọn ẹkọ ati ipilẹ gbogbo iṣẹ atunṣe. Ero awọn ọmọwe, ironu imọ sayẹnsi, igbagbọ tabi aṣẹ igbimọ ẹsin, bi wọn ti pọ to, ti wọn si tako ara wọn bi ijọ ti wọn duro fun, ohùn ọpọ eniyan—ki i ṣe ọkan tabi gbogbo awọn wọnyi ni a gbọdọ wo gẹgẹ bi ẹri fun tabi lati tako igbagbọ ẹsin. Ki a to gba igbagbọ tabi ilana kan, a nilati beere “Bayi ni Oluwa wi” lọna ti o han kedere lati ti i lẹyin.ANN 264.5

  Satani n ṣe akitiyan nigba gbogbo lati jẹki a fiye si eniyan dipo Ọlọrun. O n dari eniyan lati wo awọn biṣọbu, alufa, olukọni nipa Ọlọrun, gẹgẹ bi oludari wọn dipo ki wọn wa Iwe Mimọ lati kọ nipa ojuṣe wọn funra wọn. Nipa ṣiṣe akoso iye awọn olori wọnyi, o le dari ọpọlọpọ eniyan gẹgẹ bi ifẹ rẹ.ANN 264.6

  Nigba ti Kristi wa lati sọ ọrọ iye, awọn eniyan lasan fi tayọtayọ gbọ ọrọ Rẹ; ọpọ, ani awọn alufa ati awọn alaṣẹ gbagbọ ninu Rẹ. Ṣugbọn awọn agba ninu iṣẹ alufa ati awọn alagbara ni orilẹ ede naa pinu lati da lẹbi ati lati kọ lati gba ikọni Rẹ. Bi o tilẹ jẹ wipe lasan ni wọn ṣe ninu gbogbo akitiyan wọn lati ri ẹsun kan ka si lẹsẹ, bi o tilẹ jẹ wipe wọn ni imọlara ipa agbara ọrun ati ọgbọn ti o wa ninu ọrọ Rẹ, sibẹ wọn ri ara wọn sinu iwa ẹtanu, wọn kọ eri ti o han kedere nipa bi O ti jẹ Mesaya silẹ, ki wọn ma baa di ọmọ ẹyin Rẹ. Awọn alatako Jesu wọnyi jẹ ẹni ti a ti kọ awọn eniyan lati ọmọde wa lati bọwọ fun, wọn n tẹriba fun aṣọ wọn laibeere ibeere. Wọn beere, “Kilode ti awọn alaṣẹ ati awọn akọwe ko fi gbagbọ ninu Jesu? Ṣe awọn onifọkansin wọnyi ko ni gba a ni bi o ba jẹ wipe Oun ni Kristi naa?” Ipa iru awọn olukọ wọnyi ni o mu ki orilẹ ede Ju o kọ Olurapada wọn silẹ.ANN 265.1

  Ẹmi ti o jẹ ki awọn alufa ati awọn alaṣẹ se ohun ti wọn ṣe ni ọpọlọpọ ti wọn sọ wipe wọn jẹ olufọkansin loni n fihan. Wọn kọ lati ṣe ayẹwo ẹri Iwe Mimọ nipa otitọ pataki fun akoko yii. Wọn tọka si iye wọn, ọrọ wọn ati okiki wọn, wọn wa n fi oju abuku wo awọn ti wọn n kede otitọ gẹgẹ bi awọn eniyan perete, otoṣi, ti ko lokiki, ti wọn ni igbagbọ ti o yawọn sọtọ si araye.ANN 265.2

  Kristi ri wipe ipo aṣẹ ti ko bojumu ti awọn akọwe ati Farisi duro si, ko ni parẹ nigba ti a ba fọn awọn Ju ka. O ni iwoye isọtẹlẹ nipa iṣe gbigbe aṣẹ eniyan ga lati ṣe akoso ẹri ọkan, eyi ti o jẹ egun fun ijọ lati igba yii wa. Ibawi ẹlẹru Rẹ si awọn akọwe ati Farisi, ati ikilo Rẹ si awọn eniyan lati maṣe tẹle awọn adari afọju wọnyi, ni a kọ silẹ gẹgẹ bi ikilọ fun awọn iran ti n bọ.ANN 265.3

  Ijọ Romu fun awọn alufa nikanṣoṣo ni aṣẹ lati ṣe itumọ Iwe Mimọ. Nigba ti a ba sọ wipe awọn alufa nikan ni wọn kun oju oṣuwọn lati tumọ ọrọ Ọlọrun, o tumọ si wipe a pa a mọ kuro ni ọdọ awọn eniyan. Bi o tilẹ jẹ wipe iṣẹ Atunṣe fi Iwe Mimọ fun gbogbo eniyan, sibẹ agbekalẹ kan naa ti Romu lo di ọpọ eniyan ninu awọn ijọ Protestant lọwọ lati wa Bibeli funra wọn. A kọ wọn lati gba ikọni rẹ bi ijọ ba ṣe tumọ rẹ ti ọpọlọpọ si wa ti wọn ko gbọdọ gba ohunkohun bi o ti wu ki a ṣe fihan kedere ninu Iwe Mimọ to, bi o ba tako igbagbọ wọn, tabi ikọni ti a fi idi rẹ mulẹ ninu ijọ wọn.ANN 265.4

  Bi o tilẹ jẹ wipe Bibeli kun fun ikilọ fun awọn ẹlẹkọ eke, ọpọlọpọ ni wọn ṣetan lati jọwọ ọkan wọn si ọwọ alufa wọn. Ọpọ awọn olukọ nipa ẹsin loni wa ti ko le sọ idi miran fun ohun ti wọn gbagbọ ju eyi ti awọn adari ẹsin wọn kọ wọn lọ. Wọn re ikọni Olugbala kọja laifiyesi, wọn si gbẹkẹle ọrọ awọn alufa wọn patapata. Ṣugbọn ṣe awọn alufa ko le baku ni? Bawo ni a ṣe le fi ọkan wa si abẹ idari wọn ayafi bi a ba mọ lati inu ọrọ Ọlọrun wipe wọn n tan imọlẹ? Aini okun inú laarin ọpọ eniyan lati yago kuro ninu ọna didan aye ni o n mu ki ọpọlọpọ o maa tẹle iṣisẹ awọn amoye; nipasẹ ilọra wọn lati ṣe ayẹwo funra wọn, a n de wọn mọ ẹwọn itanjẹ pẹlu ainireti. Wọn ri wipe a fi otitọ nipa akoko yii han kedere ninu Bibeli, wọn si ri wipe agbara Ẹmi Mimọ wa pẹlu ikede rẹ, sibẹ, wọn jẹki atako awọn alufa o yi wọn kuro ninu imọlẹ. Bi o tilẹ jẹ wipe ọpọlọ ati ẹri ọkan wọn gbagbọ, awọn ọkan ti a tanjẹ wọnyi ko gbọdọ ronu yatọ si alufa wọn, wọn jọwọ ero inu ara wọn, ifẹ iyẹ ainipẹkun wọn silẹ fun aigbagbọ, igberaga ati ẹtanu ẹlomiran.ANN 265.5

  Ọpọlọpọ ọna ni Satani n gba ṣiṣẹ nipasẹ eniyan lati muni nigbekun. O ko ọpọlọpọ si ọdọ ara rẹ nipa siso ifẹ wọn pọ mọ awọn ti wọn jẹ ọta agbelebu Kristi. Ohunkohun ti isopọ yii i baa jẹ, o le jẹ ti obi, idile, igbeyawo, tabi ojulumọ, iṣẹ kan naa ni wọn n ṣe; awọn ti wọn n tako otitọ n lo agbara wọn lati dari ẹri ọkan, ti ọkan ti o wa ni abẹ iṣakoso wọn ko ni agbara ti o to tabi ominira lati ṣe igbọran si ẹri ọkan ara wọn.ANN 265.6

  Otitọ ati ogo Ọlọrun ko ṣe e ya nipa, ko ṣe e ṣe fun wa pẹlu Bibeli ni arọwọto wa, lati bọwọ fun Ọlọrun pẹlu ero ti ko tọ. Ọpọlọpọ ni wọn sọ wipe ohun ti eniyan gbagbọ ko ṣe pataki, bi o ba ti gbe igbesi aye ti o dara. Ṣugbọn igbagbọ ni o n dari igbesi aye eniyan. Bi imọlẹ ati otitọ ba wa ni arọwọto wa, ti a si kọ lati lo anfani lati gbọ ati lati ri, o tumọ si wipe a kọ ọ silẹ niyẹn; a n yan okunkun ju imọlẹ lọ.ANN 265.7

  “Ọna kan wa ti o dara loju eniyan, ṣugbon opin rẹ jẹ ọna iku.” Owe 16:25. Aimọkan ki i ṣe awawi fun ẹṣẹ tabi aṣiṣe nigba ti a ni gbogbo anfani lati mọ ifẹ Ọlọrun. Ọkunrin kan n rinrin ajo, o de ibi ti oriṣiriṣi oju ọna wa, ti patako-ajuwe si sọ ibi ti gbogbo wọn yoo yọri si. Bi ko ba gba ti patako-ajuwe, ti o si gba oju ọna yoowu ti o ba ro wipe o tọna, o le ṣe e tọkantọkan, ṣugbọn nikẹyin a ba ara rẹ ni oju ọna ti ko tọ.ANN 266.1

  Ọlọrun ti fun wa ni ọrọ Rẹ ki a le mọ awọn ikọni rẹ, ki a si mọ funra wa ohun ti O n beere lọwọ wa. Nigba ti amofin naa wa si ọdọ Jesu pẹlu ibeere, “Kini ki emi o ṣe lati le jogun iye ainipẹkun?” Olugbala da pada sinu Iwe Mimọ, O wipe: “Kini a kọ sinu ofin? Kini o ti wi?” Aimọkan ko ni jẹ awawi fun ọmọde tabi agba, bẹẹ ni ko ni yọ wọn kuro ninu ijiya ti o yẹ fun riru ofin Ọlọrun nitori agbekalẹ tootọ ofin naa ati ilana ati ojuṣe wọn ti wa lọwọ wọn. Kò tó lati ni erongba rere, ko to lati ṣe ohun ti eniyan ro wipe o tọna tabi ohun ti alufa sọ wipe o dara. Igbala ọkan rẹ ni a n sọrọ le lori, o si nilati wa Iwe Mimọ funra rẹ. Ko si bi igbagbọ ọkan rẹ ti le lagbara to, ko si bi o ti le ni igboya wipe alufa naa mọ otitọ to, eyi ki i ṣe ipilẹ rẹ. O ni aworan ti o n tọka si gbogbo oju ọna ninu irin ajo lọ si ọrun, ko si yẹ ki o ṣe àbùsọ ohun kankan.ANN 266.2

  O jẹ ojuṣe akọkọ ati eyi ti o ga julọ fun gbogbo ẹni ti n ronu lati kọ lati inu Iwe Mimọ ohun ti i ṣe otitọ, ki o wa maa rin ninu imọlẹ ki o si gba awọn miran niyanju lati tẹle apẹẹrẹ oun. Ni ojoojumọ ni o yẹ ki a maa fi tọkantọkan kẹkọ Bibeli, ki a maa yẹ gbogbo ero wo ki a si maa fi ẹsẹ we ẹsẹ. Pẹlu iranlọwọ Ọlọrun a nilati ni igbagbọ wa funra wa nitori ti a o jiyin niwaju Ọlọrun funra wa ni.ANN 266.3

  Awọn otitọ ti a fihan kedere ninu Bibeli ni awọn ọmọwe ti fi sinu iyemeji pẹlu afarawe ọgbọn nla ti wọn n kọni wipe Iwe Mimọ ni itumọ ikọkọ, itumọ aṣiri ni ọna ẹmi ti ko farahan daradara ninu ede ti a lo. Iru awọn eniyan wọnyi ni Jesu sọ fun wipe: “Ẹyin ko mọ Iwe Mimọ, tabi agbara Ọlọrun.” Maku 12:24. A nilati ṣe alaye ọrọ Bibeli gẹgẹ bi itumọ rẹ gan an, ayafi bi a ba lo ami tabi akajuwe. Kristi ti ṣe ileri funni: “Bi ẹnikẹni yoo ba ṣe ifẹ Rẹ, yoo mọ nipa ikọni naa.” Johanu 7:17. Bi awọn eniyan yoo ba gba Bibeli bi o ti wi, bi ko ba si awọn ẹlẹkọ eke lati ṣi awọn eniyan lọna ati lati dabaru iyè wọn, a ba ṣe iṣẹ ti yoo mu inu angẹli dun, ti yoo si mu ọpọ eniyan ti wọn n rare kiri ninu eke wa sinu agbo Kristi.ANN 266.4

  A nilati lo gbogbo agbara inu wa ninu ikẹkọ Iwe Mimọ a si ni lati lo oye wa ni bi eniyan ti le lo o lati mọ awọn ohun ijinlẹ Ọlọrun sibẹ a ko gbọdọ gbagbe wipe igbọran ati irẹlẹ ọmọde ni ẹmi tootọ ti o yẹ fun akẹkọ. A ko le ni oye awọn ohun ti wọn nira ninu Iwe Mimọ ni ọna kan naa ti a n gba dahun si iṣoro ero ijinlẹ. A ko gbọdọ kẹkọ Bibeli pẹlu igbẹkẹle ara ẹni eyi ti ọpọlọpọ fi n kọ ẹkọ imọ sayẹnsi, bikoṣe pẹlu igbẹkẹle Ọlọrun pẹlu adura ati ifẹ tootọ lati kọ nipa ifẹ Rẹ. A nilati wá pẹlu ẹmi irẹlẹ ti o ṣe e kọ lati gba imọ ni ọdọ EMI NI nla. Lalaiṣe bẹẹ, awọn angẹli buburu a fi ọwọ ba wa niye, wọn a si sé ọkan wa le debi pe otitọ ko ni wọ ọkan wa.ANN 266.5

  Ọpọlọpọ abala Iwe Mimọ ti awọn ọmọwe pe ni ohun ijinlẹ, tabi ti wọn fo kọja gẹgẹ bi ohun ti ko ṣe pataki, ni wọn kun fun itunu ati ikilọ fun ẹni ti a kọ ni ile ẹkọ Kristi. Idi kan ti ọpọlọpọ awọn ti wọn n kẹkọ nipa Ọlọrun ko ṣe ni oye ti o ye kooro nipa ọrọ Ọlọrun ni wipe wọn di oju wọn si otitọ ti wọn ko fẹ ṣe. Oye otitọ Bibeli ko duro pupọ lori agbara oye ti a fi kọ ọ bikoṣe ọkan kan ati ifẹ tootọ fun ododo.ANN 266.6

  A ko gbọdọ kẹkọ Bibeli laigbadura. Ẹmi Mimọ nikan ni O le mu ki a mọ iwulo awọn ohun ti o le tete yeni, tabi lati maṣe jẹki a lọ otitọ ti o nira lati yeni lọrun. O jẹ ojuṣe awọn angẹli ọrun lati pese ọkan silẹ lati le ni oye ọrọ Ọlọrun, ti ẹwa rẹ a fi wu wa, ti a o fi gba ikilọ lati inu ikilọ rẹ, ti a o fi ni okun ati agbara lati inu awọn ileri rẹ. A nilati jẹ ki ẹbẹ oniO. Dafidi o jẹ ti wa: “Iwọ ṣi mi ni oju, ki n le ri awọn ohun iyanu lati inu ofin Rẹ.” O. Dafidi 119:18. Idanwo saba maa n dabi eyi ti a ko le bori nitori pe a kọ adura ati ẹkọ Bibeli silẹ, ẹni ti a n danwo ko le tete ranti awọn ileri Ọlọrun ki o si fi awọn ohun ija Iwe Mimọ pade Satani. Ṣugbọn awọn angẹli yi awọn ti wọn ṣetan lati gba ẹkọ ninu awọn ohun Ọlọrun ka; ni akoko ti wọn ba si nilo rẹ julọ wọn a mu awọn otitọ ti wọn nilo wa si iranti wọn. Nitori naa “nigba ti ọta ba wa bi igbi omi, Ẹmi Oluwa a gbe ọpagun dide si.” Aisaya 59:19.ANN 266.7

  Jesu ṣe ileri fun awọn ọmọ ẹyin Rẹ: “Olutunu naa, eyi ti i ṣe Ẹmi Mimọ, ẹni ti Baba yoo ran ni orukọ Mi, yoo kọ yin ni ohun gbogbo, yoo si mu ohun gbogbo ti Mo ti sọ wa si iranti yin.” Johanu 14:26. Ṣugbọn a nilati kọkọ ko awọn ikọni Kristi sinu iyè na ki Ẹmi Ọlọrun to le mu wa si iranti wa ni akoko ewu. Dafidi sọ pe, “Ọrọ Rẹ ni mo pa mọ si aya mi, ki n ma baa ṣẹ si Ọ.” O. Dafidi 119:11.ANN 267.1

  Gbogbo awọn ti ohun iye ainipẹkun wọn ba ni itumo si wọn nilati ṣọra ki iyemeji ma baa wọle. Wọn a kọlu òpó otitọ funra rẹ. Ko ṣe e ṣe lati sa fun isọrọ odi si ati ọgbọn ẹwẹ ikọni ẹtan ti o gbalẹ kan ti aigbagbọ ode oni. Satani n mu ki awọn idanwo rẹ o ba gbogbo eniyan mu. O fi ẹfẹ ati ẹgan kọ lu awọn ti ko le kawe, nigba ti o fi idiwọ imọ sayẹnsi ati ironujinlẹ pade awọn ọmọwe, o ṣe gbogbo wọn lati ru ainigbẹkẹle ati ẹgan fun Iwe Mimọ soke. Ani awọn ọdọ ti wọn ko ni iriri pupọ n gbimọ lati ṣe iyemeji nipa ẹkọ ipilẹ ẹsin Kristẹni. Aigbagbọ awọn ọdọ wọnyi bi o ti kere to ni ipa tirẹ. Nipa eyi a n dari ọpọlọpọ lati fi igbagbọ awọn baba wa ṣẹfẹ ti wọn ko si ka Ẹmi oore ọfẹ si. Heberu 10:29. Ọpọlọpọ eniyan ti i ba jẹ iyin fun Ọlọrun ati ibukun fun araye ni ẹmi rirun aigbagbọ ti bajẹ. Gbogbo awọn ti wọn gbẹkẹle ifọnnu ipinu ọgbọn eniyan ti wọn si ro wipe wọn le ṣe alaye ohun ijinlẹ Ọlọrun ki wọn si mọ otitọ laisi iranlọwọ ọgbọn Ọlọrun n fi ara wọn sinu idẹkun Satani.ANN 267.2

  A n gbe ni akoko ti o lẹru ninu itan aye yii. A ti fẹrẹ bẹrẹ ipinu lori atubọtan awọn ti n gbe inu aye yii. Ọjọ iwaju ara wa ati igbala awọn ọkan miran duro lori ohun ti a n ṣe nisinsinyii. A nilo lati jẹ ki Ẹmi otitọ o dari wa. Gbogbo atẹle Kristi ni wọn nilati beere tọkantọkan wipe: “Oluwa kini O fẹ ki n ṣe?” A nilo lati rẹ ara wa silẹ niwaju Oluwa pẹlu awẹ ati adura, ki a si ronu daradara lori ọrọ Rẹ, paapaa julọ lori awọn iṣẹlẹ idajọ. Ni akoko yii a nilati ni iriri ti o jinlẹ ninu awọn ohun Ọlọrun. A ko ni akoko kan lati fi ṣofo. Awọn iṣẹlẹ ti wọn ṣe pataki n ṣẹlẹ ni ayika wa, ori ilẹ ti Satani ti n rániníyè ni a wa. Ẹ maṣe sun ẹyin aṣọna Ọlọrun, ọta n lugọ ni ayika wa, o ṣetan nigbakugba bi o ba jafara ti o si toogbe, lati bẹ lu ọ, ki o si pa ọ jẹ.ANN 267.3

  Ọpọlọpọ ni a tanjẹ nipa ipo ti wọn wa nipato niwaju Ọlọrun. Wọn ki ara wọn ku ori ire nitori iwa buburu ti wọn ko wu, wọn si gbagbe lati sọ nipa iwa rere ati iwa pipe ti Ọlọrun fẹ lati ọdọ wọn, ṣugbọn ti wọn baku lati wu. Ko to wipe wọn jẹ igi ninu ọgba Ọlọrun. Wọn nilati ṣe ohun ti O n fẹ nipa siso eso. Yoo beere lọwọ wọn gbogbo ohun rere ti wọn le ṣe nipasẹ oore ọfẹ Rẹ ti n fun wọn lokun, ṣugbọn ti wọn baku lati ṣe. Ninu iwe ọrun a kọ orukọ wọn sibẹ gẹgẹ bi ẹni ti n gbalẹ lasan. Sibẹ ọrọ awọn eniyan bawọnyi ko wa ni ainireti patapata. Pẹlu awọn ti wọn gan aanu Ọlọrun ti wọn tun ṣaata oore ọfẹ Rẹ, ọkan ifẹ ti o nipamọra si n bẹbẹ. “Nitori naa O sọ pe, Ji dide iwọ ti n sun, ki o si dide kuro ninu oku, Kristi yoo si fun ọ ni imọlẹ. Nitori naa ẹ ri wipe ẹ rin pẹlu ọgbọn, . . . ni rira igba pada, nitori ti awọn ọjọ kun fun ibi.” Efesu 5:14—16.ANN 267.4

  Nigba ti akoko idanwo ba de, a o fi gbogbo awọn ti wọn fi ọrọ Ọlọrun ṣe odiwọn igbesi aye wọn han. Ni igba ẹrun, ko si iyatọ kan pato laarin igi ti ewe rẹ ki i rẹ ati awọn igi miran, ṣugbọn nigba ti atẹgun igba otutu ba de igi ti ewe rẹ ki i rẹ koni yi pada, nigba ti ewe awọn yoku yoo si rẹ. Bẹẹ gẹgẹ ni onigbagbọ ti ọkan rẹ jẹ eke ko le ṣe e damọ yatọ si Kristẹni tootọ bayii, ṣugbọn akoko naa de bawa tan ti iyatọ a fi ara han. Ẹ jẹki atako o dide, ki igbonaraju ẹsin ati ainifarada o gbajọba, ki a tanna inunibini pada, awọn ọlọkanmeji ati awọn alagabagebe a mìsíwá mìsẹyin, wọn a si kọ igbagbọ silẹ, ṣugbọn Kristẹni tootọ yoo duro gbọin bi apata, igbagbọ rẹ yoo maa lagbara si, ireti rẹ a mọlẹ si ju ti akoko idẹra lọ.ANN 267.5

  OniO. Dafidi sọ wipe: “Awọn ẹri Rẹ ni ironu mi.” “Mo ni oye nipasẹ awọn ilana Rẹ: nitori naa mo korira gbogbo ọna eke.” O. Dafidi 119:99, 104.ANN 267.6

  “Ibukun ni fun ẹni naa ti o ri ọgbọn.” “Yoo dabi igi ti a gbin si ipa omi, ti o tan gbongbo rẹ kalẹ nibi odo, ki yoo si mọ nigba ti ooru ba de, ṣugbọn ewe rẹ yoo tutu; ki yoo si ṣe aniyan ni igba ẹrun, bẹẹ ni ki yoo ni ṣiwọ siso eso.” Owe 3:13; Jeremaya 17:8.ANN 267.7

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents