Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KEJILELOGOJI—ARIYANJIYAN NAA PARI

    Ni opin ẹgbẹrun ọdun naa, Kristi pada wa si aye. Ẹgbẹ ogun awọn ti a ra pada tẹle, ọwọ awọn angẹli si n ṣe iranṣẹ fun. Bi O ti n sọkalẹ ninu ọlanla ẹlẹru, o ji awọn eniyan buburu dide lati gba iparun wọn. Wọn jade wa, ẹgbẹ ogun nla ti wọn ko lonka bi iyanrin eti okun. Wọn ti yatọ to si awọn ti a ji dide ni ajinde akọkọ! A fi ọdọ ainipẹkun ati ẹwa wọ awọn olododo ni aṣọ. Awọn eniyan buburu ni ami aisan ati iku.ANN 294.1

    Gbogbo oju ninu ọgọọrọ awọn ero naa kiyesi ogo Ọmọ Ọlọrun. Pẹlu ohun kan awọn eniyan buburu kigbe wipe: “Ibukun ni fun Ẹni ti n bọwa ni orukọ Oluwa!” Ki i ṣe ifẹ si Jesu ni o mu ọrọ yii wa. Agbara otitọ ni o ti ọrọ naa jade kii sii ṣe pẹlu ifẹ inu wọn. Bi awọn eniyan buburu ti wọ inu iboji wọn, bẹẹ gẹgẹ ni wọn ṣe jade pẹlu iṣọta si Kristi, ati ẹmi iṣọtẹ kan naa. A ki yoo fun wọn ni akoko oore ọfẹ miran lati ṣe atunṣe igbesi aye wọn atẹyinwa mọ. Ko si ohunkohun ti eyi a mu wa. Igbesi aye ẹṣẹ ko ṣẹ ọkan wọn rọ. Bi a ba fun wọn ni akoko oore ọfẹ miran, wọn a lo o bi i ti akọkọ ni, ni sisa fun ojuṣe wọn si Ọlọrun ati riru iṣọtẹ soke si I.ANN 294.2

    Kristi sọkalẹ wa si Ori Oke Olifi, nibi ti awọn angẹli Rẹ ti ṣe atunsọ ileri ipadabọ Rẹ, lẹyin ajinde Rẹ, nigba ti O n goke lọ si ọrun. Woli naa wipe: “Oluwa Ọlọrun mi yoo wa, ati gbogbo awọn eniyan mimọ pẹlu Rẹ.” “Ni ọjọ naa, ẹsẹ Rẹ yoo duro lori oke Olifi, eyi ti o wa niwaju Jerusalẹmu ni iha ila oorun, oke Olifi yoo si pin si meji, ni aarin rẹ, . . . afonifoji nla yoo si wa.” “Oluwa yoo si jẹ ọba lori gbogbo aye: ni ọjọ naa Oluwa kan ni yoo wa, orukọ Rẹ yoo si jẹ ọkan.” Sekaraya 14:5, 4, 9. Bi Jerusalẹmu tuntun naa ninu itansan ogo rẹ ti n sọkalẹ wa lati ọrun, o duro lori ibi ti a yasi mimọ, ti a ti pese silẹ lati gba a, ti Kristi pẹlu awọn eniyan Rẹ ati awọn angẹli Rẹ si wọ inu Ilu Mimọ naa.ANN 294.3

    Satani wa mura fun ijakadi nla ti o kẹyin fun akoso. Nigba ti a gba agbara kuro ni ọwọ rẹ, ti a si ge kuro ninu iṣẹ itanjẹ rẹ, ọmọ alade iwa buburu wa ninu ibanujẹ, ko si ni alaafia; ṣugbọn bi a ti ji awọn eniyan buburu dide ti o ri ọpọ eniyan ni iha rẹ, ireti rẹ sọji, o si pinu lati maṣe juwọ silẹ ninu ijakadi nla naa. Yoo ko gbogbo awọn ọmọ ogun ègbé si abẹ asia rẹ, yoo si ṣa ipa lati mu ero rẹ ṣẹ nipasẹ wọn. Igbekun Satani ni awọn eniyan buburu n ṣe. Ni kikọ Kristi silẹ, wọn gba akoso olori awọn ọlọtẹ. Wọn ṣetan lati gba imọran rẹ ati lati ṣe aṣẹ rẹ. Sibẹ, ni otitọ si ọgbọn ẹwẹ rẹ, ko gba ara rẹ ni Satani. O pe ara rẹ ni ọmọ alade ti o ni ẹtọ si aye yii, ti a si fi ipa gba ogun ini rẹ kuro lọwọ rẹ ni ọna aitọ.ANN 294.4

    O fi ara rẹ han fun awọn atẹle rẹ ti a tanjẹ bi olurapada, o fi da wọn loju wipe agbara oun ni o mu wọn jade lati inu iboji wọn, ati pe oun fẹ gba wọn silẹ kuro ni ọwọ ika onroro. Nigba ti Kristi ti kuro nibẹ, Satani ṣe iṣẹ iyanu lati fi idi ọrọ rẹ mulẹ. O mu awọn alailera lara le, o si mi si wọn pẹlu ẹmi ati agbara ara rẹ. O pete lati dari wọn lati kọlu agọ awọn eniyan mimọ ki o si gba Ilu Ọlọrun. Pẹlu idunnu alatako o tọka si ẹgbẹlẹgbẹ awọn ti a ji dide ninu oku, o sọ wipe gẹgẹ bi olori wọn, oun le bi ilu naa ṣubu, ki oun si gba itẹ ati ijọba oun pada.ANN 294.5

    Ninu agbajọ ero nla naa ọpọ awọn ti ọjọ aye wọn gun ti wọn gbe ṣaaju Ikun Omi wa nibẹ, awọn ti wọn ga ni iri ti ironu wọn si lagbara, ni yiyọnda ara wọn silẹ fun akoso awọn angẹli ti wọn ṣubu, wọn fi gbogbo ọgbọn wọn ati imọ wọn jin fun gbigbe ara wọn ga; awọn eniyan ti iṣẹ ọna agbayanu wọn mu ki aye o jọsin ọgbọn ori wọn, ṣugbọn ti iwa ika ati iṣẹ buburu wọn, sọ aye di aimọ ti o si ba aworan Ọlọrun jẹ, ti o fi mu ki O pa wọn rẹ kuro ni ilẹ aye. Awọn ọba ati ọga ogun ti wọn ṣẹgun awọn orilẹ ede wa nibẹ, awọn alagbara ti wọn ko padanu ogun kankan ri, awọn jagunjagun agberaga ti wọn ni ifẹ agbara, ti dide wọn n mu ki awọn ijọba o wariri. Ninu iku awọn wọnyi ko ni yipada. Bi wọn ti jade wa lati inu iboji, wọn tẹsiwaju ninu ero wọn nibi ti wọn fi ori rẹ ti si. Ifẹ lati ṣẹgun kan naa ti o dari wọn nigba ti wọn ṣubu naa ni o dari wọn.ANN 294.6

    Satani ba awọn angẹli rẹ gbimọ pọ, lẹyin naa pẹlu awọn ọba ati awọn jagunjagun ati awọn alagbara wọnyi. Wọn wo agbara ati iye awọn ti o wa ni iha wọn, wọn si wipe awọn ẹgbẹgun to wa ninu ilu naa kere bi a ba fi we ara wọn, ati pe wọn le bori wọn. Wọn gbe eto lati gba ọla ati ogo Jerusalẹmu Tuntun naa kalẹ. Loju ẹsẹ gbogbo wọn mura fun ogun. Awọn oniṣẹ ọnà ti wọn lọgbọn ṣe awọn ohun elo ija. Awọn adari awọn ologun ti wọn lokiki nitori aṣeyọri wọn to awọn jagunjagun lẹgbẹẹgbẹ ati ni isọriisọri.ANN 295.1

    Ni ikẹyin a fun wọn ni aṣẹ, ti ẹgbẹ ti ko lohunka si n yan lọ—ẹgbẹ ogun ti aṣẹgun aye kan ko kojọ ri, eyi ti gbogbo iparapọ ẹgbẹ ogun lati igba ti ogun jija ti bẹrẹ ko le to. Satani, alagbara julọ ninu awọn jagunjagun, ni o dari ẹgbẹ naa ti awọn angẹli rẹ si pa agbara wọn pọ ninu ijakadi ti o kẹyin yii. Awọn ọba ati awọn jagunjagun wa ninu ẹgbẹ rẹ, ti ọpọ eniyan si n tẹle wọn ni ẹgbẹ ti o pọ ṣu u, olukuluku labẹ adari rẹ. Pẹlu iṣedeede ologun awọn ẹgbẹ naa yan kọja ilẹ ti o la si meji lori ile ti ko gún, wọn de Ilu Ọlọrun. Pẹlu aṣẹ Jesu, a ti ilẹkun Jerusalẹmu Tuntun, awọn ẹgbẹgun Satani si yi ilu naa ka, wọn ṣetan lati ṣe ikọlu.ANN 295.2

    Ni akoko yii Kristi yọ si awọn ọta Rẹ. Ni oke réré ilu naa, lori ipilẹ wura didan ni itẹ kan wa ti o ga, ti a gbe soke. Ọmọ Ọlọrun joko sori itẹ yii, awọn ọmọ ijọba Rẹ si yi I ka. Ko si ede ti o le ṣe alaye agbara ati ọlanla Kristi, ko si kalamu kan ti o le kọ ọ silẹ. Ogo Baba Ayeraye yi Ọmọ Rẹ ka. Itansan ogo Rẹ kun Ilu Ọlọrun, o tun tan jade lẹnu ilẹkun rẹ, o si bo gbogbo aye mọlẹ pẹlu itansan rẹ.ANN 295.3

    Awọn ti wọn sunmọ itẹ naa julọ ni awọn ti wọn fi igba kan ri jẹ onitara ninu iṣẹ Satani, ṣugbọn ti a yọ bi igi kuro ninu ina, ti wọn si tẹle Olugbala wọn pẹlu ifẹ ọkan gbigbona. Lẹyin naa awọn ti wọn sọ iwa Kristẹni di pipe laarin ẹtan ati aiṣotitọ, awọn ti wọn bu ọla fun ofin Ọlọrun nigba ti awọn Kristẹni ninu aye sọ wipe ko ni itumọ mọ, ati ọgọọrọ awọn eniyan, ni gbogbo iran, ti a pa nitori igbagbọ wọn. Lẹyin naa ni “ẹgbẹlẹgbẹ eniyan, eyi ti ẹnikẹni ko le ka, ninu gbogbo orilẹ ede ati ẹya ati eniyan ati ede, . . . niwaju itẹ naa, a wọ wọn ni aṣọ funfun, ati imọ ọpẹ ni ọwọ wọn.” Ifihan 7:9. Ogun wọn pari, wọn ti gba iṣẹgun. Wọn ti pari eré naa, wọn si ti de ibi èrè naa. Imọ ọpẹ ti o wa ni ọwọ wọn jẹ ami fun iṣẹgun wọn, aṣọ funfun ti wọn wọ jẹ ami ododo ailabawọn Kristi eyi ti o di tiwọn bayii.ANN 295.4

    Awọn ti a ra pada gbe orin iyin soke, eyi ti o dun ti o tun ro pada ni orule ọrun: “Ti Ọlọrun ti O joko lori itẹ ati ti Ọdọ Aguntan ni igbala.” Ẹsẹ 10. Angẹli ati serafu si pa ohun wọn pọ ni ijọsin. Bi awọn ti a rapada ti n wo agbara ati iwa ika Satani, wọn ri bi wọn ko ti ri tẹle, wipe ko si agbara kankan a fi ti Kristi nikan ṣoṣo ni o le sọ wọn di aṣẹgun. Ninu gbogbo awọn ero ti n dan naa ko si ẹni ti o gboriyin igbala fun ara rẹ, bi ẹnipe wọn ṣẹgun pẹlu agbara ati iwa rere ara wọn. A ko sọ ohun kan nipa ohun ti wọn ṣe tabi ti wọn jiya rẹ; ṣugbọn ajaga gbogbo orin, ìró gbogbo orin ni: Ti Ọlọrun wa ati ti Ọdọ Aguntan ni igbala.ANN 295.5

    Niwaju awọn olugbe aye ati ọrun ti wọn pejọ a ṣe eto ikẹyin nibi ti a ti fi ade de Ọmọ Ọlọrun. Bayi nigba ti a fun ni ọlanla ati agbara ti o ga julọ, Ọba awọn ọba ṣe idajọ lori awọn oluṣọtẹ si ijọba Rẹ, o si da awọn ti wọn tapa si ofin Rẹ ti wọn tun jẹ awọn eniyan Rẹ niya lẹjọ. Woli naa sọ pe: “Mo ri itẹ funfun nla kan, ati Ẹni ti o joko lori rẹ, niwaju Ẹni ti ọrun ati aye ka kuro, a ko si ri aye fun wọn. Mo si ri awọn oku, kekere ati nla, duro niwaju Ọlọrun; a si ṣi awọn iwe silẹ, eyi ti i ṣe iwe iye, a si ṣe idajọ awọn oku gẹgẹ bi awọn ohun ti a kọ sinu awọn iwe naa, gẹgẹ bi iṣẹ wọn.” Ifihan 20:11, 12.ANN 295.6

    Ni kete ti a ṣi awọn iwe akọsilẹ naa silẹ, ti Jesu ṣiju wo awọn eniyan buburu, wọn ranti gbogbo ẹṣẹ ti wọn da ri. Wọn ri ibi ti ẹsẹ wọn ti yẹ kuro ni ọna iwa ailabawọn ati iwa mimọ, ibi ti igberaga ati iṣọtẹ dari wọn de lati ru ofin Ọlọrun. Awọn idanwo ti n yini kuro ni ọna rere eyi ti wọn ran lọwọ nipa didẹṣẹ, awọn ibukun ti wọn ṣilo, awọn iranṣẹ Ọlọrun ti wọn kẹgan, awọn ikilọ ti wọn kọ silẹ, igbi aanu ti wọn fi ori kunkun ati ọkan ainironupiwada bi sẹyin—gbogbo wọn farahan a fi bi ẹnipe a fi ina kọ wọn.ANN 295.7

    Agbelebu wa ni oke itẹ naa; bi aworan, a ri iṣẹlẹ idanwo ati iṣubu Adamu, ati awọn igbesẹ ni ṣisẹ n tẹle ninu eto nla ti irapada. Ìbí Olugbala bi talaka, ibẹrẹ igbesi aye Rẹ ni otitọ ati igbọran, iribọmi Rẹ ni Jọdani, awẹ ati idanwo Rẹ ni aginju, iṣẹ ita gbangba Rẹ, ni fifi ibukun ọrun ti o ṣeyebiye julọ fun awọn eniyan, awọn ọjọ ti wọn kun fun iṣẹ ifẹ ati aanu, aṣalẹ adura ati iṣọna ni idanikanwa ni aarin awọn oke, ète arankan, ikorira ati ẹtanu ti a fi san oore Rẹ pada, irora ẹlẹru ti a ko le fẹnu sọ ni Getsemani labẹ ẹru wuwo ẹṣẹ gbogbo aye, ifihan Rẹ si ọwọ awọn ero apaniyan, awọn iṣẹlẹ aṣalẹ ẹlẹru naa—ẹlẹwọn ti ko janpata, ti awọn ọmọ ẹyin ti o fẹran julọ kọ silẹ, ti a fi agidi mu pẹlu ikanju la awọn adugbo Jerusalẹmu kọja, Ọmọ Ọlọrun ti a fi ayọ nla fihan niwaju Anna, ti a pe lẹjọ ninu aafin olu alufa, ni gbọngan idajọ Pilatu, niwaju Hẹrọdu, ANN 295.8

    ojo ati onroro, ti a fi ṣẹfẹ, a tabuku Rẹ, a jẹ niya, a si dajọ iku fun—gbogbo rẹ ni a fihan ketekete.ANN 296.1

    Niwaju ọgọọrọ awọn eniyan naa a ṣe afihan awọn iṣẹlẹ ikẹyin—Olujiya onisuuru to n rin lọ si Kalfari, Ọmọ Alade ọrun ti a gbe kọ ori agbelebu, awọn alufa agberaga ati awọn ero ti n rẹrin, ti wọn n fi irora iku Rẹ ṣẹfẹ, okunkun ti ki i ṣe lasan, ilẹ riri, awọn okuta ti wọn ya, awọn iboji ti wọn ṣi silẹ, ti wọn ṣe afihan akoko ti Olugbala aye jọwọ ẹmi Rẹ lọwọ.ANN 296.2

    Ifihan naa fi ara han gẹgẹ bi o ti ri. Satani, awọn angẹli rẹ, ati awọn atẹle rẹ ko ni agbara lati yiju kuro ninu aworan iṣẹ ọwọ wọn. Olukuluku ni o ranti ipa ti oun ko. Hẹrọdu ti o pa awọn ọmọ alaiṣẹ ni Bẹtlẹhẹmu ki o baa le pa Ọba Israeli, alainitiju Hẹrodia, ẹni ti ọkan rẹ jẹbi ẹjẹ Johanu Onitẹbọmi, Pilatu alailagbara ati aba-igba-yi, awọn jagunjagun ti n fini ṣẹsin, awọn alufa ati alaṣẹ ati awọn ero ti ko ni oye mọ ti n kigbe, ” Ki ẹjẹ Rẹ o wa ni ori wa, ati awọn ọmọ wa!”—gbogbo wọn ni wọn ri bi ẹbi wọn ti pọ to. Lasan ni wọn n wa ọna lati fi ara wọn pamọ kuro ninu ọlanla irisi Rẹ, eyi ti o mọlẹ ju ogo oorun lọ, nigba ti awọn ti a rapada si n fi ade wọn lelẹ ni ẹsẹ Olugbala ti wọn n wi pe: “O ku fun mi!”ANN 296.3

    Awọn apostoli Kristi wa laarin awọn ti a ra pada, Pọlu akikanju, Peteru onitara Johanu ololufẹ ati ẹni ti a fẹran, ati awọn arakunrin wọn, olootọ ọkan, pẹlu wọn ẹgbẹlẹgbẹ awọn ajẹriku; ṣugbọn ni ode ogiri naa, pẹlu gbogbo ohun buburu ati irira, ni awọn ti wọn ṣe inunibini si wọn, ti wọn fi wọn sinu tubu, ti wọn tun pa wọn wa. Nero oniwakuwa, ti o fẹran iwa ika ati iwa buburu wa nibẹ, o n wo ayọ ati igbega awọn ti o fiya jẹ nigba kan ri, ati awọn ti inu rẹ dun si irora kikan wọn bi i Satani. Iya rẹ wa nibẹ lati ṣe ẹlẹri si iṣẹ ọwọ ara rẹ, lati ri iwa ibi ti o fun ọmọ rẹ, iwa igbonara ti o ṣe iranlọwọ fún ti o si mu ki o dagba nipasẹ iwuwasi ati apẹẹrẹ rẹ, ti so eso si iwa ọdaran ti o mu ki aye o wariri.ANN 296.4

    Awọn alufa ati aṣoju popu wa nibẹ, awọn ti wọn pe ara wọn ni aṣoju Kristi, ṣugbọn ti wọn lo igi ifiyajẹni, ati ile tubu, ati ibi idanasunni ṣe akoso ẹri ọkan awọn eniyan Rẹ. Awọn alufa agberaga ti wọn gbe ara wọn ga ju Ọlọrun lọ, ti wọn tun n gbero lati yi ofin Ẹni Giga julọ pada wa nibẹ. Awọn ti wọn pe ara wọn ni baba ijọ a jẹjọ fun Ọlọrun eyi ti wọn ko ni fẹ jẹ. A ti pẹ ju fun wọn lati ri wipe Ọlọgbọn julọ n jowu nitori ofin Rẹ, ati pe ko ni da ẹlẹbi silẹ. Wọn kọ nisinsinyii bi Kristi ti fi ifẹ Rẹ han fun awọn eniyan Rẹ ti n jiya, wọn mọ agbara ọrọ ara Rẹ: “Niwọn igba ti ẹyin ti ṣe e fun eyi ti o kere julọ ninu awọn arakunrin Mi wọnyi, ẹyin ti ṣe e fun Mi.” Matiu 25:40.ANN 296.5

    Gbogbo awọn eniyan buburu aye duro niwaju aga igbẹjọ Ọlọrun pẹlu ẹsun iṣọtẹ nla si ijọba ọrun. Wọn ko ni ẹnikankan lati gbeja wọn, wọn wa ni airiwi; a wa da ẹjọ iku fun wọn.ANN 296.6

    O wa farahan bayii fun gbogbo eniyan wipe ere ẹṣẹ ki i ṣe igbesi aye ominira ọlọwọ ati iye ainipẹkun, bikoṣe ikolẹru, iparun ati iku. Awọn eniyan buburu ri ohun ti wọn padanu nipa igbesi aye iṣọtẹ wọn. Wọn kẹgan ogo ainipẹkun, ti o niwọn, ti o si pọ jọjọ, nigba ti a fifun wọn; ṣugbọn o ti wu wọn to nisinsinyii. Awọn ọkan ti wọn ṣegbe sọkun wipe: “Gbogbo iwọnyi ni i ba jẹ temi, ṣugbọn mo yan lati lé wọn jinna rere si mi. Ah, ifọju ajeji ti ifẹ okan! mo gba oṣi, itiju ati ainireti dipo alaafia, idunnu ati ọla.” Gbogbo wọn ri wipe o tọna ni bi a ko ti faaye gba wọn ni ọrun. Nipa igbesi aye wọn, wọn ti sọ pe: “A ko ni jẹ ki Ọkunrin yii [Jesu] o ṣakoso lori wa.”ANN 296.7

    Afi bi ẹni ti o wa ninu iran, awọn eniyan buburu wo iṣẹlẹ bi a ti de Ọmọ Ọlọrun lade. Wọn ri walaa okuta ofin Ọlọrun ni ọwọ Rẹ, ilana ti wọn gan, ti wọn si tẹ loju. Wọn ri bi ibuyọ iyanu, idunnu ati iyin lati ọdọ awọn ti a gbala, bi igbi orin didun ti ṣan wa si ọdọ awọn ti wọn wa ni ode ilu naa, gbogbo wọn fi ohun kan kede wipe, “Titobi ati iyanu ni iṣẹ Rẹ, Oluwa Ọlọrun Alagbara; otitọ ati ododo ni ọna Rẹ, Iwọ Ọba awọn eniyan mimọ”(Ifihan 15:3); gbogbo wọn wolẹ, wọn si jọsin fun Ọmọ Alade iye.ANN 297.1

    O dabi ẹnipe Satani ko ni agbara mọ bi o ti n wo ogo ati ọlanla Kristi. Ẹni ti o fi igba kan jẹ kerubu ti o n bò ranti ibi ti o ti ṣubu. Serafu didan, “ọmọ owurọ,” iyipada ti baa to! O ti di ẹni irẹsilẹ to! A le e kuro titi lae ni aarin igbimọ ti a ti fi igba kan bu ọla fun ri. O ri ẹlomiran ti o duro sunmọ Baba, ti o n bo ogo Rẹ. O ri ti angẹli giga ọlọla kan gbe ade le ori Kristi, o si mọ wipe ipo giga ti o je ti angẹli naa ye ki o jẹ ti oun.ANN 297.2

    O ranti ile rẹ nigba ti o wa ni ailẹṣẹ ati ni mimọ, alaafia ati itẹlọrun ti o ni ki o to bẹrẹ si nii kun si Ọlọrun ti o si n jowu Kristi. Ifẹsunkan rẹ, iṣọtẹ rẹ, itanjẹ rẹ lati ri ikaanu ati itilẹyin awọn angẹli, orikunkun rẹ lati maṣe ṣe akitiyan kankan lati ṣe atunṣe nigba ti Ọlọrun i ba fun ni idariji—gbogbo rẹ ni o wa siwaju rẹ ketekete. O ranti iṣẹ rẹ laarin awọn eniyan ati atubọtan rẹ—iṣọta eniyan si eniyan ẹlẹgbẹ rẹ, ìpa ẹmi run ni ọna ti o lẹru, idide ati iṣubu awọn ijọba, wíwó itẹ lulẹ, rogbodiyan ni ṣisẹ n tẹle fun igba pipe, wahala ati idoju ijọba bolẹ. O ranti iṣẹ rẹ ni aisinmi lati tako iṣẹ Kristi ati lati jẹ ki eniyan o tubọ tẹri si. O ri wipe ete buburu rẹ ko lagbara lati pa awọn ti wọn fi igbẹkẹle wọn sinu Kristi run. Bi Satani ti wo ijọba rẹ, eso wahala rẹ, ibaku ati iparun nikan ni o ri. O ti jẹki ọpọlọpọ o gbagbọ wipe Ilu Olorun a jẹ ohun ti wọn le ni laiṣa ipa pupọ; ṣugbọn o mọ wipe irọ ni eyi. Lati igba de igba ní bi ariyanjiyan nla naa ti n lọ, a n ṣẹgun rẹ, a si n fi ipa mu lati juwọ silẹ. O mọ agbara ati ọlanla Ẹni Ainipẹkun daradara.ANN 297.3

    Afojusun oluṣọtẹ nla naa ni lati da ara rẹ lare ati lati fihan wipe iṣejọba Ọlọrun ni o ṣe okunfa iṣọtẹ naa. Ohun ti o fi gbogbo agbara ọgbọn nla rẹ ṣe niyi. O ṣiṣẹ pẹlu ọgbọn ati eto, pẹlu aṣeyọri ti o yanilẹnu, o jẹki eniyan o gba ẹda tirẹ nipa ijakadi nla naa, eyi ti o ti bẹrẹ tipẹ. Fun ọpọ ọdun ọga ninu iṣọtẹ yii fi irọ leni lọwọ dipo otitọ. Ṣugbọn akoko ti to wayi ti a o ṣẹgun iṣọtẹ rẹ patapata ti a o si tu iwa ati itan Satani sita. Ninu akitiyan nla rẹ ti o kẹyin lati yọ Kristi loye, ki o pa awọn eniyan Rẹ run, ki o si gba Ilu Ọlọrun, a fi oju atannijẹ nla naa han. Awọn ti wọn fi ohun ṣọkan pẹlu rẹ ri wipe iṣẹ rẹ baku patapata. Awọn atẹle Kristi ati awọn angẹli olootọ ri bi ète rẹ lati tako ijọba Ọlọrun ti pọ to. O di ohun pato ti gbogbo aye korira.ANN 297.4

    Satani ri wipe bi oun ti mọọmọ ṣọtẹ si Ọlọrun ti mu ki oun di aiyẹ fun ọrun. O ti kọ gbogbo agbara rẹ lati tako Ọlọrun; iwa mimọ, alaafia ati iṣọkan ọrun yoo jẹ ifiyajẹni ti o ga julọ fun. A wa pa ifẹsunkan rẹ si aanu ati idajọ Ọlọrun lẹnumọ. Ẹgan ti o ti n ṣe akitiyan lati ko ba Jehofa ni o wa duro si ori ara rẹ patapata. Bayi Satani tẹriba o si jẹwọ ododo idajọ Rẹ.ANN 297.5

    “Tani ki yoo bẹru Rẹ Oluwa, ti ki yoo si fi ogo fun orukọ Rẹ? nitori ti Iwọ jẹ mimọ: nitori ti gbogbo orilẹ ede ni yoo wa jọsin niwaju Rẹ: nitori ti a ti fi idajọ Rẹ han.” Ẹsẹ 4. Gbogbo ibeere lori otitọ ati irọ ninu ijakadi ọlọjọ pipẹ naa ni a o fihan kedere. Atubọtan iṣọtẹ, eso kikọ ofin Ọlọrun silẹ, ni a gbekalẹ nigbangba niwaju awọn ẹda to lọgbọn lori. Abajade aṣẹ Satani ni iyatọ si iṣejọba Ọlọrun ni a gbe kalẹ niwaju gbogbo agbala aye. Iṣẹ Satani funra rẹ ni o da a lẹbi. A da ọgbọn Ọlọrun, idajọ Rẹ ati oore Rẹ lare patapata. A ri wipe gbogbo iṣesi Rẹ ninu ijakadi nla naa ni O ṣe pẹlu ero lati ri rere ainipẹkun fun awọn eniyan Rẹ ati rere gbogbo awọn aye ti O da. “Gbogbo iṣẹ Rẹ ni yoo yin Ọ Oluwa; awọn eniyan mimọ Rẹ yoo si bukun fun Ọ.” O. Dafidi 145:10. Itan ẹṣẹ yoo duro titi ayeraye gẹgẹ bi ẹri wipe idunnu gbogbo awọn ẹda Rẹ sopọ mọ iwalaaye ofin Ọlọrun. Pẹlu gbogbo otitọ inu ijakadi nla naa niwaju wọn, gbogbo agbaala aye, ati awọn olootọ ati awọn ọlọtẹ, yoo fi ohùn kan kigbe wipe: “Ododo ati otitọ ni ọna Rẹ, Iwọ Ọba awọn eniyan mimọ.”ANN 297.6

    A fihan kedere niwaju araye ẹbọ ti Baba ati Ọmọ ṣe nitori eniyan. Akoko naa to ti Kristi yoo joko ni aaye ti o tọ si ti a o si ṣe E logo ju gbogbo ipa ati agbara ati ohun gbogbo ti n jẹ orukọ lọ. Nitori ayọ ti a gbe ka iwaju Rẹ—lati le ko ọpọlọpọ ọmọ wa si inu ogo—ni O ṣe fi ara da agbelebu, ti O ṣe gan itiju. Bi ibanujẹ ati itiju naa ti pọ ju eyi ti a le ro lọ to, ayọ ati ogo si pọ ju u lọ. O wo awọn ti a rapada ti a tun ṣe ninu aworan ara Rẹ, ti gbogbo ọkan ní aworan pipe Ọlọrun, ti gbogbo oju n fi ìrí Ọba wọn han. O kiyesi irora ọkan Rẹ, o si tẹ Ẹ lọrun. Nigba naa pẹlu ohùn ti o ró de ọdọ awọn olododo ati eniyan buburu, O kede wipe: “Kiyesi awọn ti a fi ẹjẹ Mi ra! Nitori awọn wọnyi ni mo ṣe jiya, nitori ti wọn ni Mo ṣe ku, ki wọn le ma a gbe niwaju Mi titi aye ainipẹkun.” Awọn ti wọn wọ aṣọ funfun ti wọn yi itẹ naa ka si kọ orin iyin wipe: “Ọdọ Aguntan ti a pa ni O yẹ lati gba agbara, ati ọla, ati ọgbọn, ati okun, ati iyin ati ogo ati ibukun.” Ifihan 5:12.ANN 298.1

    Bi o tilẹ jẹ wipe o ti di dandan fun Satani lati gba idajọ Ọlọrun ati lati tẹriba fun akoso Kristi, iwa rẹ ko yi pada. Ẹmi iṣọtẹ, bi iṣan omi nla, tun ru jade lẹẹkan si. O kun fun ibinu, o pinu lati maṣe juwọ silẹ ninu ijakadi nla naa. Akoko ti to lati jijadu ti o kẹyin lati tako Ọba ọrun. O sare la aarin awọn atẹle rẹ kọja o si ṣe akitiyan lati mi si wọn pẹlu ibinu rẹ, ki o si ru wọn soke lati ja ogun lọgan. Ṣugbọn laarin ọpọ eniyan ti a ko le ka naa, awọn ti o tan wọ inu iṣọtẹ, ko si ẹni ti o ṣetan lati gba akoso rẹ. Agbara rẹ ti dopin. Awọn eniyan buburu kun fun ẹmi ikorira kan naa si Ọlọrun, iru eyi ti o wa ninu Satani; ṣugbọn wọn ri wipe ko si ireti lori ọrọ wọn mọ, wipe wọn ko le ṣẹgun Jehofa. Ibinu wọn ru si Satani ati awọn ti wọn jẹ aṣoju rẹ ninu itanjẹ, pẹlu ibinu bii ti awọn ẹmi aimọ, wọn kọlu wọn.ANN 298.2

    Oluwa wipe: “Nitori ti iwọ ti ṣe ọkan rẹ bi ọkan Ọlọrun, kiyesi, Emi yoo mu awọn ajeji wa ba ọ, awọn ẹlẹru ninu awọn orilẹ ede: wọn yoo si fa ida wọn yọ si ẹwa ọgbọn rẹ, wọn yoo si ba itansan rẹ jẹ. Wọn yoo mu ọ wa sinu iho.” “Emi yoo pa ọ run, kerubu ti o n bo, kuro laarin okuta ina. . . . Emi yoo ju ọ silẹ, Emi o tẹ ọ siwaju awọn ọba, ki wọn ki o le kiyesi ọ. . . . Emi yoo sọ ọ di eeru lori ilẹ aye ni oju awọn ti n wo ọ. . . . Iwọ yoo di ẹru, iwọ ki yoo si si mọ laelae.” Isikiẹli 28:6—8, 16—19.ANN 298.3

    “Gbogbo ogun jagunjagun ni o ni ariwo idarudapọ, a ti aṣọ ti a yi ninu ẹjẹ; ṣugbọn eyi yoo jẹ pẹlu jijo ati ohun amunajo.” “Ibinu Oluwa wa lori gbogbo orilẹ ede ati irunu Rẹ lori gbogbo awọn ogun wọn: O pa wọn run patapata, O ti jọwọ wọn lọwọ fun pipa.” “Yoo rọjo ẹyin ina ti n jo, ati ina ati sulfuru ati iji lile ẹlẹru si ori awọn eniyan buburu: eyi ni yoo jẹ ipin agọ wọn.” Aisaya 9:5; 34; 2; O. Dafidi 11:6. Ina sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun ni ọrun. Ilẹ aye lu sita. A ko awọn ohun ija ti a pamọ sinu ọgbun rẹ sita. Ina ajonirun tu jade lati inu awọn ọgbun ti wọn lanu silẹ wa. Awọn apata n jona. Ọjọ naa ti de ti yoo jo bi ina ileru. Awọn iṣẹda yọ nitori ooru gbigbona, ile aye pẹlu, ati awọn iṣẹ inu rẹ jona luulu. Malaki 4:1, 2; 2 Peteru 3:10. Oju ilẹ aye dabi okun kan ṣoṣo—adagun ina nla kan ti n jo. O jẹ akoko idajọ ati iparun awọn alaiwabiọlọrun—”ọjọ igbẹsan Oluwa, ati ọdun isan pada nitori ọrọ Sioni.” Aisaya 34:8.ANN 298.4

    Awọn eniyan buburu gba ẹsan wọn ninu aye. Owe 11:31. Wọn “yoo dabi ageku koriko: ọjọ naa ti n bọ wa yoo si jo wọn luulu, ni Oluwa awọn ọmọ ogun wi.” Malaki 4:1. A pa awọn kan run ni oju ẹsẹ, nigba ti awọn miran jiya fun ọjọ pipẹ. A jẹ gbogbo wọn niya “gẹgẹ bi iṣẹ wọn.” A ti ko ẹṣẹ awọn olododo sori Satani, ki yoo jiya nitori iṣọtẹ rẹ nikan, ṣugbọn fun gbogbo ẹṣẹ ti o jẹki awọn eniyan Ọlọrun o da. Ijiya ẹṣẹ rẹ pọ daradara ju ti awọn ti a tanjẹ lọ. Lẹyin ti gbogbo awọn ti wọn ṣubu nitori itanjẹ rẹ ba parun tan, yoo si wa laaye ti yoo si maa jiya lọ. Lẹyinọrẹyin awọn eniyan buburu parun ninu ina afọ-nnkan-mọ, gbongbo ati ẹka—Satani ni gbongbo, awọn atẹle rẹ ni ẹka. A ti ṣe ibẹwo ijiya ofin ni kikun, a ti ṣe ohun ti idajọ beere fun, orun ati aye yoo kiyesi, wọn yoo si kede ododo Jehofa.ANN 298.5

    Iṣẹ iparun Satani pari titi lae. Fun ẹgbẹrun ọdun mẹfa, o ti ṣe ifẹ rẹ, ni fifi iparun kun inu aye, o si n fa ibanujẹ ọkan kaakiri gbogbo agbaala aye. Gbogbo ẹda ni o kerora ti wọn si n rọbi papọ ninu irora. Nisinsinyii a gba gbogbo iṣẹda Ọlọrun kuro niwaju rẹ ati idanwo rẹ. “Gbogbo aye sinmi, o si wa ni idakẹjẹ: wọn [awọn olododo] bu si orin kikọ.” Aisaya 14:7. Gbogbo agbaala aye to jẹ olootọ a kigbe iyin ati iṣẹgun. A gbọ “ohùn ọpọ eniyan nla,” “bi iro ohùn iṣan omi pupọ, ati ohùn ara nla,” ti n wipe: Halleluya: nitori ti Oluwa Ọlọrun alagbara jọba.” Ifihan 19:6.ANN 298.6

    Nigba ti ina iparun yi aye po, awọn olododo wa ni alaafia ninu Ilu Mimọ naa. Iku keji ko lagbara lori awọn ti wọn kopa ninu ajinde akọkọ. Nigba ti Ọlọrun jẹ ina ajonirun si awọn eniyan buburu, O jẹ oorun ati aabo fun awọn eniyan Rẹ. Ifihan 20:6; O. Dafidi 84:11.ANN 299.1

    Mo ri ọrun tuntun ati aye tuntun kan: nitori ti ọrun iṣaaju ati aye iṣaaju ti kọja lọ.” Ifihan 21:1. Ina ti o jo awọn eniyan buburu run ni o fọ aye mọ. A gbá gbogbo ami egun lọ. Ko si ina ajooku ti yoo maa mu awọn ti a rapada ranti atubọtan ẹlẹru ti ẹṣẹ.ANN 299.2

    Ohun iranti kan ṣoṣo ni yoo duro: Ami ikanmọ agbelebu yoo wa ni ara Olugbala titi lae. Ni ori Rẹ ti a ti ṣa lọgbẹ, ni ẹgbẹ Rẹ, ọwọ ati ẹsẹ Rẹ, ni awọn ami ti yoo fihan iṣẹ buburu ti ẹṣẹ ṣe. Nigba ti o wo Kristi ninu ogo, woli naa wipe: “O ni itansan didan ti o n jade lati ẹgbẹ Rẹ wa: nibẹ ni ifipamọ agbara Rẹ wa.” Habakuku 3:4. Ẹgbẹ naa ti a gun ni ọkọ nibi ti ẹjẹ ti san jade bá eniyan laja pẹlu Ọlọrun—nibẹ ni ogo Olugbala wa, nibẹ ni “ifipamọ agbara Rẹ wa.” Nipasẹ ẹbọ irapada Rẹ, “O ni agbara lati gbala,” nitori naa O ni agbara lati ṣe idajọ lori awọn ti wọn gan aanu Ọlọrun. Awọn ami irẹsilẹ Rẹ ni ọla Rẹ ti o ga julọ; titi aye ainipẹkun ọgbẹ Kalfari a fi iyin Rẹ han, yoo si kede agbara Rẹ.ANN 299.3

    “Iwọ Ile Iṣọ agbo aguntan, odi ọmọbinrin Sioni, si ọdọ Rẹ ni yoo wa, ani ijọba iṣaaju.” Mika 4:8. Akoko naa de eyi ti awọn eniyan mimọ ti n wọna fun pẹlu ifẹ ọkan lati akoko ti ida ina ti sé awọn tọkọtiyawo akọkọ mọ ita Edẹni, akoko fun “irapada ohun ini ti a rà.” Efesu 1:14. Ile aye ti a kọkọ fun eniyan gẹgẹ bi ijọba rẹ, ti o fi si ọwọ Satani, ti alatako alagbara naa di mu fun igba pipẹ, ni a gba pada nipasẹ eto nla ti irapada. Gbogbo ohun ti a padanu nitori ẹṣẹ ni a mu bọ sipo pada. “Bayii ni Oluwa wi . . . ti O da aye ti O si ṣe e; O ti fi idi rẹ mulẹ, ko da a lasan, O da a ki a le maa gbe inu rẹ.” Aisaya 45:18. A mu erongba Ọlọrun lati ibẹrẹ dida aye wa si imuṣẹ bi o ti jẹ ile ayeraye fun awọn ti a rapada. “Awọn olododo yoo jogun ilẹ naa, wọn yoo si gbe ninu rẹ titi lae.” O. Dafidi 37:29.ANN 299.4

    Ibẹru lati maṣe sọ ohun ajogunba ọjọ iwaju wa di ohun ti ara jù ti jẹ ki ọpọlọpọ o ṣe alaye awọn otitọ ti wọn n dari wa lati wo o bi ile wa ni ọna ti ẹmi. Kristi fi da awọn ọmọ ẹyin Rẹ loju wipe Oun n lọ pese aye silẹ fun wọn ninu ile Baba Oun. Awọn ti wọn gba ikọni ọrọ Ọlọrun ko ni jẹ alaimọkan patapata nipa ibugbe wọn ti ọrun. Sibẹ “oju koi ti i ri, bẹẹni eti koi ti i gbọ, bẹẹni koi ti i wọ inu ọkan eniyan lọ ri, awọn ohun ti Ọlọrun ti pese silẹ fun awọn ti o fẹ Ẹ.” 1 Kọrintin 2:9. Ede eniyan ko to lati ṣe alaye ẹsan awọn olododo. Awọn ti wọn ba ri i nikan ni yoo mọ ọ. Ko si oye eniyan ti o le ni oye ogo Paradise Ọlọrun.ANN 299.5

    Ninu Bibeli, a pe ogún awọn ti a gbala ni “ilu.” Heberu 11:14—16. Nibẹ Oluṣọ aguntan ọrun a dari awọn agbo Rẹ lọ si orisun omi iye. Igi iye n so eso rẹ loṣooṣu, ewe rẹ si n ṣiṣẹ fun awọn orilẹ ede. Awọn iṣan omi ti ki i gbẹ, ti wọn mọ gaara bi kristali, wa nibẹ ti awọn igi ti n mì si ṣe ibòji sí oju ọna awọn ẹni irapada Oluwa, nibẹ awọn pẹtẹlẹ ti wọn fẹ wú ga di oke ti wọn lẹwa, ti oke Olorun si wa loke tente. Ni awọn pẹtẹlẹ alaafia wọnni, ni ẹgbẹ awọn omi iye nì, nibẹ ni awọn eniyan Ọlọrun, ti wọn ti jẹ arinrinajo ati alarinkiri fun igba pipẹ, a ṣe ile wọn si.ANN 299.6

    “Awọn eniyan Mi yoo gbe ni ibugbe alaafia, ati ni ile ti o daju, ati ni ibi isinmi idakẹrọrọ.” “A ki yoo gbọ iwa ipa mọ ni ilẹ rẹ, ifiṣofo, tabi iparun ninu aala rẹ; ṣugbọn iwọ yoo pe ogiri rẹ ni Igbala, ati ilẹkun rẹ ni Iyin.” “Wọn yoo kọ ile, wọn yoo si gbe inu rẹ; wọn yoo gbin ọgba ajara, won yoo si jẹ eso wọn. Wọn ki yoo kọ ile ki ẹlomiran o gbe inu rẹ; wọn ki yoo gbin ki ẹlomiran o jẹ ẹ: . . . Awọn ayanfẹ Mi yoo jere iṣẹ ọwọ wọn.” Aisaya 32:18; 60:18; 65:21, 22.ANN 299.7

    Nibẹ, “awọn aginju ati ibi idanikanwa yoo yọ nitori wọn; inu aṣalẹ yoo dun, yoo si yọ bi ododo.” “Igi Sipirẹsi yoo hu jade dipo ẹgun, igi miritili yoo hu jade dipo oṣuṣu.” “Ikooko pẹlu yoo maa ba ọdọ aguntan gbe pọ, amọtẹkun yoo si dubulẹ pẹlu ọmọ ewurẹ; ọmọ kekere yoo si maa dà wọn.” “Wọn ki yoo panilara, bẹẹ ni wọn ki yoo panirun ni gbogbo oke mimọ Mi,” ni Oluwa wi. Aisaya 35:1; 55:13; 11:6, 9.ANN 300.1

    Ko le si irora ni ayika ọrun. Ki yoo si ẹkun mọ, ki yoo si orin oku, ki yoo si ami ọfọ. “Ki yoo si iku mọ, tabi ẹkun: . . . nitori awọn ohun atijọ ti kọja lọ.” “Awọn olugbe rẹ ki yoo wipe, Aisan n ṣe mi: a yoo dari aiṣedeede awọn ti n gbe ninu rẹ ji.” Ifihan 21:4; Aisaya 33:24.ANN 300.2

    Eyi ni Jerusalẹmu Tuntun, olu ilu nla aye tuntun ti a ṣe logo, “ade ogo ni ọwọ Oluwa, ati ade ọba ni ọwọ Ọlọrun rẹ.” “Imọlẹ rẹ dabi okuta ti o ṣeyebiye julọ, ani bi okuta jasperi, ti o mọ bi kristali.” “Awọn orilẹ ede awọn ti a gbala yoo rin ninu imọlẹ rẹ: awọn ọba aye si n mu ogo ati ọla wọn wa si inu rẹ.” Oluwa wipe: “Emi yoo dunnu ninu Jerusalẹmu, Emi yoo si yọ ninu awọn eniyan Mi.” “Ibugbe Ọlọrun wa pẹlu awọn eniyan, yoo si wa pẹlu wọn, awọn yoo si jẹ eniyan Rẹ, Ọlọrun funra Rẹ yoo si wa pẹlu wọn, yoo si jẹ Ọlọrun wọn.” Aisaya 62:3; Ifihan 21:11, 24; Aisaya 65:19; Ifihan 21:3.ANN 300.3

    “Ki yoo si aṣalẹ” ninu Ilu Ọlọrun. Ko si ẹni ti yoo nilo tabi fẹ lati sinmi. Ki yoo si ikaarẹ ni ṣiṣe ifẹ Ọlọrun ati yinyin orukọ Rẹ. A o ni awọ tutu owurọ titi aye ki yoo si dopin. “Wọn ko si nilo fitila, tabi imọlẹ oorun; nitori ti Oluwa Ọlọrun fun wọn ni imọlẹ.” Ifihan 22:5. Imọlẹ ti itansan rẹ ko panilara a mọlẹ ju itansan oorun lọ, sibẹ ni ọna ti a ko le fẹnusọ, o mọlẹ ju itansan ọsan gangan lọ. Ogo Ọlọrun ati ti Ọdọ Aguntan fi imọlẹ ti ki i ṣa kun inu Ilu Mimọ naa. Awọn ẹni ti a rapada a rin ninu ogo ailoorun ọjọ ayeraye.ANN 300.4

    “Emi ko ri tẹmpili ninu rẹ: nitori Oluwa Ọlọrun Alagbara ati Ọdọ Aguntan ni tẹmpili rẹ.” Ifihan 21:22. Awọn eniyan Ọlọrun ni anfani lati ba Baba ati Ọmọ sọrọ lojukooju. “Bayi a n riran nipasẹ digi ti n wo baibai.” 1 Kọrintin 13:12. A n wo aworan Ọlọrun ti a fihan, bii lati inu iṣẹ iṣẹda, ati ninu ibaṣepọ Rẹ pẹlu eniyan; ṣugbọn nigba naa a o ri I lojukoju, laisi aṣọ iboju laarin. A o duro niwaju Rẹ a o si ri ogo oju Rẹ.ANN 300.5

    Nibẹ awọn ti a rapada yoo mọ, ani bi a ti mọ wọn pẹlu. Ifẹ ati ikaanu ti Ọlọrun funra Rẹ gbin sinu ọkan yoo ṣiṣẹ ni ọna tootọ, ti o tun dun julọ nibẹ. Ibaṣepọ mimọ pẹlu awọn eniyan mimọ, ifọwọsowọpọ ibagbe pẹlu awọn angẹli alabukun fun ati awọn olootọ lati igba yii wa, ti wọn ti fọ aṣọ wọn mọ ti wọn si sọ ọ di funfun ninu ẹjẹ Ọdọ Aguntan, ìdè mimọ ti o so “gbogbo idile ni ọrun ati ni aye” (Efesu 3:15) pọ—awọn wọnyi ni yoo jẹ idunnu fun awọn ti a ra pada.ANN 300.6

    Nibẹ oye aiku yoo ronu pẹlu idunnu ti ko le dopin, iyanu agbara dida nnkan, ohun ijinlẹ ifẹ irapada. Ko ni si ọta atannijẹ, lati dánniwò lati gbagbe Ọlọrun. Gbogbo agbara ẹbun eniyan ni yoo dagba soke, a o fikun gbogbo agbara. Kiko ọgbọn jọ ko ni ko aarẹ ba ọkan tabi lo agbara eniyan tan. Nibẹ a yoo ṣe iṣẹ ti o tobi julọ, a o de ibi ilepa ọkan ti o ga julọ, a o mu ifẹ ọkan ti o ga julọ ṣẹ; sibẹ, a yoo ri awọn oke tuntun miran lati gun, ohun iyanu tuntun miran lati ronu le lori, otitọ tuntun miran lati ni oye rẹ, awọn ohun tuntun ti yoo nilo agbara oye ati ọkan ati ara.ANN 300.7

    Gbogbo ohun alumọni gbogbo agbaye ni a yoo wá fun awọn ẹni irapada Ọlọrun lati kọ. Iku ti fi wọn silẹ, wọn a fo lọ laikaarẹ si awọn aye to jinna—awọn aye ti wọn kun fun ibanujẹ nigba ti wọn ri ijiya eniyan, ti wọn tun kọ orin idunnu nitori iroyin ọkan kan ti a rapada. Pẹlu idunnu ti a ko le fẹnu sọ, awọn ọmọ ile aye a wọ inu ayọ ati ọgbọn awọn ẹda ti ko ṣubu. Wọn a pin ninu ohun iṣura imọ ati oye ti a ni fun igba pipẹ ni rironu lori iṣẹ ọwọ Ọlọrun. Pẹlu iran ti ko baku, wọn a wo ogo iṣẹda—awọn oorun ati irawọ ati akojọ awọn ayé, gbogbo wọn ni ọna ti a la fun wọn ti wọn n yi itẹ Ọlọrun po. A kọ orukọ Ẹlẹda si ara ohun gbogbo, lati ori kekere de nla, a si fi ọrọ agbara Rẹ han ninu ohun gbogbo.ANN 300.8

    Bi ọdun ti n yipo, wọn a mu ifihan Ọlọrun ati ti Kristi ti o logo ti o tun pọ si wa. Bi imọ ti n pọ si, bẹẹ ni ifẹ, ijọsin ati inu didun a pọ si. Bi eniyan ti n kọ nipa Ọlọrun si, bẹẹ ni wọn a ni ifẹ iwa Rẹ si. Bi Jesu ti ṣi ọrọ irapada ati awọn iṣẹgun iyanu ninu ijakadi nla pẹlu Satani fun wọn, ọkan awọn ti a ra pada a kun fun ifọkansin onitara si, ati pẹlu idunnu ayọ nla wọn a lu duru wura wọn; ti ẹgbẹẹgbẹrun ati ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun ohùn a parapọ lati kọ orin iyin nla.ANN 301.1

    “Gbogbo ẹda ni ọrun ati ni aye ati ni abẹ ilẹ ati ti awọn ti n bẹ ninu okun ati gbogbo awọn ohun ti n bẹ ninu wọn, ni mo gbọ ti n wipe, Ibukun, ati ọla ati ogo ati agbara, fun Ẹni ti O joko lori itẹ ati fun Ọdọ Aguntan naa lae ati lae.” Ifihan 5:13.ANN 301.2

    Ijakadi nla naa pari. Ẹṣẹ ati awọn ẹlẹṣẹ ko si mọ. Gbogbo agbaala aye patapata di mimọ. Iṣan iṣọkan ati idunnu kan ṣoṣo ni o n la gbogbo agbaala aye ja. Lati ọdọ Rẹ ti O da ohun gbogbo, ni iye ti n ṣan, ati imọlẹ ati idunnu, ni gbogbo aye ti ko lopin. Lati ara ẹda ti o kere julọ titi de aye ti o tobi julọ, ohun gbogbo, eyi ti o ni ẹmi ati eyi ti ko ni ẹmi, ninu ẹwa didan ati ayọ pipe n kede wipe ifẹ ni Ọlọrun.ANN 301.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents