Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KẸSAN—ALATUNṢE TI ILẸ SWISTZERLAND

    Ni yiyan awọn ohun elo fun atunṣe ijọ, a ri agbekalẹ Ọlọrun kan naa gẹgẹ bi a ti ri i ni gbigbe ijọ kalẹ. Olukọ ọrun ré awọn ẹni giga aye kọja, awọn oloruko ati ọlọrọ, ti o ti mọ lara lati maa gba iyin ati ijọsin gẹgẹ bi adari awọn eniyan. Igberaga ati idara-ẹni-loju wọn pọ ninu ifọnnu wọn gẹgẹ bi ọga ti o fi jẹ wipe a ko le kọ wọn lati ṣe ikaanu fun awọn eniyan ẹlẹgbẹ wọn ki wọn si di olubaṣiṣẹpọ pẹlu onirẹlẹ Ara Nasarẹti. Awọn ti ko mọwe, apẹja Galili ni a pé wipe: “Ẹ tẹle mi Emi yoo si sọ yin di apẹja eniyan.” Matiu 4:19. Awọn ọmọ ẹyin wọnyi jẹ onirẹlẹ, wọn si ṣe e kọ. Bi ikọni èké akoko wọn ṣe ni ipa kekere lori wọn to, bẹẹ ni Kristi ṣe le dari wọn, ki O si kọ wọn fun iṣẹ Rẹ to. Bẹẹ gẹgẹ ni o ri ni akoko iṣẹ Atunṣe Nla. Awọn Alatunṣe ti wọn ṣe pataki julọ jẹ awọn ti ko lokiki—awọn eniyan ti wọn ko ni igberaga ti ipo igba naa n mu wa, ti itara alaimoye, ati ète awọn alufa ko ni ipa lori wọn. Eto Ọlọrun ni lati lo awọn ohun elo ti wọn rẹlẹ lati ṣe awọn ohun nla. A ko ni fun eniyan ni ogo naa, bikoṣe Ẹni ti o ṣiṣẹ nipasẹ wọn lati rò ati lati ṣe ifẹ inu rẹ.ANN 74.1

    Lẹyin ọsẹ diẹ ti a bi Luther ninu ile awakusa ni Saxony, a bi Ulric Zwingli si ile oluṣọ-aguntan laarin Alps. Awọn ohun ti wọn yi Zwingli ka ni igba ọmọde rẹ, ati ikọni rẹ bi o ṣe n dagba jẹ eyi ti wọn pese rẹ silẹ fun iṣẹ rẹ ni ọjọ iwaju. O dagba laarin ẹwa, ọwọ, ati titobi ohun ti a da, ọkan rẹ tete tẹ mọ titobi, ọla ati agbara Ọlọrun. Itan awọn iṣẹlẹ akikanju ti wọn ṣẹlẹ lori awọn oke abinibi rẹ yii ta ìlépa igba ọdọ rẹ ji. Ni ẹgbẹ iya agba ti o ni ifọkansin, o gbọ awọn itan ti wọn ṣe iyebiye lati inu Bibeli eyi ti o le ranti lati inu itan iṣẹnbaye ati awọn akọsilẹ ijọ. Pẹlu ifẹ ọkan ti o gbona, ọ gbọ nipa awọn iṣẹ nla awọn baba nla ati awọn woli, ti awọn oluṣọ-aguntan ti wọn n sọ agbo ẹran wọn ni ori oke Palestine nibi ti awọn angẹli ti ba wọn sọrọ nipa Ọmọ jojolo Betlehem ati Ọkunrin Kalfari.ANN 74.2

    Bii ti Luther, baba Zwingli fẹ ki ọmọ oun o kawe, a si tete ran ọmọ naa jade kuro ninu afonifoji ile rẹ. Iye rẹ tete ji pepe, o wa di wipe nibo ni a yoo ti ri olukọ ti o kun oju oṣuwọn lati kọ. Nigba ti o pe ọmọ ọdun mẹtala, o lọ si Bern, ilu ti o ni ile ẹkọ ti o dara julọ ni Switzerland nigba naa. Ṣugbọn nibi, isoro kan dide ti o fẹ pa ina ireti ọjọ ọla rẹ. Awọn alufa onibara pinu lati fa a wa si ile awọn ajẹjẹ ẹsin. Awọn ajẹjẹ ẹsin ti Dominican ati ti Franciscan ni wọn n jijọ n jijadu fun ẹni ti o lokiki julọ. Wọn n wọna lati ri eyi nipa bi wọn ti ṣe ile ijọsin wọn lọṣọ si, bi isin wọn ti jẹ alarinrin to, ati nini awọn ohun iranti ti wọn lokiki ati awọn ère ti n ṣiṣẹ iyanu.ANN 74.3

    Awọn ẹgbẹ Dominican ti Bern ri wipe bi wọn ba le fa ọdọmọde, ọlọpọlọ akẹkọ yii mọra, wọn a ni èrè ati ọla. Bi o ti ṣe kere to, ati ẹbun abinibi rẹ gẹgẹ bi sọrọsọrọ, ati onkọwe, oye rẹ fun orin ati ewì, yoo ṣiṣẹ pupọ fun wọn ju gbogbo aṣehan ati ayẹyẹ wọn lọ lati kó awọn eniyan wa sinu isin wọn, ati lati jẹ ki owo ẹgbẹ wọn o pọ si. Wọn fẹ fi ẹtan ati ipọnni tan Zwingli wa si inu ile ẹsin wọn. Nigba ti Luther wa ni ile ẹkọ, o de ara rẹ mọ inu yara ile awọn ajẹjẹ ẹsin, araye ki ba ti mọ ọ bi ko ba i ṣe agbara Ọlọrun ti o tu silẹ. A ko gba Zwingli laaye lati koju iru ewu yii. Ọlọrun jẹ ki baba rẹ o mọ nipa ète awọn alufa onibara yii. Ko fẹ ki ọmọ oun o gbe igbesi aye ọlẹ ati alainilari awọn alufa ajẹjẹ ẹsin. O ri wipe iwulo rẹ fun ọjọ iwaju wa ninu ewu, o si paṣẹ fun ki o wa sile kankan.ANN 74.4

    O gbọ aṣẹ baba rẹ, ṣugbọn ko tẹ ọdọ naa lọrun lati wa ninu afonifoji ile rẹ yii, laipẹ, o pada si ẹnu ẹkọ rẹ, nigba ti o lọ si Basel. Nibi ni Zwingli ti kọkọ gbọ nipa iyinrere oore ọfẹ Ọlọrun. Nigba ti Wittembach, olukọ ninu awọn ede atijọ, n kọ nipa Giriki ati Heberu, o ri Iwe Mimọ, bayi ni imọlẹ ọrun ṣe tan si ọkan awọn akẹkọ ti wọn wa ni abẹ ikọni rẹ. O sọ wipe otitọ atijọ kan wa, ti o fi ohun gbogbo niyelori ju ohun ti awọn elero ijinlẹ ati olukọ ile ẹkọ fi n kọni lọ. Otitọ atijọ yii ni wipe iku Kristi nikan ni irapada ẹlẹṣẹ. Awọn ọrọ wọnyi dabi imọlẹ ti n ba ọjọ yọ fun Zwingli.ANN 74.5

    Laipẹ a pe Zwingli lati Basel lati wa bẹrẹ iṣẹ ọjọ aye rẹ. Ile ijọsin ti o wa ni Alps ni ibi iṣẹ rẹ akọkọ, ko si jinna si afonifoji abinibi rẹ. Lẹyin ti a gbe ọwọ le lori gẹgẹ bi alufa, o “jọwọ gbogbo ọkan rẹ silẹ lati wa otitọ Ọlọrun; nitori ti o mọ daju,” bi Alatunṣe akẹgbẹ rẹ ti sọ nipa rẹ, “iye ohun ti o yẹ ki oun mọ, gẹgẹ bi ẹni ti a fi agbo Kristi le lọwọ.” Bi o ti n wa Iwe Mimọ si, bẹẹ ni iyatọ ti o wa laarin awọn otitọ inu rẹ ati awọn èké Romu n tubọ n fi ara han si. O jọwọ ara rẹ fun Bibeli gẹgẹ bi ọrọ Ọlọrun, aṣẹ kan ṣoṣo ti o tọ ti ko si le baku. O ri wipe, o nilati jẹ olutumọ ara rẹ. Ko jẹ fi Iwe Mimọ gbe awọn ikọni ati igbagbọ ti o ti gba tẹlẹ lẹsẹ, ṣugbọn o ri wipe ojuṣe oun ni lati mọ ẹkọ inu rẹ ti o han kedere ni pato. O lo gbogbo ọna ti o ri lati le ni oye kikun ti o si tọna nipa itumọ rẹ, o si bẹbẹ fun iranlọwọ Ẹmi Mimọ, eyi ti o sọ wipe yoo fihan fun gbogbo awọn ti wọn ba fi tọkantọkan ati adura wa.ANN 75.1

    Zwingli sọ wipe, “Iwe Mimọ wá lati ọdọ Ọlọrun, ki i ṣe ọdọ eniyan, ani Ọlọrun ti n funni ni òye yoo fun ọ ni òye lati mọ wipe ọrọ naa ti ọdọ Ọlọrun wa. Ọrọ Ọlọrun . . . ko le baku; o mọlẹ, o n kọni funra rẹ, o n fi ara rẹ han, o n fi gbogbo igbala ati oore ọfẹ tan imọlẹ si inu ọkan, o n tu u ninu ninu Olorun, o n rẹ ẹ silẹ, ki o baa le padanu ara rẹ, ani ki o sọ ara rẹ nu, ki o si di mọ Ọlọrun.” Zwingli funra rẹ mọ itumọ otitọ awọn ọrọ wọnyi. Nigba ti o n sọ nipa iriri rẹ ni akoko yii, o kọwe wipe: “Nigba ti . . . mo bẹrẹ si nii jọwọ ara mi patapata fun Iwe Mimọ, ero ijinlẹ, ati ẹkọ nipa Ọlọrun ti a kọ ni ile ẹkọ maa n mu ero ti o yatọ wa sinu ọkan mi. Lẹyin-ọrẹyin, mo ronu wipe, ‘O nilati fi gbogbo iwọnyi silẹ, ki o si kọ nipa Ọlọrun lati inu ọrọ otitọ Rẹ nikanṣoṣo.’ Mo wa n beere lọwọ Ọlọrun fun imọlẹ Rẹ, Iwe Mimọ wa bẹrẹ si nii rọrun fun mi.”ANN 75.2

    Zwingli ko gba ikọni ti o n waasu rẹ lati ọdọ Luther. Ikọni Kristi ni. Alatunṣe ara Swiss naa sọ wipe, “Bi Luther ba n waasu Kristi, o n ṣe ohun ti mo n ṣe. Awọn ti o kó wa si ọdọ Kristi pọ ju titemi lọ. Ṣugbọn eyi ko ni itumọ. Emi ko ni jẹ orukọ miran ayafi ti Kristi, ọmọ ogun Eni ti emi i ṣe, ti o si jẹ wipe Oun nikanṣoṣo ni Balogun mi. Luther koi tii kọ iwe kankan si mi, bẹẹ ni emi koi tii kọ iwe kankan si Luther. Kilo de? . . . Ki a baa le fihan bi Ẹmi Ọlọrun ti wa ni ibamu pẹlu ara Rẹ to ni, niwọn igba ti o jẹ wipe, awa mejeeji, laipade rí n waasu ikọni Kristi ni ọna ti o ba ara wọn mu bayii.”ANN 75.3

    Ni ọdun 1516, a pe Zwingli lati wa jẹ oniwaasu ni ile awọn ajẹjẹ ẹsin ni Einsiedeln. Yoo ni oye nipa awọn iwa ibajẹ Romu si nihin, yoo si ni ipa ti yoo rin jinna kọja Alps, ilẹ abinibi rẹ gẹgẹ bi Alatunṣe. Lara awọn ohun ti wọn ṣe pataki julọ ni Einsiedeln ni ère Wundia ti a sọ wipe o ni agbara lati ṣe iṣẹ iyanu. A kọ si ara atẹrigba oju ọna ti o wọ inu ile ijọsin naa wipe, “Ẹ le ri idariji ẹṣẹ gba nibi.” Ni gbogbo igba ni awọn arinrinajo ẹsin maa n lọ si ojubọ Wundia yii; ṣugbọn ni igba ajọdun nla iyasimimọ rẹ, ọpọlọpọ eniyan maa n wa lati gbogbo ilẹ Switzerland, ani lati France ati Germany. Inu bi Zwingli pupọpupọ nitori iṣẹlẹ yii, o wa lo anfani yii lati kede ominira nipasẹ iyinrere si awọn ti igbagbọ asan ti di ni igbekun yii.ANN 75.4

    O sọ wipe, “Ẹ maṣe ro wipe Ọlọrun wa ninu tẹmpili yii ju bi O ti wa ninu gbogbo ohun ti O da lọ. Ni ibikibi ti ẹ ba n gbe, Ọlọrun wa ni ọdọ yin, O si n gbọ yin. . . . Njẹ awọn iṣẹ ti ko ni èrè, awọn irin ajo ẹsin gigun gbọọrọ, ọrẹ, ère, gbigbadura si Wundia tabi awọn eniyan mimọ le fun yin ni oore ọfẹ Ọlọrun bi? . . . Èrè wo ni o wa ninu ọpọlọpọ ọrọ ti a n sọ ninu adura? Anfani wo ni o wa ninu aṣọ alufa didan ti a da bo ọrùn, ori ti a fá dán, aṣọ gọrọjọ ti n fẹ lẹlẹ, tabi bata pẹkẹlẹ ti a fi wura ṣe lọṣọ? . . . Ọlọrun n wo ọkan, ọkan wa si jinna si.” O sọ wipe, “Kristi, Ẹni ti a pa lẹẹkanṣoṣo ni ori agbelebu, ni ẹbọ ati ohun ti a pa fun ẹṣẹ, ti o san gbese ẹṣẹ awọn onigbagbọ titi lae.”ANN 75.5

    Ọpọlọpọ awọn olugbọ rẹ ni ko faramọ awọn ikọni yii. O jẹ ijakulẹ kikoro lati sọ fun wọn wipe asan ni irin ajo oniwahala ti wọn rin. Idariji ti a fifun wọn lọfẹ nipasẹ Kristi ko ye wọn. Ọna atijọ lati de ọrun, ti Romu la kalẹ fun wọn tẹ wọn lọrun. Wọn yago kuro ninu wahala ti o wa ninu wiwá ohun ti o dara ju eyi lọ. O rọrun lati fi igbala wọn si ọwọ awọn alufa ati popu ju lati wa ọkàn mimọ lọ.ANN 75.6

    Ṣugbọn awọn ẹgbẹ miran gba iroyin igbala nipasẹ Kristi pẹlu ayọ. Awọn ohun tí Romu ni kí wọn ṣe ko mu alaafia wá sinu ọkan wọn, wọn si fi igbagbọ gba ẹjẹ Olugbala gẹgẹ bi imukuro fun ẹṣẹ wọn. Awọn wọnyi pada lọ si ile lati fi imọlẹ iyebiye ti wọn gbà han awọn miran. Bayi ni a ṣe gbé imọlẹ lati ile de ile, ilu de ilu, ti iye awọn ti wọn n wa si ojubọ Wundia si dinku jọjọ. Iye owo ọrẹ ti n wọle dinku, nitori naa, owo oṣu Zwingli, ti a n san lati inu wọn. Ṣugbọn eyi mu inu rẹ dun ni nigba ti o ri wipe agbara itara aimọkan ati ẹsin èké ti fọ.ANN 76.1

    Oju awọn alaṣẹ ijọ kò fọ si ayọrisi iṣẹ Zwingli; ṣugbọn ni akoko yii wọn ko ṣe ohun kankan si. Wọn si n reti lati yii pada si ọna wọn, wọn ṣa ipa lati mu pẹlu ọrọ ẹtan; ṣugbọn ni akoko yii, otitọ n fi ẹsẹ mulẹ ninu ọkan awọn eniyan.ANN 76.2

    Iṣẹ Zwingli ni Einsiedeln pèsè rẹ silẹ fun iṣẹ ti o pọ si ni, eyi ti yoo bẹrẹ laipẹ. Lẹyin ọdun mẹta, a pè é wa lati jẹ oniwaasu ni katedra ti o wà ni Zurich. Eyi jẹ ilu ti o ṣe pataki julọ ninu awọn ilu ti wọn parapọ di orilẹ ede Swiss ni akoko yii, ohun ti a ba ṣe nibi yoo tan kaakiri. Awọn ijoye ijọ ti wọn pè é wa si Zurich ko fẹ ki atunṣe kankan o wà, nitori naa, wọn tẹsiwaju lati sọ awọn ojuṣe rẹ fun.ANN 76.3

    Wọn sọ fun wipe, “Wà á ṣe ohun gbogbo ti o yẹ lati gba awọn owó ti wọn tọ si ile ijọsin laifi oju fo eyi ti o kere julọ da. Wà á gba awọn onigbagbọ niyanju, lati ori pẹpẹ iwaasu, ati ninu ile ijẹwọ ẹṣẹ, lati san gbogbo idamẹwa, ati awọn owo ti o yẹ, ki wọn si fi ifẹ wọn fun ijọ han nipasẹ owo ọrẹ wọn. Wa a ṣiṣẹ daradara lati jẹ ki owo ti o n wọle lati ọdọ awọn alaisan, mass, ati lati inu gbogbo awọn ilana ijọ o pọ si.” Awọn olukọ rẹ sọ fun wipe, “Fifunni ni àmì majẹmu ijọ, iwaasu, ati biboju tó agbo naa wà lara iṣẹ oniwaasu. Ṣugbọn o le gba elomiran lati ṣe eyi, ni pataki julọ fun iṣẹ iwaasu. O kò gbọdọ fun ẹnikẹni ni ami majẹmu ayafi eniyan pataki, bi wọn ba beere fun si ni; a kì ọ nilọ lati maṣe fun ẹnikẹni laiwo ipo rẹ.”ANN 76.4

    Zwingli tẹti silẹ laisọrọ si ikilọ yii, nigba ti o n fesi, o fi imoore rẹ han fun ọla ti wọn bu fun ni pipe é wa si ipo pataki yii, o tẹsiwaju lati ṣe alaye ohun ti o gbero lati ṣe. O sọ wipe, “A ti pa igbesi aye Kristi mọ kuro ni oju awọn eniyan fun igba pipẹ. Maa waasu lori gbogbo Iyinrere ti Matiu, . . . lati orisun Iwe Mimọ nikan, maa ṣe alaye rẹ ni kikun, ni fifi awọn ẹsẹ wé ara wọn, ati wiwa òye pẹlu adura tọkantọkan atigbadégba. Maa ṣe iṣẹ iranṣẹ mi fun ogo Ọlọrun, fun iyin Ọmọ Rẹ kanṣoṣo, fun igbala tootọ fun awọn eniyan, ati fun gbigbe igbagbọ tootọ larugẹ.” Bi o tilẹ jẹ wipe diẹ lara awọn ijoye ko fi ọwọ si ilana rẹ, ti wọn si ṣa ipá lati yi pada, Zwingli duro ṣinṣin. O sọ wipe oun kò mu ilana tuntun wá, bikoṣe ilana atijọ tí ijọ nlo ni igba iṣaaju nigba ti o wà ni mimọ.ANN 76.5

    Awọn eniyan ti n nifẹ si awọn otitọ ti o n kọni; ọpọ awọn eniyan si n wọ lọ lati gbọ iwasu rẹ. Awọn ti o ti pẹ ti wọn ti wa si ile ijọsin mọ wa ninu awọn olugbọ rẹ. O bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ nipa ṣiṣi awọn Iyinrere, yoo ka a, yoo si ṣe alaye lori akọsilẹ ti a mi si nipa igbesi aye, ikọni ati iku Kristi si awọn olugbọ rẹ. Nibi, gẹgẹ bi o ti ṣe ni Einsiedeln, o fi ọrọ Ọlọrun han gẹgẹ bi aṣẹ kan ṣoṣo ti kò le baku, ati iku Kristi gẹgẹ bi irubọ ti o péye. O sọ wipe, “Mo fẹ lati dari yin si ọdọ Kristi—si ọdọ Kristi, ipilẹ tootọ fun igbala.” Oriṣiriṣi awọn eniyan ni wọn yí oniwaasu naa ká, lati ori awọn oloṣelu ati ọmọwe titi de ọdọ awọn oniṣẹ ọwọ ati agbẹ. Awọn eniyan n tẹti si ọrọ rẹ pẹlu ifẹ ọkan tootọ. Ki i ṣe wipe o n waasu igbala ti a fun ni lọfẹ nikan, ṣugbọn o fi igboya ba awọn iwa buburu ati iwa ibajẹ akoko naa wi. Ọpọlọpọ ni wọn n yin Ọlọrun logo bi wọn ti n kuro ni ile ijọsin. Wọn sọ wipe, “Oniwaasu otitọ ni ọkunrin yii. Oun ni yoo jẹ Mose wa ti yoo dari wa jade kuro ninu okunkun Ijibiti.”ANN 76.6

    Bi o tilẹ jẹ wipe a kọkọ fi idunnu gba iṣẹ rẹ, lẹyin igba diẹ, àtakò dìde. Awọn alufa ajẹjẹ ẹsin ṣiṣẹ lati dí iṣẹ rẹ lọwọ ati lati tako awọn ikọni rẹ. Awọn kan fi ṣe ẹlẹya, wọn si kẹgan rẹ; awọn miran ṣe afojudi si ti wọn si n halẹ mọ. Ṣugbọn Zwingli fi suuru fi ara da gbogbo rẹ, o sọ wipe: “Bi a ba fẹ lati jere awọn eniyan buburu si ọdọ Kristi, a nilati di oju wa si ọpọlọpọ nnkan.”ANN 76.7

    Ni aarin akoko yii, osiṣe tuntun kan wá lati ran iṣẹ atunṣe lọwọ. Ọrẹ igbagbọ ti a fọmọ yii ni Basel ran ẹnikan ti o n jẹ Lucian wa si Zurich pẹlu diẹ lara awọn iwe Luther, o sọ wipe, tita awọn iwe yii le jẹ ọna ti o lagbara lati tan imọlẹ naa ka. O kọwe si Zwingli wipe, “Woo boya ọkunrin yii ni ọgbọn ati oye ti o yẹ; bi o ba ri bẹẹ, jẹ ki o gbe awọn iṣẹ Luther kaakiri ọdọ awọn ara Swiss, lati ilu de ilu, lati ileto de ileto, lati abule de abule, ani lati ile de ile, paapaa julọ itumọ rẹ lori Adura Oluwa, eyi ti o kọ fun awọn ọmọ ijọ. Bi a ba ti ṣe mọ wọn si bẹẹ ni awọn olubara rẹ yoo ti pọ to.” Bayii ni imọlẹ ṣe ri aaye wọle.ANN 77.1

    Ni igba ti Ọlọrun n mura lati já ide aimọkan ati ẹsin èké, ni akoko naa ni Satani n ṣiṣẹ pẹlu gbogbo agbara lati ju awọn eniyan sinu okunkun ati lati dè wọn mọlẹ si. Bi awọn eniyan ti n dide ni orisirisi ilu lati fi idariji ati idalare nipasẹ ẹjẹ Kristi han awọn eniyan, Romu n tẹsiwaju pẹlu agbara lakọtun lati ṣi ọja rẹ si gbogbo ilẹ ti n ṣe ẹsin Kristẹni, o n ta idariji ẹṣẹ nitori owo.ANN 77.2

    Gbogbo ẹṣẹ ni o iye owo rẹ, ti a si n fun awọn eniyan ni aṣẹ lati dẹṣẹ laisi idiwọ, bi ile iṣura ba saa ti kun. Ẹgbẹ mejeeji yii n tẹsiwaju,—ọkan n fun ni ni idariji ẹṣẹ nitori owo, ekeji n waasu idariji ẹṣẹ nipasẹ Kristi,—Romu n faaye gba ẹṣẹ, o n sọ ọ di ọna lati ri owo; awọn Alatunṣe n ṣe ibawi ẹṣẹ, wọn n tọka si Kristi gẹgẹ bi olumukuro ẹṣẹ, ati oludande.ANN 77.3

    Awọn alufa onibara ti ẹgbẹ Dominican ni a gbe iṣẹ tita idariji ẹṣẹ fun ni Germany, Tetzel, oniwaibajẹ si ni o n ṣe adari rẹ. Ọwọ awọn ẹgbẹ Franciscan ni a fi si ni Switzerland, labẹ akoso Samson, ajẹjẹ ẹsin ara Italy. Samson ti ṣe iṣẹ ti o dara fun ijọ ná, niwọn igba ti o ti gba owo nla si inu apo ijọ padi lati Germany ati Switzerland. Nisinsinyii, o n rin ilẹ Switzerland kaakiri, ti ọpọ ero si n tẹle lẹyin, o n gba owo perete ti awọn agbẹ aroko ni lọwọ, o si n gba ẹbun nlanla lati ọdọ awọn ọlọrọ. Ṣugbọn agbara iṣẹ atunṣe naa n fi ara rẹ han ni dídí okoowo yii lọwọ, bi o tilẹ jẹ wipe kò le daa duro. Zwingli sì wà ni Einsiedeln nigba ti Samson, lẹyin ti o de si Switzerland, gbe ọja rẹ wọ inu ilu kan ti ko jina lọ. Niwọn igba ti a ti tá lólobó lori ohun ti o wa ṣe, Alatunṣe naa jade lọ ṣe atako rẹ. Awọn mejeeji kò pade ara wọn, ṣugbọn aṣeyọri Zwingli ni títú aṣiri ẹtan alufa onibara yii pọ debi wipe, o nilati fi ilu naa silẹ lọ si awọn ibomiran.ANN 77.4

    Ni Zurich, Zwingli fi itara waasu lati tako awọn ti n ta idariji ẹṣẹ; nigba ti Samson de ibẹ, iranṣẹ igbimọ ilu naa tọọ wá, o sọ fun wipe ko si aaye fun lati wọle. Pẹlu ọgbọn ẹwẹ, o ri aaye wọle nikẹyin, ṣugbọn a le kuro nibẹ laita ohun kan, laipẹ o fi Switzerland silẹ.ANN 77.5

    Ajakalẹ arun, tabi Iku Alagbara ti o wá si Switzerland ni ọdun 1519 tun fun iṣẹ atunṣe ni agbara si. Bi awọn eniyan ti n fi oju rinjú pẹlu apanirun yii, ọpọlọpọ ni wọn ri bi iwe idariji ẹṣẹ ti wọn sẹsẹ ra ti jasi asán ti ko si nitumọ to; wọn fẹ lati ni ipilẹ ti o daju fun igbagbọ wọn. Zwingli funra rẹ ri ikọlu aisan yii ni Zurich; o wọọ lara debi pe a léro wipe ara rẹ ko ni ya, a si n sọ kaakiri wipe o ti ku. Ireti ati igboya rẹ ko mi ni akoko idanwo yii. O fi igbagbọ wo agbelebu Kalfari, pẹlu igbẹkẹle ninu imukuro ẹṣẹ ti o daju. Nigba ti o pada de lati ẹnu bèbè iku, o fi itara waasu iyinrere ju ti tẹlẹ lọ; awọn ọrọ rẹ ni agbara ti o yanilẹnu. Awọn eniyan fi ayọ ki alufa wọn ọwọn kaabọ, ẹni ti o sẹsẹ ti bèbè isa òku dé. Awọn funra wọn sẹsẹ ṣiwọ titọju alaisan ati ẹni ti n ku lọ tan ni, wọn wa mọyi iyinrere ju ti tẹlẹ lọ.ANN 77.6

    Zwingli ni oye ti o mọ gaara nipa otitọ rẹ si, o si ni iriri agbara isọdimimọ rẹ si. Iṣubu eniyan ati eto igbala ni awọn ohun ti o n waasu le lori. O sọ wipe, “Gbogbo wa di oku ninu Adamu, a tẹri sinu iwa ibajẹ ati idalẹbi.” “Kristi . . . ti ra irapada ti ko le tan fun wa. . . . Ijiya rẹ jẹ . . . irubọ ayeraye, ti o si lè woni sàn patapata titi lae; ó tu idajọ Ọlọrun loju titi lae fun gbogbo ẹni ti o ba gbẹkẹle pẹlu igbagbọ ti o duro ṣinṣin, ti ko yẹ.” Sibẹ, o fi kọni kedere wipe eniyan ko ni ominira lati tẹsiwaju ninu ẹṣẹ nitori oore ọfẹ Kristi. “Nibikibi ti a ba ti ni igbagbọ ninu Ọlọrun, nibẹ ni Ọlọrun wa; nibikibi ti Ọlọrun ba wa, itara ti n muni ṣe iṣẹ rere yoo wa nibẹ pẹlu.”ANN 77.7

    Ifẹ awọn eniyan si iwaasu Zwingli pọ to bẹẹ gẹẹ ti ile ijọsin a kun akunfaya pẹlu awọn ero ti won wa n gbọ ọ. Diẹdiẹ, ní bi wọn ti ṣe le gba a, o n ṣipaya otitọ si awọn olugbọ rẹ. O sọra lati maṣe kọkọ waasu awọn ohun ti yoo dáyàfò wọn, ti yoo si fa ikunsinu. Iṣẹ rẹ ni lati jere ọkan wọn sinu ẹkọ Kristi, lati ṣẹ wọn rọ pẹlu ifẹ Rẹ, ati lati gbe apẹẹrẹ rẹ siwaju wọn; bi wọn ba ṣe n gba ikọni iyinrere, bẹẹ ni igbagbọ ati iṣẹ asan wọn yoo maa ṣi kuro.ANN 78.1

    Diẹdiẹ ni iṣẹ Atunṣe naa n tẹsiwaju ni Zurich. Awọn ọta rẹ bẹrẹ atako kikan pẹlu ibẹru. Ni ọdun kan sẹyin, ajẹjẹ ẹsin ti Wittenberg ti ṣe rárá si popu ati ọba ni Worms, ó wa dabi ẹnipe ohun gbogbo n tọka si iru ikọsilẹ aṣẹ popu kan naa ni Zurich. A ṣe atako lemọlemọ si Zwingli. Ni gbogbo igba ni a n dana sun awọn atẹle iyinrere ni agbegbe awọn atẹle popu, ṣugbọn eyi kò tó; a nilati pa olukọ ẹkọ odi lẹnu mọ. Lati ṣe eyi, biṣọbu Constance ran aṣoju mẹta lọ si igbimọ ni Zurich, wọn fi ẹsun kan Zwingli wipe o n kọ awọn eniyan lati tako awọn ofin ijọ, o si n tipa eyi da alaafia ati eto daradara ti o wa ninu awujọ ru. O sọ wipe bi a ba kọ aṣẹ ijọ silẹ, idarudapọ yoo bẹ silẹ nibi gbogbo. Zwingli dahun wipe òun ti n kọni ni iyinrere ni Zurich, “eyi ti o ni alaafia ati idakejẹ ju ilukilu lọ ninu orilẹ ede naa” fun ọdun mẹrin. O wa sọ wipe, “Njẹ ẹsin Kristẹni kọ ni o wa dara julọ fun aabo gbogbo eniyan bi?”ANN 78.2

    Awọn aṣoju naa gba awọn alaṣẹ adugbo niyanju lati duro ninu ijọ, ati pe laisi rẹ, ko si igbala. Zwingli dahun wipe: “Ẹ maṣe jẹ ki ifẹsunkanni yii o da yin laamu. Ipilẹ ijọ ni Apata kan naa, Kristi kan naa, ti o fun Peteru ni orukọ rẹ, nitori ti o fi ododo jẹwọ Rẹ. Ọlọrun gba ẹnikẹni lati gbogbo orilẹ ede ti o ba gbagbọ ninu Jesu Oluwa pẹlu gbogbo ọkan rẹ. Eyi ni ijọ tootọ, ti ẹnikẹni ti ko ba si ninu rẹ kò le ri igbala.” Nitori apero yii, ọkan ninu awọn aṣoju biṣọbu naa gba igbagbọ ti a fọ mọ.ANN 78.3

    Igbimọ naa kọ lati gbe igbesẹ kankan lati tako Zwingli, Romu wa mura fun atako miran. Nigba ti Alatunṣe naa gbọ nipa ète awọn ọta rẹ, o sọ wipe: “Jẹ ki wọn maa bọ; mo bẹru wọn bi bebe okuta ti n bẹru omi ti n ru nisalẹ rẹ.” Akitiyan awọn oloye ijọ tubọ n jẹ ki iṣẹ ti wọn fẹ bì ṣubu o maa tẹsiwaju si ni. Otitọ naa n tẹsiwaju lati tan kalẹ. Bi Luther ti poora ba ọkan awọn atẹle rẹ jẹ ni Germany, ṣugbọn wọn tun mọkan le bi wọn ti ri bi iyinrere ti n tẹsiwaju ni Switzerland.ANN 78.4

    Bi iṣẹ Atunṣe ti n fẹsẹ mulẹ ni Zurich, ayọrisi rẹ fi ara han daradara ni titẹ iwa ọdaran rì, ti o si n jẹ ki ètò ati alaafia o jọba. Zwingli kọwe wipe, “Alaafia ṣe ibugbe rẹ sinu ilu wa, kò si ija, kò si agabagebe, ko si ìjowú, ko si wahala. Nibo ni iru iṣọkan bayi tile wá bikoṣe lati ọdọ Oluwa, ati awọn ikọni wa ti wọn fi èso alaafia ati iwabi-ọlọrun kun inu wa?”ANN 78.5

    Awọn iṣẹgun ti iṣẹ Atunṣe n ri tubọ n ru awọn ẹlẹsin Romu ninu soke si ni, wọn si sa ipa si lati bi i ṣubu. Nigba ti wọn ri aṣeyọri kekere ti wọn ṣe nipa ṣiṣe inunibini lati tẹ iṣẹ Luther ri ni Germany, wọn pinu lati fi ohun ija iṣẹ atunṣe koju rẹ. Wọn yoo ṣe ariyanjiyan pẹlu Zwingli, wọn yoo ṣe eto ohun gbogbo silẹ lati ri wipe wọn ṣẹgun nipa yiyan ibi ijiroro funra wọn, ki i ṣe eyi nikan, ṣugbọn wọn a tun yan awọn ti yoo ṣe idajọ ariyanjiyan naa. Bi wọn ba si tile ni Zwingli ni ikawọ wọn, wọn a ri wipe ko bọ mọ wọn lọwọ. Bi wọn ba ti pa olori rẹ lẹnu mọ, ẹgbẹ naa yoo fọ ni kiakia. Ṣugbọn wọn fi ète yii ṣe asiri.ANN 78.6

    A yan Baden gẹgẹ bi ibi ti a o ti ṣe ariyanjiyan yii; ṣugbọn Zwingli ko si nibẹ. Awọn igbimọ Zurich ni ifura si ète awọn ẹlẹsin popu, bi wọn ti n danasun awọn ti wọn ṣe ijẹwọ iyinrere ni agbegbe awọn atẹle popu sì ti kì wọn nilọ, nitori naa, wọn ko jẹ ki alufa wọn o fi ara rẹ si inu ewu. Ni Zurich, o ṣetan lati koju gbogbo awọn aṣoju ti Romu ba le ran; ṣugbọn lati lọ si Baden, nibi ti a ti ta ẹjẹ ọpọlọpọ awọn ajẹriku fun otitọ silẹ, yoo tumọ si wiwọ ẹnu iku lọ. A yan Oecolampadius ati Haller lati ṣe aṣoju Alatunṣe naa, nigba ti ilumọọka Dr Eck, ti ọpọlọpọ awọn ọmọwe ati alufa agba ti lẹyin jẹ olugbeja Romu.ANN 78.7

    Bi o tilẹ jẹ wipe Zwingli ko si ninu apero naa, a ri ipa rẹ. Awọn atẹle popu nikan ni wọn yan awọn akọwe, wọn si kilọ fun ẹnikẹni lati maṣe kọ ohunkohun silẹ bi wọn ko ba fẹ ku. Pẹlu eleyi, Zwingli n gba iroyin kikun lori ohun ti wọn sọ ni Baden. Akẹkọ kan ti o wa ni ibi ariyanjiyan yii n ṣe akọsilẹ awọn ohun ti wọn ba sọ ni ọjọ naa bi o ba ti di aṣalẹ. Awọn akẹkọ meji kan a wa ko awọn iwe wọnyi, pẹlu awọn lẹta Oecolampadius, lọ si ọdọ Zwingli ni Zurich. Alatunṣe naa a dahun si wọn, o n gba wọn niyanju, o si n fun wọn ni imọran. Aṣalẹ ni o n kọ lẹta tirẹ, awọn akẹkọ wọnyi a si ko wọn dani pẹlu wọn lọ si Baden ni aarọ. Lati maṣe jẹ ki awọn asọbode ilu naa o funra si wọn, awọn iranṣẹ wọnyi a gbe àgò adiyẹ sori, à á sì jẹ ki wọn kọja laisi idiwọ.ANN 78.8

    Bayi ni Zwingli ṣe tẹsiwaju lati ba awọn alatako rẹ ti wọn jẹ ọlọgbọn ẹwẹ jagun. Myconius sọ wipe, o “ṣiṣẹ pupọ nipa ironu rẹ, àisun rẹ, ati imọran ti o n rán lọ si Baden, ju eyi ti i ba ṣe bi o ba funra rẹ wà nibè, ti o n jiroro pẹlu awọn ọta rẹ lọ.”ANN 79.1

    Inu awọn ẹlẹsin Romu ti n dun wipe awọn ni yoo ṣẹgun, nitori naa, wọn wa si Baden pẹlu aṣọ olowo iyebiye ati awọn ohun ọṣọ ara didan. Wọn n gbe igbesi aye ọlọrọ, ti tabili wọn si kun fun onjẹ olowo iyebiye ati ọti waini ti o dara julọ. Wọn n ṣe ẹfẹ, wọn si n ṣe ariya alariwo lati le dá ara wọn lara yá lẹyin wahala iṣẹ ìjọ. Awọn Alatunṣe yatọ patapata si eyi; awọn eniyan n wo wọn gẹgẹ bi ẹni ti o fi diẹ san ju awọn onibara lọ, awọn ti onjẹ perete ti wọn n jẹ ki i jẹ ki wọn pẹ lori tabili onjẹ. Ẹni ti o gba Oecolampadius sile n wo o ninu yara rẹ, o ri wipe biko ba kawe, a maa gbadura, o wa yaa lẹnu jọjọ, ti o fi sọ wipe ẹlẹkọ odi naa saa jẹ “olufọkansin pupọpupọ.”ANN 79.2

    Ninu apero naa, “Eck fi igberaga gun ori pẹpẹ iwasu ti a ṣe lọsọ pupọpupọ, nigba ti Oecolampadius, onirele, ẹni ti aṣọ rẹ ko lowo lori joko niwaju alatako rẹ lori apoti kan ṣa.” Ohùn Eck rinlẹ, idaniloju rẹ ko si ba a ku. Itara rẹ tun lagbara si nitori ireti goolu ati okiki; nitori owo nla ni a yoo fi ta olugbeja igbagbọ lọrẹ. Nigba ti sisọrọ ti o mọgbọn wa bàkù, o bẹrẹ si nii sọrọ ni ọna itabuku, ti o si n bura.ANN 79.3

    Oecolampadius wa ni iwọntuwọnsi, kò si gbẹkẹle ara rẹ, o súnrakì kuro ninu wahala naa, ṣugbọn nisinsinyii, o wọ inu rẹ pẹlu ileri ọlọwọ wipe: “Emi ko mọ odiwọn kan fun idajọ ayafi ọrọ Ọlọrun.” Bi o tilẹ jẹ wipe o jẹ onirẹlẹ, ti o si n bọwọ fun ni ninu iwa rẹ, o fi ara rẹ han gẹgẹ bi ẹni ti o kun oju oṣuwọn, ti o si duro ṣinṣin. Nigba ti awọn ẹlẹsin Romu, gẹgẹ bi iṣe wọn, n lo aṣa ijọ, Alatunṣe naa duro gbọingbọin pẹlu Iwe Mimọ. O sọ wipe, “Aṣa ko ni agbara ni Switzerland, ayafi bi o ba wa ni ibamu pẹlu iwe ofin; ninu ọrọ igbagbọ, Bibeli ni iwe ofin wa.”ANN 79.4

    Iyatọ ti o wa laarin awọn olujiyan mejeeji yii ni ipa. Iṣọwọronu Alatunṣe ti o da ṣaka, ti o gbé kalẹ pẹlu irẹlẹ ati suuru, ni itumọ loju awọn ti wọn fi irira yipada kuro ni ọdọ ifọnnu ati ariwo Eck.ANN 79.5

    Ọjọ mejidinlogun ni wọn fi ṣe apero naa. Ni opin rẹ, awọn atẹle popu fi igboya sọ wipe awọn ni wọn gbégbá orókè. Ọpọlọpọ awọn ijoye ni wọn ti Romu lẹyin, igbimọ naa kede wipe awọn Alatunṣe naa baku, a tun sọ wipe, ati awọn, ati olori wọn Zwingli, a yọ wọn kuro ninu ijọ. Ṣugbọn awọn eso àpérò naa fi awọn ti wọn ni ajulọ han. Ijakadi naa fun iṣẹ awọn Protestant lokun si ni, ko si pẹ pupọ lẹyin eyi ti awọn ilu Bern ati Basel ṣe ijẹwọ lati tẹle iṣẹ Atunṣe.ANN 79.6

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents