ORI KẸWA—ÌDÀGBÀSOKÈ IṢẸ ÀTUNṢE NÍ GERMANY
ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA
- Contents- ORI KINI—ÌPARUN JÉRÚSÁLẸMÙ
- ORI KEJI— INÚNIBÍNI NÍ ỌGỌRUN ỌDÚN ÀKỌKỌ
- ORI KẸTA—ÀKÓKÒ ÒKÙNKÙN TI ẸMÍ
- ORI KẸRIN—AWỌN WALDENSES
- ORI KARUN—JOHN WYCLIFFE
- ORI KẸFA—HUSS ATI JEROME
- ORI KEJE—ÌYAPA LUTHER KÚRÒ NI ROMU
- ORI KẸJỌ—LUTHER NIWAJU ÌGBÌMỌ
- ORI KẸSAN—ALATUNṢE TI ILẸ SWISTZERLAND
- ORI KẸWA—ÌDÀGBÀSOKÈ IṢẸ ÀTUNṢE NÍ GERMANY
- ORI KỌKANLA—AWỌN IJOYE FI ẸHONU HAN
- ORI KEJILA—IṢẸ ÀTUNṢE NI ORILẸ-EDE FRANCE
- ORI KẸTALA—NETHERLANDS ATI SCANDINAVIA
- ORI KẸRINLA—ALATUNṢE IKẸYIN NI ENGLAND
- ORI KARUNDINLOGUN—BIBELI ATI IDOJU IJỌBA BOLẸ NI FRANCE
- ORI KẸRINDINLOGUN—AWỌN BABA ARINRIN-AJO
- ORI KẸTADINLOGUN—AWỌN AKÉDE ÒWÚRỌ
- ORI KEJIDINLOGUN—ALATUNṢE TI ILẸ AMẸRIKA
- ORI KỌKANDINLOGUN—IMỌLẸ LAARIN OKUNKUN
- ORI OGUN—ISỌJI NLA TI ẸSIN
- ORI KỌKANLELOGUN—IKILỌ TI A KỌ SILẸ
- ORI KEJILELOGUN—AWỌN ASỌTẸLẸ WA SI IMUṢẸ
- ORI KẸTALELOGUN—KINI IBI MIMỌ?
- ORI KẸRINLELOGUN—NINU IBI MIMỌ JULỌ
- ORI KARUNDINLỌGBỌN—OFIN ỌLỌRUN WA TITI LAE
- ORI KẸRINDINLỌGBỌN—IṢẸ ATUNṢE
- ORI KẸTADINLỌGBỌN—ISỌJI TI ODE ONI
- ORI KEJIDINLỌGBỌN—DIDOJUKỌ AKỌSILẸ NIPA IGBESI AYE
- ORI KỌKANDINLỌGBỌN—IPILẸSẸ IWA BUBURU
- ORI ỌGBỌN—IKORIRA LAARIN ENIYAN ATI SATANI
- ORI KỌKANLELỌGBỌN—AṢOJU AWỌN ẸMI EṢU
- ORI KEJILELỌGBỌN—AWỌN IDẸKUN SATANI
- ORI KẸTALELỌGBỌN—ITANJẸ NLA AKỌKỌ
- ORI KẸRINLELỌGBỌN—ṢE AWỌN ENIYAN WA TI WỌN TI KU LE BA WA SỌRỌ?
- ORI KARUNDINLOGOJI—IGBOGUNTI OMINIRA ẸRI ỌKAN
- ORI KẸRINDINLOGOJI—IKỌLU TI N BỌ
- ORI KẸTADINLOGOJI—IWE MIMỌ GẸGẸ BI AABO
- ORI KEJIDINLOGOJI—IKILỌ IKẸYIN
- ORI KỌKANDINLOGOJI—AKOKO IDAMU
- ORI OGOJI—A GBA AWỌN ENIYAN ỌLỌRUN SILẸ
- ORI KỌKANLELOGOJI—ILE AYE DI AHORO
- ORI KEJILELOGOJI—ARIYANJIYAN NAA PARI
Search Results
- Results
- Related
- Featured
- Weighted Relevancy
- Content Sequence
- Relevancy
- Earliest First
- Latest First
- Exact Match First, Root Words Second
- Exact word match
- Root word match
- EGW Collections
- All collections
- Lifetime Works (1845-1917)
- Compilations (1918-present)
- Adventist Pioneer Library
- My Bible
- Dictionary
- Reference
- Short
- Long
- Paragraph
No results.
EGW Extras
Directory
ORI KẸWA—ÌDÀGBÀSOKÈ IṢẸ ÀTUNṢE NÍ GERMANY
Bi Luther ti poora ni ọna ti a ko le ṣe alaye rẹ fa ibinu kaakiri gbogbo Germany. A n beere nipa rẹ ni ibi gbogbo. A n sọ awọn àhesọ ti wọn buru julọ nipa rẹ, ti ọpọlọpọ si gbagbọ wipe a ti pa a. Ọpọ eniyan ṣọfọ nitori rẹ, ki i ṣe awọn ọrẹ rẹ nikan, ṣugbọn ati awọn ẹgbẹgbẹrun ti wọn koi ti i fi ipinu wọn han nigbangba lati ṣe atilẹyin iṣẹ Atunṣe. Ọpọ ninu wọn ni wọn si da majemu wipe wọn yoo gbẹsan iku rẹ.ANN 80.1
Awọn adari ẹsin Romu bẹru lati ri bi ikorira awọn eniyan si wọn ti pọ to. Bi o tilẹ jẹ wipe inu wọn kọkọ dun nigba ti wọn ro wipe Luther ti ku, laipẹ, wọn fẹ lati fi ara pamọ kuro ninu ibinu awọn eniyan. Iwa ogboju rẹ ko damu awọn ọta rẹ nigba ti o wa ni aarin wọn bii ti igba ti a mu kuro ni aarin wọn. Awọn ti wọn n wọna lati pa Alatunṣe onigboya naa ninu ibinu wọn wa n bẹru nisinsinyii nigba ti o di ẹni igbekun ti ko le ran ara rẹ lọwọ. Ẹnikan sọ wipe, “Ọna kan ṣoṣo ti o ṣẹku lati gba ara wa la ni lati tan fitila, ki a wa Luther kaakiri gbogbo aye, ki a si da pada fun orilẹ ede ti n beere fun.” Aṣẹ ọba ko ni agbara mọ. Inu bi awọn aṣoju popu nigba ti wọn ri wipe awọn eniyan ko fi iyè si wọn bi wọn ti ṣe fi iye si ohun ti o ṣẹlẹ si Luther.ANN 80.2
Iroyin wipe o wa ni alaafia, bi o tilẹ jẹ wipe ẹlẹwọn ni ṣẹ ibẹru awọn eniyan rọ, ṣugbọn o tun fi ifẹ rẹ kun wọn lọkan si. Awọn eniyan n fi itara ka awọn iwe rẹ ju ti tẹlẹ lọ. Iye awọn eniyan ti wọn darapọ mọ iṣẹ akọni, ti ko bẹru ohun ti yoo ṣẹlẹ, ṣugbọn ti o duro ti ọrọ Ọlọrun yii, tubọ n pọ si. Iṣẹ Atunṣe tubọ n ni agbara si lojoojumọ. Irugbin ti Luther gbin wu ni ibi gbogbo. Aisinile ṣe iṣẹ ti i ba baku lati ṣe bi o ba wa nile. Awọn oṣiṣẹ miran ri ojuṣe tuntun, niwọn igba ti olori nla wọn ko si mọ. Pẹlu igbagbọ tuntun ati ifọkansin, wọn tẹsiwaju pẹlu ohun gbogbo ti agbara wọn le ṣe, ki iṣe ti o bẹrẹ daradara ma baa ni idiwọ.ANN 80.3
Ṣugbọn Satani ko kawọ gbinra. O wa ṣe ohun ti o saba maa n ṣe ni gbogbo igba ti ẹgbẹ alatunṣe ba dide—lati tan awọn eniyan jẹ, ati lati pa wọn run nipa fifun wọn ni ayederu dipo iṣẹ tootọ. Bi awọn èké Kristi ti wa ni ọrundun akọkọ ni ijọ Kristẹni, bẹẹ gẹgẹ ni awọn woli èke dide ni ọrundun kẹrindinlogun.ANN 80.4
Awọn eniyan diẹ, ti wọn ni imọlara ohun ti o n ṣẹlẹ ninu ilana ẹsin, ni ero wipe wọn ti gba ifihan pataki lati ọrun, wọn si n sọ wipe Ọlọrun ti yan wọn lati pari iṣẹ Atunṣe ti Luther fi imẹlẹ bẹrẹ. Ni tootọ, wọn n yi iṣẹ ti o ṣe pada ni. Wọn kọ otitọ nla ti o jẹ ipilẹsẹ iṣẹ Atunṣe silẹ—wipe ọrọ Ọlọrun jẹ odiwọn ti o tọ ti o si peye fun igbagbọ ati iṣesi; wọn si fi odiwọn èrò ọkan, ati imọlara ẹmi wọn ti ko daju ti o si n yipada rọpo. Nipa bi wọn ti yẹ ohun nla ti o n da irọ ati aṣiṣe mọ si ẹgbẹ kan yii, ọna ṣi silẹ fun Satani lati maa dari ọkan awọn eniyan bi o ti fẹ.ANN 80.5
Ọkan ninu awọn woli yii sọ wipe angẹli Gabrieli ni o kọ oun. Akẹkọ kan ti o dara pọ mọ fi ẹkọ rẹ silẹ, o n sọ wipe, Ọlọrun funra rẹ ti fun oun ni ọgbọn lati ṣe itumọ ọrọ Rẹ. Awọn miran ti wọn ni ẹmi igbonaraju ẹsin dara pọ mọ wọn. Ki i ṣe ariwo kekere ni iṣesi awọn alara gbigbona ẹsin yii da silẹ. Iwaasu Luther mu ki awọn eniyan ni ibi gbogbo o ri idi ti a fi nilo atunṣe, ṣugbọn nisinsinyii, irọ awọn woli tuntun yii ṣi awọn olootọ eniyan diẹ lọna.ANN 80.6
Awọn adari ẹgbẹ yii lọ si Wittenberg, wọn si sọ igbagbọ wọn fun Melancthon ati awọn alabasiṣẹpọ rẹ. Wọn sọ wipe: “Ọlọrun ni o ran wa wá lati ki awọn eniyan nilọ. A ti bá Ouwa sọrọ; a mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ; ni ọrọ kan, a jẹ apostoli ati woli, a si wa lati ba Dr Luther sọrọ.”ANN 80.7
Ẹnu ya awọn Alatunṣe, iporuuru ọkan si mu wọn, wọn koi ti i ri iru eleyi ri, nitori naa wọn ko mọ ohun ti wọn yoo ṣe. Melancthon so wipe: “Ẹmi ti o yatọ wa ninu awọn eniyan wọnyi lootọ; ṣugbọn iru ẹmi wo ni? . . . . Ni ọna akoko, ẹ jẹ ki a sọra lati maṣe pa ina Ẹmi, ṣugboọ ni idakeji, ki a sora ki ẹmi Satani maṣe ṣi wa lọna.”ANN 80.8
Eso ẹkọ tuntun yii fi ara han laipẹ. O jẹ ki awọn eniyan o kọ Bibeli silẹ, tabi ki wọn paáti patapata. Idarudapọ de ba awọn ile ẹkọ. Awọn akẹkọ kọ gbogbo ikora-ẹni-nijanu silẹ, wọn kọ ẹkọ wọn silẹ, wọn si fi ile ẹkọ giga silẹ. Awọn ti wọn ro wipe wọn kun oju oṣuwọn lati ta iṣẹ Atunṣe ji, ati lati dari rẹ tilẹ n ti i si bebe iparun ni. Awọn ẹlẹsin Romu wa ni igboya wọn pada, wọn si sọ pẹlu idunnu wipe: “Ijakadi kan ṣoṣo ni o ku, gbogbo re yoo si jẹ tiwa.”ANN 81.1
Nigba ti Luther, ti o wa ni Wartburg gbọ ohun ti o ṣẹlẹ yii, o sọ pẹlu aniyan wipe: “Mo ti n reti wipe Satani yoo ran wahala yii si wa.” O woye iwa awọn ti wọn n pe ara wọn ni woli wọnyi o si ri ewu ti o fẹ wu iṣẹ otitọ. Atako popu ati ti ọba kò fun ni wahala ati aniyan ọkan ti ó wa n ni nisinsinyii. Awọn ọta ti o buru julọ fun iṣẹ Atunṣe jade lati inu awọn ti wọn pe ara wọn ni ọrẹ rẹ. Awọn otitọ ti wọn fun ni ayọ nla ati itunu ni a wa n lo lati fa wahala, ti a si n fi n da idarudapọ silẹ ninu ijọ.ANN 81.2
Ẹmi Ọlọrun ni o ran Luther lọwọ ninu iṣẹ Atunṣe, o si ṣe e ju bi agbara rẹ ti mọ lọ. Ko ro lati ṣe awọn ipinu ti o ṣe, tabi lati ṣe awọn ayipada nla ti o ṣe. O jẹ ohun elo ni ọwọ Agbara Ayeraye. Sibẹ o wariri fun ayọrisi iṣẹ rẹ. O sọ nigba kan wipe: “Bi mo ba ri wipe ikọni mi pa ẹnikan lara—eniyan kan ṣoṣo, bi o tile wu ki o jẹ ẹni yẹpẹrẹ, ti ko si lokiki to,—eyi ti ko le ṣe nitori iyinrere funra rẹ ni,—maa yan lati ku ni ẹẹmẹwa ju ki n kọ lati yipada lọ.”ANN 81.3
Ni akoko yii, Wittenberg funra rẹ, aarin gungun iṣẹ Atunṣe funra rẹ, n yara ṣubu sabẹ agbara igbonara ẹsin ati iwa ailofin. Awọn iṣẹlẹ buburu yii ko waye nitori awọn ikọni Luther; ṣugbọn awọn ọta rẹ n fi ẹsun yii kan an kaakiri gbogbo ilẹ Germany. Ninu ẹdun ọkan rẹ, o maa n beere nigba miran wipe: “Ṣe bi opin yoo ti deba iṣẹ Atunṣe niyii?” Ṣugbọn bi o ti ba Ọlọrun jijadu ninu adura, alaafia wa sinu ọkan rẹ. O sọ wipe, “Iṣẹ naa ki i ṣe temi, ṣugbọn ti Rẹ ni, Iwọ ko ni jẹ ki igbonara ẹsin, tabi ẹkọ eke o ba a jẹ.” Ṣugbọn ko le fi ara da a ki oun o kuro loju ija ni iru akoko wahala yii. O pinu lati pada si Wittenberg.ANN 81.4
Ni kia, o bẹre irin ajo elewu yii. A ti le kuro ninu ilu. Awọn ọta ni ominira lati pa; a ti ki awọn ọrẹ rẹ nilọ lati maṣe ran an lọwọ tabi gba a silé. Ijọba n ṣe atako si awọn atẹle rẹ lọna ti o buru julọ. Ṣugbọn o ri ti ewu n wu iṣẹ iyinrere, o si jade lọ ni oruko Oluwa, laibẹru, lati ja fun otitọ.ANN 81.5
Ninu lẹta ti o kọ si afọbajẹ, nigba ti o sọ ipinu rẹ lati kuro ni Wartburg, Luther sọ wipe: “Jẹ ki o di mimọ fun ọlanla rẹ wipe mo n lọ si Wittenberg labẹ aabo ti o fi ohun gbogbo ga ju ti awọn ijoye tabi ti afọbajẹ lọ. Mi o ro lati beere fun iranlọwọ ọlọlajulọ rẹ, bẹẹ ni mi o fẹ aabo rẹ, dipo bẹẹ, maa daabo bo ọ funra mi. Bi mo ba mọ wipe ọlọlajulo rẹ le tabi yoo daabo bo mi, mi o ni lọ si Wittenberg rara. Ko si ida kan ti o le jẹ ki iṣẹ yii o tẹsiwaju. Ọlọrun nikan ni o nilati ṣe ohun gbogbo, laisi iranlọwọ tabi atilẹyin eniyan. Ẹni ti o ba ni igbagbọ ti o tobi julọ ni o le daabo boni julọ.”ANN 81.6
Ninu lẹta keji ti o kọ loju ọna Wittenberg, Luther fi kun pe: “Mo ṣetan lati gba aidunnu ọlọlajulọ, ati ibinu gbogbo aye. Ṣe ki i ṣe awọn ara Wittenberg ni aguntan mi ni? Ṣe Ọlọrun kọ ni o fi wọn fun mi ni? Ṣe ko wa yẹ bi o ba nilo bẹẹ, lati koju iku nitori wọn? Ati wipe, mo bẹru lati ri ajalu nla ti o fẹ ṣẹlẹ ni Germany, eyi ti Ọlọrun yoo fi ṣe idajọ fun orilẹ ede wa.”ANN 81.7
O bẹrọ iṣẹ rẹ pẹlu iṣọra, irẹlẹ, sibẹ pẹlu ipinu ati iduroṣinṣin. O sọ wipe, “Ọrọ Ọlọrun ni a nilati fi bi ohun ti a fi iwa ipa tedo lulẹ, ti a si nilati fi párun. Emi ko ni wu iwa ipa lati tako awọn onigbagbo asan ati alaigbagbọ. . . . A ko nilati fi ipa mu ẹnikẹni. Ominira ni pataki igbagbọ.”ANN 81.8
Ko pẹ ti a royin rẹ kaakiri Wittenberg wipe Luther ti pada de, ati pe oun ni yoo waasu. Awọn eniyan rọ wa lati iha gbogbo, ile ijọsin si kun akunfaya. O gun ori pẹpẹ iwaasu, o si fi ọgbọn ati irẹlẹ ṣe ikọni, igbaniniyanju, ati ibaniwi. O sọ nipa awọn ti wọn n wuwa jagidijagan lati kasẹ mass kuro nilẹ wipe:ANN 82.1
“Mass ki i ṣe ohun ti o dara; Ọlọrun tako o; o yẹ ki a kasẹ rẹ kuro nilẹ; maa si fẹ ki a fi ounjẹ alẹ Oluwa ti iyinrere rọpo rẹ kaakiri gbogbo aye. Ṣugbọn ẹ maṣe jẹ ki a fi ipa mu ẹnikẹni kuro ninu rẹ. A nilati fi ọrọ naa si ọwọ Ọlọrun. Awa kọ ni yoo ṣe iṣẹ naa bikoṣe ọrọ Rẹ. Ẹ ẹ beere wipe kilo de ti o fi nilati ri bẹẹ? Nitori pe mi o ni ọkan awọn eniyan ni ọwọ mi bi amọkoko ti i ni amọ. A ni ẹtọ lati sọrọ: a ko ni ẹtọ lati muni ṣe e. Ẹ jẹ ki a waasu; Ọlọrun ni ó ni eyi ti o ku. Bi o ba ṣe wipe mo lo iwa ipá ni, kini i ba jẹ ere mi? Irora, aṣa, idibọn, iṣẹ eniyan ati agabagebe. . . . Ko ni si iṣotitọ atọkanwa, igbagbọ tabi ifẹ. Nibi ti awọn mẹtẹẹta wọnyi ko ba si, ko si ohun ti o wa nibẹ, mi o si ni fẹ lati ni iru ayọrisi yii. . . . Ọlọrun n ṣiṣẹ pẹlu ọrọ Rẹ ju eyi ti emi ati iwọ ati gbogbo aye bi a ba pa okun wa pọ le ṣe lọ. Ọlọrun n fi ọwọ ba ọkan; bi a ba si ti jere ọkan, a ti jere ohun gbogbo. . . .ANN 82.2
“Maa ṣe iwasu, maa ṣe ijiroro, maa si kọwe; ṣugbọn mi o ni fi ipa mu ẹnikẹni, nitori iṣẹ atinuwa ni igbagbọ jẹ. Ẹ wo ohun ti mo ti ṣe. Mo tako popu, tita idariji ẹṣẹ, ati awọn ẹlẹsin popu, ṣugbọn ki i ṣe pẹlu ija tabi iwa ipa. Mo gbe ọrọ Ọlọrun siwaju; mo waasu, mo tun kọwe—ohun ti mo ṣe ko ju yẹn lọ. Sibẹ nigba ti mo n sun, . . . ọrọ iwaasu bi ẹsin popu ṣubu, ko si si ọba kan tabi ijoye ti o le ṣe e ni iru ijamba yii. Sibẹ, mi o ṣe ohun kankan; ọrọ naa ni o ṣe gbogbo rẹ. Bi o ba ṣe wipe mo fẹ lati lo iwa ipa ni, gbogbo ilẹ Germany ni i ba ti kun fun ẹjẹ. Ṣugbọn ki ni eyi i ba yọri si? Iparun ati idibajẹ ara ati ọkan. Nitori naa, mo dakẹ, mo si jẹ ki ọrọ naa o maa danikan rin kaakiri aye.ANN 82.3
Luther n waasu fun ọpọ awọn ero ti wọn n fẹ lati gbọ ọ fun ọsẹ kan gbako lojoojumọ. Ọrọ Ọlọrun fọ agbara irusoke igbonara ẹsin. Agbara iyinrere si da awọn ti a ṣi lọna pada si oju ọna otitọ.ANN 82.4
Luther ko ni ero lati tako awọn alaragbigbona ẹsin, awọn ti iṣẹ wọn ti fa iwa buburu nla. O ri wọn bi ẹni ti iwoye wọn ko jinlẹ to, ti kò kó itara wọn nijanu, awọn ti wọn n sọ wipe wọn gba imọlẹ pataki lati ọrun, ṣugbọn ti wọn ko le fi ara da atako kekere, tabi ibawi tabi imọran ti a funni ninu aanu. Wọn ri ara wọn bi ẹni ti o ni aṣẹ ti o ga julọ, wọn fẹ ki gbogbo eniyan o gba aṣẹ wọn laisi ibeere. Ṣugbọn bi wọn ti sọ wipe wọn fẹ ba ni ijiroro, o gba lati pade wọn. O si fi iwa èké wọn han to bẹẹ gẹẹ ti awọn opurọ wọnyii fi nilati fi Wittenberg silẹ lọgan.ANN 82.5
Erokero nipa ẹsin yii dawọ duro fun igba diẹ; ṣugbọn lẹyin ọdun diẹ, o gbilẹ kan pẹlu agbara nla, o si ṣe awọn iṣẹ buburu nla pẹlu. Luther sọ nipa awọn adari ẹgbẹ yii pe: “Iwe Mimọ dabi oku lẹta, gbogbo wọn si bẹrẹ si nii kigbe, ‘Ẹmi! Ẹmi!’ Ṣugbọn dajudaju mi o ni tẹle wọn lọ si ibi ti ẹmi wọn n dari wọn lọ. Ki Ọlọrun aanu o pami mọ kuro ninu ijọ ti ko si awọn miran ayafi awọn eniyan alailẹṣẹ. Mo fẹ lati gbe pẹlu awọn onirẹlẹ, alailagbara, alaisan, ti wọn mọ, ti wọn si ni imọlara ẹṣẹ wọn, ti wọn n kerora, ti wọn si n kigbe nigbagbogbo si Ọlọrun lati isalẹ ọkan wọn lati gba itunu ati iranlọwọ Rẹ.”ANN 82.6
Thomas Munzer, ẹni ti o ṣe akitiyan julọ ninu awọn elerokero ẹsin jẹ ẹni ti o ni ẹbun, eyi ti o ṣe wipe bi o ba lo o daradara, yoo ran an lọwọ lati ṣe rere; ṣugbọn koi tii kọ ẹkọ akọkọ nipa ẹsin tootọ. “O ni ifẹ lati ṣe atunṣe gbogbo aye, o ti gbagbe, gẹgẹ bi gbogbo awọn onitara ti maa n ṣe, wipe iṣẹ atunṣe nilati bẹrẹ pẹlu oun gan alára.” O ni ifẹ lati ni ipo ati agbara, ko si fẹ lati jẹ ẹnikeji, ani fun Luther paapa. O sọ wipe ni fifi Iwe Mimọ rọpo popu, awọn Alatunṣe tilẹ n gbe iru ẹsin popu miran kalẹ ni. O sọ wipe a ti yan oun lati ọrun lati wa fi iṣẹ atunṣe tootọ han. Munzer sọ wipe, “Ẹnikẹni ti o ba ni ẹmi yii, ní igbagbọ tootọ, bi ko ba tilẹ tii ri Iwe Mimọ ri ni gbogbo ọjọ aye rẹ.”ANN 82.7
Awọn olukọ elerokero wọnyi n fi ara wọn silẹ lati jẹ ki ero ọkan wọn o maa dari wọn, wọn ri gbogbo ero, ati imọlara gẹgẹ bi ohùn Ọlọrun; nitori naa, wọn ṣe e ni aṣeju. Awọn miran sun Bibeli wọn níná, wọn wipe: “Lẹta n pani, ṣugbọn Ẹmi n funni ni iye.” Ikọni Munzer nipa lori ifẹ eniyan lati ri ohun agbayanu, o tun n tẹ igberaga wọn lọrun nipa gbigbe ero ati igbagbọ eniyan ga ju ọrọ Ọlọrun lọ. Ọpọ eniyan ni wọn gba awọn ikọni rẹ. Laipẹ, o kọ gbogbo eto ninu isin apapọ silẹ, o tun sọ wipe gbigbọran si awọn ijoye lẹnu tumọsi sisin Ọlọrun ati Beliali.ANN 82.8
Ọkan awọn eniyan ti o ti bẹrẹ si nii kọ ajaga popu silẹ, ti bẹrẹ si nii ṣe waduwadu labẹ ikoninijanu aṣẹ ilu. Awọn ikọni ayi-nnkan pada ti Munzer fi n kọni, ti o n fi Ọlọrun ṣe atilẹyin rẹ, mu ki wọn kuro labẹ gbogbo akoso patapata, ti wọn si fi akoso fun aimọkan, ati itara wọn. Irukerudo ati ija nla ni o tẹle, ti ilẹ Germany si kun fun ẹjẹ.ANN 83.1
Irora ọkan ti Luther ti ni mọ fun ọjọ pipẹ ṣaaju iriri rẹ ni Erfurt wa kun ọkan rẹ ni ilọpo meji bi o ti n ri abayọri irokuro ẹsin, ti a si n di ẹbi rẹ ru iṣẹ Atunṣe. Awọn ijoye ẹlẹsin popu sọ wipe—ọpọ si ṣetan lati gba ọrọ naa gbọ—wipe iṣọtẹ naa jẹ ayọrisi awọn ikọni Luther. Bi o tilẹ jẹ wipe ẹsun yii ko fi ẹsẹ mulẹ rara, o ko iporuuru ọkan ba Alatunṣe naa. Wipe a dojuti iṣẹ otitọ nipa gbigbe si ipo kan naa pẹlu erokero ti o buru julọ ju ohun ti o le farada lọ. Ni ọna keji, awọn adari ninu iṣọtẹ naa korira Luther nitori pe, ki i ṣe wipe o tako awọn ikọni wọn nikan, ṣugbọn o tun n sọ wipe ko ti ọdọ Ọlọrun wa, o tun pe wọn ni ọlọtẹ si aṣẹ ijọba. Ni ìfèsì, wọn pe e ni opurọ buruku. O dabi ẹnipe ó kó ikorira awọn ijoye ati ti awọn eniyan si ori ara rẹ.ANN 83.2
Inu awọn ẹlẹsin Romu dun, wọn n reti iṣubu iṣẹ Atunṣe; wọn si n bu Luther, ani fun awọn aṣiṣe ti o n fi tọkantọkan n ṣiṣẹ lati ṣe atunṣe rẹ. Awọn ẹgbẹ onirokuro yii, nipa sisọ wipe a wu iwa aiṣododo si wọn, ri ikaanu ọpọ awọn eniyan, bi o si ti saba maa n ṣẹlẹ si awọn ti n ṣe ohun ti ko tọ, a ri wọn gẹgẹ bi ajẹriku. Bayi ni a ṣe ikaanu fun awọn ti wọn n lo gbogbo agbara lati tako iṣẹ Atunṣe, ti a si n gboriyin fun wọn gẹgẹ bi awọn ti n jiya iwa ika ati ipalara. Iṣẹ Satani niyii, iru ẹmi iṣọtẹ kan naa ti a fihan ni ọrun naa ni o n lo wọn.ANN 83.3
Satani n ṣiṣẹ nigba gbogbo lati tan awọn eniyan jẹ ki o si jẹ ki wọn o pe ẹṣẹ ni ododo, ati ododo ni ẹṣẹ. Iṣẹ rẹ ti saba maa n ṣe aṣeyọri to! Ọpọ igba ni a maa n ṣe ibawi, ti a si n kẹgan awọn iranṣẹ Ọlọrun tootọ nitori ti wọn fi igboya duro ti otitọ! A wa n yin awọn iranṣẹ Satani, a tun sọ ọrọ didun si wọn, ani a maa n wo wọn bi ajẹriku, nigba ti a a wa fi awọn ti o yẹ ki a bọwọ fun ki a tun ran lọwọ nitori iṣotitọ wọn si Ọlọrun silẹ lati duro ni awọn nikan labẹ ifunra si ati aifọkantan.ANN 83.4
Iwa mimọ ayederu, isọdimimọ eke si n ṣe iṣẹ itanjẹ rẹ. Ni oriṣiriṣi ọna ni o gba n fi iru ẹmi kan naa han gẹgẹ bi o ti ṣe ni akoko Luther, o n yi ọkan awọn eniyan kuro ninu Iwe Mimọ o si n dari wọn lati tẹle ifẹ ati ero inu ara wọn dipo ki wọn ṣe igbọran si ofin Ọlọrun. Ọkan lara awọn ọna ti o n ṣiṣẹ julọ, ti o maa n lo lati ko ẹgan ba iwa mimọ ati otitọ niyii.ANN 83.5
Luther gbeja iyinrere ninu gbogbo atako ti o wa ni ibi gbogbo laibẹru. Ọrọ Ọlọrun fi ara rẹ han gẹgẹ bi ohun ija ti o lagbara ninu gbogbo ija. O ba aṣẹ ti popu fi ipa gba, ati ero ijinlẹ eniyan ti awọn ọmọwe fi n kọni ja pẹlu ọrọ naa, nigba ti o duro gbọin bi apata ni atako si erokero ẹsin ti o fẹ so ara rẹ pọ mọ iṣẹ Atunṣe.ANN 83.6
Olukuluku awọn ikọni alatako wọnyi ni wọn n gbe Iwe Mimọ ti si ẹgbẹ kan ni aaye wọn ti wọn si n gbe ọgbọn eniyan ga gẹgẹ bi orisun otitọ ẹsin ati imọ. Ọgbọn inu eniyan sọ iṣọwọronu eniyan di oriṣa, o si fi eyi ṣe ofin fun ẹsin. Ẹsin Romu, nipa fifun popu rẹ ni imisi ti o wa laisi iyapa lati ọdọ awọn apostoli, ti ko si le yẹ titi lae, fi aaye nla silẹ fun gbogbo aṣeju ati iwa ibajẹ ti a o si fi wọn pamọ si abẹ iwa mimọ aṣẹ awọn apostoli. Imisi ti Munzer ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ sọ wipe awọn ni kò ti ibi kankan wa ju inu ero ọkan wọn lọ, ipa rẹ ko si ni jẹ ki eniyan o tẹriba fun aṣẹ kankan, i baa jẹ ti eniyan tabi ti Ọlọrun. Ẹsin Kristẹni tootọ n gba ọrọ Ọlọrun gẹgẹ bi ile iṣura nla ti o kun fun awọn otitọ ti a mi si, ati ohun ti a le fi dan gbogbo imisi wo.ANN 83.7
Nigba ti o kuro ni Wartburg, Luther pari iṣẹ itumọ rẹ lori Majẹmu Tuntun, a si fi iyinrere fun awọn eniyan ilẹ Germany ni ede abinibi wọn laipẹ jọjọ. Gbogbo awọn ti wọn fẹran otitọ ni wọn fi ayọ nla gba itumọ yii; ṣugbọn awọn ti wọn yan aṣa ati ofin eniyan fi ẹgan kọ ọ silẹ.ANN 84.1
Ẹru ba awọn alufa nitori pe awọn eniyan lasan yoo le ba wọn ṣe ijiroro lori ẹkọ ọrọ Ọlọrun, ti a yoo si fi aimọkan wọn han. Agbara ohun ija ẹran ara ti wọn ni ko ni agbara lati tako ida Ẹmi. Romu lo gbogbo agbara rẹ lati le dena pinpin Iwe Mimọ kaakiri; ṣugbọn awọn aṣẹ, egun, ati ijiya ja si asan papọ. Bi o ti n fi ofin de Bibeli si, bẹẹ ni ifẹ awọn eniyan lati mọ ohun ti o n kọni gan an n pọ si. Gbogbo awọn ti wọn le kawe ni wọn fẹ lati kẹkọ ọrọ Ọlọrun funra wọn. Wọn n gbe kaakiri pẹlu ara wọn, wọn si n ka a ni akatunka, ko si tẹ wọn lọrun titi ti wọn fi ko abala pupọ ninu rọ sori. Nigba ti o ri ifẹ ti awọn eniyan fi gba Majẹmu Tuntun, loju ẹsẹ, o bẹrẹ si ni i ṣe itumọ Majẹmu Laelae, o si n tẹ ẹ jade, bi o ti n pari wọn labalalabala.ANN 84.2
Ati ninu ilu, ati ninu abule ni a ti fi tayọtayọ gba awọn iwe Luther. “Ohun ti Luther ati awọn ọrẹ rẹ n kọ silẹ, awọn miran n pin kaakiri. Awọn ajẹjẹ ẹsin ti oye ti ye nipa bi awọn ilana igbe aye ẹsin ko ti bofin mu to, ti wọn n fẹ lati gbe igbesi aye iṣẹ ju igbesi aye alainiṣẹ ti wọn n gbe lọ, ṣugbọn ti wọn ko le polongo ọrọ Ọlọrun nitori aimọkan wọn, n rin kaakiri gbogbo ipinlẹ, wọn n bẹ awọn ahéré ati ileto wo, nibi ti wọn n ta awọn iwe Luther ati ti awọn ọrẹ rẹ si. Laipẹ jọjọ, ilẹ Germany kun fun awọn ọtawe onigboya wọnyi.”ANN 84.3
Awọn eniyan, ati ọlọrọ, ati otoṣi, ati ọmọwe ati alaimọkan ni wọn n kẹkọ awọn ikọni wọnyi pẹlu ifẹ ọkan ti o lagbara. Ni aṣalẹ, awọn olukọ ile ẹkọ ni awọn abule yoo maa ka wọn soke si awọn ẹgbẹ ti wọn ba pejọ pọ si ẹgbẹ iná. Pẹlu gbogbo agbara, awọn ọkan yoo gbagbọ ninu otitọ, wọn yoo si gba ọrọ naa pẹlu ayọ, wọn a tun lọ sọ iroyin ayọ naa fun awọn miran.ANN 84.4
Awọn ọrọ Imisi wa si imuṣẹ: “Iwọle ọrọ Rẹ n funni ni imọlẹ; o n fi oye fun òpè.” O. Dafidi 119:130. Ẹkọ ọrọ Ọlọrun n ṣe awọn ayipada nla ni ọkan ati iye awọn eniyan. Iṣakoso popu gbe ajaga irin si ori awọn atẹle rẹ, o si de wọn mọ inu aimọkan ati abuku. Awọn eniyan n fi tọkantọkan tẹle awọn ilana rẹ pẹlu aimọkan; ṣugbọn ninu gbogbo isin wọn, ọkan wọn ati ironu wọn kò kó ipa pupọ. Iwaasu Luther fi awọn otitọ ọrọ Ọlọrun ti o yè kooro han, ọrọ naa funra rẹ ni ọwọ awọn eniyan lasan, sọ agbara wọn ti o ti sun ji, ki i ṣe wipe o sọ igbesi aye ẹmi wọn di mimọ ati pataki nikan, ṣugbọn o fi okun ati agbara tuntun kun inu oye wọn.ANN 84.5
Gbogbo eniyan ni wọn gbe Bibeli lọwọ, wọn si n wi awijare fun awọn ikọni iṣẹ Atunṣe. Awọn atẹle popu ti wọn ti fi ẹkọ Bibeli silẹ fun awọn alufa ati awọn ajẹjẹ ẹsin wa n pe wọn lati jade wa lati tako awọn ikọni tuntun wọnyi. Ṣugbọn nitori ti wọn jẹ alaimọkan ninu Iwe Mimọ ati nipa agbara Ọlọrun, awọn alufa ati awọn ajẹjẹ ẹsin maa n ri ibaku patapata niwaju awọn ti wọn da lẹbi gẹgẹ bi alaimọkan ati ẹlẹko odi. Onkọwe ọmọ ijọ Katoliki kan sọ wipe, “O ṣeni laanu wipe Luther ti rọ awọn atẹle rẹ lati maṣe ni igbagbọ ninu ohunkohun mọ ayafi Iwe Mimọ.” Ọpọ eniyan yoo pejọ pọ lati gbọ otitọ ti awọn eniyan ti kò mọwe pupọ n sọ, ani wọn tun n ṣe ijiroro pẹlu awọn ọmọwe ati awọn ti n kọ nipa Ọlọrun ti ẹnu wọn ja fafa. Aimọkan onitiju awọn eniyan nla wọnyi ni a maa n fihan nigba ti a ba fi otitọ ọrọ Ọlọrun pade awọn ironu wọn. Awọn oṣiṣẹ, jagunjagun, obinrin, ani awọn ọmọde ni imọ awọn ikọni Bibeli ju awọn alufa ati awọn ọmọwe lọ.ANN 84.6
Iyatọ ti o wa laarin awọn ọmọlẹyin iyinrere ati atẹle eke popu fi ara han laarin awọn ọmọwe gẹgẹ bi o ti fi ara han laarin awọn eniyan lasan. “Ni atako si awọn ti wọn tẹle aṣa ijọ to ti di ogbó ni ti a ri awọn ti wọn kọ ẹkọ ede ati ikọni nipa ohun atijọ silẹ, . . . awọn ọdọ ti iyè wọn ja fafa fi ara wọn jin fun ẹkọ, wọn n yẹ Iwe Mimọ wo, wọn si n ni oye eyi ti o ṣeyebiye julọ ninu awọn ohun igba atijọ. Wọn ni oye ti o yè kooro, ẹmi ti o dagba soke, ati ọkan ti o gboya, laipẹ jọjọ, awọn ọdọ wọnyi ni imọ to bẹẹ gẹẹ ti o fi jẹ wipe ko si ẹni ti o ba wọn figagbaga fun igba pipẹ. . . . Ni ọna kan naa, nigba ti awọn ọdọ agbeja iṣẹ Atunṣe wọnyi ba pade awọn ọmọwe ẹlẹsin Romu ninu apero, wọn a ṣe atako wọn pẹlu irọrun ati igboya ti o fi jẹ wipe awọn alaimọkan eniyan wọnyi a lọra, oju a ti wọn, gbogbo eniyan a si fi oju tẹnbẹlu wọn.”ANN 84.7
Bi awọn alufa ẹsin Romu ti n ri wipe awọn ọmọ ijọ wọn n din ku, wọn beere fun iranlọwọ awọn alaṣe ilu, wọn si lo ohun gbogbo ti o wa ni ikawọ wọn lati le da awọn olugbọ wọn pada. Ṣugbọn awọn eniyan ti ri ohun ti o tan aini ọkan wọn ninu awọn ikọni tuntun wọnyi, wọn si yi pada kuro ni ọdọ awọn ti wọn ti fi pantiri ẹsin eke ati aṣa eniyan bọ wọn fun igba pipẹ.ANN 85.1
Nigba ti a ba dana inunibini si awọn olukọ otitọ, wọn mu ọrọ Kristi lo, eyi ti o wipe: “Nigba ti wọn ba ṣe inunibini si yin ninu ilu kan, ẹ lọ si ibomiran.” Matiu 10:23. Imọlẹ naa tan de ibi gbogbo. Awọn ti a n le kiri n ri awọn olugbalejo kan ti yoo gba wọn sile, wọn a gbe nibẹ, wọn a si waasu Kristi, ni igba miran ninu ile ijọsin, tabi, bi a ko ba fun wọn ni anfani yii, ninu ile awọn eniyan, tabi ni ita gbangba. Nibikibi ti wọn ba ti ni olugbọ ni wọn sọ di tẹmpili mimọ. Otitọ naa, ti a fi iru agbara ati idaniloju yii waasu rẹ, tan kaakiri pẹlu agbara ti a ko le koju.ANN 85.2
Lasan ni awọn alaṣẹ ilu ati ti ijọ ṣiṣẹ lati fa ekọ odi yii tu. Lasan ni wọn lo ọgba ẹwọn, ifiyajẹni, ina, ati ida. Ẹgbẹẹgbẹrun awọn onigbagbọ ni wọn fi ẹjẹ ara wọn ṣe edidi igbagbọ wọn, sibẹ iṣẹ wọn n tẹsiwaju. Inunibini n ṣiṣẹ lati tan otitọ naa kalẹ si ni, bẹẹ si ni erokero ti Satani n ṣe akitiyan lati dapọ pẹlu rẹ ṣiṣẹ lati fi iyatọ ti o wa laarin iṣẹ Satani ati iṣẹ Ọlọrun han kedere ni.ANN 85.3