Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KARUNDINLOGUN—BIBELI ATI IDOJU IJỌBA BOLẸ NI FRANCE

    Ni ọrundun kẹrindinlogun, iṣẹ Atunṣe gbe Bibeli ti a ṣi silẹ han awọn eniyan, o n wa ọna lati wọ gbogbo orilẹ ede ti o wa ni Europe. Awọn orilẹ ede kan fi ayọ gba a gẹgẹ bi iranṣẹ lati Ọrun wa. Ni awọn ibomiran, ẹsin popu ṣe aṣeyọri pupọ lati mase jẹ ki a gba a wọle; a si ti ilẹkun mọ imọlẹ imọ Bibeli pẹlu gbogbo agbara ti n gbéni soke rẹ. Ninu orilẹ ede kan, bi o tilẹ jẹ wipe imọlẹ ri aaye wọle, okunkun ko le bori rẹ. Fun ọpọ ọdun, otitọ ati èké jijọ n jijadu fun ipo ọga. Ni ikẹyin iwa buburu bori, a si ti otitọ Ọrun sita. “Eyi ni idajọ naa pe, imọlẹ wa si inu aye, ṣugbọn awọn eniyan fẹran okunkun ju imọlẹ lọ.” Johanu 3:19. A fi orilẹ ede naa silẹ lati kore ayọrisi ohun ti o yan. A mu ìkóni-nijanu Ẹmi Ọlọrun kuro lara awọn eniyan ti wọn gan ẹbun oore ọfẹ Rẹ. A gba iwa buburu laaye lati dagba. Gbogbo aye si ri eso mimọọmọ kọ otitọ silẹ.ANN 118.1

    Ogun atako si Bibeli, ti o tẹsiwaju fun ọpọlọpọ ọdun ni France, wa pari si awọn iṣẹlẹ idoju ijọba bolẹ. Iṣẹlẹ buburu yii jẹ abayọri ti a ko le yẹ kuro nitori bi Romu ti ṣe tẹ Iwe Mimọ ri. O fi apẹẹrẹ abayọri ọgbọn iṣelu popu han kedere, eyi ti araye ti i ri ri—apẹẹrẹ atubọtan eyi ti ikọni Romu ti n tẹ si fun bi i o le ni ẹgbẹrun ọdun.ANN 118.2

    Awọn woli ti ṣe asọtẹlẹ bi a yoo ti tẹ Iwe Mimọ rì ni akoko iṣejọba popu; Olufihan si tọka si awọn atubọtan buburu ti yoo ṣẹlẹ si France latari ijẹgaba “ọkunrin ẹṣẹ.”ANN 118.3

    Angẹli Oluwa wipe: “Wọn yoo si tẹ ilu mimọ naa mọlẹ labẹ atẹlẹsẹ fun oṣu meji-le-logoji. Emi yoo si fun awọn ẹleri mi mejeeji ni agbara, wọn o wọ aṣọ ọfọ, wọn o si sọtẹlẹ fun ẹgbẹfa ọjọ o le ọgọta. . . . Nigba ti wọn ba si ti pari ẹri wọn, ẹranko ti o n ti inu ọgbun goke wa nì yoo ba wọn jagun, yoo si ṣẹgun wọn, yoo si pa wọn. Oku wọn yoo si wa ni igboro ilu nla ni, ti orukọ rẹ n jẹ Sodomu ati Ijibiti ni ti ẹmi, nibi ti a ti kan Oluwa wọn mọ agbelebu. . . . Awọn eniyan ti n gbe ori ilẹ aye yoo si yọ lori wọn, wọn o si ṣe ariya, wọn o si ta ara wọn lọrẹ; nitori ti awọn woli naa dá awọn ti n gbe ori ilẹ aye lóró. Lẹyin ọdun mẹta ati aabo naa, Ẹmi iye lati ọdọ Ọlọrun wa wọ inu wọn, wọn si dide duro ni ẹsẹ wọn; ibẹru nla si de ba awọn ti o ri wọn.” Ifihan 11:2—11.ANN 118.4

    Akoko ti a darukọ nibi—”ogoji oṣu o le meji,” ati “ẹgbẹfa ọjọ o le ọgọta”—jẹ n kankan naa, wọn jijọ duro fun akoko ti ijọ Kristi yoo jiya labẹ inira lati ọdọ Romu ni. Ẹgbẹfa o le ọgọta ọdun (1260) ti ijọba popu bẹrẹ ni A. D. 538, yoo si pari ni 1798. Ni akoko naa, ẹgbẹgun France wọ inu Romu lọ, wọn mu popu ni ẹlẹwọn, o si ku ni ilẹ ajeji. Bi o tilẹ jẹ wipe a yara yan popu miran lẹyin eyi, agbara popu ko pọ to iru eyi ti o ni tẹlẹ mọ lati igba yẹn lọ.ANN 118.5

    Ki i ṣe gbogbo akoko 1260 ọdun naa ni a fi ṣe inunibini si ijọ. Ọlọrun ninu aanu Rẹ fun awọn eniyan, gé akoko idanwo gbigbona naa kuru. Ni sisọtẹlẹ nipa “inira nla” ti yoo ba ijọ,Olugbala sọ wipe: “Ayafi bi a ba gé ọjọ naa kuru, ko si ẹni ti yoo le là á: ṣugbọn nitori awọn ayanfẹ ni a o fi ge ọjọ wọn-ọn ni kúrú.” Matiu 24:22.ANN 118.6

    Nipa awọn ẹlẹri mejeeji naa, woli naa tun sọ wipe: “Awọn wọnyi ni igi olifi meji, ati ọpa fitila meji ti wọn n duro niwaju Ọlọrun aye.” Olorin sọ wipe, “Ọrọ Rẹ ni atupa si ẹsẹ mi, ati imọlẹ si ọna mi.” Ifihan 11:4; O. Dafidi 119:105. Awọn ẹlẹri mejeeji wọnyi duro fun Majẹmu Laelae ati Tuntun. Awọn mejeeji jẹ ẹri ti o ṣe pataki nipa ibẹẹrẹ ati ìwà titi lae ofin Ọlọrun. Awọn mejeeji ni wọn jẹ ẹlẹri si eto igbala. Awọn apẹẹrẹ, irubọ, ati asọtẹlẹ Majẹmu Laelae tọka si Olugbala ti n bọ. Awọn Iyinrere ati Episteli inu Majẹmu Tuntun sọ nipa Olugbala ti O wa ni ọna gan an ti awọn apẹẹrẹ ati asọtẹlẹ gba sọ ọ.ANN 118.7

    “Won yoo sọtẹlẹ fun ẹgbẹfa o le ni ọgọfa (1260) ọjọ, ninu aṣọ ọfọ.” Ni igba ti o pọ julọ ninu akoko yii, awọn ẹlẹri Ọlọrun wa ninu ipò okunkun. Agbara ijọ padi wá ọna lati fi ọrọ otitọ pamọ kuro ni ọdọ awọn eniyan, ki o si gbe awọn ẹlẹri eke lati tako ẹri rẹ ka iwaju wọn. Nigba ti a aṣẹ ẹsin ati ti oṣelu tako Bibeli; nigba ti a ṣi awọn ẹri inu rẹ lo, ti a si ṣe ohun gbogbo ti eniyan ati awọn ẹmi aimọ le ṣe lati yi ọkan awọn eniyan kuro lara rẹ; nigba ti a dọdẹ awọn ti wọn n waasu rẹ, ti a n tu aṣiri wọn, ti a n fi iya jẹ wọn, ti a n tì wọn mọ yara inu tubu, ti wọn n di ajẹriku nitori igbagbọ wọn, tabi ti o di dandan fun wọn lati salọ si ibi aabo ni awọn oke, tabi ninu iho ilẹ ati iho inu apata—ni akoko naa ni awọn ẹlẹri tootọ n sọ asọtẹle ninu aṣọ ọfọ. Sibẹ wọn tẹsiwaju ninu ẹri wọn ni gbogbo akoko 1260 ọdun naa. Ni akoko ti o dudu julọ awọn olootọ eniyan wà ti wọn fẹran ọrọ Ọlọrun ti wọn si n jowu nitori ogo Rẹ. A fun awọn iranṣẹ olootọ wọnyi ni ọgbọn, agbara ati aṣẹ lati ṣe ikede otitọ Rẹ ninu gbogbo akoko yii.ANN 119.1

    “Bi ẹnikẹni ba fẹ pa wọn lara, ina ti ẹnu wọn jade, o si pa awọn ọta wọn run: bi ẹnikẹni ba fẹ pa wọn lara, bayii ni a o ṣe pa a.” Ifihan 11:5. Awọn eniyan ko le tẹ ofin Ọlọrun loju laisi ijiya. A ṣe itumọ gbolohun ẹlẹru yii ninu abala ti o kẹyin ninu iwe Ifihan: “Emi n jẹri fun olukuluku ẹni ti o gbọ ọrọ isọtẹlẹ iwe yii pe, Bi ẹnikẹni ba fi kun wọn, Ọlọrun yoo fi kun awọn iyọnu ti a kọ si inu iwe yii fun un: bi ẹnikẹni ba si yọ kuro ninu ọrọ isọtẹlẹ iwe yii, Ọlọrun yoo mu ipa tirẹ kuro ninu iwe iye, ati kuro ninu ilu mimọ naa, ati kuro ninu awọn ohun ti a kọ si inu iwe yii.” Ifihan 22:18, 19.ANN 119.2

    Iru awọn ikilọ bawọnyi ni Ọlọrun ṣe lati maṣe jẹ ki eniyan o yi ohun ti O fihan tabi ti O palaṣẹ pada ni ọnakọna. Awọn ikilọ alagbara wọnyi ni itumọ fun gbogbo ẹni ti n dari awọn eniyan lati fi oju tẹnbẹlu ofin Ọlọrun. Wọn nilati jẹ ki awọn ti wọn n kede wipe ko ṣe pataki boya a ṣe igbọran si ofin Ọlọrun tabi boya a ko ṣe igbọran si o bẹru, ki wọn si wariri. Gbogbo awọn ti wọn gbe ero wọn ga ju ifihan Ọlọrun lọ, gbogbo awọn ti wọn yi itumọ Iwe Mimọ ti o han kedere pada lati le tẹ ara wọn lọrun, tabi lati le wa ni ibamu pẹlu aye, n gbe ẹru wuwo le ara wọn lori. Ọrọ ti a kọ silẹ, ofin Ọlọrun, yoo ṣe odiwọn iwa gbogbo eniyan, yoo si ṣe idalẹbi fun gbogbo awọn ti odiwọn ti ko le baku yii ba ri wipe wọn ko kun oju oṣuwọn.ANN 119.3

    “Nigba ti wọn ba pari [n pari] ẹri wọn.” Akoko ti awọn ẹlẹri meji yii yoo fi sọtẹlẹ pẹlu aṣọ ọfọ pari ni 1798. Bi wọn ti n sunmọ opin iṣẹ wọn ninu ifarasin, agbara ti a ṣe afihan rẹ bi “ẹranko ti o jade wa lati inu ọgbun ainisalẹ” a ba wọn jagun. Ni ọpọlọpọ awọn orilẹ ede ni Europe, Satani ni o n dari agbara ti o n ṣe idari ninu ijọ ati ilu nipasẹ ẹsin ijọ padi. Ṣugbọn nibi, a ṣe afihan agbara Satani tuntun.ANN 119.4

    O jẹ iwuwasi Romu labẹ afarajọ wipe o n bọwọ fun Bibeli, lati ti i pá sinu ede ti a ko mọ, ati lati pa mọ kuro ni ọdọ awọn eniyan. Labẹ iṣakoso rẹ, awọn ẹlẹri meji naa sọtẹlẹ “ninu aṣọ ọfọ.” Ṣugbọn agbara miran—ẹranko ti o ti inu ọgbun ainisalẹ jade wa— yoo dide lati mọọmọ bá ọrọ Ọlọrun jagun.ANN 119.5

    “Ilu nla naa” nibi ti a gbe pa awọn ẹlẹri naa, ti oku wọn dubulẹ si ni a pe ni Ijibiti “ni ti ẹmi.” Ninu gbogbo awọn orilẹ ede ti a ri ninu itan Bibeli, Ijibiti ni o fi igboya sọ wipe ko si Ọlọrun alaaye ti o si tako awọn aṣẹ Rẹ. Ko si ọba ti o ṣọtẹ ni gbangba pẹlu afojudi si aṣẹ Ọrun bi ọba Ijibiti ti ṣe. Nigba ti Mose mu iṣẹ iranṣẹ wa si ọdọ rẹ ni orukọ Oluwa, Farao fi igberaga dahun wipe: “Tani Jehofa, ti emi yoo fi gbọ ohùn Rẹ lati jẹ ki Israeli o lọ? Emi ko mọ Jehofa, bẹẹ ni n ko si ni jẹ ki Israeli o lọ.” Eksodu 5:2. Eyi ni igbagbọ wipe ko si Ọlọrun, orilẹ ede naa ti a fi Ijibiti wé yoo sọrọ lati kọ aṣẹ Ọlọrun alaaye silẹ ni ọna kan naa, yoo si fi iru ẹmi aigbagbọ ati ipenija kan naa han. “Ilu nla naa” ni a tun fi we Sodomu “ni ti ẹmi”. Iwa ibajẹ Sodomu ni riru ofin Ọlọrun fi ara han ni pataki julọ ninu iwa aileko-ara-ẹni nijanu. Ẹṣẹ yii ni yoo jẹ iwa ti o han kedere julọ ninu orilẹ ede naa ti yoo mu alaye iwe mimọ yii ṣẹ.ANN 119.6

    Gẹgẹ bi ọrọ woli naa, nigba naa, ni akoko diẹ ṣaaju ọdun 1798 agbara kan ti ipilẹsẹ ati iwuwasi rẹ jẹ ti Satani yoo dide lati ba Bibeli jagun. Ninu ilẹ naa ti a o ti pa ẹri awọn ẹlẹri Ọlọrun mejeeji lẹnu mọ, iru aigbagbọ ninu Ọlọrun ti Farao, ati iwa aileko-ara-ẹni-nijanu ti Sodomu yoo fi ara han.ANN 119.7

    Asọtẹlẹ yii ri imuṣẹ ti o ṣe rẹgi, ti o si yanilẹnu ninu itan France. Ni akoko idoju ijọba bolẹ ni 1793, “araye, fun igba akọkọ gbọ, ti agbajọpọ eniyan, ti a bí, ti a si kọ ni ilana ọlaju, ti wọn si ni ojuṣe lati ṣe idari ọkan ninu awọn orilẹ ede ti o dara julọ ni Europe, gbe ohùn wọn soke lati kọ otitọ ti o ṣe pataki julọ ti o wa ninu ọkan eniyan silẹ, wọn si fi ohùn ṣọkan lati kọ igbagbọ ati ijọsin Ọlọrun silẹ.” “France nikan ṣoṣo ni orilẹ ede naa ti a ri akọsilẹ rẹ ni gbogbo aye, gẹgẹ bi orilẹ ede, ti o gbe ọwọ rẹ soke ni iṣọtẹ si Ẹlẹda gbogbo agbala aye. Ọpọlọpọ awọn asọrọ odi, ọpọlọpọ awọn alaigbagbọ ni wọn ti wà, ti wọn si n wà ni England, Germany, Spain, ati ni ibi gbogbo; ṣugbọn France duro yatọ ninu itan aye, gẹgẹ bi ilu kan ṣoṣo ti o kede wipe ko si Ọlọrun nipasẹ aṣẹ igbimọ aṣofin rẹ, ti gbogbo awọn ti wọn wa ni olu ilu rẹ, ati ọpọlọpọ awọn eniyan ni ibomiran, ọkunrin ati obinrin, n jo ti wọn si n kọrin pẹlu ayọ nitori pe wọn gba ikede naa.”ANN 120.1

    France tun ṣe afihan awọn iwa ti wọn mu Sodomu yatọ ni ọna pataki. Ni akoko idoju ijọba bolẹ ipa ìwà ailojuti ati iwa ibajẹ fi ara han ni ọna ti o dabi eyi ti o mu iparun ba awọn ilu ti wọn wa ni pẹtẹlẹ. Awọn opitan si sọ nipa igbagbọ ti o wipe ko si Ọlọrun ati iwa aileko-ara-ẹni-nijanu ti France, gẹgẹ bi a ti sọ ọ ninu isọtẹlẹ: “Ni ibaṣepọ timọtimọ pẹlu awọn ofin ti wọn tako ẹsin wọnyi ni eyi ti o din ibaṣepọ ti igbeyawo ku—ibaṣepọ ti o jẹ mimọ julọ ti eniyan le ṣe, eyi ti iwa titi lae rẹ maa n fun awujọ lokun—si ipo adehun lasan laarin ilu ti ko duro titi lae, eyi ti awọn eniyan meji le wọ inu rẹ ki wọn si tuka bi wọn ṣe fẹ. . . . Bi awọn eniyan buburu ba n wa ọna lati ba ohunkohun ti o lọwọ, ti o gbayi, ti o si duro titi lae ninu ile jẹ ni ọna ti o lagbara julọ, ki wọn tun ri idaniloju wipe iwa buburu ti wọn fẹ da silẹ yoo wà lati iran de iran, wọn ko le ri ọna miran ti o dara bii biba igbeyawo jẹ. . . . Sophie Arnoult, eléré itage ti o lokiki nitori awọn ọrọ ti wọn panilẹrin, ti wọn si mu ọgbọn dani ti o sọ, ṣe apejuwe igbeyawo inu ilu naa gẹgẹ bi ‘ami majẹmu agbere.’”ANN 120.2

    “Nibi ti a ti kan Oluwa wa mọ agbelebu.” France tun mu apejuwe asọtẹlẹ yii wa si imuṣẹ. Ko si ilu ti a ti fi ẹmi ikorira han si Kristi bii ti France. Ko si orilẹ ede ti otitọ ti ṣe alabapade iru atako kikoro ti o si buru bẹẹ. Ninu inunibini ti France ṣe si awọn ti wọn gbagbọ ninu iyinrere, o kan Kristi mọ agbelebu ninu awọn ọmọ ẹyin Rẹ.ANN 120.3

    Lati igba de igba ni a ti n ta ẹjẹ awọn eniyan mimọ silẹ. Nigba ti awọn Waldenses fi ẹmi wọn lelẹ ni awọn oke Piedmont “fun ọrọ Ọlọrun, ati fun ẹri Jesu Kristi,” awọn arakunrin wọn, awọn Albigenses ti France jẹ iru ẹri kan naa fun otitọ. Ni igba iṣẹ Atunṣe, a pa awọn ọmọlẹyin rẹ pẹlu ifiyajẹni ti o buru jai. Ọba ati awọn ijoye, awọn obinrin ti a bi ni ile ọla ati awọn arẹwa obinrin, awọn ohun amuyangan ati akọni ilu, pejọ pọ lati wo ijiya awọn ajẹriku fun Kristi. Awọn Huguenots onigboya, ni jijagun fun awọn ẹtọ ti wọn ṣe pataki si ọkan eniyan, wọn tu ẹjẹ wọn silẹ ni oju ija alagbara. A ri awọn Protestant gẹgẹ bi ọdaran, a si da iye lé orí wọn, a tun n dọdẹ wọn bi ẹranko igbẹ.ANN 120.4

    “Ijọ ni Aginju,” awọn arọmọdọmọ perete ti wọn ṣẹ wa lati ọdọ awọn Kristẹni igba atijọ ṣi wa ni France titi di ọrundun kejidinlogun, ti wọn n sapamọ ninu awọn oke ni iha gusu, nitori pe wọn si fẹran igbagbọ awọn baba wọn. Bi wọn ba ti fẹ pejọ pọ ni aṣalẹ ni ẹba oke tabi ninu aginju ti o farasin, awọn ẹgbẹgun a le wọn kaakiri, wọn a si wọ wọn sinu igbe aye igbekun ninu ibi ifini-ṣiṣẹ. A de awọn ti wọn ni iwa mimọ julọ, ti wọn dara julọ, ti wọn ni oye julọ, mọ ẹwọn, pẹlu ifiyajẹni ti o buru, laarin awọn jaguda ati aṣekupani. Awọn miran ti a ṣe aanu fun ni a pa laisi ija, laini ihamọra, laini oluranlọwọ, bi wọn ti wa ni ori eekun wọn ti wọn n gbadura. Ọpọ awọn arugbo lọkunrin, ati lobinrin ti ko ni aabo, ati awọn ọmọ alailẹṣẹ ni a fi oku wọn silẹ ninu ibi ipade wọn. Bi a ba gba ẹba oke tabi inu igbo ti wọn ti saba maa n pade kọja, ki i ṣe ohun ti o yanilẹnu ni “lati ri ni bi i iwọn ẹsẹ mẹrin, awọn oku eniyan ninu igbo, awọn oku ti a so rọ lori igi.” A sọ ilẹ wọn di ahoro pẹlu ida, aake, ati igi idana; “o di aginju nla ti o dakẹ roro.” “A kò wu awọn iwa buburu yii . . . ni igba oju dudu, ṣugbọn ni akoko ọlaju, ni igba ijọba Louis XIV. A ti n kọ ẹkọ ijinlẹ ni akoko naa, iwe kikọ n gbilẹ, awọn alaṣẹ inu aafin ati ni ilu jẹ ọmọwe ati awọn ti wọn ni ẹbun ọrọ sisọ, ti wọn fi iwa irẹlẹ ati ifẹ han.”ANN 120.5

    Ṣugbọn eyi ti o ni ika julọ ninu akọsilẹ iwa ika, eyi ti o buru julọ ninu awọn iwa buburu ninu gbogbo awọn ọdun ti wọn lẹru julọ ni Ipaniyan ti Batolomiu mimọ. Araye si n wariri nigba ti wọn ba ranti awọn iṣẹlẹ buburu ti ipaniyan ni ipakupa ni ọna ójo naa. Awọn alufa ẹsin Romu rọ ọba France lati fi ọwọ si iṣẹ laabi naa. Agogo ti n dun ni oru ganjọ ni aami lati bẹrẹ iṣẹ ipaniyan naa. Awọn Protestant ni iye wọn, ti n sun jẹjẹ ninu ile wọn, ti wọn gbẹkẹle ileri ọba wọn ni a wọ jade laisi ikilọ, ti a si pa wọn laiṣe wipe ija wà.ANN 121.1

    Bi Kristi ti jẹ adari ti a ko ri fun awọn eniyan Rẹ lati oko ẹru Ijibiti, bẹẹ gẹgẹ ni Satani ṣe jẹ adari ti a ko ri fun awọn eniyan rẹ ninu iṣẹ laabi ti sisọ awọn ajẹriku di pupọ yii. Iṣẹ ipaniyan nipakupa yii tẹsiwaju ninu ilu Paris fun ọjọ meje, ti ti ọjọ mẹta akọkọ, kun fun ibinu ti a ko le ṣalaye. Ki i si ṣe ninu ilu naa nikan ni a ti ṣe eyi, ṣugbọn nipasẹ aṣẹ ọba pataki, a tan an de awọn ilu ati agbegbe ti a ba ti ri awọn Protestant. A ko bọwọ fun ọjọ ori tabi boya eniyan jẹ okunrin tabi obinrin. Ati ọmọ kekere jojolo, ati agbalagba ti o ni iwu lori, ko si ẹni ti a da silẹ. Ọlọrọ ati agbẹ aroko, agbalagba ati ọmọde, ọmọ ati iya ni a ge lulẹ papọ. Iṣẹ ipaniyan yii tẹsiwaju kaakiri gbogbo ilẹ France fun oṣu meji. Ẹgbẹrun lọna aadọrin (70,000) awọn ogo orilẹ ede naa ni wọn ṣegbe.ANN 121.2

    “Nigba ti iroyin ipaniyan nipakupa yii de Romu, idunnu awọn alufa ko lopin. Kadina ti ilu Lorraine fi ẹgbẹrun kan owo ta iranṣẹ ti o mu iroyin naa wa lọrẹ; ibọn nla ti o wa ni St Angelo dun fun ajọyọ; agogo si n dun lati inu gbogbo ile ijọsin; ina ti a da fun ariya naa sọ aṣalẹ di ọsan; Gregory XII ati awọn kadina ati awọn oloye ijọ ti wọn yi i ka ṣe iwọde nla lọ si ile ijọsin St Louis, nibi ti kadina ti Lorraine ti kọ orin Te Deum (Si Ọlọrun). . . . A rọ owo ẹyọ lati ṣe iranti ipaniyan nipakupa yii; ni Vatican, a ṣi lè ri awọn aworan mẹta ti Vasari, ti o n ṣe alaye bi a ti kọlu ọgagun oju omi kan, ọba ti o n pète ipaniyan naa ninu igbimọ, ati ipaniyan naa funra rẹ. Gregory fi òdòdó wura ranṣẹ si Charles; oṣu mẹrin lẹyin ipaniyan yii, . . . o fi idẹra tẹti silẹ si iwaasu kan lati ẹnu alufa ilẹ French kan, . . . ti o sọ nipa “ọjọ naa ti o kun fun idunu ati ayọ, nigba ti baba mimọ gba iroyin naa, o wọ inu ipo ọlọwọ lati lọ dupe lọwọ Ọlọrun ati St Louis.”ANN 121.3

    Ẹmi nla kan naa ti o fa ipakupa ti Batolomiu mimọ ni o dari awọn iṣẹlẹ inu idoju ijọba bolẹ. A sọ wipe opurọ ni Jesu Kristi, ariwo kan ṣoṣo ti gbogbo awọn alaigbagbọ ilẹ France n kigbe naa ni, “Fún eniyankeniyan naa pa,” wọn n sọ nipa Kristi. Ọrọ odi ti a sọ si Ọrun ati iwa ibi ti o buru jọjọ jijọ maa n kọwọ rin ni, ti á si gbe awọn ti wọn buru julọ ninu awọn eniyan, awọn ti wọn ti yigbì ninu iwa ika ati iwa ọdaran ga si oke tente. Ninu gbogbo iwọnyi, a ṣe ijọsin ti o ga julọ fun Satani; nigba ti a kan Kristi mọ agbelebu ninu iwa otitọ, iwa mimọ, ati ifẹ alaini-imọ-ti-ara-rẹ-nikan Rẹ.ANN 121.4

    “Ẹranko naa ti o jade lati inu ọgbun ainisalẹ wá yoo ba wọn jagun, yoo si ṣẹgun wọn, yoo si pa wọn.” Agbara ti ko gbagbọ ninu Ọlọrun yii ti o ṣe akoso ni ilẹ France ni akoko idoju ijọba bolẹ ati akoso ẹru, bá Ọlọrun ati ọrọ Rẹ jagun ni ọna ti araye koi tii ri ri. Ile igbimọ aṣofin pa ijọsin Ọlọrun rẹ. A ko awọn Bibeli jọ, a si dana sun wọn ni itagbangba pẹlu gbogbo ẹgan ti a le ṣe si. A tẹ ofin Ọlọrun mọlẹ. A pa gbogbo awọn ohun ti Bibeli fi lelẹ rẹ. A kọ ọjọ isinmi ọsọọsẹ silẹ, dipo rẹ, a ya gbogbo ọjọ kẹwa sọtọ fun ariya ati isọrọ odi. A fi ofin de Itẹbọmi ati Ounjẹ Alẹ Oluwa. A si lẹ awọn ikede mọ awọn ibi isinkusi nibi ti gbogbo eniyan yoo ti ri wipe orun ayeraye ni iku jẹ.ANN 121.5

    A sọ wipe ibẹru Ọlọrun ki i ṣe ibẹrẹ ọgbọn rara, bikoṣe ibẹrẹ omugọ. A fi ofin de gbogbo ijọsin ẹsin, ayafi ti ominira ati ti orilẹ ede. “A mu biṣọbu ti ofin fi ọwọ si ni Paris jade lati wa ko ipa pataki ninu iwa alafojudi ati alabuku ti ko nitumọ ti a ti i wu ri niwaju awọn aṣoju orilẹ ede. . . . A mu wa siwaju awọn ero lati sọ fun igbimọ naa wipe ẹsin ti oun ti fi kọni fun ọpọlọpọ ọdun, ni gbogbo ọna jẹ ọgbọn ẹwẹ awọn alufa, ti ko ni ipilẹ ninu itan tabi otitọ mimọ. O kọ iwalaaye Ọlọrun, ẹni ti a tori isin Rẹ yaa sọtọ silẹ ni ọna ti o lọwọ ti o si han kedere, o si fi ara rẹ jin fun ijọsin ominira, ibadọgba, iwa rere ati iwa ọmọluabi. O wa ko awọn aṣọ alufa rẹ si ori tabili, olori igbimọ naa si di mọ gẹgẹ bi ami ibadọrẹ. Diẹ ninu awọn alufa ti wọn ya apẹyinda naa tẹle apẹẹrẹ alufa yii.”ANN 121.6

    “Awọn ti wọn n gbe ori ile aye yoo si yọ nitori wọn, wọn yoo ṣe ajọyọ, wọn yoo si fi ẹbun ranṣẹ si ara wọn; nitori ti awọn woli mejeeji wọnyi n da awọn ti n gbe ori ilẹ aye loro.” France alaigbagbọ ti pa ohùn ibawi awọn ẹlẹri Ọlọrun mejeeji yii lẹnu mọ. Ọrọ otitọ ti dubulẹ ninu igboro rẹ, awọn ti wọn korira idilọwọ ati ilana ofin Ọlọrun si n yọ. Awọn eniyan n pe Ọba ọrun nija ni gbangba. Bi awọn ẹlẹṣẹ igbaani, wọn n kigbe wipe: “Bawo ni Ọlọrun ti ṣe mọ? imọ ha wa ninu Ọga Ogo bi?” O. Dafidi 73:11.ANN 122.1

    Pẹlu igboya asọrọ odi ti o kọja ohun ti eniyan le gbagbọ, ọkan ninu awọn alufa ẹgbẹ tuntun naa sọ wipe: “Ọlọrun bi o ba wa laaye, gbẹsan nitori orukọ Rẹ ti wọn bajẹ. Mo pe Ọ nija! O dakẹ; O o tobẹ lati ran ara Rẹ. Lẹyin eyi, tani yoo gbagbọ ninu iwalaaye Rẹ?” Eyi dabi àtunsọ ohun ti Farao sọ: “Tani Jehofa, ti emi yoo fi gbọ ohùn Rẹ?” “Emi ko mọ Jehofa!”ANN 122.2

    “Aṣiwere wi ni ọkan rẹ pe, Ko si Ọlọrun.” O. Dafidi 14:1. Oluwa tun sọ nipa awọn ti wọn n yi otitọ Rẹ pada bayi pe: “Iwa were wọn han si gbogbo eniyan.” 2 Timoti 3:9. Lẹyin ti France kọ ijọsin Ọlọrun alaaye, “Ẹni nla ati Ẹni giga ti n gbe inu ayeraye” silẹ, akoko diẹ ni o ku lati tẹri sinu iwa ibọriṣa ti o n yẹpẹrẹ ẹni, nipa jijọsin Ọlọrunbinrin Imọ, tí obinrin oniwakuwa kan duro fun. Eyi si ṣẹlẹ niwaju igbimọ aṣoju orilẹ ede naa, ati nipasẹ awọn alaṣẹ iṣejọba ati iṣofin rẹ ti o ga julọ! Opitan kan sọ wipe: “Ọkan lara awọn eto akoko wèrè yii kò lẹgbẹ ninu aitọ ati ailọwọ. A ṣi ilẹkun ile igbimọ naa silẹ fun ẹgbẹ awọn akọrin kan, awọn alaṣẹ ilu ti kọkọ ṣaaju wọn wọle, wọn n kọ orin ni iyin si ominira, wọn si mu obinrin ti wọn bò loju wọle, ẹni ti wọn pe ni Ọlọrunbinrin Imọ, gẹgẹ bi ohun ti won yoo maa jọsin. Nigba ti a mu wọ aarin irin, wọn ṣi oju rẹ pẹlu ètò nla, wọn si fi si ọwọ ọtun olotu, nigba ti gbogbo eniyan ri wipe oun ni ọmọbinrin ti n jo ninu ile orin. . . . Igbimọ apapọ ti orilẹ ede France jọsin fun ẹni yii nigbangba, ẹni ti wọn ri gẹgẹ bi aṣoju imọ ti wọn n sin.ANN 122.3

    “Eto ailọwọ ti o n panilẹrin yii ni ọna kan ti a n gba ṣe e; a si tun ìfisípò Ọlọrunbinrin imọ ṣe, ti a tun ṣe awokọṣe rẹ ni gbogbo orilẹ ede naa ni awọn ibi ti awọn olugbe rẹ ba ti fẹ fihan wipe wọn de oke tente ninu gbogbo ilana idoju ijọba bolẹ.”ANN 122.4

    Sọrọsọrọ ti o ṣe afihan isin Imọ sọ wipe: “Ẹyin aṣofin! Irokuro ẹsin ti fi aye silẹ fun imọ. Oju rẹ ti o ṣu ko le wo itansan imọlẹ. Loni ero nla pejọ pọ si abẹ ile nla yii fun igba akọkọ lati wa tun otitọ naa sọ. Nibi ni awọn eniyan ilẹ France ti ṣe ajọyọ ijọsin tootọ kan ṣoṣo,—ti Ominira, ti Imọ. Nibẹ ni a ti ṣe ipinu fun ilọsiwaju orilẹ ede. Nibẹ ni a ti fi awọn ère ti ko ni ẹmi silẹ lati tẹle Imọ, lati tẹle aworan ti o ni ẹmi, eyi ti o dara julọ ninu iṣẹda.”ANN 122.5

    Nigba ti a mu ọlọrunbinrin yii wa sinu igbimọ, sọrọsọrọ kan mu lọwọ dani, o yiju si igbimọ naa o sọ wipe: “Ẹyin ẹlẹran ara, ẹ maṣe wariri mọ niwaju àrá ti ko lagbara ti Ọlọrun tí ibẹru yin da silẹ. Lati akoko yii lọ, ẹ maṣe mọ Ọlọrun miran mọ ayafi Imọ. Mo fi aworan ti o niyi julọ, ti o tun mọ julọ fun yin; bi ẹ ba fẹ ni ère, ẹ maa rubọ si ohunkohun ti o ba dabi eyi. . . . Ẹ wolẹ niwaju Aṣofin Agba ti ominira oh! Iboju Imọ!”ANN 122.6

    Lẹyin igba ti olotu dìmọ ọlọrunbinrin naa tan, a gbe si ori ọkọ nla kan, a si gba aarin ọpọ ero kọja lọ si katidra ti Notre Dame, lati lọ duro ni ipo Ọlọrun. A gbe si ori pẹpẹ giga ti o wa nibẹ, gbogbo awọn ti wọn wa nibẹ si jọsin rẹ.ANN 122.7

    Laipẹ lẹyin eyi, a sun Bibeli nina nigbangba. Ni igba kan, “Ẹgbẹ ti o lokiki ti ibi ìkó-ohun-iranti-pamọ-si” wọ gbọngan ilu lọ, wọn n kigbe wipe, “Vive la Raison!”(Ki imọ ki o wa laaye) wọn gbe àjókù awọn iwe kan, iwe orin, iwe adura ati Majẹmu Laelae ati Tuntun, eyi ti olotu sọ nipa wọn wipe, “a ṣe etutu gbogbo iwa were eyi ti wọn jẹ ki iran eniyan o wu ninu ina nla.”ANN 122.8

    Ilana popu ni o bẹrẹ iwa ti aigbagbọ ninu Ọlọrun n pari. Ilana Romu ti pese awọn aaye silẹ ni aarin awujọ, ninu iṣelu, ati ninu ẹsin, ti wọn n ti France lọ sinu iparun. Nigba ti awọn onkọwe n sọ nipa awọn iṣẹlẹ ẹlẹru ti igba idoju ijọba bolẹ, wọn sọ wipe ori ijọ ati itẹ ni o yẹ ki a di ẹsun awọn aṣeju wọnyi lé. Nitootọ, ori ijọ ni o yẹ ki a di wọn le. Ẹsin popu ti jẹ ki ọkan awọn ọba o tako iṣẹ Atunṣe, gẹgẹ bi ọta ade ati ohun ti o le fa idarudapọ ti o le ko ewu ba alaafia ati iṣọkan orilẹ ede. Ọgbọn ẹwẹ Romu ni wipe nipasẹ eyi iwa onroro ati inira ti o ga julọ yoo wá lati ori itẹ.ANN 123.1

    Ẹmi ominira maa n tẹle Bibeli ni. Nibikibi ti a ba ti gba iyinrere, iyè awọn eniyan maa n sọji. Wọn a bẹrẹ si ni ja ide ti o dè wọn ni igbekun mọ aimọkan, iwa ibajẹ, ati igba ohun asan gbọ sọnu. Wọn a bẹrẹ si nii ronu, wọn a si wuwa bi eniyan. Awọn ọba ri eyi, wọn si wariri fun iwa onroro wọn.ANN 123.2

    Romu ko lọra lati ru ibẹru ojowu wọn soke. Popu sọ fun adele ọba France ni 1525 wipe: “Ki i ṣe wipe wèrè yii [esin Protestant] yoo ko idarudapọ ati iparun ba ẹsin nikan, ṣugbọn ati gbogbo agbara, oye, ofin, ètò, ati ipo pẹlu.” Ọdun diẹ lẹyin eyi, aṣoju popu ṣe ikilọ fun ọba wipe: “Alagba, maṣe jẹ ki a tan ọ jẹ. Awọn Protestant a da oju gbogbo eto iṣelu ati ẹsin bolẹ. . . . Itẹ wa ninu ewu gẹgẹ bi pẹpẹ ti wa pẹlu. . . . Afihan ẹsin tuntun gbọdọ mu ijọba tuntun wa.” Awọn ẹlẹkọ nipa Ọlọrun naa ru aimọkan awọn eniyan soke nipa sisọ wipe ikọni Protestant “maa n tan awọn eniyan sinu iwa aimọkan, o si maa ru ifẹ fun nnkan tuntun soke; ki i jẹ ki ọba o ri ibọwọfun lati ọdọ awọn ọmọ ilu rẹ, o si n ko iparun ba ijọ ati ilu.” Bayii ni Romu se ṣe aṣeyege lati le jẹ ki France o doju ija kọ iṣẹ Atunṣe. “Lati le ṣe atilẹyin fun itẹ, lati le pa awọn ijoye mọ, lati le daabo bo ofin ni a fi kọkọ yọ ida inunibini ni France.”ANN 123.3

    Ohun kekere ni awọn alaṣẹ ri nipa atubọtan ipinu pataki yii. Ẹkọ Bibeli i ba gbin awọn igbagbọ ninu ododo, iwọntuwọnsi, otitọ, idọgba, ati aanu, awọn ti wọn jẹ gbongbo fun ilọsiwaju orilẹ ede si inu ọkan ati iye awọn eniyan. “Ododo ni i gbe orilẹ ede leke.” Nipasẹ rẹ ni “a fi n fi idi itẹ mulẹ.” Owe 14:34; 16:12. “Iṣẹ ododo yoo jẹ alafia;” ipa rẹ si ni, “idakẹjẹ ati idaniloju titi lae.” Aisaya 32:17. Ẹnikẹni ti o ba ṣe igbọran si ofin Ọlọrun yoo bọwọ fun, yoo si ṣe igbọran si ofin orilẹ ede rẹ nitootọ. Ẹni ti o ba bẹru Ọlọrun yoo bọwọ fun ọba ni siṣe ohun ti o tọ ti o si bojumu si aṣẹ. Ṣugbọn France ti iya yoo jẹ ṣe ofin lati tako Bibeli, o si le awọn ọmọ ẹyin rẹ lọ. Lati igba de igba, awọn eniyan ti wọn mọ ohun ti o tọ, ti wọn jẹ olootọ eniyan, awọn ọlọpọlọ pipe, ti wọn ni okun iwa, ti wọn ni igboya lati jẹwọ igbagbọ wọn ati igbagbọ lati jiya nitori otitọ—fun ọpọ ọdun awọn wọnyi ṣiṣẹ bi ẹru ni ibi ifini ṣiṣẹ, wọn ṣegbe ni ibi idanasunni, tabi ki wọn jẹra ninu ile tubu. Ọgọọrọ awọn eniyan ni wọn wa aabo nipa sisa lọ; eyi si ṣẹlẹ fun aadọta le ni igba (250) ọdun lẹyin ti a bẹrẹ iṣẹ Atunṣe.ANN 123.4

    O sọwọn lati ri iran awọn ọmọ France kan laarin ọdun gbọọrọ naa ti ko ri bi awọn ọmọ ẹyin iyinrere ti n salọ kuro niwaju ibinu wèrè awọn oninunibini, ti wọn si n gbe oye, iṣẹ ọnà, imura siṣẹ, eto, ninu eyi ti wọn ti tayọ julọ, dani pẹlu wọn lati lọ bukun ibi ti wọn ba ti ri aabo. Bi wọn ba si ti ṣe bukun ilẹ miran pẹlu awọn ẹbun rere wọnyi, bẹẹ gẹgẹ ni ilẹ wọn a ṣe padanu wọn. Bi gbogbo awọn ti a le kuro ba si wa ni France; ni ọgọrun mẹta (300) ọdun yii, bi ọgbọn isọwọ ṣiṣẹ awọn ti a lé kuro ba n ro oko rẹ; bi ọgbọn iṣẹ ọna won ba n jẹ ki ile iṣẹ rẹ o dagba laarin 300 ọdun yii; bi, laarin 300 ọdun yii, ijafafa wọn, ati agbara iwoye wọn ba n bukun ẹkọ iwe ati ẹkọ imọ ijinlẹ rẹ; bi ọgbọn wọn ba ti n ṣe idari igbimọ rẹ, ti igboya wọn n ja awọn ogun rẹ, ti idọgba wọn n ṣe awọn ofin rẹ, ti ẹsin Bibeli si n fun iwoye awọn eniyan lokun, ti o tun n ṣe idari ẹri ọkan awọn eniyan rẹ, iru ogo wo ni i ba yi France ka loni! Iru orilẹ ede nla, ọlọrọ ati alayọ—apẹẹrẹ fun awọn orilẹ ede—wo ni i ba jẹ!ANN 123.5

    “Ṣugbọn itara aimoye, ti o fọju ti ko si ṣe e sẹrọ le gbogbo olukọ iwa rere, gbogbo ọgagun ninu eto, gbogbo olugbeja itẹ nitootọ kuro ni ori ilẹ rẹ; o sọ fun awọn ti i ba jẹ ki orilẹ ede wọn o ‘ni ogo ati okiki’ ninu aye wipe, Yan eyi ti iwọ ba fẹ, ina tabi didi isansa. Ni ikẹyin isọdahoro orilẹ ede naa de gongo; ko si ẹri ọkan kankan lati tako mọ; ko si ẹsin kankan lati wọ lọ si ibi isunninina mọ; ko si ifẹran ilu ti a lè lé jade mọ.” Idoju ijọba bolẹ, ati gbogbo iwa ipa rẹ, ni ayọrisi buburu rẹ.ANN 123.6

    “Pẹlu bi awọn Huguenots ti salọ, ifasẹyin ba lé ilẹ France. Awọn ilu ti wọn ti gbọrẹgẹtigẹ ninu iṣẹ siṣe di ahoro; awọn ilẹ ti wọn lọra pada di aginju; aimọkan ati ifasẹyin ninu iwa wiwu rọpo akoko idagbasoke ti ko lẹgbẹ. Paris di ile nla ti a ti n ṣe itọrẹ aanu, a ṣe isiro rẹ wipe, bi i 200,000 alaini ni wọn n gba itọrẹ aanu lati ọwọ ọba ni igba ti idoju ijọba bolẹ bẹrẹ. Awọn Jesuit nikan ni wọn n gbadun ninu orilẹ ede ti n jẹra naa, wọn si ṣe akoso pẹlu iwa onroro lori awọn ile ijọsin, ile ẹkọ, ọgba ẹwọn, ati ibi ifinisiṣẹ.”ANN 124.1

    Iyinrere i ba fun France ni idahun si wahala iṣelu ati ti awujọ ti wọn ya ọgbọn awọn alufa, ọba, ati awọn aṣofin rẹ lẹnu, ti o wa ti orilẹ ede naa sinu ailofin ati iparun nikẹyin. Ṣugbọn labẹ iṣakoso Romu awọn eniyan padanu ikọni rere Olugbala nipa ifi-ara-eni-rubọ ati ifẹ aini-imọ-ti-ara-ẹni-nikan. A ti fa wọn kuro ninu siṣe isẹra ẹni nitori rere ẹlomiran. Awọn ọlọrọ ko ri ibawi fun bí wọn ti n ni awọn alaini lara, awọn alaini ko ri iranlọwọ fun imunisin ati irẹsilẹ wọn. Imọ-ti-ara-ẹni-nikan awọn ọlọrọ ati ti awọn alagbara tubọ n pọ si, o tubọ n fi ara han si, o si n tubọ n nini lara si. Fun ọpọ ọdun oju kokoro ati inakuna awọn ọlọrọ maa n jasi ilọnilọwọgba ti o nira fun awọn talaka. Awọn ọlọrọ ṣẹ awọn alaini, awọn alaini si korira awọn ọlọrọ pẹlu.ANN 124.2

    Ni ọpọlọpọ agbegbe, awọn ọlọrọ ni wọn ni ilẹ, awọn oṣiṣẹ si jẹ ayalẹlo lasan; ikawọ awọn onilẹ ni wọn wa, eyi si jẹ ki wọn o tẹsí ibeere wọn bi o ti wu ki o ga to. Wahala titọju ijọ ati ilu bọ si ori awọn ti n ṣiṣẹ ati awọn otoṣi, wọn n san owo ori nla fun ilu ati awọn alufa. “A ka igbadun awọn ọlọrọ si ofin ti o ga julọ; awọn agbẹ ati alaini lè ma jẹun, eyi ko kan awọn ti n ni wọn lara rara. . . . A fi agbara mu awọn eniyan ni gbogbo ọna lati ṣe aajo fun ifẹ awọn onilẹ wọn nikan. Igbesi aye awọn agbẹ jẹ eyi ti o kun fun iṣẹ laisimi ati ijiya ti ko lopin; bi wọn ba gboya lati ṣe aroye, pẹlu ẹgan ni a maa n fi tẹti si wọn. Awọn ile idajọ saba maa n tẹti si ọlọrọ lati tako otoṣi; awọn onidajọ maa n gba abẹtẹlẹ; erokero to ba ti ọkan awọn ọlọrọ jade si maa n ni agbara ofin, nitori iwa ibajẹ ti o gbilẹ kan. Awọn owo ori ti awọn alaṣẹ ilu n gba ni ọna kan, ati eyi ti awọn alufa n gba ni ọna keji, eyi ti o n de apo ijọ tabi ti ijọba ko to idaji; inakuna ni ọna itẹra-ẹni-lọrun ni wọn a fi na eyi ti o ku. Awọn eniyan ti wọn si n sọ awọn ara ilu bii ti wọn di talaka yii kii san owo ori, ofin tabi aṣa ilu si fun wọn ni gbogbo ipo inu ilu. Awọn ti wọn ni anfani ninu ilu to 150,000, a si sọ ẹgbẹlẹgbẹ awọn to ku di alainireti ti o n gbe igbe aye irẹsilẹ nitori igbadun wọn.”ANN 124.3

    Aafin kun fun igbadun ati inakuna. Ifọkantan perete ni o wa laarin awọn eniyan ati awọn adari. Pẹlu ifura ni awọn eniyan fi n wo gbogbo iṣẹ ijọba wipe o ni ete kan ti wọn fẹ pa ati wipe o ni imọ-ti-ara-ẹni-nikan ninu. Fun o le ni aadọta ọdun ṣaaju idoju ijọba bolẹ, Louis XV ni o wa ni ori itẹ, ẹni ti a ri gẹgẹ bi ọba onimẹlẹ, alainilari ati onifẹkufẹ ara, ani ni iru akoko buburu yii. Pẹlu awọn alaṣẹ oniwa-ibajẹ ti wọn jẹ onroro, ati awọn ọmọ ilu alaimọkan ti a sọ di alaini, owo ijọba ko to ná, o si ti su awọn eniyan, a ko nilo oju woli lati ri rogbodiyan ti o de tan. Ọba, saba maa n da awọn olubadamọran rẹ lohun nigba ti wọn ba ki i nilọ bayii pe: “Ẹ ṣe akitiyan lati ri wipe ohun gbogbo n tẹsiwaju niwọn igba ti mo ba si le wa laaye; lẹyin ti mo ba ku, o le ri bi o ba ti ṣe fẹ.” Lasan ni a ṣe ikilọ fun atunṣe. O ri awọn iwa ibi naa, ṣugbọn ko ni igboya tabi agbara lati koju wọn. Iparun ti o n duro de France ni o ṣe alaye rẹ rẹgi ninu idahun onimẹlẹ ati ti imọ-ti-ara-ẹni-nikan ti o sọ wipe, “Lẹyin mi, igbi omi!”ANN 124.4

    Nipa ṣiṣiṣẹ lori ẹmi owu awọn ọba ati awọn ti n ṣe akoso, Romu jẹ ki wọn ti awọn eniyan mọ inu igbekun, nitori ti o mọ daradara wipe ijọba naa a di alailagbara, o si gbero wipe nipa eyi yoo le di awọn alaṣẹ ati awọn ero ilu mọ abẹ iṣakoso rẹ. Pẹlu iwoye ti o ri ọjọ iwaju o mọ wipe lati le mu awọn eniyan nigbekun daradara, a nilati de ẹwọn naa mọ ọkan wọn; nitori ọna ti o daju julọ lati maṣe jẹ ki wọn le bọyọ kuro ninu igbekun wọn ni lati maṣe jẹ ki wọn le ja fun ominira. Ọpọlọpọ ijiya ti o ju ti ara lọ ti o wá lati ara ilana rẹ ni iwa ibajẹ. A fi Bibeli dun wọn, a tun fi wọn silẹ fun ikọni lori fifi aimoye di nnkan mu ati imọ-ti-ara-ẹni nikan, awọn eniyan wa ninu aimọkan ati igbagbọ asan, wọn tẹri sinu iwa ipa, titi ti wọn ko fi le ṣe akoso ara wọn.ANN 124.5

    Ṣugbọn abayọri gbogbo iwọnyi yatọ patapata si erongba Romu. Dipo ki o jẹ ki awọn eniyan o gba ikọni rẹ ni aironu, iṣẹ rẹ yori si sisọ awọn eniyan di alaigbagbọ ati oluṣọtẹ. Wọn kọ ẹsin Romu silẹ gẹgẹ bi ète awọn alufa. Wọn ri awọn alufa gẹgẹ bi ara awọn ti n ni wọn lara. Romu ni ọlọrun kan ṣoṣo ti wọn mọ; ikọni rẹ si ni ẹsin wọn kan ṣoṣo. Wọn ri iwa wọbia ati onroro rẹ gẹgẹ bi awọn eso ohun ti Bibeli fi n kọni, wọn ko si ni ni ohun kankan ṣe pẹlu rẹ.ANN 125.1

    Romu ti fi iwa Ọlọrun ati awọn ilana rẹ han ni ọna ti ko tọ, ni akoko yii, awọn eniyan kọ Bibeli ati Ẹni ti o kọ ọ silẹ. O fẹ ki awọn eniyan o ni igbagbọ ninu awọn ikọni rẹ ni aironu nipa sisọ wipe Iwe Mimọ fi ọwọ si. Ni atako si eyi, Voltaire ati awọn akẹgbẹ rẹ kọ ọrọ Ọlọrun silẹ patapata, wọn si fọn majele aigbagbọ ka ibi gbogbo. Romu ti fi bata irin lọ awọn eniyan mọlẹ; bayii awọn eniyan ti a rẹ silẹ ti a tun fiya jẹ, ni kikọ ifiyajẹni rẹ silẹ, kọ gbogbo idanilẹkun silẹ. Wọn binu nitori arẹnijẹ ti o n dan yinrin ti wọn ti n tẹriba fun fun igba pipẹ, wọn kọ otitọ ati irọ silẹ lapapọ; wọn fi ainiwọntuwọnsi pe ominira, awọn ẹru iwa ipa n yọ nitori ohun ti wọn pe ni ominira.ANN 125.2

    Ni igba ti idoju ijọba bolẹ bẹrẹ, nipa aṣẹ ọba awọn eniyan ni aṣoju ti o ju ti apapọ awọn ijoye ati ti awọn alufa lọ. Nipasẹ eyi, agbara wa ni ọwọ wọn; ṣugbọn wọn ko ṣetan lati lo o pẹlu ọgbọn ati iwọntuwọnsi. Pẹlu itara lati ṣe atunṣe si gbogbo iya ti wọn ti jẹ, wọn pinu lati ṣe atunto ni awujọ. Awọn ero ilu ti inu n bi, ti ọkan wọn kun fun ikoro ati iranti ijiya ọjọ pipẹ, pinu lati yi ijiya inu ilu, eyi ti wọn ko le gbe mọ pada, ki wọn si gbẹsan ara wọn lara gbogbo awọn ti wọn ri gẹgẹ bi okunfa ijiya wọn. Awọn ti a n fiya jẹ lo ẹkọ ti wọn kọ ni abẹ inira, wọn wa di olufiyajẹ awọn ti n fi iya jẹ wọn.ANN 125.3

    France ti iya n jẹ n kore ohun ti o gbin ninu ẹjẹ. Ayọrisi bi o ti tẹriba fun aṣẹ Romu jẹ eyi ti o buru jọjọ. Nibi ti France gbe igi idanasunni si ni igba iṣẹ Atunṣe labẹ akoso ẹsin Romu, nibẹ naa ni idoju ijọba bolẹ gbe ero ibẹnilori rẹ akọkọ si. Ni ibi gan an pato ti a ti dana sun awọn ajẹriku akọkọ ni ọrundun kẹrindinlogun, nibẹ ni a ti bẹ awọn olujiya akọkọ lori ni ọrundun kejidinlogun. Ni kikọ iyinrere, eyi ti i ba wo o san silẹ, France ṣilẹkun silẹ fun aigbagbọ ati iparun. Nigba ti a ti kọ ikoninijanu ofin Ọlọrun silẹ, a ri wipe ofin eniyan ko tó lati da igbi ifẹkufẹ alagbara inu eniyan duro; a si ti orilẹ ede naa sinu iṣọtẹ ati idarudapọ. Biba Bibeli jagun ni o bẹrẹ akoko ti a pe ni Akoso Ẹru ninu itan aye. Alaafia ati ayọ kuro ninu ile ati ọkan awọn eniyan. Ko si ẹni ti o ni aabo. A le funra si ẹni ti n ṣẹgun loni, ki a si ṣe idalẹbi fun ni ọla. Iwa ipa ati ifẹkufẹ ara n ṣe akoso laisi idiwọ.ANN 125.4

    A fi ipa mu ọba, awọn alufa, ati awọn ijoye lati bọwọ fun iwa buburu ti awọn eniyan ti wọn ti ya were yii n wu. Bi wọn ti pa ọba tubọ n ru ongbẹ wọn fun igbẹsan soke ni; awọn ti wọn si paṣẹ iku fun naa tẹle lọ si ibi ibẹnilori laipẹ. A ṣe ipinu lati pa gbogbo awọn ti a ba funra si wipe wọn ko fẹran idoju ijọba bolẹ naa. Awọn ọgba ẹwọn kun akunfaya, ni akoko kan, awọn bi i o le ni 200,000 ni wọn wa ninu rẹ. Awọn iṣẹlẹ ẹlẹru ni wọn kun inu awọn ilu ijọba naa. Ẹgbẹ awọn ọlọtẹ kan n tako omiran, France wa di oju ija nla fun awọn eniyan ti wọn jijọ n jijadu, awọn ti igbona ifẹkufẹ n dari. “Ni Paris rogbodiyan kan n tẹle omiran, ti gbogbo awọn olugbe inu rẹ si pin ara wọn si ẹlẹgbẹjẹgbẹ ti n jijọ n ja, ti erongba wọn ko ju ki wọn maa pa ara wọn lọ.” Lati pakun ijiya awọn eniyan, orilẹ ede naa n ba awọn orilẹ ede awọn agbara nla ni Europe ja ija alagbara ọlọjọ pipẹ. Orilẹ ede naa ti di otoṣi, awọn ọmọ ogun n beere fun owo ti wọn jẹ wọn, ebi n pa awọn ara Paris, awọn ọmọ ita ti ba awọn agbegbe jẹ, iwa ọlaju si ti fẹrẹ kasẹ nilẹ nitori iwa rogbodiyan ati iwa ainiwọntuwọnsi.”ANN 125.5

    Awọn eniyan ti kọ ẹkọ iwa ika ati ifiyajẹni ti Romu fi kọni daradara. Ọjọ igbẹsan ti de ni ikẹyin. Kii ṣe awọn ọmọlẹyin Kristi ni a n ti mọ inu tubu, ti a tun n wọ lọ si ibi isuninina ni akoko yii. O pẹ ti a ti pa wọn, tabi ti a ti le wọn lọ si ilẹ ajeji. Romu ti kii ṣaanu funni wa ni imọlara agbara buburu awọn ti o ti kọ lati ni inudidun si iṣẹ ẹjẹ. “Apẹẹrẹ inunibini ti awọn alufa France ti fihan fun ọjọ pipẹ, ni a wa n wu si wọn pẹlu agbara nla. Ibi ibẹnilori pupa foo pẹlu ẹjẹ awọn alufa. Ibi ifipa muni siṣẹ ati ọgba ẹwọn, ti awọn Huguenots fi igba kan kun inu wọn wa kun fun awọn ti n ṣe inunibini si wọn. A fi ẹwọn de wọn mọ àga ìjòkó, ti wọn si n ṣiṣẹ pẹlu obele, awọn alufa Katoliki ti Romu ni iriri gbogbo ijiya ti ijọ wu si awọn ẹlẹkọ odi oniwapẹlẹ laisi idiwọ.”ANN 125.6

    “Lẹyin eyi ni akoko ile igbẹjọ ti o buru julọ, ti o lo awọn ofin ti wọn buru julọ; nigba ti eniyan ko le ki alabagbe rẹ, tabi gba adura . . . laisi ewu wipe o le di ọran nla; nigba ti awọn amí wa ni ibi gbogbo; nigba ti ibi ibẹnilori n ji ṣiṣẹ laraaro; nigba ti ọgba ẹwọn kun fọfọ bi awọn ọkọ ti a fi n ko awọn ẹru; nigba ti awọn ibi ti omi n gba san kọja n san fun ẹjẹ lọ si odo Seine. . . . Nigba ti ọkọ n ko awọn ti wọn jẹbi gba aarin igboro Paris kọja lojoojumọ lọ si ibi iparun wọn, awọn alaṣẹ ti igbimọ aṣejọba ran lọ si awọn ẹka ile iṣẹ n yọ ninu iwa ika ti o buru jai eyi ti a ko mọ ninu olu ilu. Ọbẹ ẹrọ ti a fi n pani ko yara to fun iṣẹ ipaniyan wọn. A fi ibọn pa ọpọlọpọ awọn eniyan miran. A da iho lu si abẹ ọkọ oju omi ti a ko ọpọlọpọ eniyan si. Ilu Lyons di aṣalẹ. Ni ilu Arras, a ko ṣe aanu buburu ti iku ti o yá kankan fun awọn ẹlẹwọn. Titi de Loire, lati Saumur titi de okun, ọpọ awọn ẹyẹ loriṣiriṣi ni wọn n jẹ awọn oku ti wọn wa ni ihoho, ti a fi okun so pọ lọna to banilẹru. A ko fi aanu han fun ọkunrin tabi obinrin, ọmọde tabi agba. Iye awọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin ti ọjọ ori wọn to ọmọ ọdun mẹtadinlogun ti ijọba buburu naa pa ni a o maa ka iye wọn ni ọgọrọọrun. A ja awọn ọmọ jojolo gba kuro ni ọyan iya wọn, ti a si n sọ wọn lati ori ọkọ kan de ikeji laarin awọn ọmọ ẹgbẹ Jacobin.” Laarin ọdun mẹwa pere, ọgọọrọ awọn eniyan ni wọn ṣegbe.ANN 126.1

    Gbogbo iwọnyi ṣẹlẹ gẹgẹ bi Satani ti fẹ. Ohun ti o ti n ṣiṣẹ fun ọdun pipẹ lati ri niyii. Ẹtan ni ilana rẹ lati ibẹrẹ titi de opin, erongba kan ṣoṣo ti o ni si ni lati ko ewu ati ijiya ba eniyan, lati ba iṣẹ Ọlọrun jẹ, ki o si mu kuro, lati ba erongba aanu ati ifẹ Ọlọrun jẹ, ki o si fa ibanujẹ ni ọrun. Nipasẹ ọgbọn ẹwẹ itanjẹ rẹ, o fọ awọn eniyan loju, yoo si jẹ ki wọn da Ọlọrun lẹbi nitori iṣẹ rẹ wọnyi, afi bi ẹnipe gbogbo ijiya wọnyi jẹ abayọri eto Ẹlẹda. Ni ọna kan naa, nigba ti awọn ti o fi agbara rẹ rẹ silẹ ti o tun fiyajẹ ba ri ominira wọn, o n dari wọn lati ṣe aṣeju ati lati wuwa buburu. Awọn onroro ati afiyajẹni a wa na ọwọ si iṣẹlẹ aileko-ara-ẹni-nijanu yii gẹgẹ bi apẹẹrẹ ayọrisi ominira.ANN 126.2

    Nigba ti a ba da irọ kan mọ ninu iboju kan, Satani a tun fun ni iboju miran, awọn eniyan a si fi itara gba a bii ti iṣaaju. Nigba ti awọn eniyan ri ẹsin Romu gẹgẹ bi ẹtan, ti ko si le lo awọn iranṣẹ rẹ lati jẹ ki wọn o tẹ ofin Ọlọrun loju, o dari wọn lati jẹ ki wọn ri gbogbo ẹsin gẹgẹ bi itanjẹ, ati Bibeli gẹgẹ bi itan arosọ; ati ni kikọ aṣẹ mimọ silẹ, wọn fi ara wọn silẹ fun ẹṣẹ patapata. Aṣiṣe nla ti o mu ewu yii wa si ori awọn olugbe France ni bi wọn ti se kọ otitọ nla kan yii silẹ: wipe inu ifofinde ofin Ọlọrun ni ominira tootọ wa. “Ibaṣepe iwọ fi eti si ofin Mi! nigba naa ni alaafia rẹ iba da bi odò, ati òdodo rẹ bi igbi omi okun.” “Alaafia ko si fun awọn eniyan buburu, ni Oluwa wi.” “Ṣugbọn ẹni ti o ba fi eti si Mi yoo maa gbe ni ailewu, yoo si fi ara balẹ kuro ninu ibẹru ibi.” Aisaya 48:18, 22; Owe 1:33.ANN 126.3

    Awọn ti ko gbagbọ ninu iwalaaye Ọlọrun, awọn alaigbagbọ, ati awọn afasẹyin tako ofin Ọlọrun, wọn si kọ ọ silẹ; ṣugbọn ayọrisi ipa wọn fihan wipe wiwa ni alaafia eniyan so pọ mọ ṣiṣe igbọran si ilana Ọlọrun. A rọ gbogbo awọn ti ko ni ka ẹkọ lati inu iwe Ọlọrun lati ka a ninu itan awọn orilẹ ede.ANN 126.4

    Nigba ti Satani n ṣiṣẹ nipasẹ ijọ Romu lati maṣe jẹ ki awọn eniyan o ṣe igbọran, o fi ero rẹ pamọ, o si fi iboju bo iṣẹ rẹ debi pe a ko ri irẹsilẹ ati ijiya ti o tẹle gẹgẹ bi eso ẹṣẹ. Ẹmi Ọlọrun si ni o n di agbara rẹ lọwọ ti ko fi jẹ ki erongba rẹ o wa si imuṣẹ patapata. Awọn eniyan ko le tọ ipasẹ ayọrisi naa de ibẹrẹ rẹ ki wọn si ri okunfa ijiya wọn. Ṣugbọn ninu idoju ijọba bolẹ, ile igbimọ aṣofin apapọ kọ ofin Ọlọrun silẹ patapata. Ninu Iṣakoso Ibẹru ti o tẹle, gbogbo eniyan ni wọn le ri iṣọwọṣiṣẹ okunfa ati ayọrisi naa.ANN 126.5

    Nigba ti France kọ Ọlọrun silẹ ni gbangba, ti o kọ Bibeli silẹ, awọn eniyan buburu ati ẹmi okunkun yọ nitori bi wọn ti ṣe ri ohun ti wọn ti n wa fun igba pipẹ—ijọba ti ko ni ni ikalọwọko ofin Ọlọrun. Nitori ti a ko tete ṣe idajọ si iṣẹ buburu, ọkan awọn ọmọ eniyan “pinu ninu wọn lati ṣe ibi.” Oniwasu 8:11. Ṣugbọn riru ofin pipe ati ofin ododo gbọdọ yori si ijiya ati iparun ni. Bi o tilẹ jẹ wipe a ko ṣe idajọ rẹ lọgan, iwa buburu eniyan yoo ṣiṣẹ iparun wọn dandan ni. Iwa ifasẹyin ati iwa ọdaran ti a ti n wu fun ọpọ ọdun ti n ko ara wọn jọ pọ fun ibinu di ọjọ igbẹsan; nigba ti iwa ẹṣẹ wọn kun, o ti pẹ ju ki awọn ti wọn gan Ọlọrun to mọ wipe ohun ti o lẹru ni lati da suuru Ọlọrun lagara. A mu Ẹmi Ọlọrun ti n kani lọwọ ko, ti o n di agbara buburu Satani lọwọ, kuro pupọpupọ, a si gba ẹni ti o jẹ wipe idunnu rẹ kan ṣoṣo ni ijiya eniyan laaye lati ṣe iṣẹ rẹ bi o ti fẹ. A fi awọn ti wọn yan iṣẹ iṣọtẹ silẹ lati ka eso rẹ titi ti ilẹ naa fi kun fun iwa ọdaran ti wọn buru ju eyi ti a le kọ silẹ lọ. A gbọ igbe—igbe ibanujẹ kikoro—lati awọn agbegbe ti a ti sọ di ahoro ati ilẹ ti a ti parun. Ẹsin, ofin, alaafia awujọ, idile, ilu ati ijọ—gbogbo wọn ni ọwọ aimọ ti a gbe si ofin Ọlọrun bi lulẹ. Ọkunrin ọlọgbọn naa sọ nitootọ wipe: “Eniyan buburu yoo ṣubu ninu iwa buburu rẹ.” “Bi ẹlẹṣẹ tilẹ ṣe ibi ni igba ọgọrun, ti ọjọ rẹ si gun, ṣugbọn nitootọ emi mọ wipe yoo dara fun awọn ti wọn bẹru Ọlọrun, ti wọn wariri niwaju Rẹ: ṣugbọn ki yoo dara fun eniyan buburu.”ANN 126.6

    Owe 11:5; Oniwaasu 8:12, 13. “Wọn korira imọ, wọn ko yan ibẹru Oluwa;” “nitori naa, wọn yoo jẹ ninu eso ọna wọn, wọn o si kun fun ète ara wọn.” Owe 1:29, 31.ANN 127.1

    Awọn ẹlẹri tootọ fun Ọlọrun, ti agbara asọrọ odi ti o “jade wa lati inu ọgbun ainisalẹ” pa, ko ni dakẹ jẹẹ fun igba pipẹ. “Lẹyin ọjọ mẹta ati aabọ, Ẹmi iye lati ọdọ Ọlọrun wọ inu wọn, wọn si duro lori ẹsẹ wọn; ẹru nla si ba gbogbo awọn ti wọn ri wọn.” Ifihan 11:11. Ni ọdun 1793 ni igbimọ France fi ọwọ si ofin ti o pa ẹsin Kristẹni rẹ, ti o si kọ Bibeli silẹ. Ọdun mẹta ati aabọ lẹyin eyi, igbimọ yii kan naa pa aṣẹ ti o yi ofin yii pada, o si fi aaye gba Iwe Mimọ. Araye n woran pẹlu iyalẹnu si iru ẹbi ti o jẹyọ latari kikọ Ọrọ Mimọ silẹ, awọn eniyan si mọ bi o ti ṣe pataki tó lati ni igbagbọ ninu Ọlọrun ati ọrọ Rẹ gẹgẹ bi ipilẹ fun iwa rere ati iwa ọmọluabi. Oluwa wipe: “Tani iwọ kẹgan, ti o si sọrọ buruku si? tani iwọ si gbe oju rẹ ga si, ti o si gbe ohun rẹ soke gangan? si Ẹni Mimọ Israeli.” Aisaya 37:23. “Nitori naa sa wo o, Emi o mu ki wọn mọ lẹẹkan yii, Emi o si mu ki wọn mọ ọwọ Mi ati ipa Mi; wọn o si mọ wipe orukọ Mi ni Jehofa.” Jeremaya 16:21.ANN 127.2

    Nipa awọn ẹlẹri naa, woli naa tẹsiwaju lati sọ wipe: “Wọn si gbọ ohun nla lati ọrun ti o n sọ fun wọn wipe, Ẹ goke wa sihin. Wọn si goke lọ si ọrun ninu ikuuku awọsanma; awọn ọta wọn si kiyesi wọn.” Ifihan 11:12. Lati akoko ti France ti ba ẹlẹri Ọlọrun mejeeji jagun, a bu ọla fun wọn ju bi a ti ṣe tẹlẹ ri lọ. Ni 1804, a da British ati Foreign Bible Society silẹ. Awọn ẹgbẹ miran ti wọn fi ara jọ ọ tẹle, pẹlu ọpọlọpọ ẹka ni orilẹ ede Europe. Ni 1816, a da American Bible Society silẹ. Nigba ti a da British Society silẹ, aadọta ede ni a fi tẹ Bibeli sita. Lati igba naa lọ, a ti ṣe itumọ rẹ ni ọpọlọpọ ede.ANN 127.3

    Fun aadọta ọdun ṣaaju 1792, a ko kọbiara si iṣẹ iranṣẹ ni ilẹ okeere. A ko da ẹgbẹ tuntun silẹ, awọn ijọ perete si ni wọn n ṣa ipa lati tan ẹsin Kristẹni ka ilẹ awọn abọriṣa. Ṣugbọn bi ọrundun kejidinlogun ti n lọ si opin, ayipada nla ṣẹlẹ. Abayọri iṣọwọronu eniyan ko tẹ wọn lọrun mọ wọn ri wipe wọn nilo ifihan Ọlọrun ati ẹsin ti o jade lati inu wa. Lati akoko yii, iṣẹ ilẹ okeere dagba ni ọna ti ko gba ṣẹlẹ ri.ANN 127.4

    Idagbasoke ninu iṣẹ itẹwe fun iṣẹ pinpin Bibeli kiri lagbara. Awọn ohun elo ibara ẹni sọrọ laarin awọn orilẹ ede ti o pọ si, wíwó idiwọ aimọkan ati idanikanwa gẹgẹ bi orilẹ ede ati bi popu Romu ti ṣe padanu agbara oṣelu ṣi ọna silẹ lati jẹ ki ọrọ Ọlọrun wọle. Fun ọdun diẹ, a ta Bibeli laarin igboro Romu laisi idiwọ, bayi, a ti gbe de ibi gbogbo ti eniyan n gbe lori ilẹ aye.ANN 127.5

    Voltaire alaigbagbọ fi igba kan fọnnu wipe: “O su mi lati gbọ bi awọn eniyan ti n tẹnumọ wipe awọn ọkunrin mejila ni wọn da ẹsin Kristeni silẹ. Maa fi daniloju wipe ẹnikan ṣoṣo le doju rẹ bolẹ.” Ọpọ iran ni wọn ti kọja lẹyin iku rẹ. Ọgọọrọ awọn eniyan si ni wọn darapọ mọ awọn ti n ba Bibeli jagun. Ṣugbọn dipo ki a pa run, nibi ti ọgọrun wa ni akoko Voltaire, ẹgbẹrun mẹwa, ani ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun ẹda iwe Ọlọrun ni wọn wa. Ninu ọrọ Alatunṣe iṣaaju nipa ijọ Kristẹni, “Bibeli jẹ irin alagbẹdẹ ti o ti lo ọpọlọpọ òòlù gbó.” Oluwa wipe: “Ko si ohun ija ti a ṣe lodi si ọ ti yoo ṣe deede; gbogbo ahọn ti o ba dide si ọ ni idajọ ni iwọ yoo da lẹbi.” Aisaya 54:17 “Ọrọ Ọlọrun yoo wa titi lae.” “Gbogbo aṣẹ Rẹ daju. Wọn duro gbọin titi lae, a si ṣe wọn ninu otitọ ati ododo.” Aisaya 40:8; O. Dafidi 111:7,8. Ohunkohun ti a ba kọ si ori aṣẹ eniyan yoo bi wo; ṣugbọn eyi ti a ba pilẹ rẹ si ori apata ọrọ Ọlọrun ti ko le yipada yoo duro titi lae.ANN 127.6

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents