Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KẸRINDINLOGUN—AWỌN BABA ARINRIN-AJO

    Nigbati awọn Alatunṣe England n kọ ẹkọ Romu silẹ, wọn di ọpọlọpọ awọn iṣesi rẹ mu. Bi o tilẹ jẹ wipe wọn kọ aṣẹ Romu silẹ, ki i ṣe diẹ ninu awọn aṣa ati iṣesi rẹ ni wọn ko wọ inu ijọsin ijọ England. A sọ wipe awọn nnkan wọnyi ko ni i ṣe pẹlu ẹri ọkan; ati pe bi o tilẹ jẹ wipe Iwe Mimọ ko pa wọn laṣẹ, nitori naa wọn ko ṣe pataki tobẹẹ, ati nitori pe a ko tako wọn, wọn ko lewu. Siṣe awọn nnkan wọnyi jẹ ki ọgbun ti o pin awọn ijọ ti a fọ mọ ati Romu niya o kere si, wọn si sọ wipe wọn n jẹ ki awọn atẹle Romu o gba igbagbọ Protestant.ANN 129.1

    Si awọn ti ko fẹ ayipada ti wọn si n fẹ ibarẹ, o dabi ẹnipe iṣọwọronu yii muna doko. Ṣugbọn awọn kan wa ti wọn ko ronu bẹẹ. Wipe awọn aṣa wọnyi “le di ọgbun ti o wa laarin Romu ati iṣẹ Atunṣe” jẹ idi kan ti o lagbara lati fi kọ wọn silẹ. Wọn ri wọn gẹgẹ bi ami ẹru ninu eyi ti a ti gba wọn silẹ ti wọn ko si ni ero lati pada sinu rẹ. Wọn ronu wipe Ọlọrun ti gbe awọn ilana ti wọn n dari ijọsin Rẹ kalẹ sinu ọrọ Rẹ, ati pe awọn eniyan ko ni ominira lati fikun wọn tabi yọ kuro ninu wọn. Ohun ti o fa iyapa nla ti akọkọ ni wiwa ọna lati fi aṣẹ ijọ ran ti Ọlọrun lọwọ. Romu bẹrẹ nipa pipaṣẹ ohun ti Ọlọrun ko tako, o pari rẹ si titako ohun ti Ọlọrun palaṣẹ.ANN 129.2

    Ọpọ ni wọn fi tọkantọkan fẹ ki a pada si iwa mimọ ati ailabula ti wọn wa ninu ijọ akọkọ. Wọn ri ọpọlọpọ awọn aṣa ijọ ilẹ Gẹẹsi gẹgẹ bi ohun iranti ẹsin ibọriṣa, ẹri ọkan wọn ko si le jẹ ki wọn darapọ mọ ijọsin rẹ. Ṣugbọn nitori pe aṣẹ ilu n ti ijọ lẹyin, ko fi aaye gba ki ẹnikẹni o yapa kuro ninu ilana rẹ. Ofin pa a laṣẹ pe ki a kopa ninu ijọsin rẹ, a ko si fi aaye gba ipejọpọ fun ijọsin ti a ko ba pa laṣẹ, pẹlu ijiya lilọ si ọgba ẹwọn, kikuro ni ilu, ati iku.ANN 129.3

    Ni ibẹrẹ ọrundun kẹtadinlogun, ọba ti o ṣẹṣẹ gun ori itẹ England sọ wipe oun ti pinu lati mu ki awọn Puritans “o dabi awọn toku, tabi . . . ki wọn o da wọn lagara titi ti wọn a fi kuro lori ilẹ naa, tabi ohun ti o buru ju eyi lọ.” A dọdẹ wọn, a ṣe inunibini si wọn, a tun ti wọn mọle, wọn ko ri aami fun akoko rere ni ọjọ iwaju, ọpọlọpọ wa gbagbọ wipe, fun awọn ti wọn ba fẹ sin Ọlọrun gẹgẹ bi ẹri ọkan wọn ba ti sọ ọ, “England ko le jẹ ibugbe fun wọn mọ lae.” Ni ikẹyin awọn miran pinu lati wa aabo ni Holland. Wọn doju kọ iṣoro, adanu, ati ọgba ẹwọn. Erongba wọn ko wa si imuṣẹ. Ṣugbọn iforiti pẹlu iduroṣinṣin ṣẹgun nikẹyin, wọn ri aabo ni orilẹ ede Dutch.ANN 129.4

    Nigba ti wọn n sa kiri, wọn fi ile wọn, ẹru wọn, ati ọna ati ri onjẹ oojọ wọn silẹ. Wọn di ajeji ni ilẹ miran, laarin awọn eniyan ti n sọ ede miran, ti wọn tun ni aṣa miran. O di dandan fun wọn lati wa iṣẹ tuntun ti wọn ko ṣe ri lati le ri onjẹ jẹ. Awọn ti wọn ti fi idaji ọjọ aye wọn ro oko, wa nilati lọ kọ iṣẹ ọwọ. Ṣugbọn wọn fi tayọtayọ gba ipo naa, wọn ko fi akoko ṣofo laiṣiṣẹ tabi ṣe irahun. Bi o tilẹ jẹ wipe àìní n ba wọn fínra, wọn dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ibukun ti wọn si n ri gba wọn tun ri ayọ nitori pe wọn le ṣe ijọsin laisi idiwọ. “Wọn mọ wipe arinrin-ajo ni wọn, wọn ko si tẹjumọ awọn nnkan wọnyẹn, ṣugbọn wọn gbe oju wọn si oke ọrun, ilu ti wọn fẹran julọ, ọkan wọn si balẹ.”ANN 129.5

    Lẹyin odi ati ninu inira, ifẹ ati igbagbọ wọn tubọ n lokun si ni. Wọn gbẹkẹle ileri Ọlọrun, ko si bà wọn kù ni akoko aini wọn. Angẹli Rẹ wà ni ẹba wọn lati mu wọn lọkan le ati lati ran wọn lọwọ. Nigba ti o si dabi ẹnipe ọwọ Ọlọrun n tọka wọn si ikọja okun, si ilẹ ti wọn ti le ri aaye fun ara wọn, ti wọn a le fun awọn ọmọ wọn ni ominira ẹsin ti o ṣe iyebiye gẹgẹ bi ohun ajogunba, wọn tẹsiwaju laibẹru si oju ọna aanu Ọlọrun.ANN 129.6

    Ọlọrun gba wahala laaye lati ba awọn eniyan Rẹ lati le pese wọn silẹ lati le ṣe ohun agbayanu ti O fẹ fun wọn. A rẹ ijọ silẹ, ki a baa le gbe e ga. Ọlọrun fẹ fi agbara Rẹ han nitori wọn, lati le fun araye ni ẹri miran wipe Oun ko ni kọ awọn ti wọn ba gbẹkẹle Oun silẹ. O ṣe ohun gbogbo lati jẹ ki ibinu Satani ati ète awọn eniyan buburu o jasi igbega ogo Rẹ ati lati le kó awọn eniyan Rẹ wa si ibi aabo. Inunibini ati ileni kuro ni ilu n pese ọna silẹ fun ominira.ANN 129.7

    Nigba ti a kọkọ fi ipa mu wọn lati yapa kuro ninu ijọ England, awọn Puritan ti jẹ ẹjẹ ọlọwọ, gẹgẹ bi ẹni ominira Oluwa, “lati rin papọ ninu gbogbo ọna Rẹ ti a fi han wọn tabi ti a yoo fi han wọn.” Eyi gan an ni ẹmi iṣẹ atunṣe nitootọ, ẹkọ ti o ṣe pataki ninu ẹsin Protestant. Pẹlu erongba yii ni awọn Arinrin-ajo fi kuro ni Holland lati wa ilé ni Amerika. John Robinson, alufa wọn, ti iṣọwọṣiṣẹ Ọlọrun ko jẹ ki o tẹle wọn lọ sọ fun awọn arinrinajo wọnyi ninu ọrọ odigboṣe rẹ wipe:ANN 130.1

    “Ẹyin ará, laipẹ a yoo pinya, Oluwa si mọ boya maa tun ri oju yin lẹẹkan si. Ṣugbọn boya Oluwa fi aaye gba a tabi ko fi aaye gba a, mo rọ yin niwaju Ọlọrun ati awọn angẹli alabunkun Rẹ lati maṣe tẹle mi ju bi mo ba ti ṣe tẹle Kristi lọ. Bi Ọlọrun yoo ba fi ohun miran han fun yin nipasẹ ohun èlò Rẹ miran, ẹ ṣetan lati gba a, gẹgẹ bi ẹ ti ṣetan lati gba otitọ ninu iṣẹ iranṣẹ mi; nitori ti o damiloju wipe Oluwa ní awọn otitọ miran ati imọlẹ ti koi ti bú jade lati inu ọrọ mimọ Rẹ wá.”ANN 130.2

    “Ni ipa ti emi, mi o le sọkun fun ipo awọn ijọ ti a fọ mọ tó, awọn ti wọn ti de gbedeke kan ninu ẹsin, ti wọn ko si ni lọ kọja ohun elo ti a fi ṣe atunṣe wọn. A ko le mu awọn atẹle Luther lọ kọja ohun ti Luther ri; . . . ẹ ri awọn atẹle Calvin, wọn duro gbọin si ibi ti eniyan nla Ọlọrun naa fi wọn silẹ si, sibẹ ko ri ohun gbogbo. A nilati ṣe ikaanu fun iwa oṣi yii gidigidi; nitori pe bi o tilẹ jẹ wipe wọn jẹ ina ti n jo ti o si n tan ni akoko wọn, sibẹ, wọn ko wọ inu gbogbo imọran Ọlọrun, ṣugbọn bi o ba jẹ wipe wọn si wa laaye ni, wọn i ba fẹ lati gba imọlẹ miran gẹgẹ bi eyi ti wọn kọkọ gba.”ANN 130.3

    “Ẹ ranti ẹjẹ ijọ yin, ninu eyi ti ẹ ti fi ohùn ṣọkan lati rin ninu gbogbo ọna Oluwa, ti a fi han yin, tabi ti a o fi han yin. Ẹ ranti lati pa ileri ati ẹjẹ yin mọ pẹlu Ọlọrun ati ara yin, lati gba imọlẹ ati otitọ ti a o fi han fun yin ninu ọrọ Rẹ ti a kọ silẹ; ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, mo bẹ yin, ẹ ṣọra fun ohun ti ẹ o gba gẹgẹ bi otitọ, ki ẹ ṣe afiwe rẹ pẹlu awọn iwe otitọ ki ẹ to gba a; nitori ko ṣe e ṣe ki awọn Kristẹni ti wọn ṣẹṣẹ ti inu iru okunkun dudu ti o tako ilana Kristẹni yẹn jade, ki imọ ti o peye ni kikun o si bu yọ lẹẹkan naa.”ANN 130.4

    Ifẹ fun ominira ẹri ọkan ni o jẹ ki awọn Arinrin-ajo o doju kọ wahala irinajo gigun la okun ja, lati fi ara da iṣoro ati ewu inu aginju, ati pẹlu ibukun Ọlọrun, lati fi ipilẹ orilẹ ede nla lelẹ si ilẹ Amẹrika. Sibẹ pẹlu bi wọn ti jẹ olootọ ti wọn si bẹru Ọlọrun to, awọn Arinrin-ajo koi tii ni oye nipa ikọni ti ominira ti ẹsin. Wọn ko ṣetan lati fun awọn miran ni ominira ti wọn padanu ohun pupọ lati ri gba. “Perete, ani awọn ti wọn jẹ ọga ninu ironu ati iwuwasi ni ọrundun kẹtadinlogun ni wọn ni oye kiun nipa ẹkọ nla yii, eyi ti o jẹ jade lati inu Majẹmu Tuntun wa, ti o ri Ọlọrun gẹgẹ bi onidajọ kan ṣoṣo lori igbagbọ eniyan.” Ikọni wipe Ọlọrun ti fun ijọ ni ẹtọ lati ṣe akoso ẹri ọkan, ati lati ṣe itumọ ẹkọ odi ki o si fiya jẹ ẹ, jẹ ọkan lara eyi ti o jinlẹ julọ ninu awọn aṣiṣe ijọ padi. Nigba ti awọn Alatunṣe kọ ikọni Romu silẹ, ẹmi ainifarada rẹ ko kuro lara wọn tan. Okunkun nla ti ẹsin popu fi bo gbogbo ẹsin Kristẹni fun ọpọ ọdun ti o fi ṣe akoso koi tii kuro tan patapata. Ọkan lara awọn ọga ninu iṣẹ alufa ni Massachusetts Bay sọ wipe: “Ifarada ni o jẹ ki aye o tako ẹsin Kristẹni; ijọ ko si wu iwa buburu nipa fifi iya jẹ awọn ẹlẹkọ odi.” Awọn ti wọn tẹdo ṣe ofin wipe awọn ọmọ ijọ nikan ni wọn le dasi ọrọ oṣelu. A dá eyi ti o dabi ijọ ilu silẹ, a fẹ ki gbogbo eniyan o san owo lati ran awọn alufa lọwọ, a si fun awọn alaṣẹ ilu ni aṣẹ lati tẹ ẹkọ odi rì. Nipa eyi agbara oṣelu wa lọwọ ijọ. Ko pẹ pupọ ti awọn ilana wọnyi jade si abayọri ti a ko le fẹku — inunibini.ANN 130.5

    Ọdun mọkanla lẹyin ti a da ibudo akọkọ silẹ, Roger Williams wa si Ilẹ Tuntun naa. Bi i ti awọn Arinrin-ajo akọkọ, o wá lati wa jẹ igbadun ominira ẹsin; ṣugbọn ni iyatọ si wọn, o ri—ohun ti iwọnba perete awọn eniyan ni akoko rẹ ri—wipe ominira jẹ ẹtọ fun gbogbo eniyan eyi ti a ko le gba kuro, ohunkohun ti wọn i ba a gbagbọ. O jẹ ẹni ti n fi tọkantọkan wa otitọ, o gba pẹlu Robinson wipe ko ṣe e ṣe ki a ti gba gbogbo imọlẹ lati inu ọrọ Ọlọrun tan. Williams “ni ẹni akọkọ ni igba ọlaju Kristẹni lati dá ijọba silẹ lori ikọni ominira ti ẹri ọkan, ati ibadọgba gbogbo igbagbọ niwaju ofin.” O sọ wipe ojuṣe awọn alaṣẹ ilu ni lati dena iwa ọdaran, ṣugbọn ki i ṣe lati ṣe idari ẹri ọkan. O sọ wipe, “Awọn ara ilu tabi awọn alaṣẹ le ṣe pinu lori ohun ti o yẹ eniyan si ara wọn; ṣugbọn nigba ti wọn ba n ṣe akitiyan lati ṣe alaye lori ojuṣe eniyan si Ọlọrun, wọn n kọja aye wọn, ko si le si aabo; nitori pe o han kedere wipe bi alaṣẹ ba ni agbara, o le pa aṣẹ awọn ilana igbagbọ kan loni, ki o tun pa omiran lọla; ati bi a si ti ṣe ri ni England labẹ oriṣiriṣi awọn ọba ati ọbabinrin, ati oriṣiriṣi popu ati igbimọ ninu ijọ Romu; ti o fi jẹ wipe igbagbọ a wa di idarudapọ nla.”ANN 130.6

    A ṣe ofin wipe ki gbogbo eniyan o pejọpọ fun ijọsin bi wọn ko ba fẹ jiya sisan owo itanran tabi itimọle. “Williams tako ofin naa; ofin ti o buru julọ ni England ni eyi ti o kan an nipa fun awọn eniyan lati jọsin ninu ile ijọsin. O ri fifi ipa mu awọn eniyan ti igbagbọ wọn yatọ lati parapọ gẹgẹ bi titẹ ẹtọ wọn loju; lati wọ eniti ko gbagbọ ninu ẹsin, ati ẹni ti ko nifẹ si wa sinu isin tumọ si wipe wọn n fẹ agabagebe. . . . O sọ pe, ‘A ko gbọdọ fi ipa mu ẹnikẹni lati jọsin, tabi ki o ṣe atilẹyin ijọsin kan ni atako si ero ọkan rẹ.’ Awọn alatako kigbe pẹlu iyalẹnu si ikọni rẹ wipe, ‘Kini! ṣe alagbaṣe ko to fun iṣẹ ọya rẹ ni?’ O dahun wipe, ‘Bẹẹni, ṣugbọn fun ẹni ti o ya a.’”ANN 131.1

    Wọn bọwọ fun Roger Wiliams, wọn si fẹran rẹ gẹgẹ bi alufa olootọ, ẹni ti o ni ẹbun ti o ṣọwọn, ti iṣotitọ rẹ kii yẹ, ti o si ni ẹmi aanu tootọ; sibẹ a ko le fi ara da bi o ti fi iduroṣinṣin tako ẹtọ awọn alaṣẹ ilu lati ṣe akoso lori ijọ, ati bi o ti n beere fun ominira ẹsin. Wọn sọ wipe, lilo ikọni tuntun yii yoo “bi ipilẹ ilu ati ijọba orilẹ ede naa wo.” A ṣe idajọ fun wipe ki o kuro ni awọn ibudo naa, ki a ma baa ti i mọle, o salọ nikẹyin ninu otutu ati atẹgun igba yinyin, o lọ sinu igbo kìjikìji.ANN 131.2

    O sọ wipe, “Fun osẹ mẹrinla, a ti mi kaakiri kikankikan ninu akoko kikoro, laimọ ohun ti a n pe ni ounjẹ tabi ibusun.” Ṣugbọn “awọn ẹyẹ oju ọrun fun mi ni ounjẹ ninu aginju,” iho inu igi si jẹ ibugbe fun mi. Bayi ni o ṣe tẹsiwaju ninu irinajo rẹ gba inu yinyin ati igbo ti ko ni ipasẹ kọja titi ti o fi ri aabo pẹlu ẹya awọn Indian kan ti wọn fi ọkan tan an, ti wọn si fẹran rẹ, nigba ti oun n ṣa ipa lati kọ wọn ni awọn otitọ iyinrere.ANN 131.3

    Ni ikẹyin o rin de bebe Narragansett Bay lẹyin ọpọ oṣu ninu irinkiri ati iyipada, nibẹ o ṣe ipilẹ ijọba akọkọ ni akoko ọlaju ti yoo funni ni ominira ẹsin nikikun. Ipilẹ igbagbọ ibudo Roger Williams ni wipe, “gbogbo eniyan ni o yẹ ki o ni ominira lati sin Ọlọrun gẹgẹ bi imọlẹ inu ọkan wọn.” Ipinlẹ kekere rẹ, Rhode Island, di ibi aabo fun awọn ti a n ni lara, o si n pọ si, o si n ṣe rere titi ti igbagbọ ipilẹ rẹ—ominira oṣelu ati ẹsin—fi di okuta igun ile orilẹ ede Amẹrika.ANN 131.4

    Ninu iwe atijọ pataki nì eyi ti awọn baba nla wa gbe kalẹ gẹgẹ bi iwe ẹtọ wọn—Ikede Ominira—wọn sọ wipe: “A gba wipe awọn otitọ wọnyi fi ara han funra wọn, wipe, a da gbogbo eniyan dọgba; wipe Ẹlẹda wọn fun wọn ni awọn ẹtọ kan ti a ko le gba kuro lọwọ wọn; wipe lara wọn ni ẹmi, ominira ati ilepa idunnu wa.” Iwe iṣejọba, ni ọna ti o han kedere julọ fihan wipe a ko gbọdọ fi ipa mu ẹri ọkan eniyan: “A ko nilo ayẹwo ẹsin gẹgẹ bi odiwọn fun ipo ijọba ni United States.” “Ile igbimọ aṣofin ko gbọdọ ṣe ofin lati da ẹsin silẹ tabi lati tako ṣiṣe ẹsin kankan.”ANN 131.5

    “Awọn ti wọn kọ iwe iṣejọba mọ ipilẹ ẹkọ ayeraye nì wipe ibaṣepọ eniyan pẹlu Ọlọrun ga ju ofin eniyan lọ, ati pe a ko le gba awọn ẹtọ rẹ si ẹri ọkan rẹ kuro. A ko nilo ironu lati fi idi otitọ yii mulẹ; a ni imọ rẹ ninu ookan aya wa. Imọlara yii, eyi ti o pe awọn ofin eniyan nija, ni o fun ọpọlọpọ awọn ajẹriku lokun ninu ijiya ati ina. Wọn ri wipe ojuṣe wọn si Ọlọrun ga ju ofin eniyan lọ, ati wipe eniyan ko le lo aṣẹ lori ẹri ọkan wọn. O jẹ ikọni ti a bi ni mọ ti ohunkohun ko le mu kuro.”ANN 131.6

    Bi iroyin ti tan ka awọn orilẹ ede Europe nipa ilẹ kan ti gbogbo eniyan a ti jẹ igbadun eso iṣẹ ọwọ rẹ, ti yoo si ṣe igbọran si ẹri ọkan ara rẹ, ẹgbẹlẹgbẹ ni wọn ṣi lọ si Ilẹ Tuntun naa. Awọn ibudo yara pọ kiakia. “Pẹlu ofin pataki, Massachusetts gba awọn Kristẹni lati orilẹ ede yoo wu ki o ti wa wọle lọfẹ, ti wọn ba sá kọja okun Atlantic lati sa kuro lọwọ ogun tabi ìyàn, tabi inilara awọn oninunibini wọn.’ O tun fun wọn ni iranlọwọ lati inu owo ilu. Bayi ni awọn ti a le kuro ni ilu ati awọn ẹni itẹmọlẹ ṣe di alejo agbajọpọ ilu latari ofin.” Ni aarin ogun ọdun ti a kọkọ tẹdo si Plymouth, ẹgbẹẹgbẹrun awọn arinrin-ajo ni wọn tẹdo si New England.ANN 131.7

    Lati le ri ohun ti wọn n wa, “o tẹ wọn lọrun lati ri onjẹ oojọ ranpẹ jẹ pẹlu igbesi aye wahala ati aini. Wọn ko beere ohunkohun lọwọ ilẹ ayafi èrè iṣẹ wọn, eyi ti o si bojumu. Wọn ko jẹ ki ìran ologo kan o mu imọlẹ atannijẹ kan wa si ọna wọn. . . . Wọn jẹ ki itẹsiwaju agbegbe wọn ti ko yara kankan ṣugbọn ti o n yatọ lojoojumọ o tẹ wọn lọrun. Wọn fi suuru fi ara da aini inu aginju, ti wọn si n bu omi rin igi ominira pẹlu omije ati oogun oju wọn, titi ti o fi fi gbongbo mulẹ.”ANN 132.1

    Wọn gba Bibeli gẹgẹ bi ipilẹ igbagbọ, orisun ọgbọn ati iwe adehun ominira. Wọn n fi tọkantọkan kọ awọn ikọni rẹ ninu ile, ninu ile ẹkọ, ati ninu ijọ, ti awọn eso rẹ si n fi ara han ninu iṣọwona, oye, iwa mimọ, ati iwọntuwọnsi. Eniyan le gbe ni ibudo awọn Puritans fun ọpọ ọdun ki, “o ma ri ọmuti, tabi gbọ ki a bura, tabi ki o pade oníbárà.” A fihan wipe awọn ikọni Bibeli ni aabo ti o dara julọ fun igbega orilẹ ede. Awọn ibudo ti ko lagbara tabi ti wọn danikan wà parapọ lati di ilu alagbara kan, ti o si jẹ iyalẹnu fun araye lati ri alaafia ati ọrọ “ijọ laisi popu, ati ilu laisi ọba.”ANN 132.2

    Ṣugbọn ni igba gbogbo ni ọpọ eniyan n wa si ilẹ Amerika ti erongba wọn yatọ patapata si ti awọn Arinrin-ajo akọkọ. Bi o tilẹ jẹ wipe igbagbọ akọkọ ati iwa mimọ ní ipa ti o pọ, ti o si lagbara, sibẹ ipa rẹ tubọ n kere si ni bi iye awọn ti wọn n wa nitori ọrọ aye nikan ṣe tubọ n pọ si.ANN 132.3

    Ofin ti awọn olutẹdo akọkọ fi lelẹ, wipe awọn ọmọ ijọ nikan ni wọn le dibo tabi di ipo oṣelu mu yọri si iṣẹlẹ ti o buru jai. Wọn ṣe ofin yii lati le jẹ ki ilu o wa ni mimọ, ṣugbọn o fa iwa ibajẹ ninu ijọ. Niwọn igba ti o jẹ wipe jijẹ ọmọ ijọ ni a nilo lati le dibo tabi di ipo ilu mu, ọpọlọpọ ti o jẹ wipe ifẹ aye nikan ṣoṣo ni o wa lọkan wọn, ni wọn darapọ mọ ijọ laisi iyipada ọkan. Bayi ni awọn ti ko ni iyipada ọkan ṣe di pupọ ninu ijọ; ani ninu iṣẹ alufa, ki i ṣe awọn ti igbagbọ wọn ko tọna nikan ni wọn wa nibẹ, ṣugbọn awọn ti wọn ko mọ nipa agbara Ẹmi Mimọ ti n yini pada. Lẹẹkansi, a tun ri ayọrisi buburu ti a saba maa n ri ninu itan ijọ lati akoko Constantine titi di akoko yii, nipa gbigbe ijọ ró nipasẹ iranlọwọ ilu, nipa lilo agbara aye lati ṣe iranlọwọ fun iyinrere Ẹni ti o sọ wipe: “Ijọba Mi ki i ṣe ti aye yii.” Johanu 18:36. Idapọ ijọ pẹlu ijọba, bi o ti wu ki o kere mọ, nigba ti o ba n fihan wipe o n jẹ ki aye sunmọ ijọ, ni tootọ, o n jẹ ki ijọ sunmọ aye ni.ANN 132.4

    Awọn ọmọ wọn gbagbe ẹkọ nla ti Robinson ati Roger Williams fi kọni, wipe otitọ n tẹsiwaju, wipe awọn Kristẹni nilati ṣetan lati gba gbogbo otitọ ti o ba tan si wọn lati inu ọrọ mimọ Ọlọrun. Awọn ijọ Protestant ni Amẹrika,—ati awọn ti wọn wa ni Europe pẹlu,—ti a fi oju rere han fun ni ọpọ yanturu nipa gbigba ibukun iṣẹ Atunṣe, baku lati tẹsiwaju ni oju ọna atunṣe. Bi o tilẹ jẹ wipe awọn olootọ perete dide, lati igba de igba, lati kede otitọ tuntun ati lati ṣe afihan awọn aṣiṣe ti a ti gba fun igba pipe, ọpọlọpọ, bii ti awọn Ju ni akoko Kristi tabi awọn atẹle popu ni akoko Luther, ni itẹlọrun lati gbagbọ bi awọn baba wọn ti gbagbọ, ati lati gbe gẹgẹ bi wọn ti gbe. Nitori naa, ẹsin tun bajẹ di aṣa lasan; ti aṣiṣe ati igbagbọ ninu ohun asan, eyi ti wọn i ba sọ danu bi o ba jẹ wipe ijọ tẹsiwaju lati rin ninu imọlẹ ọrọ Ọlọrun di eyi ti wọn gbagbọ ti wọn tun nifẹsi. Bayii ni ẹmi ti iṣẹ Atunṣe ru soke ṣe rọra ku tan titi ti ijọ Protestant fi nilo atunṣe gẹgẹ bi ijọ Romu ti nilo rẹ ni akoko Luther. Iru ifẹ aye ati orun ẹmi, iru ibọwọ fun ero eniyan, ati fifi imọ eniyan rọpo ikọni Ọlọrun kan naa ni o wa.ANN 132.5

    Bi a ti pin Bibeli kaakiri ni ibẹrẹ ọrundun kọkandinlogun, ati imọlẹ nla ti o tan sinu aye nitori rẹ ko mu itẹsiwaju wa ninu imọ otitọ Ọlọrun, tabi titẹle ohun ti eniyan gbagbọ. Satani kò lè pa ọrọ Ọlọrun mọ wipe ki o ma de ọdọ awọn eniyan gẹgẹ bii ti igba atijọ; o ti wa ni arọwọtọ gbogbo eniyan; ṣugbọn lati le gbe ero inu rẹ jade, ko jẹ ki ọpọ awọn eniyan o kaa si. Awọn eniyan kọ lati wa inu Iwe Mimọ, nipasẹ eyi, wọn tẹsiwaju lati gba itumọ eke, ati lati fẹran awọn ikọni ti ko ni ipilẹ ninu Bibeli.ANN 132.6

    Nigba ti o ri ibaku akitiyan rẹ lati pa otitọ run nipasẹ inunibini, Satani tun pada si ilana ibarẹ aye ti o fa iyapa nla, ti o si fa dida ijọ Romu silẹ. O mi si awọn Kristẹni lati so ara wọn pọ, ki i ṣe pẹlu awọn abọriṣa nisinsinyii, ṣugbọn pẹlu awọn ti wọn fi ara wọn han bi abọriṣa, nipasẹ ifẹ ti wọn ni si ohun aye yii, ti wọn dabi ẹni ti n tẹriba fun ère. Abayọri ibaṣepọ yii buru jọjọ gẹgẹ bi ti igba akọkọ; igberaga ati inakuna n tẹsiwaju o n fi ẹsin boju, awọn ijọ si n dibajẹ. Satani tẹsiwaju lati yi awọn ikọni Bibeli pada, awọn aṣa eniyan ti n pa ọpọlọpọ eniyan run si n fi ẹsẹ mulẹ. Ijọ di awọn ikọni eniyan mu, o tun n gbeja wọn, dipo ki o jà fun “igbagbọ ti a fifun awọn eniyan mimọ lẹẹkan ṣoṣo.” Bayii ni a ṣe ba ipilẹ ẹkọ ti awọn Alatunṣe ṣiṣẹ takuntakun fun ti wọn si jiya nitori rẹ jẹ.ANN 133.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents