Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Ìbáṣepọ̀ Àwọn Ẹ̀mí Ọ̀run

  A ní láti mò ju bí a se mò lo, isé àwon ańgélì. Yóò dára láti rántí pé gbogbo omo Olórun nítòótó ní ìbásepò àwon èmí òrun. Àwon ajagun ìmólè àti agbára tí a kò lè fojú rí, à ma a bá àwon onírèlè okàn rìn, àwon tí ó gbàgbó tí ó sì gba ìlérí Olórun.IIO 258.2

  Kérúbù àti Séráfù àti àwon angeli tí ó yege nínú agbára dúró lápá òtún Olórun, “Gbó àwon èmí ìránsé, a rán won láti jísé fún àwon ajogún ìgbàlà”.-The Acts of Apostles, p. 154.IIO 258.3

  Rántí pé Jésù Olúwa wa ni Olórí òsìsé. Ó bomi rin irúgbìn tí a gbìn, ó fi òrò tí yóò lè yí okàn padà sínú ayé e wa.-Testimonies, Vol. 9, p. 41.IIO 258.4

  Ya ara re sótò pátápátá fún isé Olórun. Òun ni agbára re, yóò sò wa ní owó òtún Rè, yóò ràn ó lówó láti gbé àmì àánú Rè káàkiri (Testimonies, Vol. 9, p. 41).IIO 258.5

  Ogbón òrun yóò sisè pò pèlú àwon òsìsé ayé, àwon tí ó ń wà pèlú ìgbàgbó tí ó dúró gboin nínú ìwà àti ìse. Fún gbogbo àwon tí ó bá darapò láti sisé yìí, Kristi wípé “Mo wà lápá òtún re láti ràn ó lówó”.-Christ’s Object Lessons, p. 332.IIO 258.6

  Bí ìfé ti ènìyàn se darapò mó ìfé ti Olórun, ó di agbára àìlópin. Gbogbo ohun tí a ní láti se nínú àse Rè, yóò se é se nínú agbára. Gbogbo ìdáwólé yóò yorí sí rere. - Christ’s Object Lessons, p. 333.IIO 258.7

  Ní síse isé fún àwon okàn tí ó sègbé, a ní ìbásepò àwon angeli. Egbegbèrún ni ó dúró láti darapò mó àwon omo ìjo wa láti tan ìmólè Olórun tí a fi fún wa, kí àwon ènìyàn lè múra sílè de bíbò Jésù (Testimonies, Vol. 9, p. 129).IIO 259.1

  Nínú isé yìí, gbogbo angélì ni ó setàn láti darapò. Gbogbo ohun èlò òrun wà ní ìkáwó eni tí ó ń sisé láti mú àwon tí ó ti sonù wá ságbo padà. Ańgélì yóò ràn ó lówó láti se ìbápàdé àwon aláìbìkítà àti àwon olókàn líle. Nigbà tí a bá gba ènìyàn bó ságbo inú gbogbo òrun kún fún ayò, Kérúbù àti Séráfù a fowókan ohun èlò orin olókun won tí a fi wúrà se, won á sì korin ògo sí Olórun àti òdó àgùtàn fún àánú àti ìfé rè sí ìran omo ènìyàn.-Christ’s Object Lessons, p. 197.IIO 259.2

  Eni tí ó pe àwon apeja Gálílì, sì ti ń pe àwon ènìyàn fún isé. Ó si setán láti fi agbáran hàn bí ó se fihàn ní ìgbà àwon omo èyìn àkókó. Bí a kó tilè pé, tí a jé elésè, Olórun fé bá wá dòwòpò, láti jé omo isé Krístì. Ó ń pè wá láti wá sí abé ìlànà òrun rè, kí a darapò mó Krístì láti se isé Olórun (The Desire of Ages, p. 297).IIO 259.3

  Ǹ jé o rò pé Krístì mo iye àwon tí ó gbé tokàn-tokàn fun? Ǹ jé o rò pé ó má wá àwon tí ó wà ní ipò tí ó léwu bìi Johanu nítorí isé rè? A má wá àwon olótító rè, a sì má bá won se, a gbà wón níyànjú, á sì má fún won lókun àwon angélì Olórun tí ó tayo nínú agbára ni ó má rán sí won, fún ìrànlówó láti bá àwon tí kò mo òtító sòrò (Testimonies, Vol. 8, p. 17).IIO 259.4

  Gbogbo òrun ni ó ń sisé, àwon angélì Olórun sì ń dúró láti bá àwon òsìsé darapò kí okàn tí Jésù kú fún lè gbó òrò ìyè ti ìgbàlà. Ángélì tí ó bá àwon tí yóò jogún ìyè ǹ so fùn gbogbo àwon ènìyàn mímó tòótó pé “Isé wà fún o láti se”. “Lo, dúró, kí o sì sòrò ìyè fún gbogbo ènìyàn”. Ìse Àwon Àpóstélì 5:20. Tí àwon tí a bá sòrò yìí bá lè tétí sí òrò náà, Olúwa yóò pèsè ònà tí won yóò tò.- Testimonies, pp. 433, 434.IIO 259.5

  Ní irú àkókò yìí, gbogbo omo Olórun gbodò máa sisé láti ran elòmíràn lówó. Bí àwon tí ó ní ìmò Bíbélì se ń tiraka láti wá àwon tí ó ń wá ìmólè lo, angélì Olórun yóò dúró tì wón. Ibi tí angélì bá sì lo kò sí ìdí kan tí a gbodọ̀ fi fòyà láti tèsíwájú. Nípa isé àwon òsìsé tí a yàn, òpòlopò ni yóò fi ìbòrìsà sílè láti máa sin Olórun àyè òhun òtító. Òpòlopò ni yóò dékun àti máa bòwò fún àwon Olórun kékèké inú ayé yìí, yóò sì dúró láìfòyà ní apá ti Olórun ayé àti òfin rè (Prophets and Kings, p. 171).IIO 260.1

  Àwon agbára òrun ń wo ogun tí àwon òsìsé Kristi dojúko. À ń borí ìjà titun, à ń gba èye titun bí àwon Kristeni ti fé àsíá olùrapàdà wón lo láti ja ìjà ìgbàgbó. Gbogbo òrun ni ó wà pèlú eni tí ó ń sisé pèlu ìrèlè okàn, àwon tí ó gbàgbó nínú Olórun bí àwon omo ogun ayé yìí ti ń korin ìyìn, ní àwon akorin òrun ń darapò mó won láti fi ìyìn fún Olrun àti omo Rè (The Acts of Apostles, p. 154).IIO 260.2

  Kìí se agbára tí omo ènìyàn ní ni ó jé kí isé náà jé àseyorí, bíkòse agbára òrun tí ó ń bá omo ènìyàn sisé nínú ogbón ni ó ń mú isé náà jé àseyorí. Páùlù lè gbìn, kí Àpóllò sì máa bomi rin, sùgbón Olórun ni ó ń mú ìsodipúpò wá. Omo ènìyàn kò lè se ipá ti Olórun nínú isé náà. Gégé bí òsìsé ayé, o lè darapò mó wa pèlú ogbón òrun, kí a sì fi ìrèlè sa ipa wa láì gbàgbé pé Olórun ni Òga isé wa. Òṣìṣé lè kú, kí a sì sin-ín, ṣùgbón iṣé rè yóò gbé títí láíláí láti ṣe iṣé náà títí dé òpin (Review and Herald, Nov. 14, 1893).IIO 260.3

  Krìsténì máa ń fi gbogbo ìgbà ní olùrànlówó nínú Olórun, a lè má mo bí Olóuun yóò ṣe ṣe ìrànlówó, ṣùgbón a mo èyí, kò ní dójú ti àwon tí ó gbékè lé E. Krìsténì lè mo iye ìgbà tí Olúwa ti topasè ònà won, kí ìmò òta má le ṣe lé won lórí, won ò ní ma ṣe àso mó, ìgbàgbó won yóò dúró nínú Olórun. Kò sì sí ìdánwò tí yóò lágbára lórí won. Wọn ó mò gégé bí ogbón àti Olùṣedééde won, yóò sì mú wá sí ìmúṣe ohun tí ó fé ṣe pèlú won (Prophets and Kings, p. 576).IIO 261.1

  Gbogbo àwon tí ó ń ṣiṣẹ́ ìhìnrere jé owó ìrànlówó fún Olórun. Wọ́n jé alábàáṣiṣépò àwon angeli, wón jé àwon ènìyàn tí angeli ń lò láti sisé won. Angeli sòrò nípasè ohùn won, wón ṣiṣé nípasè owó won. Àwon òsìsé ènìyàn tí ó ń bá àwon èmí òrun ṣiṣé pò ní ànfààní láti dàgbà nínú èkó àti ìrírí (Education, p. 271).IIO 261.2

  Olorun pe gbogbo ènìyàn láti gbé ìhámóra Olórun wò, kí won ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sisé. “Èmi ni owó òtun re láti ràn ó lówó”. Ni Ó wí. So gbogbo ìdánwò òhun ìṣòro re fún Olórun. Òun kì yóò dà ó. Kò sí ohun tí ó ṣe iyebíye sí Olórun bí ohun tí ó ti ràpadà. Ìjo Rè, àwon òṣìṣé tí ó ń tèsíwájú láti gbin èso òtító. Ronú nípa Jesu, Ó wà ní ibi mímó, kò sì ní dánìkan gbé, ṣùgbon Ó wà láarin àwon egbegbèèrún angeli mímó tí ó ń dúró láti ṣiṣé Rè. Ó sì ń rán wón láti lo ṣiṣé pèlú òjíṣé tí ó ní ìrèwèsì jùlo, tí ó fi ìgbàgbó rè sínú Olórun. Ìrànlówó kan náà ni ó ní fún gbogbo èdá, olówó, tálákà, àwon tí ó ní ìbòwò fún àti àwon tí a rè sílè. —The Southern Watchman, November 7, 1905.IIO 261.3

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents