Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Fífi Sùúrù Dúró De Èrè Ń lá

  Tí ó bá dàbí ẹni pé àkókò náà gùn láti dúró de Olùgbàlà a wa láti dé; tí ìpọ́njú bá terí i wa ba, tí iṣẹ́ náà pin wá lẹ́mì í, tí a kò ní sùúrù fún iṣẹ́ ẹ wa láti parí, kí a sì gba ìdásílẹ̀ ọlọ́lá kúrò nínú ogun náà, ẹ jẹ́ kí a rántí- ẹ sì jẹ́ kí ìrántí yì í dẹ́kun gbogbo kíkùn-wípé Ọlọ́run fi wá sílẹ̀ sínú ayé yì í láti dojúkọ ìjì àti wàhálà, láti dé abala ìwà onígbàgbọ́ tó pé, láti mọ Ọlọ́run sí i dáadáa gẹ́gẹ́ bí i Bàbá a wa àti Kristi Arákùnrin Ẹ̀gbọ́n ọ wa Àgbà, kí a sì ṣiṣẹ́ fún Ọ̀gá Àgbà nípa jíjèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn fún Kristi àti pẹ̀lú ọkàn ìdùnnú kí a ba à lè gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀, “Káàbọ̀, ọmọ ọ̀dọ̀ rere, bọ́ sínú ayọ̀ Olúwa Ọlọ́run-ùn rẹ.- Review and Herald, Oct.25, 1881.IIO 275.1

  Ẹ̀yin jagunjagun onígbàgbọ́, ẹ mú sùúrù. Láìpẹ́ jọjọ, Ẹni tí yóò wá, yóò wá. Àṣálẹ́ ẹ dídúró tàárẹ̀ tàárẹ̀ ní ṣíṣọ́nà òhun ìbànújẹ́ fẹ́rẹ̀ dópin. A yóò gba èrè náà láìpẹ́, òórọ̀ ayérayé fẹ́rẹ̀ ẹ́ dé. Kò sí ààyè fún oorun sísùn báyìí- kò sí àkókò láti má a kábámọ̀ tí kò wúlò. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń tòògbé báyìí yóò pàdánù ọ̀pọ̀lọpọ̀ ànfààní láti ṣe rere. A fún wa ní ànfààní ìbùkún láti ru ìtí nínú ìkórè ń lá náà; àti ọkàn kọ̀ọ̀kan tí a gbàlà ni yóò jẹ́ àfikún ìràwọ̀ lórí adé e Jésù, Olùràpadà a wa ọ̀wọ́n tí a júbà. Ta ni ẹni náà tí ó fẹ́ bọ́ àhámọ́ ogun sílẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ wípé ìgbìyànjú díẹ̀ ló kù tí yóò fi ṣetán tí yóò sì fi gba ìṣẹ́gun titun tí yóò sì gba ife ẹ̀yẹ fún ayérayé? - Review and Herald; Oct.25, 1881. IIO 275.2

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents