Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Ìsọji Àti Àtunṣe Ni a Nílò

  Àwọn onígbàgbọ́ gbọdọ̀ múra sílẹ̀ fún ohun tí ó ń bọ̀ wá ṣẹ lórí ayé gẹ́gẹ́ bí ìyanu tí ó muni lómi fún ìmúra sílẹ̀ yìí wọ́n gbọdọ̀ fi pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́ kékọ̀ ọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọn sì gbìyànjú láti jẹ́ kí ayé wọn wà nì ìbámu pẹ̀lú àwọn àṣẹ rẹ̀....Ọlọ́run ń pè fún ìsọjí àti àtúnṣe.-Prophets and Kings, p.626.IIO 41.3

  Ìsọjí ti ìwà bí Ọlọ́run tòótọ́ wa ni ó tóbi tí ó sì ṣe pàtàkì.Láti wá èyí gbọdọ̀ jẹ́ iṣẹ́ ẹ wa àkọ́kọ́.-Review and Herald, March, 22, 1887.IIO 41.4

  Àsìkò ti tó fún ìsọjí tòótọ́ láti ṣẹlẹ̀. Nígbà tí ìsọjí yì í bá bẹ̀rẹ̀, ẹ̀mí àdúrà yóò mú onígbàgbọ́ kọ̀ọ̀kan, tí yóò sì lé ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ àti ìjà kúrò nínú ìjọ.-Testimonies, vol.8, p.251.IIO 42.1

  Ìsọjí àti àtúnṣe gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ìṣàkóso ti ẹ̀mí mímọ́,ìsọjí àti àtúnṣe jẹ́ oríṣi n ǹkan méjì, ìsọjí túmọ̀ sí ìsọdọ̀tun ti ìgbé ayé nínú ẹ̀mí,ìsọ agbára ti ọkàn àti ẹ̀mí di ọtun, àjíǹde kúrò nínú ikú nípa ti ẹ̀mí. Àtúnṣe dúró fún àtúntò, ìpààrọ̀ nínú èrò àti àwọn èrò orí, àwọn ìwà àti àwọn ìṣe, Àtúnṣe kò lè mú èso òdòdò dára dára wá àyàfi tí a bá so ó pọ̀ mọ́ ìsọjí ti ẹ̀mí.Ìsọjí àti àtúnṣe ní láti ṣe iṣẹ́ tí a yàn wọ́n àti nínú ṣíṣe iṣẹ́ yì í wọ́n gbọdọ̀ dàpọ̀ mọ́ra.-Reẹiew and Herald, Feb.25,1902.IIO 42.2

  Ìwé mímọ́ kò a pè fún iṣẹ́ mímọ́ ju èyí tí a ń rí yìí lọ?...Ọlọrun n pe awọn ti wọn fẹ ki ẹmi mimọ dari i wọn ninu iṣẹ ayipada tò jinlẹ̀. Mo rí rògbòdìyàn yì í níwájú u wa, Ọlọ́run sì ń pe àwọn alágbàṣe láti wá. Nísinsinyìí ọkàn kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ dúró ní ipò ti jínlẹ, tí ó sì jẹ́ òótọ́ nínú u fífi ara ẹni jì fún Ọlọ́run ju bí àwọn ọdún tí a ti lò sẹ́yin lọ....Orí ì mí wú nípa àwọn ìran tí ó kọjá níwájú ù mi ní òru, ó dàbí ìṣípò padà ń lá-iṣẹ́ ti ìṣọjí- ń lọ síwájú ní ibi púpọ̀.Àwọn ènìyàn wa sì ń rin lọ lọ́wọ̀ọ̀wọ́, wọ́n ń dáhùn sí ìpè Ọlọ́run.- General Conference Bulletin, May 19,1913, p.34.IIO 42.3

  Nínú àwọn ìran ti òru, àwọn àwòrán kọjá níwájú ù mi nípa ìrìn àwọn alátúnṣe láarin àwọn ènìyàn Ọlọ́run. ọ̀pọ̀ ló sì ń yin Ọlọ́run. Àwọn aláìsàn rí ìwòsàn, àwọn iṣẹ́ ìyanu mìíràn sì ṣẹlẹ̀ Ọgọọ́gọ̀rún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn ni wọ́n rí tí wọ́n ń bẹ àwọn ìdílé wò, tí a sì ṣí ìwe mímọ́ kalẹ̀ níwáju u wọn. Àwọn ọkàn ni a dá lẹ́bi nípa agbára ti ẹ̀mí mímọ́, àti pé ẹ̀mí àtúnbí tòótọ́ sì farahàn. Ní ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan, àwọn ilẹ̀kùn ṣí sílẹ̀ fún pípolongo ti òtítọ́, ipa ìmọ́lẹ̀ ọ̀run sì dàbí i pé ó mọ́lẹ̀ sí ayé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún ni àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ọlọ́run àti onírẹ̀lẹ̀ rí gbà.-Testimonies,vol.9, p.126.IIO 42.4

  Ọ̀rànanyàn ń lá wà fún àtúnṣe láarin àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Ipò tí ìjọ wà mú wọn lọ ṣe ìwádìí, Ǹ jẹ́ èyin jẹ́ aṣojú u rẹ̀ tòótọ́ ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ fún wa?-Testimonies, vol.3,p.474.IIO 43.1

  Nígbà tí ẹ̀gàn ti ìmẹ́lẹ́ àti ìlọ́ra yóò di mínú kúrò nínú ìjọ, Ẹ̀mí Olúwa yóò farahàn. Agbára Ọ̀run yóò sì di ìfihàn. Ìjọ yóò rí ìpèsè iṣẹ́ ti Oluwa àwọn ọmọ ogun.Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ yóò tán pẹ̀lú ìtàsán tí ó lágbára, gẹ́gẹ́ bí i ti ìgbà àwọn àpóstélì, ọ̀pọ̀ ọkàn ni yóò sì yípadà kúrò nínú ìṣìnà sí òtítọ́. Ilé ayé yóò sì mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ògo ti Olúwa. Testimonies,vol.9, p.46.IIO 43.2

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents