Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Àkójọpọ̀ Ipá Àwọn Àtẹ̀lé e Krístì.

  Ará l’ọ́kùnrin àti l’óbìnrin nínú ìgbàgbọ́, ǹ jẹ́ ìbéèrè yìí ń gbé yin nínú “Ǹ jẹ́ èmi jẹ́ olùtójú arákùnrin mi bí? Tí o bá pe ara rẹ ní oọmọo OỌloọ́run; o jẹ́ olùtọ́jú arákùnrin rẹe, Oọloọ́run yóò sì béèrè eẹ̀mí àwọon tí ó yẹe kí o gbàlà ní oọwoọ́ àwọon ìjọo.-Historical sketches, p. 291.IIO 13.4

  Olùgbàlà ti fi ẹ̀mí rẹ̀ iyebíye lẹ́lẹ̀ làti lè gbé ìjọ tí ó kún ojú òsùwon kalẹ̀ láti máa bomirin ọkàn tì a pọ́n lójú àti àwọn tí a ń dánwò.Àkójọpọ̀ onígbàgbọ́ le è má lọ́lá, tàbí jẹ́ púrúǹtù, tàbí ẹni tí kò gbajúmọ̀, ṣùgbọ́n nínú u Krístì, wọ́n lè ṣe iṣẹ́ nínú ilé e wọn, láarin àwùjọ àti pàápàá jùlọ ní ẹlẹ́kùn jẹkùn, tí àyọrísíi rẹ yóó fẹ́rẹ̀ ga dé ọ̀run. The Ministry of Healing, p.106.IIO 13.5

  Bí ó tilẹ̀ lè rí bí aláìpé àti aláìlera, ìjọ jẹ́ ohun kan lára eyi ti Ọlọ́run bu ọlá fún ní àrà ọ̀tọ̀ ,ó jẹ́ bí orí ìtàgé tí a ti ń ṣe àfiwè oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ nínú èyí tí ó ní inú dídùn láti ṣe àfihàn agbára rẹ̀ ní yíyí àwọn ọkàn padà.-The Acts of the Apostles.p.12.IIO 13.6

  Ẹnìkan ló ní láti mú iṣẹ́ Krístì ṣẹ, ẹnìkan ni ó níláti gbé iṣẹ́ tí Krístì bẹ̀rẹ̀ lárugẹ, a sì ti fi ànfààní yìí fún ìjọ.Fún ìdí Pàtàkì tí a fi dá wọn sílẹ̀. Kí ń wá ló dé tí àwa ọmọ ìjọ kò ti fíì gba ànfààní yìí?-Testimonies, vol.6p.295.IIO 14.1

  Ó pe ìjọ láti jí gììrì sí iṣẹ́ tí a pè wọ́n sí nípa dídúró lórí i gbèdéke tí ó ní ìsọdọ̀tun ní agbègbè e wọn, kí o sì fi àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ní ìkọ́ni àti ìrìrì láti tẹ̀ síwájú sí àwọn ibití ìhìnrere kò tíì dé.-Testimonies, vol.6 p.292IIO 14.2

  Àwọn Onígbàgbọ́ ọ Tẹsalóníkà jẹ́ ajíhìnrere tòótọ́, wọ́n jèrè ọkàn wọn nípa òtítọ́ tí a fi hàn wọ́n, a sì jèrè ọkàn kún iye àwọn tí ó gbàgbọ́-The Acts of the Apostles, p.256.IIO 14.3

  Níbi ìgbọ́wọ́ lé lórí àwọn méjìlá ni ìgbésè àkọ́kọ́ ti ṣẹlẹ̀ nínú ìdájọ sílẹ̀ pé nígbà tí Krístì bá kùrò tán iṣẹ́ e rẹ̀ yóò tẹ̀ síwájú ní ayé-The Acts of the Apostles, p.18.IIO 14.4

  Ìjọ Ọlọ́run jẹ́ bí i gbọ̀ngàn ìgbé ayé mímọ́ tí ó kún fún oníruurú ẹ̀bùn tí ó ti ọwọ́ ẹ̀mí mímọ́ wá. Àwọn ọmọ ìjọ gbọdọ̀ ní inù dídùn nínú ìdùnnù àwọn tí a ràn lọ́wọ́ tí a sì bùkún. Ìyanu ni iṣẹ́ tí Ọloọ́run gbé lé ìjọ rẹ̀ lọ́wọ́ làti parí àti kí orúkọ rẹ̀ leè di gbígbé ga.-Acts pp.12-13.IIO 14.5

  A ti ṣe àgbékalẹ̀ iṣẹ́ ẹ wa nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Onígbàgbọ́ gbọdọ̀ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ e rẹ̀, ìjọ sí ìjo, ènìyàn bí ohun èlò kí ó wà ní ìjọ̀wọ̀ ara ẹni sí ìsàkóso ẹ̀mí mímọ́, kí gbogbo wọn sì parapọ̀ láti fún ayé ní ìròyìn ayọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlórun.-General Conference Bulletin, Feb,28,1893,p.421.IIO 14.6

  Àwọn ìjọ gbọdọ̀ fọwọ́sowọ́pọ̀ ninu iṣẹ́ oko ríro ti ẹ̀mí nírètí láti kórè rẹ̀ nígbà tí ó bá yá… ilẹ̀ lè nira láti kọ, a kò gbọdọ̀ káárẹ̀ láti kọ ibi tí a kò tí ì kọ rí, a kò gbọdọ̀ ṣaláì má fúrúgbìn òdodo. Ẹ máṣe dára dúró, olùkọ́ tí Ọlọ́run fẹ́ràn,bí ìgbà tí ẹ̀ ń ṣe iyèméjì lórí bóyá iṣẹ́ wà yóò dàgbàsókè bí a ṣe ṣe é-Testimonies; vol.6, p.420.IIO 14.7

  Ìjọ Ọlọ́run jẹ́ aṣojú tí a ti yàn fún ìgbàlà ènìyàn. A ṣètò o rẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ sì ni láti mú ìhìnrere lọ sí gbogbo ayé. Láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀epẹ̀e ni Ọloọ́run ti ṣètò pé nípasẹ̀ ìjọ rẹ̀ ni a ó ṣe fi ẹ̀kún Ọlórun kún aráyé. Ọmọ ìjọ tí a ti pè jáde láti inú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu gbọdọ̀ fi ògo Ọlọ́run hàn-The Acts of the Apostles, p.9.IIO 15.1

  Kí ìjọ máṣe fi ojú kíkéré wo ara a rẹ̀ ní ní ipa àti ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn nínú iṣẹ́ ń lá ti àkókò yìí.IIO 15.2

  Ará, ẹ lọ sí ibi iṣẹ́, kìí ṣe nínú ìpàdé àgó ń lá tàbí àpéjọpọ̀ àti ìgbìmọ̀ nìkan ni a ti lè rí àkànṣe ojú rere Ọlọ́run, akitiyan wa pẹ̀lú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ láì sí ìmọ̀ t’ara ẹni nìkan ni á yóò dé ládé pẹ̀lú ìbùkún un rẹ̀, ṣa ipá tìrẹ, Ọlọ́run yóò sì fi kún ipa à rẹ- Review and Herald, March 13, 1888. IIO 15.3

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents