Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Ìbáṣepọ̀ pẹ́kí pẹ́kí i Ti Ọlọ́danni

  A nílò láti súnmọ́ àwọn ènìyàn nípa ìgbìyànjú ẹnìkọ̀ọ̀kan. Tí a bá fi àsìkò díẹ̀ fún ìwáásù, tí a sì lo ọ̀pọ̀ àsìkò nínú ìwáásù àtilé dé ilé, àyọrísí tí ó pọ̀ ni a máa rí.- The Ministry of Healing, p.143.IIO 117.1

  Oluwa nífẹ̀ ẹ́ sí kí a mú ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ ẹ RẸ̀ wá fún ọkàn kọ̀ọ̀kan. Dé ìpele kan a gbọdọ̀ ṣe àṣeparí eléyìí nípa iṣẹ́ ọlọ́danni. Eléyìí jẹ́ ìlànà a ti Krísti.- Christ’s Objẹct Lessons, p.229.IIO 117.2

  Gbogbo àwọn tí wọ́n ń ṣe àṣeyọrí jùlọ nínú ìjèrè- ọkàn jẹ́ ọkùnrin àti obìnrin tí wọn kò gbé ara a wọn ga lórí agbára a wọn, ṣùgbọ́n ẹni nínú ìrẹ̀lẹ̀ àti ìgbàgbọ́ ọ wa láti ran àwọn tí ó wà nípa wọn lọ́wọ́. Jesu ṣe iṣẹ́ yìí. Ó súnmọ́ àwọn tí ọkàn-an RẸ̀ fẹ́ láti dé ọ̀dọ̀ ọ wọn.- Gospel workers, p.194.IIO 117.3

  Nínú ìkáánú bí i ti Krístì a gbọdọ̀ súnmọ́ àwọn ènìyàn ní ẹnìkọ̀ọ̀kan, kí a sì wá láti sọ ìfẹ́ ẹ wọn jí sí ohun ń lá a ti ìyè àìnípẹ̀kun. Àwọn ọkàn-an wọn lè le koko bí i opopo ọna, ó lè dabi ìgbìyànjú ofo láti fi Olùgbàlà hàn wọ́n; Ṣùgbọ́n nígbà tí ọgbọ́n atinuda bá kọ̀ láti mú ìtẹ̀síwájú wá, tí àríyànjíyàn sì kọ̀ láti mú ìyípadà ọkàn wá, ìfẹ́ ẹ Krístì náà fihàn nínú ìwàásù àtilé dé ilé, lè sọ ọkàn òkúta di rírọ̀, kí irúgbìn òtítọ́ kí ó lè ní gbòǹgbò.- Christ’s Object Lessons, p.57.IIO 117.4

  Ẹ dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ó wà ní àyíká a yín nípa iṣẹ́ àdáṣe. Ẹ jẹ́ ojúlùmọ̀ pẹ̀lú u wọn.Ìwáásù kò ní ṣiṣẹ́ tí a ní láti ṣe. Ańgẹ́lì Ọlọrun wà pẹ̀lú ù rẹ ní àwọn ìbùgbé àwọn tí o ṣàbẹ̀wò sí. Iṣẹ́ yìí kò ṣe é ṣe pẹ̀lú ìdúró fún. Owó tí a yá ni tàbi tí a fún ni kò le è parí i rẹ̀. Àwọn ìwàásù kò le ṣe é. Nípa bìbẹ ènìyàn wò, ọ̀rọ̀ sísọ, gbígbàdúrà, ìbánikẹ́dùn pẹlú u wọn, ó lè jèrè àwọn ọkàn-an wọn. Èyí ni iṣẹ́ ajíhìnrere tí ó ga jù lọ tí o lè ṣe. Láti ṣe é, ìwọ yóò nílò ìpinnu, ìgbàgbọ́ tí ó ní ìfaradà, sùúrù tí kì í ṣàárẹ̀, àti ìfẹ́ tí ó jinlẹ̀ fún àwọn ọkàn.- Testimonies, vol.9, p.41.IIO 118.1

  Nípa ìpè e ti Jòhánù àti Ańdérù àti Símíònì, ti Fílípì àti Nàtáníẹ̀lì, bẹ̀rẹ̀ ìpìlẹ̀ ní ti ìjọ onígbàgbọ́. Jòhánù darí àwọn àtẹ̀lé e rẹ̀ méjì sí Kristi. Ọ̀kan lára a wọn ni, Ańdérù, rí arákùnrin-in rẹ̀, ó sì pè é fún Olùgbàlà. Lẹ́hìn náà, wọ́n pe Fílípì, ó sì lọ láti wá Nàtáníẹ̀lì.Àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí gbọdọ̀ kọ́ wa ní pàtàkì ìgbìyànjú ọlọ́danni, nípa pípàrọwà fún àwọn ìbátan a wa, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ wa àti àwọn aládúgbò o wa. Àwọn mìíràn wà tí ó jẹ́ pé nínú ìgbé ayé e wọn ti jẹ́wọ́ láti jẹ́ ojúlùmọ̀ pẹ̀lú u Kristi, síbẹ̀ tí wọn kò tíì ṣe ìgbìyànjú Kankan láti mú ọkàn kan ó kéré tán wá fún Olùgbàlà. Wọ́n fi gbogbo iṣẹ́ náà fún òjíṣẹ́ Ọlọrun. Ó lè jẹ́ ẹni àmúyẹ fún ìpè e rẹ̀, ṣùgbọ́n kò lè ṣe èyí tí Krístì fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ìjọ.IIO 118.2

  Àwọn mìíràn wà tí wọ́n nílò iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ìfẹ́ ọkàn onígbàgbọ́. Ọ̀pọ̀ ló ti lọ láti pa àwọn tí ó yẹ kí a gbàlà run, tí àwọn aládúgbò o wọn, àwọn ọkùnrin àti obìnrin lásan bá lè lọ pẹ̀lú ìgbìyànjú u wọn fún wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń dúró láti lè bá wọn ṣọ̀rọ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Nínú ìdílé, ní àdúgbò, ní ìlú tí à ń gbé, iṣẹ́ wà fún wa láti ṣe bí àwọn ajíhìnrere fún Kristi. Tí a bá jẹ́ onígbàgbọ́, iṣẹ́ yìí yóò jẹ́ adùn fún wa. Kò sí ọkàn tí a yípadà láìpẹ́ ju ẹni tí a bí nínú ìfẹ́ ẹ rẹ̀ láti mú kí àwọn mìíràn mọ ọ̀rẹ́ iyebíye tí ó rí nínú u Jesu.A kò le è dí ìgbàlà àti òtítọ́ tí a ti sọ di mímọ́ mọ́ ọkàn-an rẹ̀.- The Desire of Ages, p. 141.IIO 118.3

  Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí ó ní èso rere jù tí a fi lè fi ìmọ́lẹ̀ fúnni ni nípa ìgbìyànjú ọlọ́dànni. Ní àyíká ilé, ní ẹ̀bá iná, ní etí ibùsùn aláìsàn, ní ọ̀nà tí kò pariwo o lè ka ìwé mímọ́ kí o sì sọ ọ̀rọ̀ ọ Jesu àti òtítọ́ náà. Nípa báyìí, o le è gbin èso iyebíye tí yóò hù jáde tí yóò sì so èso.-Testimonies, vol.6, pp.428, 429.IIO 118.4

  Iyọ̀ gbọdọ̀ darapọ̀ mọ́ ohun tí a dà á mọ́; ó gbọdọ̀ wọ inu kí ó sì yòrò kí ó tó lè dènà ìdibàjẹ́. Báyìí, nípa ìbápàdé lẹ́nìkọ̀ọ̀kan àti ìbákẹ́gbẹ́ ni a fi ń dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn nípa agbára ìgbàlà àti ìhìnrere. A kò gbà wọ́n là ní kíkópọ̀, ṣùgbọ́n bí ẹnìkọ̀ọ̀kan. Ipa ẹnìkọ̀ọ̀kan jẹ́ agbára. A gbọdọ̀ súnmọ́ àwọn tí a bá fẹ́ láti ṣe ní rere.- Thought from the Mount of Blessings, p.59.IIO 119.1

  Jesu rí i nínú àwọn ọkàn tí a ní láti fún ní ìpè ìjọba ọ̀run. Ó dé ọ̀dọ̀ àwọn ọkàn ènìyàn nípa lílọ sí àarin wọn bí ẹni tí ó nífẹ̀ ẹ́ sí rere e wọn. Ó wá wọn kiri ní àwọn òpópónà, ní abẹ́lẹ́ ní àwọn ilé, nínú àwọn ọkọ̀ ojú omi, nínú ilé ìjọsìn, ní àwọn etí i bèbè òkun, àti níbi àsè ìgbeyàwó. Ó bá wọn pàdé níbi àwọn, iṣẹ́ òòjọ́ ọ wọn, Ó sì ṣàfihàn nípa níní ìfẹ́ sí àwọn ohun ti ayé e wọn. Ó gbé ikọni i RẸ̀ lọ sí àwọn ìdílé, mímú àwọn ìdílé nínú ilé e wọn sí abẹ́ ipá àti ìfarahàn-an ọ̀run-un RẸ̀. Ìkáánú u RẸ̀ tí ó lágbára ràn-Án lọ́wọ́ láti jèrè àwọn ọkàn. - The Desire of Ages, p.151.IIO 119.2

  Ìlànà Kristi nìkan lè mú àṣeyọrí tòótọ́ wá nínú u dídé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn. Olùgbàlà darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn bí ẹnìkan tí ó nífẹ̀ ẹ́ sí rere e wọn. O fi ìbánikẹ́dùn un RẸ̀ fún wọn, Ó bá àìní i wọn pàdé, Ó sì jèrè ìgbẹ́kẹ̀lé e wọn. Ó pàṣẹ fún wọn, “Tẹ̀lé mi”. - The Ministry of Healing, p.143.IIO 119.3

  A gbọdọ̀ ṣe bí Kristi ti ṣe. Níbikíbi tí Ó bá wà, nínú gbọ̀gàn ìjọ, ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, nínú ọkọ̀ ojú omi tí ó gúnlẹ̀ ní orí ilẹ̀, níbi àpèjẹ̀ àwọn Farisí tàbí ní orí i tábìlì àwọn agbowó òde, Ó sọ nípa àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ ìgbé ayé gíga. Àwọn ohun ti ìwà ẹ̀dá, àwọn ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ìgbé ayé e wọn ojoojúmọ́, ni a kópọ̀ nípa a RẸ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́. Ọkàn àwọn olùgbọ́ ọ̀rọ̀ ọ RẸ̀ sì fà sí i; nítorí pé Ó ti wo àrùn-un wọn sàn, ó ti tu àwọn oníròbìnújẹ́ nínú, Ó sì ti gbé àwọn ọmọ kékeré e wọn sí apá a RẸ̀ tí ó sì súre fún wọn. Nígbà tí ó la ẹnu u RẸ̀ láti sọ̀rọ̀, wọ́n fetísílẹ̀ sí i, àti pé gbogbo ọ̀rọ̀ ọ RẸ̀ dàbí adùn ayé sínú ìyè ní ọkàn àwọn mìíràn. IIO 119.4

  Bákan náà o gbọdọ̀ wà pẹ̀lú u wa. Níbikíbi tí a bá wà, a gbọdọ̀ wá ànfààní láti sọ̀rọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn nípa Olùgbàlà. Tí a bá tẹ̀lé àpẹẹrẹ Kristi nínú u rere ṣíṣe, àwọn ọkàn á ṣí ṣílẹ̀ bí wọ́n ṣe ṣe fún-Un.kì í ṣe ní ṣìnkún ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọgbọ́n tí a bí pẹ̀lú ìfẹ́ àtòkè wá, a le è sọ fún wọn nípa a RẸ̀ ẹni tí ó jẹ́ “olórí pàtàkì láarin ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá,” àti ẹnìkan “lápapọ̀ ni ó nífẹ̀ ẹ́.” Èyí ni iṣẹ́ tí ó ga jùlọ tí a le lo ẹ̀bun ọ̀rọ̀ sísọ fún. A fi fún wa láti lè fi Kristi hàn bí Olùgbàlà tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni.- Christ’s Object Lessons, pp.338, 339.IIO 120.1

  Ìfarahàn-an RẸ̀ mú àyíká tí ó mọ́ jù sínú ilé, àti ìgbé ayé e RẸ̀ jẹ́ bí ìwúkàrà tí ó ń ṣiṣẹ́ láarin àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ohun kan ní àwujọ ọ wa. Láìní ìpalára àti láì lábàwọ́n, Ó rìn láarin àwọn tí kò nírònú, àwọn agbéraga, àwọn tí kò ní inú rere; láarin àwọn aláì ṣòótọ́, àwọn agbowó òde, àwọn onínákúnàá tí kò bìkítà, àwọn aláìgbàgbọ́ ọ Samáríà, àwọn ọmọ ogun kèfèrí, àwọn àgbẹ̀ pálapàla, àti onírúurú ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ó sọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn níbi àti ọ̀rọ̀ lọ́hùn-ún, (Correct) bí ó ṣe rí àwọn ènìyàn tí àárẹ̀ mú, síbẹ̀ Ó ń fi agbára mú láti ru àwọn ẹrù wúwo. Ó pín nínú àwọn ìṣoro o wọn, Ó sì ṣe àwí-tún-wí àwọn ẹ̀kọ́ tí Ó ti kọ́ láti ara ìṣẹ̀dá, ní ti ìfẹ́, ti àánú àti ìṣoore ti Ọlọ́run.IIO 120.2

  Ó kọ́ wọn láti rí ara a wọn bí ẹni tí a fi àwọn tálẹ́ǹtì iyebíye fún, tí ó jẹ́ pé tí wọ́n bá lò ó dáa dáa yóò fi ọrọ́ ti ọ̀run pamọ́ fún wọn. Ó tu koríko ohun asán kúrò nínú ayé e wọn àti nípa àpẹẹrẹ ẹ RẸ̀ kọ́ wọn pé ìṣẹ́jú kan nínú àsìkò jẹ́ ìbẹ̀rù pẹ̀lú àwọn èrè ayérayé; pé kí ó ṣọ̀wọ́n bí ìṣúra, kí wọn sì fi ṣiṣẹ́ fún ohun mímọ́.IIO 120.3

  Kò kọjá lára àwọn mìíràn bí aláìyẹ, ṣùgbọ́n Ó wá láti le ṣe àtúnṣe ìgbàlà fún ọkàn kọ̀ọ̀kan. Nínú ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ tí Ó bá ara a RẸ̀, Ó ń fi ẹ̀kọ́ tí ó bá àsìkò o wọn mu àti ohun ṣíṣe e wọn. Ó wá láti mú lókun pẹ̀lú ìrètí fún àwọn pálapàla àti àì nírètí, tí ó fi ìdánilójú fún wọn pé wọ́n lè jẹ́ aláì lẹ́bi àti aláìní palára, tí wọ́n bá ti ní irú ìwà yìí tí yóò fi wọ́n hàn bí ọmọ Ọlọ́run.Ní ọ̀pọ̀ ìgbà Ó pàdé àwọn tí wọ́n wà ní abẹ́ ète àti ìṣàkóso Sátánì pàdé, àti àwọn tí wọn kò lágbára láti já okùn ìdè e rẹ̀. Sí irú àwọn wọ̀nyí, àwọn tí ìrẹ̀wẹsì dé bá, aláàárẹ̀, àwọn tí a dán wò, àti àwọn tí wọ́n ṣubú. Jesu yóò sọ ọ̀rọ̀ àánú ní pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n nilò tí ó sì yé wọn. Ó bá àwọn mìíràn níbi tí wọ́n ti ń ja ìjà ọwọ́ pẹ̀lú ọ̀tá a ti ẹ̀mí.Àwọn wọ̀nyí ni ó gbà níyànjú láti ní ìforítì, tí ó sì fì dá wọn lójú pé wọn yóò ṣẹ́gun; nítorí pé àwọn ángẹ́lì ọ̀run wà ní ìhà a tiwọn, wọn yóò sì fún wọn ní ìṣẹ́gun.- The Desire of Ages, p.90.IIO 120.4

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents