Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Iṣẹ́ Inú Ilé Ẹ̀kọ́

    A gbọdọ̀ dá àwọn ilé oúnjẹ títà fún ètò ìlera àti yàrá tí a ti lè ṣe ìtọ́jú aláìsàn sílẹ̀. A gbọdọ̀ fi kún àwọn ìgbìyànjú u wa ní ọ̀nà tí a yóò fi ṣe àfikún-un pípèjọ ní etí òkun sí i. Gẹ́gẹ́ bí ohùn Jòánù Onítẹ̀bọmi tí a gbọ́ ní aginjù , “Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe”, bákan náà a gbọdọ̀ gbọ́ ohùn àwọn ìránṣẹ́ ẹ RẸ̀ ní ojú ọ̀nà ìrìn-àjò àti ìpéjọ ní etí òkun.- Testimonies, vol.7, pp.55,56.IIO 138.1

    A ti fi ìmọ́lẹ̀ yìí hàn mí pé ó yẹ kí ilé oúnjẹ dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn yàrá tí a ti ń tọ́jú aláìsàn. Awọn méjèèjì le è fowọ́sowọ́pọ̀ láti ṣe àtìlẹhìn fún àwọn ìpìlẹ̀ tí ó tọ́. Nínú ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn yìí, ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó yẹ ní ṣíṣe láti ní àwọn yàrá tí yóò dúró bíi ibi tí a le fi aláìsàn wọ̀ sí. Àwọn ìfilẹ́lẹ̀ yìí yóò dúró bíi olùbọ́ sí àwọn ibùgbé àwọn aláìsàn tí ó wà káàkiri orílẹ̀-èdè.- Testimonies, vol.7, p.60.IIO 138.2

    Ọlọ́run ní iṣẹ́ fún àwọn ìlú ń lá ń lá, iṣẹ́ náà ni kí á polongo nínú àwọn ìpàdé àgọ́ ọ wa, àti nípa igbiyanju u wa fún gbogbo ènìyàn, àti nípasẹ̀ àwọn ìwé àtẹ̀jáde e wa. Ní àfikún sí eléyìí, a ní láti fi ilé ounjẹ ti ètò ìmọ́tótó lélẹ̀ ní àwọn ilu ń lá ń lá, nípasẹ̀ ẹ wọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti ìwọ̀n-tu-wọ̀n-sì ni a yóò le è polongo. A gbọdọ̀ ṣètò bí a ṣe le ṣe àwọn ìpàdé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ilé ounjẹ títà a wa. Tí ó bá ṣe é ṣe nígbà kúùgbà, kí a pèsè yàrá níbi tí a yóò ti pe aláfẹ̀hìntì láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ẹ ti ètò ìlera àti ìwọ̀n-tun-wọ̀n-sì onígbàgbọ́, níbi tí wọ́n yóò ti ní ìmọ̀ lórí bí a ṣe le è pèsè oúnjẹ tí ó péye, àti àwọn àkòrí mìíràn tí ó ṣe pàtàkì. - Testimonies, vol.7, p.115.IIO 138.3

    A gbọdọ̀ fún àwọn tí wọ́n bá wá sí ilé ìtaja ounjẹ́ ẹ wa ní àwọn iwe kika. A gbọdọ pe àkíyèsí i wọn sí àwọn ìwé lórí ìwọ̀n-tun-wọ̀n-sì ati iṣé àtúnṣe sí àwọn ounjẹ tí à ń fún ni, àti àwọn ìwé pélébé pélébé tí ó sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀kọ́ ọ Kristi ni a ní láti fún wọn bákan náà.Pínpín áwọn iwe kika yìí gbọdọ̀ jẹ́ ẹrù tí gbogbo àwọn ènìyàn-an wa yóò rù. Agbọdọ̀ fún gbogbo ẹni tí ó wa ni ohun kan láti kà. Ọpọlọpọ le è fi awọn iwe ìléwọ́ yìí sílẹ̀ láì kà, ṣùgbọ́n lára àwọn tí o fi iwe yìí lé lọ́wọ́ lè má a wá ìmọ́lẹ̀ nínú u rẹ̀. Wọn yóò kà á wọn yóò sì ṣàṣàrò lórí ohun tí o fún wọn, wọn yóò sì tún fi fún àwọn mìíràn.- Testimonies, vol.7, p.116.IIO 138.4

    A ti fún mi ní ìmọ̀ pé ọ̀kan lára ìdí pàtàkì tí ìmọ́tótó ilé àwọn ìtaja ounjẹ àti yàrá ibi tí a ti ń tọ́jú aláìsàn ṣe gbọdọ̀ wà ní dídá sílẹ̀ ní àwọn ìlu ń lá ń lá, ni pé nípa ọ̀nà yìí àkíyèsí àwọn adarí ni a yóò pè sí iṣẹ iranṣẹ ti angẹli kẹta. Ṣe àkíyèsí pé àwọn ile ìtaja ounjẹ ṣe àkóso o rẹ̀ lọ́nà tó yàtọ̀ pátá pátá sí ọ̀nà tí a fi ṣe àkóso àwọn ilé oúnjẹ títà tí kò ṣe pàtàkì. Awọn eniyan olóye yóò bẹ̀rẹ̀ láti máa bèèrè nínú àwọn ìdí fún ìyàtọ̀ nínú àwọn ìlànà òwò ṣíṣe, wọn yóò sì tọpinpin àwọn ìpìlẹ̀ ti yóò darí i wọn láti pín oúnjẹ tí ó dára jù. Báyìí wọn yóò lè darí i wọn sí ìmọ̀ ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àsìkò yìí.- Testimonies, vol.7, pp.122,123.IIO 139.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents