Go to full page →

ORÍ KỌKÀNDÍNLÓGÚN IBI IṢẸ́ Ẹ TI ILÉ ÀTI TI ÒKÈÈRÈ. IIO 199

Iṣẹ́ Tí Pàtàkì Rẹ̀ Jẹ́ Bákan náà Pẹ̀lú Iṣẹ́ Ti Òkèèrè IIO 199

Ẹ dìde, ẹ dìde, ẹ̀yin ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, kí ẹ sì lọ ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti gbogbo ibi tí iṣẹ́ kò tíì dé. Ohunkóhun tí ẹ bá fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ ní ilẹ̀ òkèèrè kò túmọ̀ sí wí pé iṣẹ́ yin ti parí. Iṣẹ́ wà láti ṣe ní ìlú òkèèrè, ṣùgbọ́n iṣẹ́ wà láti ṣe ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà èyí sì ṣe pàtàkì. Ọpọ̀lọpọ̀ ènìyàn onírúurú ẹ̀yà ni wọ́n wà ní àwọn ìlú ńlá-ńlá ni Amẹ́ríkà. Àwọn wọ̀nyìí nílò ìmọ́lẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún ìjọ Rẹ̀.—Testimonies, vol. 8, p. 36. IIO 199.1

Nígbà tí a ní i lọ́kàn láti kìlọ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lókééré, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ni ó yẹ kí a ṣe nítorí àwọn àlejò tí wọ́n wá sí ilẹ̀ wa. Àwọn ọkàn tí ó wà ní ilẹ̀ ‘China’ kò ṣe pàtàkì ju àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ wa lọ. Àwọn ènìyàn Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ takun-takun ní àwọn ìlú òkèèrè nítorí àánú Ọlọ́run lèè la ọ̀nà, bákan náà ni ó yẹ ki wọ́n ṣe ojúṣe wọn sí àwọn àlejò tí ó wá láti oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè èyí tí ó wà ní àwọn ìlú ńlá-ńlá àti àwọn ìletò tí ó wà nítòsí.—Review and Herald, Oct. 29, 1914. IIO 199.2

Ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ńlá-ńlá gẹ́gẹ́ bíi ‘New York’, ‘Chicago’ àti ní àwọn ìlú ńlá mìíràn gbogbo ni àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àlejò èyí tí wọn kò tì ì gbọ́ nípa ìkìlọ̀. Ìtara ńlá ni ó wà láàárín àwọn ọmọ Ìjọ Onírètí, èmi kò sọ wí pé ìtara yìí pọ̀ jù èyí tí ó lèè ṣiṣẹ́ ní àwọn orílẹ̀ èdè òkèèrè; ṣùgbọ́n ìbá ti wun Ọlọ́run tó tí irú ìtara báyìí bá wà láti ṣiṣẹ́ ní àwọn ìlú ńlá tí ó wà nítòsí. Àwọn eniyan Re nílò láti fi ọgbọ́n tẹ̀síwájú. Wọ́n sì nílò láti ṣe àgbékalẹ̀ iṣẹ́ yìí ní àwọn ìlú ńlá pẹ̀lú ìtara gidigidi. A gbọ́dọ̀ rán àwọn ènìyàn tí a ti yà sí mímọ́ tí wọ́n sì ní ẹ̀bùn lọ sí àwọn ìlú ńlá wọ̀nyìí láti ṣiṣẹ́. Àgbáríjọpọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ni ó yẹ kí wọ́n jìjọ ṣiṣẹ́ láti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn.—Review and Herald, Oct. 29, 1914. IIO 199.3