Go to full page →

Àdánù Ńlá Nínú Àwọn Tó Ṣẹ́kù Lókéérè IIO 197

Owó gọbọi ni à ń ná lóríi àwọn ìpàdé ìpàgọ́ wa. Àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ti ń pòkìkí irọ́ tẹ́lẹ̀, wọ́n ń ṣiṣẹ́ takuntakun báyìí níbi àwọn ìpàdé ńlá yìí láti gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti àánú yìí láti ọ̀dọ̀ Olùrapàdà tí a kàn mọ́ àgbélèbú lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn otòṣì ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ń ṣubú lọ. Láti kọ etí ọ̀gbọin sí àwọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí dàbí ẹni wí pé a yẹpẹrẹ Ọlọ́run àti àwọn ohun ìkìlọ̀ àti ẹ̀bẹ̀ Rẹ̀. Ṣíṣe aláìwá sí ibi ìpàdé yìí lèè mú ìjàm̀bá bá ìdàgbàsókè ẹmi wa. Ẹ ti pàdánù agbára títí ó yẹ kí ẹ ri gbà nípa fífetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ àti dídàpọ̀ mọ́ àwọn tí agbára títí ó yẹ kí ẹ rí gbà nípa fífetísílẹ́ sí àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ àti dídàpọ̀ mọ́ àwọn tí wọn gba òtítọ́ gbọ́.—Testimonies, vol. 4, p. 115. IIO 197.3

Ohun kékeré kọ́ ni fún ìdílé kan láti dúró gẹ́gẹ́ bí aṣojú Kírísítì èyí tí ń pa òfin Ọlọ́run mọ́ nínú àwùjọ àwọn aláìgbàgbọ. Ìwé ìhìnrere ti àwọn ènìyàn mọ̀ tí wọ́n sì ń kà ni ó yẹ kí a jẹ́ fún gbogbo ènìyàn. Ipò yìí mú ojúṣe tó ní ẹ̀rù lọ́wọ́. Láti gbé nínú ìmọ́lẹ̀ túmọ̀ sí kí a wá láti ibi ìmọ́lẹ̀. Ẹnì kọọ̀kan nípa fífi-ara-ẹni-jìn ni ó gbọ́dọ̀ rí i gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ láti lọ pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ sí ibi ìpàdé ọdọọdún, àwọn tí ó fẹ́ òtítọ́ yìí. Yóò fún wọn ní okun láti dúró gírí ní ìgbà ìdààmú àti nígbà tí ìpè sí iṣẹ́ báyá. Kìí ṣe ohun tó dára fún wọn láti pàdánù àǹfààní àti dàrapọ̀ mọ́ àwọn tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan bíkòṣe bẹ́ẹ̀, òtítọ́ yìí lè bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ pàtàkì rẹ nù nínú wọn, kí ọkàn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní rẹ̀wẹ̀sì kí wọ́n sì wá ṣe bẹ́ẹ̀ pàdánù ìgbé ayé ẹ̀mí wọn. Ọkàn wọn kò gba agbára nípasè ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí à ń tipasẹ̀ àwọn oníwàásù sọ fún wọn. Àwọn àníyàn ayé tí ó ń gba ọkàn wọn kan ni ó ń pa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó wà nínú wọn.—Testimonies, vol. 4, p. 106. IIO 197.4

Gbogbo àwọn tí ó bá ṣeéṣe fún ni kí wọn ó máa lọ sí ìpàgọ́ ọlọ́dọọ́dún yìí. Gbogbo ènìyàn ni ó yẹ kí ó mọ̀ wí pé ohun tí Ọlọ́run ń bèèrè lọ́wọ́ wọn nìyẹn. Tí wọn kò bá lo àǹfààní tí Ọlọ́run fún wọn yìí láti lè jẹ́ alágbára nínú Rẹ̀ àti nínú agbára oore-ọ̀fẹ́, iná ẹ̀ẹ̀mí wọn yóò sì máa kú díẹ̀díẹ̀ títí di ìgbà tí wọ́n kò ní ìtara láti ya ohun gbogbo sí mímọ́ fún Ọlọ́run. IIO 197.5

Ẹ wá, ẹ̀yin ara lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ibi ìpàdé mímọ́ yìí ni a ti lè è ṣalábàpàdé Jésù. Yóò ba wa pé, yóò wà níbẹ̀, yóò sì ṣe ohun tí ó yẹ kí ó ṣe. Iṣẹ́ rẹ kò yẹ kí ó jẹ́ ọ lógún ju ẹ̀ẹ̀mí àwọn ènìyàn lọ. Gbogbo ìṣura tí o ní, bí ó ṣe wù kí wọn ó níye lórí tó kò leè tó láti ra àlàáfíà àti ìrètí tí yóò jẹ́ èrè ńlá; ọ̀kan lára ohun tí ó wà títí ayérayé àti ọkàn láti jọ̀wọ́ ohun gbogbo fún Kírísítì, jẹ́ ìbùkún tí ó níye lórí ju gbogbo ọrọ̀, aadùn àti ògo ayé.—Testimonies, vol. 2, pp. 575, 576. IIO 198.1