Go to full page →

Yíyọ Àlìkámà Kúrò Láarin Èpò IIO 56

Àsìkò ìdájọ́ Ọlọ́run tí yóò mú ìparun wá ni àsìkò àánú fún àwọn tí kò ní ààyè láti kọ ohun tí í ṣe ti òtítọ́. Jẹ́jẹ́ ni Olúwa yóò wò wọ́n. Ó fi ọwọ́ kan ọkàn àánú u Rẹ̀. Ó sì tún ń na ọwọ́ ọ Rẹ̀ jáde láti gbàlà, nígbà tí ìlẹ̀kùn yóò tì mọ́ àwọn tí kò ní wọlé.-Testimonies,vol.9,p.97. IIO 56.3

Láìpẹ́ ogun náà yóò gbóná girigiri láarin àwọn tí wọ́n ń sìn àti àwọn tí kò sìn Ín. Láìpẹ́ gbogbo ohun tí wọ́n lè mì àti àwọn ohun tí a kò le è mì lè dúró.-Testimonies,vol.9,pp.15,16. IIO 56.4

Ní àsìkò ìpọ́njú àti ìdààmú ti àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò wá tí wọn kò tí ì jọ̀wọ́ ara wọn pátápátá fún ìwà ìbàjẹ́ ẹ ti inú ayé àti tí iṣẹ́ ìsìn ti èṣù. Àwọn tí wọn yóò rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, tí wọn yóò sì yípadà sí I pẹ̀lú gbogbo ọkàn an wọn tí wọn yóò sì rí ìtẹ́wọ́gbà àti ìdáríjì gbà.- Testimonies,vol.1,p.269. IIO 56.5

Ọ̀pọ̀ ló wà tí wọn ǹ ka ìwé mímọ́ tí òye ìtumọ̀ pàtàkì i rẹ̀ kò yé. Ní gbogbo àgbáyé ọkùnrin àti obìnrin ni wọn ń wò tí wọ́n sì ń tẹjúmọ́ ọ̀run. Àwọn àdúrà àti omijé àti àwọn ìwádì í ń lọ láti àwọn ọkàn tí ń fojú sọ́nà fún ìmọ́lẹ̀, fún oore-ọ̀fẹ́, fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ọ̀pọ̀ ló wà létí bèbè ti ìjọba ọ̀run, tí wọ́n ń dúró láti mú wọ ilé. - The Acts of the Apostles, p.109. IIO 57.1