Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Yíyọ Àlìkámà Kúrò Láarin Èpò

    Àsìkò ìdájọ́ Ọlọ́run tí yóò mú ìparun wá ni àsìkò àánú fún àwọn tí kò ní ààyè láti kọ ohun tí í ṣe ti òtítọ́. Jẹ́jẹ́ ni Olúwa yóò wò wọ́n. Ó fi ọwọ́ kan ọkàn àánú u Rẹ̀. Ó sì tún ń na ọwọ́ ọ Rẹ̀ jáde láti gbàlà, nígbà tí ìlẹ̀kùn yóò tì mọ́ àwọn tí kò ní wọlé.-Testimonies,vol.9,p.97.IIO 56.3

    Láìpẹ́ ogun náà yóò gbóná girigiri láarin àwọn tí wọ́n ń sìn àti àwọn tí kò sìn Ín. Láìpẹ́ gbogbo ohun tí wọ́n lè mì àti àwọn ohun tí a kò le è mì lè dúró.-Testimonies,vol.9,pp.15,16.IIO 56.4

    Ní àsìkò ìpọ́njú àti ìdààmú ti àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò wá tí wọn kò tí ì jọ̀wọ́ ara wọn pátápátá fún ìwà ìbàjẹ́ ẹ ti inú ayé àti tí iṣẹ́ ìsìn ti èṣù. Àwọn tí wọn yóò rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, tí wọn yóò sì yípadà sí I pẹ̀lú gbogbo ọkàn an wọn tí wọn yóò sì rí ìtẹ́wọ́gbà àti ìdáríjì gbà.- Testimonies,vol.1,p.269.IIO 56.5

    Ọ̀pọ̀ ló wà tí wọn ǹ ka ìwé mímọ́ tí òye ìtumọ̀ pàtàkì i rẹ̀ kò yé. Ní gbogbo àgbáyé ọkùnrin àti obìnrin ni wọn ń wò tí wọ́n sì ń tẹjúmọ́ ọ̀run. Àwọn àdúrà àti omijé àti àwọn ìwádì í ń lọ láti àwọn ọkàn tí ń fojú sọ́nà fún ìmọ́lẹ̀, fún oore-ọ̀fẹ́, fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ọ̀pọ̀ ló wà létí bèbè ti ìjọba ọ̀run, tí wọ́n ń dúró láti mú wọ ilé. - The Acts of the Apostles, p.109.IIO 57.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents