Go to full page →

ORÍ — KÉJE ÌFỌWỌ́-SO-WỌ́-PỌ̀ LÁARIN ÀWỌN ÀLÙFÁÀ ÀTI ÀWỌN ỌMỌ ÌJỌ IIO 67

Fífi Ìṣọ̀kan Wọ Iṣẹ́ Ìsìn. IIO 67

Jẹ́ kí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ ijọ lọ sí inú àwọn oko tí ó ti pọ́n. Wọn yóò rí àwọn ìkórè e wọn níbikíbi tí wọ́n ti pólongo áwọn òtítọ́ ọ Bíbélì tí wọ́n gbàgbé. Wọn yóò rí àwọn tí wọn yóò gba òtítọ́ náà àti àwọn tí wọn yóò jọ̀wọ́ ayé e wọn fún jíjèrè àwọn ọkàn fún Krístì.-Australian Signs of The Times, Aug.3,1903. IIO 67.1

Kì í ṣe èrò Ọlórun pé kí a fi àwọn àlùfáà nìkan sílẹ̀ láti ṣe èyí tí ó tóbi jù nínú iṣẹ́ ẹ gbíngbin òtítọ́. Àwọn eniyan tí a kò pè sí iṣẹ́ ìhìnrere ni a gbọdọ̀ gbà níyànjú láti ṣiṣẹ́ fún Olúwa gẹgẹ bi agbára wọn bá ṣe pọ̀ tó. Àwọn ọ̀pọ̀ eniyan l’ọ́kùnrin ati l’óbìnrin tí ọwọ́ ọ wọn dilẹ̀ lè ṣe iṣẹ́ ìsìn tí ó ní ìtẹ́wọ́gbà. Nípa gbígbé òtítọ́ lọ sí àwọn ilé àwọn ọ̀rẹ́ ẹ wọn àti àwọn aládúgbò o wọn, wọ́n lè ṣe iṣẹ́ takun takun fún Olúwa a wọn.-Testimonies, vol.7, p.21. IIO 67.2

Ọlọrun ti fún àwọn òjíṣẹ́ ẹ Rẹ̀ ní iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti òtítọ́ lati polongo. Eyi ni àwọn ìjọ gbọdọ̀ gbà, àti ní gbogbo ọ̀nà tó rọrùn láti sọ fún, láti mú àwọn ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ àkọ́kọ́ àti láti tàn wọ́n kálẹ̀.- Testimonies, vol.6, p.425. IIO 67.3

Àwọn ènìyàn gbọdọ̀ ṣe ìgbélárugẹ pẹ̀lú àwọn àlùfáà kí wọn ṣe àtìlẹyìn fún akitiyan-an rẹ̀ àti láti ràn án lọ́wọ́ ni riru awọn ẹrù u rẹ̀, nípa báyì í kò ní lè ṣiṣẹ́ tayọ kí ó sì wá rẹ̀wẹ̀sì. Kò sí ipa kankan tí a lè gbé ka orí ìjọ tí a le faradà àyàfi tí awọn eniyan bá rìn pẹ̀lú òye, kúrò nínú ìpìlẹ̀, láti ṣe ohun tí wọ́n lè ṣe láti tẹ iṣẹ́ náà síwájú.-Review and Herald, Aug.23, 1881. IIO 67.4