Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORÍ — KÉJE ÌFỌWỌ́-SO-WỌ́-PỌ̀ LÁARIN ÀWỌN ÀLÙFÁÀ ÀTI ÀWỌN ỌMỌ ÌJỌ

    Fífi Ìṣọ̀kan Wọ Iṣẹ́ Ìsìn.

    Jẹ́ kí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ ijọ lọ sí inú àwọn oko tí ó ti pọ́n. Wọn yóò rí àwọn ìkórè e wọn níbikíbi tí wọ́n ti pólongo áwọn òtítọ́ ọ Bíbélì tí wọ́n gbàgbé. Wọn yóò rí àwọn tí wọn yóò gba òtítọ́ náà àti àwọn tí wọn yóò jọ̀wọ́ ayé e wọn fún jíjèrè àwọn ọkàn fún Krístì.-Australian Signs of The Times, Aug.3,1903.IIO 67.1

    Kì í ṣe èrò Ọlórun pé kí a fi àwọn àlùfáà nìkan sílẹ̀ láti ṣe èyí tí ó tóbi jù nínú iṣẹ́ ẹ gbíngbin òtítọ́. Àwọn eniyan tí a kò pè sí iṣẹ́ ìhìnrere ni a gbọdọ̀ gbà níyànjú láti ṣiṣẹ́ fún Olúwa gẹgẹ bi agbára wọn bá ṣe pọ̀ tó. Àwọn ọ̀pọ̀ eniyan l’ọ́kùnrin ati l’óbìnrin tí ọwọ́ ọ wọn dilẹ̀ lè ṣe iṣẹ́ ìsìn tí ó ní ìtẹ́wọ́gbà. Nípa gbígbé òtítọ́ lọ sí àwọn ilé àwọn ọ̀rẹ́ ẹ wọn àti àwọn aládúgbò o wọn, wọ́n lè ṣe iṣẹ́ takun takun fún Olúwa a wọn.-Testimonies, vol.7, p.21.IIO 67.2

    Ọlọrun ti fún àwọn òjíṣẹ́ ẹ Rẹ̀ ní iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti òtítọ́ lati polongo. Eyi ni àwọn ìjọ gbọdọ̀ gbà, àti ní gbogbo ọ̀nà tó rọrùn láti sọ fún, láti mú àwọn ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ àkọ́kọ́ àti láti tàn wọ́n kálẹ̀.- Testimonies, vol.6, p.425.IIO 67.3

    Àwọn ènìyàn gbọdọ̀ ṣe ìgbélárugẹ pẹ̀lú àwọn àlùfáà kí wọn ṣe àtìlẹyìn fún akitiyan-an rẹ̀ àti láti ràn án lọ́wọ́ ni riru awọn ẹrù u rẹ̀, nípa báyì í kò ní lè ṣiṣẹ́ tayọ kí ó sì wá rẹ̀wẹ̀sì. Kò sí ipa kankan tí a lè gbé ka orí ìjọ tí a le faradà àyàfi tí awọn eniyan bá rìn pẹ̀lú òye, kúrò nínú ìpìlẹ̀, láti ṣe ohun tí wọ́n lè ṣe láti tẹ iṣẹ́ náà síwájú.-Review and Herald, Aug.23, 1881.IIO 67.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents