Go to full page →

Fífi Ẹ̀nìkọ̀ọ̀kan Sí Ààyè e Rẹ̀. IIO 74

Ẹnìkọ̀ọkan, tí a fikún àwọn ẹgbẹ́ nípa ìyílọ́kàn padà ni a ní láti yan iṣẹ́ fún. Ẹnìkọ̀ọ̀kan ni ó gbọdọ̀ nífẹ̀ ẹ́ láti ṣe ohun kan nínú ogun jíjà yì í. - Testimonies, vol.7, p.30. IIO 74.1

Kì í ṣe àwọn ilé-ìwé gíga, àwọn ilé ń lá ń lá tàbí àsehàn ni Ọlọ́run ń bèrè, ṣùgbọ́n wíwà ní pípé ti ènìyàn ọ̀tọ̀, àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run ti yàn tí wọn nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni yóò dúró ní ipò àti ààyè e rẹ̀, ni yóò ronú, ni yóò sọ̀rọ̀, ni yóò sì kópa nínú ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run.Títí di ìgbà tí èyí yóò jẹ́ ṣíṣe,àgbájọpọ̀ iṣẹ́ yóò wà láì fì síbì kan.- Testimonies,vol.6, p.293. IIO 74.2

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà bí àwọn tí ó jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun bá ṣe kún ojú òṣùwọ̀n tò ni yóò fi bí agbára a wọn ṣe tó hàn.Olórí ogun tó lọ́gbọ́n yóò pàṣẹ fún àwọn adarí ogun láti kọ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan kí ó jẹ́ akíkanjú . Ó ń fẹ́ ìmúdàgbà agbára ní ọ̀dọ̀ ọ gbogbo wọn. Tí ó bá fẹ́ gbáralé àwọn adarí ogun rẹ̀ nìkan ni, kò ní ṣe é ṣe láti ṣe àṣeyọrí nínú ìpolongo. Ó gbáralé òótọ́ àti iṣẹ́ láì ṣàárẹ̀ láti ọ́dọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú ẹgbẹ́ ológun u n rẹ̀.Púpọ̀ nínú ẹrù iṣẹ́ yìí dúró lórí àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ẹgbẹ́ ológun yì í,- Testimonies, vol.9, p.116. IIO 74.3

Olúwa ń pè fún àwọn òṣìṣẹ́ ìhìnrere. Tani yóò dáhùn? Kì í ṣe gbogbo ẹni tí ó wọ ẹgbẹ́ ológun ni yóò jẹ́ olórí ogun, Balógun, oyè nínú ogun, tàbí pàápàá oyé nínú àwọn ológun. Kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó ní aájò àti láti dúró bí olórí.Àwọn onírúurú iṣẹ́ tí ó lágbára mìíràn wà láti ṣe. Àwọn díẹ̀ lè gbẹ́ kòtò kí wọn sì kọ́ odi ààbò , àwọn mìíràn lè dúró bí alóre, Àwọn kan lè dúró bí òjíṣẹ́.Níbi tí àwọn adarí ogun kò ti tó n ǹkan, wọ́n nílò àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun ní onírúurú ipò láarin ológun; sibẹ àṣeyorì dúró lórí ìfaramọ́ tàbí òtítọ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan. Ìwà ojo tàbí ìwa àrekérekè ẹnìkan lè fa ìparun sórí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun. Gospel Workers, pp.84, 85. IIO 74.4