Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Fífi Ẹ̀nìkọ̀ọ̀kan Sí Ààyè e Rẹ̀.

    Ẹnìkọ̀ọkan, tí a fikún àwọn ẹgbẹ́ nípa ìyílọ́kàn padà ni a ní láti yan iṣẹ́ fún. Ẹnìkọ̀ọ̀kan ni ó gbọdọ̀ nífẹ̀ ẹ́ láti ṣe ohun kan nínú ogun jíjà yì í. - Testimonies, vol.7, p.30.IIO 74.1

    Kì í ṣe àwọn ilé-ìwé gíga, àwọn ilé ń lá ń lá tàbí àsehàn ni Ọlọ́run ń bèrè, ṣùgbọ́n wíwà ní pípé ti ènìyàn ọ̀tọ̀, àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run ti yàn tí wọn nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni yóò dúró ní ipò àti ààyè e rẹ̀, ni yóò ronú, ni yóò sọ̀rọ̀, ni yóò sì kópa nínú ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run.Títí di ìgbà tí èyí yóò jẹ́ ṣíṣe,àgbájọpọ̀ iṣẹ́ yóò wà láì fì síbì kan.- Testimonies,vol.6, p.293.IIO 74.2

    Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà bí àwọn tí ó jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun bá ṣe kún ojú òṣùwọ̀n tò ni yóò fi bí agbára a wọn ṣe tó hàn.Olórí ogun tó lọ́gbọ́n yóò pàṣẹ fún àwọn adarí ogun láti kọ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan kí ó jẹ́ akíkanjú . Ó ń fẹ́ ìmúdàgbà agbára ní ọ̀dọ̀ ọ gbogbo wọn. Tí ó bá fẹ́ gbáralé àwọn adarí ogun rẹ̀ nìkan ni, kò ní ṣe é ṣe láti ṣe àṣeyọrí nínú ìpolongo. Ó gbáralé òótọ́ àti iṣẹ́ láì ṣàárẹ̀ láti ọ́dọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú ẹgbẹ́ ológun u n rẹ̀.Púpọ̀ nínú ẹrù iṣẹ́ yìí dúró lórí àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ẹgbẹ́ ológun yì í,- Testimonies, vol.9, p.116.IIO 74.3

    Olúwa ń pè fún àwọn òṣìṣẹ́ ìhìnrere. Tani yóò dáhùn? Kì í ṣe gbogbo ẹni tí ó wọ ẹgbẹ́ ológun ni yóò jẹ́ olórí ogun, Balógun, oyè nínú ogun, tàbí pàápàá oyé nínú àwọn ológun. Kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó ní aájò àti láti dúró bí olórí.Àwọn onírúurú iṣẹ́ tí ó lágbára mìíràn wà láti ṣe. Àwọn díẹ̀ lè gbẹ́ kòtò kí wọn sì kọ́ odi ààbò , àwọn mìíràn lè dúró bí alóre, Àwọn kan lè dúró bí òjíṣẹ́.Níbi tí àwọn adarí ogun kò ti tó n ǹkan, wọ́n nílò àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun ní onírúurú ipò láarin ológun; sibẹ àṣeyorì dúró lórí ìfaramọ́ tàbí òtítọ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan. Ìwà ojo tàbí ìwa àrekérekè ẹnìkan lè fa ìparun sórí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun. Gospel Workers, pp.84, 85.IIO 74.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents