Go to full page →

Àṣẹ Ìtẹ̀síwájú IIO 77

Aláṣẹ ti Wellington ni ó wà níbi tí ẹgbẹ́ àwọn ọkùnrin onígbàgbọ́ kan ti ń jíròrò nípa bí ó ṣe le ṣe é ṣe látí ṣe àṣeyọrí nínú ìgbìyànjú ìhìnrere láarin àwọn kèfèrí. Wọ́n pàrọwà sí alaṣẹ yii láti sọ bóyá nínú ìdájọ́ ọ rẹ̀ irú àwọn ìgbìyànjú yìí le e mu aṣeyọri ti o yẹ jade. IIO 77.3

Ògbólógbò ó jagun jagun yìí dáhùn: “Ẹ̀yin arákùnrin, kíni àwọn àṣẹ ìtẹ̀síwájú u yín? Àṣeyọrí kìí ṣe ìbéèrè fún yín láti jíròrò lé lórí. Tí mo bá ka àṣẹ ẹ yín dáadáa, ó lọ báyìí, ” Ẹ lọ sí gbogbo ayé kí ẹ sì wàásù ìhìnrere fún gbogbo ẹ̀dá'. Arákùnrin, ẹ gbọ́ràn sí àṣẹ ẹ yín.”- Gospel Workers, p.115. IIO 77.4