Go to full page →

Àwọn Àkànṣe Ètò Pàtàkì Ní Àwọn Ìpàdé Ìpàgọ́ Nígbà tí Òpin Bá Ń Súnmọ́ IIO 197

A fi hàn mí wí pé àwọn ìpàgọ́ wa gbọ́dọ̀ máa pọ̀ si pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn àti àṣeyọrí. Bí òpin ayé ti ń súnmọ́ wa. Mo ti rí i wí pé nínú àwọn ìpàgọ́ wọ̀nyìí, kò gbọdọ̀ sí ìwàásù púpọ̀ bíkòṣe ìdànílẹ́kọ̀ọ́ láti inú Bíbélì. A gbọ́dọ̀ ní àwọn ẹgbẹ́ kékèèké ní gbogbo ìpàgọ́ pẹ̀lú Bíbélì wọn ní ọwọ́ wọn tí olúkúlukú wọn yóò sì máa kọ́ni gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.-Testimonies, Vol. 6, p. 87. IIO 197.2