Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    IYE MI ATI OHUN GBOGBO MI

    ’Gbati mo nwo agbelebu
    Ti a kan Ọba Ogo mọ;
    Mo kà gbogbo ọrọ̀ s’ ofo,
    Mo kẹgan gbogbo ogo mi.

    Wo b’ ẹdùn pẹlu ‘fẹ ti ns̩an
    Lat’ ori, ọwọ, ẹsẹ Rẹ̀;
    Ifẹ ‘dapọ m’ ẹdun bē̩ ri,
    A f’ ẹ̀gun s’ ade ogo ri!

    K’ a má se gbọ pe mo nhalẹ̀
    B’ o yẹ n’ iku OÌuwa mi;
    Gbogbo nkan asan ti mo nfẹ,
    Mo kọ silẹ fun ẹjẹ Rẹ̀.

    Gbogbo aiye ba jẹ temi,
    Ko to ọrẹ ti mba mu wá;
    Ifẹ ‘yanu t’o pọ to yi,
    Yẹ k’ o gba gbogbòo ẹmi mi.
    IOK 55.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents