Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Is̩ẹ ati Iye

    Ọlọrun ni orisun iye, ati imọlẹ, ati ayọ̀ fun gbogbo ẹda aiye. Gẹgẹbi itans̩an imọlẹ õrun, ati bi omi ti ns̩an lati inu odo wa, ni awon ibukun ns̩an lati ọdọ Rẹ̀ wa sori gbogbo ẹda. Ati nibikibi ti ẹmi Ọlọrun ba ti wà ni ọkan enia, yioIOK 56.1

    Ayọ Olugbala wa wà ninu igbesoke ati irapada ti is̩ubu enia. Nitori eyi, ko ka ẹmi ara Rẹ̀ si ohun ti o s̩ọwọn fun U, s̩ugbọn O fi ara da agbelebu, ko si ka itiju nã si. Bē̩ ni awọn angẹli ns̩is̩ẹ nigbagbogbo fun inudidun ẹnikeji wọn. Eyi jẹ ayọ wọn pẹlu. Iru is̩ẹ ti ọkan imọ-ti-ara-ẹni kasi is̩ẹ ti o rẹni-silẹ, lati jis̩ẹ fun awọn otòs̩i ati awọn ti o rẹ̀hin ju wọn lọ nipa ìbí ati ipo ti aiye, ni awọn angẹli alailẹs̩ẹ nyọ mọ lati s̩e. Ẹmi ifi-ara-ẹni-rubọ ti Kristi, jẹ iru ẹmi ti o kun inu awọn ọrun, on nã si ni orisun ayọ̀ ti o wa nibẹ. Eyi ni iru ẹmi ti awọn atẹle Kristi nilati ni, eyi si ni iru is̩ẹ ti nwọn nilati s̩e.IOK 56.2

    Nigbati ifẹ Kristi ba hàn ninu ọkan gẹgẹbi ororo olõrun didun, kò le fi ara sin. Gbogbo awọn ti a ba mba pade ni yio ma mọ nipa agbara iwa mimọ nã. Ẹmi Kristi ninu ọkan enia dabi orisun omi tutu ni ilẹ as̩álẹ̀ ti o ns̩an fun itura gbogbo enia, ti o si nmu ki awọn wọnni ti o s̩etan lati kú le ni itara lati wá mu ninu omi iye na.IOK 56.3

    Ifẹ si Kristi yio farahan nipa nini ifẹ lati s̩e iru is̩ẹ ti On se fun ibukun ati igbega iru ọmọ Adamu. Ẹmi na yio sin wa lọ sinu ifẹ iwa-jẹjẹ ati ti ibanikẹdun si gbogbo ohun ẹlẹmi ti mbẹ labẹ itọju Baba wa orun.IOK 56.4

    Igbe-aiye Olugbala ki is̩e ti fãji, ko si lo akoko nã fun ti ara Rẹ̀, s̩ugbọn O s̩e wahala pẹlu iforiti, itara, ati aìs̩ãrẹ̀ fun igbala enia ti o ti sọnu. Lati igbà ìbí Rẹ̀ ni ibùjẹ-ẹran titi fi di akoko iku Rè lori oke Kalfari, O tọ ona isẹra-ẹni, On ko si wa pe ki a da On silẹ kuro ninu is̩ẹ nla nã ti o ni irora ti on ti idãmu. Sugbọn O wipe, “Ọmọ enia ko wa ki a mã se irans̩ẹ fun U, bikos̩e lati s̩e irans̩ẹ fun ni, ati lati fi emi Rè se iranada fun opolopọ enia.” (Matt. 20:28.) “Eyi si ni is̩ẹ nla ti O ba wá si aiye. Gbogbo ohun ti o s̩ẹku mbẹ labẹ ọkans̩os̩o yi. Onjẹ Rẹ̀ ni lati s̩e ifẹ ti Ọlọrun ati lati pari is̩ẹ Rẹ̀. Ifẹ ti ara ẹni tabi ti imọ-ti-ara-ẹni ko ri ãye ninu is̩ẹ ti Kristi s̩e li aiye.IOK 56.5

    Nitori eyi yi, awọn wọnni ti nwọn jẹ alábapin õre-ọfẹ ti Kristi nilati s̩etan fun irubọ k’ irubọ lati le mu ki awọn ti Kristi ku fun di alabapin ẹbun ọrun. Nwọn O sa gbogbo ipa wọn lati le mu ki aiye dara si nipa wiwa wọn nibẹ. Ẹmi yi ni idaniloju idagba ọkan ti a yipada si Ọlọrun. Lẹsẹkẹsẹ ti ẹnikan ba ti tọ Kristi wa, ni imã wà ninu ọkan wọn lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa iru ọrẹ iyebiye ti Jesu jẹ fun wọn. Otitọ ti igbala nã ko tun f’ ara sin mọ ninu ọkan rẹ̀. Bi a ba fi ododo Kristi wọ wa, ti a si fi ẹmi ayọ̀ Rẹ̀ kun inu wa, a ko ni le dakẹ mọ. Bi a ba ti tọ wo pe rere ni Òluwa, ao sọ nipa Rẹ̀ fun ẹlomiran. Ohun ti Filipi s̩e nigbati O ri Olugbala ni awa nã yio s̩e, ao pe ẹlomiran wa si ọdọ Rẹ̀. A O wá ãye lati fi ifẹ ifanimọra ti Kristi han wọn ati ti idaniloju aiye ti mbọ ti a ko ti f’ oju ri. Ifẹ ti O lagbara yio wa lati tẹle oju ọna ti Jesu ti tọ̀. Igbona ọkan yio wa lati le mu ki awọn ti O yi wa ká le wo “Ọdọ-agutan Ọlọrun, ẹniti O ko ẹs̩ẹ aiye lọ.”IOK 57.1

    Bi a ti nlàkàkà lati bukun awọn ẹlomiran, ibukun na yio si pada wa di tiwa. Eyi lo mu ki Ọlọrun papa ninu ero Rẹ̀ fi ãye silẹ fun enia lati lọwọ ninu is̩ẹ ti irapada. O ti fi anfãni fun enia lati di alábapin iwà ẹda ọrun, ati nipa bẹ ki ibukun le mã ti ọdọ wọn s̩an jade fun awọn ẹlẹgbẹ wọn. Eyi ni ọla ati ayọ̀ ti O ga julọ ti Ọlọrun le fifun enia. Awọn wọnni ti O ti ipa bẹ di alabapin ninu is̩ẹ ti ifẹ nã li a mu sunmọ ọdọ Ẹlẹda wọn.IOK 57.2

    Ò s̩es̩e fun Ọlọrun lati fi is̩ẹ ihinrere ati ti gbogbo is̩ẹ irans̩ẹ ti ifẹ nã le awọn angẹli lọwọ. O si tun le lo awọn ona miran lati mu ero Rẹ̀ s̩ẹ. S̩ugbọn ninu ifẹ Rẹ̀ ainipekun, O yàn lati sọ wa di alabas̩isẹpọ pẹlu ara Rẹ̀, ati pẹlu Kristi, ati awọn angẹli, ki a ba le di alabapin ibukun, ayọ, ati igbega ti ẹmi, eyi ti O jẹ ayọrisi is̩ẹ irans̩ẹ ati aimọ-ti-araẹni-nikan.IOK 57.3

    A so wa di abanikẹdun pẹlu Kristi nipa biba A jiya. Gbogbo irubọ ti a ns̩e fun rere awọn ẹlomiran, li O nfun ẹmi ti won lokun lati le mo riri ọkan isõre. O si nmu ki wọn sunmo ọdo Olurapada araiye si, “Ẹniti O ti jẹ ọlọrọ ri, s̩ugbọn nitori nyin O di talaka, ki a le sọ nyin di ọlọrọ nipa aini Rè. Afi nipa mimu ero ti ọrun yi s̩ẹ n’igbe-aiye wa s̩e le jẹ ibukun fun wa.IOK 57.4

    Bi iwọ yio ba jade lọ lati s̩is̩ẹ gẹgẹbi Kristi ti lana silẹ fun awọn ọmọ-ẹhin, ati lati jere ọkan fun U, o nilati ri iriri ti o jinlẹ ti o si tobi nipa ti nkan ti is̩e ti ọrun, ebi ti ododo yio mã pa ọ, ongbẹ yio si mã gbẹ ọ sipa ti ododo. Iwọ yio mã ba Ọlọrun sọrọ, a o si sọ igbagbọ rẹ di alagbara, ọkan rẹ yio si mà mu lati inu kanga jinjin ti is̩e ti igbala. Awọn Alátakò ati idanwo ti iwọ yio ba pade yio mu ọ sunmọ Bibeli pẹlu adura. Iwọ yio mã dagba soke ninu õre-ọfẹ ati ninu imọ Kristi, iriri rẹ ti o ti niye lori yio si di gbigbõro.IOK 58.1

    Fifi ẹmi aimọ-tara-ẹni-nikan s̩is̩ẹ fun awọn ẹlomiran, a mã funni ni ijinlẹ iduros̩ins̩in, iwa ifanimọra bi ti Kristi, a si mã mu alafia ati ayọ wa fun ẹniti o ba ni. Itara ati igbona ọkan li a o gbega soke. Ko si ãye fun iwa ọlẹ ati imọ-taraẹni-nikan. Awọn ti wọn ba lo ẹbun ti igbagbọ wọnyi gẹgẹbi a ti lana rẹ̀ silẹ yio mã dagba soke, nwọn o si di alagbara lati s̩is̩ẹ fun Ọlọrun. Nwọn o ni imoye ti ẹmi ti o ye kõro, igbagbọ ti nfi suru dàgba, ati agbara adura ti o pọ̀. Ẹmi Ọlọrun, ti nrá-bàbà ninu ẹmi tiwọn, nmu is̩ọkan ẹmi hàn gbangba, gẹgebi ami ifọwọkan ti ẹmi lati ọrun wa. Áwọn ti nwọn ba fi akoko wọn s̩is̩ẹ fun ire ẹlomiran laisi iwa imọtara-ẹni-nikan, ns̩is̩ẹ fun igbala ara wọn dajudaju.IOK 58.2

    Ona kan s̩os̩o ti a lè mã fi dagba soke ninu õre-ọfẹ ni sis̩e is̩ẹ ti Kristi palas̩ẹ fun wa laisi ikunsinu, ki a mã sa ipa wa nigbagbogbo lati mà wa ọna ibukun ati ti iranlọwọ fun awọn wọnni ti nwon s̩e alaini ti nwọn si nfẹ iranlọwọ wa. Agbara mã npọ si i nigbati a ba nlo o. Apọn s̩is̩e lo ngbé ẹmi duro. Awọn wọnni ti won fẹ lati mã gbe igbesiaiye onigbagbọ nipa titẹwọgba ibukun ti o wa nipa õre-ọfẹ nikan, ti nwọn ko si se nkan daindain fun Kristi, nwon nfẹ wa lãye, lati mã jẹun lais̩is̩ẹ. Bi o ti ri nipa ti ara, bakanna ni nipa ti ẹmi, pe iru igbe-aiye bẽ a mã yori si ailagbara ati idibaje. Bi enia kan ba kọ̀ lati lo apa ati ẹsẹ rẹ̀, laipẹ jọjọ ko ni le lo won mọ. Be gẹge ni bi onigbagbọ ko ba lo agbara ti Olọrun fifun u. ki is̩e kiki pe yio bàku ni didagba soke ninu Kristi nikan ni, bikos̩e pe gbogbo agbara eyiti o ti ni yio sọnu pẹlu.IOK 58.3

    Ọlọrun ti yàn ijọ Kristi gẹgẹbi ohun pataki fun igbàla omọ enia, is̩ẹ rẹ ni lati mu ihinrere igbala lọ si gbogbo aiye. Is̩ẹ nla yi si simi le ori gbogbo atẹle Kristi. Olukuluku gẹgẹbi agbara (talenti) ti a fifun u nilati mu asẹ Olugbala se. Ife Kristi ti a fihan wa sọ wa di ajigbese fun awọn ti kò mọ̀ Ọ. Ọlọrun ti fun wa ni imọlẹ, ki is̩e fun ti ara wa nikan, bikos̩e lati tan imọlẹ nà si awọn ẹlomiran.IOK 58.4

    Bi gbogbo atẹle Kristi yio ba ji giri si is̩ẹ nã, ẹgbẹgbẹrun enia ni yio mã kede ihinrere nã si awọn keferi nibiti ẹnikan s̩os̩o wa loni. Gbogbo awọn wọnni ti ko le jade lọ fun is̩ẹ nã yio mã s̩e iranlọwọ nipa fifi silẹ ninu ohun ini wọn pẹlu ẹmi ibanikẹdun, ati adura. Itara yio wà lati s̩is̩ẹ fun igbala ọkan ni ilẹ gbogbo nibiti ọrọ nã ko tankalẹ de.IOK 59.1

    Ko di igbati a ba lọ si ilẹ awọn keferi, tabi ti a kuro lãrin agbo ile wa, bi o ba jẹpe ibẹ ni is̩ẹ wa wa, ki a to le s̩is̩ẹ fun Kristi. A le s̩e eyi lãrin agbo ile wa, ninu ile Ọlọrun wa, larin awọn ti a mbá kẹgbẹ pọ, ati awọn ti a mba s̩is̩ẹ.IOK 59.2

    Nibi is̩ẹ gbẹnagbẹna ni Nasareti, li Olugbala gbe fi suru lo pupọ akoko Rẹ̀ li aiye. Awọn angẹli jis̩ẹ fun Oluwa iyè bi O ti nrin lãrin awọn talaka, alagbase, ati awọn ti a ko kasi, ti nwọn ko si lọla. Bi Kristi ti jẹ olõtọ nidi is̩ẹ Rẹ̀ gẹgẹbi gbẹna-gbẹna, bē̩ nã ni O jẹ nigbati O nmu ọlọkunrun larada, tabi nigbati O nrin lori riru igbi omi okun ni Galili. Bakannã ni awa nã pẹlu, iru is̩ẹkis̩ẹ to wu ki a mã s̩e li aiye, a le ba Kristi rin ki a si ba A s̩is̩ẹ pọ.IOK 60.1

    Aposteli nì wipe, “Jẹki olukuluku enia ninu eyiti a pe e ki o duro ni ọkanna pẹlu Ọlọrun.” (I Kor. 7:24) Ónis̩owo le s̩is̩ẹ òwo rẹ li ọna ti o le mu iyin wa fun Oluwa nipa is̩ododo rẹ̀. Bi o ba jẹ atẹle Kristi tõtọ yio mu iwa isin rẹ̀ lọ sinu ohun gbogbo ti o ba ns̩e, yio si fi ẹmi Kristi han enia. Os̩is̩ẹ nidi ero le fi aworan Jesu ti o s̩is̩ẹ larin awọn oke Galili han. Ẹnikẹni ti o ba npe orukọ Kristi nilati s̩is̩ẹ bē̩ gẹgẹ, ki awọn ẹlomiran le ri is̩ẹ rere rẹ̀, ki nwọn le yin Ẹlẹda ati Oluràpadá wọn l’ogo.IOK 60.2

    Awọn ẹlomiran ns̩e awawi lati fi ohun ini wọn silẹ fun is̩ẹ isin Kristi, nitoripe awọn ẹlomiran ni anfani ati ẹbun ti o ga ju tiwọn lọ. Ero na tan kalẹ tobẹ ti wọn fi nro pe, kiki awọn wọnni ti o ni talenti ati agbara pupọ lo le ya ara ati ohun ini wọn si mimọ fun isin Ọlọrun. Ọpọlọpọ wọn nro pe awọn kan pataki ti Ọlọrun fẹran ni O nfi talẹnti fun ati pe O ya awọn ti a ko pe sinu is̩ẹ ati ere nã sọtọ. S̩ugbọn kò ri bẹ ninu owe nã, “nigbati bale ile na si pe awọn iranẹ rẹ o fi is̩e olukuluku fun.”IOK 60.3

    Pẹlu ifẹ a le s̩e awọn is̩ẹ ti o rẹlẹ julọ ni aiye gẹgẹbi fun Oluwa. (Kolose 3:23) Bi ifẹ Ọlọrun ba mbe ninu ọkan, yio fi ara han ninu igbe aiye wa. õrun didun Kristi yio si yi wa ka, is̩esi tabi ihuwasi wa yio gbega soke, yio si mu ibukun wa.IOK 60.4

    Mase duro de akoko nla kan pataki, tabi ki o mã reti agbara iyanu kan ki o to jade lọ s̩is̩ẹ fun Ọlọrun. Mase mã ro nipa ohun ti araiye yio mã ro nipa re. Bi igbe-aiye re ojojumo ba ti njẹri si iwa mimọ ati is̩ododo igbagbọ rẹ, ti awọn elomiran ba si ri pe o jẹ iranlọwọ fun wọn, lãlã rẹ ki yio jasi lasan.IOK 60.5

    Eniti o relè julọ ti o si talaka julọ ninu awọn atẹle Kristi le je ibukun fun ẹnikeji rẹ̀. Awon tikarawọn le má fura pe nwon nse nkankan ti o je rere, s̩ugbọn iwà aiye wọn ti wọn ko kasi, ti jasi apẹre ibukun ti o gbõro. ti o si jinlẹ, nwọn si lè má mọ iyọrisi rẹ̀ titi yio fi di ọjọ nla ni. Nwọn ko mọ tabi fura pe nwọn nẹe ohun ribiribi kan. Nwọn ko dãmu ẹmi wọn lati lè mọ iyọrisi ohun ti nwọn ti s̩e, kiki pe nwọn jade lọ jẹjẹ ki nwọn si s̩e is̩ẹ ti Ọlọrun yan silẹ fun wọn pẹlu ẹmi otitọ, igbesi aiye wọn ko si ni jasi asan. Ẹmi wọn yio mã dagba siwaju si, ni aworan ti Kristi : nwọn jẹ alabas̩is̩ẹ pẹlu Ọlọrun li aiye yi, bē̩ni a si sọ wọn di yiyẹ fun is̩ẹ ti o ga ju ati ayọ aiye ti mbọ ti o hàn kedere.IOK 60.6

    “Jesu kọ ọ si õkan aiya mi
    Pe iwọ ni ohun kanna ti o yẹ ki enia ni.
    Bi mo tilẹ yapa kuro ninu ohun gbogbo,
    S̩ugbọn nko le fi ọ silẹ lai.”
    IOK 61.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents