Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Jronupiwada

    Bawo ni enia yio s̩e le jẹ olõtọ si Ọlọrun? Bawo ni ẹlẹs̩ẹ yio s̩e di olododo? Afi nipa Kristi ni a fi le ni idapọ pẹlu Ọlọrun, ati iwa mimọ; s̩ugbọn bawo ni awa yio ti s̩ẹ le wa si ọdọ Kristi? Ọpọlọpọ li o mbere ibere yi gẹgẹbi ogunlọgọ ti se bẽre ni ọjọ Pentikọsti, nigbati nwọn mọ̀ ẹbi ẹs̩ẹ, nwọn kigbe wipe ; “Kini ki awa ki o se? Gbolohun akọkọ Peteru ni pe “RONUPIWADA”. Is̩e Aposteli 2:38. Ko pẹ lẹhin eyi, o wipe, “RONUPIWADA, ki ẹ si tun yipada, ki a le pa ẹs̩ẹ nyin rẹ.” Ise 2:38; 3:19.IOK 17.1

    Ikãnu fun ẹs̩ẹ nbẹ ninu Ironupiwada, ati yiyi kuro ni ọna rẹ̀. Awa ki yio le ko silẹ afi bi a ba ri aidara rẹ̀. O di igbati awa ba yi ọkan wa kuro lọna ẹs̩ẹ, ki iyipada pataki to wa si Igbesi aiye wa.IOK 17.2

    Ọpọlọpọ ni ironupiwada tõtọ ko ye. Ogunlọgọ nkãnu nitori ti nwọn ti s̩ẹ̀, ati pãpã nwọn a ma se atuns̩e ode ara, nitori nwọn bẹru pe iwa buburu wọn yio mu ijiya ba wọn. Sugbọn eyi ki s̩e ironupiwada ti Bibeli sọ. Nwọn nkãnu fun ijiya ju fun ẹs̩ẹ. Iru ibanujẹ Esau niyi nigbati o mọ pe ogun-ibi bọ kuro lọwọ on lailai. Balamu wariri nigbati o ri angẹli ti o duro ni ọna rẹ̀ pẹlu ida, O jẹwọ iwa buburu rẹ̀ ki o má bã ku ; s̩ugbọn ki se ironupiwada tõtọ fun ẹs̩ẹ ko si iyipada ninu ero, kò si ikorira fun iwa buburu. Lẹhin igbati Judasi Iskariotu ta Oluwa rẹ tan, o wipe. “Emi s̩ẹ li eyi ti mo fi ẹjẹ alais̩ẹ han.” Matt. 27:4.IOK 17.3

    Ibẹru idajọ ti mbọ ati ti idalẹbi li o mu ki iru ijẹwọ yi ti ọkan rẹ wa pẹlu agbara. Awọn ayọrisi ohun ti o s̩e mu u kun fun iberu s̩ugbọn ko si ibanuje ti o jinlẹ lati ọkan rẹ̀ wa pe, on ti fi Ọmọ Ọlọrun Ẹniti ko dẹs̩ẹ han, ati pe On ti s̩ẹ́ Ẹni Mimọ Israeli. Nigbati Farao njiya labẹ idajọ Ọlọrun, o jẹwọ ẹs̩ẹ rẹ ki o ba le bọ lọwọ ijiya ti o mbọ, lẹhin igbati a mu arun nwọnyi kuro, o tun bẹrẹ si is̩e ohun ti o lodi si ọrun. Gbogbo awọn nwọnyi ni wọn sọkun fun ère ẹs̩ẹ, s̩ugbọn wọn ko kãnu fun ẹs̩ẹ papa.IOK 17.4

    S̩ugbọn nigbati ọkan ba jọwọ ara rẹ̀ fun Emi Mimọ Ọlọrun, ẹri ọkan yio sọji, ẹlẹs̩ẹ yio mọ ijinlẹ iwa Mimọ ofin Ọlọ- run, ati ipilẹ ijọba Rẹ̀ ni ọrun ati ni aiye. “Imọle otitọ ti ntan imọlẹ fun olukuluku enia ti o wa si aiye,” (Johannu 1:9) ntan imọlẹ si kọrọ ọkan, awọn ohun ikọkọ li o si farahan. Iyipada a ma bẹrẹ ninu ero ati ọkan. Ẹlẹs̩ẹ yio ni imọ ododo ti Olugbala, a si bẹru lati farahan ninu ẹbi ati iwa ẽri rẹ, niwaju ẹniti nse awari ọkan. On yio ri ifẹ Ọlọrun, ẹwa iwa Mimọ, ayọ iwa pipe, iwẹnumọ yio mã wù u, yio si fẹ imupada si idapọ pẹlu Ọrun.IOK 17.5

    Adura ti Dafidi gba lẹhin is̩ubu rẹ̀ fihanni gbangba ohun ti ikãnu fun ẹs̩ẹ jẹ. Ironupiwada rẹ̀ daju o si jinlẹ. Ko si s̩e awawi fun as̩is̩e rẹ̀; ko gbiyanju lati bọ lọwọ idajọ rẹ̀ bi o ti s̩e ngbadura kikan. Dafidi ri ibajẹ ọkan rẹ̀, o si korira ẹs̩ẹ rẹ̀. Ko gbadura fun idariji nikan s̩ugbọn fun ọkan mimọ.IOK 19.1

    O nwoye fun ayọ iwaMimọ lati pada sinu idọgba ati irẹpọ pẹlu Ọlọrun. Eyi ni asaro ọkan rẹ̀.”IOK 19.2

    “Ibukun ni fun awọn ti a dari irekọja wọn ji, ti a si bo ẹs̩ẹ wọn mọlẹ. Ibukun ni fun ọkunrin na eniti Õluwa ko ka ẹs̩ẹ si lọrun, ati ninu ẹmi ẹniti ẹtan ko si.” Dafidi 32:1, 2.IOK 19.3

    Ọlọrun, s̩ãnu fun mi. gẹgẹbi is̩eun ifẹ rẹ; gẹgẹbi irọnu opọ ãnu re, nu irekọja mi nu kuro. Nitoriti mo jẹwo irekọja mi: nigbagbogbo ni ẹs̩ẹ mi si mbẹ niwaju mi. Fi ewehissọpu fọ mi, emi o si mọ; wẹ mi, emi o si fún ju ẹ̀gbọn owu lo.IOK 19.4

    Da aiya titun sinu mi, Ọlọrun, ki o si tun ọkan didurosinsin s̩e sinu mi. Mase s̩a mi ti kuro niwaju rẹ; ki o ma si se gba Ẹmi Mimọ re lọwọ mi. Mu ayọ igbala rẹ pada tọ mi wa ; ki o si fi ẹmi Omnira rẹ gbe mi duro. Ọlọrun gba mi lowo ẹbi ẹje, Iwo Ọlọrun Igbala mi : ahọn mi yio ma kọrin ododo rẹ kikan.” Dafidi 51:1-14. Iru ironupiwada yi ju agbara wa lọ ni s̩is̩e, lati ọdo Kristi nikan ni a ti le ri gba, Ẹni ti o ti goke re orun, ti o si ti fi awọn ẹbun fun enia.IOK 19.5

    Lori evi gãn ni ọpolọpọ ti ndesẹ, nwon a si baku lati gba iranlọwo ti Kristi fẹ fun wọn. Nwọn ro pe awọn ko le wa si ọdo Kristi afi bi wọn ba kokọ ronupiwada, ati wipe ironupiwada ni vio mu won setan fun idariji ese won. Otitọ ni pe ironupiwada ni sãju idariji awọn ẹs̩ẹ; nitoripe irobinujẹ ati irẹlẹ ọkan ni o le mu ki a wa Olugbala. Sugbọn elẹsẹ ha gbọdọ duro titi yio fi ronupiwada ki o to le wa sọdọ Jesu? Ironupwada ha gbọdọ jẹ ohun idena lãrin ẹlẹẹẹ ati Olugbala?IOK 19.6

    Bibeli ko kó ni pe elese ni lati ronupiwada ki o to gba ipe ti Kristi, “Ẹ wa sọdọ mi gbogbo ẹnyin ti ns̩is̩ẹ ti a si di ẹru wuwo le lori, emi o si fun nyin ni isimi.” Matteu 11:28. Iwa pipe ti o nti ọdọ Kristi jade li o nmu wa mọ ironupiwada pipe. Peteru fiye ni gbangba ni isọrọ rẹ̀ si awọn ọmọ lsraeli nigbati o wipe, “On ni Ọlọrun fi ọwọ ọtun Rẹ̀ gbega lati jẹ ọmọ alade ati Olugbala, lati fi ironupiwada fun Israeli, ati idariji ẹs̩ẹ.” Ise Aposteli 5:31. Awa ko le ni ironupiwada laisi Emi ti Kristi lati mu ẹri ọkan sọji, bẹni ko le si idariji laisi Kristi.IOK 19.7

    Kristi ni orisun gbogbo ero rere. On nikan li o le fi ọta sãrin ẹs̩ẹ ati ọkan wa. Gbogbo ifẹ otitọ ati iwa mimọ, gbogbo mimọ ẹbi ẹs̩ẹ wa, nfihan wipe Ẹmi Mimọ Rẹ̀ nẹis̩ẹ ninu ọkan wa.IOK 20.1

    Jesu wipe, “ati emi, bi a ba gbe mi soke kuro ni aiye, emi o fa gbogbo enia sọdọ ara mi.” Johannu 12:32. A nilati fi Kristi han gẹgẹbi Olugbala ti o ti ku fun ẹs̩ẹ ti aiye; ati bi awa ti nwo ọdọ-agutan Ọlọrun lori agbelebu ni Kalfari, ijinlẹ irapada bẹrẹ farahan ninu ero wa, õre Ọlọrun a si sin wa lọ si Ironupiwada. Ni kiku fun awọn ẹlẹs̩ẹ Kristi fi awamaridi ifẹ rẹ̀, han ; ni igbati ẹlẹs̩ẹ ba si nwo ifẹ yi O nsọ ọkan di rirọ, o wọni-lọkan o si nmu iyipada ba ọkan.IOK 20.2

    Õtọ ni pe ọna awọn ẹlẹs̩ẹ mà nmu itiju ba wọn, nigbamiran, nwọn a si fi diẹ ninu iwa buburu wọn silẹ, ki nwọn to mọ wipe Kristi ni o nrọ̀ wọn gãn a. Nigbakigba ti nwọn ba gbiyanju lati s̩e atuns̩e ati lati ni ifẹ ati ẹe ohun ti o tọ́, agbara Oluwa li o nfa wọn. Agbara ti wọn ko nãni ns̩is̩ẹ ninu wọn, iye inu wọn a sọji, atuns̩e a si wa ni ode ara wọn. Bi Kristi si ti nrọ̀ wọn lati wo agbelebu Rẹ̀, ati lati wo On Ẹniti ẹs̩ẹ wọn ti pa lara, ofin nã a wa sinu ero ọkan wọn. Iwa buburu Igbesi aiye wọn, ẹs̩ẹ ti o ti jinlẹ ni inu ọkan, a si hàn si wọn gbangba. Nigbati wọn ba si woye ododo Kristi, wọn a wipe, — “kini ẹs̩ẹ, ti o nilati gba irubọ nla fun irapada ẹniti o dẹs̩ẹ? Eyi ha is̩e ifẹ, ati ijiya, ati irẹlẹ ọkan, ti a bere lọwọ wa ki a ma ba s̩e s̩egbe, s̩ugbọn ki a le ni iye-ainipẹkun?”IOK 20.3

    Ẹlẹs̩ẹ le kọ ifẹ yi, o le kọ lati wa sọdọ Kristi; s̩ugbọn bi ko ba kọ ao fa a wa sọdọ Jesu ; imọ nipa ilana igbala yio mu u wa si ẹsẹ agbelebu fun ironupiwada ẹs̩ẹ rẹ, eyi ti o ti mu ijiya ba ọmọ Ọlọrun.IOK 20.4

    Ọkan mimọ kanna ti ns̩is̩ẹ lori awọn ohun ẹda ni o nba ọkan awọn enia sọrọ, on ni o si nmu ki wọn s̩e afẹri nla fun ohun ti nwọn ko ni. Ohun ti aiye ko le tẹ ifẹ wọn lọrun. Ẹmi Ọlọrun ni mbẹ wọn lati mã wá awọn nkan wọnni ti o le funni ni alafia ati isimi, ore-ọfẹ Krsti, ati ayọ iwa mimọ. Nipa agbara ti a ri ati eyiti a ko ri, nigbagbogbo ni Olugbala wa ns̩is̩ẹ lati fa ero enia kuro ninu fãji ẹs̩ẹ ti ki tẹnilọrun si awọn ibukun ti yio jẹ ti wọn ninu Rẹ̀. Fun gbogbo ọkan wọnyi, ti nlakaka lati mu omi ninu kanga gbigbẹ aiye yi, ni is̩ẹ ọrún yi wa fun pe “ati ẹniti ongbẹ ngbẹ ki o wa. Ẹmkẹni ti o ba si fẹ ki o gba omi iye na lọfẹ.” Ifihan 22:17.IOK 20.5

    Iwọ ẹniti nfẹ ninu ọkan rẹ ohun ti o dara ju ohun ti aiye yi le fifunni lọ, mọ̀ ifẹ yi gẹgẹbi ohùn Ọlọrun si ọkan rẹ. Bere lọwọ Rẹ̀ ki o fun ọ ni ironupiwada, lati le fi Kristi han ọ ninu titobi ifẹ Rẹ̀, ati ninu iwa pipe Rẹ̀. Ninu Igbesi aiye Òlugbala, ipilẹ ofin Ọlọrun-ifẹ si Ọlọrun ati enia — ni a fi han gbangba. Inurere ati ikonimọra, ni iye fun ọkan Rẹ̀. Afi bi a ba wo o gẹgẹbi imọlẹ lati ọdọ Olugbala wa ti nmọlẹ sori wa ni a to le ri gẹgẹbi ọkan wa ti kun fun ẹs̩ẹ to.IOK 21.1

    Awa ti le gbe ara wa ni iyi, gẹgẹbi Nikodemu ti se, wipe igbesi aiye wa ti jẹ pipe, iwa wa si ti yege, ki awa si ro pe ko tun yẹ fun wa lati rẹ ọkan wa silẹ niwaju Ọlọrun, gẹgẹbi otos̩i-ẹlẹs̩ẹ s̩ugbọn nigbati imọlẹ Kristi ba ntan si ọkan wa nigbana ni awa yio ri ipo aimọ wa; awa yio si ri iwa imọtara-ẹni wa, ati ọtẹ si Ọlọrun, ti o ti ba iwa igbesi-aiye wa jẹ. Nigbana ni a o mọ pe ododo ti-ara-wa bi akisa ẹlẹgbin ni, ati pe ẹjẹ Kristi nikan ni o le wẹ wa mọ kuro ninu ibajẹ ẹs̩ẹ, ti o si le sọ ọkan wa di titun gẹgẹbi irisi on pãpã.IOK 21.2

    Itans̩an ogo Ọlọrun, ati didan iwa pipe ti Kristi, ti nwọ inu ọkan lọ, sọ gbogbo alẽbu wa di hihan gbangba, a si s̩i ibi alẽbu ati abùkù iwa enia si kedere. A mã fi gbogbo awọn ohun aimọ ti a fẹ, aigbagbọ ọkan, ati awọn isọkusọ ti nti ẹnu wa jade han wa. Aibọwọ ati aibikita awọn ẹlẹs̩ẹ fun ofin Ọlọrun a si wã han gbangba ni oju ẹlẹs̩ẹ, ẹmi rẹ a dãmu a si wariri labẹ agbara Ẹmi Ọlọrun ti ns̩e awari. On a korira ara rẹ̀ nigbati o ba nwò pipe, ati ailabùkù iwa Kristi.IOK 21.3

    Nigbati Woli Danieli ri ogo ti o yi iransẹ Ọrun ti a ran si i ka, imoye ailera ati aipe on funrarẹ da a lagara. Nigbati o s̩e apejuwe ohun iyanu ti o ri, o wipe, “Ko si ku agbara ninu mi : ẹwa mi si yipada lara mi di ibajẹ, emi ko si lagbara mọ.” Danieli 10:8. Ọkan ti0 a ba sọji bayi yio korira imọti-ara-eni re, yio si mã s̩e afẹri iwa mimo ọkan ti o ni idapọ pẹlu ofin Ọlọrun ati iwa Kristi nipa ododo Rè.IOK 21.4

    Paul wipe, “niti ododo ti o wa ninu ofin” — ati gẹgẹ bi iwa ti ode ara, o wipe “mo jẹ alailẹgan.” Fillipi. 3:6; sugbọn nigbati iwa ti Ẹmi nipa ti ofin farahan, o mọ ara rẹ li ẹlẹs̩ẹ. Ti a ba sọ nipa ọrọ ti ofin gẹgẹbi ti iwa ẹda enia, O jẹ alais̩ẹ; s̩ugbọn nigbati o nwo jinjin ti ofin mimọ, ti o si ri ara rẹ gẹgẹbi Ọlọrun ti ri i, o kunlẹ pẹlu irẹlẹ, o si jẹwọ iwa buburu rẹ̀. O wipe, “Emi si ti wa lãye laisi ofin ni igbakan ri, sugbọn nigbati ofin de, ẹs̩ẹ sọji, emi si ku.” Romu 7:9. Nigbati o ri iwa ẹda ti ọfin, ẹs̩ẹ farahan laisi iboju, igberaga rẹ̀ si fo lọ.IOK 21.5

    Ọlọrun ko ka awọn ẹs̩ẹ si Iwọn kanna ; gbogbo ẹs̩ẹ li o ni osuwọn loju Rẹ̀ ati loju awa enia pãpã, sugbọn sibẹsibẹ bi o tilẹ jẹpe ẹs̩ẹ miran a mã kere loju enia, ko si ẹs̩ẹ ti o kere ni iwaju Ọlọrun. Ais̩õtọ ati aipe wá ninu idajọ ti enia; s̩ugbọn Ọlọrun a mã diwọn ohun gbogbo gẹgẹbi nwọn ti ri gãn. A kẹgan ọmuti, a si sọ fun wipe ẹs̩ẹ yio mu kuna ijọba Ọlọrun, nigbati igberaga, imọ-tara-ẹni, ati ojukokoro nlọ siwaju laisi ibawi. Awọn ẹs̩ẹ wọnyi jẹ eyi ti nbi Ọlọrun ninu; nitori wọn lodi si ifẹ inurere Rẹ̀, ati si ayika aiye ti ko dẹs̩ẹ. Ẹniti o ba da ẹs̩ẹ nla le mọ̀ itiju rẹ̀, os̩i rẹ̀ ati aini rẹ̀ fun õre ọfẹ Krsti : s̩ugbọn igberaga ko mọ aini yi, a si ma se ilẹkun ọkan mọ́ Kristi ati ibukim ailopin ti O wa lati funni.IOK 22.1

    Agbowode ti o gbadura pe, “Ọlọrun s̩ãnu fun mi, emi ẹlẹs̩ẹ.” (Luku 18:13), ka ara rẹ̀ si ẹni buburu julọ, awọn enia si nwõ bē̩ ẹ ; s̩ugbọn o mọ aini rẹ̀ o si wa siwaju Ọlọrun pẹlu ẹru ẹs̩ẹ rẹ̀ ati itiju, o mbere fun ãnu Rẹ̀. O ti s̩i ilẹkun ọkan rẹ̀ silẹ fun Ẹmi Oluwa lati s̩e is̩ẹ Ore-ọfẹ Rẹ̀, ati ki o ba le mu ki o bọ lọwọ agbara ẹs̩ẹ. Adura igberaga ti Farisi fihàn kedere pe agbara Ẹmi Mimọ kò lè ri aye ninú ọkan rẹ. Nitoriti o jinna si Ọlọrun, ko si mọ riri ẹru ẹbi ẹs̩ẹ rẹ̀, yatọ si pipe Ẹmi Ọrun. Gbogbo nkan ni o ti tẹ ẹ lọrun. Ko si ri nkankan gba mọIOK 22.2

    Bi iwọ ba mọ titobi ẹs̩ẹ rẹ, mas̩e pẹ lati s̩e atuns̩e. Enia melo ni o wa ti wọn ro pe awọn ko mọ tó lati tọ Kristi lọ. Njẹ iwọ ha le di pipe nipa agbara ara rẹ? “Ara Etiopia le yi awọ rẹ̀ pada, tabi ẹkun le yi ila rẹ̀ pada? bē̩ni ẹnyin pẹlu iba le s̩e rere, ẹnyin ti a kọ ni iwa buburu.” Jeremiah 13:23. Lati ọwọ Ọlọrun nikan ni a ti le ri iranlọwọ gbà. Awa ko nilati duro de iyipada ọkan ti o lagbara miran, tabi fun ãye miran, tabi ọkan pipe. Awa ko le s̩e nkankan nipa agbara ara wa. A nilati wa sọdọ Kristi ni ipo ti a wa gãn.IOK 22.3

    Ki ẹnikẹni mas̩e tan ara rẹ̀ jẹ ninu ero rẹ pe Ọlọrun, ninu ifẹ nla ati ore-ọfẹ Rẹ̀, yio gba awọn ti wọn tilẹ kọ õreọfẹ Rẹ̀ silẹ la. Ninu imọlẹ agbelebu nikan s̩os̩o ni a ti le mọ buburu ẹs̩ẹ. Nigbati awọn enia ba ntẹnu mọ́ wipe Ifẹ Ọlọrun pọ tobē̩ ti On ko fi le ta ẹlẹs̩ẹ nù, jẹki wọn ranti Kalfari. Nitori ọna miran ko si ti awa fi le ni igbala, ati nitoripe laisi irubọ yi, ko s̩ẽs̩ẽ fun ẹda lai le bọ lọwọ agbara ẹs̩ẹ, ki o si ni idapọ pẹlu awọn Mimọ,—ko tun le s̩ẽs̩ẽ fun wọn lati jẹ alabapin igbe-aiye nipa ti ẹmi,—nitori idi eyi ni Kristi pãpã fi ru ẹbi ti awọn alaigbọran, ti o si jiya dipò ẹlẹs̩ẹ. Gbogbo ijiya ati iku Ọmọ Ọlọrun li o nfihan bi ẹs̩ẹ ti buru to, o si nfihan pe ko si ajabọ ninu agbara rẹ̀, ko si ireti fun aiye ti mbọ, afi nipa jijọwọ ọkan wa fun Kristi.IOK 22.4

    Awọn alaironupiwada a mã wi nipa awọn onigbagbọ bē̩bē̩ nigbamiran pe, “Emi na pe to wọn. Awọn na ko le sera-wọn, tabi wà lairekọja, tabi jẹ olus̩ọra ju temi nã lọ. Nwọn fẹ afẹ ati fãji bi ti emi na.” Bayi ni wọn mã nfi as̩is̩e awọn ẹlomiran s̩e awawi fun ikọsilẹ is̩ẹ tiwọn. S̩ugbọn ẹs̩ẹ ati as̩is̩e awọn ẹlomiran ko dá ẹnikẹni lare; nitori Oluwa ko fi enia ẹlẹs̩ẹ s̩e apẹrẹ wa. Ọmọ Ọlọrun ti ko labawọn ni O fi fun wa fun apẹrẹ, awọn ti wọn ns̩e awawi nipa as̩is̩e awọn afẹnujẹ-onigbagbọ li o nilati fi apẹrẹ ti o dara ti o si lọla ju han. Bi o ba jẹ pe nwọn ni ero giga nipa ohun ti onigbagbọ nilati jẹ tobẹ, njẹ ẹs̩ẹ ti wọn ko ha pọ ju? Nwọn mọ ohun ti o yẹ, sibẹ nwọn kọ lati s̩ẽ.IOK 24.1

    Ijafara lewu. Maẹe fi is̩ẹ ati kọ awọn ẹs̩ẹ rẹ silẹ, ki o si mã wa ọkàn pipe ninu Jesu. Lọna yi ni ẹgbẹgbẹrun lọna ẹgbẹgbẹrun ti s̩ìna, si iparun ara wọn. Emi ko fẹ tẹnumọ kikuru ati aidaniloju igbesi aiye; s̩ugbọn ewu nla kan wa. ewu eyiti ko ye wa tobẹ-nipa jijafara lati fi ara wa fun Oluwa nigbati Ẹmi Mimọ mba nrọ wa, ni yiyan lati mã gbe inu ẹs̩ẹ; nitori bē̩ li ewu ijafara jẹ gãn. Ẹs̩ẹ, bi-o-ti-wu ki o kere to, o le mu ewu nla ba wa ti a ko ba kọ ọ silẹ. Ohun ti a ko ba s̩ẹgun ni yio s̩ẹgun wa, ti yio si s̩is̩ẹ iparun wa.IOK 24.2

    Adamu ati Efa dun ara wọn ninu pe nipa jijẹ eso igi imọ-rere ati buburu kọ le si iru amuwa ti Ọlọrun ti sọ. Ọran kekere yi jẹ riru ofin mimọ Ọlọrun ti ko le yipada, o si mu wa yapa kuro lọdọ Ọlọrun, o si si ilekun fun iku ati fun egbé ti a ko le fẹnusọ sori aiye wa yi. Igba de igba ti kọja ninu eyiti igbe ati ipohunrere ẹkun ti wà laidakẹ, gbogbo awọn ẹda ns̩ọfọ nwọn si nrọbi ninu irora fun amuwa aigboran enia. Ọrun pãpã mọ nipa ayọrisi ọtẹ si Ọlọrun, Kalfari duro fun iranti irubọ ti o yanilẹnu fun etutu riru ofin Mimọ na. Ẹ mas̩e jẹki a ka ẹs̩ẹ si ohun kekere rara.IOK 24.3

    Gbogbo iwa riru ofin. gbogbo aikasi tabi kiko ore-ọfẹ Kristi, li o ns̩is̩ẹ lara iwọ pãpã, o nmu ọkan le, o nbà ifẹ jẹ, o npa ero ku, ki isi se pe o nmu ki a mã dinku ninu ifẹ wa lati jọwọ ara wa lọwọ nikan. sugbon o nmu agbara ati jọwọ ara wa lọwọ fun ẹ̀bẹ̀ ti Ẹmi Mimọ Ọlọrun pẹlu wa dinku.IOK 24.4

    Ọpọlọpọ ni o ndun ara wọn ninu nipa riro pe awọn le yi ọna buburu awọn pada nigbati awọn ba fẹ ; pe wọn le fi ipe ãnu s̩ire ki nwọn si mã gbọ ohùn ipe sibẹ sibẹ. Nwọn ro pe lẹhin ti nwọn ba ti tapa si ore-ọfẹ, lẹhin igbati igbẹkẹle wọn ba ti wa lọdọ es̩u, ni akoko na gan awọn le yipada. Eyi ko rọrun lati s̩e. Iriri, ẹkọ, ti is̩e ti gbogbo igbe-aiye wọn ti s̩e iwa wọn ni ọna ti o jẹ pe diẹ ninu wọn ni o tun ni ifẹ ati gba aworan Jesu.IOK 25.1

    Ani aidã kan s̩os̩o ninu iwa, ifẹ ohun ẹs̩ẹ ti a mã nwa nigbagbogbo, yio sọ agbara ti ihinrere di ainilari. Gbogbo ọna ẹs̩ẹ ni mã ya ọkan nipa kuro lọdọ Ọlọrun. Ẹniti o fi ọkan aigbagbọ lile, tabi ti o se alainãni otitọ, o nkore nkan ti o ti gbin ni. Ninu gbogbo Iwe Mimọ ko si ọrọ ikilọ ti o bani-lẹru lati mã fi buburu s̩ire ju ọrọ ọlọgbọn ni lọ, ti o wipe, “Ẹs̩ẹ ẹni buburu ni yio mu ontikararẹ.” Owe 5:22.IOK 25.2

    Kristi s̩etan lati gba wa kuro lọwọ ẹs̩ẹ, s̩ugbọn On ki yio mu wa pẹlu agbara ; bi o ba jẹpe nipa didẹs̩ẹ nigbakugba ifẹ wa a mã fà si ati s̩e ibi, ti a kò ba si fẹ ki a da wa n’ìde bi awa ba si kọ õre-ọfẹ Rẹ̀, kini On tun le s̩e fun wa ? Awa ti pa ara wa run nipa kikọ̀ ifẹ Rẹ̀ dele. “Kiyesi, nisisiyi ni akoko itẹwọgba; kiyesi i, nisisiyi ni ọjọ igbala.” “Loni bi ẹnyin ba gbọ ohun Rẹ̀, ẹ mas̩e sé ọkan nyin le.” II Kọrinti 6:2; Heberu 3:7, 8.IOK 26.1

    “Enia a mã wo oju, Oluwa a mã wo ọkan,” (I Samuel 16:7) ani ọkan enia, pẹlu ijakadi ayọ ati ibanujẹ rẹ̀; ọkan is̩ako ati aigbọran ni is̩e ibugbe àimọ́ ati ẹ̀tan gbogbo. Kristi mọ ero-inu ati ete ọkan. Lọ si ọdọ Rẹ̀ pẹlu gbogbo abawọn ẹs̩ẹ ọkan rẹ. Gẹgẹbi Olorin ti wi, s̩i ilẹkun agbala ọkan rẹ silẹ si ẹniti o ri ohun gbogbo, wipe, “Ọlọrun wadi mi, ki o si mọ aiya mi. Dan mi wo, ki o si mọ erọ inu mi: ki o si wo bi ipa-ọna buburu kan ba wa ninu mi, ki ọ si fi ẹsẹ mi le ọna ainipẹkun.” Orin Dafidi 139:23, 24.IOK 26.2

    Ọpọ ni o gba igbagbọ li agba-sori, afarawe iwa bi-Ọlọrun nigbati ọkan jẹ kiki ẹgbin. Jẹki eyi jẹ adura rẹ, “Da aiya titun sinu mi Ọlọrun, ki o si tun ọkan diduro-s̩ins̩in s̩e sinu mi.” Dafidi 51:10. Jẹ olotitọ si ọkan ara rẹ. Ni itara ati ifarada gẹgẹbi iwọ yio ti s̩e bi igbesi aiye rẹ ba wà ninu ewu. Eyi wa fun ipinnu lãrin Ọlọrun ati ọkan rẹ, ti a pinnu titi lai. Ireti bē̩bē̩, laisi nkan miran ni yio mu iparun ba ọ.IOK 26.3

    Mã kọ́ ọrọ Ọlọrun pẹlu adura. Ọrọ ti a gbe ka iwaju rẹ, ninu ofin Ọlọrun ati igbesi aiye ti Kristi, ipilẹ ìwà Mimọ, eyi ti o jẹ wipe lasi rẹ̀ “ko si ẹniti yio ri Oluwa.” Heberu 12:14. O fi ẹs̩ẹ han ; o nfi ọna igbala han kerede. Tẹtì silẹ si i, gẹgẹbi ohun Ọlọrun ti mba ọkan rẹ sọrọ.IOK 26.4

    Nigbati o ba mọ riri ẹsẹ rẹ nigbati o ba ri ara rẹ gãn gẹgẹbi o ti ri, mase so ireti nu. Nitoripe awọn ẹlẹs̩e nã ni Kristi wa lati gbala. Ki s̩epe awa mba Olọrun laja fun ara wa. A! ife iyanu! Ọlọrun ninu Kristi li “O mba araiye laja sodo ara Rẹ̀.” II Korinti 5:19. O nro ọkan as̩ako awọn ọmọ rẹ̀ nipa ifẹ Rẹ̀. Ko si obi kan li aiye ti o le ni suru niti ẹbi ati as̩is̩e awọn omọ rẹ̀, gẹgẹbi Ọlọrun ti se fun awọn asako ti On nwa ona lati gbala. Ko si ẹniti o le fi ifẹ rọ̀ ẹlẹs̩ẹ bi tirè Ko si ẹnu ẹda kan ti o ti bẹbẹ fun asako gegẹ bi ti Kristi ri. Gbogbo awọn ileri Rẹ̀, awọn ikilọ Rẹ̀, li o jẹ nipa ti ifẹ ti ẹnu ko le sọIOK 26.5

    Nigbati es̩u ba sọ fun ọ pe ẹlẹs̩ẹ gãn ni ọ, gbe oju rẹ soke si Oludande rẹ, so nipa awọn itoye Rẹ. Ohun ti yio ran ọ lọwọ ni lati wo imọlẹ Rẹ̀. Jẹwọ ẹs̩ẹ rẹ, s̩ugbọn sọ fun ọta pe, “Kristi Jesu wa si aiye lati gba ẹlẹss̩ẹ la.” (I Timoteu 1:15.) ati pe a o gba ọ la nipa ifẹ Rẹ̀ ti ko lẹgbẹ. Jesu bi Simoni ni ibere kan nipa ti awọn ajigbese meji. Ẹnikan jẹ Õluwa rẹ ni gbese diẹ, ẹnikeji si jẹ ẹ ni eyiti o pọ; s̩ugbọn O dariji awọn mejẽji, Kristi bi Simoni lere pe tani yio fẹran Oluwa wọn julọ ninu awọn ajigbese wọnyi. Simoni dahun wipe, “Mo s̩ebi, ẹniti o dariji ju ni.” Luku 7:43. Awa ti jẹ ẹlẹs̩ẹ nla, s̩ugbọn Kristi ku ki awa ba le ni idariji. Itoye irubọ Rẹ̀ ti to lati fihan Baba nitori tiwa. Awọn ti a dariji lọpọ ni yio fẹran Rẹ̀ ju, awọn ni yio sunmọ itosi itẹ Rẹ̀ lati yin I, nitori ifẹ nla ati irubọ Rẹ̀ ti ko ni iwọn. O di igbati a ba mọ ifẹ Ọlọrun ni kikun ki a to mọ buburu ẹs̩ẹ. Nigbati a ba mọ irubọ nla ti Kristi s̩e nitori tiwa, ọkan wa yio si kun fun iwa pẹlẹ ati ironupiwada.IOK 27.1

    1. Atupa ti nfọna han wa
    Ki awa ma sina;
    Òre-ọfẹ ti nt’ ọrun wa;
    Ti ns̩an si ọna arinrin ajo

    2. Onjẹ ọkan wa ti a fi nbọwa;
    Manna tõtọ lati ọrun;
    Olutọna wa ati aworan ti nfi
    Ijọba ọrun han wa.

    3. Okuta Ina ti ns’ okunkun lọkankan
    Ati awọsanma didan l’ ọsan
    Nigbati igbi lori ọkọ omi wa
    Idakọro wa ati iduro wa.

    4. “Ọrọ Ọlọrun wa lailai,
    Ifẹ Ọmọ Rẹ̀ ti o l’ogo;
    Laisi rẹ bawo ni aiye s̩e le wa
    Tabi lati jere ọrun?”
    IOK 27.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents