Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ayọ ninu Oluwa

    A pe awọn ọmọ Ọlọrun lati jẹ as̩oju Kristi ni fifi õre ati ãnu Oluwa hãn. Gẹgẹbi Jesu ti se fi otitọ iwa Baba hàn wa, bakannã ni awa nã ni lati fi Kristi hàn araiye ti ko mọ nipa ifẹ ati ãnu Rẹ̀. Jesu wipe, “Gẹgẹbi Iwọ ti ran mi wa si aiye, bē̩li emi si ran wọn si aiye pẹlu.” “Emi ninu wọn ati iwọ ninu mi. . . ki araiye ba le mọ pe Iwọ li o ran mi ;” (Johannu 17:18, 23.) Aposteli Paulu sọ fun gbogbo onigbagbọ pe, “Bi a ti fi nyin hàn pe, iwe Kristi ni nyin” “ti gbogbo enia si ka.” 2 Korinti 3:3, 2. Jesu ran iwe kọkan si aiye ninu olukuluku ọmọ Rẹ̀. Bi iwọ ba jẹ atẹlẹ Kristi, O fi iwe kan sọwọ ninu rẹ si idile rẹ, ileto rẹ, ati opópo ita rẹ, nibiti iwọ ngbe. Nigbati Jesu ba ngbe inu rẹ, O fẹ ti ipasẹ rẹ ba awọn wọnni ti ko ti mọ Ọ sọrọ. Bọya nwọn ki i ka Bibeli, tabi gbọ ohùn ti mba wọn sọrọ lati inu Iwe Mimọ, nwọn ki si sakiyesi ifẹ Ọlọrun nipa awọn is̩ẹ Rẹ̀. S̩ugbọn bi o ba jẹ as̩oju Jesu nitõtọ, o le jẹ nipasẹ rẹ ni nwọn yio ti ni imọ nipa õre Rẹ̀, ti nwọn yio si ma di ẹniti o fẹran Rẹ̀, ti yio si mã sin I.IOK 85.1

    A gbe awọn onigbagbọ ka lẹ gẹgẹbi olufunni ni imọlẹ li oju ọna ti o lọ si ọrun. Nwọn ni lati fi imọlẹ ti ntan si wọn lati ọdọ Kristi han araiye. Igbe aiye ati iwa wọn ni lati jẹ eyoiti yio mu awọn ẹlomiran ni imo-rere nipa Kristi ati isin Rẹ̀.IOK 85.2

    Bi awa ba jẹ as̩oju Kristi nitõtọ, a o jẹki isin Rẹ fanimọra gẹgẹbi o ti jasi nitõtọ. Awọn onigbagbọ ti nkojọpọpẹlu ọkan wuwo ati ikùnsinu jasi ẹniti nfi Ọlọrun hàn araiye li ọna ti o lodi si igbagbọ Kristi. Nwọn fihan fun araiye pe Ọlọrun ko ni inudidun si ayọ awọn ọmọ Rẹ̀, nipa s̩is̩ebē̩ nwọn jẹri eke si Baba wa ọrun.IOK 85.3

    Inu Satani amã dun nigbati o ba ti le mu awọn ọmọ Ọlọrun siyemeji tabi sọ ireti nu. A ma yọ nigbati o ba ti ri pe a kò gbekẹle Ọlorun ti a si ns̩iyemeji ifẹ ati agbara Rẹ̀ lati gba wa là. A mã fẹ mu wa ro pe Ọlọrun fẹ s̩e wa nibi nipa awọn ilana Rẹ̀. Is̩ẹ Satanni lati mã fi Jesu han bi ẹniti ko ni inurere ati ãnu, A ma tumọ̀ otitọ nipa Rẹ̀ s’òdi. O mu ninu otitọ ti Baba wa ọrun, igbà pupọ ni a nfi ọkan si arekereke ti Es̩u, ti a si ns̩aibọwọ fun Ọlọrun nipa s̩is̩e iyemeji ati kikun si I. Satan ngbiyanju nigbagbogbo lati da as̩ọ ọfọ bò isin Ọlọrun lori. O fẹ lati mã mu ki isin Ọlọrun farahan bi ohun is̩oro ati ohun ti ndani-lagara; nigbati atẹle Kristi ba si fi iru oju bẹ wa sin I, ti o si s̩e alaigbagbọ mọ, o ngbè irọ Es̩u lẹsẹ̀ ni.IOK 85.4

    Ọpọlọpọ, ti nrin li ọna igbe-aiye, ni nro nipa as̩is̩e wọn ati ireti wọn ti o s̩aki, ọkan wọn a si kun fun ibanujẹ ati ifoiya. Nigbati mo wa ni ilu awọn Gē̩hi, arabirin kan ti o wà ni iru ipo ibọkanjẹ bayi, kọwe simi, o nfẹ ọrọ iyanju. Ni oru ọjọ keji ti mo ka iwe rẹ̀, mo la ala pe mo wa ninu ọgba kan, ẹniti o si dabi ẹnipe on lo ni ọgba nã bẹrẹ si mu mi rin awọn oju ọna ti o wa ninu rẹ̀. Mo bẹrẹ si já awọn ododo, mo si ngbọ õrun didun wọn, nigbati arabinrin yi ti o nrin lẹgbẹ mi, pe mi lati se afiyesi awọn ẹgun to farasin ti ndi on lọna. Nibẹ li o wa, ti nkãnu pẹlu ibinujẹ ọkan. On ko mã rin li oju ọna na ki o si mã tọ amọna lẹhin gán, s̩ugbọn o rin larin ẹ̀gun. Bayi ni o bẹrẹ si kanú pe, “A! Ko ha s̩e-ni lanu lati ri pe ẹ̀gun ti ba ọgba daradara yi jẹ.” Nigbanã ni amọna dahun pe, “Fi awọn ẹgun silẹ ki nwọn má bá pa ọ lara. Sa mã ko ododo, lili, ati pinki jọ.”IOK 86.1

    Ko ha ti si ohun rere kan ninu iriri rẹ li aiye? Ko ha ti si akoko kan ti ọkan rẹ kun fun ayọ ni idahun si ohun ti Ẹmi Ọlọrun? Bi o ti nronu nipa iriri igbe-aiye rẹ, iwọ ko ha ti ri awọn oju iwe to dun mọ ọ ninu? Awọn ileri Ọlọrun, ko ha dabi awọn itanna olõran didun, ti ndagba lẹbẹba oju ọna re li aiye? Iwọ ki yio ha jẹki õrun didun wọn ati ẹwa wọn, fi ayọ kun ọkan rẹ?IOK 86.2

    Egún ati os̩ùsú yio sa mã bà o lọkan jẹ ni bi o ba si jẹ pe kiki wọn li o nko jọ ti o si nfi fun awọn ẹlomiran, lẹhin pe iwọ tikarararẹ ka õre Ọlorun-si lasan. iwọ ko ha jẹ idiwọ fun awọn miran ti iba mã rin loju ọna iyè?IOK 86.3

    Kò dara lati mã kó awọn ohun ti kò dara ninu igbe-aiye wa jo nigbagbogbo, awon ẹs̩e ati ikùna inu rẹ — lati mã sọrọ nina wọn ati lati ma kãnu le won lori nigbagbogbo tobē̩ ti ifoiya won o fi bori wa. Ọkan irẹwẹsi kun fun okunkun, ti o ntari imolẹ Olọrun jade ninu re, ti o si nmu ojiji wa si ọna awọn elomiran.IOK 86.4

    A dupe fun aworan didan ti Olorun fifun wa. Ẹ jẹki a pa awon idaniloju ti o ni ibukun ti ife Rè po sokan. ki a le mã wọ wọn ngbakugba ; Ọmọ Ọlọrun fi ori itẹ́ Baba Rẹ̀ silẹ, 0 fi awọ enia bo ẹda Rẹ ọrun, ki On bã lè gba enia la kuro lọwọ agbara Satani. Ayọ is̩ẹgun Rẹ̀ nitori tiwa, o s̩i ọrun silẹ fun enia, o fi iran ibugbe nà hàn enia, nibiti Ọlọrun gbe ti ogo Rẹ̀ han kedere; o goe enia soke lati inu iho egbe ti ẹs̩ẹ ti a tì i si, O mu u wa sinu idapọ ti Ọlọrun alãye, lẹhin ti a ba si ti fi ara da idanwo mimọ nã nipa igbagbọ ninu Olurapada wa, ti a si fi ododo ti Kristi wọ wa, ti a ba wa gbe ka ori itẹ Rẹ̀ — iwọnyi ni awọn aworan ti Ọlọrun nfẹ ki a mã ro nipa nigbakugba.IOK 86.5

    Nigbati o ba dabi ẹnipe a ns̩e iyemeji si ifẹ Ọlọrun, ti a s̩e alaigbẹkẹle ileri Rẹ̀, a tabuku fun u, a si nmu Ẹmi Mimọ Ọlọrun binu. Bawo m inu abiyamọ yio ti ri, bi awọn ọmọ rẹ ba nfi ẹjọ rẹ̀ sun mgbagbogbo bi ẹnipe on ko nãni wọn, nigbati o jẹpe aniyan wọn li o wà li ọkan rẹ̀ ni gbogbo ọjọ fun ire ati itunu wọn? Bi nwọn ba s̩iyemeji ifẹ rẹ̀; ọkan rẹ̀ yio daru. Bawo ni inu obi ti le ri bi awọn ọmọ rẹ̀ ba hu iru iwa yi si i? Bawo ni Baba wa ọrun ti le kà wa si, nigbati a ba s̩iyemji si ifẹ Rẹ̀, ifẹ ti o mu ki O fi Ọmọ bibi Rẹ kans̩os̩o fun wa, ki a oba le ni iye? Aposteli nì kọwe bayi pe, “Ẹniti kò da Ọmọ Ontikalararẹ si, s̩ugbọn ti o jọwọ Rẹ̀ lọwọ fun gbogbo wa, yio ha ti s̩e ti ki yio fun wa li ohun gbogbo pẹlu Rẹ̀ lọfẹ? Romu 8:32. Sibẹsibẹ ọpọlọpọ nipa iwa ati ọrọ wọn ni nsọ pe, “Oluwa ko ro iru nkan bayi-bayi fun mi. Boya o fẹran awọn miran, s̩ugbọn ko fẹran mi.”IOK 87.1

    Gbogbo iru ọrọ bawọnyi npa ọkan rẹ lara, nitoripe olukuluku ọrọ iyemeji ti a nsọ jade li o npe idanwo Es̩u; o tubọ nfi agbara fun ẹmi iyemeji, o si mba inu awọn Angẹli ti is̩e emi ti njis̩ẹ jẹ. Nigbati Satani ba ndan ọ wo, mas̩e sọrọ is̩iyemeji tabi ti okunkùn. Bi o ba s̩ilẹkun silẹ fun imọran rẹ̀, ọkàn rẹ yio kun fun aigbẹkẹle ati èro ọ̀tẹ. Bi o ba sọ awọn ero rẹ jade, olukuluku ọro iyemeji ti o sọ ko s̩is̩ẹ lara iwọ nikan mọ, s̩ugbọn o di irugbin ti yio hu ti yio si so eso ninu igbe-aiye ẹlomiran, o si le má s̩ẽs̩e lati yi amuwa rẹ mọ. Iwọ tikalararẹ le bori is̩oro to de ba ọ, ati kuro ninu ikẹkun Es̩u yi, s̩ugbọn awọn miran ti o ti s̩ina nipa ihuwasi rẹ, le se alailẽbo ninu imọran aigbagbọ re ti o ti gbin si ọkan wọn. Bawo lo ti s̩e pataki to lati mà sọ kiki ọrọ to le fun awọn ẹlomiran ni agbara nipa ẹmi ati iye!IOK 87.2

    Awọn Angẹli nreti si iru irohin ti o fun araiye nipa ti Oluwa wa ọrun. Jẹki gbogbo ọrọ re jẹ nipa ti ẹniti mbẹ lãye ti o si mbebẹ fun o niwaju Baba. Nigbati o ba bọ ẹnikeji rẹ lọwọ jẹki iyin si Ọlọrun ma wà li ẹnu rẹ ati li ọkan rẹ. Eyi yi yio ma dari ero ọmọnikeji rẹ sọdọ Jesu.IOK 87.3

    Gbogbo wa li a ni is̩oro, ikãnu ti o nira lati fi ara da, ati idanwo ti o s̩oro lati dojukọ. Mas̩e sọ nipa is̩oro rẹ fun awọn ara rẹ, s̩ugbọn mu u tọ Ọlọrun lọ ninu adura. S̩e li ofin fun ara rẹ lati má sọ ọrọ iyemeji tabi ifoiya. O wa ni ipa rẹ lati mu aiye awọn ẹlomiran dara, ati lati fi agbara fun igbiyanju wọn, nipa ọrọ ireti ati ti itujuka.IOK 88.1

    Ẹlomiran ti o gboju ni idanwo ndalamu, ti o si fẹrẹ mã dáku ninu ijakadi pẹlu ara ati agbara Esu. Mase jẹki ọkan iru ẹni bē̩ rẹwẹsi ninu ijakadi nla na. Fi ọrọ igboiya on ireti da a laraya eyiti yio ran a lọwọ li ọna rẹ̀. Bayi ni imọlẹ Kristi s̩e le tan jade lati ọdọ rẹ. “Ko si ẹnikan ti o wà lãye fun ara rẹ̀, Romu 14:7. Is̩esi wa ti awa papa ko mọ, a mã fun awọn ẹlomiran lagbara ati okun, bi bē̩ si kọ o le fun wọn ni irẹwẹsi ọkan ati ifasẹhin kuro li ọdọ Kristi ati kuro ninu otitọ.IOK 88.2

    Ọpọlọpọ lo ni ero ti o yatọ nipa igbe-aiye ati iwa Kristi. Nwọn ro pe igbe-aiye Rẹ̀ ko dara debi pe ki o fanimọra, ati pe o jẹ onrorò, onikanra, ati alailayọ. Ni ọna pupọ li a si ti nfi iru oju bayi wo isin Kristi.IOK 88.3

    Ni ọpọ igba li a nsọ pe Jesu sọkun, ati pe a ko gbọ nigbakan ri pe o rẹrin. Lotọ Olugbala wa jẹ Ẹni-ikanu, o si mọ ibinujẹ, nitoripe o nfi okan Rẹ̀ wo gbogbo ègbé ọmọ araiye. S̩ugbọn bi-o-ti-lẹ-jẹpe igbe-aiye Rè jẹ ti isẹra-ẹni, ti irora ati aniyan si siji bo o. ẹmi Rẹ̀ ko rẹ̀wẹsi. Iwò oju Rẹ̀ ko fi ibanuje ati imi-ẹdun hàn, bikos̩e iwò ti alafia ti o lọla pẹlu. Ọkan Rẹ̀ jẹ orisun omi iyè; ibikibi ti O ba si lọ, pẹlu ibalẹ̀ ọkan. alafia, ayọ, ati inu didun ni.IOK 88.4

    Olugbala jẹ ẹniti nronu jinlẹ pẹlu itara nla, s̩ugbọn ki ifi ibanujẹ dori-kodo. Igbe-aiye awọn ti o ba ns̩e afarawe Rẹ̀, yio kun fun ero itara ; nwọn o ni ironu to jinlẹ nipa ohun ti o ba jẹ eru wọn. Nwọn o kọ̀ ohun asan silẹ, ko ni si afẹfẹyẹ̀yẹ̀ s̩is̩e, ko ni si òro awada ti ko ni-lãri ; s̩ugbọn isin Jesu yio fun wọn ni alafia bi odo to ns̩an. Ko ni pa ina ayọ wọn, ko ni da inudidun duro, ko si ni fi ikuku bo imolẹ oju erin won mọlẹ. “Kristi ko wa ki a má se iransẹ fun U, bikos̩e lati se irans̩e fun ni ;” nigbati ifẹ Rẹ̀ ba si mbẹ l’ ọkan wa, awa na o tele apere Rè.IOK 88.5

    Bi o ba se iwa aidã ati aitọ awọn ẹlomiran li a nfi sinu ọkan wa nigbagbogbo, ko ni s̩ese fun wa lati fẹran won gẹgẹbi Kristi ti s̩e feran wa: s̩ugbọn bi ero okan wa ba je nipa ti ifẹ iyanu ati ãnu Kristi lori wa, iru ẹmi bẹ ni yio mã s̩an jade lati ọdọ wa si ọdọ awọn ẹlomiran. O yẹ ki a fẹran, ki a si mã bu ọla fun ọmọnikeji wa, lai ro ti aidã ati iwa aipe wọn ti a nri. A nilati kọ iwa irẹlẹ ati ti aijọ-ara-ẹni-loju, ki a si mã mu suru nipa as̩is̩e awọn ẹlomiran. Eyi yio pa imọ-ti-ara-ẹni run, yio si wa sọ wa di ọmọluabi ati oninurere.IOK 88.6

    Olorin wi bayi pe, “Gbẹkẹle Oluwa ki o si mã s̩e rere, mã gbe ilẹ nã ki o si mã hu iwa otitọ.” Orin 37:3. “Gbẹkẹle Oluwa.” 01ukuluku ọjọ kọkan li o ni lãlã tirẹ, aniyan ati idamu tirẹ; nigbakugba ti a ba si pade ni a nsọrọ niti idanwo wa. Ọpọ iyọnu wọnyi li a gba lati ọdọ awọn miran, ọpọ ibẹru li a fun laye, ọpọ aniyan li a nfihan, tobẹ ti ẹlomiran fi le mã ro pe, a ko ni Olugbala alanu ati olufẹ, ti o s̩etan lati f’eti si ẹbẹ wa, ati lati ran wa lọwọ ni akoko aini.IOK 90.1

    Awọn ẹlomiran mbẹru, nwọn si nfi ọwọ fa iyọnu. Ojojumọ li a fi ami ifẹ Ọlọrun yi wọn ka; nwọn si ngbadura ipese Ọlọrun lojojumọ; s̩ugbọn nwọn gboju fo awọn ibukun ti nwọn ni wọnyi da. Igba gbogbo ni ọkan wọn ma nwa lori ohun ti ko dara, ti nwọn mbẹru pe o le s̩ẹlẹ ; tabi is̩oro die tilẹ le wa lotọ, bi o si tilẹ jẹ eyiti ko nilari a si fọ wọn loju si awọn ibukun ti nwọn iba mã dupẹ fun. Dipo ki awọn is̩oro ti nwọn mba pade fa wọn wa sọdọ Ọlọrun, Orisun iranlọwọ wọn kans̩os̩o, o nya wọn kuro lọdọ Rẹ ni, nitori nwọn mu aisimi ati ẹdun sọji ninu wọn.IOK 90.2

    O ha se dara lati jẹ alaigbagbọ bẹ? Ẽ ha ti s̩e ti a o fi jẹ alailọpẹ, ati alainigbekẹle? Ọrẹ wa ni Jesi is̩e; gbogbo awọn ọrun li o ni inudidun si ire wa. A ko nilati fi ãye silẹ fun awọn idãmu, ati hilahilo ojojumọ lati mã bi wa ninu ati lati mu wa fa oju ro. Bi a ba fi ãye fun wọn, ojojumo li a o mã ri awọn nkan ti yio mã bi wa ninu. Ko yẹ lati fi aye fun aibalẹ-aiya ti yio wulẹ mã dẹruba wa, ti yio si ma da wa lamu, ti ko si ni ran wa lọwọ lati fi ara da idanwo.IOK 90.3

    Is̩e re le da ọ lãmu, ilọsiwaju rẹ le dabi ẹnipe ko nilari, o tilẹ le dabi enipe o padanu, s̩ugbon mas̩e ba ọkan jẹ; ko aniyan rẹ le 01orun lọwọ, duro jẹ, ki o si tujuka. Gbadura fun ogbon lati le seto ọran ara re li ọna ti o yẹ, nipa bẹ ki ofò ati buburu si fò lọ. Sa gbogbo ipa rẹ lati le mu avorisi ti o dara jade wa. Jesu ti seleri iranlọwọ Rè, s̩ugbon ki is̩e laisi igbiyanju tiwa nibẹ. Bi o ba gbẹkẹle Oluranlọwọ wa. ti o si ti sa gbogbo ipa rẹ, tẹwogba iyọrisi na pelu ayọ. Ki is̩e ifẹ Ọlọrun pe ki aniyan bo ọkan awọn enia Rẹ̀ mọlẹ pata- pata. S̩ugbọn Oluwa ki i tan wa jẹ. On ki i sọ pe, “Mase bẹru ; ko si ewu loju ọna rẹ.” O mọ pe ewu ati is̩oro wa, O si nsọ fun wa gbangba bẹ. Ko si ninu ero Rẹ lati ko awọn enia Rẹ̀ kuro ninu aiye ẹs̩ẹ ati ibi yi, s̩ugbọn O ntọka wọn si abo ti ki iyẹ̀. Adura Rẹ̀ fun awọn ọmọ-ẹhin Rẹ nipe, “Emi ko gbadura pe ki O mu wọn kuro li aiye, s̩ugbọn ki Iwọ le pa wọn mọ kuro ninu ibi. Johannu 17:15. O si tun wipe “Ninu aiye ẹnyin o ni ipọnju ; s̩ugbọn ẹ tujuka; mo ti s̩ẹgun aiye.” Johannu 16:33.IOK 90.4

    Ninu iwasu Rẹ̀ lori oke, Kristi kọ awọn ọmọ-ẹhin Rẹ̀ ni ẹkọ iyebiye nipa gbigbẹkẹle Ọlọrun. Awọn ẹkọ wọnyi wa fun apẹrẹ ati lati mã fun awọn ọmọ Ọlọrun ni is̩iri lati irandiran, nwọn si wa titi di akoko tiwa yi, lati mã fun wa ni ẹkọ ati itunu. Olugbala tọka awọn atẹle Rẹ̀ si ẹiyẹ oju ọrun, bi nwọn ti nkọrin iyin si Ọlọrun, laisi ero aniyan ti nda wọn lãmu, nitoripe, “nwọn ki fun irugbin, bẹni nwọn ki kore.” Sibẹ Baba wa ọrun npese fun aini wọn. Olugbala bere pe, “Ẹnyin ko ha san ju wọn lọ? Matt. 6:26. Olupese nla fun enia ati ẹranko la ọwọ Rẹ̀ O si tẹ awọn ẹda Rẹ̀ lọrun. Awọn ẹiyẹ oju ọrun ko kere ju fun U lati s̩e akiyesi. Ki is̩e pe On papa lo nfi onjẹ si ẹnu wọn, s̩ugbọn O pese silẹ fun aini wọn. Nwọn nilati ko awọn ọka ti O ti fọnkalẹ fun wọn jọ fun arà wọn. Nwọn nilati tọju ohun elo itẹ ara wọn. Nwọn nilati bọ awọn ọmo wọn. Nwọn jade lọ pẹlu orin iyin si ibi lala wọn, nitori, Baba nyin ti mbẹ li ọrun mbọ wọn.” “Ẹnyin ko ha san ju wọn lọ?” Ẹnyin ko ha jẹ ọlọgbọn, ati olusin nipa ẹmi ti o niye lori ju awọn ẹiyẹ oju ọrun lọ? Njẹ Olupilẹs̩ẹ ẹda wa, ati Olupamọ ẹmi wa, Ẹniti O s̩e wa li aworan Onitikarare ki yio ha pese fun wa, bi a ba gbẹkẹle E?IOK 91.1

    Kristi tọka awọn ọmọ-ẹhin Rẹ̀ si awọn ododo inu igbẹ, bi nwọn ti ndagba pẹlu orun didun, ti nwọn si ndan ninu awọ irelẹ ti Baba wa ọrun fifun wọn, gẹgẹbi ami ifẹ Rẹ̀ si enia. O wipe, “Kiyesi lili ti mbẹ ni igbẹ, bi nwọn ti ndagba.” Ẹwa ati irẹlẹ awọn ododo wọnyi tayo ogo ati ọlanla ti Solomoni. Awon as̩ọ ti o lewa julọ ti a fi ọgbon enia hun ko to lati fi we didan ogo ati ewa ododo gẹgẹbi Ọlorun ti se da wọn. Jesu bere pe, “Njẹ bi Ọlọrun ba wọ koriko igbẹ li asọ bẹ, eyiti o wa loni. ti a si gba a sinu ina lọla, melomelo ni ki yio fi le wọ nyin li as̩ọ ẹnyin onikekere igbagbọ?” Matt. 6: 28, 30. Bi Ọlorun ẹniti is̩e ọlọgbọn ọrun ba fun awọn ododo ti a nparun lojojumọ, ni awo oris̩iris̩i ti o si dara bayi, es̩e ti On ki yio fi s̩ajo nyin ju bẹlọ, ẹnyin ti O da ni aworan ara Rẹ̀? Ẹkọ ti Kristi yi jẹ ibawi fun ọkan ti ns̩aniyan, ti ndãmu pẹlu iyemeji ati aigbagbọ.IOK 91.2

    Oluwa nfẹ ki awọn ọmọ Rẹ̀ l’ọkunrin ati l’obirin ni ayọ ati alafia ki wọn si jẹ olugbọran. Jesu wipe, “Alafia mi ni mo fifun nyin : ki is̩e bi aiye ti fun ni, ni mo se fun nyin. Ẹ mase jẹki ọkan nyin daru, ẹ ma si s̩e jẹki o wariri.” “Nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, ki ayọ mi ba le wa ninu nyin, ati pe ki ayọ nyin le kun.” Johannu 14:27 ; 15:11.IOK 92.1

    Ayọ ti a fi ifẹkufẹ wa kiri, ti o yapa kuro li oju ọna is̩ẹ, ki i dara, ki i kún, fun igba diẹ si ni; a si kọja lọ, ibanujẹ ati ẹdun a si kun inu ọkan; s̩ugbọn ayọ ati itẹlọrun mbẹ ninu isin Ọlọrun; a ko fi onigbagbọ silẹ lati mã rin ọna aidaniloju; a ko fi i silẹ lati mã kabamọ lori ohun asan ati imulẹmofo. Bi awa ko tilẹ ni ipin ninu jijẹ adun aiye, ọkan wa le kun fun ayọ sibẹ nigbati a ba nwo aiye ti mbọ.IOK 93.1

    S̩ugbọn sibẹ nihin awọn onigbagbọ le ni ayọ idapọ pẹlu Kristi ; nwọn le ni ayọ imọlẹ Rẹ̀, itunu wiwà Rẹ̀ pẹlu wọn nigbagbogbo. Is̩isẹ kọkan ni igbe aiye le ma mu wa sunmọ Jesu si i, yio si mã fun wa ni iriri ijinlẹ ifẹ Rẹ̀, o si le mã mu wa sunmọ ilẹ ibukun ati alafia nì ni is̩isẹ kọkan si i. Njẹ nitori eyi, ẹ mas̩e jẹki a sọ igbẹkẹle wa nu, s̩ugbọn ẹ jẹki a ni idaniloju, ti o fi ẹsẹ mulẹ ju ti is̩aju lọ. “Titi de ihin ni Oluwa ran wa lọwọ,“I Samueli 7:12. On yio si ran wa lọwọ titi de opin. Ẹ jẹki a mã wo awọn ami iranti, ti nran wa leti ohun ti Oluwa ti s̩e fun wa, lati tu wa ninu, ati lati gba wa la kuro lọwọ apanirun ni. Ẹ jẹki a ma ranti gbogbo awọn ãnu wọnni ti Ọlọrun ti fihan wa, awọn omije ti O ti nu kuro loju wa, irora ti O ti gbọn danu, ipaiya ti O ti mu kuro, ibẹru ti O ti tuka, ipese fun awọn aini wa, awọn ibukun ti O ti tudà sori wa, bayi li a o mã mu ara wa l’ọkan le fun iyoku irin-ajo aiye wa.IOK 93.2

    A ko le s̩ai gboju soke ki a si wo awọn idamu titun ti ija nla ti mbọ, s̩ugbọn a le wo awọn ohun ti o ti kọja ati awọn ohun ti mbọ, ki a si wipe, “Titi de ihin ni Oluwa ran wa lọwọ.” “Bi ọjọ rẹ, bẹ ni agbara rẹ yio ri.” Deut. 33:25. Idanwo na ko ni le tayọ agbara ti o fifun wa lati Je farada a. Nitorina ẹ jẹki a ki is̩ẹ wa mọlẹ giri s̩e nibikibi ti a ba ti ri, ni igbagbọ pe ohunkohun ti o wu ki o de, a o fun wa ni agbara ti o to lati pade rẹ.IOK 93.3

    Laipẹ jojọ awọn ilẹkun ọrun yio s̩i silẹ gbangba lati gba awọn ọmọ Ọlọrun, ati lati ete Ọba Ogo ni ibukun yio ti ma wọ eti won gegẹbi orin ti o s̩ọwon julọ, pe, “Ẹ wa, Ẹnyin alabukunfun Baba mi, ẹ jogun ijoba ti a ti pese silẹ fun nyin lati ipilẹs̩e aiye wa.” Matt. 25:34.IOK 93.4

    Nigbana ni a o ki awon ẹni-irapada ku abo si ile na ti Jesu ti npese fun wọn. Nibẹ ẹgbẹ wọn ki yio jẹ ẹgbẹ ibajẹ ti aiye, eleke, abọris̩a, alaimọ, ati alaigbagbo ; s̩ugbọn nwọn o da ara pọ mọ awọn oniwa-pipe, ti nwọn s̩ẹgun Satani nipa õre-ọfẹ. Gbogbo ero ẹs̩ẹ, gbogbo iwa aipe ti o ti pọn wọn loju mhin, ni ẹjẹ Kristi ti mu kuro, ati ọlanla ogo Rẹ̀ ti o tayọ didan ti ọrun, li a si fifun wọn. Ẹwà iwa-rere Rẹ̀ ti is̩e iwa pipe, tan imọlẹ jade lara wọn, ninu ẹwà iwà ti o tayọ ẹwà ti ode ara. Nwọn jẹ alailabuku niwaju itẹ funfun na, nwọn npin ninu ọla ati anfani ti awọn Angẹli.IOK 93.5

    Niti ireti ogo eyiti o le jẹ tirẹ, “Kini enia iba fi se pasiparọ ọkan rẹ?” Matt. 16:26. Lotọ o le jẹ talaka, sibẹ o ni ọrọ ati ọla eyiti aiye ko le fifun ni ninu ara rẹ. Ẹmi ti a ti ra pada, ti a si wẹnu mọ kuro ninu ẹs̩ẹ, pẹlu agbara rẹ ti a ti ya sọtọ fun is̩ẹ-isin Ọlọrun jẹ eyiti o tayọ ọs̩ọ iyebiye ; ayọ si mbẹ li ọrun, niwaju Ọlọrun, ati niwaju awọn angẹli Rẹ̀ mimọ, lori ọkan kan ti a rapada, ayọ ti a fihan ninu orin mimọ ti is̩ẹgun.IOK 94.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents