Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Jmọ nipa Ọlọrun

  Oris̩iris̩i ọna li Ọlọrun nwa lati fi ara Rẹ̀ han wa ati lati mu wa wà ni idapọ pẹlu ara Rẹ̀. Awọn ohun ẹda nsọrọ Rẹ̀ si eti-gbọ wa nigbagbogbo. Ifẹ ati ogo Ọlọrun han kedere lara awọn is̩ẹ ọwọ Rẹ̀ si ọkan ti ko sebọ. Eti ti o ba s̩i silẹ le gbọ ki o si mọ awọn ohun ti Ọlọrun wi nipa ẹ̀dá, Awọn pápá oko tutù, awọn igi giga, ọmunu ewe ati òdòdó rẹ̀, ikuku loju ọrun, ojo ti nrọ, odo ti ns̩àn ati gbogbo awọn ogo ọrun nsọrọ si ọkan wa, nwọn si npe wa lati wa si ọdọ Ẹnikan na ti O da gbogbo wa.IOK 62.1

  Ninu awọn ohun ti Olugbala wa da li O pa awọn ẹkọ iyebiye Rẹ̀ mọ si. Awọn igi igbẹ, ẹiyẹ oju ọrun, awọn ododo daradara larin afonifoji awọn oke, adagun omi, ati awọsanma didan pẹlu gbogbo awọn is̩ẹlẹ ati awọn is̩oro ti ọjọ de ọjọ laiye wa li a so pọ pẹlu ọrọ otitọ Ọlọrun, ki awọn ẹkọ Rẹ̀ le ma wá si iranti wa nigbagbogbo, papa julọ larin ãpọn fun aniyan aiye ti is̩e ipin enia.IOK 62.2

  Ọlọrun nfẹ ki gbogbo awọn enia Rẹ̀ mọ iyi is̩ẹ ọwọ Rẹ̀, ki inu wọn si dun ninu ẹwa ti O fi s̩e aiye, ti is̩e ibugbe wa lọs̩ọ. Ọlọrun fẹran ẹwa, s̩ugbọn On fẹ ẹwa iwa rere, ju gbogbo ọs̩ọ ode ara lọ; Ọlọrun fẹ ki a kọ iwa mimọ ati irẹlẹ, papa julọ gẹgẹbi awọn ododo ti o logo.IOK 62.3

  Bi a o ba feti silẹ, awọn ohun ẹda Ọlọrun yio kọ wa li ẹkọ iyebiye ti igbọran ati igbẹkẹle. Lati awọn irawọ ti ntẹle ipa ọna ti a s̩e fun wọn lati ọjọ ti a ti da wọn, titi fi de awọn ẹda ti o kere julọ, awọn ohun ti a da ntẹle ife Ẹlẹda wọn. Olọrun ntọju, O si ns̩e iranlọwọ fun gbogbo nkan wọnni ti O ti da. O ntọju wọn, O si mu ẹsẹ wọn duro sins̩in. Bi o tilẹ jẹ pe ogunlọgọ awon aiye ni o wa ni itọju Rẹ̀, sibẹ O nranti eiyẹ ologosẹ ti nkọrin irẹlẹ rẹ̀ pẹlu igboiya t’ọsan t’oru. Ibas̩e ọlọrọ, talaka, agba tabi ọmọde, olukuluku wa ni Ọlọrun ns̩ọ nigbati a ba lọ si ibi is̩ẹ õjọ wa, tabi nigbati a ba ngbadura, On wa pẹlu wa lori akete wa ni oru ati li owuro nigbati a ba ji kuro ni oju orun wa. Ko si ibanujẹ kan ti o ba wa ti Ọlọrun ko mọ. Ko si ayọ ti a ni ti o s̩ẹhin Rẹ̀.IOK 62.4

  S̩ugbọn bi awa yio ba gba nkan wọnyi gbọ nitõtọ, gbogbo awọn aniyan aiye ti ko nilari li a o mu kuro. Aiye wa ki ba ti kun fun ainireti bi o ti ri fun wa nisisiyi; nitori ohun gbogbo, ibas̩e nla, tabi kekere, li a o fi le Ọlọrun lọwọ, Ẹniti agara ko da fun ọpọlọpọ itọju Rẹ̀ lori wa, ti wiwuwo wọn ko si le dẹ́rùpa. Nigbanã li a o wa gbadun ibalẹ aiya ti ọpọlọpọ ti s̩alaini fun igba pipẹ.IOK 63.1

  Bi inu rẹ ti ndun nitori awọn ohun didara ti o nfanimọra li aiye ẹs̩ẹ yi, o yẹ ki o ro nipa aiye ti mbọ ninu eyiti ami ẹs̩ẹ ati iku ko ni si; nibiti oju ẹda ki yio ti gbe ojiji egún wọ mọ. Fi oju ẹmi wo awọn ti a gbala yio si ye ọ pe yio logo pupọ ju ohun didan julọ ti iwọ le fi inu ọkan rẹ ro lọ. Ninu oris̩iris̩i ẹbun ti Ọlọrun nfifun ẹda, a nri itans̩an ogo Rẹ ti o kere julọ. A ti kọ pe, “Ohun ti oju ko ri, ati ti eti ko gbọ, ti ko si wọ ọkan enia lọ, ohun wọnni ti Ọlọrun ti pese silẹ fun awọn ti o fẹ Ẹ.” I Kọrinti 2:9.IOK 63.2

  Akéwì ati akẹkọ pataki nipa ohun ẹda ti a da, sọrọ pupọ lori awọn is̩ẹ ọwọ Ọlọrun, s̩ugbọn Onigbagbọ li o ngbadun ẹwà aiye ti o si mọyì rẹ̀ julọ; nitori on mọ Ẹlẹda wọn ti s̩e Ọlọrun, Baba wa ; on si mọ ifẹ Rẹ lati ara ododo ati igi igbẹ. Ko si ẹniti o le mọ riri awọn oke, afonifoji, odo ati okun ni kikun, ti ki yio si wo wọn gẹgẹbi ohun ti nfi Ifẹ Ọlọrun han si enia.IOK 63.3

  Ọlọrun nsọrọ si wa nipa awọn is̩ẹ ọwọ ati Ẹmi Rẹ t’o wa ni ọkan wa. Bi a ba la oju wa, a le ri awọn ẹkọ iyebiye kọ́ ni ipò ti a wà, ati ni ayika wa, ati ninu awọn iyipada ti o ns̩ẹlẹ yi wa ka lojojumọ. Nigbati Dafidi ro nipa is̩ẹ ọwọ Ọlọrun ati ipese fun awọn ẹda Rẹ̀, o wipe, “Ilẹ aiye kun fun ãnu Oluwa” Orin 33:5. “Ẹniti o gbọn, yio si kiyesi nkan wọnyi; awọn nã li oye Oluwa yio mã yé.” Orin 107:43.IOK 63.4

  Ọlọrun mba wa sọrọ ninu Iwe Rẹ̀. Ninu Ọrọ Rẹ̀ yi ni iwa Rẹ̀, ilosi Rẹ pẹlu awọn enia ati is̩ẹ irapada nla Rẹ̀ gbe hàn si wa kedere. Ninu ọrọ Rẹ̀ yi li a ti s̩i itan awọn baba nla wa, ati ti awọn enia mimọ miran silẹ fun wa. Awọn enia “Oniru iwa bi awa” Jakọbu 5:17, li awọn nã. Nwọn ni is̩oro bi tiwa, nwọn ẹubu sinu idanwo gẹgẹbi awa na pẹlu ti s̩e, sibẹ nwọn dide pẹlu ọkan giri. nwọn si s̩egun nipa õreofẹ Ọlọrun ; nipa akiyesi, a o ni isiri bi a ti nlepa iwa ododo. Nigbati a ba ka nipa iriri ti a fi fun wọn. imọlẹ, ifẹ Ọlọrun, ati ibukun Rẹ̀ ti nwọn gbadun, ati is̩e nla ti nwon se nipa õre-ọfẹ ti a fun wọn, Ẹmi Mimo ti o nfun wọn ni imisi, a si tan imole si ọkan wa lati jọwọ wọn ni ọna mimọ, ati ifẹ lati dabi wọn ninu iwa—ki a ba Ọlọrun rin gẹgẹbi wọn ti s̩e.IOK 63.5

  Jesu sọ fun wa nipa Iwe Majẹmu ti lailai eyiti o si tun jẹ õtọ fun Majẹmu titun pe — “Wọnyi si li awọn ti njẹri Mi.” (Johannu 5:39.) ani Olurapada, ninu Ẹniti awa ni ireti iye ainipẹkun. Lõtọ gbogbo Bibeli li o sọrọ nipa Kristi. Lati inu akọsilẹ akọkọ nipa dida aiye, —nitoripe “lẹhin Rẹ̀ a ko si da ohun kan ninu ohun ti a da.” Johannu 1:3 — titi fi de ileri ikẹhin, “Kiyesi i, emi mbọ kánkán,” Ifihan 22:12, li a ti nka nipa awọn is̩ẹ ọwọ Rẹ, ti a si nfi eti silẹ si ohun Rẹ̀. Nipa kikọ Iwe Mimọ nikan ni a ti le mọ nipa Olugbala.IOK 64.1

  Jẹki ọkan rẹ kun fun ọrọ Ọlọrun. Awọn li omi iye fun ọkan rẹ ti ongbẹ ngbẹ. Awọn si li onjẹ iye nã lati ọrun wa, jesu wipe “Bikos̩epe ẹnyin ba jẹ ara Ọmọ enia, ki ẹyin si mu ẹjẹ Rẹ̀, Ẹnyin ko ni iye ninu nyin” Johannu 6:53. O si tun se ilaye ọrọ Rẹ̀ nipa sisọ pe, “Ọrọ wọnni ti mo sọ fun yin, ẹmi ni, iye si ni.” Johannu 6:63. Ohun ti a njẹ ati ohun ti a nmu li o ndi ẹran ara wa ; gẹgẹbi itọju ti ara, bẹ pẹlu ni itọju ti ẹmi, nkan ti a ba ns̩e as̩aro nipa ni o nfun wa li ilera ati agbara nipa ohun ti ẹmi.IOK 64.2

  Itan irapada jẹ ọkan pataki ti awọn Angẹli nfẹ lati mọ, eyi pẹlu ni yio si jẹ ọgbọn ati orin awọn ti a rapada titi aiye ailopin. Njẹ ko ha tọ pe ki a ma ronu ki a si ma kọ nipa rẹ nisisiyi? Anu ati ifẹ ailopin ti Jesu ni si wa, ati irubọ Rẹ nitori wa, nfẹ ero ti o jinlẹ lọpọlọpọ. O yẹ ki a ronu nipa iwa Olurapada ati Alagbawi wa ọwọn. A ni lati ma ronu nipa is̩e Ẹniti o wa lati gba awọn enia Rẹ̀ kuro ninu ẹs̩ẹ wọn. Bi a ba ti nro bayi nipa awọn nkan ti ọrun, Igbagbọ ati ifẹ wa yio ma lagbara si i, awọn adura wa yio si tubọ ma jẹ itẹwọgba lọdọ Ọlọrun, nitoripe nwọn yio ma dapọ mọ igbagbọ ati ifẹ. Nwọn yio kun fun oye pẹlu itara ọkan. Igbẹkẹle timọtimo ninu Jesu, at iriri ojojumọ ninu agbara Rẹ̀ lati gbala titi de opin, awọn ti o ba tọ Ọlọrun wa nipasẹ Rẹ̀.IOK 64.3

  Gẹgẹbi a ba ti nro nipa iwa pipe ti Olugbala wa, awa yio ni ifẹ lati ni iyipada patapata ki a si dabi Tirẹ̀ ni aworan iwa mimọ Rẹ̀. Awa yio ni ifẹ ti o gbona lati dabi Oluwa wa, ẹniti awa nsin. Bi ifẹ Kristi ba ti wa lọkan wa to, bẹ na li ao ma sọ nipa Rẹ fun awọn ẹlomiran to, awa yio si jẹ as̩oju Rẹ̀ tõto si araiye.IOK 64.4

  A ko kọ Bibeli fun awọn ọmọwe nikan, s̩ugbọn Bibeli wa fun gbogbo enia. Awọn otitọ pataki ti o nsọ ọna igbala fun olukuluku ọkan li a si fihan kedere gẹgẹbi imọlẹ ọsan gangan. Ko si si ẹniti o le s̩es̩i fi ọna na silẹ, afi awọn wọnni ti nwọn ba ntẹlẹ ọgbọn ti ara wọn, ti nwọn si kọ ọrọ otitọ Ọlọrun ti o han kedere silẹ.IOK 64.5

  Awa ko ni lati tẹle ẹri enia pe eyi tabi eyini ni Bibeli kọ wa, awa papa nilati ka ọrọ Ọlọrun ki a si kọ fun ara wa. Bi o ba jẹ pe awọn ẹlomiran ni nronu fun wa, agbara ironu wa yio di alailera, awa yio si di ojo, ẹniti ko le ta giri ki o si da nkan ti o ba tọ s̩e laisi ifoiya. Nipa aironu fun ara ẹni ọgbọn ati agbara ironu wa le di kikuru ati alailagbara tobẹ ti yio fi sọ agbara lati le mọ itumọ ijinlẹ Ọrọ Ọlọrun nu patapata. Kika ati kikọ Ọrọ Ọlọrun yio fi imọ ati oye kun ọkan wa, papa julọ nigbati awa ba mọ bi a ti s̩e nfi awọn ọrọ inu Iwe Mimọ we ara wọn, ti a si nfi awọn nkan ti ẹmi we ara wọn pẹlu.IOK 66.1

  Ohun ti o fun enia ni ọgbọn to kikọ Bibeli ko si laiye yi. Ko si is̩ẹ miran ti o lagbara lati sọ enia di ọlọgbọn, ti o si le sọ awọn imọ wa di alagbara gẹgẹbi awọn otitọ Bibeli ti is̩e ọrọ Ọlọrun. Bi a ba kọ ọrọ Ọlọrun bi o ti yẹ gan awọn enia yio ni oye, iwa ọlọtọ ati ero ti o lagbara, iru eyi ti o s̩ọwọn laiye loni.IOK 66.2

  S̩ugbọn ki o ye wa pe, ko si anfani kankan ti o ni lari ti a le ri gba nipa kika Bibeli pẹlu ikanju. Enia le ka Bibeli lati ibẹrẹ de opin ki o ma si ri ẹwa rẹ̀ tabi mọ ijinlẹ itumọ rẹ̀ ti o farasin. Iba diẹ ti a ba ka titi itumọ rẹ̀ fi ye wa, ti a mọ ibatan rẹ ninu ilana igbala wa s̩e anfani pupọ ju kika opọlọpọ ori iwe ninu Bibeli laimọ itumọ wọn. Mas̩e jẹki Bibeli rẹ kuro ni ọdọ rẹ nigbakankan. Nigbakugba ti aye ba ti si sile, ka Bibeli rẹ ki o si jẹki awọn ẹsẹ ti o ba ka wa lori rẹ nigbagbogbo. Ki is̩e ohun ti o buru lati ma ka Bibeli lori irin, ki a si ma ro nipa rẹ̀ pẹlu ; nipa bẹ ọrọ Ọlọrun yio fi gbongbo mulẹ li ọkan wa.IOK 66.3

  Laika Bibeli wa pẹlu ifarabalẹ ati adura a ko le ni ọgbọn. Awọn ibomiran wa ninu Bibeli ti o yé enia daradara, s̩ugbon awọn ori iwe miran wa ti itumọ wọn ko le tete ye enia lojukanna. A nilati ma fi iwe Mimọ we ara wọn. Peli ifarabale ati adura ni a ni lati ma wa inu iwe Mimo. Kikọ Bibeli ni iru ọna yi nikan ni o le fun enia ni ẹkun ibukun. Gẹgẹbi awakusa (miner) ti ma nwá ohun ọrọ̀ ti o wà labẹ ri, gẹgẹ bẽ li ẹniti nwa inu ọrọ Ọlọrun laisimi fun isura ti a fi pamọ sibẹ yio ri otitọ Olọrun ti o niye lori ju gbogbo ọrọ lọ, eyiti o farasin fun eniti o nfi aibikita wá inu iwe Mimo. Awon oro imisi ti a ba rò wo ninu ọkan yio dabi awọn odo ti nsan lati orisun omi ìyè.IOK 66.4

  Ki a ma ri pe a nkọ Bibeli laigbadura. Ki a to s̩i Iwe Mimọ a nilati gbadura fun iranlọwọ Ẹmi Mimọ a o si fifun yin. Nigbati Natanaẹli tọ Jesu wa, Olugbala wipe “Wõ ọmọ Israẹli nitõtọ, ninu ẹniti ẹtan ko si!” Nataniẹli wipe, “Nibo ni iwọ ti mọ mi?” Jesu dahun pe, “Ki Fillipi to pe Ọ, nigbati iwọ wa labẹ igi ọpọtọ mo ti ri ọ.” Johannu 1:47, 48. Bakanna ni Jesu yio ri wa ninu iyẹwu wa bi a ti ngbadura bi awa yio ba wa a lati fun wa ni imọlẹ ki a le mọ nkan ti is̩e etitọ. Awọn Angẹli imọlẹ lati ọrun yio wa pẹlu awọn wọnni ti o fi irẹlẹ ọkan jọwọ ara wọn fun itọju Ọlọrun.IOK 67.1

  Ẹmi Mimọ gbe Ólugbala ga, o si yin logo. Is̩ẹ Ẹmi Mimọ ni lati fi Kristi han pẹlu ododo rẹ̀ mimọ, ati igbala Rẹ̀ nla ti awa ni nipasẹ Rẹ̀.IOK 67.2

  Jesu wipe, “On yio gba ninu ti emi, yio si mã sọ ọ fun yin” Jọhannu 16:14. Ẹmi otitọ nikans̩os̩o li Olukọ ti o lagbara lati ko wa nipa otitọ Ọlọrun. Bawo li Ọlọrun iba tun se gbe enia ga, nigbati o fi Ọmọ Rẹ̀ silẹ lati ku fun wọn, ti O si yan Ẹmi Rẹ lati jẹ olukọni fun enia ati lati samọna fun u nigbagbogbo.IOK 67.3

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents