Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KẸTADINLOGUN—AWỌN AKÉDE ÒWÚRỌ

    Ọkan ninu awọn otitọ ti o ṣe pataki julọ ti o si ni ogo julọ ti a fihan ninu Bibeli ni ti ipadabọ Kristi lẹẹkeji lati pari iṣẹ nla ti irapada. Awọn eniyan Ọlọrun ti wọn jẹ arinrin-ajo, ti a fi silẹ fun igba pipẹ lati rin ni “agbegbe ati ojiji iku,” ni a fun ni ireti ti o ṣe iyebiye, ti o n mu ayọ wa, ninu ileri ifarahan Rẹ, Ẹni ti i ṣe “ajinde ati iye,” lati “mu awọn eniyan Rẹ ti a le kuro ni ilu wa sile.” Ikọni ti ipadabọ lẹẹkeji jẹ eyi ti o fi ara han kedere ninu Iwe Mimọ. Lati ọjọ tí tọkọtaya akọkọ ti yi ẹsẹ ibanujẹ wọn kuro ni Edẹni, awọn ọmọ igbagbọ ti n duro de wiwa Ẹni ti a ṣeleri lati ba agbara apanirun jẹ ati lati da wọn pada si Paradise ti wọn ti padanu. Awọn eniyan mimọ ti igba atijọ wo ọjọ iwaju fun wiwa Mesaya ninu ogo, gẹgẹ bi imuṣẹ ireti wọn. A gba Enọku, iran keje lati ọdọ awọn ti wọn gbe ni Edẹni, ẹni ti o fi ọgọrun ọdun mẹta rin pẹlu Ọlọrun rẹ ninu aye, laaye lati ri wiwa Olugbala ni jijina réré. O si wipe, “Kiyesi, Oluwa n bọwa pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun awọn ẹni mimọ Rẹ, lati wa ṣe idajọ gbogbo eniyan.” Juda 14, 15. Jobu, baba nla, ninu aṣalẹ ijiya rẹ sọ pẹlu igbẹkẹle ti ko mì wipe: “Mo mọ wipe Oludande mi wa laaye, yoo si dide nikẹyin lori ilẹ aye: . . . ninu ẹran ara mi, emi yoo ri Ọlọrun: Ẹni ti emi yoo ri funra mi, oju mi yoo ri i, ki si i ṣe ti ẹlomiran.” Jobu 19:25—27.ANN 134.1

    Wiwa Kristi lati mu akoko iṣakoso ododo wa ti mí si ọrọ otitọ pataki awọn onkọwe mimọ. Awọn akewi ati awọn woli inu Bibeli ti ṣe aṣaro lori rẹ pẹlu ina ọrun. Akọrin kọ nipa agbara ati ọlanla Ọba Israeli: “Lati Sioni wa, pipe ẹwa, Ọlọrun tan imọlẹ jade. Ọlọrun wa yoo wa, ki yoo si dakẹ. . . . Yoo ké sí awọn ọrun lati oke wa, ati si aye, ki o baa le ṣe idajọ awọn eniyan Rẹ.” O. Dafidi 50:2—4. “Jẹ ki awọn ọrun o yọ, ki inu aye o si dun . . . niwaju Oluwa nitori ti O n bọ lati ṣe idajọ aye: yoo ṣe idajọ aye pẹlu ododo, ati awọn eniyan pẹlu otitọ Rẹ.” O. Dafidi 96:11—13.ANN 134.2

    Woli Aisaya wipe: “Ẹ dide, ki ẹ si kọrin, ẹyin ti n gbe ninu erupẹ: nitori ìrì rẹ dabi ìrì eweko, ilẹ yoo si sọ awọn oku jade.” “Awọn oku inu rẹ yoo wa laaye, wọn yoo dide pẹlu ara kiku mi.” “Yoo gbe iku mi ni iṣẹgun; Oluwa Ọlọrun yoo si nu omije kuro ni oju gbogbo eniyan; yoo si ko ẹgan awọn eniyan Rẹ kuro ni gbogbo aye: nitori Oluwa ni o sọ ọ. A yoo si sọ ni ọjọ naa wipe, Kiyesi, Ọlọrun wa ni eyi: awa ti duro de e, yoo si gba wa: Oluwa ni eyi; awa ti duro de e, inu wa yoo dun, a o si yọ ninu igbala Rẹ.” Aisaya 26:19; 25:8, 9.ANN 134.3

    Habakuku lọ ninu iran mimọ, o kiyesi ifarahan Rẹ. “Ọlọrun ti Teman jade wa, Ẹni Mimọ lati ori oke Parani. Ogo Rẹ bo awọn ọrun, aye si kun fun iyin Rẹ. Itansan Rẹ si dabi imọlẹ.” “O duro, O si wọn ile aye: O kiyesi, O si pin awọn orilẹ ede niya; a fọn awọn oke ayeraye ka, awọn oke igba laelae tẹriba: awọn ọna Rẹ wà titi ayeraye.” “Iwọ gun awọn ẹsin Rẹ ati kẹkẹ ẹsin igbala Rẹ.” “Awọn oke ri Ọ, wọn si wa rìrì: . . . ibú fọ ohùn rẹ, o si gbe ọwọ rẹ soke giga. Oorun ati oṣupa duro sojukan ni ibugbe wọn: wọn kọja nibi ọfa imọlẹ Rẹ, ati nibi itansan ogo didan Rẹ.” “Iwọ kọja lọ fun igbala awọn eniyan Rẹ, ani fun igbala pẹlu ẹni ami ororo Rẹ.” Habakuku 3:3, 4, 6, 8, 10, 11, 13.ANN 134.4

    Nigba ti Olugbala fẹ kuro ni ọdọ awọn ọmọ ẹyin Rẹ, O tù wọn ninu pẹlu idaniloju wipe Oun yoo pada wa: “Ẹ maṣe jẹ ki ọkan yin daru. . . . Ninu ile Baba Mi, ọpọ ibugbe ni o wa. . . . Emi n lọ pese aye silẹ fun yin. Bi Emi ba si lọ lati pese aye silẹ fun yin, Emi yoo pada wa lati gba yin si ọdọ Emi tikara Mi.” Johanu 14:1—3. “Ọmọ eniyan yoo wa ninu ogo Rẹ, ati gbogbo awọn angẹli mimọ Rẹ pẹlu Rẹ.” “Nigba naa ni yoo joko ni ori itẹ ogo Rẹ: gbogbo orilẹ ede yoo si pejọ siwaju Rẹ.” Matiu 25:31, 32.ANN 134.5

    Awọn angẹli ti wọn duro lẹyin ni ori oke Olifi lẹyin igbasoke Kristi tun ileri ipadabọ Rẹ sọ fun awọn ọmọ ẹyin: “Jesu yii kan naa, ti a gba kuro lọwọ yin lọ si ọrun, yoo pada wa ni ọna kan naa bi ẹyin ti ri ti O n goke lo si ọrun.” Iṣe 1:11. Aposteli Pọlu pẹlu jẹri nipasẹ Ẹmi Mimọ wipe: “Oluwa funra Rẹ yoo sọkalẹ lati ọrun wa pẹlu ariwo, pẹlu ohùn Olu angẹli, ati kàkàkí Ọlọrun.” I Tẹsalonika 4:16. Woli oke Patmosi sọ wipe: “Kiyesi, O n bọ pẹlu awọsanma; gbogbo oju ni yoo si ri I.” Ifihan 1:7ANN 134.6

    Awọn ogo “imubọsipo gbogbo nnkan, ti Ọlọrun sọ lati ẹnu gbogbo awọn woli mimọ Rẹ lati igba ti aye ti bẹrẹ,” (Iṣe 3:21) rọ mọ iṣẹlẹ wiwa Rẹ. Nigba naa ni iṣakoso iwa buburu, eyi ti o ti wa fun ọjọ pipẹ yoo dopin; “ijọba aye yii” yoo di “ijọba Oluwa wa, ati ti Kristi Rẹ; yoo si jọba titi laelae.” Ifihan 11:15. “Ogo Oluwa yoo farahan, gbogbo ẹran ara yoo si jumọ ri i.” “Oluwa Ọlọrun wa yoo jẹ ki òdodo ati iyin o yọ jade niwaju gbogbo awọn orilẹ ede.” Yoo si jẹ “ade ogo, ati ade ẹwa si iyoku awọn eniyan Rẹ.” Aisaya 40:5; 61:11; 28:5.ANN 135.1

    Nigba naa ni a o fi idi ijọba alaafia ti Mesaya ti a ti n reti fun igba pipẹ mulẹ labẹ gbogbo ọrun. “Oluwa yoo tu Sioni ninu: yoo tu gbogbo ibi isọdahoro rẹ ninu; yoo jẹ ki gbogbo awọn aginju rẹ o dabi Edẹni, ati awọn aṣalẹ rẹ bi ọgba Oluwa.” “A yoo fi ogo Lebanoni fun un, titayọ ogo Kamẹli ati Sharoni.” “A ki yoo pe ọ ni ẹni ti a kọ silẹ mọ; bẹẹ ni a ki yoo pe ilẹ rẹ ni Ahoro: ṣugbọn a yoo pe ọ ni Idunnu mi ati ilẹ rẹ ni Beulah.” “Bi ọkọ iyawo ti n yọ lori iyawo rẹ, bẹẹ ni Ọlọrun rẹ yoo yọ lori rẹ.” Aisaya 51:3; 35:2; 62:4, 5.ANN 135.2

    Wiwa Oluwa ni ireti gbogbo awọn atẹle Rẹ tootọ ni igba gbogbo. Ileri ti Olugbala fi silẹ ni ori oke Olifi wipe Oun n pada bọ mu ki ọjọ iwaju o fuyẹ fun awọn ọmọ ẹyin Rẹ, o fi ayọ ati ireti ti ibanujẹ ko le pa ku, ti wahala ko le sẹrọ kun inu ọkan wọn. Ninu ijiya ati inunibini, “ifarahan Ọlọrun wa nla ati Jesu Kristi Olugbala wa” ni “ireti ti o ni ibukun.” Nigba ti awọn Kristẹni ni Tesalonika kun fun ibanijẹ bi wọn ti n sin awọn ololufẹ wọn, ti wọn ni ireti lati wa laaye lati ri wiwa Oluwa, Pọlu, olukọ wọn, tọka wọn si ajinde ti yoo ṣẹlẹ ni igba wiwa Oluwa. Nigba naa ni awọn oku ninu Kristi yoo jinde, a o si gba wọn soke pẹlu awọn ti wọn wa laaye lati lọ pade Oluwa ninu afẹfẹ. O wa sọ wipe, “Bayi ni a o yoo wa titi lae pẹlu Oluwa. Nitori naa, ẹ fi awọn ọrọ wọnyi tu ara yin ninu.” 1 Tẹsalonika 4:16—18.ANN 135.3

    Lori apata Patmosi, ọmọ ẹyin ti a fẹran gbọ ileri, “Nitootọ Emi n bọ kankan,” esi olùwọna ti o fọ sọ adura ijọ ninu gbogbo irin ajo rẹ, “Ani maa bọ wa Jesu Oluwa.” Ifihan 22:20.ANN 135.4

    Lati inu tubu, ibi idanasunni, ibi ibẹnilori, nibi ti awọn eniyan mimọ ati awọn ajẹriku ti jẹri si otitọ, ọrọ igbagbọ ati ireti wọn n jade wa fun ọpọ ọdun. Ọkan ninu awọn Kristẹni wọnyi sọ wipe, nitori ti wọn ni “idaniloju ajinde Rẹ, ati nitori naa, titi wọn ní igba wiwa Rẹ, nitori idi eyi, wọn fi oju tẹnbẹlu iku, wọn ri wipe wọn ga ju u lọ.” Wọn gba lati lọ si inu iboji ki wọn ba le “dide ni ominira.” Wọn wọna fun “Oluwa lati wá lati ọrun ninu ikuuku awọsanma pẹlu ogo Baba Rẹ, “ki O mu akoko ijọba naa wa fun awọn olododo”. Awọn Waldenses ni iru igbagbọ kan naa. Wycliffe wo ọjọ iwaju fun ifarahan Olurapada gẹgẹ bi ireti ijọ.ANN 135.5

    Luther sọ wipe: “O damiloju nitootọ, wipe ọjọ idajọ ko le jinna to ọgọrun ọdun mẹta mọ. Ọlọrun ko le jẹ, ko si ni jẹ ki aye buburu yii o tẹsiwaju fun igba pipẹ mọ.” “Ọjọ nla n sunmọle ninu eyi ti a o bi ijọba irira yii ṣubu.”ANN 135.6

    Melancthon sọ wipe, “Aye ti o dogbo yii ko jinna si opin rẹ.” Calvin rọ awọn Kristẹni “lati maṣe lọra, ki wọn fi tọkantọkan ni ifẹ si ọjọ wiwa Kristi gẹgẹ bi iṣelẹ ti o dara julọ;” o tun sọ wipe “gbogbo idile awọn olootọ yoo wọna fun ọjọ naa.” O sọ pe, “A nilati pongbẹ fun Kristi, a nilati wa A, ki a ṣe asaro, titi ti ọjọ nla naa a fi yọ, nigba ti Oluwa wa yoo fi ogo ijọba Rẹ han ni kikun.”ANN 135.7

    Knox Alatunṣe ti ilẹ Scotland sọ wipe, “Njẹ Jesu Oluwa ko ha gbe ẹran ara wa lọ si ọrun bi? ṣe ko wa ni pada wa bi? A mọ wipe yoo pada wa, yoo si ṣe e ni kankan.” Ridley ati Latimer, ti wọn fi ẹmi wọn lelẹ nitori otitọ, fi igbagbọ wọna fun wiwa Oluwa. Ridley kọwe wipe: “Aye, laisi iyemeji,—eyi ni mo gbagbọ, nitori naa ni mo fi sọ ọ—n lọ si opin. Pẹlu Johanu iranṣẹ Ọlọrun, ẹ jẹ ki a kigbe si Kristi Olugbala wa ninu ọkan wa, Maa bọ, Jesu Oluwa, wa.”ANN 135.8

    Baxter sọ wipe, “Ero nipa wiwa Oluwa ni o dun mọ mi, ti o si fun mi layọ julọ.” “Iṣẹ igbagbọ ati iṣesi awọn eniyan mimọ Rẹ ni lati fẹran wiwa Rẹ ati lati wọna fun ireti ti o ni ibukun.” “Bi iku ba jẹ ọta ikẹyin ti a o parun ni asiko ajinde, a le kọ nipa bi o ti yẹ ki awọn onigbagbọ o ṣe fi tọkantọkan wọna fun, ki wọn si gbadura fun ipadabọ Kristi lẹẹkeji, nigba ti a yoo ṣe iṣẹgun kikun ti o kẹyin yii.” “Eyi ni ọjọ ti o yẹ ki gbogbo onigbagbọ o wọna, ki wọn ni ireti, ki wọn si duro de, gẹgẹ bi aṣekagba gbogbo iṣẹ irapada wọn, ati gbogbo ifẹ ati akitiyan ọkan wọn.” “Oluwa, jẹ ki ọjọ alabukun yii o yara kankan!” Iru ireti ijọ apostoli niyi, ti “ijọ ninu aginju,” ati ti awọn Alatunṣe.ANN 136.1

    Ki i ṣe wipe asọtẹle sọ nipa bi Kristi yoo ti wa, ati ohun ti O n bọ wa ṣe nikan, ṣugbọn o ṣe afihan awọn ohun ti eniyan a fi mọ igba ti o ba sunmọle. Jesu sọ wipe: “Ami yoo wa ninu oorun, ati oṣupa, ati irawọ.” Luku 21:25. “Oorun yoo ṣokunkun, oṣupa ki yoo si fi imọlẹ rẹ han, awọn irawọ oju ọrun yoo jabọ, a o si mi awọn agbara ti n bẹ ni oju ọrun. Nigba naa ni wọn o ri Ọmọ eniyan ti n bọ ninu ikuuku awọsanma pẹlu agbara nla ati ogo.” Maku 13:24—26. Onifihan ṣe alaye akọkọ ninu awọn ami ti yoo ṣẹlẹ ṣaaju ipadabọ lẹẹkeji bayi pe: “Ilẹ ríri nla si wà; oorun si dudu bi aṣọ ọfọ, oṣupa si dabi ẹjẹ.” Ifihan 6:12.ANN 136.2

    A ri awọn ami wọnyi ki ọrundun kọkandinlogun o to bẹrẹ. Ni imuṣẹ si isọtẹlẹ yii, ni ọdun 1755, ilẹ riri ti o buru julọ ti a ti i riri ṣẹlẹ. Bi o tilẹ jẹ wipe a saba maa n pe e ni ilẹ ríri ti Lisbon, o de ọpọ ilẹ Europe, Africa, ati America. A ni imọlara rẹ ni Greenland, iha iwọ oorun Indies, ni erekusu Madeira, ni Norway ati Sweden, Great Britain ati Ireland. O dé bi i iwọn milliọnu mẹrin maili. Imọlara rẹ pọ ni Africa bii ti Europe. Pupọ lara ilu Algiers ni o parun; ibi kan ti ko jinna pupọ si Morroco, abule kan ti o ni to bi ẹgbẹrun mẹjọ si mẹwa eniyan ni o tẹri. Igbi omi nla rọlu bebe Spain ati Africa, o bo awọn ilu nla mọlẹ, o si fa ọpọlọpọ iparun.ANN 136.3

    Ni Spain ati Portugal ni a ti ni imọlara agbara rẹ julọ. Ni Cadiz, a sọ pe igbi omi ti o rọ wọle ga to ẹsẹ bata ọgọta. Awọn oke, “diẹ lara awọn ti wọn tobi julọ ni Portugal, mi kikankikan, lati ipilẹ wọn wa, diẹ lara wọn sán loke, wọn ya bolẹ ni ọna ti o lagbara, wọn si ṣubu si afonifoji ti o wa ni ẹba wọn. A gbọ wipe ina ṣẹyọ lati ara awọn oke wọnyi.”ANN 136.4

    Ni Lisbon “a gbọ iró àrá ni isalẹ ilẹ, lọgan lẹyin eyi, ilẹ ti o mi tìtì bi eyi ti o pọ julọ ninu ilu naa ṣubu. Laarin iṣẹju mẹfa awọn bi ẹgbẹrun lọna ọgọta eniyan ni wọn ṣègbé. Òkun kọkọ sa sẹyin diẹ, ti isalẹ rẹ si gbẹ; o wa pada wa, o fi aadọta ẹsẹ tabi ju bẹẹ lọ ga ju bi o ti yẹ lọ.” “Lara awọn iṣẹlẹ agbayanu ti wọn sọ wipe o ṣẹlẹ ni akoko ijamba ti Lisbon ni bi ibùdokọ oju omi kan ti o tẹri; okuta mabu ni a fi kọ gbogbo rẹ, pẹlu owo gọbọi. Ọpọ ero ni wọn salọ sibẹ fun aabo, gẹgẹ bi ibi ti ọwọ iparun ko ti le to wọn; ṣugbọn lojiji, ebute naa rì wọlẹ, pẹlu gbogbo awọn ti wọn wa ni ori rẹ, ko si si oku ẹnikankan ti o lefo si ori omi.”ANN 136.5

    “Ìgbọn tìtì” ilẹ ríri yii “jẹ ki awọn ile ijọsin ati ile awọn ajẹjẹ ẹsin o ṣubu loju ẹsẹ, gbogbo ile nla inu ilu naa ati eyi ti o ju ida kan lọ ninu awọn ile ti a n gbe ni wọn wo lulẹ. Ni aarin wakati meji lẹyin igbọn titi yii, ina ṣẹyọ ni oriṣiriṣi ibi, ti o si jo kikankikan fun bi ọjọ mẹta, titi ti ilu naa fi parun tan. Ọjọ mimọ ni iṣẹlẹ ilẹ riri yii ṣẹlẹ nigba ti awọn ile ijọsin ati ile awọn ajẹjẹ ẹsin kun fun awọn eniyan, iwọnba awọn eniyan perete ni wọn sa asala.” Ibẹru awọn eniyan kọja ohun ti a le ṣalaye. Ko si ẹni ti o sọkun; o kọja ẹkun. Wọn sa sihin sọhun, wọn n ṣe rànrán nitori ipaya ati iyalẹnu, wọn n lu oju ati aya wọn, pẹlu igbe, ‘Misericordia! the world is at an end!’ (Oṣe o! Aye ti parẹ!) Awọn iya gbagbe awọn ọmọ wọn, wọn n sare kiri pẹlu ère kekere Jesu lori agbelebu lọrun wọn. O ṣenilaanu, ọpọlọpọ ni wọn salọ sinu ile ijọsin fun aabo; ṣugbọn lasan ni a fi aami majẹmu han; lasan ni awọn ẹni ikaanu naa dirọ mọ pẹpẹ; awọn ère, awọn alufa, ati awọn eniyan tẹri sinu iparun kan naa.” A ṣe iṣiro rẹ pe o to bi ẹgbẹrun lọna aadọrun eniyan ti wọn padanu ẹmi wọn lọjọ buruku naa.ANN 136.6

    Ni ọdun marundinlọgbọn lẹyin eyi, àmi miran ti a sọ nipa rẹ ninu asọtẹlẹ naa—iṣokunkun oorun ati oṣupa—fi ara han. Ohun ti o tun jẹ ki eyi o yanilẹnu si ni wipe a tọka si igba ti yoo ṣẹlẹ ni pato. Ninu ijiroro Olugbala pẹlu awọn ọmọlẹyin Rẹ ni ori oke Olifi, lẹyin ti o ṣe alaye akoko gbọọrọ ti ijiya ijọ,—1260 ọdun ti inunibini ijọ padi, nipa inira ti O ṣe ileri wipe a o gé kuru,—O wa ṣe alaye awọn iṣẹlẹ kan ti yoo ṣaaju wiwa Rẹ, O si da igba ti akọkọ ninu awọn wọnyi yoo ṣẹlẹ: “Ni awọn ọjọ naa, lẹyin ipọnju naa, oorun yoo ṣokunkun, oṣupa ki yoo si fi imọlẹ rẹ han.” Maku 13:24. 1260 ọjọ tabi ọdun pari ni 1798. Ọdun marundinlọgbọn ṣaaju eyi, inunibini ti fẹrẹẹ pari patapata. Lẹyin inunibini yii, gẹgẹ bi ọrọ Kristi, oorun yoo ṣokunkun. Ni ọjọ kọkandinlogun oṣu karun, 1780, asọtẹlẹ yii wa si imuṣẹ.ANN 136.7

    “O fẹrẹ dabi ẹnipe iṣẹlẹ yii da yatọ, gẹgẹ bi eyi ti o yanilẹnu julọ ti a ko tun le ṣe alaye rẹ, . . . ọjọ dudu ti May 19, 1780,—okunkun ti a ko le ṣalaye ṣu bolẹ ni gbogbo New England.”ANN 137.1

    Ẹni ti iṣẹlẹ naa ṣe oju rẹ kòró, ti o n gbe ni Massachusetts ṣe alaye rẹ bayi: “Ni aarọ, oorun yọ kedere, ṣugbọn laipẹ ikuuku bò ó mọlẹ. Ikuuku naa bo oju ọrun, o dudu, o si banilẹru, lọgan bi o n ti yọ, mọnamọna kọ, àrá sán, òjò diẹ si rọ. Ni bii aago mẹsan, ikuuku naa n wọ kuro, oju ọrun si dabi àwọ idẹ, ti àwọ ilẹ, apata, igi, ilé, omi, ati eniyan yipada nitori imọlẹ ti o ṣajeji yii. Lẹyin iṣeju diẹ, ikuuku dudu biribiri bo gbogbo oju ọrun, o wa fi alafo tooro kan loju ọrun sile, oju ọrun ṣokunkun ayafi bii aago mẹsan alẹ ni igba ẹrun. . . .ANN 137.2

    “Ibẹru, aniyan ati ipaya, n bo ọkan awọn eniyan. Awọn obinrin duro si ẹnu ọna, wọn n wo ita ti o ṣokunkun; awọn ọkunrin pada wale lati ibi iṣẹ wọn lori oko; awọn gbẹnagbẹna fi irin iṣẹ wọn silẹ, awọn alagbẹdẹ fi ewiri wọn silẹ, awọn oniṣowo fi idi òwò wọn silẹ. A tu awọn ile ẹkọ ka, pẹlu iwariri, awọn akẹkọ sa pada sile. Awọn arinrinajo duro ni ilé oko ti o sunmọ julọ. ‘Kini o n bọwa?’ ni gbogbo ẹnu ati ọkan n beere. O dabi ẹnipe ẹfuufu lile fẹ la ilẹ naa kọja, tabi pe akoko opin ohun gbogbo ti de.ANN 137.3

    “A tan abẹla; ibi idana si n tan yoyoyo afi bi aṣalẹ ti oṣupa ko yọ. . . . Awọn adiyẹ pada si itẹ wọn wọn lọ sun, awọn malu pejọ pọ si ile onjẹ, wọn n ké, awọn ọpọlọ n ké, awọn ẹyẹ n kọrin alẹ, awọn adan si n fo kiri. Ṣugbọn eniyan mọ wipe aṣalẹ koi tii de….ANN 137.4

    “Dr Nathaniel Whittaker, alufa ijọ Tabernacle ni Salem, ṣe isin ni ile ijọsin, o si waasu, ninu iwaasu rẹ o sọ wipe okunkun naa ki i ṣe lasan. Awọn olujọsin pejọ pọ ni ọpọlọpọ ibomiran. Awọn ẹsẹ iwaasu jẹ eyi ti o fihan wipe okunkun naa wa ni ibamu pẹlu asọtẹlẹ Iwe Mimọ. . . . Okunkun naa dudu julọ ni lọgan lẹyin agogo mọkanla.” “Ni ọpọlọpọ oko, o pọ ni ọsan debi wipe awọn eniyan ko le fi aagọ sọ iye akoko ti o lu, tabi jẹun, tabi ṣe iṣẹ ile wọn lailo ina abẹla. . . .ANN 137.5

    “Bi okunkun naa ti gbilẹ to kọja afẹnusọ. A ṣe akiyesi rẹ de ibi jijina réré ni iha ila oorun de Falmouth. Si iha iwọ oorun, o de ibi ti o jinna julọ ni Connecticut, titi de Albany. Lọ si iha gusu, o de eti bebe okun; lọ si iha ariwa, o lọ jinna de ibi ti ilẹ Amẹrika jinna de.”ANN 137.6

    Lẹyin okunkun biribiri ọjọ naa, fun bi wakati kan tabi meji ni irọlẹ, oju ọrun mọlẹ diẹ, oorun si fi ara han, bi o tilẹ jẹ wipe ikuuku dudu ṣi bo o mọlẹ. “Lẹyin ti oorun wọ, ikuuku tun bo oju ọrun, oju si tete ṣokunkun.” “Ki i ṣe wipe okunkun ti aṣalẹ jẹ lasan, tabi wipe ko banilẹru bii ti ọsan; bi o tilẹ jẹ wipe oṣupa fẹrẹ yọ tan, a ko le da ohunkohun mọ lalaisi iranlọwọ atupa, eyi ti o dabi ẹnipe o mọlẹ jade lati inu okunkun awọn ara Ijibiti, ti ko le jẹ ki imọlẹ o kọja nigba ti a ba n wo o lati ile ẹlomiran tabi lati ọna jinjin.” Ẹni ti iṣẹlẹ naa ṣe oju rẹ sọ wipe: “Nigba naa, mo n ronu wipe bi a ba fi okunkun biribiri bo gbogbo ohun ti n tan imọlẹ ninu aye, tabi bi a ba pa wọn run, okunkun naa ko le pọ ju eyi lọ.” Bi o tilẹ jẹ wipe oṣupa ti yọ ni kikun ni aago mẹsan alẹ ọjọ naa, “ko ni agbara kankan lati tu okunkun biribiri naa ka.” Lẹyin aago mejila oru, okunkun naa kuro, nigba ti oṣupa si kọkọ fi ara han daradara, o pọn bi ẹjẹ.ANN 137.7

    May 19, 1780, duro ninu itan gẹgẹ bi “Ọjọ Dudu.” Lati akoko Mose, ko si okunkun ti o ṣe bẹyẹn dudu, ti o gbilẹ, ti o si pẹ ti a ti i ri. Alaye iṣẹlẹ yii ti awọn ti iṣẹlẹ naa ṣe oju wọn ṣe jẹ atunsọ ọrọ Oluwa ti woli Joẹli, ni ẹgbẹrun meji abọ (2500) ọdun sọ ṣaaju ki wọn to ṣẹlẹ: “Oorun yoo ṣokunkun, oṣupa yoo si di ẹjẹ, ki ọjọ nla Oluwa ti o lẹru o to de,” Joẹli 2:31.ANN 137.8

    Kristi ti sọ fun awọn eniyan Rẹ lati wọna fun awọn ami wiwa Rẹ, ki wọn si bú si ayọ bi wọn ṣe n ri awọn ami ti n sọ wipe Ọba wọn n bọ wá. O sọ wipe, “Nigba ti awọn nnkan wọnyi ba n ṣẹlẹ, ẹ wòkè, ki ẹ si gbe ori yin soke, nitori idande yin sunmọle.” O tọka awọn atẹle Rẹ si igi ti n ruwe, o si sọ wipe: “Nigba ti wọn ba n ruwe, ẹ wo o ki ẹ si mọ ninu ara yin wipe igba ẹrun sunmọ etile. Bẹẹ gẹgẹ, nigba ti ẹyin ba ri ti nnkan wọnyi ba n ṣẹlẹ, ẹ mọ wipe ijọba ọrun n sunmọ etile.” Luku 21:28, 30, 31.ANN 138.1

    Ṣugbọn bi ẹmi igberaga ati aṣa lasan ti rọpo ẹmi irẹlẹ ati ifọkansin ninu ijọ, ifẹ fun Kristi ati igbagbọ ninu wiwa Rẹ di tutu. Wọn kun fun ifẹ aye ati wíwá ifẹkufẹ ara, oju awọn ti wọn n pe ara wọn ni eniyan Ọlọrun fọ si awọn ikilọ Kristi nipa ifarahan Rẹ. A kọ ikọni nipa ipadabọ lẹẹkeji silẹ; a si ṣi awọn ẹsẹ Bibeli ti wọn sọ nipa rẹ tumọ titi ti a ko fi ni oye nipa rẹ mọ, ti wọn si gbagbe rẹ. Eyi wọpọ julọ ninu awọn ijọ ilẹ Amẹrika. Ominira ati ifọkanbalẹ ti gbogbo eniyan n jẹgbadun, ifẹ gbigbona fun ọrọ ati faaji, ti o jẹ ki wọn ni ifọkansin gbigbona fun wiwa owó, itara lati ni agbara ati lati di gbajugbaja, eyi ti o dabi ẹnipe o wa ni arọwọto gbogbo eniyan, jẹ ki awọn eniyan o gbe ifẹ ati ireti wọn si ori awọn ohun aye yii, wọn si fi ọjọ ẹlẹru, ninu eyi ti ohun gbogbo ti a n ri wọnyi yoo kọja lọ, si ọjọ jijina réré.ANN 138.2

    Nigba ti Olugbala tọka awọn ọmọ ẹyin Rẹ si awọn ami wiwa Rẹ, O sọ nipa ipo ifasẹyin ti yoo wà ni kete ṣaaju ipadabọ Rẹ lẹẹkeji. Gẹgẹ bii ti ọjọ Noa, awọn akitiyan ati irọkẹkẹ okoòwò aye ati wiwa faaji—rira, tita, gbingbin, kikọle, gbigbeyawo, ati fifunni ni iyawo—pẹlu ainaani Ọlọrun ati igbe aye ti n bọ. Iyanju Kristi fun awọn ti n gbe ni akoko yii ni pe: “Ẹ kiyesi ara yin ki ọkan yin maṣe kun fun ajẹki ati imutipara, ati ìgbòkègbodò aye yii, ki ọjọ naa ma baa ba yin ni airotẹlẹ.” “Nitori naa, ẹ maa sọna ki ẹ si maa gbadura nigba gbogbo, ki a baa le ka yin yẹ lati jẹ ọkan ninu awọn ti yoo la awọn ohun ti n bọ wa ṣẹ ja, ki ẹ si le duro niwaju Ọmọ eniyan.” Luku 21:34, 36.ANN 138.3

    Ọrọ Olugbala ninu iwe Ifihan ṣe alaye ipo ti ijọ wa ni akoko yii: “Iwọ ni orukọ wipe iwọ wa laaye, ṣugbọn iwọ ti ku.” A tun ṣe ikilọ ẹlẹru yii fun awọn ti wọn kọ lati ji dide kuro ninu ipo aibikita, ṣugbọn ti wọn ro wipe wọn wa ninu aabo wipe: “Bi iwọ ko ba sọna, Emi yoo dé si o gẹgẹ bi ole, iwọ ki yoo si mọ akoko ti Emi yoo wa si ọdọ rẹ.” Ifihan 3:13.ANN 138.4

    Awọn eniyan nilati mọ iru inu ewu ti wọn wa; wipe wọn nilati ji lati mura silẹ fun awọn iṣẹlẹ ti wọn rọ mọ akoko opin aanu. Woli Ọlọrun kede wipe: “Ọjọ Oluwa lagbara, o si ni ẹru gidigidi; tani yoo le duro dee?” Tani yoo le duro nigba ti O ba yọ, Ẹni ti, “oju Rẹ mọ ju atiwo iwa buburu lọ,” ti ko si le wo aiṣedeede.”? Joẹli 2:11; Habakuku 1:13. Si awọn ti n kigbe wipe, “Ọlọrun mi, a mọ Ọ,” sibẹ ti wọn n tẹ majẹmu Rẹ loju, ti wọn si mura lati tẹle ọlọrun miran lẹyin, ti wọn n fi aiṣedeede pamọ sinu ọkan wọn, ti wọn si fẹran ọna aiṣododo—si awọn wọnyi, ọjọ Oluwa yoo jẹ “okunkun to dudu biribiri, ki si i ṣe imọlẹ, ki yoo si didan kan ninu rẹ.” Hosia 8:21; O. Dafidi 16:4; Amosi 5:20. “Yoo si ṣe ni akoko naa,” ni Oluwa wi, “ni Emi yoo tu Jerusalẹmu wò pẹlu fitila, Emi yoo si fi iya jẹ awọn ti wọn n gbarale gẹdẹgẹdẹ wọn: ti wọn n sọ ninu ọkan wọn wipe, Oluwa ko ni ṣe rere, bẹẹ ni ko ni ṣe ibi.” Sefanaya 1:12. “Emi yoo fi iya jẹ araye nitori iwa buburu wọn, ati awọn eniyan buburu nitori aiṣedeede wọn; Emi yoo fi opin si igberaga awọn agberaga, Emi yoo si rẹ igberaga awọn eniyan buburu silẹ.” Aisaya 13:11. “Fadaka wọn tabi wura wọn ki yoo le gba wọn;” “ohun ini wọn yoo di ikogun, ilẹ wọn yoo si di ahoro.” Sefanaya 1:18, 13.ANN 138.5

    Woli Jeremaya, nigba ti o n wo ọjọ iwaju fun akoko ẹlẹru yii, sọ wipe: “O dun mi de inu ọkan. . . . Emi ko le dakẹ, nitori ti iwọ ti gbọ, ọkan mi, ohùn kàkàkí, ati idagiri ogun. Iparun lori iparun ni a n kigbe.” Jeremaya 4:19, 20.ANN 138.6

    “Ọjọ naa jẹ ọjọ ibinu, ọjọ wahala ati ipaya, ọjọ ìfiṣòfò ati isọdahoro, ọjọ okunkun ati ibanujẹ, ọjọ ikuuku ati okunkun dudu, ọjọ kakaki ati idagiri.” Sefanaya 1:15, 16. “Kiyesi, ọjọ Oluwa n bọ wa, . . . lati sọ ilẹ naa di ahoro: yoo si pa awọn ẹlẹṣẹ run kuro ninu rẹ.” Aisaya 13:9.ANN 139.1

    Nipa ọjọ nla yii ọrọ Ọlọrun, ni ọna ti o lẹru ati ni ede ti o muni lọkan julọ, pe awọn eniyan Rẹ lati ji kuro ninu aarẹ ẹmi ti o n mu ọkan wọn, ki wọn si wa oju Rẹ pẹlu ironupiwada ati irẹra-ẹni-silẹ: “Ẹ fun kakaki ni Sioni, ki ẹ si fun ohùn ipè ni ori oke mimọ Mi: ẹ jẹ ki gbogbo awọn olugbe ilẹ naa o bẹru: nitori ti ọjọ Oluwa n bọwa, nitori ti o sunmọ etile.” “Ẹ yan awẹ, ẹ pe ajọ mimọ: ẹ kó awọn eniyan jọ, ẹ ya ajọ eniyan si mimọ, ẹ pe awọn alàgbà jọ, ẹ ko awọn ọmọde jọ: . . . ẹ jẹ ki ọkọ iyawo o jade kuro ninu iyẹwu rẹ, ati iyawo kuro ninu yara rẹ. Ẹ jẹ ki awọn alufa, awọn ojiṣẹ Oluwa, o sọkun laarin ìloro ati pẹpẹ.” “Ẹ yipada si ọdọ Mi pẹlu gbogbo ọkan yin, ati pẹlu awẹ, ati pẹlu ẹkun, ati pẹlu ọfọ: ki ẹ si fa ọkan yin ya, ki si i ṣe aṣọ yin, ki ẹ si yipada si Oluwa Ọlọrun yin: nitori ti O jẹ oloore ọfẹ ati alaanu, O n lọra lati binu, O si kun fun inurere lọpọlọpọ.” Joẹli 2:1, 15—17, 12, 13.ANN 139.2

    A nilati ṣe iṣẹ atunṣe nla lati pese awọn eniyan silẹ lati le duro ni ọjọ Ọlọrun. Ọlọrun ri wipe ọpọ awọn ti wọn pe ara wọn ni eniyan Oun ko kọle fun igba ainipẹkun, ninu aanu Rẹ, O fẹ ran iṣẹ iranṣẹ ikilọ lati le ta wọn ji kuro ninu orun wọn, ati lati dari wọn lati le wa ni imura silẹ fun wiwa Oluwa.ANN 139.3

    A ri ikilọ yii ninu iwe Ifihan 14. Nibi ni a ti ri ipele iṣẹ iranṣẹ mẹta ti awọn ẹda lati ọrun wa n kede rẹ, ati pe lọgan lẹyin eyi, Ọmọ eniyan wá lati kore “ikore aye.” Akọkọ ninu awọn ikilọ yii kede idajọ ti n bọ. Woli naa ri angẹli kan ti n fo “ni agbede meji ọrun ti oun ti iyinrere ainipẹkun lati waasu fun awọn ti n gbe ori ilẹ aye, ati orilẹ ede, ati ẹya, ati ede, ati eniyan, o n wi ni ohun rara wipe, Bẹru Ọlọrun ki ẹ si fi ogo fun Un; nitori ti wakati idajọ Rẹ de: ki ẹ si sin Ẹni ti o da ọrun ati aye, ati okun, ati awọn orisun omi.” Ifihan 14:6, 7.ANN 139.4

    A sọ wipe iṣẹ iranṣẹ yii wa lara “iyinrere ainipẹkun.” A kò fun awọn angẹli ni iṣẹ iwaasu iyinrere, ṣugbọn awọn eniyan ni a fifun. A gba awọn angẹli mimọ laaye lati dari rẹ, wọn si ni aṣẹ lori awọn ẹgbẹ nla fun igbala awọn eniyan; ṣugbọn iṣẹ ikede iyinrere ni pato wà fun awọn iranṣẹ Kristi lori ilẹ aye.ANN 139.5

    Awọn olootọ eniyan, ti wọn ṣe igbọran si imisi ẹmi Ọlọrun ati awọn ikọni inu ọrọ Rẹ ni yoo kede ikilọ yii fun araye. Awọn ni awọn ti wọn tẹti si “ọrọ asọtẹlẹ ti o yè kooro,” “imọlẹ ti n tan ni ibi okunkun, titi ti ọjọ yoo fi yọ, ti irawọ owuro yoo fi yọ.” 2 Peteru 1:19. Wọn wa imọ Ọlọrun ju ohun iṣura ti o pamọ lọ, wọn ri wipe o “dara ju okoowo fadaka lọ, ati èrè rẹ ju wura didan lọ.” Owe 3:14. Oluwa fi awọn ohun nla ti ijọba han wọn. “Aṣiri Oluwa wa pẹlu awọn ti wọn bẹru Rẹ. Yoo si fi majẹmu Rẹ han fun wọn.” O. Dafidi 25:14ANN 139.6

    Ki i ṣe awọn ọjọgbọn ninu ẹkọ Ọlọrun ni wọn ni oye otitọ yii, tabi ti wọn ṣiṣẹ lati kede rẹ. Bi o ba jẹ wipe awọn wọnyi jẹ alore olootọ, ti wọn n fi pẹlẹkutu ati adura n kẹkọ Iwe Mimọ ni, wọn i ba mọ akoko òru; awọn asọtẹlẹ i ba fihan wọn awọn iṣẹlẹ to fẹ ṣẹlẹ. Ṣugbọn wọn ko duro ninu ipo yii, a si fi iṣẹ iranṣẹ naa fun awọn ti ko tó wọn. Jesu sọ wipe: “Ẹ rin nigba ti ẹyin ni imọlẹ, ki okunkun ma baa ba yin.” Johanu 12:35. Awọn ti wọn yiju kuro ninu imọlẹ ti Ọlọrun fifunni, tabi ti wọn kọ lati wa nigba ti o wà ni arọwọto wọn, wà ninu okunkun. Ṣugbọn Olugbala kede wipe: “Ẹnikẹni ti o ba tẹle Mi, ki yoo rin ninu okunkun, ṣugbọn yoo ni imọlẹ iye.” Johanu 8:12. Ẹnikẹni ti o ba fi tọkantọkan wa lati ṣe ifẹ Ọlọrun, ti o n fi tọkantọkan ṣe igbọran si imọlẹ ti a fifun, yoo gba imọlẹ nla si; a yoo ran irawọ ti n tan lati ọrun wa lati dari iru ọkan bẹẹ sinu gbogbo otitọ.ANN 139.7

    Ni igba ti Kristi wa ni akọkọ awọn alufa ati akọwe Ilu Mimọ, awọn ti a fi ọrọ Ọlọrun fun, i ba mọ awọn ami akoko ti wọn i ba si kede wiwa Ẹni ti a ti ṣeleri. Asọtẹlẹ Mika sọ nipa ibi ti a o bi I si; Daniẹli ṣe alaye igba wiwa Rẹ. Mika 5:2; Danieli 9:25. Ọlọrun gbe awọn asọtẹlẹ wọnyi le awọn adari Ju lọwọ; wọn wa ni airiwi bi wọn ko ba mọ, ki wọn si kede wipe wiwa Mesaya ti sunmọ etile. Aimọkan wọn jẹ abayori aika nnkan si, eyi ti i ṣe ẹṣẹ. Awọn Ju n kọ ohun iranti fun awọn woli Ọlọrun ti a pa, nigba ti wọn n fihan nipa itẹriba wọn fun awọn eniyan nla aye wipe wọn n jọsin awọn iranṣẹ Satani. Ija fun ipo ati agbara laarin awọn eniyan gba wọn lọkan, wọn fi oju fo ọla ọrun eyi ti Ọba ọrun fi n lọ wọn da.ANN 139.8

    Pẹlu ifẹ ọlọwọ, ti o jinlẹ, ni o yẹ ki awọn alagba Israeli fi kọ ẹkọ nipa ìbí, akoko, ati awọn ayika iṣẹlẹ ti o tobi julọ ninu itan aye—wiwa Ọmọ Ọlọrun lati pari iṣẹ irapada eniyan. O yẹ ki gbogbo awọn eniyan o sọna ki wọn si duro ki wọn baa le wà lara awọn ti yoo kọkọ ki Olurapada aye kaabọ. Ṣugbọn, kiyesi, ni Bẹtlẹhẹmu, awọn arinrinajo meji ti o rẹ lati awọn oke Nasareti rin gbogbo adugbo tooro lọ si iha ariwa opin ilu, wọn ko ri ibi isinmi ati ilé ìgbé fun aṣalẹ. A ko ṣi ilẹkun kankan silẹ lati gba wọn. Nikẹyin, wọn ri ibi aabo ninu agọ kan ti a pese silẹ fun malu, nibẹ si ni a bi Olugbala aye si.ANN 140.1

    Awọn angẹli ọrun ti ri ogo ti Ọmọ Ọlọrun ni pẹlu Baba ki aye o to wà, wọn si wọna pẹlu ifẹ gbigbona fun ifarahan Rẹ lori ilẹ aye gẹgẹ bi iṣẹlẹ ti o kun fun ayọ nla fun awọn eniyan. A ran awọn angẹli lati sọ iroyin ayọ naa fun awọn ti wọn ṣetan lati gba, ti wọn yoo si fi tayọtayọ sọ ọ fun awọn olugbe aye. Kristi ti rẹ ara Rẹ silẹ lati gbe ara eniyan wọ; yoo gbe ẹru wahala nla ti a ko le ṣalaye rù bi O ti n fi ọkan Rẹ ṣe etutu fun ẹṣẹ; sibẹ, ani ninu irẹsilẹ Rẹ, awọn angẹli n fẹ ki Ọmọ Ọga ogo O fi ara han niwaju eniyan pẹlu irisi ati ogo ti o wà ni ibamu pẹlu iwa Rẹ. Ṣe awọn eniyan nla aye yoo pejọ pọ si olu ilu Israeli lati ṣe ayẹsi wiwa Rẹ bi? Njẹ ọgọọrọ awọn angẹli ti wọn wa nibe yoo fihan awọn ẹgbẹ ti n wọna bi?ANN 140.2

    Angẹli kan bẹ aye wò lati wo awọn ti wọn mura silẹ lati ki Kristi kaabọ. Ṣugbọn ko ri ami wipe wọn reti Rẹ. Ko gbọ ohùn iyin ati iṣẹgun wipe akoko wiwa Mesaya ti sunmọ. Angẹli naa rababa fun igba diẹ lori ilu ti a yan ati tẹmpili nibi ti Ọlọrun ti fi ara Rẹ han fun ọpọ ọdun; ṣugbọn nibi, iru aibikita kan naa ni o wa. Awọn alufa, ninu iwuga ati igberaga wọn n ṣe irubọ ti o ti ni abawọn ninu tẹmpili. Awọn Farisi n ba awọn eniyan sọrọ pẹlu ohùn rara, tabi wọn n gbadura afunnu wọn ninu adugbo ilu. Ni aafin awọn ọba, ni apejọpọ awọn alarojinlẹ, ninu ile ẹkọ awọn rabbi, gbogbo wọn lapapọ ni ko kọbi ara si ohun iyanu ti o mu ayọ ati iyin kun gbogbo ọrun—wipe Olurapada eniyan ti fẹ fi ara han ninu aye.ANN 140.3

    Ko si ẹri kan wipe a n reti Kristi, ko si imurasilẹ kankan fun Ọmọ alade iye. Pẹlu iyalẹnu iranṣẹ lati ọrun fẹ pada si ọrun pẹlu iroyin atinilójú yii, nigba ti o ri ẹgbẹ awọn darandaran kan ti wọn n sọ agbo ẹran wọn ni alẹ, wọn n wo oju ọrun, wọn n ronu lori asọtẹlẹ nipa Mesaya ti yoo wa si aye, wọn n wọna fun dide Olurapada aye. Nibi ni a ti ri ẹgbẹ kan ti wọn ṣetan lati gba iṣẹ iranṣẹ lati ọrun. Lojiji angẹli Oluwa fi ara han, o n kede iroyin ayọ nla naa. Ogo ọrun mọlẹ si gbogbo ilẹ, ogunlọgọ awọn angẹli ti a ko le ka farahan, afi bi ẹnipe ayọ naa tobi ju fun iranṣẹ kan lati mu wa lati ọrun, ọpọ ìró ohùn bu yọ ninu orin ti gbogbo orilẹ ede ti a gbala yoo kọ lọjọ kan: “Ogo fun Ọlorun ni oke ọrun, ati lori ilẹ aye alaafia, inu rere si gbogbo eniyan.” Luku 2:14.ANN 140.4

    Ah iru ẹkọ wo ni itan agbayanu ti Bẹtlẹhẹmu yii jẹ! O ba aigbagbọ wa, igberaga wa ati iwa mototan wa wi. O ki wa nilọ lati ṣọra, ki a ma baa kuna lati mọ awọn ami akoko, ti ki yoo ni jẹ ki a mọ akoko ibẹwo wa, nitori aibikita wa.ANN 140.5

    Ki i ṣe ni ori awọn oke Judea nikan, ki i ṣe laarin awọn darandaran nikan ni awọn angẹli ti ri awọn ti n wọna fun wiwa Mesaya. Ni ilẹ awọn keferi pẹlu, a ri awọn ti wọn n wọna fun; wọn jẹ ọlọgbọn eniyan, wọn jẹ ọlọrọ, ijoye ni wọn, awọn alarojinlẹ lati iha ila oorun. Wọn ni oye nipa iṣẹda, awọn Amoye ri Ọlọrun ninu iṣẹ ọwọ Rẹ. Lati inu Iwe Mimọ Heberu wọn kọ nipa Irawọ kan ti yoo ti Jakobu jade wa, pẹlu ifẹ atọkanwa, wọn duro de wiwa Rẹ, Ẹni ti ki yoo jẹ “Itunu Israeli” nikan, ṣugbọn “Imọlẹ lati mọlẹ si awọn Keferi” ati “fun igbala titi de opin aye.” Luku 2:25, 32; Iṣe 13:47. Wọn n wa imọlẹ, imọlẹ lati itẹ Ọlọrun si tan si ọna ẹsẹ wọn. Nigba ti awọn alufa ati rabbi ni Jerusalẹmu, awọn ti a yan lati pa otitọ mọ ati lati ṣe itumọ rẹ, wà ninu okunkun, irawọ ti a ran lati Ọrun dari awọn Keferi ajeji wọnyi lọ si ibi ti a bi Ọba tuntun si.ANN 140.6

    Fun “awọn ti n wọna fun” ni Kristi yoo “farahan fun ni igbakeji, laisi ẹṣẹ si igbala.” Heberu 9:28. Gẹgẹ bi iroyin ìbí Olugbala, ki i ṣe awọn adari ẹsin ni a fi iṣẹ iranṣẹ ipadabọ lẹẹkeji fun. Wọn kuna lati daabo bo ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun, wọn si kọ imọlẹ lati ọrun silẹ; nitori naa, a ko ka wọn kun iye ti apostoli Pọlu ṣe alaye rẹ wipe: “Ṣugbọn ẹyin ara ko si ninu okunkun ki ọjọ naa ma baa ba yin bi ole. Ọmọ imọlẹ ni ẹyin i ṣe ati ọmọ ọsan: ẹ ki i ṣe ti oru tabi ti okunkun.” I Tẹsalonika 5:4, 5.ANN 141.1

    Awọn alore lori odi Sioni ni o yẹ ki wọn kọkọ gba iroyin wiwa Olugbala, ẹni akọkọ lati gbe ohun wọn soke lati kede wipe ó wa nitosi, ẹni akọkọ lati ṣe ikilọ fun awọn eniyan lati mura silẹ fun wiwa Rẹ. Ṣugbọn wọn wa ni ifọkanbalẹ, wọn lá àlá alaafia ati aabo, nigba ti awọn eniyan n sun ninu ẹṣẹ wọn. Jesu ri ijọ Rẹ, bi igi ọpọtọ ti ko ni eso, ti o kun fun ewé agabagebe, sibẹ, ko ni eso ti o ṣe iyebiye. Wọn fọnnu wipe wọn tẹle aṣa ẹsin, ṣugbọn wọn ko ni—ẹmi irẹlẹ nitootọ, ironupiwada ati igbagbọ eyi kan ṣoṣo ti o le jẹ ki isin wọn o jẹ itẹwọgba ni ọdọ Ọlọrun. Dipo awọn ẹbun Ẹmi, wọn fi igberaga, aṣa, ògo asán, imọ-ti-ara-ẹni-nikan ati ininilara han. Ijọ ti o n fa sẹyin di oju rẹ si awọn ami akoko. Ọlọrun ko kọ wọn silẹ, bẹẹ ni ko jẹ ki ododo Rẹ o baku; ṣugbọn wọn yà kuro ni ọdọ Rẹ, wọn si pin ara wọn niya kuro ni ọdọ ifẹ Rẹ. Nitori ti wọn kọ lati ṣe ohun ti o yẹ, awọn ileri ibukun Rẹ ko le ṣẹ si wọn lara.ANN 141.2

    Iru atubọtan bayi ni o maa n tẹle ainaani ati aiṣiṣẹ lori imọlẹ ati anfani ti Ọlọrun fifunni. Ayafi bi ijọ ba tẹsiwaju lati tẹle iṣeun Rẹ, ti wọn n gba gbogbo itansan imọlẹ, ti wọn n ṣe gbogbo ojuṣe ti a fihan, laiṣe bẹẹ, ẹsin yoo fasẹyin di ṣiṣe aṣa lasan, ti ẹmi iwabiọlọrun ti o ṣe pataki yoo si poora. Lati igba de igba ni otitọ yii ti n fi ara han ninu itan ijọ. Ọlọrun fẹ ki awọn eniyan Rẹ o fi iṣẹ igbagbọ han ati igbọran ti o wa ni ibamu pẹlu ibukun ati anfani ti a fifun wọn. Igbọran nilo irubọ ati agbelebu; idi si ni yii ti ọpọlọpọ ti wọn pe ara wọn ni atẹle Kristi fi kọ lati gba imọlẹ lati ọrun, ati bi i ti awọn Ju igbaani, wọn kò mọ igba ibẹwo wọn. Luku 19:44. Nitori igberaga ati aigbagbọ wọn, Oluwa ré wọn kọja, O si fi otitọ Rẹ han fun awọn, bi i ti awọn oluṣọ aguntan ti Bẹtlẹhẹmu ati awọn Amoye lati iha ila oorun wa, ti wọn ṣe igbọran si gbogbo imọlẹ ti wọn gba.ANN 141.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents